Orí Kejì
Ẹ Gbé Jèhófà Ga Nítorí Òun Nìkan Ni Ọlọ́run Tòótọ́
1. Ta ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà?
BÍBÉLÌ jẹ́ ká mọ̀ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àìmọye ni ohun táwọn èèyàn kà sí Ọlọ́run, “ní ti gidi, fún àwa, Ọlọ́run kan ní ń bẹ, Baba.” (1 Kọ́ríńtì 8:5, 6) Jèhófà, Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo ni “Ọlọ́run kan” ọ̀hún. (Diutarónómì 6:4; Ìṣípayá 4:11) Jésù pè é ní “Ọlọ́run mi àti Ọlọ́run yín.” (Jòhánù 20:17) Ohun tó sọ bá ohun tí Mósè ti sọ tẹ́lẹ̀ mu, pé: “Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́; kò sí òmíràn yàtọ̀ sí i.” (Diutarónómì 4:35) Jèhófà ju ohunkóhun mìíràn táwọn èèyàn ń jọ́sìn lọ fíìfíì, ì báà jẹ́ òrìṣà, ì báà jẹ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n ti sọ dàkúnlẹ̀bọ, tàbí Sátánì Èṣù ọ̀tá rẹ̀, tó jẹ́ “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́ríńtì 4:3, 4) Jèhófà yàtọ̀ sí gbogbo àwọn wọ̀nyí, òun ni “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà,” bí Jésù ṣe pè é.—Jòhánù 17:3.
2. Báwo ló ṣe yẹ kí ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ nípa Ọlọ́run nípa lórí ìgbésí ayé wa?
2 Àwọn ènìyàn tí kì í ṣe abaraámóorejẹ, tí wọ́n kọ́ nípa àwọn ànímọ́ amọ́kànyọ̀ tí Ọlọ́run ní, àtàwọn nǹkan tó ti ṣe sẹ́yìn àtèyí tó ṣì máa ṣe fún wa, ń sún mọ́ ọn. Bí ìfẹ́ wọn fún Jèhófà ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ló ń wù wọ́n láti gbé e ga. Lọ́nà wo? Ọ̀nà kan jẹ́ nípa sísọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa rẹ̀. Ìwé Róòmù 10:10, sọ pé: “Ẹnu ni a fi ń ṣe ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà.” Ọ̀nà mìíràn jẹ́ nípa fífarawé ìwà àti ìṣe rẹ̀. Ìwé Éfésù 5:1, sọ pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” Ká bàa lè ṣe bẹ́ẹ̀ ní kíkún sí i, a ní láti mọ Jèhófà gidigidi gan-an.
3. Kí ni lájorí ànímọ́ Ọlọ́run?
3 Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin ló fi àwọn ànímọ́ aláìlẹ́gbẹ́ tí Ọlọ́run ní hàn. Lájorí ànímọ́ rẹ̀ mẹ́rin ni ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo, agbára, àti ìfẹ́. “Ọgbọ́n . . . wà pẹ̀lú rẹ̀.” (Jóòbù 12:13) “Gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Diutarónómì 32:4) Òun ní “okun inú nínú agbára.” (Aísáyà 40:26) “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ó dára, èwo ló ta yọ jù lọ nínú lájorí ànímọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà, tó ń fi irú Ọlọ́run tó jẹ́ hàn jù lọ?
“Ọlọ́run Jẹ́ Ìfẹ́”
4. Èwo nínú àwọn ànímọ́ Ọlọ́run ló mú kó ṣẹ̀dá ayé òun ọ̀run àti gbogbo ohun abẹ̀mí?
4 Ronú nípa ohun tó mú kí Jèhófà ṣẹ̀dá ayé òun ọ̀run, tó dá àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí àtàwọn ènìyàn onílàákàyè. Kí ló mú un ṣẹ̀dá rẹ̀, ṣé ọgbọ́n rẹ̀ ni tàbí agbára tó ní? Rárá o, òótọ́ ni pé Ọlọ́run tún lo àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn, àmọ́ àwọn kọ́ ló sún Ọlọ́run ṣẹ̀dá ayé òun ọ̀run. Ìdájọ́ òdodo rẹ̀ kò sì béèrè pé kó fúnni lẹ́bùn ìwàláàyè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ gíga tí Ọlọ́run ní ló sún un láti jẹ́ kí àwọn míì nípìn-ín nínú ayọ̀ wíwàláàyè gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́nlóye ẹ̀dá. Ìfẹ́ ló mú kó gbé e kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ète rẹ̀ pé ẹ̀dá ènìyàn onígbọràn á wà láàyè títí láé nínú Párádísè. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15) Ìfẹ́ ló mú kó ṣètò láti mú ìdálẹ́bi tí ìrélànàkọjá Ádámù mú wá sórí aráyé kúrò.
5. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, àpẹẹrẹ ànímọ́ wo ni Jèhófà jẹ́, èé sì ti ṣe?
5 Nítorí náà, nínú gbogbo ànímọ́ tí Ọlọ́run ní, èyí tó gbawájú jù lọ nínú wọn ni ìfẹ́. Ohun tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an nìyẹn. Pẹ̀lú bí ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo, àti agbára rẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó, Bíbélì kò sọ ọ́ rí pé Jèhófà jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Àmọ́ ó sọ pé ó jẹ́ ìfẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà jẹ́ ojúlówó àpẹẹrẹ ìfẹ́. Ìlànà ló ń darí ìfẹ́ yìí, kì í ṣe bí nǹkan bá ṣe rí lára èèyàn. Àwọn ìlànà òtítọ́ àti òdodo ló ń dárí ìfẹ́ Ọlọ́run. Òun ni oríṣi ìfẹ́ tó ga jù lọ, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ṣe fi àpẹẹrẹ rẹ̀ hàn. Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ló ń fi hàn pé èèyàn kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan rárá, àwọn ìgbésẹ̀ akọni kan sì tún máa ń bá a rìn.
6. Kí ló mú ká lè ṣàfarawé Ọlọ́run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jù wá lọ fíìfíì?
6 Ànímọ́ ìfẹ́ tí ó jẹ́ àgbàyanu yìí gan-an ló mú ká lè fara wé Ọlọ́run. A lè máa ronú pé a ò ní lè ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé ẹ̀dá tí kò já mọ́ nǹkankan, tó jẹ́ aláìpé, tó sì lè dẹ́ṣẹ̀ ni wá. Àmọ́, àpẹẹrẹ mìíràn tún wà tó fi ìfẹ́ gíga lọ́lá tí Jèhófà ní hàn: ìyẹn ni pé Ó mọ ibi tí agbára wa mọ, kò sì retí ìjẹ́pípé lọ́dọ̀ wa. Ó mọ̀ pé a ò tíì dé ìjẹ́pípé lọ́wọ́ tá a wà yìí. (Sáàmù 51:5) Ìdí nìyẹn tí Sáàmù 130:3, 4, fi sọ pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró? Nítorí ìdáríjì tòótọ́ ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” (Ẹ́kísódù 34:6) “Ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5) Ìtùnú ńlá mà lèyí o! Ẹ ò ri bó ṣe ń tuni lára tó láti jọ́sìn Ọlọ́run àgbàyanu yìí, ká sì gbádùn ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú rẹ̀!
7. Báwo la ṣe lè rí ìfẹ́ Jèhófà nínú àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀?
7 A tún lè rí ìfẹ́ Jèhófà nínú àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀. Ronú nípa ọ̀pọ̀ nǹkan rere tí Jèhófà pèsè fún ìgbádùn wa, bí àwọn òkè rírẹwà, àwọn igbó kìjikìji, àwọn adágún omi, àtàwọn agbami òkun. Ó fún wa lónírúurú oúnjẹ tó máa dùn mọ́ wa lẹ́nu, tá á sì gbẹ́mìí wa ró. Kò tán síbẹ̀ o, àwọn òdòdó rírẹwà olóòórùn dídùn tí Jèhófà pèsè tún lọ jàra, bẹ́ẹ̀ náà tún ni ìṣẹ̀dá àwọn ẹranko tó jẹ́ àgbàyanu. Ó ṣe àwọn nǹkan tó máa mú kí ìgbésí ayé àwọn èèyàn dùn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe dandan pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́, a ò lè gbádùn àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣẹ̀dá tó bo ṣe yẹ nínú ayé búburú yìí nínú ipò àìpé tá a wà. (Róòmù 8:22) Àmọ́, sáà wo ohun tí Jèhófà máa ṣe fún wa nínú Párádísè bí ó ti ga lọ́lá tó! Onísáàmù náà sọ pé: “Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn [rere] gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.”—Sáàmù 145:16.
8. Àpẹẹrẹ wo ló ta yọ jù lọ nínú ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún wa?
8 Àpẹẹrẹ wo ló ta yọ jù lọ nínú ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún ìran ènìyàn? Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Ṣé ìwà èèyàn ló wá dáa tó bẹ́ẹ̀ ni tí Jèhófà fi ṣe èyí? Ìwé Róòmù 5:8 dáhùn pé: “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ pípé wá sáyé láti wá fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ẹbọ ìràpadà tó máa gbà wá lóko ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Mátíù 20:28) Èyí ló ṣí ọ̀nà àtiní ìyè àìnípẹ̀kun sílẹ̀ fáwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. A mà dúpẹ́ o, pé ìfẹ́ Ọlọ́run nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ gbogbo ẹni tó bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ rẹ̀, nítorí Bíbélì sọ fún wa pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
9. Báwo ló ṣe yẹ kí fífi tí Jèhófà fi Ọmọ rẹ̀ rà wá padà nípa lórí wa?
9 Báwo ló ṣe yẹ kí fífi tí Jèhófà fi Ọmọ rẹ̀ rà wá padà, èyí tó ṣí ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun sílẹ̀ fún wa, nípa lórí bá a ṣe ń lo ìgbésí ayé wa nísinsìnyí? Ó yẹ kó mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ náà jinlẹ̀ sí i. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó yẹ kó mú ká fẹ́ láti fetí sí Jésù, tó ń ṣojú fún Ọlọ́run. “[Jésù] kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.” (2 Kọ́ríńtì 5:15) Ẹ ò rí i pé ìtura gbáà ló jẹ́ láti tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù, nítorí pé ó fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ ní fífarawé ìfẹ́ àti àánú Jèhófà! Ohun tí Jésù sọ fáwọn onírẹ̀lẹ̀ fí èyí hàn, ó sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.”—Mátíù 11:28-30.
Fífi Ìfẹ́ Hàn sí Àwọn Ẹlòmíràn
10. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fìfẹ́ hàn sáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa?
10 Báwo la ṣe lè fi hàn pé irú ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù ní fún wa làwa náà ní fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa? Onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà ṣe é rèé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀, kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù. Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe. Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́. A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.”—1 Kọ́ríńtì 13:4-8; 1 Jòhánù 3:14-18; 4:7-12.
11. Àwọn wo ló tún yẹ ká fìfẹ́ hàn sí, báwo la ó sì ṣe ṣe é?
11 Àwọn wo ló tún yẹ ká fìfẹ́ hàn sí, báwo la ó sì ṣe ṣe é? Jésù sọ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Èyí kan sísọ ìhìn rere ayé tuntun ẹlẹ́wà ti Ọlọ́run, tó ń bọ̀ lọ́nà, fún àwọn tí kò tíì di Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa. Kedere ni Jésù sọ ọ́ pé kì í ṣe àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nìkan ni ká nífẹ̀ẹ́. Ó tiẹ̀ sọ pé: “Bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ [kìkì] àwọn tí wọ́n ń nífẹ̀ẹ́ yín, èrè wo ni ẹ ní? Àwọn agbowó orí kò ha ń ṣe ohun kan náà bí? Bí ẹ bá sì kí àwọn arákùnrin yín nìkan, ohun àrà ọ̀tọ̀ wo ni ẹ ń ṣe? Àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú kò ha ń ṣe ohun kan náà bí?”—Mátíù 5:46, 47; 24:14; Gálátíà 6:10.
“Máa Rìn ní Orúkọ Jèhófà”
12. Èé ṣe tó fi jẹ́ pé Ọlọ́run nìkan ló lè jẹ́ orúkọ tó ń jẹ́?
12 Ọ̀nà mìíràn tá a tún lè gbà gbé Ọlọ́run tòótọ́ náà ga ni pé ká mọ Jèhófà, orúkọ aláìlẹ́gbẹ́ tó ń jẹ́, ká máa lò ó, ká sì máa fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Onísáàmù náà sọ ohun tó wù ú yìí jáde látọkànwá pé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 83:18) Orúkọ náà Jèhófà túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Òun ni Atóbilọ́lá Olùpète, gbogbo ohun tó bá wà lọ́kàn rẹ̀ láti ṣe ló máa ń ṣe yọrí. Àní Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà ló lè jẹ́ orúkọ yìí, nítorí pé ẹ̀dá ènìyàn kò lè fọwọ́ sọ̀yà pé gbogbo akitiyan táwọn ń ṣe ló máa kẹ́sẹ járí. (Jákọ́bù 4:13, 14) Jèhófà nìkan ló lè sọ pé ọ̀rọ̀ tóun sọ “yóò ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú” nínú ohun tó tìtorí rẹ̀ rán an. (Aísáyà 55:11) Inú ọ̀pọ̀ èèyàn dùn gan-an nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ rí orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì wọn tí wọ́n sì kọ́ ohun tó túmọ̀ sí. (Ẹ́kísódù 6:3) Àmọ́ o, kìkì bí wọ́n bá “rìn ní orúkọ Jèhófà . . . títí láé” ni ìmọ̀ yìí á tó lè ṣe wọ́n láǹfààní o.—Míkà 4:5.
13. Kí ni mímọ orúkọ Jèhófà àti rírìn ní orúkọ rẹ̀ jẹ́?
13 Sáàmù 9:10 sọ nípa orúkọ Ọlọ́run pé: “Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé ọ.” Ohun tí èyí túmọ̀ sí ju pé kéèyàn kàn mọ orúkọ náà Jèhófà, nítorí ìyẹn kò túmọ̀ sí pé èèyàn ń gbẹ́kẹ̀ lé e. Mímọ orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí pé kéèyàn mọ irú Ọlọ́run tí Jèhófà jẹ́ kó sì fi ìmọrírì hàn fún un, kéèyàn bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ̀, kéèyàn sì gbọ́kàn lé e pátápátá. (Òwe 3:5, 6) Bákan náà, rírìn ní orúkọ Jèhófà túmọ̀ sí pé ká ya ara wa sí mímọ́ fún un ká sì sọ ara wa di ọ̀kan lára àwọn olùjọ́sìn rẹ̀, ká máa fi gbogbo ìgbésí ayé wa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. (Lúùkù 10:27) Ṣé ò ń ṣe bẹ́ẹ̀?
14. Bí a óò bá jọ́sìn Jèhófà títí ayé, irú ẹ̀mí wo la óò fi jọ́sìn rẹ̀?
14 Bí a óò bá jọ́sìn Jèhófà títí ayé, ohun tó gbọ́dọ̀ máa mú wa sìn ín yẹ kí ó ju tìtorí pé ó di dandan fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì tó tiẹ̀ ti ń jọ́sìn Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún nímọ̀ràn pé: “Máa kọ́ ara rẹ pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìfojúsùn rẹ.” (1 Tímótì 4:7) Inú ọkàn tó kún fún ìmọrírì ni ìfọkànsìn ti máa ń wá. “Fífọkànsin Ọlọ́run” túmọ̀ sí kéèyàn ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà. Ó tún túmọ̀ sí kéèyàn sún mọ́ ọn dáadáa, nítorí ojú ribiribi téèyàn fi ń wo òun àtàwọn ọ̀nà rẹ̀. Ìfọkànsìn yìí ló ń mú ká fẹ́ kí gbogbo èèyàn ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún orúkọ rẹ̀. Bí a bá fẹ́ rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà títí láé, a gbọ́dọ̀ ní ìfọkànsìn Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé wa.—Sáàmù 37:4; 2 Pétérù 3:11.
15. Báwo la ṣe lè fún Ọlọ́run ní ìjọsìn tá a yà sọ́tọ̀ gedegbe
15 Bí a óò bá jọ́sìn Ọlọ́run ní ọ̀nà tó fẹ́, a kò gbọ́dọ̀ sin ohun mìíràn pẹ̀lú rẹ̀ nítorí pé “Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe” ni. (Ẹ́kísódù 20:5) A kò lè fẹ́ràn Ọlọ́run, lẹ́sẹ̀ kan náà ká tún fẹ́ràn ayé búburú tí Sátánì jẹ́ ọlọ́run rẹ̀. (Jákọ́bù 4:4; 1 Jòhánù 2:15-17) Jèhófà mọ irú èèyàn tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fẹ́ jẹ́ dáadáa. (Jer. 17:10) Kò ṣaláìmọ̀ tí a bá fẹ́ràn òdodo lóòótọ́, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò tá à ń kojú lójoojúmọ́. Ó ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ alágbára tì wá lẹ́yìn, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìwà ibi tó pọ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ nínú ayé tá a wà yìí. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Yóò tún ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ́ kí ìrètí lílágbára tá a ní nípa ìwàláàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé ṣákìí. Ìrètí àgbàyanu ńláǹlà mà lèyí o! Ó yẹ ká dúpẹ́ ká tún ọpẹ́ dá nítorí rẹ̀ ká sì fi tọkàntọkàn jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà, ẹni tó mú kó ṣeé ṣe.
16. Kí ló yẹ kó o fẹ́ láti ṣe pẹ̀lú ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn mìíràn?
16 Ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn kárí ayé ti fayọ̀ gba ìkésíni onísáàmù náà pé: “Ẹ gbé Jèhófà ga lọ́lá pẹ̀lú mi, ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ ga.” (Sáàmù 34:3) Jèhófà ń ké sí ọ pé kó o máa bọ̀ wá dara pọ̀ mọ́ ògìdìgbó àwọn ènìyàn tí iye wọn ń pọ̀ sí i látinú gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n sì ń gbé orúkọ rẹ̀ ga.
Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
• Irú èèyàn wo ni Jèhófà jẹ́? Báwo la ṣe ń jàǹfààní nínú níní òye tó ṣe kedere nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀?
• Báwo la ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run?
• Kí ni mímọ orúkọ Jèhófà àti rírìn ní orúkọ rẹ̀ jẹ́?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ìfẹ́ ńláǹlà tí Jèhófà ní á mú kó ‘ṣí ọwọ́ rẹ̀, kó sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn’