ORÍ 18
Ọgbọ́n Wà Nínú “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”
1, 2. Lẹ́tà wo ni Jèhófà kọ sí wa, kí sì nìdí tó fi kọ ọ́?
ṢÉ O ti gba lẹ́tà rí látọ̀dọ̀ èèyàn ẹ kan tó ń gbé níbi tó jìnnà gan-an sí ẹ? Tá a bá gba lẹ́tà ayọ̀ látọ̀dọ̀ ẹnì kan tá a fẹ́ràn, inú wa máa ń dùn gan-an. A máa ń fẹ́ mọ̀ bóyá àlàáfíà ló wà, ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí i, àtàwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe. Tá a bá ń gbúròó àwọn èèyàn wa dáadáa, èyí á jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ra bá a tiẹ̀ ń gbé níbi tó jìn síra.
2 Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ tí Ọlọ́run bá kọ lẹ́tà sí ẹ? Ó dájú pé ìyẹn á múnú ẹ dùn ju lẹ́tà tó o gbà látọ̀dọ̀ èèyàn ẹ kan lọ. Jèhófà ti fún wa ní ohun kan tó dà bíi lẹ́tà, ìyẹn Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lára nǹkan tó wà nínú lẹ́tà yẹn ní irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, àwọn nǹkan tó ti ṣe, àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe àti ọ̀pọ̀ nǹkan míì. Jèhófà fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ torí pé ó fẹ́ ká sún mọ́ òun. Torí pé Jèhófà ni orísun ọgbọ́n, ọ̀nà tó dáa jù lọ ló ń gbà bá wa sọ̀rọ̀. Àwọn nǹkan tó wà nínú Bíbélì àti bí wọ́n ṣe kọ ọ́ jẹ́ ká rí i pé ọgbọ́n Jèhófà kò láfiwé.
Kí Nìdí Tí Jèhófà Fi Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Wà Lákọsílẹ̀?
3. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fún Mósè ní Òfin?
3 Àwọn kan lè béèrè pé kí nìdí tí Jèhófà ò ṣe lo ọ̀nà ìyanu láti máa bá àwa èèyàn sọ̀rọ̀, bíi pé ká máa gbọ́ ohùn ẹ̀? Àwọn ìgbà kan wà tí Jèhófà gbẹnu àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀rọ̀ látọ̀run. Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tó fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní Òfin. (Gálátíà 3:19) Nígbà tí wọ́n gbọ́ ohùn kan tó sọ̀rọ̀ látọ̀run, ẹ̀rù bà wọ́n débi pé wọ́n ní kí Jèhófà má ṣe bá àwọn sọ̀rọ̀ ní tààràtà mọ́, pé kó máa rán Mósè sáwọn. (Ẹ́kísódù 20:18-20) Ìyẹn ló mú kí Jèhófà sọ àwọn Òfin tó jẹ́ nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) fún Mósè lọ́kọ̀ọ̀kan, Mósè sì kọ ọ́ sílẹ̀.
4. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ ká ní Mósè ò kọ òfin Ọlọ́run sílẹ̀?
4 Àmọ́ kí ló máa ṣẹlẹ̀ ká ní Mósè ò kọ Òfin yẹn sílẹ̀? Ṣé ó máa lè rántí gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yẹn kó sì sọ ọ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bó ṣe gbọ́ ọ gẹ́lẹ́? Báwo làwọn èèyàn náà á ṣe rántí gbogbo ohun tí Mósè sọ fún wọn gẹ́lẹ́, kí wọ́n sì sọ ọ́ fún àwọn ọmọ wọn àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn? Ká sòótọ́, ìyẹn kì í ṣe ọ̀nà tó dáa láti gbà fún àwọn èèyàn ní òfin Ọlọ́run, torí kò ní péye. Bí àpẹẹrẹ, kí ló máa ṣẹlẹ̀ ká sọ pé o fẹ́ sọ ìtàn kan fún àwọn èèyàn tó wà lórí ìlà, tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn á sì máa tún ìtàn náà sọ fún ẹni tó kàn títí táá fi dé ọ̀dọ̀ ẹni tó kẹ́yìn lórí ìlà náà? Ó dájú pé ohun ti ẹni tó kẹ́yìn máa gbọ́ á ti yàtọ̀ gan-an sí ohun tó o sọ fún ẹni àkọ́kọ́. Àmọ́ èyí ò lè ṣẹlẹ̀ sí Òfin Ọlọ́run láé.
5, 6. Kí ni Jèhófà sọ pé kí Mósè ṣe sí ọ̀rọ̀ òun, kí sì nìdí tó fi jẹ́ pé oore ńláǹlà ni Jèhófà ṣe wá bó ṣe jẹ́ kí wọ́n kọ Ọ̀rọ̀ òun sílẹ̀?
5 Ó bọ́gbọ́n mu gan-an bí Jèhófà ṣe ní ká kọ ọ̀rọ̀ òun sílẹ̀. Ó sọ fún Mósè pé: “Kọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀, torí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni èmi yóò fi bá ìwọ àti Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú.” (Ẹ́kísódù 34:27) Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ Bíbélì lọ́dún 1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni nìyẹn. Fún ẹgbẹ̀jọ ó lé mẹ́wàá (1,610) ọdún tó tẹ̀ lé e, nǹkan bí ogójì (40) ọkùnrin ni Jèhófà ‘bá sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà àti lọ́pọ̀ ọ̀nà,’ tí wọ́n sì kọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀. (Hébérù 1:1) Ní àkókò yẹn, àwọn adàwékọ ṣiṣẹ́ kára gan-an láti ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́ kó má bàa pa run.—Ẹ́sírà 7:6; Sáàmù 45:1.
6 Oore ńláǹlà ni Jèhófà ṣe wá bó ṣe jẹ́ kí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀. Ṣé o ti gba lẹ́tà kan rí tó o fẹ́ràn púpọ̀ torí pé ó tù ẹ́ nínú gan-an, débi pé ńṣe lo tọ́jú ẹ̀ kó o lè máa kà á nígbàkigbà tó bá wù ẹ́? Ńṣe ni Bíbélì dà bí irú lẹ́tà bẹ́ẹ̀. Torí pé Jèhófà jẹ́ kí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ òun sílẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wa láti máa kà á déédéé, ká sì máa ronú lórí ohun tá a kà. (Sáàmù 1:2) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á máa rí “ìtùnú látinú Ì wé Mímọ́” nígbàkigbà tá a bá nílò rẹ̀.—Róòmù 15:4.
Kí Nìdí Tó Fi Lo Èèyàn Láti Kọ Bíbélì?
7. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu bí Jèhófà ṣe lo àwọn èèyàn láti kọ Bíbélì?
7 Jèhófà fi ọgbọ́n rẹ̀ hàn bó ṣe lo àwọn èèyàn láti kọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀. Rò ó wò ná: Ṣé o rò pé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì máa wọ̀ wá lọ́kàn dáadáa ká sọ pé àwọn áńgẹ́lì ni Jèhófà lò láti kọ ọ́? Lóòótọ́, ká ní àwọn áńgẹ́lì ló kọ ọ́, wọ́n á ṣàlàyé irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ lọ́nà àgbàyanu ju àwa èèyàn lọ, àwọn fúnra wọn á sọ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sin Ọlọ́run, wọ́n á sì tún sọ ìtàn àwọn èèyàn tó jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́ ohun tí wọ́n bá sọ lè má yé wa torí pé ẹ̀dá ẹ̀mí ni wọ́n, ìmọ̀ àti òye wọn ju tiwa lọ, wọ́n sì tún lágbára gan-an jù wá lọ.—Hébérù 2:6, 7.
8. Kí ni Jèhófà gba àwọn tó kọ Bíbélì láyè láti ṣe? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
8 Bí Jèhófà ṣe lo àwọn èèyàn láti kọ Bíbélì, mú kó fún wa ní ohun tá a nílò gẹ́lẹ́, ìyẹn àkọsílẹ̀ kan tí “Ọlọ́run mí sí” síbẹ̀ tí ohun tó wà nínú ẹ̀ bá bí nǹkan ṣe ń rí lára àwa èèyàn mu. (2 Tímótì 3:16) Báwo ló ṣe ṣe é? Ẹ̀rí fi hàn pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà jẹ́ kí àwọn tó kọ Bíbélì ronú fúnra wọn kí wọ́n lè lo “àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára,” kí wọ́n sì lè “ṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó péye tó sì jẹ́ òtítọ́.” (Oníwàásù 12:10, 11) Ohun tójú ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ti rí, bí nǹkan ṣe rí lára wọn àti bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà hàn nínú ohun tí wọ́n kọ tàbí ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ ọ́. Torí náà, ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ ìwé Bíbélì kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra.a Síbẹ̀, ńṣe làwọn tó kọ Bíbélì “sọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí wọn.” (2 Pétérù 1:21) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi jẹ́ “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ní tòótọ́.—1 Tẹsalóníkà 2:13.
“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí”
9, 10. Kí nìdí tó fi dáa gan-an pé àwọn èèyàn ni Ọlọ́run lò láti kọ Bíbélì?
9 Bí Ọlọ́run ṣe lo àwọn èèyàn láti kọ Bíbélì mú kó wọni lọ́kàn kó sì fani mọ́ra gidigidi. Ẹlẹ́ran ara bíi tiwa làwọn tó kọ ọ́. Torí pé wọ́n jẹ́ aláìpé, oríṣiríṣi ìṣòro àti àdánwò làwọn náà dojú kọ. Nígbà míì, Jèhófà mí sí wọn láti ṣàkọsílẹ̀ bí nǹkan ṣe rí lára wọn àtàwọn ìṣòro tó ń bá wọn fínra. (2 Kọ́ríńtì 12:7-10) Torí náà, nígbà tí wọ́n ń sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n sọ ọ́ lọ́nà tá a fi máa lóye bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, tó bá jẹ́ pé àwọn áńgẹ́lì ló kọ ìtàn náà, wọn ò ní lè kọ ọ́ bẹ́ẹ̀.
10 Wo àpẹẹrẹ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn tí Dáfídì dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan tó burú jáì, ó kọ sáàmù kan tó fi sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀, tó sì ń bẹ Ọlọ́run pé kó dárí ji òun. Ó sọ pé: “Wẹ̀ mí mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nítorí mo mọ àwọn àṣìṣe mi dáadáa, ẹ̀ṣẹ̀ mi sì wà níwájú mi nígbà gbogbo. Wò ó! A bí mi ní ẹlẹ́ṣẹ̀, inú ẹ̀ṣẹ̀ sì ni ìyá mi lóyún mi. Má ṣe gbé mi sọ nù kúrò níwájú rẹ; má sì gba ẹ̀mí mímọ́ rẹ kúrò lára mi. Àwọn ẹbọ tó ń mú inú Ọlọ́run dùn ni ọkàn tó gbọgbẹ́; ìwọ Ọlọ́run, o kò ní pa ọkàn tó gbọgbẹ́ tó sì ní ìdààmú tì.” (Sáàmù 51:2, 3, 5, 11, 17) Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ yìí mà wọni lọ́kàn o! A rí i pé ọkàn ẹ̀ gbọgbẹ́ gan-an, inú ìbànújẹ́ ńláǹlà ló sì wà. Kò sí áńgẹ́lì tó lè sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí.
Kí Nìdí Tí Bíbélì Fi Sọ̀rọ̀ Púpọ̀ Nípa Àwọn Èèyàn?
11. Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí ìtàn àwọn èèyàn pọ̀ nínú Bíbélì?
11 Ohun míì tún wà tó mú kí Bíbélì fani mọ́ra. Bíbélì sọ ìtàn ọ̀pọ̀ èèyàn tó gbé ayé lóòótọ́, àwọn kan lára wọn sin Ọlọ́run, àwọn kan lára wọn ò sì sìn ín. A kà nípa àwọn ìṣòro tí wọ́n ní àtàwọn nǹkan tó múnú wọn dùn. A ríbi táwọn ìpinnu tí wọ́n ṣe yọrí sí. Àwọn ìtàn yìí sì wà nínú Bíbélì, ká lè “gba ẹ̀kọ́.” (Róòmù 15:4) Jèhófà lo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn yẹn láti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó máa wọ̀ wá lọ́kàn. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan.
12. Báwo làwọn ìtàn tí Bíbélì sọ nípa àwọn aláìṣòótọ́ èèyàn ṣe ń ràn wá lọ́wọ́?
12 Bíbélì sọ ìtàn àwọn aláìṣòótọ́ àtàwọn èèyàn burúkú, ó sì jẹ́ ká mọ wàhálà tó dé bá wọn. Àwọn ìtàn yìí jẹ́ ká rí irú ìwà tí wọ́n hù àti bó ṣe burú tó. Bí àpẹẹrẹ, ibì kan nínú Bíbélì lè sọ fún wa pé ìwà ọ̀dàlẹ̀ ò dáa. Àmọ́ nígbà tá a ka ìtàn bí Júdásì ṣe da Jésù, ó túbọ̀ yé wa pé ìwà burúkú gbáà ni ìwà ọ̀dàlẹ̀. (Mátíù 26:14-16, 46-50; 27:3-10) Àwọn ìtàn bí èyí máa ń wọ̀ wá lọ́kàn gan-an, ó sì máa ń jẹ́ ká mọ àwọn ìwà àti ìṣe tí kò dáa tó yẹ ká máa sá fún.
13. Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ní àwọn ìwà àti ìṣe tó fani mọ́ra?
13 Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. A kà nípa bí wọ́n ṣe sin Ọlọ́run tọkàntọkàn tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́. A rí àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tó láwọn ìwà àti ìṣe tó yẹ ká ní ká lè sún mọ́ Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ kan ni ìgbàgbọ́. Bíbélì sọ ohun tí ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé ká ní ìgbàgbọ́ ká tó lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Hébérù 11:1, 6) Ṣùgbọ́n a tún rí àpẹẹrẹ àwọn kan nínú Bíbélì tí wọ́n ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́. Ronú nípa bí Ábúráhámù ṣe fi hàn pé òun nígbàgbọ́ nígbà tó gbìyànjú láti fi Ísákì rúbọ. (Jẹ́nẹ́sísì orí 22; Hébérù 11:17-19) Irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ ká túbọ̀ mọ ohun tí ọ̀rọ̀ náà, “ìgbàgbọ́” túmọ̀ sí. Torí náà, Jèhófà ò kàn sọ fún wa pé ká ní àwọn ìwà àti ìṣe tó dáa, ó tún fún wa láwọn àpẹẹrẹ tó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí jẹ́ ká rí i pé ọgbọ́n Jèhófà ò láfiwé!
14, 15. Kí ni Bíbélì sọ nípa obìnrin kan tó wá sí tẹ́ńpìlì, kí sì ni ìtàn yìí kọ́ wa nípa Jèhófà?
14 Ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn nínú Bíbélì sábà máa ń kọ́ wa ní nǹkan kan nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ obìnrin kan tí Jésù kíyè sí nínú tẹ́ńpìlì. Bí Jésù ṣe jókòó sí tòsí àpótí ìṣúra, ó ń wo bí àwọn èèyàn ṣe ń fi ọrẹ wọn síbẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ wá síbẹ̀, wọ́n sọ owó sínú rẹ̀ “látinú àjẹṣẹ́kù wọn.” Ṣùgbọ́n Jésù kíyè sí opó aláìní kan dáadáa. “Ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré gan-an” ni obìnrin náà fi sínú rẹ̀.b Gbogbo ohun tó ní nìyẹn. Jésù jẹ́ ká mọ irú ojú tí Jèhófà fi wo ohun tí obìnrin yìí ṣe, ó sọ pé: “Ohun tí opó aláìní yìí fi sílẹ̀ ju ti gbogbo àwọn yòókù tó fi owó sínú àwọn àpótí ìṣúra.” Ohun tí Jésù sọ yìí fi hàn pé lójú Jèhófà, owó tí obìnrin náà fi sínú àpótí ìṣúra náà ju àpapọ̀ gbogbo owó táwọn tó kù fi síbẹ̀ lọ.—Máàkù 12:41-44; Lúùkù 21:1-4; Jòhánù 8:28.
15 Ó wúni lórí gan-an pé Jésù fara balẹ̀ kíyè sí opó yẹn nínú gbogbo àwọn èèyàn tó wá sí tẹ́ńpìlì lọ́jọ́ náà, Jèhófà sì jẹ́ kí wọ́n kọ ohun tí opó náà ṣe sínú Bíbélì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tá à ń ṣe, ó sì mọyì ẹ̀. Inú ẹ̀ máa ń dùn tí ẹ̀bùn tá a fún un bá tọkàn wa wá, kódà tó bá tiẹ̀ kéré sí tàwọn ẹlòmíì, ó máa ń mọyì ẹ̀ gan-an. Ó dájú pé bí Jèhófà ṣe jẹ́ ká mọ òtítọ́ pàtàkì yìí fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó sì múnú wa dùn gan-an!
Ohun Tí Bíbélì Ò Sọ
16, 17. Báwo ni àwọn ohun tí Jèhófà ò kọ sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pàápàá ṣe jẹ́ ká rí i pé ọlọ́gbọ́n ni?
16 Tó o bá ń kọ lẹ́tà sí ọ̀rẹ́ ẹ kan, kì í ṣe gbogbo nǹkan lo máa lè kọ tán sínú lẹ́tà náà, ńṣe lo máa fọgbọ́n pinnu ohun tó o máa kọ. Ohun tí Jèhófà ṣe náà nìyẹn, àwọn èèyàn kan àtàwọn ohun kan tó ṣẹlẹ̀ ló jẹ́ kí wọ́n kọ nípa wọn sínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Bíbélì máa ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ìtàn yìí. (Jòhánù 21:25) Bí àpẹẹrẹ, tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìdájọ́ Ọlọ́run, ohun tó sọ lè má dáhùn gbogbo ìbéèrè wa. Àwọn ohun tí Jèhófà ò kọ sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí pàápàá jẹ́ ká rí i pé ọlọ́gbọ́n ni. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
17 Ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ Bíbélì máa ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. Hébérù 4:12 sọ pé: “Ọ̀rọ̀ [tàbí, ìsọfúnni] Ọlọ́run wà láàyè, ó sì ní agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni, àní débi pé ó ń pín ọkàn àti ẹ̀mí níyà . . . ó sì lè mọ ìrònú àti ohun tí ọkàn ń gbèrò.” Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì máa ń wọni lọ́kàn, ó sì máa ń jẹ́ ká mọ ohun tá à ń rò àti ìdí tá a fi ń ṣe ohun tá à ń ṣe. Inú máa ń bí àwọn tó máa ń wá àṣìṣe nínú Bíbélì tí wọ́n bá rí i pé àwọn ìtàn kan ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ tó bí wọ́n ṣe fẹ́. Àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè máa jiyàn pé bóyá ni Jèhófà jẹ́ onífẹ̀ẹ́, ọlọ́gbọ́n àti onídàájọ́ òdodo.
18, 19. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká dààmú tí ìtàn Bíbélì kan bá rú wa lójú tá ò sì rí ojútùú rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? (b) Kí ló gbà ká tó lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, báwo lèyí sì ṣe jẹ́ ẹ̀rí ọgbọ́n ńlá Jèhófà?
18 Àmọ́ tá a bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì ṣe bẹ́ẹ̀ tọkàntọkàn, àá mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ látinú ohun tí Bíbélì lódindi sọ nípa ẹ̀. Ìyẹn ni kò ní jẹ́ kí inú bí wa tí ìtàn kan ò bá yé wa tá ò sì rí ojútùú ẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì torí pé a fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ a máa mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an. Ká tiẹ̀ wá ní ìtàn kan kọ́kọ́ rú wa lójú, tàbí pé a ò rí bí ìtàn náà ṣe bá ànímọ́ Ọlọ́run mu, àwọn ohun tá a ti kọ́ látinú Bíbélì nípa Jèhófà máa jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, àti pé ohun tó tọ́ ló máa ń ṣe ní ìgbà gbogbo.
19 Torí náà, ká tó lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ní láti ni ọkàn tó dáa, ká fara balẹ̀ kà á, ká sì kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ tọkàntọkàn. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n lè kọ̀wé tó jẹ́ pé kìkì “àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye” ló máa yé. Àmọ́ ní ti Bíbélì, àwọn tó ní ọkàn tó dáa nìkan ló lè yé, èyí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà jẹ́ ọlọ́gbọ́n!—Mátíù 11:25.
Ìwé “Ọgbọ́n Tó Gbéṣẹ́”
20. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan ló lè sọ ọ̀nà tó dáa jù lọ láti gbé ìgbésí ayé wa, kí ló sì wà nínú Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́?
20 Nínú Bíbélì, Jèhófà jẹ́ ká mọ ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà gbé ìgbésí ayé wa. Òun ni Ẹlẹ́dàá wa, ó mọ ohun tá a nílò jù wá lọ. Ó máa ń wu àwa èèyàn ká ní ẹni tó máa nífẹ̀ẹ́ wa, ká máa láyọ̀, ká sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì. Bó ṣe rí nìyẹn nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, bó sì ṣe rí títí dòní nìyẹn. Inú Bíbélì la ti lè rí “ọgbọ́n tó gbéṣẹ́” tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé tó dáa. (Òwe 2:7) Apá kọ̀ọ̀kan ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ò ń kà yìí ló ní orí tá a ti ṣàlàyé béèyàn ṣe lè fi ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì sílò. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan.
21-23. Ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa dárí ji àwọn èèyàn, ká má sì máa dì wọ́n sínú?
21 Ṣé o ti kíyè sí i pé, àwọn èèyàn tí kì í dárí jini tí wọ́n sì máa ń bínú jù kì í fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀? Téèyàn bá ń bínú jù, ó máa ń jẹ́ káyé súni. Bákan náà, tá ò bá máa dárí ji àwọn èèyàn, ọkàn wa ò ní balẹ̀, a ò sì ní láyọ̀ mọ́. Kódà, ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe fi hàn pé téèyàn bá ń bínú jù tí kì í sì í dárí jini, ó lè fa àrùn ọkàn àti àìmọye àìsàn burúkú míì. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó ṣe ìwádìí yìí ni Bíbélì ti sọ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n yìí pé: “Fi ìbínú sílẹ̀, kí o sì pa ìrunú tì.” (Sáàmù 37:8) Àmọ́ báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
22 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa ní ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n yìí pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí èèyàn ní ló máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀, ẹwà ló sì jẹ́ fún un pé kó gbójú fo àṣìṣe.” (Òwe 19:11) Tẹ́nì kan bá ní ìjìnlẹ̀ òye, kì í ṣe ohun táwọn èèyàn bá sọ tàbí tí wọ́n ṣe nìkan láá máa rí. Kàkà bẹ́ẹ̀ á máa ronú nípa ìdí tí wọ́n fi sọ ọ̀rọ̀ kan tàbí hùwà lọ́nà kan. Tá a bá gbìyànjú láti lóye ìdí tẹ́nì kan fi ṣe ohun kan, bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ àtàwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó máa ṣẹlẹ̀ sí i, a ò ní dá a lẹ́bi, a ò sì ní bínú sí i mọ́.
23 Ìmọ̀ràn míì tún wà nínú Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ máa fara dà á fún ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà.” (Kólósè 3:13) Gbólóhùn náà, “ẹ máa fara dà á fún ara yín” ń sọ fún wa pé ká máa ní sùúrù fáwọn èèyàn, ká sì máa fara dà á tí wọ́n bá ṣe ohun tó bí wa nínú. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní máa di àwọn èèyàn sínú torí ọ̀rọ̀ tí ò tó nǹkan. Ọ̀rọ̀ náà ‘dárí jì,’ túmọ̀ sí pé tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá, ká dìídì gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. Ọlọ́run wa tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n mọ̀ pé ó yẹ ká máa dárí ji àwọn ẹlòmíì nígbà tó bá yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Kì í ṣe fún àǹfààní tiwọn nìkan, ó tún máa jẹ́ kí ọkàn tiwa náà balẹ̀. (Lúùkù 17:3, 4) Ọgbọ́n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mà jinlẹ̀ o!
24. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run sílò?
24 Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ò lẹ́gbẹ́, ìdí nìyẹn tó fi ń wù ú pé kó bá wa sọ̀rọ̀. Ó sì yan ọ̀nà tó dáa jù lọ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó lo àwọn èèyàn láti kọ lẹ́tà kan, ó sì fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí wọn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ọgbọ́n Jèhófà gan-an ló wà nínú ìwé náà látòkè délẹ̀. Ọgbọ́n yìí sì “ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá.” (Sáàmù 93:5) Tá a bá ń fi ọgbọ́n Jèhófà sílò, tá a sì ń sọ ọ́ fáwọn èèyàn, ó máa jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run wa tó jẹ́ ọba ọgbọ́n. Ní orí tó kàn, a máa sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà míì tí Jèhófà ń gbà lo ọgbọ́n rẹ̀ tí kò láfiwé: ìyẹn bó ṣe ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú àti bó ṣe ń mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.
a Bí àpẹẹrẹ, torí pé olùṣọ́ àgùntàn ni Dáfídì, ó lo àpẹẹrẹ àwọn nǹkan tó rí nígbà tó ń tọ́jú àwọn àgùntàn. (Sáàmù 23) Mátíù tó jẹ́ agbowó orí mẹ́nu kan nọ́ńbà àti iye owó lọ́pọ̀ ìgbà. (Mátíù 17:27; 26:15; 27:3) Lúùkù tó jẹ́ oníṣègùn lo àwọn ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ẹni tó mọ̀ nípa ìṣègùn ni.—Lúùkù 4:38; 14:2; 16:20.
b Ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹyọ owó yìí jẹ́ lẹ́pítónì, òun sì ni ẹyọ owó tó kéré jù lọ táwọn Júù ń ná nígbà yẹn. Tí a bá pín owó iṣẹ́ ọjọ́ kan sí ọ̀nà mẹ́rìnlélọ́gọ́ta (64), ìdá kan nínú rẹ̀ jẹ́ lẹ́pítónì méjì. Ẹyọ owó méjì yìí kò tiẹ̀ tó ra ẹyẹ ológoṣẹ́ kan ṣoṣo, ẹyẹ yìí sì ni owó rẹ̀ kéré jù lọ tágbára àwọn aláìní ká láti rà.