Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Jẹ́ Kí Ìtẹ̀síwájú Yín Fara Hàn Kedere
“Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”—1 TÍM. 4:15.
1. Kí ní Ọlọ́run fẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́?
SÓLÓMỌ́NÌ Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì kọ̀wé pé: “Máa yọ̀, ọ̀dọ́kùnrin, ní ìgbà èwe rẹ, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ ṣe ọ́ ní ire ní àwọn ọjọ́ ìgbà ọ̀dọ́kùnrin rẹ.” (Oníw. 11:9) Jèhófà Ọlọ́run tó mí sí Sólómọ́nì láti kọ ọ̀rọ̀ yìí fẹ́ kẹ́yin ọ̀dọ́ máa yọ̀, kì í ṣe nígbà tẹ́ ẹ wà lọ́dọ̀ọ́ nìkan, àmọ́ títí dìgbà tẹ́ ẹ bá dàgbà. Àmọ́ ṣa o, èèyàn sábà máa ń ṣàwọn àṣìṣe tó lágbára gan-an nígbà ọ̀dọ́, téèyàn á sì wá máa kábàámọ̀ ẹ̀ nígbà tó bá dàgbà. Jóòbù tó jẹ́ olóòótọ́ èèyàn pàápàá kédàárò nípa “àbájáde àwọn ìṣìnà ìgbà èwe [rẹ̀]”. (Jóòbù 13:26) Àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni sábà máa ń ní láti ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà àti nígbà tí wọ́n bá di ọ̀dọ́langba. Ṣíṣe ìpinnu tí kò tọ́ lè fa ìbànújẹ́ tí kò ní lọ bọ̀rọ̀ àti ìṣòro téèyàn á máa bá yí títí ọjọ́ ayé ẹ̀.—Oníw. 11:10.
2. Ìmọ̀ràn Bíbélì wo làwọn ọ̀dọ́ ní láti fi sílò tí wọn ò bá fẹ́ ṣe àṣìṣe tó burú jáì?
2 Ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa lo làákàyè nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣèpinnu. Wo ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó wà nílùú Kọ́ríńtì. Ó sọ pé: “Ẹ má ṣe di ọmọ kéékèèké nínú agbára òye, . . . Ẹ dàgbà di géńdé nínú agbára òye.” (1 Kọ́r. 14:20) Fífi ìmọ̀ràn náà sílò pé ká ní agbára láti ronú bíi ti àgbàlagbà, á ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti má ṣe ṣe àwọn àṣìṣe tó burú jáì.
3. Kí lo lè ṣe kó o bàa lè dẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí?
3 Tó bá jẹ́ ọ̀dọ́ ni ẹ́, máa fi sọ́kàn pé ó gba ìsapá gan-an kéèyàn tó lè dẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí. Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan fojú tẹ́ńbẹ́lú èwe rẹ láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, di àpẹẹrẹ fún àwọn olùṣòtítọ́ nínú ọ̀rọ̀ sísọ, nínú ìwà, nínú ìfẹ́, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́. . . . Máa bá a lọ ní fífi ara rẹ fún ìwé kíkà ní gbangba, fún ìgbani-níyànjú, fún kíkọ́ni. . . . Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tím. 4:12-15) Ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni máa tẹ̀ síwájú, kí wọ́n sì jẹ́ kí ìlọsíwájú wọn fara hàn kedere fún gbogbo èèyàn.
Kí Ni Ìlọsíwájú?
4. Kí ni ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí wé mọ́?
4 Ìlọsíwájú ni pé “kéèyàn ní ìtẹ̀síwájú, kí ìgbésí ayé èèyàn yí pa dà sí rere.” Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì pé kó máa tẹ̀ síwájú nínú ọ̀rọ̀ sísọ, ìwà, ìfẹ́, ìgbàgbọ́ àti ìwà mímọ́, kó lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ, kó bàa lè ṣeé ṣe fún un láti túbọ̀ ṣe dáadáa sí i. Ó gbọ́dọ̀ sapá láti mu kí ọ̀nà tó ń gbà gbé ìgbé ayé ẹ̀ jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. Tímótì ní láti máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.
5, 6. (a) Ìgbà wo ni ìlọsíwájú Tímótì ti bẹ̀rẹ̀ sí fara hàn? (b) Báwo làwọn ọ̀dọ́ lóde òní ṣe lè fara wé Tímótì tó bá dọ̀rọ̀ ìtẹ̀síwájú?
5 Tímótì ti di alàgbà tó nírìírí nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ ìmọ̀ràn yìí, láàárín ọdún 61 sí ọdún 64 Sànmánì Kristẹni. Kì í ṣe pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ síwájú. Nígbà tí Tímótì wà ní nǹkan bí ọmọ ogún ọdún, ìyẹn lọ́dún 49 tàbí 50 Sànmánì Kristẹni, àwọn ará tó ti rí ìtẹ̀síwájú ẹ̀ ‘ní Lísírà àti Íkóníónì ròyìn rẹ̀ dáadáa.’ (Ìṣe 16:1-5) Ìgbà yẹn ni Pọ́ọ̀lù mú Tímótì dání lẹ́nu ìrìn àjò tó rìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti wo ìtẹ̀síwájú Tímótì fún nǹkan bí oṣù mélòó kan, ó wá rán an lọ sí Tẹsalóníkà kó lè lọ tu àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀ nínú kó sì mú kí wọ́n fìdí múlẹ̀ gbọn-in. (Ka 1 Tẹsalóníkà 3:1-3, 6.) Ó ṣe kedere pé, ìgbà tí Tímótì ti wà lọ́dọ̀ọ́ ni ìlọsíwájú ẹ̀ ti fara hàn kedere fún gbogbo èèyàn.
6 Ẹ̀yin ọ̀dọ́ tẹ́ ẹ wà nínú ètò Ọlọ́run, ẹ sapá gidigidi kẹ́ ẹ lè láwọn ànímọ́ tẹ̀mí nísinsìnyí, kó lè hàn kedere pé ẹ̀ ń tẹ̀ síwájú nínú ọ̀nà tẹ́ ẹ gbà ń gbé ìgbé ayé yín gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni àti nínú ọ̀nà tẹ́ ẹ gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìgbà tí Jésù ti wà lọ́mọ ọdún méjìlá ló ti “ń bá a lọ ní títẹ̀síwájú ní ọgbọ́n.” (Lúùkù 2:52) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo bẹ́ ẹ ṣe lè jẹ́ kí ìlọsíwájú yín fara hàn láwọn ọ̀nà mẹ́ta yìí nígbèésí ayé yín: (1) nígbà tẹ́ ẹ bá dójú kọ ìṣòro, (2) tẹ́ ẹ bá ń múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó, àti (3) bẹ́ ẹ ṣe ń sapá láti di “òjíṣẹ́ àtàtà.”—1 Tím. 4:6.
Lo “Ìyèkooro Èrò Inú” Nígbà Ìṣòro
7. Ipa wo ni ìṣòro tó ń pinni lẹ́mìí máa ń ní lórí àwọn ọ̀dọ́?
7 Kristẹni ọ̀dọ́, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, tó ń jẹ́ Carol sọ pé: “Nígbà míì kì í wù mí kí n dìde tílẹ̀ bá mọ́ torí pé gbogbo nǹkan máa ń tojú sú mi.”a Kí ló fà á tí nǹkan fi máa ń sú u tó bẹ́ẹ̀? Nígbà tí Carol wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá, bàbá àti ìyá ẹ̀ kọra wọn sílẹ̀, Carol wá lọ ń gbé lọ́dọ̀ ìyá ẹ̀, tí kì í fàwọn ìlànà Bíbélì nípa ìwà rere sílò. Bíi ti Carol, ìwọ náà lè máa dojú kọ àwọn ìṣòro tó ń pinni lẹ́mìí, tó sì lè dà bíi pé kò sírètí.
8. Àwọn ìṣòro wo ni Tímótì ní?
8 Tímótì náà láwọn ìṣòro tó le gan-an, nígbà tó ń gbìyànjú láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, ó fara da “ọ̀ràn àìsàn . . . tí ó ṣe lemọ́lemọ́” nítorí ìṣòro inú tó ń yọ ọ́ lẹ́nu. (1 Tím. 5:23) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rán Tímótì lọ sí Kọ́ríńtì kó lè lọ bójú tó ìṣòro kan táwọn kan tó ń ta ko àpọ́sítélì náà dá sílẹ̀, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará ìjọ náà pé kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Tímótì, kó má bàa sí “ìbẹ̀rù kankan fún un” láàárín wọn. (1 Kọ́r. 4:17; 16: 10, 11) Ó jọ pé Tímótì máa ń tijú.
9. Kí ni ìyèkooro èrò inú, báwo ló sì ṣe yàtọ̀ sí ẹ̀mí ojo?
9 Kí Pọ́ọ̀lù lè ran Tímótì lọ́wọ́, ó rán an létí pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọ́run fún wa bí kò ṣe ti agbára àti ti ìfẹ́ àti ti ìyèkooro èrò inú.” (2 Tím. 1:7) “Ìyèkooro èrò inú” wé mọ́ kéèyàn lè ronú lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání. Ó tún kan kéèyàn lè fara da ipòkípò téèyàn bá bára ẹ̀, bí nǹkan ò tiẹ̀ rí béèyàn ṣe fẹ́. Àwọn ọ̀dọ́ kan tí òtítọ́ ò jinlẹ̀ nínú wọn máa ń ṣojo, wọ́n sì máa ń wá bí wọ́n ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tó ń pinni lẹ́mìí nípa sísùn ju bó ṣe yẹ lọ, wíwo tẹlifíṣọ̀n láwòjù, lílo oògùn olóró, mímú ọtí lámujù, lílọ síbi àríyá nígbà gbogbo tàbí ṣíṣe ìṣekúṣe. Àmọ́, Ìwé Mímọ́ gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n “kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé àti láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.”—Títù 2:12.
10, 11. Báwo ni ìyèkooro èrò inú ṣe ń jẹ́ ká lè gbára lé okun tí Ọlọ́run ń pèsè?
10 Bíbélì gba àwọn “ọ̀dọ́kùnrin níyànjú láti yè kooro ní èrò inú.” (Títù 2:6) Títẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí gba pé kéèyàn máa gbàdúrà nígbà tó bá níṣòro, kó sì gbẹ́kẹ̀ lé okun tí Ọlọ́run ń fúnni. (Ka 1 Pétérù 4:7.) Nípa bẹ́ẹ̀, wàá lè fi tọkàntọkàn gbára lé “okun tí Ọlọ́run ń pèsè.”—1 Pét. 4:11
11 Àdúrà àti ìyèkooro èrò inú ló ran Carol lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Ohun tó ṣòro fún mi jù lọ ni bí mi ò ṣe ní lọ́wọ́ sí ìwà pálapàla tí màmá mi ń hù. Àmọ́ àdúrà ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Mo mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú mi, torí náà ẹ̀rù ò bà mí mọ́.” Má gbàgbé pé tó o bá fara da ìṣòro, ńṣe ló máa sọ ẹ́ di alágbára. (Sm. 105:17-19; Ìdárò 3:27) Ìṣòro yòówù kó o ní, mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ò ní gbàgbé ẹ. Á “ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.”—Aísá. 41:10.
Mímúra Sílẹ̀ fún Ìgbéyàwó Aláyọ̀
12. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn Kristẹni tó ń ronú àtigbéyàwó fi ìlànà tó wà nínú Òwe 20:25 sílò?
12 Àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń kánjú ṣègbéyàwó, wọ́n rò pé ìyẹn ló máa yanjú ìṣòro àìláyọ̀, ìdánìkanwà, kí nǹkan máa súni tàbí ìṣòro míì tí wọ́n ní nínú ilé. Àmọ́, má gbàgbé pé ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó kì í ṣọ̀rọ̀ ṣeréṣeré o! Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn kan jẹ́ ẹ̀jẹ́ mímọ́ láìfara balẹ̀ ronú lórí ohun tó wé mọ́ ọn. (Ka Òwe 20:25.) Nígbà míì àwọn ọ̀dọ́ kì í ronú dáadáa lórí ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ ọkọ tàbí aya. Ẹ̀yìn tí wọ́n bá ti wọnú ẹ̀ tán ni wọ́n á wá rí i pé ó ju báwọn ṣe rò lọ.
13. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ káwọn tó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́sọ́nà ronú lé lórí, ibo ni wọ́n sì ti lè rí ìmọ̀ràn tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́?
13 Torí náà, kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ ẹnì kan sọ́nà, bi ara ẹ pé: ‘Kí nìdí tí mo fi fẹ́ ṣègbéyàwó? Kí làwọn ohun tí mò ń retí? Ṣé ẹni tó yẹ kí n fẹ́ nìyí? Ǹjẹ́ mo ti múra tán láti ṣe ojúṣe mi gẹ́gẹ́ bí ọkọ tàbí aya?’ “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti tẹ àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí kókó yìí jáde, kó lé ṣeé ṣe fún ẹ láti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ẹni tó o máa fẹ́.b (Mát. 24:45-47) Ńṣe ni kó o máa wo àwọn ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ bíi pé Jèhófà ló dìídì ń bá ẹ sọ̀rọ̀. Fara balẹ̀ gbé ohun tó wà níbẹ̀ yẹ̀ wò, kó o sì fi wọ́n sílò. Má ṣe sọ ara rẹ di “ẹṣin tàbí ìbaaka tí kò ní òye.” (Sm. 32:8, 9) Rí i pé o lóye ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ ọkọ tàbí aya. Tó o bá wá rí i pé ó ti ṣe tán láti ní ẹni tó o máa fẹ́, má gbà gbé láti jẹ́ “àpẹẹrẹ . . . nínú ìwà mímọ́.”—1 Tím. 4:12.
14. Bí òtítọ́ bá jinlẹ̀ nínú ẹ, báwo ló ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá ṣègbéyàwó?
14 Tí òtítọ́ bá jinlẹ̀ nínú ẹni, èyí tún máa ń jẹ́ kí nǹkan máa lọ dáadáa nínú ìdílé lẹ́yìn ìgbéyàwó. Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ máa ń sapá láti “dé orí ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi.” (Éfé. 4:11-14) Ó máa ń sapá gan-an láti fìwà jọ Kristi. Kristi tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ wa “kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀.” (Róòmù 15:3) Bí ọkọ tàbí aya ò bá gbájú mọ́ tara ẹ̀ nìkan, àmọ́ tó ń ronú nípa ẹnì kejì, àlàáfíà àti ìtura á wà nínú ilé wọn. (1 Kọ́r. 10:24) Ọkọ á máa fi ìfẹ́ tí kì í ṣe ti onímọtara-ẹni-nìkan hàn sí aya ẹ̀, aya náà á sì máa tẹrí bá fún ọkọ ẹ̀, bí Jésù ṣe ń tẹrí ba fún Orí rẹ̀.—1 Kọ́r. 11:3; Éfé. 5:25.
“Ṣàṣeparí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Ní Kíkún”
15, 16. Báwo lo ṣe lè mú kí ìtẹ̀síwájú rẹ fara hàn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?
15 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ pàtàkì tí Tímótì ṣe, ó ní: “Mo pàṣẹ fún ọ lọ́nà tí ó wúwo rinlẹ̀ níwájú Ọlọ́run àti Kristi Jésù, . . . wàásù ọ̀rọ̀ náà, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú.” Ó fi kún un pé: “Ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere, ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún.” (2 Tím. 4:1, 2, 5) Kí Tímótì bàa lè ṣe iṣẹ́ yìí, ó ní láti máa fi “àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ bọ́” ara ẹ̀ dáadáa.—Ka 1 Tímótì 4:6.
16 Báwo nìwọ náà ṣe lè máa fi “àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ bọ́” ara rẹ? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Máa bá a lọ ní fífi ara rẹ fún ìwé kíkà ní gbangba, fún ìgbani-níyànjú, fún kíkọ́ni. Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá.” (1 Tím. 4:13, 15) Béèyàn bá fẹ́ máa tẹ̀ síwájú, ó gbọ́dọ̀ máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Gbólóhùn náà, “fi ara rẹ fún wọn pátápátá” túmọ̀ sí pé kéèyàn máa fi tọkàntọkàn ṣe nǹkan. Báwo lo ṣe ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́? Ṣé o ti fi ara rẹ fún kíkẹ́kọ̀ọ́ “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”? (1 Kọ́r. 2:10) Àbí ìwọ̀nba díẹ̀ lò ń ṣe? Tó o bá ń ronú lórí ohun tó o kọ́, èyí á mú kó o máa fi sílò.—Ka Òwe 2:1-5.
17, 18. (a) Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o sapá láti máa ṣe? (b) Tó o bá nírú ẹ̀mí tí Tímótì ní, báwo ló ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?
17 Ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Michelle sọ pé: “Kí n lè máa ṣe dáadáa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, mo ní ètò tó dáa fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, mi ò sì ń pa ìpàdé jẹ. Ìyẹn ló jẹ́ kí n máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.” Ká sòótọ́, iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mú kí ọ̀nà tó o gbà ń lo Bíbélì lóde ẹ̀rí sunwọ̀n sí i, á sì jẹ́ kó o tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Sapá láti máa kàwé lọ́nà tó tọ́, kó o sì máa jẹ́ kí ìdáhùn ẹ láwọn ìpàdé nítumọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, ó yẹ kó o máa múra iṣẹ́ tó o bá ní nípàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà táwọn ará á fi rí ẹ̀kọ́ kọ́, kó o sì mú iṣẹ́ rẹ láti ibi tí wọ́n bá ti yanṣẹ́ fún ẹ.
18 ‘Ṣíṣe iṣẹ́ ajíhìnrere’ gba pé kó o jẹ́ kí ọ̀nà tó o gbà ń wàásù túbọ̀ dáa, kó o sì máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti rí ìgbàlà. Èyí ń béèrè pé kó o mú kí “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” rẹ sunwọ̀n sí i. (2 Tím. 4:2) Tó o bá ń ṣètò láti jáde òde ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn tó nírìírí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wàá lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kọ́ni, bí Tímótì ṣe kẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ Pọ́ọ̀lù nígbà tó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú rẹ̀. (1 Kọ́r. 4:17) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ti ràn lọ́wọ́, ó sọ pé, kì í ṣe pé òun wàásù ìhìn rere fún wọn nìkan ni, àmọ́ òun tún fún wọn ní ‘ọkàn òun,’ tàbí pé òun fi ẹ̀mí òun wewu nítorí wọn, torí pé wọ́n di olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún òun. (1 Tẹs. 2:8) Kó o lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, o ní láti nírú ẹ̀mí tí Tímótì ní, tọkàntọkàn ló fi ń bójú tó àwọn ẹlòmíì, ó sì ‘sìnrú fún ìtẹ̀síwájú ìhìn rere.’ (Ka Fílípì 2:19-23.) Ṣéwọ náà máa ń firú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ bẹ́ẹ̀ hàn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?
Ìtẹ̀síwájú Máa Ń Mú Ojúlówó Ìtẹ́lọ́rùn Wá
19, 20. Kí nìdí tí ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí fi ń máyọ̀ wá?
19 Ó gba ìsapá gan-an béèyàn bá fẹ́ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Àmọ́ tó o bá fara balẹ̀ mú kí ọ̀nà tó o gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ sunwọ̀n sí i, tó bá yá, wàá láǹfààní láti “sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di ọlọ́rọ̀” nípa tẹ̀mí, wọ́n á sì di “ìdùnnú tàbí adé ayọ̀ ńláǹlà” fún ẹ. (2 Kọ́r. 6:10; 1 Tẹs. 2:19) Arákùnrin Fred, tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún sọ pé: “Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, mò ń lo àkókò mi láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Òótọ́ ni pé ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírí gbà lọ.”
20 Nígbà tí ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Daphne, ń sọ̀rọ̀ nípa ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tó rí látinú jíjẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, ó ní: “Mo wá dẹni tó túbọ̀ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa rẹ̀. Tó o bá ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ débi tágbára ẹ gbé e dé, ọkàn ẹ á balẹ̀, wàá sì ní ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn!” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn lè má tètè kíyè sí ìtẹ̀síwájú rẹ nípa tẹ̀mí, mọ̀ pé Jèhófà ń rí i, ó sì mọrírì ẹ̀. (Héb. 4:13) Kò sí àníàní pé ẹ̀yin ọ̀dọ́ lè mú ìyìn àti ògo bá Baba wa ọ̀run. Torí náà, máa bá a lọ láti mú ọkàn Jèhófà yọ̀, bó o ṣe ń fi tọkàntọkàn jẹ́ kí ìtẹ̀síwájú rẹ fara hàn.—Òwe 27:11.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ṣé Ẹni Tó Yẹ Kí N Fẹ́ Nìyí?” nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá kejì; “Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run Lórí Ọ̀ràn Yíyan Ẹni Tí A Óò Fẹ́,” nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 2001; àti “Bawo Ni Igbeyawo Aitọmọ ogun-ọdun Ti Lọgbọn Ninu Tó?” nínú Jí! October 22, 1984.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Kí ni ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí wé mọ́?
• Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí ìtẹ̀síwájú rẹ fara hàn . . .
nígbà ìṣòro?
tó o bá ń múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó?
lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àdúrà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè mú kí ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wọn sunwọ̀n sí i?