Ìwọ Ha Ń Ṣe Ìfẹ́-Inú Ọlọrun Bí?
NÍNÚ iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé wọn, méjì lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pàdé àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Episcopal kan. Ó jọ pé ọkùnrin dáradára kan ni, ó nírùngbọ̀n, ó tó ẹni 60 ọdún, ó wọ ẹ̀wù alápá péńpé tí a fi orúkọ ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ dárà sí. Ní gbólóhùn kan, ó sọ pé: “Ó wù mí pé kí àwọn mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì wa ní ìtara nínú títan Ọ̀rọ̀ náà kálẹ̀ bíi tiyín, ṣùgbọ́n mo fẹ́ láti sọ fún yín pé kí ẹ máṣe wá sí ilé mi mọ́ láti ìsinsìnyí lọ.”
Bẹ́ẹ̀ni, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ni ń bẹ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí wọ́n sì ń gbóríyìn fún wọn fún ìtara àti ìtara-ọkàn wọn. Síbẹ̀, wọn kò lọ́kàn-ìfẹ́ rárá nínú ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò jẹ́ gbé ṣíṣe iṣẹ́ náà fúnraawọn yẹ̀wò. Bí ó ti wù kí ó rí, ipò ọ̀ràn títakora yìí kìí ṣe ohun titun. Jesu kíyèsí i ní ọjọ́ rẹ̀, ó sì tẹnumọ́ kókó náà nípasẹ̀ àpèjúwe amúnironújinlẹ̀ kan.
“Kí ni ẹ̀yin ń rò? Ọkùnrin kan wà tí ó ní ọmọkùnrin méjì; ó tọ èkínní wá, ó sì wí pé, Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ lónìí nínú ọgbà àjàrà mi. Ó sì dáhùn wí pé, Èmi kì yóò lọ: ṣùgbọ́n ó ronú níkẹyìn, ó sì lọ. Ó sì tọ èkejì wá, ó sì wí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Ó sì dáhùn wí fún un pé, Èmi ó lọ, baba: kò sì lọ. Nínú àwọn méjèèjì, èwo ni ó ṣe [“ìfẹ́-inú,” NW] baba rẹ̀?”—Matteu 21:28-31.
Ìdáhùn náà ṣe kedere. Gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀pọ̀ èrò tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Jesu, àwa yóò fèsì pé, “Èyí èkínní.” Ṣùgbọ́n jìnnà réré sí ohun tí ó ṣeé fojúrí, nípasẹ̀ àpèjúwe yẹn, Jesu ń pè é wá sí àfiyèsí wa pé ṣíṣe ohun tí baba fẹ́ ni ohun tí ó ṣe pàtàkì jù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọkùnrin kejì sọ pé ohun kì yóò lọ, ó lọ níkẹyìn a sì gbóríyìn fún un fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Ṣíṣe irú iṣẹ́ títọ́ kan ṣe pàtàkì lọ́nà kan náà. Ọmọ kejì gbégbèésẹ̀ nípa ṣíṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà baba náà; kò jáde lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà tirẹ̀.
Ìtumọ̀ wo ni gbogbo eyí ní fún wa? Kí ni Ọlọrun béèrè lọ́wọ́ àwọn olùjọ́sìn lónìí? Kí ni a lè kọ́ nínú ìgbésí-ayé Jesu tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́-inú Baba rẹ̀? Àwọn ìbéèrè pàtàkì nìwọ̀nyí, wíwá tí a wa ìdáhùn títọ́ rí yóò sì túmọ̀sí ire wa ayérayé, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé “ẹni tí ó ba ń ṣe [“ìfẹ́-inú,” NW] Ọlọrun ni yóò dúró láéláé.”—1 Johannu 2:17; Efesu 5:17.
Kí Ni “Ìfẹ́-Inú Ọlọrun”?
Ọ̀rọ̀ orúkọ náà “ìfẹ́-inú” ní a tò tẹ̀léra ní ìgbà tí ó ju 80 lọ nínú Comprehensive Concordance of the New World Translation of the Holy Scriptures. Nǹkan bíi 60 nínú ìgbà tí ó farahàn wọ̀nyí (tàbí nǹkan bí ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún iye ìgbà náà) ìtọ́kasí náà jẹ́ sí ìfẹ́-inú Ọlọrun. Àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ bíi “ìfẹ́-inú ti Ọlọrun,” “ìfẹ́-inú Baba mi,” àti “ìfẹ́-inú Ọlọrun” farahàn ní ìgbà tí ó ju 20 lọ. Láti inú èyí a lè ríi pé ìfẹ́-inú Ọlọrun ni ó níláti jẹ́ ohun ṣíṣe pàtàkì jùlọ fún wa. Ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun níláti jẹ́ ohun tí ó kàn wá gbọ̀ngbọ̀n jùlọ nínú ìgbésí-ayé wa.
Ní Yoruba ọ̀rọ̀ orúkọ náà “ìfẹ́-inú” túmọ̀sí ‘ìfẹ́-ọkàn, ìdàníyànfẹ́, ìpinnu, ohun tí ẹnìkan nífẹ̀ẹ́-ọkàn sí, ní pàtàkì yíyàn tàbí ìpinnu ẹnìkan tí ó ní ọlá-àṣẹ tàbí agbára.’ Nítorí náà, Jehofa, Aláṣẹ Gíga Jùlọ, ní ìfẹ́-inú, ìfẹ́-ọkàn tàbí ìpinnu kan. Kí ni ó jẹ́? Ìwé Mímọ́ sọ fún wa lápákan pé “ìfẹ́-inú [Ọlọrun] ni pé kí a lè gba gbogbo oríṣiríṣi ènìyàn là kí wọn sì wá sínú ìmọ̀ pípéye ti òtítọ́.” (1 Timoteu 2:4, NW) Jesu Kristi àti àwọn Kristian ìjímìjí ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn láti mú ìmọ̀ pípéye yìí tọ àwọn ẹlòmíràn lọ.—Matteu 9:35; Iṣe 5:42; Filippi 2:19, 22.
Ta ni ń ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun lónìí? Lára iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó billion méjì ènìyàn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jesu Kristi, mélòó ni ó dàbí ọmọkùnrin inú àkàwé Jesu, tí ó lọ tí ó sì ṣe ìfẹ́-inú baba rẹ̀? Ìdáhùn náà kò nira láti rí. Àwọn ọmọlẹ́yìn tí ń tẹ̀lé ipasẹ̀ Jesu Kristi nítòótọ́ yóò máa ṣe iṣẹ́ tí ó sọ pé wọn yóò ṣe: “A kò lè ṣàìmá kọ́ wàásù ìhìnrere ní gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Marku 13:10) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí wọ́n tó million mẹ́rin àti àbọ̀ kárí ayé, ń wàásù ìhìnrere Ijọba Ọlọrun wọ́n sì ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn taápọntaápọn, ní títọ́ka sí Ìjọba náà gẹ́gẹ́ bí ìrètí kanṣoṣo tí aráyé ní fún àlàáfíà àti àìléwu. Ìwọ ha ń nípìn-ín lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ nínú ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun bí? Ìwọ ha ń wàásù ìhìnrere Ìjọba náà gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣe bí?—Iṣe 10:42; Heberu 10:7.
Rírí Ayọ̀ nínú Ṣíṣe Ìfẹ́-Inú Ọlọrun
Nígbà tí ó jẹ́ pé ayọ̀ wà nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ ohun tí ìfẹ́-inú Baba jẹ́, ayọ̀ títóbi jù wà nínú kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn ní ìfẹ́-inú Ọlọrun. Jesu rí ayọ̀ nínú kíkọ́ àwọn ènìyàn nípa Baba rẹ̀. Ó dàbí oúnjẹ fún un. (Johannu 4:34) Àwa pẹ̀lú yóò gbádùn ayọ̀ tòótọ́ bí a bá ṣe gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣe, ìyẹn ni pé, kí a wàásù kí a sì kọ́ni ní ohun tí òun kọ́ni, àwọn ohun tí òun rí gbà láti ọ̀dọ̀ Baba rẹ̀. (Matteu 28:19, 20) Gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣèlérí, “bí ẹ̀yin bá mọ nǹkan wọ̀nyí, [“aláyọ̀,” NW] ni yín, bí ẹ̀yin bá ń ṣe wọ́n.”—Johannu 13:17.
Láti ṣàkàwé: Ìyá kan tí ó padà wọnú iṣẹ́-òjíṣẹ́ aṣáájù-ọ̀nà ní àìpẹ́ yìí sọ pé: “Láti rí bí ojú akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan tí ń tàn yòò bí oríṣiríṣi àwọn òtítọ́ Bibeli tí ń wọ̀ ọ́ lọ́kàn ń rùmọ̀lárasókè gan-an ni! Irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀ ni mo ní láti rí akẹ́kọ̀ọ́ kan ní pàtó tí ó fi ọwọ́ kọ gbogbo ẹsẹ ìwé mímọ́ ṣáájú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tí ó sì ń ṣàkọsílẹ̀ nígbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ ń lọ lọ́wọ́ kí ó baà lè dáhùn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò èyíkéyìí lẹ́yìn náà.” Òmíràn lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀ ti bá òtítọ́ pàdé nígbà tí ó wà ní ọ̀dọ́langba. Nísinsìnyí tí ó ti lọ́kọ tí ó sì ń dàníyàn nípa àwọn ìṣòro ara-ẹni kan, ó ń yáhànhàn láti wá àwọn Ẹlẹ́rìí rí. Ẹ wo bí ayọ̀ rẹ̀ ti pọ̀ tó, nígbà tí arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà náà rí i! A ru adélébọ̀ náà sókè láti tún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀ bẹ̀rẹ̀.
Pípa Ayọ̀ Ṣíṣe Ìfẹ́-Inú Ọlọrun Mọ́
Ọba Dafidi ti Israeli ìgbàanì jẹ́ ẹnìkan tí ó wá ọ̀nà láti ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun ní gbogbo ìgbésí-ayé rẹ̀. Láìka gbogbo ìnira ati ìkìmọ́lẹ̀ ti a mú wa sórí rẹ̀ sí, a mísí i láti sọ pé: “Inú mi dùn láti ṣe [“ìfẹ́-inú,” NW] rẹ, Ọlọrun mi, nítòótọ́, òfin rẹ ń bẹ ni àyà mi.” (Orin Dafidi 40:8) Ṣíṣe ìfẹ́-inú Jehofa wà lọ́kàn Dafidi gan-an, nínú òun fúnraarẹ̀. Ìyẹn ni àṣírí ayọ̀ rẹ̀ ti kìí ṣá nínú ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa. Ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun kìí ṣe ìnira fún Dafidi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ inúdídùn, ohun kan tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ̀ wá. Jálẹ̀ gbogbo ìgbésí-ayé rẹ̀, o jìjàkadì láti ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe láti ṣiṣẹ́sin Ọlọrun rẹ̀, Jehofa, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì kùnà ní àwọn ìgbà mìíràn.
Lẹ́kọ̀ọ̀kan, ayọ̀ wa lè jórẹ̀yìn. Ó lè rẹ̀ wá tàbí kí a rẹ̀wẹ̀sì. Bóyá àwọn ìrírí tí a ti ní nígbà tí ó ti kọjá, ẹ̀rí-ọkàn wa lè máa dààmú wa lórí àwọn ìwà àìtọ́ tí a ti hù tipẹ́tipẹ́. Ó sábà máa ń ṣeéṣe láti ṣẹ́gun ìmọ̀lára wọ̀nyí nípa títúbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun jinlẹ̀jinlẹ̀. A lè fi ṣe góńgó wa láti tẹ òfin Ọlọrun mọ́ “àyà” wa gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti ṣe. Bí a bá gbìyànjú láti ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun tọkàntọkàn, ìyẹn ni pé, dé ibi tí agbára wa lè gbe dé, òun yóò san èrè fún wa lọ́nà kan náà nítorí pé òun jẹ́ olùṣòtítọ́.—Efesu 6:6; Heberu 6:10-12; 1 Peteru 4:19.
Ó dùnmọ́ni pé ní Heberu 10:5-7, aposteli Paulu fa ọ̀rọ̀ Dafidi yọ ní Orin Dafidi 40:6-8 ó sì fi wọ́n sọ̀rọ̀ nípa Jesu Kristi. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ Paulu ṣàlàyé bí Jesu ti súnmọ́ Baba rẹ̀ tímọ́tímọ́ tó. Ọ̀rọ̀ Heberu náà fún “ìfẹ́-inú” ní èrò ‘inúdídùn, ìfẹ́-ọkàn, ojúrere, tàbí ìdùnnú.’ Nítorí náà, Orin Dafidi 40:8 lè kà nípa Kristi pé: “Láti ṣe ìdùnnú rẹ̀, óò Ọlọrun mi, ni mo ní inúdídùn sí.”a Jesu fẹ́ láti ṣe ohun tí ó dùn mọ́ Baba rẹ̀ nínú. Jesu ṣe ju ohun ti a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ láti ṣe. Ó ṣe ohun tí ó wà ní ọkàn-àyà Baba rẹ̀, ó sì gbádùn ṣíṣe e.
Gbogbo ìgbésí-ayé Jesu rọ̀gbà yíká kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn ní ohun tí ìfẹ́-inú Ọlọrun jẹ́ àti ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe láti jèrè ìbùkún Ọlọrun. Òun jẹ́ oníwàásù àti olùkọ́ni alákòókò kíkún ó sì rí ayọ̀ títóbi nínú ṣíṣe iṣẹ́ yẹn. Ohun tí ó ń yọrísí nígbà náà ni pé bí a bá ti ṣe iṣẹ́ Jehofa tó, bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ tí a óò rígbà yóò ti pọ̀ tó. Ìwọ pẹ̀lú ha lè sìn fún àkókò kíkún nínú iṣẹ́ ìwàásù náà kí ayọ̀ rẹ baà lè kúnrẹ́rẹ́ bí?
Ìrànwọ́ síwájú síi fún pípa ayọ̀ mọ́ nínú ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun ni láti fi ọjọ́-ọ̀la sí ọ̀kánkán iwájú. Ìyẹn ni ohun tí Jesu ṣe. “Nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ̀, tí ó farada [“igi oro,” NW] láìka ìtìjú sí.” Fún un, ayọ̀ náà jẹ́ jíjásí olùṣòtítọ́ sí Ọlọrun títí dé òpin àti lẹ́yìn náà gbígba èrè ipò ọba ní ọwọ́ ọ̀tún Baba rẹ̀.—Heberu 12:2.
Ronú ayọ̀ ọjọ́-ọ̀la tí àwọn wọnnì tí wọ́n ń ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun nìṣó yóò ní. Wọn yóò rí ìparun àwọn wọnnì tí wọn tẹramọ́ ṣíṣe ìfẹ́-inú onímọtara-ẹni-nìkan wọn àní bí èyí bá tilẹ̀ mu ìjìyà wá fún àwọn wọnnì tí wọ́n ń sapá láti ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun. (2 Tessalonika 1:7, 8) Ronú nípa ayọ̀ àwọn olólùfẹ́ tí a jí dìde ní jíjèrè àǹfààní náà láti kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun. Tàbí kí o ṣàgbéyẹ̀wò ìfẹ́-inú Ọlọrun láti sọ ilẹ̀-ayé di Paradise. Àti ní paríparì rẹ̀, ronú nípa òmìnira tí yóò wá láti inú pípa Satani, alátakò ìfẹ́-inú Jehofa rẹ́ ráúráú.
Bẹ́ẹ̀ni, ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun lónìí lè mú ayọ̀ púpọ̀ wá nísinsìnyí àti ìdùnnú tí kò lópin ní ọjọ́-ọ̀la. Láìka ìdáhùnpadà tí a ń rí gbà nínú iṣẹ́ ìwàásù náà sí, ẹ jẹ́ kí a ṣàfarawé àpẹẹrẹ Jesu níti rírí ìdùnnú nínú ṣíṣe ìfẹ́-inú Baba rẹ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àlàyé etí ìwé lórí Orin Dafidi 40:8, (NW).