Ẹ Má Ṣe Wo “Àwọn Ohun Tí Ń bẹ Lẹ́yìn”
“Kò sí ènìyàn tí ó ti fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun ìtúlẹ̀, tí ó sì ń wo àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn tí ó yẹ dáadáa fún ìjọba Ọlọ́run.”—LÚÙKÙ 9:62.
BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?
․․․․․
Kí nìdí tó fi yẹ ká “rántí aya Lọ́ọ̀tì”?
․․․․․
Àwọn nǹkan mẹ́ta wo ni kò yẹ ká máa ronú nípa rẹ̀?
․․․․․
Báwo la ṣe lè máa bá ètò Jèhófà rìn?
1. Ìkìlọ̀ wo ni Jésù fúnni, ìbéèrè wo ló sì jẹ yọ?
“Ẹ RÁNTÍ aya Lọ́ọ̀tì.” (Lúùkù 17:32) Ìkìlọ̀ tí Jésù Kristi fúnni ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] sẹ́yìn yìí ti wá ṣe pàtàkì gan-an lásìkò yìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Àmọ́ kí ni Jésù ní lọ́kàn pẹ̀lú ìkìlọ̀ tó gbàrònú yìí? Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti yé àwọn Júù tó ń bá sọ̀rọ̀ torí pé wọ́n mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí aya Lọ́ọ̀tì. Nígbà tí òun àti ìdílé rẹ̀ ń sá jáde kúrò ní ìlú Sódómù, ó hùwà àìgbọràn nípa bíbojú wo ẹ̀yìn, ó sì di ọwọ̀n iyọ̀.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 19:17, 26.
2. Kí ló ṣeé ṣe kó mú kí aya Lọ́ọ̀tì bojú wo ẹ̀yìn, kí sì ni ìwà àìgbọràn rẹ̀ yọrí sí?
2 Àmọ́ kí nìdí tí aya Lọ́ọ̀tì fi bojú wo ẹ̀yìn? Ṣé ó fẹ́ mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ni? Ṣé àìnígbàgbọ́ ló mú kó bojú wẹ̀yìn? Àbí ńṣe ni ọkàn rẹ̀ kò kúrò nínú àwọn ohun ìní tí wọ́n fi sílẹ̀ ní ìlú Sódómù? (Lúùkù 17:31) Ohun yòówù kó mú kó bojú wẹ̀yìn, ẹ̀mí rẹ̀ ló fi dí ìwà àìgbọràn tó hù. Ronú nípa èyí ná! Ọjọ́ kan náà tí àwọn èèyàn ìlú Sódómù àti Gòmórà tí wọ́n ti jingíri sínú ìwà ìbàjẹ́ kú ni òun náà kú. Abájọ tí Jésù fi sọ pé: “Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì”!
3. Báwo ni Jésù ṣe tẹnu mọ́ ọn pé ká má ṣe bojú wẹ̀yìn?
3 Àsìkò tí kò yẹ ká bojú wẹ̀yìn ni àwa náà ń gbé yìí. Jésù tẹnu mọ́ kókó yìí nígbà tó ń fèsì ìbéèrè ọkùnrin kan tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá òun lè lọ sọ fún àwọn mọ̀lẹ́bí òun pé ó dìgbòóṣe kí òun tó wá di ọmọ ẹ̀yìn. Jésù sọ pé: “Kò sí ènìyàn tí ó ti fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun ìtúlẹ̀, tí ó sì ń wo àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn tí ó yẹ dáadáa fún ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 9:62) Ṣé bí Jésù ṣe dáhùn yìí fi hàn pé ó jẹ́ ẹni tó le koko tàbí ẹni tí kì í fi òye báni lò? Rárá o. Jésù mọ̀ pé ńṣe ni ọkùnrin náà kàn ń ṣe àwáwí kó lè yẹ ohun tí ì bá jẹ́ ojúṣe rẹ̀ sílẹ̀. Jésù sọ pé ńṣe ni fífi òní dónìí fọ̀la dọ́la bẹ́ẹ̀ dà bíi wíwo “àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn.” Ǹjẹ́ ó burú kí ẹni tó ń túlẹ̀ kàn sáré wo ohun tó wà lẹ́yìn fìrí tàbí kó fi ohun èlò ìtúlẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kó sì yíjú sẹ́yìn? Kò sí èyí tó ṣe nínú méjèèjì tí kò ní pín ọkàn rẹ̀ níyà kúrò nínú ohun tó ń ṣe, ó sì lè nípa tí kò dára lórí iṣẹ́ rẹ̀.
4. Kí ló yẹ ká máa tẹjú mọ́?
4 Dípò tí a ó fi máa ronú nípa àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ńṣe ló yẹ ká tẹ ojú wa mọ́ àwọn ohun tó wà níwájú. Wo bí Òwe 4:25 ṣe sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí lọ́nà tó ṣe kedere, ó ní: “Ní ti ojú rẹ, ọ̀kánkán tààrà ni kí ó máa wò, bẹ́ẹ̀ ni, kí ojú rẹ títàn yanran tẹjú mọ́ ọ̀kánkán gan-an ní iwájú rẹ.”
5. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa wo àwọn ohun tó wà lẹ́yìn?
5 Ìdí pàtàkì wà tí kò fi yẹ ká máa wo àwọn ohun tó wà lẹ́yìn. Kí ni ìdí náà? Òun ni pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí. (2 Tím. 3:1) Kì í ṣe pípa ìlú burúkú méjì run là ń fojú sọ́nà fún, bí kò ṣe ìparun gbogbo ètò àwọn nǹkan búburú ti ayé yìí. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tí irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí aya Lọ́ọ̀tì kò fi ní ṣẹlẹ̀ sí wa? Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn ohun tó wà lẹ́yìn tó lè ṣe wá bíi pé ká lọ wò. (2 Kọ́r. 2:11) Torí náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun tí àwọn nǹkan náà jẹ́ àti bá a ṣe lè yẹra fún títẹ ojú wa mọ́ wọn.
NÍGBÀ TÍ NǸKAN ṢÌ DÁA
6. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa gbára lé ìrònú wa?
6 Ríronú pé àwọn ìgbà kan ti wà rí tí nǹkan dáa ju bó ṣe rí báyìí lọ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ewu tó yẹ ká sá fún. Kò yẹ ká máa gbára lé ìrònú wa torí pé gbogbo ìgbà kọ́ la máa ń rántí bí nǹkan ṣe rí gẹ́lẹ́. A lè wò ó pé àwọn ìṣòro tá a ní nígbà náà kò tó nǹkan, ká sì wá máa rò pé a láyọ̀ nígbà yẹn jù báyìí lọ, ìyẹn lè mú kó dà bíi pé nǹkan dára gan-an nígbà yẹn ju bó ṣe rí ní tòótọ́. Tá a bá ní irú èrò tí kò tọ́ yìí, ó lè máa wù wá pé kí nǹkan pa dà sí bó ṣe rí nígbà yẹn. Àmọ́ Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Má sọ pé: ‘Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọjọ́ àtijọ́ sàn ju ìwọ̀nyí lọ?’ nítorí pé ọgbọ́n kọ́ ni ìwọ fi béèrè nípa èyí.” (Oníw. 7:10) Kí nìdí tí irú èrò yìí fi léwu?
7-9. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n wà ní Íjíbítì? (b) Kí ló yẹ kó máa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láyọ̀? (d) Torí kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn tí wọ́n sì ń kùn?
7 Jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Mósè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àlejò ni wọ́n kọ́kọ́ ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí nílẹ̀ Íjíbítì, àmọ́ lẹ́yìn tí Jósẹ́fù kú, àwọn ọmọ Íjíbítì “yan àwọn olórí tí ń fipá múni ṣòpò lé [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] lórí fún ète níni wọ́n lára nínú ẹrù ìnira tí wọ́n ń rù.” (Ẹ́kís. 1:11) Nígbà tó yá Fáráò gbìyànjú láti dín iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kù torí náà ó ní kí wọ́n máa pa gbogbo ọmọkùnrin tí wọ́n bá bí. (Ẹ́kís. 1:15, 16, 22) Abájọ tí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Mósè kò fi yani lẹ́nu, ó sọ pé: “Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, mo ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ní Íjíbítì níṣẹ̀ẹ́, mo sì ti gbọ́ igbe ẹkún wọn nítorí àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́; nítorí tí mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú.”—Ẹ́kís. 3:7.
8 Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ayọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á ṣe pọ̀ tó nígbà tí wọ́n di òmìnira, tí wọ́n sì yan jáde kúrò ní ilẹ̀ tí wọ́n ti ń fi wọ́n ṣe ẹrú? Ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ ni wọ́n gbà rí ọwọ́ agbára Jèhófà nígbà tó mú Ìyọnu Mẹ́wàá wá sórí Fáráò agbéraga àtàwọn èèyàn rẹ̀. (Ka Ẹ́kísódù 6:1, 6, 7.) Ká sòótọ́, kì í ṣe pé àwọn ọmọ Íjíbítì kàn yọ̀ǹda àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa lọ lómìnira nìkan ni, ńṣe ni wọ́n ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa lọ, wọ́n sì tún fún wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà àti fàdákà, débi tá a fi lè sọ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run “gba tọwọ́ àwọn ará Íjíbítì.” (Ẹ́kís. 12:33-36) Inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún wá dùn sí i nígbà tí wọ́n rí bí Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣe pa run sínú Òkun Pupa. (Ẹ́kís. 14:30, 31) Ẹ ò rí i pé ó máa fún ìgbàgbọ́ ẹni lókun gan-an tí irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ bá ṣojú ẹni!
9 Àmọ́ ó yani lẹnu gan-an pé kò pẹ́ rárá lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè lọ́nà ìyanu tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn tí wọ́n sì ń kùn. Nípa kí ni? Nípa oúnjẹ ni! Ohun tí Jèhófà pèsè fún wọn kò tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàròyé pé: “Ẹ wo bí a ṣe rántí ẹja tí a máa ń jẹ ní Íjíbítì lọ́fẹ̀ẹ́, àwọn apálá àti bàrà olómi àti ewébẹ̀ líìkì àti àlùbọ́sà àti aáyù! Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ọkàn wa ti gbẹ táútáú. Ojú wa kò rí nǹkan kan rárá bí kò ṣe mánà yìí.” (Núm. 11:5, 6) Kò sí àní-àní pé ìrònú wọn kò tọ̀nà mọ́, débi pé wọ́n fẹ́ pa dà sí ilẹ̀ tí wọ́n ti ṣe ẹrú! (Núm. 14:2-4) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wo ohun tí ń bẹ lẹ́yìn, wọ́n sì pàdánù ojúure Jèhófà.—Núm. 11:10.
10. Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
10 Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú èyí lóde òní? Nígbà tí a bá kojú ìṣòro àti ìnira, ẹ má ṣe jẹ́ ká máa ronú lórí àwọn nǹkan tó dà bí ohun tó dára lójú wa tẹ́lẹ̀, bóyá ká tiẹ̀ tó ní ìmọ̀ òtítọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ohun tó burú tá a bá ṣàṣàrò lórí ohun tá a rí kọ́ látinú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá tàbí ká mọyì wọn, a gbọ́dọ̀ wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ká sì ní èrò tó tọ́ nípa wọn. Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a lè wá di ẹni tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn mọ́ nípa ipò tá a wà báyìí, kó sì wá máa ṣe wá bíi pé ká tún bẹ̀rẹ̀ sí í gbé irú ìgbésí ayé tí à ń gbé tẹ́lẹ̀.—Ka 2 Pétérù 2:20-22.
ÀWỌN NǸKAN TÁ A TI YÁÁFÌ
11. Ojú wo ni àwọn kan fi ń wo àwọn ohun tí wọ́n ti yááfì nígbà kan?
11 Ó báni nínú jẹ́ pé àwọn kan ń ronú nípa àwọn nǹkan tí wọ́n ti yááfì nígbà kan, wọ́n sì ń wò ó pé àwọn ti gbé ẹ̀tọ́ àwọn sọ nù. Ó ṣeé ṣe kó o ti ní àǹfààní lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga, wíwà ní ipò ọlá, tàbí kó o ní àǹfààní láti rí towó ṣe, àmọ́ o pinnu láti má ṣe lépa àwọn nǹkan yẹn. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ló ti fi ipò ńlá nídìí iṣẹ́ ajé, eré ìnàjú, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tàbí eré ìdárayá sílẹ̀. Ọjọ́ pẹ́ báyìí tí wọ́n ti fi àwọn nǹkan wọ̀nyẹn sílẹ̀ síbẹ̀, òpin kò tíì dé. Ǹjẹ́ o máa ń ronú nípa ipò tó ṣeé ṣe kó o wà báyìí ká ní o kò yááfì àwọn nǹkan yẹn nígbà yẹn?
12. Ojú wo ni Pọ́ọ̀lù fi wo àwọn ohun tó ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn?
12 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yááfì kó bàa lè di ọmọlẹ́yìn Kristi. (Fílí. 3:4-6) Ojú wo ló fi wo àwọn ohun tó ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn? Ó sọ fún wa pé: “Àwọn ohun tí ó jẹ́ èrè fún mi, ìwọ̀nyí ni mo ti kà sí àdánù ní tìtorí Kristi.” Kí nìdí? Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ní tòótọ́ mo ka ohun gbogbo sí àdánù pẹ̀lú ní tìtorí ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa mi. Ní tìtorí rẹ̀, èmi ti gba àdánù ohun gbogbo, mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí, kí n lè jèrè Kristi.”a (Fílí. 3:7, 8) Bí ẹnì kan tó da pàǹtírí tàbí ìdọ̀tí nù kò ṣe ní kábàámọ̀ pé òun pàdánù ohunkóhun, bẹ́ẹ̀ náà ni Pọ́ọ̀lù kò ṣe kábàámọ̀ àwọn àǹfààní tara èyíkéyìí tí ì bá rí látinú àwọn ohun tó ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn. Kò tún ṣe é bíi pé àwọn nǹkan yẹn ṣe pàtàkì mọ́.
13, 14. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀?
13 Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá rí i pé a ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa àwọn nǹkan tó dà bí àǹfààní tá a gbé sọ nù? Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ronú nípa bí àwọn ohun tó o ní báyìí ṣe níye lórí tó. O ti ní àjọṣe tó ṣeyebíye pẹ̀lú Jèhófà, ó sì mọ̀ ẹ́ sí olóòótọ́ èèyàn. (Héb. 6:10) Àwọn nǹkan tara wo ni ayé lè fúnni tá a lè fi wé àwọn ìbùkún tẹ̀mí tí à ń gbádùn báyìí àtàwọn tá a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú?—Ka Máàkù 10:28-30.
14 Lẹ́yìn náà ni Pọ́ọ̀lù wá mẹ́nu ba ohun kan tó máa jẹ́ ká lè máa bá a lọ láti jẹ́ olóòótọ́. Ó sọ pé òun ti ‘gbàgbé àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn òun sì ń nàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú.’ (Fílí. 3:13) Kíyè sí i pé ohun méjì ni Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́, àwọn méjèèjì sì ṣe pàtàkì. Àkọ́kọ́, a ní láti gbàgbé àwọn ohun tá a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn, ká má ṣe máa lo okun wa àti àkókò wa tó ṣe pàtàkì lórí ṣíṣàníyàn nípa wọn. Èkejì, bíi ti sárésáré tó kù díẹ̀ kó sáré dé òpin, a gbọ́dọ̀ máa nàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú, ká pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀.
15. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ṣàṣàrò lórí àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́?
15 Tá a bá ṣàṣàrò lórí àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, yálà láyé àtijọ́ tàbí lóde òní, a lè túbọ̀ rí ìṣírí gbà láti máa tẹ̀ síwájú dípò tí a ó fi máa wo àwọn ohun tó wà lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé Ábúráhámù àti Sárà ń bá a nìṣó láti máa rántí ìlú Úrì, “àyè ì bá ṣí sílẹ̀ fún wọn láti padà.” (Héb. 11:13-15) Àmọ́ wọn kò pa dà síbẹ̀. Nígbà tí Mósè kọ́kọ́ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, ohun tó fi sílẹ̀ ní ìlú náà pọ̀ ju ohun tí èyíkéyìí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa dà wá fi sílẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà lọ fíìfíì. Síbẹ̀, kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé ó fẹ́ pa dà ní àwọn nǹkan yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni pé “ó ka ẹ̀gàn Kristi sí ọrọ̀ tí ó tóbi ju àwọn ìṣúra Íjíbítì; nítorí tí ó tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà.”—Héb. 11:26.
ÀWỌN ÀṢÌṢE TÓ TI ṢẸLẸ̀ KỌJÁ
16. Báwo ni àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa kọjá ṣe lè nípa lórí wa?
16 Àmọ́ ṣá ó, kì í ṣe gbogbo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá náà ló máa ń dára. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìrònú nípa ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn tàbí àwọn àṣìṣe tá a ṣe ló ń kó ìdààmú bá wa. (Sm. 51:3) Ìbáwí tí wọ́n fún wa ṣì lè máa dùn wá. (Héb. 12:11) A lè máa ronú nípa àìṣèdájọ́ òdodo, èyí tó wáyé lóòótọ́ tàbí èyí tá a rò pé ó wáyé. (Sm. 55:2) Kí la lè ṣe tí a kò fi ní jẹ́ kí irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ mú ká máa ronú nípa àwọn nǹkan tí ń bẹ lẹ́yìn? Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ mẹ́ta yẹ̀ wò.
17. (a) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi ṣàpèjúwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ẹni tí ó kéré ju kékeré jù lọ nínú gbogbo ẹni mímọ́”? (b) Kí ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ tí kò fi jẹ́ kí èrò tí kò tọ́ mú òun rẹ̀wẹ̀sì?
17 Àwọn àṣìṣe tá a ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ẹni tí ó kéré ju kékeré jù lọ nínú gbogbo ẹni mímọ́.” (Éfé. 3:8) Kí ló mú kó rò bẹ́ẹ̀? Ó sọ pé: “Nítorí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 15:9) Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bó ṣe máa rí lára Pọ́ọ̀lù nígbà tó pàdé àwọn tó ti ṣe inúnibíni sí nígbà kan? Àmọ́, dípò tí Pọ́ọ̀lù á fi jẹ́ kí èrò tí kò tọ́ yìí mú kó rẹ̀wẹ̀sì, ńṣe ló pọkàn pọ̀ sórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run ti fi hàn sí i. (1 Tím. 1:12-16) Ìmọrírì tí èyí mú kó ní ló fún un lágbára lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Àwọn ìwà ẹ̀ṣẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù ti hù sẹ́yìn wà lára àwọn ohun tó pinnu láti gbàgbé. Bí àwa náà bá ń ronú nípa àánú tí Jèhófà ti fi hàn sí wa, a kò ní jẹ́ kí àníyàn nípa àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá tí a kò sì lè ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀ mu wá lómi. A ó lè máa lo okun wa fún iṣẹ́ tó wà lọ́wọ́ wa.
18. (a) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í bínú nítorí ìbáwí tí wọ́n fún wa? (b) Báwo la ṣe lè fi ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì nípa gbígba ìbáwí sílò?
18 Ìbáwí tó dùn wá gan-an. Tá a bá wá bẹ̀rẹ̀ sí í bínú nítorí ìbáwí tí wọ́n fún wa ńkọ́? Èyí lè dùn wá gan-an, ó lè mú ká banú jẹ́, kó sì mú ká “rẹ̀wẹ̀sì.” (Héb. 12:5) Yálà a kọ ìbáwí náà torí pé a “fi ojú kékeré” wò ó tàbí ńṣe la “rẹ̀wẹ̀sì” lẹ́yìn tá a gbà á, tí a kò sì fi sílò, ohun kan náà ló máa ń yọrí sí, ìbáwí náà kò ní ṣe wá láǹfààní tàbí kó mú ká ṣàtúnṣe. Ẹ ò rí i pé ó dára gan-an ká fi ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì sílò, ó sọ pé: “Di ìbáwí mú; má ṣe jẹ́ kí ó lọ. Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, nítorí òun ni ìwàláàyè rẹ.” (Òwe 4:13) Bíi ti awakọ̀ tó ń tẹ̀ lé àwọn àmì ojú ọ̀nà, ẹ jẹ́ ká máa gba ìbáwí, ká máa fi í sílò, ká sì máa bá ìgbésí ayé wa lọ.—Òwe 4:26, 27; ka Hébérù 12:12, 13.
19. Báwo la ṣe lè ní ìgbàgbọ́ bíi ti Hábákúkù àti Jeremáyà?
19 Àìṣèdájọ́ òdodo, èyí tó wáyé lóòótọ́ tàbí èyí tá a rò pé ó wáyé. Nígbà míì ọ̀rọ̀ wa lè dà bíi ti wòlíì Hábákúkù, tó ké pe Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, torí kò mọ ìdí tí Jèhófà fi fàyè gbà á pé kí àwọn nǹkan kan tó kù díẹ̀ káàtó ṣẹlẹ̀. (Háb. 1:2, 3) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí àwa náà ní ìgbàgbọ́ bíi ti wòlíì yẹn, ó sọ pé: “Síbẹ̀, ní tèmi, dájúdájú, èmi yóò máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà; èmi yóò kún fún ìdùnnú nínú Ọlọ́run ìgbàlà mi.” (Háb. 3:18) Bíi ti Jeremáyà ìgbàanì, tá a bá ní “ẹ̀mí ìdúródeni,” tá a sì ní ìgbàgbọ́ tó kún rẹ́rẹ́ nínú Jèhófà, Ọlọ́run onídàájọ́ òdodo, a lè ní ìdánilójú pé yóò ṣàtúnṣe ohun gbogbo ní àkókò tó tọ́.—Ìdárò 3:19-24.
20. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń “rántí aya Lọ́ọ̀tì”?
20 Àkókò amóríyá là ń gbé yìí. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu ń ṣẹlẹ̀ lásìkò yìí, ọ̀pọ̀ sì tún ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ láìpẹ́. Ǹjẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa bá ètò Jèhófà rìn. Ẹ sì jẹ́ ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ pé ká máa wo àwọn ohun tó wà níwájú ká má ṣe máa wo àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn. A óò sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé à ń “rántí aya Lọ́ọ̀tì”!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a túmọ̀ sí “pàǹtírí” nínú ẹsẹ yìí tún túmọ̀ sí “ẹlẹ́bọ́tọ,” “ìgbọ̀nsẹ̀” tàbí, “ohun tá a jù sí àwọn ajá.” Ọ̀mọ̀wé nípa Bíbélì kan sọ pé bí Pọ́ọ̀lù ṣe lo ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ó “kẹ̀yìn sí ohunkóhun tí kò ní láárí tó sì ń kóni nírìíra tí èèyàn kò fẹ́ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú rẹ̀ mọ́.”