Jèhófà Ni Ó Yẹ Kí A gbọ́kàn Lé
“Ní ti tòótọ́, Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò jẹ́ ìgbọ́kànlé rẹ.”—ÒWE 3:26.
1. Bí ọ̀pọ̀ tilẹ̀ ń sọ pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, kí ní fi hàn pé wọn kì í fìgbà gbogbo ṣe bẹ́ẹ̀?
ÀKỌLÉ tí ó wà lára owó ilẹ̀ United States kà pé: “Ọlọ́run Ni A Gbẹ́kẹ̀ Lé.” Ṣùgbọ́n, ṣé gbogbo àwọn tí ń ná owó yìí ní ilẹ̀ yẹn tàbí níbòmíràn ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run lóòótọ́? Àbí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó pọ̀ jù lọ sínú owó náà fúnra rẹ̀? A kò lè fi irú ìgbẹ́kẹ̀lé nínú owó ilẹ̀ yẹn tàbí ti orílẹ̀-èdè èyíkéyìí mìíràn wé ìgbẹ́kẹ̀lé nínú olódùmarè Ọlọ́run ìfẹ́, tí kì í ṣí agbára rẹ̀ lò, tí kò sì jẹ́ oníwọra rárá. Àní, ó ka ìwọra léèwọ̀ pátápátá.—Éfésù 5:5.
2. Ẹ̀mí wo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ ní nípa agbára tí ọrọ̀ ní?
2 Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń fi ìgbọ́kànlé wọn sínú Ọlọ́run, kì í ṣe nínú ọrọ̀, pẹ̀lú “agbára ìtannijẹ” rẹ̀. (Mátíù 13:22) Wọ́n mọ̀ pé agbára tí owó ní láti mú kí ayọ̀ pọ̀ sí i àti láti pa ìwàláàyè mọ́ ní ààlà gidigidi. Àmọ́ agbára Ọlọ́run Olódùmarè kò rí bẹ́ẹ̀. (Sefanáyà 1:18) Nígbà náà, ẹ wo bí ìṣínilétí náà ti bọ́gbọ́n mu tó pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí òun ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà’”!—Hébérù 13:5.
3. Báwo ni àyíká ọ̀rọ̀ Diutarónómì 31:6 ṣe tànmọ́lẹ̀ sórí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù yọ lò nínú ẹsẹ yẹn?
3 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ ọ̀rọ̀ tí ń bẹ lókè yìí sí àwọn Kristẹni tí í ṣe Hébérù, ó ṣàyọlò ìtọ́ni tí Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kété kí ó to kú, pé: “Ẹ jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má fòyà tàbí kí o gbọ̀n rìrì níwájú wọn, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ẹni tí ń bá ọ lọ. Òun kì yóò kọ̀ ọ́ tì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ pátápátá.” (Diutarónómì 31:6) Àyíká ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé Mósè ń rọ̀ wọ́n láti ní ìgbọ́kànlé tí ó ré kọjá wíwulẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò pèsè ohun ti ara fún wọn. Lọ́nà wo?
4. Báwo ni Ọlọ́run ṣe fi han àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé òun tó gbẹ́kẹ̀ lé?
4 Ní 40 ọdún tí Ísírẹ́lì fi ń rìn kiri nínú aginjù, Ọlọ́run kò dẹ́kun pípèsè àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé fún wọn. (Diutarónómì 2:7; 29:5) Ó tún pèsè aṣáájú fún wọn. Ọ̀nà kan tí ó gbà ṣe èyí ni nípa ìkùukùu lọ́sàn-án àti iná lóru, èyí tí ó ṣamọ̀nà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé “ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.” (Ẹ́kísódù 3:8; 40:36-38) Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí wọn wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà, Jèhófà yan Jóṣúà láti gbapò Mósè. Kò sí àní-àní pé àwọn olùgbé ilẹ̀ náà kò ní gbà lójú bọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n Jèhófà ti ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ rìn bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, nítorí náà wọn kò ní láti fòyà rárá. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìdí púpọ̀ láti gbà pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tí àwọn lè gbẹ́kẹ̀ lé!
5. Báwo ni ipò àwọn Kristẹni lónìí ṣe bá ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mu kí wọ́n tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí?
5 Àwọn Kristẹni lónìí ti ń rìn nínú aginjù ètò àwọn nǹkan burúkú ti ayé yìí bí wọ́n ti ń rin ìrìn àjò wọn lọ sí ayé tuntun ti Ọlọ́run. Ó ti lé ní 40 ọdún tí àwọn kan lára wọn ti ń rin ọ̀nà náà. Wàyí o, wọ́n ti dé bèbè ayé tuntun ti Ọlọ́run. Síbẹ̀, àwọn ọ̀tá ṣì dúró sójú ọ̀nà, pẹ̀lú èrò pé àwọn yóò ṣèdíwọ́ fún ẹnikẹ́ni láti wọ ibi tí yóò dàbí Ilẹ̀ Ìlérí, tí ògo rẹ̀ pọ̀ ju ti ìgbàanì tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin lọ. Nítorí náà, ẹ wo bí ọ̀rọ̀ Mósè, tí Pọ́ọ̀lù tún sọ ti ṣe wẹ́kú tó fún àwọn Kristẹni lónìí, pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà”! Ó dájú gbangba gbàǹgbà pé, gbogbo ẹni tí ó bá dúró gẹ́gẹ́ bí alágbára àti onígboyà, tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ kún, tí ó gbọ́kàn lé Jèhófà, yóò gba èrè rẹ̀.
Ìgbọ́kànlé Tí A Gbé Ka Ìmọ̀ àti Ìbádọ́rẹ̀ẹ́
6, 7. (a) Kí ni ó dán ìgbọ́kànlé Ábúráhámù nínú Jèhófà wò? (b) Báwo ni ìmọ̀lára Ábúráhámù yóò ti rí nígbà tí ó ń rìnrìn àjò lọ sí ibi tí yóò ti fi Ísákì rúbọ?
6 Nígbà kan, a pàṣẹ fún Ábúráhámù baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti fi ọmọ rẹ̀, Ísákì, rúbọ. (Jẹ́nẹ́sísì 22:2) Kí ni ó ran baba onífẹ̀ẹ́ yìí lọ́wọ́ láti ní irú ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀ tí kò yẹ̀ nínú Jèhófà, tí ó fi múra tán lójú ẹsẹ̀ láti ṣègbọràn? Hébérù 11:17-19 dáhùn rẹ̀ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù, nígbà tí a dán an wò, kí a kúkú sọ pé ó ti fi Ísákì rúbọ tán, ọkùnrin tí ó sì ti fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gba àwọn ìlérí gbìdánwò láti fi ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo rúbọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti wí fún un pé: ‘Ohun tí a ó pè ní ‘irú-ọmọ rẹ’ yóò jẹ́ nípasẹ̀ Ísákì.’ Ṣùgbọ́n ó ṣírò pé Ọlọ́run lè gbé e dìde, àní kúrò nínú òkú; láti ibẹ̀, ó sì tún rí i gbà lọ́nà àpèjúwe.”
7 Rántí pé ó gba Ábúráhámù àti Ísákì ní ọjọ́ mẹ́ta láti dé ibi tí wọn á ti ṣèrúbọ náà. (Jẹ́nẹ́sísì 22:4) Ábúráhámù ní àkókò tí ó pọ̀ tó láti tún ronú lórí ohun tí a ní kó ṣe. A ha lè finú wòye ìmọ̀lára rẹ̀ bí? Ìbí Ísákì jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀ tí ó mú ayọ̀ wá. Ẹ̀rí pé ó ní ọwọ́ Ọlọ́run nínú yìí mú kí ìbátan tí Ábúráhámù, àti aya rẹ̀ tí ó yàgàn tẹ́lẹ̀, Sárà, ní pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ jinlẹ̀. Ó dájú pé lẹ́yìn náà, wọ́n fojú sọ́nà fún bí ọjọ́ ọ̀la Ísákì àti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ yóò ti rí. Ó ha lè jẹ́ pé, lójijì, àlá wọn ti fẹ́ di èyí tí kò lè ṣẹ mọ́, nítorí ohun tí Ọlọ́run béèrè nísinsìnyí?
8. Báwo ni ìgbọ́kànlé Ábúráhámù nínú Ọlọ́run ṣe ju wíwulẹ̀ gbà gbọ́ pé Ó lè jí Ísákì díde?
8 Síbẹ̀, Ábúráhámù ní ìgbọ́kànlé tí ó gbé karí bí àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì ti mọ ara wọn sí. Gẹ́gẹ́ bí “ọ̀rẹ́ Jèhófà,” Ábúráhámù “ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, a sì kà á sí òdodo fún un.” (Jákọ́bù 2:23) Ìgbọ́kànlé tí Ábúráhámù ní nínú Jèhófà ju wíwulẹ̀ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run lè jí Ísákì dìde. Ábúráhámù tún gbà pé ohun tí Jèhófà ní kí òun ṣe tọ́, àní bí Ábúráhámù kò tilẹ̀ mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀. Kò ní ìdí kankan láti béèrè lọ́wọ́ Jèhófà bóyá ó tọ́ láti pàṣẹ pé kí òun ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, a fún ìgbọ́kànlé Ábúráhámù lókun nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà dá sí ọ̀ràn náà, tí kò jẹ́ kí ó pa Ísákì láti fi rúbọ.—Jẹ́nẹ́sísì 22:9-14.
9, 10. (a) Ìgbà wo ni Ábúráhámù ti kọ́kọ́ fi ìgbọ́kànlé hàn nínú Jèhófà? (b) Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni a rí kọ́ lára Ábúráhámù?
9 Ábúráhámù fi irú ìgbọ́kànlé yìí náà hàn nínú òdodo Jèhófà ní ọdún 25 sẹ́yìn. Nígbà tí a kìlọ̀ fún un pé ìparun ń bọ̀ wá sórí Sódómù àti Gòmórà, ìdààmú bá a nítorí ire àwọn olódodo tí ń gbé níbẹ̀, títí kan Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ábúráhámù bẹ Ọlọ́run pé: “Kò ṣeé ronú kàn nípa rẹ pé o ń gbé ìgbésẹ̀ ní irú ọ̀nà yìí láti fi ikú pa olódodo pẹ̀lú ẹni burúkú tí ó fi jẹ́ pé ó ní láti ṣẹlẹ̀ sí olódodo bí ó ti ń rí fún ẹni burúkú! Kò ṣeé ronú kàn nípa rẹ. Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé kì yóò ha ṣe ohun tí ó tọ́ bí?”—Jẹ́nẹ́sísì 18:25.
10 Ó dá Ábúráhámù lójú gbangba pé Jèhófà kì í hùwà àìṣòdodo. Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin lẹ́yìn náà pé: “Olódodo ni Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, ó sì jẹ́ adúróṣinṣin nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.” (Sáàmù 145:17) Ó dára kí a bi ara wa léèrè pé: ‘Mo ha ń gba ohun tí Jèhófà bá yọ̀ǹda pé kí ó ṣẹlẹ̀ sí mi láìkọminú nípa òdodo rẹ̀? Mo ha gbà pé ohunkóhun tí ó bá yọ̀ǹda kí ó ṣẹlẹ̀ sí mi yóò jẹ́ fún ire mi àti fún ire àwọn ẹlòmíràn?’ Bí a bá lè dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, a ti kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì lára Ábúráhámù.
Fífi Ìgbọ́kànlé Hàn Nínú Àwọn Tí Jèhófà Yàn
11, 12. (a) Apá wo nínú ìgbọ́kànlé ni ó ti jẹ́ èyí tí ó pọndandan fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run? (b) Kí ní lè jẹ́ ìṣòro fún wa nígbà mìíràn?
11 Àwọn tí ó bá fi Jèhófà ṣe ìgbọ́kànlé wọn tún máa ń fi ìgbọ́kànlé hàn nínú àwọn ọkùnrin tí Jèhófà yàn láti mú ète rẹ̀ ṣẹ. Ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí túmọ̀ sí fífi ìgbọ́kànlé hàn nínú Mósè àti lẹ́yìn náà nínú arọ́pò rẹ̀, Jóṣúà. Ní ti àwọn Kristẹni ìjímìjí, ó túmọ̀ sí fífi ìgbọ́kànlé hàn nínú àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin mìíràn ti ìjọ Jerúsálẹ́mù. Fún àwa lónìí, ó túmọ̀ sí níní ìgbọ́kànlé nínú “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” tí a yàn láti pèsè “oúnjẹ” tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,” àti àwọn kan lára wọn tí wọ́n jẹ́ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso.—Mátíù 24:45.
12 Ní tòótọ́, fífi ìgbọ́kànlé wa sínú àwọn tí ń mú ipò iwájú nínú ìjọ Kristẹni jẹ́ fún àǹfààní ara wa. A sọ fún wa pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.”—Hébérù 13:17.
Yẹra fún Kíkọminú Nípa Àwọn Tí Jèhófà Yàn
13. Ìdí wo ni a ní fún níní ìgbọ́kànlé nínú àwọn tí a yàn láti mú ipò iwájú?
13 Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ láti wà déédéé nínú fífi ìgbọ́kànlé hàn nínú àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín àwọn ènìyàn Jèhófà. A lè béèrè lọ́wọ́ ara wa pé: ‘Mósè ha ṣàṣìṣe rí bí? Ìgbà gbogbo ha ni àwọn àpọ́sítélì ń fi ìṣarasíhùwà bíi ti Kristi, tí Jésù fẹ́ kí wọ́n ní hàn bí?’ Ìdáhùn náà ṣe kedere. Jèhófà ti yàn láti lo àwọn ọkùnrin adúróṣinṣin àti olùfọkànsìn láti ṣamọ̀nà àwọn ènìyàn rẹ̀, àní bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ aláìpé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí àwọn alàgbà lónìí tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, ó ṣì yẹ kí a kà wọ́n sí àwọn “tí ẹ̀mí mímọ́ yàn . . . ṣe alábòójútó, láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run.” Wọ́n yẹ fún ìtìlẹ́yìn àti ọ̀wọ̀ wa.—Ìṣe 20:28.
14. Kí ní yẹ fún àfiyèsí nípa yíyàn tí Jèhófà yan Mósè ṣe aṣáájú dípò Áárónì tàbí Míríámù?
14 Ọdún mẹ́ta ni Áárónì fi ju Mósè lọ, ṣùgbọ́n arábìnrin wọn, Míríámù, ju àwọn méjèèjì lọ. (Ẹ́kísódù 2:3, 4; 7:7) Níwọ̀n bí ọ̀rọ̀ sì ti já gaara lẹ́nu Áárónì ju Mósè lọ, a yàn án gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀sọ fún àbúrò rẹ̀. (Ẹ́kísódù 6:29–7:2) Síbẹ̀, láti lè ṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Jèhófà kò yan Míríámù, tí ó dàgbà jù lọ, tàbí Áárónì, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ já gaara jù lọ. Mósè ni ó yàn nítorí gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó mọ̀ nípa rẹ̀ àti ohun tí ó jẹ́ àìní kánjúkánjú nígbà náà. Ní àkókò kan, nígbà tí wọn kò ní òye yìí, Áárónì àti Míríámù ráhùn pé: “Ṣé kìkì nípasẹ̀ Mósè nìkan ṣoṣo ni Jèhófà ti gbà sọ̀rọ̀ ni? Kò ha ti sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwa pẹ̀lú bí?” A fìyà jẹ Míríámù, tí ó ṣeé ṣe kí ó ti jẹ́ olórí rìgímọ̀ náà, fún ìwà àìlọ́wọ̀ tí ó hù sí ẹni tí Jèhófà yàn, ẹni tí òun àti Áárónì yẹ kí wọ́n mọ̀ sí “ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.”—Númérì 12:1-3, 9-15.
15, 16. Báwo ni Kálébù ṣe fi hàn pé òun ní ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà?
15 Nígbà tí a rán amí 12 jáde láti lọ ṣamí Ilẹ̀ Ìlérí wá, àwọn 10 mú ìròyìn búburú wá. Wọ́n kó jìnnìjìnnì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ Kénáánì “àwọn ọkùnrin tí ó tóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.” Èyí pẹ̀lú mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “kùn sí Mósè àti Áárónì.” Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo àwọn amí náà ni kò gbọ́kàn lé Mósè àti Jèhófà. A kà pé: “Nígbà náà ni Kálébù gbìyànjú láti mú àwọn ènìyàn náà pa rọ́rọ́ níwájú Mósè, ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: ‘Ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ tààràtà, ó sì dájú pé a ó gbà á, nítorí pé a lè borí rẹ̀ dájúdájú.’” (Númérì 13:2, 25–33; 14:2) Jóṣúà, tí òun àti Kálébù jọ jẹ́ amí, di ìdúróṣinṣin rẹ̀ mú bíi ti Kálébù. Àwọn méjèèjì fi hàn pé àwọn ti fi Jèhófà ṣe ìgbọ́kànlé àwọn, nígbà tí wọ́n wí pé: “Bí Jèhófà bá ní inú dídùn sí wa, dájúdájú, nígbà náà òun yóò mú wa wá sínú ilẹ̀ yìí, yóò sì fi í fún wa, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin. Kìkì . . . kí ẹ má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà . . . Jèhófà sì wà pẹ̀lú wa. Ẹ má bẹ̀rù wọn.” (Númérì 14:6-9) Wọ́n rí èrè ìgbọ́kànlé yìí tí wọ́n ní nínú Jèhófà gbà. Nínú ìran àwọn àgbàlagbà tí ó wà láàyè nígbà náà, Kálébù, Jóṣúà, àti àwọn ọmọ Léfì díẹ̀ nìkan ni wọ́n láǹfààní láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí.
16 Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, Kálébù wí pé: “Ní tèmi, mo tọ Jèhófà Ọlọ́run mi lẹ́yìn ní kíkún. . . . Wàyí o, kíyè sí i, Jèhófà ti pa mí mọ́ láàyè, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí, ní ọdún márùn-dín-láàádọ́ta yìí, láti ìgbà tí Jèhófà ti ṣe ìlérí yìí fún Mósè, nígbà tí Ísírẹ́lì rìn ní aginjù, wàyí o, èmi rèé lónìí, mo di ẹni ọdún márùn-dín-láàádọ́rùn-ún. Síbẹ̀, mo lágbára lónìí gẹ́gẹ́ bí mo ti ní in ní ọjọ́ tí Mósè rán mi jáde. Bí agbára mi ti rí nígbà yẹn, bẹ́ẹ̀ ni agbára mi rí nísinsìnyí.” (Jóṣúà 14:6-11) Kíyè sí ẹ̀mí rere tí Kálébù ní, ìṣòtítọ́ rẹ̀, àti agbára rẹ̀. Síbẹ̀, Jèhófà kò yan Kálébù ṣe arọ́pò Mósè. Jóṣúà ni a nawọ́ àǹfààní yìí sí. A lè ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà ní ìdí fún yíyan ẹni tí ó yàn, ìyẹn sì ni yíyàn tí ó dára jù lọ.
17. Kí ní ti lè mú kí ó dà bí pé Pétérù kò tóótun fún ẹrù iṣẹ́?
17 Àpọ́sítélì Pétérù sẹ́ Ọ̀gá rẹ̀ nígbà mẹ́ta. Ìwàǹwára tún mú kí ó fúnra rẹ̀ ṣèdájọ́, ní gígé etí ẹrú àlùfáà àgbà sọnù. (Mátíù 26:47-55, 69-75; Jòhánù 18:10, 11) Àwọn kan lè sọ pé Pétérù jẹ́ ojo, ẹni tí kò wà déédéé, tí kò yẹ kí ó gbádùn àǹfààní àrà ọ̀tọ̀. Síbẹ̀, ta ni a fún ní àwọn kọ́kọ́rọ́ Ìjọba náà, ẹni tí a fún láǹfààní láti ṣí ọ̀nà ìpè ti ọ̀run fún ẹgbẹ́ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀? Pétérù ni.—Ìṣe 2:1-41; 8:14-17; 10:1-48.
18. Gẹ́gẹ́ bí Júúdà ti mẹ́nu kàn án, àṣìṣe wo ni a óò fẹ́ láti yẹra fún?
18 Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí fi hàn pé a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún gbígbé ìdájọ́ wa ka ìrísí òde. Bí a bá fi ìgbọ́kànlé wa sínú Jèhófà, a kò ní kọminú nípa àwọn tí ó yàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn aláìpé, tí wọn kò sọ pé àwọn jẹ́ ẹni tí kò lè ṣàṣìṣe ni ó wà nínú ètò àjọ ti orí ilẹ̀ ayé, ó ń lò wọ́n lọ́nà gíga lọ́lá. Júúdà, iyèkan Jésù, kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní nípa àwọn kan tí “ń ṣàìka ipò olúwa sí, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ àwọn ẹni ògo tèébútèébú.” (Júúdà 8-10) Kí a má ṣe dà bí wọn láé.
19. Èé ṣe tí a kò ní ìdí kankan láti kọminú nípa àwọn tí Jèhófà yàn?
19 Ó hàn gbangba pé àwọn tí wọ́n ní ànímọ̀ yíyẹ láti lè darí àwọn ènìyàn Jèhófà lọ́nà tí ó fẹ́ kí wọ́n tọ̀ ní àkókò kan pàtó ni ó ń yan àwọn ẹrù iṣẹ́ kan pàtó fún. Ó yẹ kí a gbìyànjú láti tẹ́wọ́ gba òtítọ́ yìí, kí a má máa kọminú nípa àwọn tí Ọlọ́run yàn, ṣùgbọ́n kí a máa fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ sìn níbi tí Jèhófà bá yan olúkúlùkù wa sí. Nípa báyìí a ń fi hàn pé a ti fi Jèhófà ṣe ìgbọ́kànlé wa.—Éfésù 4:11-16; Fílípì 2:3.
Fífi Ìgbọ́kànlè Hàn Nínú Òdodo Jèhófà
20, 21. Kí ni a lè rí kọ́ nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá Mósè lò?
20 Nígbà mìíràn, bí a bá ní ìtẹ̀sí láti ní ìgbọ́kànlé nínú ara wa ju níní in nínú Jèhófà, ẹ jẹ́ kí a kẹ́kọ̀ọ́ lára Mósè. Nígbà tí ó jẹ́ ẹni 40 ọdún, ó fúnra rẹ̀ jáde láti dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ kúrò ní ìgbèkùn Íjíbítì. Kò sí àní-àní pé ó ní ète rere lọ́kàn, ṣùgbọ́n kò yọrí sí dídá Ísírẹ́lì nídè lójú ẹsẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ipò òun alára kò sunwọ̀n sí i. Àní, ó pọndandan fún un láti sá lọ. Ìgbà tí ó tó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lílekoko fún 40 ọdún ní ilẹ̀ àjèjì ni ó tó tóótun láti di ẹni tí a yàn fún ohun tí ó ti fẹ́ ṣe tẹ́lẹ̀. Wàyí o, ó lè ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà wà lẹ́yìn òun nítorí pé nísinsìnyí ó ń ṣe àwọn nǹkan lọ́nà ti Jèhófà, ní àkókò tí ó bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ Rẹ̀ mu.—Ẹ́kísódù 2:11–3:10.
21 Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè bi ara wa léèrè pé: ‘Ìgbà mìíràn ha wà tí mo máa ń ṣáájú Jèhófà àti àwọn alàgbà tí ó yàn sípò nínú ìjọ, tí mo ń gbìyànjú láti mú kí nǹkan yá kánkán tàbí ṣe nǹkan lọ́nà ti ara mi? Kàkà tí n óò fi rò pé a gbé àwọn àǹfààní kan fò mí, mo ha ṣe tán láti tẹ́wọ́ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí a ń fún mi lọ́wọ́lọ́wọ́ bí?’ Ní tòótọ́, a ha ti rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ lára Mósè bí?
22. Láìka pípàdánù àǹfààní ńláǹlà sí, ojú wo ni Mósè fi wo Jèhófà?
22 Síwájú sí i, a lè kọ́ ẹ̀kọ́ mìíràn lára Mósè. Númérì 20:7-13 sọ àṣìṣe tí ó ṣe fún wa, tí ó sì ná an ni ohun tí ó ṣeyebíye fún un. Ó pàdánù àǹfààní ṣíṣamọ̀nà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Ìhùwàpadà rẹ̀ lẹ́yìn náà ha fi hàn pé ó gbà pé ìpinnu Jèhófà lórí ọ̀ràn náà kò tọ́? Kí a sọ ọ́ lọ́nà àpèjúwe, ǹjẹ́ ó ká gúlútú, tí ó sì ń kùn nítorí tí ó rò pé ohun tí Ọlọ́run ṣe sí òun kò tọ́ rárá bí? Mósè ha sọ ìgbọ́kànlé rẹ̀ nínú Jèhófà nù bí? A lè rí ìdáhùn nínú ọ̀rọ̀ tí Mósè fúnra rẹ̀ sọ fún Ísírẹ́lì kété kí ó tó kú. Mósè sọ nípa Jèhófà pé: “Pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:4) Ó dájú pé Mósè pa ìgbọ́kànlé rẹ̀ nínú Jèhófà mọ́ títí dé òpin. Àwa ńkọ́? Olúkúlùkù wa ha ń gbé ìgbésẹ̀ láti fún ìgbọ́kànlé wa nínú Jèhófà àti òdodo rẹ̀ lókun bí? Báwo ni a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ kí a gbé e yẹ̀ wò.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Ìdí wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní fún gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà?
◻ Ní ti ìgbọ́kànlé, kí ni a lè rí kọ́ lára Ábúráhámù?
◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a yẹra fún kíkọminú nípa àwọn tí Jèhófà bá yàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà wé mọ́ bíbọ̀wọ̀ fún àwọn tí ń mú ipò iwájú nínú ìjọ