Kí Ìjọ Máa Yin Jèhófà
“Ṣe ni èmi yóò máa polongo orúkọ rẹ fún àwọn arákùnrin mi; ṣe ni èmi yóò máa . . . yìn ọ́ ní àárín ìjọ.”—HÉBÉRÙ 2:12.
1, 2. Kí ló mú kí ìjọ ṣe pàtàkì gan-an, kí sì ni olórí ohun tí ìjọ wà fún?
LÁTAYÉBÁYÉ làwọn èèyàn ti máa ń ní ìfararora àti ìfọ̀kànbalẹ̀ nínú ìdílé. Àmọ́ yàtọ̀ sí ìdílé, Bíbélì fi yé wa pé ibì kan tún wà tí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn jákèjádò ayé lónìí ti ń ní ìfararora àti ìfọ̀kànbalẹ̀ tí kò lẹ́gbẹ́. Ibo nìyẹn? Ìjọ Kristẹni ni. Yálà ẹ sún mọ́ra yín pẹ́kípẹ́kí tẹ́ ẹ sì ń ran ara yín lọ́wọ́ nínú ilé tó o ti wá tàbí ẹ kì í ṣe bẹ́ẹ̀, o lè mọ ohun tí Ọlọ́run ti pèsè nípasẹ̀ ìjọ, àní ó tiẹ̀ yẹ kó o mọ̀ ọ́n. Tó bá sì wá jẹ́ pé ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lò ń lọ, ó lè ti rí i pé ìfararora àti ìfọkànbalẹ̀ tó ò ń ní níbẹ̀ kò lẹ́gbẹ́.
2 Ìjọ tá à ń wí yìí kì í wulẹ̀ ṣe ìpàdé ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Kì í ṣe ẹgbẹ́ táwọn aráàlú dá sílẹ̀ tàbí ẹgbẹ́ mìíràn láwùjọ níbi táwọn kan ti ń kóra jọ, irú bí àwọn tí iṣẹ́ tàbí òwò dà pọ̀ tàbí àwọn tó jọ nífẹ̀ẹ́ sí eré ìdárayá kan náà. Ohun tí ìjọ wà fún ní pàtàkì ni láti máa yin Jèhófà Ọlọ́run. Bó sì ti rí nìyẹn látọdúnmọdún gẹ́gẹ́ bí ìwé Sáàmù ṣe fi hàn. Sáàmù 35:18 sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ nínú ìjọ ńlá; èmi yóò máa yìn ọ́ láàárín àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ níye.” Bákan náà, Sáàmù 107:31, 32 gbà wá níyànjú pé: “Kí àwọn ènìyàn máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà nítorí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn. Kí wọ́n sì máa kókìkí rẹ̀ nínú ìjọ àwọn ènìyàn.”
3. Kí ni nǹkan míì tí Pọ́ọ̀lù sọ pé ìjọ wà fún?
3 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun pàtàkì mìíràn tí ìjọ wà fún nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa “agbo ilé Ọlọ́run, èyí tí í ṣe ìjọ Ọlọ́run alààyè, ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́.” (1 Tímótì 3:15) Ìjọ wo ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Àwọn ọ̀nà wo ni Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ”? Ipa wo ló sì yẹ kí ìjọ ní lórí ìgbésí ayé wa? Láti lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo onírúurú ọ̀nà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ.”
4. Àwọn wo ni ọ̀rọ̀ náà “ìjọ” tọ́ka sí ní ọ̀pọ̀ jù lọ ibi tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ti lò ó?
4 Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a sábà máa ń tú sí “ìjọ” wá látinú ọ̀rọ̀ kan nínú èdè Hébérù tó túmọ̀ sí ‘pè jọ.’ (Diutarónómì 4:10; 9:10) Onísáàmù kan lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ” fún àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run, wọ́n sì tún lè lo ọ̀rọ̀ náà fún àwọn aṣebi. (Sáàmù 26:5; 89:5-7) Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni ọ̀rọ̀ náà “ìjọ” tọ́ka sí ní ọ̀pọ̀ jù lọ ibi tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ti lò ó. Ọlọ́run fi hàn pé Jákọ́bù “yóò di ìjọ àwọn ènìyàn,” ó sì rí bẹ́ẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 28:3; 35:11; 48:4) Jèhófà pe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde, ìyẹn ni pé ó yàn wọ́n láti jẹ́ “ìjọ Jèhófà,” tàbí “ìjọ Ọlọ́run tòótọ́.”—Númérì 20:4; Nehemáyà 13:1; Jóṣúà 8:35; 1 Sámúẹ́lì 17:47; Míkà 2:5.
5. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì wo la sábà máa ń túmọ̀ sí “ìjọ,” àwọn wo la sì lè lo ọ̀rọ̀ náà fún?
5 Ohun táwọn Gíríìkì máa ń pe “ìjọ” ní èdè wọn ni ek·kle·siʹa. Inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì méjì kan tó túmọ̀ sí “jáde” àti “pè” ni ọ̀rọ̀ yìí ti wá. Wọ́n lè lo ọ̀rọ̀ náà fún ẹgbẹ́ tí kì í ṣe ti ìsìn, irú bí “àpéjọ” àwọn èèyàn tí Dímẹ́tíríù kó jọ láti ta ko Pọ́ọ̀lù ní Éfésù. (Ìṣe 19:32, 39, 41) Àmọ́ ìjọ Kristẹni ni ọ̀rọ̀ náà tọ́ka sí ní ọ̀pọ̀ jù lọ ibi tí Bíbélì ti lò ó. Nínú àwọn Bíbélì kan, wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà sí “ṣọ́ọ̀ṣì,” ṣùgbọ́n ìwé atúmọ̀ èdè Bíbélì náà The Imperial Bible-Dictionary sọ pé ọ̀rọ̀ náà “kò . . . túmọ̀ sí ilé táwọn Kristẹni máa ń kóra jọ sí fún ìjọsìn.” Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ó kéré tán, ọ̀nà mẹ́rin ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ.”
Ìjọ Ọlọ́run Tí Í Ṣe Àwọn Ẹni Àmì Òróró
6. Kí ni Dáfídì àti Jésù ṣe nínú ìjọ?
6 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé Jésù ni ọ̀rọ̀ Dáfídì tó wà nínú Sáàmù 22:22 ṣẹ sí lára. Ó sọ pé: “‘Ṣe ni èmi yóò máa polongo orúkọ rẹ fún àwọn arákùnrin mi; ṣe ni èmi yóò máa fi orin yìn ọ́ ní àárín ìjọ.’ Nítorí náà, ó di dandan fún [Jésù] láti dà bí ‘àwọn arákùnrin’ rẹ̀ lọ́nà gbogbo, kí ó lè di àlùfáà àgbà tí ó jẹ́ aláàánú àti olùṣòtítọ́ nínú àwọn ohun tí ó jẹmọ́ ti Ọlọ́run.” (Hébérù 2:12, 17) Dáfídì pẹ̀lú máa ń yin Ọlọ́run nínú ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un. (Sáàmù 40:9) Ṣùgbọ́n, kí ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí nígbà tó sọ pé Jésù yin Ọlọ́run “ní àárín ìjọ”? Ìjọ wo nìyẹn?
7. Àwọn wo ni Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ” fún ní pàtàkì?
7 Ọ̀rọ̀ inú Hébérù 2:12, 17 tá a kà yẹn ṣe pàtàkì gan-an ni. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé Kristi jẹ́ ara ìjọ tóun alára ti polongo orúkọ Ọlọ́run fáwọn arákùnrin rẹ̀. Àwọn wo làwọn arákùnrin rẹ̀ yìí? Àwọn ni àwọn tó di ara “irú-ọmọ Ábúráhámù,” ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù, tí wọ́n jẹ́ “alábàápín ìpè ti ọ̀run.” (Hébérù 2:16–3:1; Mátíù 25:40) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn tí Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ” fún ní pàtàkì ni àpapọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn. Àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì para pọ̀ jẹ́ “ìjọ àwọn àkọ́bí tí a ti kọrúkọ wọn sílẹ̀ ní ọ̀run.”—Hébérù 12:23.
8. Kí ni Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìdásílẹ̀ ìjọ Kristẹni?
8 Jésù fi hàn pé a óò dá “ìjọ” Kristẹni yìí sílẹ̀. Ní nǹkan bí ọdún kan ṣáájú ìgbà tí wọ́n pa Jésù, ó sọ fún Pétérù pé: “Ìwọ ni Pétérù, orí àpáta ràbàtà yìí sì ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi sí dájúdájú, àwọn ibodè Hédíìsì kì yóò sì borí rẹ̀.” (Mátíù 16:18) Pétérù àti Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé Jésù alára ni àpáta ràbàtà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yìí, òye tí wọ́n ní yìí sì tọ̀nà. Nínú ìwé tí Pétérù kọ, ó sọ pé “àwọn òkúta ààyè” tí wọ́n fi kọ́ ilé tẹ̀mí sórí àpáta ràbàtà yìí, ìyẹn Kristi, ni “àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí [wọ́n] lè polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá” ẹni tó pè wọ́n jáde.—1 Pétérù 2:4-9; Sáàmù 118:22; Aísáyà 8:14; 1 Kọ́ríńtì 10:1-4.
9. Ìgbà wo la dá ìjọ Ọlọ́run sílẹ̀?
9 Ìgbà wo ni “àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní” yìí di ìjọ Kristẹni? Ọjọ́ àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni. Ìgbà yẹn ni Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọlẹ́yìn tí wọ́n pé jọ ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tó yá, lọ́jọ́ yẹn kan náà, Pétérù sọ àsọyé tó ta àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù jí. Pípa tí wọ́n pa Jésù dun ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wọn gan-an, wọ́n ronú pìwà dà, wọ́n sì ṣe ìrìbọmi. Ìtàn yìí fi hàn pé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta èèyàn ló ronú pìwà dà tí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi lọ́jọ́ náà, èyí tó mú kí wọ́n di ara ìjọ Ọlọ́run tó jẹ́ ìjọ tuntun táwọn tó wà nínú rẹ̀ ń pọ̀ sí i. (Ìṣe 2:1-4, 14, 37-47) Ìjọ náà ń gbèrú nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù ni wọ́n rí i pé lóòótọ́, Ọlọ́run ti kọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀, pé wọn kì í ṣe ìjọ Ọlọ́run mọ́. Àwọn tó wá di ìjọ Ọlọ́run tòótọ́ ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” nípa tẹ̀mí.—Gálátíà 6:16; Ìṣe 20:28.
10. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ sí ìjọ Ọlọ́run?
10 Bíbélì sábà máa ń fi hàn pé Jésù yàtọ̀ sí àwọn ẹni àmì òróró. Irú ìyàtọ̀ bẹ́ẹ̀ hàn nínú ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yìí, “nípa Kristi àti ìjọ.” Jésù ni orí ìjọ yìí tí í ṣe àpapọ̀ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Pọ́ọ̀lù sọ pé Ọlọ́run “fi [Jésù] ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ, èyí tí ó jẹ́ ara rẹ̀.” (Éfésù 1:22, 23; 5:23, 32; Kólósè 1:18, 24) Lóde òní, ìwọ̀nba kéréje ló ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ ìjọ náà. Ó sì dá wa lójú hán-ún pé Jésù Kristi tí í ṣe Orí wọn nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Éfésù 5:25 sọ bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn tó, ó ní: “Kristi pẹ̀lú . . . nífẹ̀ẹ́ ìjọ, . . . ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” Jésù nífẹ̀ẹ́ wọn nítorí pé tọkàntara ni wọ́n fi ń “rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀,” gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ṣe nígbà tó wà láyé ńbí.—Hébérù 13:15.
Àwọn Ọ̀nà Míì Tí Bíbélì Gbà Lo Ọ̀rọ̀ Náà “Ìjọ”
11. Kí ni ọ̀nà kejì tí Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ”?
11 Nígbà míì, Bíbélì máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ” lọ́nà tí kò tọ́ka sí gbogbo àwọn ẹni àmì òróró tó para pọ̀ jẹ́ “ìjọ Ọlọ́run,” tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwùjọ Kristẹni kan, ó ní: “Ẹ máa fà sẹ́yìn kúrò nínú dídi okùnfà ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì pẹ̀lú àti fún ìjọ Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 10:32) Lóòótọ́, bí Kristẹni kan nílùú Kọ́ríńtì ìgbàanì bá ṣe ohun tí kò bójú mu, ìyẹn lè mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀. Àmọ́, ṣé ìwà tí kò bójú mu tí Kristẹni kan bá hù nígbà yẹn lè máa jẹ́ okùnfà ìkọ̀sẹ̀ fún gbogbo àwọn Gíríìkì, àwọn Júù àtàwọn ẹni àmì òróró látayé ìgbà yẹn títí dòní? Kò lè rí bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ó dà bíi pé àwọn tí ẹsẹ yìí pè ní “ìjọ Ọlọ́run” ni àwọn Kristẹni tó wà lákòókò kan pàtó. Ìdí nìyẹn tá a fi lè sọ pé Ọlọ́run ń tọ́ ìjọ sọ́nà, tàbí pé ó ń ran ìjọ lọ́wọ́, tàbí pé ó ń bù kún ìjọ, tó túmọ̀ sí gbogbo Kristẹni tó wà lákòókò kan pàtó níbikíbi tí wọn ì báà wà. Tá a bá sì sọ pé ayọ̀ àti àlàáfíà wà nínú ìjọ Ọlọ́run lónìí, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ayọ̀ àti àlàáfíà wà láàárín gbogbo àwọn ará lápapọ̀.
12. Kí ni ọ̀nà kẹta tí Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ”?
12 Ọ̀nà kẹta tí Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ” jẹ́ láti tọ́ka sí gbogbo àwọn Kristẹni tó ń gbé lágbègbè ibì kan. Bíbélì sọ pé: “Ìjọ jákèjádò Jùdíà àti Gálílì àti Samáríà wọnú sáà àlàáfíà.” (Ìṣe 9:31) Àwùjọ àwọn Kristẹni tó wà ní àgbègbè ńlá yẹn ju ẹyọ kan lọ, àmọ́ Bíbélì pe gbogbo àwùjọ àwọn Kristẹni wọ̀nyí tó wà ní Jùdíà, Gálílì àti Samáríà lápapọ̀ ní “ìjọ.” Tá a bá wo iye àwọn tó ṣèrìbọmi lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni àtàwọn tó ṣèrìbọmi láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ó ṣeé ṣe kí àwùjọ àwọn Kristẹni tó máa ń pàdé pọ̀ déédéé ní àgbègbè Jerúsálẹ́mù ju ẹyọ kan lọ. (Ìṣe 2:41, 46, 47; 4:4; 6:1, 7) Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kìíní ṣàkóso Jùdíà títí dìgbà ikú rẹ̀ lọ́dún 44 Sànmánì Kristẹni, ohun tí Tẹsalóníkà kìíní orí kejì ẹsẹ kẹrìnlá sì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé ní nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Kristẹni, àwọn ìjọ mélòó kan ti wà ní Jùdíà. Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé nígbà tí Bíbélì sọ pé Hẹ́rọ́dù ‘fojú àwọn kan lára àwọn tí ó jẹ́ ti ìjọ gbolẹ̀,’ ó ṣeé ṣe kí ìjọ tí ẹsẹ yìí mẹ́nu kàn ju ẹyọ kan lọ tó máa ń pàdé ní Jerúsálẹ́mù.—Ìṣe 12:1.
13. Kí ni ọ̀nà kẹrin tí Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ,” tó sì jẹ́ ọ̀nà tó wọ́pọ̀ jù tí Bíbélì gbà lò ó?
13 Ọ̀nà kẹrin tí Bíbélì sábà máa ń gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ,” tó sì jẹ́ ọ̀nà tí kò gbòòrò, jẹ́ láti fi tọ́ka sí àwọn Kristẹni tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ ìjọ kan, irú bí ìjọ tó ń pàdé nínú ilé. Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ìjọ Gálátíà.” Ó tó ìjọ mélòó kan tó wà ní ìpínlẹ̀ Gálátíà tí í ṣe ọkàn lára ìpínlẹ̀ tó wà lábẹ́ ìjọba Róòmù. Ẹ̀ẹ̀méjì ni Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ náà “àwọn ìjọ,” tó fi hàn pé ìjọ tó wà ní ìpínlẹ̀ Gálátíà ju ẹyọ kan lọ. Lára wọn ni ìjọ tó wà ní Áńtíókù, Déébè, Lísírà, àti Íkóníónì. Wọ́n yan àwọn àgbà ọkùnrin sí àwọn ìjọ wọ̀nyí, ìyẹn àwọn alábòójútó, tí wọ́n kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè lọ́wọ́ ẹni tó bá máa jẹ́ alábòójútó. (1 Kọ́ríńtì 16:1; Gálátíà 1:2; Ìṣe 14:19-23) “Ìjọ Ọlọ́run” ni Ìwé Mímọ́ pe gbogbo ìjọ wọ̀nyí.—1 Kọ́ríńtì 11:16; 2 Tẹsalóníkà 1:4.
14. Kí la lè sọ nípa bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ” nínú àwọn ẹsẹ mélòó kan?
14 Nígbà míì, àwọn àwùjọ tó ń pàdé pọ̀ fún ìjọsìn máa ń kéré níye, tó fi jẹ́ pé ilé àdáni máa ń gbà wọ́n. Síbẹ̀, Bíbélì pe irú àwọn àwùjọ kéékèèké bẹ́ẹ̀ ní “ìjọ.” Àwọn kan tá a rí nínú Bíbélì ni àwọn ìjọ tó ń ṣèpàdé nínú ilé Ákúílà àti Pírísíkà, Nímífà, àti Fílémónì. (Róòmù 16:3-5; Kólósè 4:15; Fílémónì 2) Ó dájú pé ìṣírí ńlá lèyí máa jẹ́ fáwọn ìjọ kéékèèké tó wà lóde òní, tí wọ́n lè máa pàdé pọ̀ déédéé nínú ilé àdáni. Jèhófà ò fojú pa irú ìjọ kéékèèké bẹ́ẹ̀ rẹ́ ní ọ̀rúndún kìíní, ó sì dájú pé kò ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn tòde òní pẹ̀lú, àní ó ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí wọn, ó sì fi ń tì wọ́n lẹ́yìn.
Àwọn Ìjọ Ń Yin Jèhófà
15. Kí làwọn ohun tí ẹ̀mí mímọ́ máa ń mú káwọn kan nínú àwọn ìjọ kan ní ọ̀rúndún kìíní ṣe?
15 A sọ lẹ́ẹ̀kan pé Jésù yin Ọlọ́run láàárín ìjọ gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 22:22 ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Hébérù 2:12) Ohun táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ sì ní láti ṣe gan-an nìyẹn. Ní ọ̀rúndún kìíní, lọ́jọ́ tí Ọlọ́run fẹ̀mí yan àwọn Kristẹni tòótọ́ láti di ọmọ Ọlọ́run kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di arákùnrin Kristi, ẹ̀mí mímọ́ tún ń lo àwọn kan lára wọn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ẹ̀mí yìí jẹ́ kí wọ́n láwọn ẹ̀bùn kan lọ́nà ìyanu. Lára àwọn ohun tí ẹ̀bùn ẹ̀mí yìí ń mú kí wọ́n ṣe ni pé, ó ń mú kí wọ́n sọ̀rọ̀ ọgbọ́n àti ìmọ̀ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó fún wọn lágbára láti wo àwọn èèyàn sàn àti láti sọ àsọtẹ́lẹ̀, ó tiẹ̀ máa ń mú kí wọ́n fi èdè tí wọn ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ sọ̀rọ̀.—1 Kọ́ríńtì 12:4-11.
16. Kí ni ohun kan tí ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ lọ́nà ìyanu wà fún?
16 Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa fífi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, ó ní: “Ṣe ni èmi yóò fi ẹ̀bùn ẹ̀mí kọrin ìyìn, ṣùgbọ́n èmi yóò fi èrò inú mi kọrin ìyìn pẹ̀lú.” (1 Kọ́ríńtì 14:15) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì káwọn tóun ń bá sọ̀rọ̀ lóye ohun tóun ń sọ, kí wọ́n lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ níbẹ̀. Ohun tó jẹ Pọ́ọ̀lù lógún ni pé kó máa yin Jèhófà nínú ìjọ. Ó gba àwọn mìíràn tí wọ́n ní ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ níyànjú, ó ní: “Ẹ wá ọ̀nà láti pọ̀ gidigidi nínú wọn fún gbígbé ìjọ ró,” ìyẹn ìjọ tí wọ́n ti ń lo ẹ̀bùn ẹ̀mí yẹn. (1 Kọ́ríńtì 14:4, 5, 12, 23) Ó hàn gbangba pé ọ̀rọ̀ àwọn ìjọ yìí jẹ Pọ́ọ̀lù lógún, ó mọ̀ pé àwọn ìjọ náà máa jẹ́ káwọn Kristẹni láǹfààní láti yin Ọlọ́run.
17. Kí ló dá wa lójú pé Ọlọ́run ń ṣe fáwọn ìjọ tó wà lóde òní?
17 Jèhófà ń bá a nìṣó láti máa lo ìjọ rẹ̀, ó sì tún ń ṣàtìlẹ́yìn fún un. Ó ń bù kún àwọn tó para pọ̀ jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé. Ohun kan tó fi hàn pé Jèhófà ń bù kún wọn ni ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí táwọn èèyàn Ọlọ́run ń gbádùn. (Lúùkù 12:42) Jèhófà ń bù kún ẹgbẹ́ ará kárí ayé lápapọ̀. Ó tún ń bù kún ìjọ kọ̀ọ̀kan, níbi tá a ti ń fi ìwà àti ìṣe wa àti ìdáhùn wa nípàdé yin Ẹlẹ́dàá. Ibẹ̀ la ti ń gba ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ tó máa jẹ́ ká lè máa yin Ọlọ́run láwọn ibòmíràn yàtọ̀ sí ìpàdé ìjọ.
18, 19. Ìjọ yòówù kí Kristẹni tòótọ́ wà, kí ló máa fẹ́ láti ṣe?
18 Rántí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ ìyànjú fáwọn Kristẹni tí ń bẹ nínú ìjọ tó wà nílùú Fílípì ní ilẹ̀ Makedóníà pé: ‘Èyí ni ohun tí mo ń bá a lọ ní gbígbàdúrà, pé kí ẹ lè kún fún èso òdodo, èyí tí í ṣe nípasẹ̀ Jésù Kristi, fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.’ Lára ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe èyí ni pé kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wọn nínú Jésù àti ìrètí àgbàyanu tí wọ́n ní fáwọn tí kì í ṣara ìjọ. (Fílípì 1:9-11; 3:8-11) Ìyẹn ni Pọ́ọ̀lù fi gba àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ níyànjú pé: “Nípasẹ̀ [Jésù], ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.”—Hébérù 13:15.
19 Ǹjẹ́ inú rẹ máa ń dùn láti yin Ọlọ́run “ní àárín ìjọ” bíi ti Jésù? Ṣé inú rẹ máa ń dùn láti fi ẹnu rẹ yin Jèhófà lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ò tíì mọ Ọlọ́run, tí wọn ò sì tíì máa yìn ín? (Hébérù 2:12; Róòmù 15:9-11) Dé ìwọ̀n ayé kan, ojú tí kálukú wa fi ń wo ipa tí ìjọ tóun wà ń kó nínú ìṣètò Ọlọ́run ló máa pinnu ohun tó máa jẹ́ ìdáhùn wa sí ìbéèrè yẹn. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a óò jíròrò bí Jèhófà ṣe ń darí ìjọ tí a wà àti bó ṣe ń lo ìjọ náà, a óò tún jíròrò ipa tó yẹ kí ìjọ wa ní lórí ìgbésí ayé wa lóde òní.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo la ṣe dá “ìjọ Ọlọ́run,” tí í ṣe àpapọ̀ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, sílẹ̀?
• Kí ni àwọn ọ̀nà mẹ́ta míì tí Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ìjọ”?
• Kí ni Dáfídì, Jésù àtàwọn Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní ṣe nínú ìjọ, kí ló sì yẹ kí èyí mú káwa náà máa ṣe?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ìjọ wo ni Jésù jẹ́ ìpìlẹ̀ rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwùjọ àwọn Kristẹni kọ̀ọ̀kan ń pàdé pọ̀ gẹ́gẹ́ bí “àwọn ìjọ Ọlọ́run”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Benin, àwa náà lè máa yin Jèhófà láàárín àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ níye