Ẹ Máa Ru Ara Yín Lọ́kàn Sókè Sí Ìfẹ́ àti Sí Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà—Báwo?
“Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nìkínní kejì lati ru ara wa lọ́kàn sókè sí ìfẹ́ ati sí awọn iṣẹ́ àtàtà, . . . kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nìkínní kejì, pàápàá jùlọ bí ẹ̀yin ti rí ọjọ́ naa tí ń súnmọ́lé.”—HEBERU 10:24, 25.
1, 2. (a) Èéṣe tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn Kristian ìjímìjí rí ìtùnú àti ìṣírí nínú pípàdé pọ̀ wọn? (b) Ìmọ̀ràn Paulu wo ni ó sọ̀rọ̀ lórí àìní náà láti máa pàdé pọ̀?
WỌ́N pàdé níkọ̀kọ̀, wọ́n fara pamọ́ sẹ́yìn ilẹ̀kùn tí a tìpa. Ewu wà níbi gbogbo, lẹ́yìn òde. A ṣẹ̀ṣẹ̀ pa Aṣáájú wọn, Jesu, ní gbangba ni, ó sì ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé a kì yóò bá wọn lò lọ́nà tí ó sàn ju tòun lọ. (Johannu 15:20; 20:19) Ṣùgbọ́n bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nípa Jesu olùfẹ́ wọn ọ̀wọ́n, ó kéré tán wíwà papọ̀ wọn yóò ti mú kí wọ́n nímọ̀lára ààbò.
2 Bí ọdún ti ń rékọjá lọ, àwọn Kristian dojúkọ oríṣiríṣi àdánwò àti inúnibíni. Gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àkọ́kọ́ wọ̀nyẹn, wọ́n rí ìtùnú àti ìṣírí gbà nínú pípàdé papọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, aposteli Paulu kọ̀wé nínú Heberu 10:24, 25 pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nìkínní kejì lati ru ara wa lọ́kàn sókè sí ìfẹ́ ati sí awọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa ṣá ìpéjọpọ̀ ara wa tì, bí awọn kan ti ní àṣà naa, ṣugbọn kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nìkínní kejì, pàápàá jùlọ bí ẹ̀yin ti rí ọjọ́ naa tí ń súnmọ́lé.”
3. Èéṣe tí o fi lè sọ pé Heberu 10:24, 25 kì í wulẹ̀ ṣe àṣẹ lásán pé kí àwọn Kristian máa pàdé pọ̀?
3 Àwọn ọ̀rọ̀ náà láti máa bá a nìṣó ní pípàdé papọ̀ ní nínú ju àṣẹ lọ fíìfíì. Wọ́n fún gbogbo ìpàdé Kristian ní ọ̀pá-ìdiwọ̀n tí ó ní ìmísí àtọ̀runwá—níti tòótọ́, àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ èyíkéyìí nígbà tí àwọn Kristian bá ń jùmọ̀ kẹ́gbẹ́pọ̀. Lónìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ, nígbà tí a ń rí ọjọ́ Jehofa tí ń rọ̀dẹ̀dẹ̀ ní kedere, àwọn ìkìmọ́lẹ̀ àti ewu ètò-ìgbékalẹ̀ búburú yìí ń mú kí ó di ọ̀ràn kánjúkánjú pé kí àwọn ìpàdé wa dàbí ibi ààbò, orísun okun àti ìṣírí fún gbogbogbòò. Kí ni a lè ṣe láti mú èyí dájú? Ó dára, ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ Paulu dáradára, ní bíbéèrè ìbéèrè pàtàkì mẹ́ta: Kí ni ó túmọ̀ sí láti ‘máa gba ti ara wa rò lẹ́nìkínní kejì’? Kí ni ó túmọ̀ sí láti ‘máa ru ara wa lọ́kàn sókè sí ìfẹ́ ati sí awọn iṣẹ́ àtàtà’? Lákòótán, báwo ni a ṣe lè ‘máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nìkínní kejì’ ní àwọn àkókò tí ó lekoko yìí?
‘Ẹ Máa Gba Ti Ara Yín Rò Lẹ́nìkínní Kejì’
4. Kí ni ó túmọ̀ sí láti máa “gba ti ara wa rò lẹ́nìkínní kejì”?
4 Nígbà tí Paulu rọ àwọn Kristian láti ‘máa gba ti ara wọn rò lẹ́nìkínní kejì,’ ó lo ọ̀rọ̀-ìṣe Griki náà ka·ta·no·eʹo, ọ̀rọ̀ amọ́rọ̀jinlẹ̀ ti èdè ìsọ̀rọ̀ tí a sábà máa ń lò náà “láti róye.” Ìwé Theological Dictionary of the New Testament sọ pé ó túmọ̀ sí “láti darí gbogbo ìrònú sí ohun kan.” Gẹ́gẹ́ bí W. E. Vine ṣe sọ ọ́, ó tún lè túmọ̀ sí “láti lóye lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, láti gbé yẹ̀wò fínnífínní.” Nítorí náà nígbà tí àwọn Kristian bá ń ‘gba ti ara wọn rò lẹ́nìkínní kejì,’ kì í ṣe kìkì pé wọ́n ń rí oréfèé lásán bíkòṣe pé wọ́n ń lo gbogbo agbára ọgbọ́n èrò-orí wọn tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti rí nǹkan délẹ̀délẹ̀.—Fiwé Heberu 3:1.
5. Àwọn nǹkan wo nípa ẹnì kan ni ó lè farasin, èésìtiṣe tí a fi níláti gba àwọn wọ̀nyí yẹ̀wò?
5 Ó pọndandan fún wa láti rántí pé ohun tí ẹnì kan jẹ́ níti gidi ju wíwo ìrísí rẹ̀, iṣẹ́ rẹ̀ lóréfèé lásán lọ, tàbí ohun tí àwọn àkópọ̀ ìwà rẹ̀ lè ṣípayá. (1 Samueli 16:7) Lọ́pọ̀ ìgbà dídákẹ́ rọ́rọ́ máa ń bo ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ tàbí ànímọ́ fífanimọ́ra ti ìdẹ́rìn-ínpani tí ẹnì kan ní mọ́lẹ̀. Bákan náà, pẹ̀lú, ipò-àtilẹ̀wá yàtọ̀ síra gidigidi. Àwọn kan ti la ìdánwò lílekoko já nínú ìgbésí-ayé wọn; nísinsìnyí àwọn mìíràn ń farada àwọn ipò kan tí yóò ṣòro fún wa láti finúrò. Ẹ wo bí ó ti sábà máa ń ṣẹlẹ̀ tó pé àwọn àlèébù kan tí ń rí wa lára nínú arákùnrin tàbí arábìnrin kan ń yọ́ dànù nígbà tí a bá túbọ̀ kọ́ ohun púpọ̀ síi nípa ipò-àtilẹ̀wá tàbí àyíká ipò ẹni náà.—Owe 19:11.
6. Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo ni a fi lè túbọ̀ mọ ara wa síi lẹ́nìkínní kejì, rere wo ni ó sì lè yọrí sí?
6 Àmọ́ ṣáá o, èyí kò túmọ̀ sí pé a níláti máa tọpinpin ọ̀ràn ẹlòmíràn bí a kò bá pè wá sí i. (1 Tessalonika 4:11) Síbẹ̀, ó dájú pé a lè fi ọkàn-ìfẹ́ ara-ẹni hàn sí ẹnìkínní kejì. Èyí ní nínú ju ìkíni lásán nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ. Èéṣe tí o kò fi yan ẹnì kan tí ìwọ yóò fẹ́ láti túbọ̀ mọ̀ síi kí o sì ní in gẹ́gẹ́ bí góńgó láti jíròrò fún ìṣẹ́jú díẹ̀ ṣáájú tàbí lẹ́yìn ìpàdé? Ó tún sàn jù, láti “tẹ̀lé ìlà ipa-ọ̀nà aájò àlejò” nípa kíkésí ọ̀rẹ́ kan tàbí méjì wá sí ilé rẹ fún ìpápánu díẹ̀. (Romu 12:13) Fi ọkàn-ìfẹ́ hàn. Tẹ́tísílẹ̀. Wíwulẹ̀ béèrè bí ẹnì kan ṣe mọ Jehofa tí ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lè ṣí ohun púpọ̀ payá. Àmọ́ ṣáá o, o ṣì lè kọ́ ohun púpọ̀ síi, nípa ṣíṣiṣẹ́ papọ̀ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé. Gbígba ti ara wa rò lẹ́nìkínní kejì ní irú àwọn ọ̀nà yẹn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú ojúlówó ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì, tàbí ẹ̀mí ìfọ̀rànrora-ẹni dàgbà.—Filippi 2:4; 1 Peteru 3:8.
‘Ẹ Máa Ru Ara Yín Lọ́kàn Sókè Lẹ́nìkínní Kejì’
7. (a) Báwo ni ẹ̀kọ́ Jesu ṣe ní ipa lórí àwọn ènìyàn? (b) Kí ni ó mú kí ẹ̀kọ́ rẹ̀ jẹ́ alágbára tí ń súnni ṣiṣẹ́ tóbẹ́ẹ̀?
7 Nígbà tí a bá ń gba ti ara wa rò lẹ́nìkínní kejì, a túbọ̀ ń múra wa sílẹ̀ láti ru ara wa lọ́kàn sókè, láti sún ara wa lẹ́nìkínní kejì ṣiṣẹ́. Àwọn Kristian alàgbà ní pàtàkì ń kó ipa ṣíṣekókó nínú èyí. Ní àkókò kan nígbà tí Jesu ti sọ̀rọ̀ ní gbangba, a kà pé: “Ipa ìyọrísí rẹ̀ ni pé háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” (Matteu 7:28) Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn àwọn ọmọ ogun tí a tilẹ̀ rán láti lọ mú un wá fi í sílẹ̀ ní sísọ pé: “Ènìyàn mìíràn kan kò tí ì sọ̀rọ̀ bayii rí.” (Johannu 7:46) Kí ni ó mú kí ẹ̀kọ́ Jesu jẹ́ èyí tí ń súnni ṣiṣẹ́ tóbẹ́ẹ̀? Fífi èrò-ìmọ̀lára àṣerégèé hàn ha ni bí? Rárá o; Jesu sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ń buyì kúnni. Síbẹ̀, ó máa ń fìgbà gbogbo fẹ́ láti dé inú ọkàn-àyà àwọn olùgbọ́ rẹ̀. Nítorí pé ó gba ti àwọn ènìyàn rò, ó mọ bí òun ṣe lè sún wọn ṣiṣẹ́ gan-an. Ó lo àwọn àkàwé rírọrùn, tí kò lọ́júpọ̀, tí ó ń fi àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí-ayé ojoojúmọ́ hàn. (Matteu 13:34) Bákan náà, àwọn wọnnì tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́-àyànfúnni wọn ní àwọn ìpàdé wa níláti ṣàfarawé Jesu nípa fífúnni ní àwọn ìgbékalẹ̀-ọ̀rọ̀ ọlọ́yàyà, tí ó kún fún ìtara èyí tí ń súnni ṣiṣẹ́. Bíi ti Jesu, a lè pa ìrònú pọ̀ sórí wíwá àwọn àkàwé tí ó bá àwọn àwùjọ wa mu tí ó sì ń dé inú ọkàn-àyà wọn.
8. Báwo ni àpẹẹrẹ Jesu ṣe runi lọ́kàn sókè, báwo sì ni a ṣe lè ṣàfarawé rẹ̀ nínú èyí?
8 Ní ṣíṣiṣẹ́sin Ọlọrun wa, gbogbo wa lè ru ara wa lọ́kàn sókè lẹ́nìkínní kejì nípa fífi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Dájúdájú Jesu ru àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lọ́kàn sókè. Ó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian ó sì gbé iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà ga. Ó sọ pé ó dàbí oúnjẹ fún òun. (Johannu 4:34; Romu 11:13) Irú ìtara ọkàn bẹ́ẹ̀ máa ń ranni. Ìwọ bákan náà ha lè jẹ́ kí ìdùnnú-ayọ̀ rẹ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ di mímọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn bí? Bí o ti ń fi tìṣọ́ratìṣọ́ra yẹra fún ọ̀rọ̀ ìṣògo, ṣàjọpín àwọn ìrírí dáradára tí o ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ. Nígbà tí o bá késí àwọn ẹlòmíràn láti bá ọ ṣiṣẹ́, ṣàkíyèsí bí o bá lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ojúlówó ìgbádùn nínú bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa, Jehofa.—Owe 25:25.
9. (a) Kí ni àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí a lè fi ru àwọn ẹlòmíràn lọ́kàn sókè tí a níláti yẹra fún, èésìtiṣe? (b) Kí ni ó gbọ́dọ̀ sún wa láti fi ara wa fún iṣẹ́-ìsìn Jehofa?
9 Ṣùgbọ́n, ṣọ́ra rẹ kí o máṣe ru àwọn ẹlòmíràn lọ́kàn sókè lọ́nà òdì. Fún àpẹẹrẹ, láì mọ̀ rárá a lè mú kí wọn nímọ̀lára ẹ̀bi fún ṣíṣàì ṣe púpọ̀ síi. Láì mọ̀ọ́mọ̀ a lè dójú tì wọ́n nípa fífi wọ́n wéra lọ́nà tí kò tọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ń nípìn-ín títayọ nínú ìgbòkègbodò Kristian, tàbí kí a tilẹ̀ gbé ọ̀pá-ìdiwọ̀n tí kò ṣeé yípadà kalẹ̀ kí a sì bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn wọnnì tí kò lè kúnjú ìwọ̀n rẹ̀. Èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà wọ̀nyí lè sún àwọn kan ṣiṣẹ́ fún àkókò kan, ṣùgbọ́n Paulu kò kọ̀wé pé, ‘Ẹ ru ara yín lọ́kàn sókè sí ẹ̀bi àti àwọn iṣẹ́ àtàtà.’ Rárá, a gbọ́dọ̀ ru ara wa lọ́kàn sókè sí ìfẹ́, nígbà náà iṣẹ́ náà yóò tẹ̀lé e láti inú ète ìsúnniṣe tí ó dára. A kò níláti sún ẹnì kan ṣiṣẹ́ kìkì nítorí èrò tí àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ yóò ní nípa rẹ̀ bí kò bá ṣe tó bí a ṣe ń retí.—Fiwé 2 Korinti 9:6, 7.
10. Èéṣe tí a fi níláti rántí pé a kì í ṣe ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn?
10 Láti ru ara wa lọ́kàn sókè lẹ́nìkínní kejì kò túmọ̀ sí pé kí a máa darí ara wa lẹ́nìkínní kejì. Bí ó tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọlá-àṣẹ tí Ọlọrun fún un, aposteli Paulu fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ rán ìjọ Korinti létí pé: ‘Àwa kì í ṣe ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ yín.’ (2 Korinti 1:24) Bí a bá fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ gbà pé kì í ṣe iṣẹ́ wa láti pinnu bí àwọn ẹlòmíràn ṣe níláti ṣe tó nínú iṣẹ́-ìsìn sí Jehofa, tàbí kí a máa darí ẹ̀rí-ọkàn wọn fún wọn nínú àwọn ìpinnu ti ara-ẹni mìíràn, a óò yẹra fún dídi ‘olódodo àṣelékè,’ aláìní ìdùnnú-ayọ̀, aláìṣeéyípadà, elérò-òdì, tàbí agbélànàrù. (Oniwasu 7:16) Irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ kì í runi lọ́kàn sókè; wọ́n máa ń ninilára ni.
11. Kí ni ó fa ìsúnniṣe náà láti ṣe ìtọrẹ nígbà tí àwọn ọmọ Israeli ń kọ́ àgọ́ àjọ, báwo sì ni ìyẹn ṣe lè jẹ́ òtítọ́ ní ọjọ́ tiwa?
11 A fẹ́ kí gbogbo ìsapá nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa jẹ́ èyí tí a ń ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí kan náà gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe ní Israeli ìgbàanì nígbà tí a nílò ọrẹ fún kíkọ́ àgọ́ àjọ. Eksodu 35:21 kà pé: “Wọ́n sì wá, olúkúlùkù ẹni tí ọkàn rẹ̀ ru nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù ẹni tí ọkàn rẹ̀ mú un fẹ́, wọ́n sì mú ọrẹ OLUWA wá fún iṣẹ́ àgọ́ àjọ náà.” Kì í ṣe ipá láti ẹ̀yìn òde ni ó mú wọn lápàpàǹdodo bíkòṣe ipá láti inú lọ́hùn-ún, láti inú ọkàn-àyà. Ní tòótọ́, èdè Heberu náà kà ní olówuuru níhìn-ín pé “gbogbo ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ gbé sókè” fúnni ní irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀. (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Síwájú síi, ẹ jẹ́ kí a máa sakun láti gbé ọkàn-àyà wa lẹ́nìkínní kejì sókè nígbàkígbà tí a bá wà papọ̀. Ẹ̀mí Jehofa lè ṣe ìyókù.
‘Ẹ Máa Fún Ara Yín Ní Ìṣírí Lẹ́nìkínní Kejì’
12. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìtumọ̀ tí ọ̀rọ̀ Griki náà tí a túmọ̀ sí “ìṣírí” ní? (b) Báwo ni àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ Jobu ṣe kùnà láti fún un ní ìṣírí? (d) Èéṣe tí a fi níláti fàsẹ́yìn fún dídá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́?
12 Nígbà tí Paulu kọ̀wé pé a níláti ‘máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nìkínní kejì,’ ó lo irú ọ̀rọ̀ Griki náà pa·ra·ka·leʹo, tí ó tún lè túmọ̀ sí ‘láti fúnni lókun, láti tuninínú.’ Nínú ìtumọ̀ Septuagint ti Griki, a lo ọ̀rọ̀ kan náà yìí ní Jobu 29:25, níbi tí a ti ṣàpèjúwe Jobu gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń tu àwọn aṣọ̀fọ̀ nínú. Lọ́nà tí kò bára dọ́gba, nígbà tí Jobu fúnra rẹ̀ wà lábẹ́ àdánwò lílekoko, kò rí irú ìṣírí bẹ́ẹ̀ gbà. Ọwọ́ àwọn ‘olùtùnú’ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dí jọjọ fún dídá a lẹ́jọ́ àti nínà án lọ́rẹ́ ọ̀rọ̀ débi pé wọ́n kùnà láti lóye rẹ̀ tàbí kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ro ara wọn wò. Ní tòótọ́, nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ, kò sí ìgbà kan tí wọ́n tilẹ̀ dárúkọ Jobu. (Fiwéra pẹ̀lú Jobu 33:1, 31.) Ó hàn gbangba pé wọ́n wò ó gẹ́gẹ́ bí ìṣòro dípò kí wọ́n wò ó gẹ́gẹ́ bí ènìyàn kan. Abájọ tí Jobu fi bá wọn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìyanu nínú ìjákulẹ̀ rẹ̀ pé: “Bí ọkàn yín bá wà ní ipò ọkàn mi”! (Jobu 16:4) Bákan náà lónìí, bí o bá fẹ́ fún ẹnì kan ní ìṣírí, fi ọ̀ràn náà ro ara rẹ wò! Máṣe dáni lẹ́jọ́. Gẹ́gẹ́ bí Romu 14:4 ṣe sọ, “ta ni iwọ lati ṣèdájọ́ ìránṣẹ́ ilé ẹlòmíràn? Lọ́dọ̀ ọ̀gá oun fúnra rẹ̀ ni ó dúró tabi ṣubú. Nítòótọ́, a óò mú un dúró, nitori Jehofa lè mú un dúró.”
13, 14. (a) Òtítọ́ ìpìlẹ̀ wo ni a níláti mú dá àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa lójú láti lè tù wọ́n nínú? (b) Báwo ni áńgẹ́lì kan ṣe fún Danieli lókun?
13 A tún túmọ̀ irú pa·ra·ka·leʹo kan àti ọ̀rọ̀-orúkọ tí ó tan mọ́ ọn sí “ìtùnú” ní 2 Tessalonika 2:16, 17 pé: “Jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí Oluwa wa Jesu Kristi fúnra rẹ̀ ati Baba wa Ọlọrun, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa tí ó sì fúnni ní ìtùnú àìnípẹ̀kun ati ìrètí rere nípasẹ̀ inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, tu ọkàn-àyà yín nínú kí ó sì fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in ninu gbogbo iṣẹ́ rere ati ọ̀rọ̀.” Ṣàkíyèsí pé Paulu so èrò títu ọkàn-àyà wa nínú pọ̀ mọ́ òtítọ́ ìpìlẹ̀ náà pé Jehofa nífẹ̀ẹ́ wa. Nítorí náà a lè fún ara wa ní ìṣírí kí a sì tu ara wa nínú lẹ́nìkínní kejì nípa mímú kí ẹ̀rí òtítọ́ ṣíṣepàtàkì yẹn dánilójú.
14 Nígbà kan ìdààmú bá wòlíì Danieli lẹ́yìn tí ó rí ìran akópayàbáni kan tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi sọ pé: “Kò sì ku agbára nínú mi: ẹwà mi sì yípadà lára mi di ìbàjẹ́, èmi kò sì lágbára mọ́.” Jehofa ran áńgẹ́lì kan tí ń rán Danieli létí lọ́pọ̀ ìgbà pé ó jẹ́ “olùfẹ́ gidigidi” lójú Ọlọrun. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Danieli sọ fún áńgẹ́lì náà pé: “Ìwọ ti mú mi lára le.”—Danieli 10:8, 11, 19.
15. Báwo ni àwọn alàgbà àti alábòójútó arìnrìn-àjò ṣe níláti mú kí ìgbóríyìn wà déédéé pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà?
15 Nítorí náà, a tún rí ọ̀nà mìíràn níhìn-ín láti fún àwọn ẹlòmíràn ní ìṣírí. Gbóríyìn fún wọn! Ó rọrùn púpọ̀ láti kó sínú ẹ̀mí ìṣelámèyítọ́, tí ó lekoko. Òtítọ́ ni pé, àwọn ìgbà mìíràn ń bẹ nígbà tí àtúnṣe lè pọndandan, ní pàtàkì nípasẹ̀ àwọn alàgbà àti alábòójútó arìnrìn-àjò. Ṣùgbọ́n yóò ṣe wọ́n láǹfààní bí a bá lè máa rántí wọn fún ìṣírí amọ́kànyọ̀ tí wọ́n ń fúnni dípò rírántí wọn fún níní ìwà awẹ́sùn-síni-lẹ́sẹ̀.
16. (a) Nígbà tí a bá ń fún àwọn tí ó soríkọ́ ní ìṣírí, èéṣe tí kò fi tó nígbà gbogbo láti wulẹ̀ rọ̀ wọ́n láti túbọ̀ ṣe púpọ̀ síi nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa? (b) Báwo ni Jehofa ṣe ran Elijah lọ́wọ́ nígbà tí ó soríkọ́?
16 Ní pàtàkì àwọn tí wọ́n soríkọ́ nílò ìṣírí, Jehofa sì ń retí pé kí àwa gẹ́gẹ́ bí Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn jẹ́ orísun ìrànlọ́wọ́—ní pàtàkì bí a bá jẹ́ alàgbà. (Owe 21:13) Kí ni a lè ṣe? Ìdáhùn náà lè má jẹ́ èyí tí ó rọrùn bíi sísọ fún wọn pé kí wọn túbọ̀ ṣe púpọ̀ síi nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa. Èéṣe? Nítorí pé ìyẹn lè túmọ̀ sí pé ìsoríkọ́ wọn jẹ́ nítorí pé ohun tí wọ́n ń ṣe kò tó. Ọ̀ràn kì í máa fìgbà gbogbo rí bẹ́ẹ̀. Wòlíì Elijah soríkọ́ gidigidi nígbà kan tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi fẹ́ láti kú; síbẹ̀ èyí wáyé nígbà kan tí ọwọ́ rẹ̀ dí jọjọ nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa. Báwo ni Jehofa ṣe bá a lò? Ó rán áńgẹ́lì kan sí i láti pèsè ìrànlọ́wọ́ tí ó gbéṣẹ́. Elijah tú ọkàn-àyà rẹ̀ jáde sí Jehofa, ó ṣípayá pé òun nímọ̀lára pé òun kò jámọ́ nǹkankan bí àwọn babańlá òun tí ó ti kú, pé iṣẹ́ òun ti jẹ́ lórí asán, àti pé òun dá wà gírogíro. Jehofa tẹ́tísílẹ̀ ó sì tù ú nínú pẹ̀lú fífi agbára Rẹ̀ amúniní-ìbẹ̀rù-ọlọ́wọ̀ hàn ó sì mú un dá a lójú pé kò dá wà rárá àti pé yóò parí iṣẹ́ tí ó ti bẹ̀rẹ̀. Jehofa tún ṣèlérí láti fún Elijah ní alábàkẹ́ẹ́gbẹ́pọ̀ kan tí òun yóò dálẹ́kọ̀ọ́ ẹni tí yóò rọ́pò rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.—1 Ọba 19:1-21.
17. Báwo ni alàgbà kan ṣe lè fún ẹnì kan tí ń ṣe lámèyítọ́ ara rẹ̀ láṣerégèé ní ìṣírí?
17 Ìyẹn mà fúnni ní ìṣírí o! Ǹjẹ́ kí àwa bákan náà fún àwọn wọnnì tí ń bẹ láàárín wa tí wàhálà débá níti èrò-ìmọ̀lára ní ìṣírí. Gbìyànjú kárakára láti lóye wọn nípa títẹ́tísílẹ̀! (Jakọbu 1:19) Pèsè ìtùnú tí ó bá àìní ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mu láti inú Ìwé Mímọ́. (Owe 25:11; 1 Tessalonika 5:14) Láti lè fún àwọn wọnnì tí ń ṣe lámèyítọ́ ara wọn ní àṣerégèé ní ìṣírí, àwọn alàgbà lè fi pẹ̀lú inúrere fún wọn ní ẹ̀rí inú Ìwé Mímọ́ pé Jehofa nífẹ̀ẹ́ wọn ó sì kà wọ́n sí.a Jíjíròrò ìràpadà lè jẹ́ ọ̀nà kan tí ó lágbára láti fún àwọn wọnnì tí wọ́n nímọ̀lára pé àwọn kò jámọ́ nǹkankan ní ìṣírí. Ẹnì kan tí ó ní ẹ̀dùn-ọkàn nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan tí ó ti dá sẹ́yìn ni ó lè pọndandan kí a ṣàlàyé fún pé ìràpadà ti wẹ̀ ẹ́ mọ́ tónítóní bí ó bá jẹ́ pé ó ti ronúpìwàdà nítòótọ́ tí ó sì ti yípadà kúrò nínú irú àṣà bẹ́ẹ̀.—Isaiah 1:18.
18. Báwo ni a ṣe níláti lo ẹ̀kọ́ ìràpadà láti fún ẹnì kan ti ẹlòmíràn ti fìyà jẹ, bíi nípasẹ̀ ìfipábánilòpọ̀ ní ìṣírí?
18 Àmọ́ ṣáá o, alàgbà kan yóò ronú lórí ọ̀ràn náà ní pàtó láti lè lo ẹ̀kọ́ náà lọ́nà tí ó yẹ. Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀wò: Ẹran tí a ń fi rúbọ nínú Òfin Mose jẹ́ òjìji ìṣáájú fún ẹbọ ìràpadà Kristi, èyí tí a béèrè fún ṣíṣètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀. (Lefitiku 4:27, 28) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò sí ipò àfilélẹ̀ kankan, pé ẹnì kan tí a fipá bálòpọ̀ níláti rú irú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀. Òfin wí pé kí wọn “máṣe ohun kan” láti fìyà jẹ ẹ́. (Deuteronomi 22:25-27) Bákan náà lónìí, bí a bá kọlu arábìnrin kan tí a sì fipá bá a lòpọ̀ tí èyí sì ti mú kí ó nímọ̀lára ẹ̀gbin àti àìníláárí, yóò ha yẹ láti tẹnumọ́ bí ó ṣe nílò ìràpadà tó láti wẹ̀ ẹ́ mọ́ tónítóní kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́. Kò dẹ́ṣẹ̀ níti pé a fipá kọlù ú. Ẹni tí ó fipá bá a lòpọ̀ ni ó dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì nílò ìwẹ̀mọ́ tónítóní. Bí ó ti wù kí ó rí, ìfẹ́ tí Jehofa àti Kristi fi hàn nípa pípèsè ìràpadà ni a lè lo gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé a kò tí ì sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin lójú Ọlọrun nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíràn ṣùgbọ́n pé ó ṣeyebíye fún Jehofa ó sì wà nínú ìfẹ́ rẹ̀.—Fiwé Marku 7:18-23; 1 Johannu 4:16.
19. Èéṣe tí a kò fi níláti retí pé gbogbo ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ wa pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa yóò jẹ́ èyí tí ń fúnni ní ìṣírí, ṣùgbọ́n kí ni ó níláti jẹ́ ìpinnu wa?
19 Bẹ́ẹ̀ni, ohun yòówù tí ipò ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú ìgbésí-ayé lè jẹ́, láìka àyíká ipò ríronilára tí ó ti lè mú kí ipò àtẹ̀yìnwá rẹ̀ jẹ́ oníbànújẹ́ sí, ó yẹ kí ó lè rí ìṣírí nínú ìjọ àwọn ènìyàn Jehofa. Òun yóò sì rí i bí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bá ń làkàkà láti gba ti ara wa rò lẹ́nìkínní kejì, tí a ń ru ara wa lọ́kàn sókè lẹ́nìkínní kejì, tí a sì ń fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nìkínní kejì nígbàkígbà tí a bá jùmọ̀ ń kẹ́gbẹ́ pọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, nítorí pé a jẹ́ aláìpé, gbogbo wa ń kùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà mìíràn. Láìṣeé yẹ̀ sílẹ̀, a máa ń já ẹnìkínní kejì wa kulẹ̀ tí a sì tilẹ̀ ń fa ìrora fún ẹnìkínní kejì nígbà mìíràn. Gbìyànjú láti máṣe kó àfiyèsí rẹ jọ sórí àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn nínú ọ̀ràn yìí. Bí o bá kó àfiyèsí rẹ jọ sórí àwọn àìdójú-ìwọ̀n, o ń fi dídi ẹni tí ń ṣe lámèyítọ́ ìjọ láṣejù ṣeré o sì lè ṣubú sínú páńpẹ́ náà gan-an tí Paulu ń háragàgà láti ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún, ìyẹn ni, ṣíṣá ìpéjọpọ̀ ara wa tì. Kí ìyẹn máṣe ṣẹlẹ̀ láé! Bí ètò-ìgbékalẹ̀ ògbólógbòó yìí ti túbọ̀ ń léwu tí ó sì ń ninilára síi, ẹ jẹ́ kí a pinnu láìyẹhùn láti ṣe ohun tí a bá lè ṣe láti mú kí ìkẹ́gbẹ́pọ̀ wa ní àwọn ìpàdé jẹ́ èyí tí ń gbéniró—àti pẹ̀lú bí a ti rí i pé ọjọ́ Jehofa ń súnmọ́lé!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Alàgbà kan lè yàn láti kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ń fúnni ní ìṣírí nínú Ilé-Ìsọ́nà àti Jí! pẹ̀lú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀—fún àpẹẹrẹ, “Iwọ Yoo Ha Jere-àǹfààní Lati Inú Inúrere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí?” àti “Jíja-àjàṣẹ́gun nínú Ìjà-ogun Lodisi Ìsoríkọ́.”—Ilé-Ìṣọ́nà, February 15 àti March 1, 1990.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Èéṣe tí ó fi ṣekókó pé kí àwọn ìpàdé àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ wa jẹ́ èyí tí ń fúnni ní ìṣírí ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí?
◻ Kí ni ó túmọ̀ sí láti máa gba ti ara wa rò lẹ́nìkínní kejì?
◻ Kí ni ó túmọ̀ sí láti máa ru ara wa lọ́kàn sókè lẹ́nìkínní kejì?
◻ Kí ni fífún ara wa lẹ́nìkínní kejì ní ìṣírí ní nínú?
◻ Báwo ni a ṣe lè fún àwọn tí wọ́n soríkọ́ àti àwọn tí wọ́n ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ní ìṣírí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Aájò àlejò ń ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ ara wa síi lẹ́nìkínní kejì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Nígbà tí Elijah soríkọ́, Jehofa fi pẹ̀lú inúrere tù ú nínú