Ìwé Kìíní Pétérù
4 Níwọ̀n bí Kristi ti jìyà nínú ẹran ara,+ kí ẹ̀yin náà fi irú èrò kan náà gbára dì;* torí ẹni tó ti jìyà nínú ẹran ara ti jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀,+ 2 kó lè fi àkókò tó ṣẹ́ kù fún un láti gbé nínú ẹran ara ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run,+ kó má fi ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ èèyàn mọ́.+ 3 Torí àkókò tó ti kọjá tí ẹ fi ṣe ìfẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè ti tó yín,+ nígbà tí ẹ̀ ń hu ìwà àìnítìjú,* tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, tí ẹ̀ ń mu ọtí àmujù, ṣe àríyá aláriwo, ṣe ìdíje ọtí mímu àti àwọn ìbọ̀rìṣà tó jẹ́ ohun ìríra.+ 4 Ó ń yà wọ́n lẹ́nu pé ẹ ò tún bá wọn lọ́wọ́ sí irú ìwà pálapàla tó ń buni kù bẹ́ẹ̀ mọ́, torí náà, wọ́n ń sọ̀rọ̀ yín láìdáa.+ 5 Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn yìí máa jíhìn fún ẹni tó ti ṣe tán láti ṣèdájọ́ àwọn tó wà láàyè àtàwọn tó ti kú.+ 6 Kódà, ìdí nìyẹn tí a fi kéde ìhìn rere fún àwọn òkú pẹ̀lú,+ kó lè jẹ́ pé bí a tiẹ̀ ṣèdájọ́ wọn nínú ẹran ara lójú àwọn èèyàn, wọ́n á lè wà láàyè nípa tẹ̀mí lójú Ọlọ́run.
7 Àmọ́ òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé. Torí náà, kí ẹ máa ronú jinlẹ̀,+ kí ẹ sì wà lójúfò,* kí ẹ lè máa gbàdúrà.+ 8 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ara yín,+ torí ìfẹ́ máa ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.+ 9 Ẹ máa ṣe ara yín lálejò láìráhùn.+ 10 Bí kálukú bá ṣe ń rí ẹ̀bùn gbà, ẹ máa fi ṣe ìránṣẹ́ fún ara yín bí ìríjú àtàtà tó ń rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run gbà lóríṣiríṣi ọ̀nà.+ 11 Tí ẹnikẹ́ni bá ń sọ̀rọ̀, kó sọ ọ́ bíi pé ó ń kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; tí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe ìránṣẹ́, kó ṣe é bí ẹni tó gbára lé okun tí Ọlọ́run ń fúnni;+ ká lè yin Ọlọ́run lógo nínú ohun gbogbo+ nípasẹ̀ Jésù Kristi. Ògo àti agbára jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín.
12 Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn àdánwò gbígbóná tó ń bá yín yà yín lẹ́nu,+ bíi pé nǹkan àjèjì ló ń ṣẹlẹ̀ sí yín. 13 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa yọ̀+ torí ibi tí ẹ lè bá Kristi jìyà dé,+ kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè yọ̀, kí ayọ̀ yín sì kún nígbà ìfihàn ògo rẹ̀.+ 14 Inú yín máa dùn tí wọ́n bá ń gàn yín* nítorí orúkọ Kristi,+ torí pé ẹ̀mí ògo, àní ẹ̀mí Ọlọ́run, ti bà lé yín.
15 Àmọ́ ká má ṣe rí ẹnikẹ́ni nínú yín tó ń jìyà torí pé ó jẹ́ apààyàn tàbí olè tàbí aṣebi tàbí torí ó ń tojú bọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀.+ 16 Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá jìyà torí pé ó jẹ́ Kristẹni, kó má ṣe tijú,+ àmọ́ kó túbọ̀ máa yin Ọlọ́run lógo bó ṣe ń jẹ́ orúkọ yìí. 17 Torí àkókò tí ìdájọ́ máa bẹ̀rẹ̀ ní ilé Ọlọ́run ti tó.+ Tó bá wá bẹ̀rẹ̀ lọ́dọ̀ wa,+ kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere Ọlọ́run?+ 18 “Tí kò bá ní rọrùn láti gba olódodo là, kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti ẹlẹ́ṣẹ̀?”+ 19 Nítorí náà, kí àwọn tó ń jìyà lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu máa fi ara* wọn lé Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ olóòótọ́ lọ́wọ́,* kí wọ́n sì máa ṣe rere.+