Kristi Ni Aṣáájú Ìjọ Rẹ̀
“Wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” —MÁTÍÙ 28:20.
1, 2. (a) Nígbà tí Jésù tí a ti jí dìde ń pàṣẹ pé ká máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn, kí ló ṣèlérí fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? (b) Ètò wo ni Jésù alára ṣe fún dídarí ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀?
KÍ Jésù Kristi Aṣáájú wa tó gòkè re ọ̀run lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, ó fara han àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó sì sọ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mátíù 23:10; 28:18-20.
2 Kì í ṣe pé Jésù gbé iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà ti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ nìkan ni, ó tún ṣèlérí pé òun máa wà pẹ̀lú wọn. Ìtàn ẹ̀sìn Kristẹni láti ìbẹ̀rẹ̀ pàá, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé Ìṣe tó wà nínú Bíbélì, fi hàn gbangba-gbàǹgbà pé Kristi lo ọlá àṣẹ tá a fún un láti fi darí ìjọ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ náà. Ó rán “olùrànlọ́wọ́” tó ṣèlérí—ìyẹn ẹ̀mí mímọ́—kí ó lè fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lókun, kí ó sì máa darí ìgbòkègbodò wọn. (Jòhánù 16:7; Ìṣe 2:4, 33; 13:2-4; 16:6-10) Jésù tí a jí dìde lo àwọn áńgẹ́lì tó wà lábẹ́ ìdarí rẹ̀ láti ṣètìlẹyìn fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Ìṣe 5:19; 8:26; 10:3-8, 22; 12:7-11; 27:23, 24; 1 Pétérù 3:22) Kò tán síbẹ̀ o, Aṣáájú wa tún pèsè ìtọ́sọ́nà fún ìjọ nípa ṣíṣètò pé kí àwọn ọkùnrin tó tóótun máa sìn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ olùṣàkóso.—Ìṣe 1:20, 24-26; 6:1-6; 8:5, 14-17.
3. Àwọn ìbéèrè wo la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Àmọ́ ọjọ́ tiwa, tí í ṣe “ìparí ètò àwọn nǹkan,” wá ńkọ́? Báwo ni Jésù Kristi ṣe ń darí ìjọ Kristẹni lóde òní? Báwo la sì ṣe lè fi hàn pé a gbà pé òun ni Aṣáájú wa?
Ọ̀gá Náà Ní Ẹrú Olóòótọ́
4. (a) Àwọn wo ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà? (b) Kí ni Ọ̀gá ní kí ẹrú náà máa bójú tó?
4 Nígbà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀, ó sọ pé: “Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀, láti fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu? Aláyọ̀ ni ẹrú náà bí ọ̀gá rẹ̀ nígbà tí ó bá dé, bá rí i tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Òun yóò yàn án sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.” (Mátíù 24:45-47) Jésù Kristi Aṣáájú wa ni “ọ̀gá” náà. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà—ìyẹn ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé—ló sì yàn ṣe olórí gbogbo nǹkan ìní rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.
5, 6. (a) Nínú ìran kan tí àpọ́sítélì Jòhánù rí, kí ni “ọ̀pá fìtílà méje oníwúrà” àti “ìràwọ̀ méje náà” dúró fún? (b) Kí ni wíwà tí “ìràwọ̀ méje náà” wà ní ọwọ́ ọ̀tún Jésù fi hàn?
5 Ìwé Ìṣípayá inú Bíbélì fi hàn pé ẹrú olóòótọ́ àti olóye wà lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi ní tààràtà. Nínú ìran kan tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nípa “ọjọ́ Olúwa,” ó rí “ọ̀pá fìtílà méje oníwúrà, àti ní àárín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnì kan tí ó dà bí ọmọ ènìyàn,” tí ó “ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.” Jésù sọ fún Jòhánù nígbà tó ń ṣàlàyé ìran náà fún un pé: “Ní ti àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìràwọ̀ méje tí ìwọ rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, àti ti ọ̀pá fìtílà méje oníwúrà náà: Ìràwọ̀ méje náà túmọ̀ sí àwọn áńgẹ́lì ìjọ méje, ọ̀pá fìtílà méje náà sì túmọ̀ sí ìjọ méje.”—Ìṣípayá 1:1, 10-20.
6 “Ọ̀pá fìtílà méje oníwúrà” náà dúró fún gbogbo ìjọ Kristẹni tòótọ́ tó wà ní “ọjọ́ Olúwa,” èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní 1914. Àmọ́ “ìràwọ̀ méje náà” wá ńkọ́? Níbẹ̀rẹ̀, wọ́n dúró fún gbogbo àwọn alábòójútó ẹni àmì òróró tí a fi ẹ̀mí bí, àwọn tí ń bójú tó ìjọ wọ̀nyẹn ní ọ̀rúndún kìíní.a Àwọn alábòójútó wọ̀nyẹn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún Jésù—ìyẹn lábẹ́ ìtọ́sọ́nà àti ìdarí rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni o, Kristi Jésù ló ń darí ẹgbẹ́ ẹrú tí kì í ṣe ẹnì kan ṣoṣo gíro yìí. Àmọ́, nísinsìnyí àwọn alábòójútó tó jẹ́ ẹni àmì òróró ti kéré níye gan-an. Báwo ni Kristi ṣe ń darí àwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún [93,000] ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé?
7. (a) Báwo ni Jésù ṣe ń lo Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso láti darí àwọn ìjọ kárí ayé? (b) Èé ṣe tá a fi lè sọ pé ẹ̀mí mímọ́ ló yan àwọn Kristẹni alábòójútó?
7 Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọ̀rúndún kìíní, àwùjọ kéréje àwọn ọkùnrin tí ó tóótun láti ara àwọn alábòójútó ẹni àmì òróró ló ń sìn báyìí gẹ́gẹ́ bí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, àwọn ló ń ṣojú fún ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà. Aṣáájú wa ń lo Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso yìí láti yan àwọn ọkùnrin tó tóótun—wọn ì báà jẹ́ àwọn tí a fẹ̀mí bí tàbí tí a kò fẹ̀mí bí—gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú àwọn ìjọ àdúgbò. Ẹ̀mí mímọ́, tí Jèhófà fún Jésù láti lò, ń kó ipa tí kò kéré nínú ọ̀ràn yìí. (Ìṣe 2:32, 33) Àmọ́, àwọn alábòójútó wọ̀nyí ní láti kọ́kọ́ dójú ìlà ohun tá a là sílẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ̀mí mímọ́ mí sí. (1 Tímótì 3:1-7; Títù 1:5-9; 2 Pétérù 1:20, 21) Ìdámọ̀ràn àti ìyannisípò máa ń wáyé lẹ́yìn àdúrà àti lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́. Kò tán síbẹ̀ o, àwọn tó bá ń so èso ẹ̀mí yẹn làwọn tá à ń yàn sípò. (Gálátíà 5:22, 23) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé gbogbo alàgbà, ì báà jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí tí kì í ṣe ẹni àmì òróró, ni ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù bá wí, pé: “Ẹ kíyè sí ara yín àti gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yín ṣe alábòójútó.” (Ìṣe 20:28) Àwọn ọkùnrin tá a yàn sípò wọ̀nyí ń gba ìdarí látọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn bójú tó ìjọ. Lọ́nà yìí la fi lè sọ pé Kristi wà pẹ̀lú wa lóde òní, àti pé òun fúnra rẹ̀ ló ń darí ìjọ.
8. Báwo ni Kristi ṣe ń lo àwọn áńgẹ́lì láti darí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
8 Jésù tún ń lo àwọn áńgẹ́lì pàápàá láti darí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lónìí. Níbàámu pẹ̀lú àkàwé àlìkámà àti èpò, àkókò ìkórè yóò dé ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Àwọn wo ni Ọ̀gá náà yóò lò fún iṣẹ́ ìkórè ọ̀hún? Kristi sọ pé: “Àwọn áńgẹ́lì . . . ni akárúgbìn.” Ó fi kún un pé: “Ọmọ ènìyàn yóò rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ jáde, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tí ń fa ìkọ̀sẹ̀ jáde kúrò nínú ìjọba rẹ̀ àti àwọn ènìyàn tí ń hu ìwà àìlófin.” (Mátíù 13:37-41) Ìyẹn nìkan kọ́ o, gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì kan ṣe darí Fílípì pé kó lọ bá ìwẹ̀fà ará Etiópíà, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀rí rẹpẹtẹ wà lónìí pé Kristi ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti darí iṣẹ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ kí wọ́n lè rí àwọn olóòótọ́ ọkàn.—Ìṣe 8:26, 27; Ìṣípayá 14:6.
9. (a) Ọ̀nà wo ni Kristi gbà ń darí ìjọ Kristẹni lónìí? (b) Ìbéèrè wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò bá a bá fẹ́ jàǹfààní nínú ìtọ́sọ́nà Kristi?
9 Ẹ ò rí i pé ó ń fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an láti mọ̀ pé Jésù Kristi ń darí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lóde òní nípasẹ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, ẹ̀mí mímọ́, àtàwọn áńgẹ́lì! Kódà bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan bá wà nínú ipò tí wọn kò ti ráyè kàn sí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso fún sáà kan, bóyá nítorí inúnibíni tàbí irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀, Kristi yóò ṣì máa fi ẹ̀mí mímọ́ àtàwọn áńgẹ́lì darí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Àmọ́, àfi tá a bá gbà pé òun ni Aṣáájú wa nìkan la fi lè jàǹfààní nínú ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a gbà pé Kristi ni Aṣáájú wa?
“Ẹ Jẹ́ Onígbọràn . . . Ẹ sì Jẹ́ Ẹni Tí Ń Tẹrí Ba”
10. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àwọn alàgbà tá a yàn sípò nínú ìjọ?
10 Aṣáájú wa ti fún ìjọ ní “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”—“àwọn kan gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere, àwọn kan gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́.” (Éfésù 4:8, 11, 12) Ìwà àti ìṣesí wa sí wọn ló máa fi hàn kedere bóyá a gba Kristi gẹ́gẹ́ bí Aṣáájú wa. Ńṣe ló yẹ ká máa ‘fi ara wa hàn ní ẹni tó kún fún ọpẹ́’ nítorí àwọn ọkùnrin tó tóótun nípa tẹ̀mí tí Kristi fún wa. (Kólósè 3:15) Ó tún yẹ ká máa bọlá fún wọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí a ka àwọn àgbà ọkùnrin tí ń ṣe àbójútó lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ yẹ fún ọlá ìlọ́po méjì.” (1 Tímótì 5:17) Báwo la ṣe lè fọpẹ́ hàn, ká sì fi hàn pé a mọyì àwọn àgbà ọkùnrin—ìyẹn àwọn alàgbà, tàbí alábòójútó—nínú ìjọ? Pọ́ọ̀lù dáhùn pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba.” (Hébérù 13:17) Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ ká máa ṣègbọràn, ká máa tẹrí ba fún wọn, ká má máa ṣagídí sí wọn.
11. Kí nìdí tí ọ̀ràn bíbọlá fún ètò níní alàgbà nínú ìjọ fi wé mọ́ gbígbé níbàámu pẹ̀lú ìrìbọmi wa?
11 Ẹni pípé ni Aṣáájú wa. Àmọ́ àwọn ọkùnrin tó fún wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn kì í ṣe ẹni pípé. Nítorí náà, wọ́n lè ṣe àṣìṣe nígbà míì. Síbẹ̀, ó pọn dandan pé ká kọ́wọ́ ti ètò tí Kristi ṣe. Ohun tó tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ ni pé, bí a bá fẹ́ fi hàn pé lóòótọ́ là ń gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ àti ìbatisí wa, a ní láti gbà pé ẹ̀mí ló yan àwọn èèyàn sípò nínú ìjọ, ká sì máa fi tọkàntọkàn tẹrí ba fún wọn. Ìrìbọmi tá a ṣe ‘lórúkọ ẹ̀mí mímọ́’ jẹ́ ìpolongo ní gbangba pé a mọ ohun tí ẹ̀mí mímọ́ jẹ́, pé a sì mọ ipa tó ń kó nínú ète Jèhófà. (Mátíù 28:19) Ìrìbọmi wa fi hàn pé a ṣe tán láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí náà, ká má sì ṣe ohunkóhun tó máa dí iṣẹ́ rẹ̀ láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lọ́wọ́. Níwọ̀n bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń kó ipa pàtàkì nínú dídámọ̀ràn àti yíyan àwọn alàgbà, ǹjẹ́ a lè fi tòótọ́-tòótọ́ sọ pé à ń gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa bí a bá kọ̀ láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò níní alàgbà nínú ìjọ?
12. Àpẹẹrẹ àwọn wo ni Júúdà mẹ́nu kàn pé wọn ò bọlá fún ọlá àṣẹ, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú èyí?
12 Ìwé Mímọ́ kún fún àpẹẹrẹ tó kọ́ wa ní ìjẹ́pàtàkì ìgbọràn àti ìtẹríba. Nígbà tí ọmọ ẹ̀yìn nì, Júúdà, ń tọ́ka sí ọ̀ràn àwọn tó ń sọ̀rọ̀ èébú sí àwọn ọkùnrin tá a yàn sípò nínú ìjọ, ó mẹ́nu kan àwọn èèyàn mẹ́ta kan tó yẹ ká fi ọ̀ràn wọn ṣàríkọ́gbọ́n. Ó sọ pé: “Ó mà ṣe fún wọn o, nítorí wọ́n ti lọ ní ipa ọ̀nà Kéènì, wọ́n sì ti rọ́ wọnú ipa ọ̀nà ìṣìnà Báláámù fún èrè, wọ́n sì ti ṣègbé nínú ọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ Kórà!” (Júúdà 11) Kéènì kọ etí ikún sí ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà fún un, kò yọwọ́ nínú ìwà ìkórìíra tó yọrí sí ìpànìyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 4:4-8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé léraléra ni Ọlọ́run kìlọ̀ fún Báláámù, síbẹ̀ ó sáà fẹ́ fi àwọn èèyàn Ọlọ́run ré, nítorí owó. (Númérì 22:5-28, 32-34; Diutarónómì 23:5) Ipò pàtàkì kan ni Kórà dì mú ní Ísírẹ́lì, àmọ́ ìyẹn ò tó o. Ó dìtẹ̀ mọ́ Mósè ìránṣẹ́ Ọlọ́run, Mósè tó jẹ́ pé òun ni ọlọ́kàn tútù jù lọ láyé. (Númérì 12:3; 16:1-3, 32, 33) Kéènì, Báláámù àti Kórà kàgbákò. Ẹ yáa jẹ́ ká fi tiwọn ṣàríkọ́gbọ́n o, ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn tí Jèhófà gbé ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́, ká sì máa bọlá fún wọn!
13. Àwọn ìbùkún wo ni wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò dé bá àwọn tó bá ń tẹrí ba fún ètò níní alàgbà nínú ìjọ?
13 Ta ni kò ní fẹ́ jàǹfààní nínú ètò àbójútó tó pinmirin tí Aṣáájú wa ti ṣe fún ìjọ Kristẹni? Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìbùkún tó ń jẹ yọ látinú ètò gbígbámúṣé yìí. Ó ní: “Wò ó! Ọba kan yóò jẹ fún òdodo; àti ní ti àwọn ọmọ aládé, wọn yóò ṣàkóso bí ọmọ aládé fún ìdájọ́ òdodo. Olúkúlùkù yóò sì wá dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.” (Aísáyà 32:1, 2) Alàgbà kọ̀ọ̀kan ni yóò jẹ́ irú “ibi” ààbò àti àìléwu bẹ́ẹ̀. Kódà bí àtitẹríba fún àwọn tó wà nípò àṣẹ bá tilẹ̀ nira fún wa, ẹ jẹ́ ká máa gbìyànjú tàdúrà-tàdúrà láti ṣègbọràn, ká sì máa tẹrí ba fún ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run ṣètò nínú ìjọ.
Bí Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Tẹrí Ba fún Kristi Aṣáájú Wa
14, 15. Báwo làwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ ṣe ń fi hàn pé àwọn ń tẹrí ba fún Kristi gẹ́gẹ́ bí Aṣáájú?
14 Gbogbo Kristẹni—àgàgà àwọn alàgbà—ló yẹ kó máa tẹ̀ lé Kristi Aṣáájú wa. A ti fún àwọn alábòójútó, ìyẹn àwọn alàgbà, ní àwọn ọlá àṣẹ kan nínú ìjọ. Àmọ́ wọn kì í fẹ́ láti fi ara wọn jẹ ‘ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn’ nípa jíjẹ gàba lé wọn lórí. (2 Kọ́ríńtì 1:24) Àwọn alàgbà máa ń rántí ọ̀rọ̀ Jésù, pé: “Ẹ mọ̀ pé àwọn olùṣàkóso orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn ènìyàn ńlá a sì máa lo ọlá àṣẹ lórí wọn. Báyìí kọ́ ni láàárín yín.” (Mátíù 20:25-27) Bí àwọn alàgbà ṣe ń ṣe ojúṣe wọn, wọ́n ń sapá tọkàntọkàn láti máa ṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíràn.
15 A rọ àwọn Kristẹni pé: “Ẹ máa rántí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, . . . bí ẹ sì ti ń fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò bí ìwà wọ́n ti rí, ẹ máa fara wé ìgbàgbọ́ wọn.” (Hébérù 13:7) Kì í ṣe pé àwọn alàgbà jẹ́ aṣáájú la fi sọ pé káwọn Kristẹni máa fara wé wọn. Jésù sọ pé: “Ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi.” (Mátíù 23:10) Ìgbàgbọ́ àwọn alàgbà la ní kí wọ́n máa fara wé nítorí pé wọ́n jẹ́ aláfarawé Kristi, tí í ṣe Aṣáájú wa gan-an. (1 Kọ́ríńtì 11:1) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ọ̀nà kan tí àwọn alàgbà lè gbà sapá láti fìwà jọ Kristi nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ.
16. Láìka ọlá àṣẹ tí Jésù ní sí, ọwọ́ wo ló fi mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kì í ṣẹgbẹ́ ẹ̀dá ènìyàn aláìpé rárá, Baba rẹ̀ sì tún fún un ní ọlá àṣẹ tí kò lẹ́gbẹ́, síbẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ ló fi bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lò. Kò fi ìmọ̀ tó ní yangàn lójú àwọn olùgbọ́ rẹ̀. Jésù lójú àánú, ó fi ìyọ́nú hàn sáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó mọ ohun tí ara wọn ń fẹ́. (Mátíù 15:32; 26:40, 41; Máàkù 6:31) Kò ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ṣe kọjá agbára wọn, kò sì dẹrù pa wọ́n rí. (Jòhánù 16:12) “Onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà” ni Jésù. Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi rí ìtura lọ́dọ̀ rẹ̀.—Mátíù 11:28-30.
17. Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn alàgbà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ bíi ti Kristi nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ?
17 Bí Kristi Aṣáájú wa bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ẹ ò rí i pé ó yẹ kí àwọn tí ń mú ipò iwájú nínú ìjọ jẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú! Wọ́n máa ń yẹra fún jíjẹ́ kí agbára tá a fún wọn máa gùn wọ́n gàlègàlè. Wọn kì í sì í “wá pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àsọrégèé,” kí àwọn èèyàn lè máa kan sáárá sí wọn. (1 Kọ́ríńtì 2:1, 2) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń sapá láti fi tọkàntọkàn sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó máa tètè yéni. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn alàgbà kì í retí kí àwọn èèyàn ṣe kọjá agbára wọn, wọ́n sì mọ ibi tí bàtà ti ń ta àwọn èèyàn lẹ́sẹ̀. (Fílípì 4:5) Níwọ̀n bí wọ́n ti mọ̀ pé kálukú ló ní àléébù tirẹ̀, wọ́n máa ń fi tìfẹ́tìfẹ́ fi èyí sọ́kàn nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ará. (1 Pétérù 4:8) Ǹjẹ́ àwọn alàgbà tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti onínú tútù kì í tuni lára? Wọ́n ń tuni lára mọ̀nà.
18. Ẹ̀kọ́ wo làwọn alàgbà lè rí kọ́ nínú ọwọ́ tí Jésù fi mú àwọn ọmọdé?
18 Jésù jẹ́ adùn-únbárìn, ó sì ń kó gbogbo èèyàn mọ́ra, títí kan àwọn ẹni rírẹlẹ̀. Ronú nípa èsì rẹ̀ nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn èèyàn wí nítorí pé wọ́n ń “mú àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ rẹ̀.” Jésù sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun.” Ó wá “gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn.” (Máàkù 10:13-16) Jésù máa ń yá mọ́ni. Ó jẹ́ onínúure. Adùn-únbárìn sì ni. Jésù kì í ṣe àkòtagìrì. Àwọn ọmọdé pàápàá ń túra ká níbi tó bá wà. Àwọn alàgbà pẹ̀lú ń kóni mọ́ra. Ìfẹ́ àtọkànwá àti inú rere tí wọ́n sì ń fi hàn, ń mú kí àwọn èèyàn—títí kan àwọn ọmọdé pàápàá—túra ká níbi tí wọ́n bá wà.
19. Kí ni níní “èrò inú Kristi” wé mọ́, ìsapá wo ló sì ń béèrè?
19 Ibi tí àwọn alàgbà bá mọ Jésù Kristi dé ni wọ́n máa fara wé e dé. Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Ta ni ó ti wá mọ èrò inú Jèhófà, kí ó lè fún un ní ìtọ́ni?” Ó wá fi kún un pé: “Ṣùgbọ́n àwa ní èrò inú ti Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 2:16) Níní èrò inú Kristi wé mọ́ mímọ bó ṣe ń ronú àti àkópọ̀ ànímọ́ rẹ̀, ká lè mọ irú ìgbésẹ̀ tó lè gbé nínú ipò kan tó bá dìde. Ẹ wo bí ì bá ti dára tó ká ní a lè mọ Aṣáájú wa dunjú-dunjú bí èyí! Dájúdájú, èyí ń béèrè fífarabalẹ̀ ka àwọn ìwé Ìhìn Rere, ká sì máa fi ẹ̀kọ́ nípa ìgbésí ayé àti àpẹẹrẹ Jésù kún ọkàn wa. Bí àwọn alàgbà bá làkàkà láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi Aṣáájú wa títí dé àyè yẹn, àwọn ará nínú ìjọ á túbọ̀ gbìyànjú láti fara wé ìgbàgbọ́ wọn. Inú àwọn alàgbà á sì dùn pé àwọn ẹlòmíràn ń fi tayọ̀tayọ̀ tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Aṣáájú wa.
Máa Tẹ̀ Lé Kristi Aṣáájú Wa Nìṣó
20, 21. Bá a ṣe ń wọ̀nà fún ayé tuntun tá a ṣèlérí, kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
20 Ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa máa tẹrí ba fún Kristi Aṣáájú wa. Bá a ṣe ń sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan yìí, ọ̀ràn wa dà bíi ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n wà ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lọ́dún 1473 ṣááju Sànmánì Tiwa. Wọ́n ti dé bèbè Ilẹ̀ Ìlérí náà, Ọlọ́run sì gbẹnu Mósè wòlíì kéde fún wọn pé: “Ìwọ [Jóṣúà] ni yóò mú àwọn ènìyàn yìí wọ ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá wọn láti fi fún wọn.” (Diutarónómì 31:7, 8) Jóṣúà ni aṣáájú tí Ọlọ́run yàn. Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fẹ́ wọ Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n ní láti máa tẹ̀ lé Jóṣúà aṣáájú wọn.
21 Ohun tí Bíbélì sọ fún wa ni pé: “Ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi.” Kristi nìkan ló lè mú wa dé ayé tuntun tá a ṣèlérí, nínú èyí tí òdodo yóò máa gbé. (2 Pétérù 3:13) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu láti máa tẹrí ba fún Aṣáájú wa ní gbogbo ọ̀nà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Ìràwọ̀” wọ̀nyí kì í ṣe àwọn áńgẹ́lì ní ti gidi. Ó dájú pé ẹ̀dá ènìyàn kọ́ ni Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ní kí ó kọ ìsọfúnni ránṣẹ́ sí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò ṣeé fojú rí. Fún ìdí yìí, àwọn “ìràwọ̀” náà dúró fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n jẹ́ alábòójútó, ìyẹn àwọn alàgbà nínú ìjọ, tí wọ́n jẹ́ ońṣẹ́ Jésù. Méje tí wọ́n jẹ́ túmọ̀ sí pípé pérépéré ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo ni Kristi ṣe darí ìjọ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀?
• Báwo ni Kristi ṣe ń darí ìjọ rẹ̀ lónìí?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tẹrí ba fáwọn tí ń mú ipò iwájú nínú ìjọ?
• Àwọn ọ̀nà wo làwọn alàgbà lè gbà fi hàn pé Kristi ni Aṣáájú wọn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Kristi ló ń darí ìjọ rẹ̀, àwọn alábòójútó sì ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
“Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jésù ń yá mọ́ni, ó sì ń kóni mọ́ra. Àwọn Kristẹni alàgbà ń sapá láti dà bíi rẹ̀