‘Fífi Ọwọ́ Títọ̀nà Mú Ọ̀rọ̀ Òtítọ́’
Ọ̀RỌ̀ Ọlọrun kún fún àwọn ìlànà tí ó ṣe pàtàkì fún àṣeyọrí ìgbésí ayé. Ó lè ran òjíṣẹ́ kan lọ́wọ́ láti kọ́ni, láti báni wí, àti láti tọ́ni sọ́nà. (2 Timoteu 3:16‚ 17) Ṣùgbọ́n, láti lè jàǹfààní kíkún láti inú ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá yìí, a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn aposteli Paulu sí Timoteu pé: “Sa gbogbo ipá rẹ lati fi ara rẹ hàn fún Ọlọrun ní ẹni tí a fi ojúrere tẹ́wọ́gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan lati tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—2 Timoteu 2:15.
Ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn, a fi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wé wàrà tí ń ṣara lóore, oúnjẹ líle, omi tí ń tuni lára tí ó sì ń wẹni mọ́, jígí, àti idà mímú. Lílóye ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí yóò ran òjíṣẹ́ kan lọ́wọ́ láti fòye lo Bibeli.
Pípín Wàrà Ọ̀rọ̀ Ọlọrun
Oúnjẹ tí àwọn ìkókó nílò ni wàrà. Bí ìkókó náà ti ń dàgbà, a óò bẹ̀rẹ̀ sí í fi oúnjẹ líle kún oúnjẹ rẹ̀ díẹ̀díẹ̀, ṣùgbọ́n lákọ̀ọ́kọ́ ná, kìkì wàrà ni ó lè dà lára rẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà, àwọn tí wọ́n mọ ohun díẹ̀ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọrun dà bí ìkókó. Yálà ẹnì kan ṣẹ̀ṣẹ̀ ń lọ́kàn-ìfẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tàbí tí ó ti mọ̀ nípa rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, bí kò bá mọ̀ ju àwọn òye ìpìlẹ̀ nípa ohun tí Bibeli sọ lọ, ó ṣì jẹ́ ìkókó nípa tẹ̀mí, ó sì nílò oúnjẹ tí ó lè tètè dà—“wàrà” tẹ̀mí. “Oúnjẹ líle,” àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, kò tí ì lè dà lára rẹ̀.—Heberu 5:12.
Bí ipò nǹkan ti rí nìyí ní ìjọ Korinti tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀, nígbà tí Paulu kọ̀wé sí wọn pé: “Wàrà ni mo fi bọ́ yín, kì í ṣe nǹkan lati jẹ, nitori ní àkókò yẹn ẹ̀yin kò tí ì lókun tó.” (1 Korinti 3:2) Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn ará Korinti ní láti kọ́ “awọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ninu awọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́-ọlọ́wọ̀ ti Ọlọrun.” (Heberu 5:12) Níbi tí wọ́n dàgbà dé, “awọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọrun” kò lè yé wọn.—1 Korinti 2:10.
Bíi Paulu, àwọn Kristian òjíṣẹ́ lónìí ń fi àníyàn wọn fún àwọn ìkókó nípa tẹ̀mí hàn nípa fífún wọn ní “wàrà,” ìyẹn ni, nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-ingbọn-in nínú ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Kristian. Wọ́n ń fún irú àwọn ẹni tuntun tàbí àwọn tí kò dàgbà dénú bẹ́ẹ̀ ní ìṣírí láti ‘yánhànhàn fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ naa.’ (1 Peteru 2:2) Aposteli Paulu fi hàn pé òún fòye mọ àkànṣe àfiyèsí tí àwọn ẹni tuntun nílò nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń mu ninu wàrà jẹ́ aláìdojúlùmọ̀ ọ̀rọ̀ òdodo, nitori tí ó jẹ́ ìkókó.” (Heberu 5:13) A ń béèrè sùúrù, ìgbatẹnirò, òye àti ìwà pẹ̀lẹ́ lọ́wọ́ àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun bí wọ́n ti ń ṣàjọpín wàrà Ọ̀rọ̀ mímọ́ gaara náà pẹ̀lú àwọn ẹni tuntun àti àwọn aláìnírìírí, nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé àti nínú ìjọ.
Lílo Oúnjẹ Líle Ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun
Fún Kristian kan láti dàgbà dé ipò rírí ìgbàlà, ó nílò ju “wàrà” lọ. Níwọ̀n bí ó bá ti lóye àwọn òtítọ́ ìpìlẹ̀ Bibeli kedere, tí ó sì tẹ́wọ́ gbà wọ́n, ó ti ṣe tán láti lọ sórí ‘oúnjẹ lílé tí ó wà fún àwọn tí ó dàgbà dénú.’ (Heberu 5:14) Báwo ni ó ṣe lè ṣe èyí? Ní pàtàkì, ó jẹ́ nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ déédéé àti ìkẹ́gbẹ́pọ̀ ní àwọn ìpàdé Kristian. Irú àṣà dídára bẹ́ẹ̀ yóò mú kí Kristian kan lágbára nípa tẹ̀mí, kí ó dàgbà dénú, kí ó sì gbéṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. (2 Peteru 1:8) Kí a má ṣe gbàgbé pé, ní àfikun sí ìmọ̀, ṣiṣẹ ìfẹ́ Jehofa pẹ̀lú wà nínú oúnjẹ nípa tẹ̀mí.—Johannu 4:34.
Lónìí, a ti yan “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” láti fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ní oúnjẹ ní àkókò tí ó tọ́ àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye “ọ̀pọ̀ oríṣiríṣi ọgbọ́n Ọlọrun.” Nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀, Jehofa ṣí àwọn ìjìnlẹ̀ òtítọ́ Ìwé Mímọ́ payá nípasẹ̀ àwọn ẹrú rẹ̀ adúróṣinṣin yìí, tí ń fòtítọ́ tẹ “oúnjẹ” tẹ̀mí jáde “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu.” (Matteu 24:45-47; Efesu 3:10‚ 11; fi wé Ìṣípayá 1:1‚ 2.) Kristian kọ̀ọ̀kan ni ó ní ẹrù iṣẹ́ láti lo ìpèsè tí a ń tẹ̀ jáde bẹ́ẹ̀ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.—Ìṣípayá 1:3.
Dájúdájú, àwọn ohun kan wà nínú Bibeli tí ó “nira lati lóye,” àní fún àwọn Kristian tí wọ́n dàgbà dénú pàápàá. (2 Peteru 3:16) Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó rúni lójú, àwọn àsọtẹ́lẹ̀, àti àwọn àkàwé wà tí ń béèrè ìkẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ àti àṣàrò. Nítorí náà, ìdákẹ́kọ̀ọ́ ní wíwalẹ̀ lọ sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun nínú. (Owe 1:5, 6; 2:1-5) Ní ti ọ̀ràn yìí, àwọn alàgbà ní pàtàkì ní ẹrù iṣẹ́, nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ ìjọ. Yálà nígbà tí wọ́n bá ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tàbí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà, tí wọ́n bá ń sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn, tàbí tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ kíkọ́ni mìíràn, àwọn alàgbà ní láti lóye ohun tí wọ́n ń sọ gidigidi, kí wọ́n sì ṣe tán láti fi àfiyèsí sí “ọgbọ́n-ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” wọn, bí wọ́n ti ń fún ìjọ ní oúnjẹ líle nípa tẹ̀mí.—2 Timoteu 4:2.
Omi Tí Ń Tuni Lára Tí Ó Sì Ń Wẹni Mọ́
Jesu sọ fun obìnrin ará Samaria ní etí kànga pé, òun yóò fún un ní omi tí yóò mu, tí yóò di “ìsun omi ninu rẹ̀ tí ń tú yàà sókè lati fi ìyè àìnípẹ̀kun fúnni.” (Johannu 4:13‚ 14; 17:3) Omi tí ń fúnni ní ìyè yìí ní gbogbo ìpèsè Ọlọrun fún jíjèrè ìyè nípasẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọrun nínú, a sì ṣàlàyé àwọn ìpèsè wọ̀nyí nínú Bibeli. Gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan tí òùngbẹ “omi” náà ń gbẹ, a tẹ́wọ́ gba ìkésíni tí ẹ̀mí àti ìyàwó Kristi fún wa láti “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣípayá 22:17) Mímu omi yìí lè túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun.
Síwájú sí i, Bibeli fi àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù àti tẹ̀mí lélẹ̀ fún àwọn Kristian tòótọ́. Bí a ti ń lo àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n àtọ̀runwá tí a là sílẹ̀ wọ̀nyí, Ọ̀rọ̀ Jehofa ń wẹ̀ wá mọ́, ó ‘ń sọ wa di mímọ́’ kúrò nínú gbogbo ìṣe tí Jehofa Ọlọrun kórìíra. (1 Korinti 6:9-11) Nítorí ìdí èyí, a pe òtítọ́ tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ tí a mí sí ní “ìwẹ̀ omi.” (Efesu 5:26) Bí a kò bá yọ̀ọ̀da fún òtítọ́ Ọlọrun láti wẹ̀ wá mọ́ ní ọ̀nà yìí, òun kì yóò tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa.
Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, a fi àwọn alàgbà tí “ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́” wé omi pẹ̀lú. Isaiah sọ pé wọ́n dà “bí odò omi ní ibi gbígbẹ.” (Isaiah 32:1, 2) Àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ ń bá àpèjúwe yìí mu nígbà tí wọ́n bá ṣèbẹ̀wò sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn nípa tẹ̀mí, tí wọ́n lo Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ń tuni lára láti fún wọn ní ìsọfúnni nípa tẹ̀mí tí ń gbéni ró, tí ń tuni nínú, tí ń fúnni lókun, tí ó sì ń dáàbò boni.—Fi wé Matteu 11:28, 29.a
Àwọn mẹ́ḿbà ìjọ máa ń fojú sọ́nà fún ìbẹ̀wò àwọn alàgbà. Bonnie sọ pé: “Mo mọ bí àwọn alàgbà ti ń tuni lára tó, mo sì láyọ̀ pé Jehofa ṣe ìpèsè yìí.” Lynda, ìyá anìkàntọ́mọ, kọ̀wé pé: “Pẹ̀lú ìṣírí Ìwé Mímọ́, àwọn alàgbà ràn mí lọ́wọ́ láti kojú rẹ̀. Wọ́n tẹ́tí sílẹ̀ wọ́n sì fi ìyọ́nú hàn.” Michael sọ pé: “Wọ́n jẹ́ kí n nímọ̀lára pé mo jẹ́ apá kan ètò àjọ kan tí ó bìkítà.” Òmíràn sọ pé: “Ìbẹ̀wò àwọn alàgbà ràn mí lọ́wọ́ láti borí àwọn àkókò ìsoríkọ́ líle koko.” Ìbẹ̀wò tí ń gbéni ró nípa tẹ̀mí tí alàgbà kan ṣe dà bí omi tútù, tí ń tuni lára. A ń tu àwọn ẹni bí àgùntàn nínú bí àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí bí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ ti bá ipò wọn mu.—Romu 1:11‚ 12; Jakọbu 5:14.
Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Bíi Jígí
Nígbà tí ẹnì kan bá ń jẹ oúnjẹ líle, ète náà kì í ṣe kìkì láti gbádùn adùn rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń retí láti rí ohun tí ń ṣara lóore, tí yóò mú kí ó lè ṣiṣẹ́. Bí ó bá jẹ́ ọmọdé, ó ń retí pé kí oúnjẹ náà ran òun lọ́wọ́ láti dàgbà di géńdé. Bí ó ti rí pẹ̀lú oúnjẹ tẹ̀mí nìyẹn. Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lè gbádùn mọ́ni, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìdí rẹ̀ nìkan nìyẹn. Oúnjẹ tẹ̀mí yẹ kí ó yí wa padà. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ èso tẹ̀mí, kí a sì mú un dàgbà, ó sì tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ‘àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ẹni tí ó dá a.’ (Kolosse 3:10; Galatia 5:22-24) Oúnjẹ tẹ̀mí tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà dénú, ó ń mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti lo àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ lọ́nà tí ó dára ní kíkojú àwọn ìṣòro wa àti ní ríran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti kojú tiwọn.
Báwo ni a ṣe lè mọ̀ bóyá Bibeli ń ní irú ipa bẹ́ẹ̀ lórí wa? A lè lo Bibeli gẹ́gẹ́ bíi jígí. Jakọbu sọ pé: “Ẹ di olùṣe ọ̀rọ̀ naa, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan . . . Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ naa, tí kò sì jẹ́ olùṣe, ẹni yii dàbí ènìyàn kan tí ń wo ojú àdánidá rẹ̀ ninu jígí. Nitori ó wo ara rẹ̀, ó sì lọ kúrò ati lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó gbàgbé irú ènìyàn tí oun jẹ́. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé naa tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn, ẹni yii, nitori tí oun kò di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, bíkòṣe olùṣe iṣẹ́ naa, yoo láyọ̀ ninu ṣíṣe é.”—Jakọbu 1:22-25.
A ń wo inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní “àwòfín” nígbà tí a bá ń yẹ̀ ẹ́ wò dáradára, tí a sì ń fi ohun tí a jẹ́ wé ohun tí ó yẹ kí a jẹ́, ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọrun. Ní ṣiṣe èyí, a óò di “olùṣe ọ̀rọ̀ naa, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan.” Bibeli yóò máa ní ipa dídára lórí wa.
Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Gẹ́gẹ́ Bí Idà
Paríparí rẹ̀, aposteli Paulu ràn wá lọ́wọ́ láti rí bí a ṣe lè lo Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí idà. Nígbà tí ó ń kìlọ̀ fún wà lòdì sí “awọn alákòóso, lòdì sí awọn aláṣẹ, lòdì sí awọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yii, lòdì sí awọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní awọn ibi ọ̀run,” ó rọ̀ wá láti “tẹ́wọ́gba . . . idà ẹ̀mí, èyíinì ni, ọ̀rọ̀ Ọlọrun.” (Efesu 6:12‚ 17) Ọ̀rọ̀ Ọlọrun jẹ́ ohun ìjà ogun tí a kò lè ṣàìní, tí a lè lò láti mú èrò èyíkéyìí tí a bá “gbé dìde lòdì sí ìmọ̀ Ọlọrun” kúrò.—2 Korinti 10:3-5.
Láìṣe àní àní, “ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè ó sì ń sa agbára.” (Heberu 4:12) Jehofa ń lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a mí sí láti bá aráyé sọ̀rọ̀. Lò ó lọ́nà rere láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn àti láti túdìí àṣírí ẹ̀kọ́ ìsìn èké. Lò ó láti funni níṣìírí, gbéni ró, fúnni nítura, tuni nínú, súnni ṣiṣẹ́, àti láti fún àwọn ẹlòmíràn lókun nípa tẹ̀mí. Ǹjẹ́ kí Jehofa ‘fi ohun rere gbogbo mú ọ gbaradì lati ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀,’ kí o baà lè máa ṣe ohun tí ó “wuni gidigidi ní ojú rẹ̀.”—Heberu 13:21.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà tí ó ní àkọlé náà, “Wọ́n Ń Fi Ìyọ́nú Ṣolùṣọ́ Àwọn Àgùtàn Kékeré Náà,” September 15, 1993, ojú ìwé 20 sí 23.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwọn alàgbà ń fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí, ‘ní fífi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́’