Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
AUGUST 5-11
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 TÍMÓTÌ 1-4
“Ọlọ́run Kò Fún Wa Ní Ẹ̀mí Ojo”
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Jẹ́ Kí Ìtẹ̀síwájú Yín Fara Hàn Kedere
9 Kí Pọ́ọ̀lù lè ran Tímótì lọ́wọ́, ó rán an létí pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọ́run fún wa bí kò ṣe ti agbára àti ti ìfẹ́ àti ti ìyèkooro èrò inú.” (2 Tím. 1:7) “Ìyèkooro èrò inú” wé mọ́ kéèyàn lè ronú lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání. Ó tún kan kéèyàn lè fara da ipòkípò téèyàn bá bára ẹ̀, bí nǹkan ò tiẹ̀ rí béèyàn ṣe fẹ́. Àwọn ọ̀dọ́ kan tí òtítọ́ ò jinlẹ̀ nínú wọn máa ń ṣojo, wọ́n sì máa ń wá bí wọ́n ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tó ń pinni lẹ́mìí nípa sísùn ju bó ṣe yẹ lọ, wíwo tẹlifíṣọ̀n láwòjù, lílo oògùn olóró, mímú ọtí lámujù, lílọ síbi àríyá nígbà gbogbo tàbí ṣíṣe ìṣekúṣe. Àmọ́, Ìwé Mímọ́ gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n “kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé àti láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.”—Títù 2:12.
‘Ẹ Jẹ́ Onígboyà Àti Alágbára!’
7 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ lẹ́tà sí Tímótì, ó sọ pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọ́run fún wa bí kò ṣe ti agbára . . . Nítorí náà, má tijú ẹ̀rí nípa Olúwa wa.” (2 Tímótì 1:7, 8; Máàkù 8:38) Lẹ́yìn tá a ti ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, a lè bi ara wa léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ ohun ti mo gbà gbọ́ máa ń tì mí lójú, àbí mo nígboyà? Níbi iṣẹ́ mi (tàbí nílé ìwé), ǹjẹ́ mo jẹ́ káwọn ẹlẹgbẹ́ mi mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, àbí mi ò jẹ́ sọ fáwọn èèyàn bí mo ṣe jẹ́? Ṣé yíyàtọ̀ sáwọn yòókù máa ń tì mí lójú, àbí inú mi máa ń dùn pé mo yàtọ̀ nítorí àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà?’ Tí ẹ̀rù bá ń ba ẹnì kan láti wàásù ìhìn rere náà tàbí nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò fẹ́ràn ohun tó gbà gbọ́, kírú ẹni bẹ́ẹ̀ rántí ohun tí Jèhófà sọ fun Jóṣúà pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára.” Má ṣe gbà gbé pé kì í ṣe èrò àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí èrò àwọn ọmọ ilé ìwé ẹlẹgbẹ́ wa ló ṣe pàtàkì bí kò ṣe ti Jèhófà àti Jésù Kristi.—Gálátíà 1:10.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Bá A Ṣe Lè Ní Ọrọ̀ Tòótọ́
13 Tímótì náà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù pe Tímótì ní “ọmọ ogun àtàtà ti Kristi Jésù,” Pọ́ọ̀lù sọ fún un pé: “Kò sí ènìyàn tí ń sìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun tí ń kó wọnú àwọn iṣẹ́ òwò ìgbésí ayé, kí ó bàa lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà ẹni tí ó gbà á síṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun.” (2 Tím. 2:3, 4) Lónìí, gbogbo àwa ọmọ ẹ̀yìn Jésù ló ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí sílò, títí kan àwọn tó lé ní mílíọ̀nù kan tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Wọn ò jẹ́ kí onírúurú ìpolówó ọjà àtàwọn nǹkan míì táyé ń gbé lárugẹ mú kí wọ́n máa lépa ọrọ̀, wọ́n sì ń fi ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí sọ́kàn pé: ‘Ayá-nǹkan ni ìránṣẹ́ awínni.’ (Òwe 22:7) Ohun tí Sátánì fẹ́ ká ṣe ni pé ká máa fi gbogbo ayé wa lépa bá a ṣe máa rí towó ṣe. Ohun táwọn kan ṣe ti mú kí wọ́n tọrùn bọ gbèsè tó gbà wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọdún láti san. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń yáwó ní báǹkì fi kọ́lé, àwọn míì sì ń yáwó fi lọ sílé ìwé. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn míì ń yáwó torí kí wọ́n lè ra mọ́tò olówó gọbọi tàbí kí wọ́n lè ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó táyé gbọ́ tọ́run mọ̀. A lè fi hàn pé a jẹ́ ọlọ́gbọ́n tá a bá jẹ́ kí nǹkan díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, tá ò tọrùn bọ gbèsè, tá a sì ń ra kìkì ohun tá a nílò. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé Ọlọ́run là ń sìnrú fún kì í ṣe ètò ìṣòwò inú ayé yìí.—1 Tím. 6:10.
Àwọn Èèyàn Jèhófà “Kọ Àìṣòdodo Sílẹ̀ Ní Àkọ̀tán”
10 Lóde òní, àwọn apẹ̀yìndà ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ mọ́ nínú ìjọ. Síbẹ̀, bí irú ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu bẹ́ẹ̀ bá yọjú, ẹ jẹ́ ká dúró lórí ìpinnu wa pé ọ̀nà yòówù kí irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ gbà wá, a ò ní gbà á láyè. Kò ní bọ́gbọ́n mu pé ká máa bá àwọn apẹ̀yìndà fa ọ̀rọ̀, yálà lójúkojú, tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tàbí lọ́nà èyíkéyìí mìíràn téèyàn ti lè bá ẹlòmíì sọ̀rọ̀. Kódà tá a bá rò pé ṣe la fẹ́ ran onítọ̀hún lọ́wọ́, ńṣe ni irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ á mú ká tàpá sí ìtọ́ni Ìwé Mímọ́ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò rẹ̀ tán yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, a kì í ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn apẹ̀yìndà, ńṣe la máa ń yẹra fún wọn, torí pé èèyàn Jèhófà ni wá.
Bíbélì Kíkà
AUGUST 12-18
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | TÍTÙ 1–FÍLÉMÓNÌ
“Ẹ Yan Àwọn Alàgbà”
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ kò ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa bí wọ́n ṣe ń yan àwọn ọkùnrin sípò nígbà yẹn, àwọn ohun kan wà tó jẹ́ ká mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe é. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ń pa dà sílé lẹ́yìn ìrìn àjò míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ tí wọ́n lọ, “wọ́n yan àwọn àgbà ọkùnrin sípò fún wọn nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan àti pé, ní gbígba àdúrà pẹ̀lú àwọn ààwẹ̀, wọ́n fi wọ́n lé Jèhófà lọ́wọ́, ẹni tí wọ́n ti di onígbàgbọ́ nínú rẹ̀.” (Ìṣe 14:23) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Títù tí wọ́n jọ máa ń rìnrìn àjò, ó ní: “Ìdí yìí ni mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè, kí o lè ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó ní àbùkù, kí o sì lè yan àwọn àgbà ọkùnrin sípò láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá, gẹ́gẹ́ bí mo ti fún ọ ní àwọn àṣẹ ìtọ́ni.” (Títù 1:5) Bákan náà, ó jọ pé Pọ́ọ̀lù fún Tímótì tó ti rìnrìn àjò káàkiri pẹ̀lú rẹ̀ ní irú ọlá àṣẹ kan náà. (1 Tím. 5:22) Torí náà, ó ṣe kedere pé àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ló ń yan àwọn ọkùnrin sípò nígbà yẹn, kì í ṣe àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Jerúsálẹ́mù.
Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì yìí ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní lọ́kàn tó fi ṣe àtúnṣe sí ọ̀nà tá à ń gbà yan àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sípò. Bẹ̀rẹ̀ láti September 1, 2014, ọ̀nà tá à ń gbà yan àwọn èèyàn sípò rèé: Alábòójútó àyíká á fara balẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò ìdábàá táwọn alàgbà ìjọ tó wà nínú àyíká rẹ̀ ṣe. Nígbà ìbẹ̀wò tó ń ṣe sáwọn ìjọ, á gbìyànjú láti mọ àwọn tí wọ́n dábàá náà, á sì bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tó bá ṣeé ṣe. Lẹ́yìn tí òun àtàwọn alàgbà bá ti jíròrò nípa àwọn tí wọ́n dábàá náà, iṣẹ́ alábòójútó àyíká ni láti yan àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sípò nínú àwọn ìjọ tó wà nínú àyíká tó ń bójú tó. Lọ́nà yìí, ìṣètò náà túbọ̀ jọ ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní.
Ta ló ń bójú tó apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí yíyan àwọn èèyàn sípò pín sí? Bó ṣe rí látẹ̀yìn wá, iṣẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ni láti máa bọ́ àwọn ará ilé Ọlọ́run. (Mát. 24:45-47) Èyí kan wíwá inú Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ láti pèsè ìtọ́sọ́nà nípa bá a ṣe lè lo àwọn ìlànà Bíbélì tó dá lórí ṣíṣètò àwọn ìjọ kárí ayé. Ẹrú olóòótọ́ tún ń yan gbogbo àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ̀ọ̀kan á wá pèsè ìrànwọ́ tó gbéṣẹ́ káwọn ará lè máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n rí gbà. Ojúṣe pàtàkì tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kọ̀ọ̀kan ní ni láti gbé àwọn arákùnrin tí wọ́n fẹ́ dábàá yẹ̀ wò kínníkínní bóyá wọ́n kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìyànsípò nínú ìjọ Ọlọ́run. Ojúṣe pàtàkì tí alábòójútó àyíká kọ̀ọ̀kan ní ni láti fara balẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò ìdábàá tí àwọn alàgbà ṣe, kó sì ṣe bẹ́ẹ̀ tàdúràtàdúrà. Lẹ́yìn náà, kó yan àwọn ọkùnrin tó bá kúnjú ìwọ̀n sípò.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
w89 5/15 31 ¶5
Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Onkawe
Ó dájú pé kò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìpẹ̀gàn èyíkéyìí táwọn kan lè máa sọ lòdì sí àwọn ará ìlú Kírétè. Àwa lè ní ìdánilójú nípa ìyẹn, nítorí Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àwọn Kristẹni rere tí Ọlọ́run ti fọwọ́sí-tẹ́wọ́gbà tí ó sì fi ẹ̀mí Rẹ̀ yàn wà ní Kírétè. (Iṣe 2:5, 11, 33) Àwọn Kristẹni olùfọkànsìn pọ̀ níbẹ̀ débí tí wọ́n fi ní àwọn ìjọ ní “ìlú ńlá dé ìlú ńlá.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irúfẹ́ àwọn Kristẹni bẹ́ẹ̀ kìí ṣe àwọn ẹ̀dá ènìyàn pípé, àwa lè ní ìdánilójú pé wọn kì í ṣe èké àti ọ̀lẹ alájẹkì; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn kì yóò máa báa lọ láti ní ojú rere Jèhófà. (Fílípì 3:18, 19; Ìfihàn 21:8) Gẹ́gẹ́ bí àwa lónìí sì ti ríi ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ó ṣé e ṣe kí a rí àwọn ènìyàn ní Kírétè tí wọ́n jẹ́ olóòtọ́ ọkàn, tí wọ́n ṣe tán láti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere, torí pé wọ́n kórìíra àwọn ìwà tó ń tini lójú táwọn èèyàn tó wà ní àyíká wọn ń hù.—Ìsíkíẹ́lì 9:4; fi wé Ìṣe 13:48.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Títù, Fílémónì àti Hébérù
15, 16—Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù kò fi sọ fún Fílémónì pé kó sọ Ónẹ́símù dòmìnira? Pọ́ọ̀lù ò fẹ́ kúrò nídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́, ìyẹn ‘wíwàásù ìjọba Ọlọ́run àti kíkọ́ni láwọn ohun tó jẹ mọ́ Jésù Kristi Olúwa.’ Nítorí náà, kò fẹ́ láti lọ́wọ́ nínú ọ̀rọ̀ àárín ẹrú àti ọ̀gá rẹ̀ tàbí irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.—Ìṣe 28:31.
Bíbélì Kíkà
AUGUST 19-25
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | HÉBÉRÙ 1-3
“Nífẹ̀ẹ́ Òdodo, Kórìíra Ìwà Tí Kò Bófin Mu”
Ẹ Yin Kristi, Ọba Ògo!
8 Ọdún 1914 ni Jèhófà gbé Ọmọ rẹ̀ gorí ìtẹ́ ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba. “Ọ̀pá aládé àkóso rẹ̀ jẹ́ ọ̀pá aládé ìdúróṣánṣán,” torí náà ó dájú pé ó máa fi òdodo ṣàkóso kò sì ní ṣe ojúsàájú. Ọlá àṣẹ rẹ̀ bófin mu, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ‘Ọlọ́run ni ìtẹ́ rẹ̀.’ Ìyẹn ni pé, Jèhófà ni ìpìlẹ̀ ìjọba rẹ̀. Síwájú sí i, ìtẹ́ Jésù máa wà “fún àkókò tí ó lọ kánrin,” tàbí títí láé. Ǹjẹ́ kò wú ẹ lórí láti máa sin Jèhófà lábẹ́ irú Ọba alágbára tí Ọlọ́run yàn sípò yìí?
Ẹ Yin Kristi, Ọba Ògo!
7 Ka Sáàmù 45:6, 7. Jésù ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún òdodo ó sì kórìíra ohunkóhun tó lè tàbùkù sí Baba rẹ̀, Jèhófà. Nítorí náà, Jèhófà yàn án gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Mèsáyà. Ó “fòróró ayọ̀ ńláǹlà” yan Jésù ju “àwọn alájọṣe,” rẹ̀, ìyẹn àwọn ọba Júdà tó ti ìlà ìdílé Dáfídì wá. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ohun kan ni pé, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló yan Jésù. Ó tún wá yàn án gẹ́gẹ́ bí Ọba àti Àlùfáà Àgbà. (Sm. 2:2; Héb. 5:5, 6) Ní àfikún sí ìyẹn, ẹ̀mí mímọ́ ni Ọlọ́run fi yan Jésù, ìṣàkóso rẹ̀ kò sì ní jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé bí kò ṣe ní òkè ọ̀run.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 1185 ¶1
Àwòrán
Ṣé àtìbẹ̀rẹ̀ ni Jésù ti máa ń gbé ògo Bàbá rẹ̀ yọ lọ́nà tó ṣe rẹ́gí?
Àwòrán Ọlọ́run ni Jésù, àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run, tó jẹ́ èèyàn nígbà kan rí. (2Kọ 4:4) Níwọ̀n bó ti ṣe kedere pé Ọmọ yẹn ni Ọlọ́run ń bá sọ̀rọ̀ nígbà tó sọ pé, “Jẹ́ ká dá èèyàn ní àwòrán wa,” àtìgbà tí Ẹlẹ́dàá ti dá Ọmọ rẹ̀ yìí ni òun àti Bàbá rẹ̀ ti jọra. (Jẹ 1:26; Jo 1:1-3; Kol 1:15, 16) Ẹni pípé ni nígbà tó wà láyé, torí náà, ó gbé àwọn ìwà àti ànímọ́ Bàbá rẹ̀ yọ, lọ́nà tí ara ẹ̀dá èèyàn lè gbé e dé, ìdí nìyẹn tó fi lè sọ pé “ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.” (Jo 14:9; 5:17, 19, 30, 36; 8:28, 38, 42) Àmọ́ lẹ́yìn tí Jésù tún wá jíǹde sí ọ̀run, tó sì di ẹ̀dá ẹ̀mí, Jèhófà Ọlọ́run fún un ní “gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé.” (1Pe 3:18; Mt 28:18) Ní báyìí tí Ọlọ́run ti gbé Jésù “sí ipò gíga,” Ọmọ Ọlọ́run ti wá ń gbé ògo Bàbá rẹ̀ yọ lọ́nà tó tún wá ga ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, kódà, ó ga ju ti ìgbà tó fi ọ̀run sílẹ̀ wá sí ilẹ̀ ayé. (Flp 2:9; Heb 2:9) Ó ti wá di “àwòrán irú ẹni tó [Ọlọ́run] jẹ́ gẹ́lẹ́.”—Heb 1:2-4.
it-1 1063 ¶7
Ọ̀run
Àwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 102:25, 26 ń tọ́ka sí Jèhófà Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe àyọlò ọ̀rọ̀ yẹn láti tọ́ka sí Jésù Kristi. Ìdí ni pé Jésù yìí ni Ọlọ́run lò láti dá àgbáyé yìí. Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín bí Jésù ṣe máa wà títí láé, sí bí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá ṣe máa pẹ́ tó, tí Ọlọ́run bá fẹ́, ó lè ‘ká wọn jọ bí aṣọ àwọ̀lékè’ kó sì pa wọ́n tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.—Heb 1:1, 2, 8, 10-12; fi wé 1Pe 2:3, àlàyé ìsàlẹ̀.
Bíbélì Kíkà
AUGUST 26–SEPTEMBER 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | HÉBÉRÙ 4-6
“Sa Gbogbo Ipá Rẹ Kó O Lè Wọnú Ìsinmi Ọlọ́run”
Kí Ni Ìsinmi Ọlọ́run?
3 Ìdí méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà tá a fi lè sọ pé ọjọ́ keje tí Ọlọ́run fi ń sinmi ṣì ń bá a nìṣó ní ọ̀rúndún kìíní. Kọ́kọ́ ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún àwọn alátakò tó bínú sí i torí pé ó wo ẹnì kan sàn lọ́jọ́ Sábáàtì, tí wọ́n sì kà á sí i lọ́rùn pé iṣẹ́ ló ń ṣe dípò kó máa sinmi. Olúwa sọ fún wọn pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí, èmi náà sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́.” (Jòh. 5:16, 17) Kí ni Jésù ní lọ́kàn? Wọ́n ń fi ẹ̀sùn kan Jésù pé ó ń ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ Sábáàtì. Jésù sì dá wọn lóhùn pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́.” Lédè mìíràn, ohun tí Jésù ń sọ fún àwọn tó ń fẹ̀sùn kàn án ni pé: ‘Irú iṣẹ́ kan náà ni èmi àti Baba mi ń ṣe. Níwọ̀n bí Baba mi sì ti ń bá a nìṣó láti máa ṣiṣẹ́ jálẹ̀ ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún tó jẹ́ Sábáàtì rẹ̀, kò sí ohun tó burú níbẹ̀ bí èmi náà bá ń bá a nìṣó láti máa ṣiṣẹ́, àní lọ́jọ́ Sábáàtì pàápàá.’ Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé, Sábáàtì ńlá Ọlọ́run, ìyẹn ọjọ́ keje tó fi ń sinmi kúrò nínú ṣíṣẹ̀dá àwọn nǹkan sórí ilẹ̀ ayé, kò tíì parí nígbà tí òun wà láyé.
4 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ìdí kejì tó fi hàn pé ọjọ́ keje tí Ọlọ́run fi sinmi ṣì ń bá a nìṣó. Ó lo ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:2 nígbà tó ń ṣàlàyé nípa ìsinmi Ọlọ́run. Ó sọ lábẹ́ ìmísí pé: “Àwa tí a ti lo ìgbàgbọ́ wọnú ìsinmi náà ní tòótọ́.” (Héb. 4:3, 4, 6, 9) Èyí fi hàn pé ọjọ́ keje yẹn ṣì ń bá a nìṣó nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà láyé. Ìgbà wo ni ọjọ́ ìsinmi yẹn máa dópin?
5 Ká tó lè dáhùn ìbéèrè yẹn, ó ṣe pàtàkì ká rántí ohun tí Jèhófà fẹ́ lo ọjọ́ keje fún. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 2:3 ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run sì tẹ̀ síwájú láti bù kún ọjọ́ keje, ó sì ṣe é ní ọlọ́wọ̀.” Ọlọ́run ‘ṣe ọjọ́ yẹn ní ọlọ́wọ̀,’ èyí tó túmọ̀ sí pé Jèhófà ya ọjọ́ náà sí mímọ́ tàbí pé ó yà á sọ́tọ̀ kó bàa lè lò ó láti ṣe àṣeparí ohun tó fẹ́ kí ilẹ̀ ayé jẹ́. Kí ni Ọlọ́run fẹ́ kí ilẹ̀ ayé jẹ́? Ó fẹ́ kó jẹ́ ibi tí àwọn ọkùnrin àti obìnrin onígbọràn á máa gbé tí wọ́n á máa bójú tó, tí wọ́n á sì máa tọ́jú gbogbo ohun alààyè tó wà níbẹ̀. (Jẹ́n. 1:28) Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi tó jẹ́ “Olúwa sábáàtì” fi “ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí.” (Mát. 12:8) Ọjọ́ ìsinmi Ọlọ́run á máa bá a nìṣó títí dìgbà tí ilẹ̀ ayé a fi rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi.
Kí Ni Ìsinmi Ọlọ́run?
6 Ọlọ́run ṣàlàyé ohun tó fẹ́ fún Ádámù àti Éfà lọ́nà tó ṣe kedere, àmọ́ wọn kò fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, Ádámù àti Éfà ni ẹ̀dá èèyàn tó kọ́kọ́ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn mìíràn pẹ̀lú sì ti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Kódà, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, tó jẹ́ àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá, ṣàìgbọràn léraléra. Torí náà, Pọ́ọ̀lù rí i pé ó pọn dandan kí òun kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní pé àwọn kan lára wọn lè di aláìgbọràn bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa láti wọnú ìsinmi yẹn, kí ẹnikẹ́ni má bàa ṣubú sínú àpẹẹrẹ ọ̀nà àìgbọràn kan náà.” (Héb. 4:11) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí jẹ́ ká rí i pé àwọn aláìgbọràn kò lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run. Kí nìyẹn túmọ̀ sí fún wa? Ṣé ohun tó túmọ̀ sí ni pé lọ́nà èyíkéyìí, tá a bá ṣe ohun tó lòdì sí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ láti ṣe a kò ní wọnú ìsinmi rẹ̀? Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ ìdáhùn ìbéèrè yìí, a sì máa sọ púpọ̀ sí i nípa rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ búburú táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi lélẹ̀ àti ohun tó kọ́ wa nípa bá a ṣe lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run.
Kí Ni Ìsinmi Ọlọ́run?
16 Kò wọ́pọ̀ káwọn Kristẹni lónìí sọ pé ó di dandan káwọn pa Òfin Mósè mọ́ káwọn bàa lè rí ìgbàlà. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ sí àwọn ará Éfésù ṣe kedere. Ó sọ pé: “Nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí, a ti gbà yín là nípasẹ̀ ìgbàgbọ́; èyí kì í sì í ṣe ní tìtorí tiyín, ẹ̀bùn Ọlọ́run ni. Bẹ́ẹ̀ kọ́, kì í ṣe ní tìtorí àwọn iṣẹ́, kí ènìyàn kankan má bàa ní ìdí fun ṣíṣògo.” (Éfé. 2:8, 9) Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo wá ni àwọn Kristẹni ṣe lè wọnú ìsinmi Ọlọ́run? Jèhófà ya ọjọ́ keje sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi rẹ̀ kó bàa lè lò ó láti ṣe àṣeparí ohun tó fẹ́ kí ilẹ̀ ayé jẹ́. A lè wọnú ìsinmi Jèhófà tàbí, ká dara pọ̀ mọ́ ọn nínú ìsinmi rẹ̀, tá a bá jẹ́ onígbọràn tá a sì ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ fún wa nípa ọ̀nà tí ìfẹ́ rẹ̀ ń gbà ní ìmúṣẹ.
17 Àmọ́ bí a kò bá fi ojú pàtàkì wo ìmọ̀ràn Bíbélì tá à ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye, tá a sì yàn láti máa ṣe ohun tó wù wá, a jẹ́ pé ńṣe là ń ṣe ohun tó lòdì sí ọ̀nà tí ìfẹ́ Ọlọ́run ń gbà ní ìmúṣẹ. Èyí sì lè ba àjọṣe rere tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ipò díẹ̀ kan tó wọ́pọ̀ èyí tó lè dán ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run wò, a sì tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí ìpinnu wa yálà láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run tàbí láti máa ṣe ohun tó wù wá ṣe lè fi hàn bóyá òótọ́ la ti wọnú ìsinmi Ọlọ́run.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” tí Hébérù 4:12 sọ pé ó “yè, ó sì ń sa agbára”?
▪ Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ṣáájú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí àtèyí tó sọ lẹ́yìn rẹ̀ fi hàn pé ète Ọlọ́run tá a rí nínú Bíbélì ló ń sọ.
Nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, a sábà máa ń tọ́ka sí Hébérù 4:12 láti jẹ́ ká mọ̀ pé Bíbélì lágbára láti yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà, ó sì tọ̀nà tá a bá sọ bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ó yẹ ká ronú nípa ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ ṣáájú ẹsẹ Bíbélì yìí àtèyí tí wọ́n sọ lẹ́yìn rẹ̀. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ fáwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni ni pé kí wọ́n máa ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Wọ́n sì lè mọ ìfẹ́ Ọlọ́run tàbí ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé nínú Ìwé Mímọ́ tó wà nígbà yẹn. Pọ́ọ̀lù sọ àpẹẹrẹ kan, ìyẹn ni bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní láti wọ ilẹ̀ ìlérí “tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin,” níbi tí wọ́n á ti ní ojúlówó ìsinmi.—Ẹ́kís. 3:8; Diu. 12:9, 10.
Ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun fẹ́ ṣe fún wọn nìyẹn. Àmọ́ torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ya alágídí, wọn ò sì lo ìgbàgbọ́, púpọ̀ lára wọn ò wọnú ìsinmi Ọlọ́run. (Núm. 14:30; Jóṣ. 14:6-10) Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù tún fi kún un pé àǹfààní ṣì wà fún wọn láti wọnú ‘ìsinmi Ọlọ́run.’ (Héb. 3:16-19; 4:1) Ó dájú pé ìlérí yẹn wà lára àwọn ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun máa ṣe fáráyé. Bíi tàwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni, ó yẹ káwa náà mọ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, ká sì máa gbé ìgbé ayé tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Pọ́ọ̀lù fi ohun tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:2 àti Sáàmù 95:11 gbe ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yin káwọn èèyàn náà lè mọ̀ pé kì í ṣe èrò tiẹ̀ ló sọ.
Inú wa dùn pé ‘ìlérí kan ṣì wà nílẹ̀ fún wíwọnú ìsinmi Ọlọ́run.’ A nígbàgbọ́ pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé a máa wọnú ìsinmi Ọlọ́run, a sì ń ṣe ohun táá jẹ́ ká wọnú rẹ̀. Kì í ṣe pípa Òfin Mósè mọ́ láá mú kéèyàn rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe nípa ìsapá wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa lo ìgbàgbọ́, ká gbà pé Jèhófà máa ṣe ohun tó ní lọ́kàn fáráyé, ká sì tún máa fayọ̀ gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Láfikún síyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, táwọn náà sì ń kọ́ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun máa ṣe fáráyé. Ọ̀pọ̀ lára wọn lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, wọ́n yí ìgbésí ayé wọn pa dà, wọ́n sì ṣèrìbọmi. Àwọn ìyípadà tí wọ́n ń ṣe yìí jẹ́ ká rí i dájú pé lóòótọ́ ni “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” Awọn ohun tí Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì pé òun máa ṣe là ń jẹ́ kó darí ìgbésí ayé wa, wọ́n á sì máa sa agbára lórí wa títí láé.
it-1 1139 ¶2
Ìrètí
Ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun àti àìdíbàjẹ́ fún àwọn tó gbọ́ “ìpè ti ọ̀run” (Heb 3:1) ni a gbé ka ohun tá a lè gbára lé pátápátá. Ohun méjì ló ti ìrètí yìí lẹ́yìn, àwọn nǹkan tó jẹ́ pé kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti fi parọ́, àwọn nǹkan méjì náà ni, ìlérí rẹ̀ àti ìbúra rẹ̀, ìrètí náà sì wà lọ́dọ̀ Kristi, tó ti gbé àìkú wọ̀ ní ọ̀run báyìí. Torí náà, ìrètí yìí ni Bíbélì pè ní “ìdákọ̀ró fún ọkàn, ó dájú, ó fìdí múlẹ̀, ó sì wọlé sẹ́yìn aṣọ ìdábùú [bí àlùfáà àgbà ṣe máa ń wọnú Ibi Mímọ́ ní Ọjọ́ Ètùtù], níbi tí aṣíwájú kan ti wọ̀ nítorí wa, ìyẹn Jésù, ẹni tó ti di àlùfáà àgbà ní ọ̀nà ti Melikisédékì títí láé.”—Heb 6:17-20.
Bíbélì Kíkà