Orí Kìíní
Ìṣọ̀kan Ìjọsìn ní Àkókò Wa—Kí Ló Túmọ̀ Sí?
1, 2. (a) Ohun tó ń wúni lórí wo ló ń ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ wa? (b) Ìrètí àgbàyanu wo làwọn olóòótọ́ ọkàn ní?
KÁRÍ ayé, àwọn èèyàn kan ń kóra jọ pọ̀ lọ́nà tó ń wúni lórí láti jọ́sìn ní ìṣọ̀kan. Jíjọ́sìn ní ìṣọ̀kan yìí ń so ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ènìyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà àti èdè pọ̀. Ọdọọdún sì ni ọ̀pọ̀ ń dara pọ̀ mọ́ wọn. Àwọn tá à ń sọ yìí ni Bíbélì pè ní àwọn “ẹlẹ́rìí” Jèhófà ó sì tún pè wọ́n ní “ogunlọ́gọ̀ ńlá.” Wọ́n ń ṣe “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún [Ọlọ́run] tọ̀sán-tòru.” (Aísáyà 43:10-12; Ìṣípayá 7:9-15) Kí ló ń mú wọn ṣe èyí? Ìdí ni pé wọ́n ti mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà. Èyí ń sún wọn láti mú ìgbésí ayé wọn bá àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ mu. Bákan náà, wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé búburú ìsinsìnyí ni à ń gbé, pé Ọlọ́run máa tóó pa á run, tí yóò sì fi ayé tuntun rẹ̀ tó jẹ́ Párádísè rọ́pò rẹ̀.—2 Tímótì 3:1-5, 13; 2 Pétérù 3:10-13.
2 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:10, 11) “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.
3. Báwo ni ìṣọ̀kan tòótọ́ nínú ìjọsìn ṣe ń wáyé?
3 Àwọn tí à ń mú ṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́ nísinsìnyí ni yóò kọ́kọ́ máa gbé inú ayé tuntun yẹn. Wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́, wọ́n sì ń ṣe é dé gbogbo ibi tí agbára wọn gbé e dé. Nígbà tí Jésù ń fi bí èyí ṣe ṣe pàtàkì tó hàn, ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17.
Ìtumọ̀ Rẹ̀ Gan-an
4. (a) Kí ni kíkó ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn jọ sínú ìjọsìn tó ṣọ̀kan túmọ̀ sí gan-an ní ọjọ́ wa? (b) Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ìkójọpọ̀ yìí?
4 Kí tiẹ̀ ni kíkó ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn jọ sínú ìjọsìn tó ṣọ̀kan ní ọjọ́ wa túmọ̀ sí gan-an ná? Ó jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere pé a ti sún mọ́ òpin ayé búburú yìí gidigidi àti pé kété lẹ́yìn náà ayé tuntun Ọlọ́run á tẹ̀ lé e. À ń fojú rí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó sọ nípa ìkójọpọ̀ pàtàkì yìí. Ọ̀kan lára irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ sọ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́ [àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí] pé òkè ńlá ilé Jèhófà [ìjọsìn tòótọ́ rẹ̀ tí a gbé ga] yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá [yóò ga ju ìsìn èyíkéyìí mìíràn lọ], . . . àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ́ tìrítìrí lọ síbẹ̀. Dájúdájú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò lọ, wọn yóò sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà àti sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù; òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.’”—Míkà 4:1, 2; Sáàmù 37:34.
5, 6. (a) Báwo ló ṣe jẹ́ òótọ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè ń yí padà sọ́dọ̀ Jèhófà? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ́ ká bi ara wa?
5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè lápapọ̀ kọ̀ láti wá sínú ilé tẹ̀mí Jèhófà fún ìjọsìn, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ète onífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àti àkópọ̀ ìwà rẹ̀ tí ń fani mọ́ra, wọ́n ń fi tọkàntọkàn ṣe ohun tí ó yẹ. Tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ni wọ́n fi ń fẹ́ láti mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe. Àdúrà wọn rí bíi ti onísáàmù náà, ẹni tó sọ pé: “Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí pé ìwọ ni Ọlọ́run mi.”—Sáàmù 143:10.
6 Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo ara rẹ láàárín àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ènìyàn tí Jèhófà ń kó jọ pọ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí sínú ìjọsìn tá a mú ṣọ̀kan? Ǹjẹ́ bí o ṣe ń fi ìtọ́ni tí o ti gbà látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò fi hàn pé òótọ́ lo mọyì pé Jèhófà ni Orísun rẹ̀? Báwo ni wà á ṣe “rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀” pẹ́ tó?
Bí Ọwọ́ Ṣe Lè Tẹ̀ Ẹ́
7. (a) Báwo ni ìṣọ̀kan ìjọsìn á ṣe gbòòrò tó lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn? (b) Èé ṣe tó fi jẹ́ kánjúkánjú láti di olùjọsìn Jèhófà nísinsìnyí, báwo la sì ṣe lè ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?
7 Ète Jèhófà ni pé kí gbogbo ẹ̀dá onílàáákàyè ṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́. A mà ń fojú sọ́nà gidigidi de ọjọ́ náà o, nígbà tí gbogbo àwọn tó wà láàyè yóò máa jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà! (Sáàmù 103:19-22) Àmọ́ kí ìyẹn tó ṣẹlẹ̀, Jèhófà yóò mú gbogbo àwọn tó kọ̀ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ tá a gbé karí òdodo, kúrò. Nínú àánú rẹ̀, ó pèsè ìkìlọ̀ ṣáájú nípa ohun tó máa ṣe, kí àwọn ènìyàn níbi gbogbo lè ní àǹfààní láti yí ìwà wọn padà. (Aísáyà 55:6, 7) Ìdí rèé tí ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ kánjúkánjú yìí fi ń lọ sọ́dọ̀ “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn” ní ọjọ́ wa pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé, nítorí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.” (Ìṣípayá 14:6, 7) Ṣé ìwọ náà ti tẹ́wọ́ gba ìkésíni yẹn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àǹfààní ló jẹ́ fún ọ láti tún ké sí àwọn mìíràn láti wá mọ Ọlọ́run tòótọ́ náà kí wọ́n sì jọ́sìn rẹ̀.
8. Lẹ́yìn tá a bá ti kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì, ìtẹ̀síwájú wo ló yẹ ká fi taratara sapá láti ní?
8 Jèhófà kò fẹ́ àwọn olùjọsìn tí wọ́n á máa fẹnu lásán sọ pé àwọn gba òun gbọ́ àmọ́ tí wọ́n ṣì ń bá a lọ láti máa ṣe ìfẹ́ inú tara wọn. Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn èèyàn ní “ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ rẹ̀” kí wọ́n sì fi èyí hàn nínú ìgbésí ayé wọn. (Kólósè 1:9, 10) Abájọ tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn táwọn èèyàn tó mọrírì bá ti mọ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ Bíbélì tán, wọ́n tún máa ń fẹ́ ẹ́ tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú Kristẹni. Ìfẹ́ ọkàn wọn ni pé kí wọ́n túbọ̀ mọ Jèhófà dáadáa, kí wọ́n mú òye wọn nípa Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pọ̀ sí i, kó sì jinlẹ̀ sí i, kí wọ́n sì túbọ̀ fi sílò ní kíkún nínú ìgbésí ayé wọn. Wọ́n ń gbìyànjú láti ní àwọn ànímọ́ Baba wa ọ̀run kí wọ́n sì máa wo àwọn nǹkan lọ́nà tó ń gbà wò wọ́n. Èyí ń sún wọn láti máa wá àwọn ọ̀nà láti kópa nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà tí Jèhófà ti ṣètò pé kí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ ṣe lórí ilẹ̀ ayé ní ọjọ́ wa. Ṣe ìyẹn lohun tó wà lọ́kàn ìwọ náà?—Máàkù 13:10; Hébérù 5:12-6:3.
9. Àwọn ọ̀nà wo ni ìṣọ̀kan tòótọ́ fi lè ṣeé ṣe nísinsìnyí?
9 Bíbélì fi hàn pé gbogbo àwọn tó ń sin Jèhófà gbọ́dọ̀ wà ní ìṣọ̀kan. (Éfésù 4:1-3) Ìṣọ̀kan yìí ní láti wáyé nísinsìnyí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń gbé nínú ayé tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ tá a sì tún ń bá àwọn àìpé tiwa fúnra wa jìjàkadì. Jésù fi taratara gbàdúrà pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun jẹ́ ọ̀kan, kí wọ́n gbádùn ìṣọ̀kan tòótọ́. Kí lèyí máa túmọ̀ sí? Àkọ́kọ́, pé wọ́n á ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀. Èkejì, pé ìṣọ̀kan á wà láàárín wọn. (Jòhánù 17:20, 21) Láti lè mú kí èyí ṣeé ṣe, ìjọ Kristẹni ni ètò àjọ tí Jèhófà ń lò láti kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.
Àwọn Ohun Wo Ló Túbọ̀ Ń Jẹ́ Kí Ìṣọ̀kan Wà?
10. (a) Kí ni à ń mú dàgbà nígbà tá a bá fúnra wa lo Bíbélì láti wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó kàn wá? (b) Ṣàyẹ̀wò ní kínníkínní, àwọn ohun tó ń jẹ́ kí ìṣọ̀kan Kristẹni wà nípa dídáhùn àwọn ìbéèrè tá a tò sísàlẹ̀ ìpínrọ̀ yìí.
10 Àwọn ohun méje pàtàkì tó túbọ̀ ń jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà nínú ìjọsìn la kọ sísàlẹ̀ yìí. Bó o ti ń dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọn, ronú lórí bí kókó kọ̀ọ̀kan ṣe kan àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ. Ríronú lórí àwọn ohun wọ̀nyí àti ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí àmọ́ tá ò fa ọ̀rọ̀ wọn yọ yóò jẹ́ kó o túbọ̀ ní àwọn ànímọ́ tí gbogbo wa nílò, tí í ṣe ọgbọ́n tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ìmọnúúrò àti ìfòyemọ̀. (Òwe 5:1, 2; Fílípì 1:9-11) Gbé àwọn kókó wọ̀nyí yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.
(1) A gbà pé Jèhófà ló ni ẹ̀tọ́ láti gbé àwọn ìlànà kalẹ̀ ní ti ohun tó dára àti ohun tó burú. “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6.
Èé ṣe tó fi yẹ ká wá ìmọ̀ràn Jèhófà àti ìtọ́sọ́nà rẹ̀ nígbà tá a bá ń ṣe àwọn ìpinnu? (Sáàmù 146:3-5; Aísáyà 48:17)
(2) A ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti tọ́ wa sọ́nà. “Nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ pẹ̀lú nínú ẹ̀yin onígbàgbọ́.”—1 Tẹsalóníkà 2:13.
Ewu wo ló wà nínú ṣíṣe ohun kan tí a kàn “rò” pé ó dára? (Òwe 14:12; Jeremáyà 10:23, 24; 17:9)
Bá ò bá mọ ìmọ̀ràn tí Bíbélì pèsè lórí ọ̀ràn kan pàtó, kí ló yẹ ká ṣe? (Òwe 2:3-5; 2 Tímótì 3:16, 17)
(3) Gbogbo wa là ń jàǹfààní látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ oúnjẹ tẹ̀mí kan náà. ‘Gbogbo ọmọ rẹ yóò jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.’ (Aísáyà 54:13) “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.”—Hébérù 10:24, 25.
Àwọn àǹfààní wo ni àwọn tó ń lo ìpèsè tẹ̀mí tí Jèhófà ṣe lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ń gbádùn? (Aísáyà 65:13, 14)
(4) Jésù Kristi ni Aṣáájú wa, kì í ṣe ẹ̀dá ènìyàn kankan. “Kí a má ṣe pè yín ní Rábì, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín, nígbà tí ó jẹ́ pé arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín lórí ilẹ̀ ayé, nítorí ọ̀kan ni Baba yín, Ẹni ti ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni kí a má pè yín ní ‘aṣáájú,’ nítorí ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi.”—Mátíù 23:8-10.
Ṣé ó yẹ kí ẹnikẹ́ni nínú wa máa ronú pé òun sàn ju àwọn mìíràn lọ? (Róòmù 3:23, 24; 12:3)
(5) Ìjọba Ọlọ́run ni à ń wò pé ó jẹ́ ìrètí kan ṣoṣo tí aráyé ní. “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’ Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.”—Mátíù 6:9, 10, 33.
Báwo ni ‘wíwá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́’ ṣe ń ṣèrànwọ́ láti dáàbò bo ìṣọ̀kan wa? (Míkà 4:3; 1 Jòhánù 3:10-12)
(6) Ẹ̀mí mímọ́ máa ń jẹ́ kí àwọn olùjọsìn Jèhófà ní àwọn ànímọ́ tó ṣe kókó fún ìṣọ̀kan Kristẹni. “Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.”—Gálátíà 5:22, 23.
Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí ẹ̀mí Ọlọ́run lè mú àwọn èso rẹ̀ jáde nínú wa? (Ìṣe 5:32)
Báwo ni níní ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ń nípa lórí àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa? (Jòhánù 13:35; 1 Jòhánù 4:8, 20, 21)
(7) Gbogbo àwọn olóòótọ́ olùjọsìn Ọlọ́run máa ń lọ́wọ́ nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba rẹ̀. “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14.
Kí lohun tó yẹ kó máa sún wa láti fẹ́ kópa ní kíkún nínú iṣẹ́ ìwàásù yìí? (Mátíù 22:37-39; Róòmù 10:10)
11. Nígbà tá a bá fi àwọn òtítọ́ Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wa, kí ló máa yọrí sí?
11 Jíjọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan túbọ̀ ń mú wa sún mọ́ ọn ó sì ń jẹ́ ká lè gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ alárinrin pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Sáàmù 133:1 sọ pé: “Wò ó! Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!” Ẹ ò rí i pé ó ń tuni lára gan-an láti yàgò fún ayé pẹ̀lú gbogbo ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan rẹ̀, ìṣekúṣe rẹ̀ àti ìwà ipá rẹ̀ ká sì pé jọ pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ní tòótọ́ tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀!
Yàgò fún Àwọn Ohun Tó Lè Fa Ìpínyà
12. Kí ni ìdí tó fi yẹ ká yàgò fún ẹ̀mí láti fẹ́ dá wà lómìnira?
12 A gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn ohun tó lè fa ìpínyà ká má bàa ba ìṣọ̀kan wa kárí ayé tó ṣeyebíye jẹ́. Ọ̀kan lára wọn ni fífẹ́ láti wà lómìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run àtàwọn òfin rẹ̀. Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ láti yàgò fún ẹ̀mí yìí nípa jíjẹ́ ká mọ ẹni tó jẹ́ olùdásílẹ̀ rẹ̀, ìyẹn Sátánì Èṣù. (2 Kọ́ríńtì 4:4; Ìṣípayá 12:9) Sátánì lẹni tó mú kí Ádámù àti Éfà dágunlá sí ohun tí Ọlọ́run sọ fún wọn tí wọ́n sì ṣe àwọn ìpinnu tó tako ìfẹ́ Ọlọ́run. Ìyọnu ló kó àwọn àti àwa náà sí. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6, 17-19) Ẹ̀mí láti máà fẹ́ sí lábẹ́ òfin Ọlọ́run ló kún inú ayé. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ kápá ẹ̀mí yẹn nínú ara wa.
13. Kí ló máa fi hàn bóyá tọkàntọkàn la fi ń múra sílẹ̀ láti gbé nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run?
13 Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ìlérí amọ́kànyọ̀ tí Jèhófà ṣe láti fi àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun nínú èyí tí ‘òdodo yóò máa gbé’ rọ́pò ayé búburú ìsinsìnyí. (2 Pétérù 3:13) Ǹjẹ́ kò yẹ kí ìyẹn sún wa láti bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ báyìí láti gbé lákòókò yẹn nígbà tí òdodo yóò gba ayé kan? Èyí túmọ̀ sí pé ká kọbi ara sí ìmọ̀ràn Bíbélì tó ṣe ṣàkó náà pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀.” (1 Jòhánù 2:15) Nítorí náà, a ó yàgò pátápátá fún ẹ̀mí ayé yìí, ìyẹn ẹ̀mí ohun-tó-wù-mí-ni-màá-ṣe àti ọ̀nà tó ń gbà pe àfiyèsí síra rẹ̀, ìṣekúṣe rẹ̀ àti ìwà ipá rẹ̀. A ó sọ́ ọ di àṣà láti máa tẹ́tí sí Jèhófà ká sì máa ṣègbọràn sí i látinú ọkàn wa wá, láìka ti pé ẹran ara aláìpé wa kò fẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀ sí. Ọ̀nà ìgbésí ayé wa lápapọ̀ yóò sì fẹ̀rí hàn pé ìrònú wa àtàwọn ohun tó ń sún wa ṣe nǹkan ni a mú kó bá ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run mu.—Sáàmù 40:8.
14. (a) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti lo àǹfààní tí a ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà nísinsìnyí ká sì máa tẹ̀ lé e ní ìgbésí ayé wa? (b) Kí ni àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nínú ìpínrọ̀ yìí túmọ̀ sí fún wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?
14 Nígbà tí àkókò bá tó lójú Jèhófà láti pa ètò àwọn nǹkan búburú yìí run àti gbogbo àwọn tó fara mọ́ àwọn ọ̀nà rẹ̀, kò ní fi nǹkan falẹ̀. Kò ní sún àkókò yẹn síwájú tàbí kó yí àwọn ìlànà rẹ̀ padà láti bá ti àwọn tó ṣì ń toro mọ́ ayé mu, tí wọn ò fi tọkàntọkàn kọ́ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì ṣe é. Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò náà láti ṣe ohun tí ó yẹ! (Lúùkù 13:23, 24; 17:32; 21:34-36) Nígbà náà, ẹ ò ri pé ó ń mọ́kàn ẹni yọ̀ láti rí ogunlọ́gọ̀ ńlá ènìyàn tí wọ́n ń gbá àǹfààní ṣíṣeyebíye yìí mú! Wọ́n ń fi ìháragàgà wá ìtọ́ni tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò àjọ rẹ̀, wọ́n sì ń bá a lọ ní rírìn ní ìṣọ̀kan lójú ọ̀nà rẹ̀ tó lọ sínú ayé tuntun! Nítorí náà, bá a bá ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà sí, bẹ́ẹ̀ náà la ó ṣe máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí, tí a ó sì máa fẹ́ láti sìn-ín.
Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
• Kí ni ohun tí Jèhófà fẹ́ nípa ìjọsìn?
• Lẹ́yìn tá a bá ti mọ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì, báwo ló ṣe yẹ ká fi taratara tẹ̀ síwájú tó?
• Kí ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe láti wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn olùjọ́sìn Jèhófà yòókù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
‘Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà’