Àìsáyà
2 Ẹnì kọ̀ọ̀kan máa dà bí ibi tó ṣeé fara pa mọ́ sí* kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù,
Ibi ààbò* kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò,
Bí omi tó ń ṣàn ní ilẹ̀ tí kò lómi,+
Bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ tó gbẹ táútáú.
3 Ojú àwọn tó ń ríran kò ní lẹ̀ pọ̀ mọ́,
Etí àwọn tó ń gbọ́ràn sì máa ṣí sílẹ̀.
4 Ọkàn àwọn tí kì í fara balẹ̀ máa ronú nípa ìmọ̀,
Ahọ́n tó sì ń kólòlò máa sọ̀rọ̀ tó já geere, tó sì ṣe kedere.+
5 Wọn ò tún ní pe aláìnírònú ní ọ̀làwọ́ mọ́,
Wọn ò sì ní pe oníwàkiwà ní èèyàn pàtàkì mọ́;
6 Torí aláìnírònú máa sọ̀rọ̀ òmùgọ̀,
Ọkàn rẹ̀ sì máa gbèrò ibi,+
Láti gbé ìpẹ̀yìndà lárugẹ,* kó sì máa sọ ọ̀rọ̀kọrọ̀ sí Jèhófà,
Láti mú kí ẹni tí ebi ń pa* wà láìjẹun,
Kó sì fi ohun mímu du ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ.
7 Ohun búburú ni ọkùnrin oníwàkíwà ń gbèrò;+
Ìwà àìnítìjú ló ń gbé lárugẹ,
Kó lè fi irọ́ ba ti ẹni tí ìyà ń jẹ jẹ́,+
Kódà nígbà tí aláìní bá ń sọ ohun tó tọ́.
9 “Ẹ̀yin obìnrin tí ara tù, ẹ dìde, kí ẹ fetí sí ohùn mi!
Ẹ̀yin ọmọbìnrin+ tí ẹ ò ka nǹkan sí, ẹ fiyè sí ohun tí mò ń sọ!
10 Láàárín ọdún kan ó lé díẹ̀, jìnnìjìnnì máa bá ẹ̀yin tí ẹ ò ka nǹkan sí,
Torí a ò ní tíì kó èso kankan jọ nígbà tí ìkórè èso àjàrà bá dópin.+
11 Ẹ wárìrì, ẹ̀yin obìnrin tí ara tù!
Ẹ gbọ̀n jìnnìjìnnì, ẹyin tí kò ka nǹkan sí!
12 Ẹ lu ọmú yín bí ẹ ṣe ń dárò
Torí àwọn pápá tí ẹ fẹ́ràn àti àjàrà tó ń méso jáde.
13 Torí ẹ̀gún àti òṣùṣú máa bo ilẹ̀ àwọn èèyàn mi;
Wọ́n máa bo gbogbo ilé tí wọ́n ti ń yọ̀,
Àní, ìlú tó ń yọ̀ gidigidi.+
Ófélì+ àti ilé ìṣọ́ ti di ahoro títí láé,
Ààyò àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó,
Ibi ìjẹko àwọn agbo ẹran,+
15 Títí dìgbà tí a bá tú ẹ̀mí jáde sórí wa látòkè,+
Tí aginjù di ọgbà eléso,
Tí a sì ka ọgbà eléso sí igbó.+
17 Àlàáfíà ni òdodo tòótọ́ máa mú wá, +
Èso òdodo tòótọ́ sì máa jẹ́ ìparọ́rọ́ àti ààbò tó máa wà pẹ́ títí.+
18 Ibi tí àlàáfíà ti jọba làwọn èèyàn mi á máa gbé,
Nínú àwọn ibi tó ní ààbò àtàwọn ibi ìsinmi tó pa rọ́rọ́.+
19 Àmọ́ yìnyín máa mú kí igbó tẹ́ pẹrẹsẹ,
Ìlú sì máa di ibi tó tẹ́jú pátápátá.