ORÍ 19
“Ọgbọ́n Ọlọ́run Nínú Àṣírí Mímọ́” Kan
1, 2. “Àṣírí mímọ́” wo ló yẹ kó wù wá láti mọ̀, kí sì nìdí?
ÀṢÍRÍ! Lọ́pọ̀ ìgbà, tí wọ́n bá sọ pé káwọn èèyàn ṣe ọ̀rọ̀ kan láṣìírí, ó sábà máa ń ṣòro fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ pé: “Ògo Ọlọ́run ni láti pa ọ̀rọ̀ mọ́ ní àṣírí.” (Òwe 25:2) Òótọ́ sì ni, Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó fẹ́ ká mọ̀ àti ohun tí kò fẹ́ ká mọ̀. Òun náà ló sì tún mọ ìgbà tó tọ́ láti ṣí àṣírí payá. Ó ṣe tán òun ló dá wa, òun sì ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run.
2 Àṣírí tó ń múnú ẹni dùn kan wà tí Jèhófà ṣí payá nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àṣírí yìí ni Bíbélì pè ní “àṣírí mímọ́ nípa ìfẹ́ [Ọlọ́run].” (Éfésù 1:9) Ó dájú pé inú ẹ máa dùn gan-an láti mọ àṣírí náà. Àmọ́ kò mọ síbẹ̀, tó o bá mọ̀ ọ́n, ó máa jẹ́ kó o rí ìgbàlà, wàá sì túbọ̀ lóye bí ọgbọ́n Jèhófà ṣe pọ̀ tó.
Jèhófà Ṣí Àṣírí Náà Payá Díẹ̀díẹ̀
3, 4. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ṣe mú ká nírètí, kí sì ni “àṣírí mímọ́” tó wà nínú ọ̀rọ̀ náà?
3 Nígbà tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, ṣe ló dà bíi pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ò ní ṣeé ṣe mọ́. Ẹ rántí pé Jèhófà fẹ́ kí ayé yìí di Párádísè káwọn èèyàn tó pé sì máa gbébẹ̀ títí láé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ mú kó dà bíi pé kò ní ṣeé ṣe, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Ọlọ́run bójú tó ìṣòro náà. Ó ní: “Màá mú kí ìwọ àti obìnrin náà di ọ̀tá ara yín, ọmọ rẹ àti ọmọ rẹ̀ yóò sì di ọ̀tá. Òun yóò fọ́ orí rẹ, ìwọ yóò sì ṣe é léṣe ní gìgísẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:15.
4 Ọ̀rọ̀ yìí ta kókó, ó sì lè mú ká béèrè àwọn ìbéèrè bíi: Ta ni obìnrin yìí? Ta ni ejò náà? Ta ni “ọmọ” obìnrin náà tó máa fọ́ orí ejò yìí? Ádámù àti Éfà ò lè mọ̀ ọ́n. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ yìí máa jẹ́ káwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà tó bá jẹ́ olóòótọ́ nírètí pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ máa ṣẹ. Ó máa jẹ́ kó dá wọn lójú pé ó máa fòpin sí ìwà burúkú, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Àmọ́ ìbéèrè náà ni pé, báwo ló ṣe máa ṣẹ? Àṣírí ńlá mà nìyẹn o! Abájọ tí Bíbélì fi pè é ní “ọgbọ́n Ọlọ́run nínú àṣírí mímọ́, tó jẹ́ ọgbọ́n tí a fi pa mọ́.”—1 Kọ́ríńtì 2:7.
5. Ṣàpèjúwe ìdí tó fi jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ni Jèhófà ń ṣí àṣírí ẹ̀ payá.
5 Jèhófà ni “Ẹni tó ń ṣí àwọn àṣírí payá,” torí náà ó máa jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lóye àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àṣírí yìí. (Dáníẹ́lì 2:28) Àmọ́, díẹ̀díẹ̀ ló máa ṣe é ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ bàbá kan àti ọmọkùnrin ẹ̀ ṣàpèjúwe ohun tá à ń sọ. Ká sọ pé ọmọ náà bi bàbá ẹ̀ pé, “Dádì mi, báwo ni mo ṣe dáyé?” Ó dájú pé bàbá tó gbọ́n ò kàn ní tú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀ sílẹ̀, dípò bẹ́ẹ̀ ìwọ̀nba àlàyé tó lè yé ọmọ yẹn ló máa ṣe fún un. Bí ọmọ náà sì ṣe ń dàgbà sí i bẹ́ẹ̀ ni bàbá ẹ̀ á máa ṣàlàyé síwájú sí i. Lọ́nà kan náà, Jèhófà ló máa pinnu ìgbà tó dáa jù láti jẹ́ káwọn èèyàn ẹ̀ mọ ohun tó fẹ́ ṣe.—Òwe 4:18; Dáníẹ́lì 12:4.
6. (a) Kí nìdí táwọn èèyàn fi máa ń fọwọ́ sí ìwé àdéhùn tàbí bára wọn dá májẹ̀mú? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi bá àwa èèyàn dá májẹ̀mú?
6 Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà mú káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ túbọ̀ lóye àṣírí mímọ́ yìí? Ó lo onírúurú májẹ̀mú tàbí àdéhùn láti jẹ́ ká mọ púpọ̀ nípa àṣírí mímọ́ náà. Ó ṣeé ṣe kó o ti fọwọ́ sí ìwé àdéhùn kan rí, bóyá nígbà tó o fẹ́ ra ilé, tó o fẹ́ yá owó, tàbí nígbà tó o fẹ́ yá ẹnì kan lówó. Àwọn èèyàn máa ń ṣe irú àdéhùn yìí lábẹ́ òfin, ńṣe ló máa ń jẹ́ kó dáni lójú pé àwọn tó fọwọ́ sí ìwé àdéhùn máa mú ìlérí wọn ṣẹ. Àmọ́, ṣó tún nílò kí Jèhófà bá àwa èèyàn dá májẹ̀mú kó lè fi dá wa lójú pé òun máa mú ọ̀rọ̀ òun ṣẹ? Ó ṣe tán, tí Jèhófà bá ṣèlérí pé òun máa ṣe ohun kan, kò sóhun náà láyé yìí tàbí lókè ọ̀run tó lè dí i lọ́wọ́ tàbí tó lè ní kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ má ṣẹ. Àmọ́ Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn, ó sì mọ̀ pé aláìpé ni wá. Torí náà, ó fi àwọn májẹ̀mú tàbí àdéhùn tó ṣe yẹn ti ọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́yìn kó lè túbọ̀ dá wa lójú pé òun máa mú gbogbo ìlérí òun ṣẹ.—Hébérù 6:16-18.
Jèhófà Bá Ábúráhámù Dá Májẹ̀mú
7, 8. (a) Májẹ̀mú wo ni Jèhófà bá Ábúráhámù dá, kí nìyẹn sì jẹ́ ká mọ̀ nípa àṣírí mímọ́ náà? (b) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ ká mọ ìlà ìdílé ti ọmọ náà ti máa wá?
7 Lẹ́yìn ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún tí Jèhófà lé Ádámù àti Éfà kúrò nínú Párádísè, Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ kan fún Ábúráhámù ìránṣẹ́ rẹ̀, ó ní: “Ó . . . dájú pé màá mú kí ọmọ rẹ pọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run . . . Gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé yóò gba ìbùkún fún ara wọn nípasẹ̀ ọmọ rẹ torí pé o fetí sí ohùn mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18) Ọ̀rọ̀ yìí kọjá kéèyàn kàn ṣèlérí lásán; ńṣe ni Jèhófà sọ ọ́ bí ẹni ń tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn, tó sì tún ń búra pé kò sóhun tó lè yẹ̀ ẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 17:1, 2; Hébérù 6:13-15) Ó wúni lórí gan-an pé Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ bá àwa èèyàn dá májẹ̀mú, tó sì tún búra pé òun máa bù kún aráyé!
“Màá mú kí ọmọ rẹ pọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run”
8 Májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ábúráhámù dá jẹ́ ká mọ̀ pé ọmọ tí Jèhófà ṣèlérí máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù. Àmọ́, ta ni ọmọ náà? Nígbà tó yá, Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé nínú gbogbo àwọn ọmọ Ábúráhámù, ọmọ tí Jèhófà ṣèlérí náà máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ísákì. Nínú àwọn ọmọ méjì tí Ísákì bí, ìlà ìdílé Jékọ́bù ni ọmọ tí Jèhófà ṣèlérí náà ti máa wá. (Jẹ́nẹ́sísì 21:12; 28:13, 14) Lẹ́yìn ìyẹn, Jékọ́bù súre fún ọ̀kan nínú àwọn ọmọ méjìlá tó bí pé: “Ọ̀pá àṣẹ kò ní kúrò lọ́dọ̀ Júdà, ọ̀pá aláṣẹ kò sì ní kúrò láàárín ẹsẹ̀ rẹ̀ títí Ṣílò [tàbí “Ẹni Tí Nǹkan Tọ́ Sí,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé] yóò fi dé, òun ni àwọn èèyàn yóò máa ṣègbọràn sí.” (Jẹ́nẹ́sísì 49:10) Ìgbà yìí la wá mọ̀ pé ọba ni ọmọ tí Jèhófà ṣèlérí náà máa jẹ́ àti pé ìlà ìdílé Júdà ló ti máa wá!
Májẹ̀mú Pẹ̀lú Ísírẹ́lì
9, 10. (a) Májẹ̀mú wo ni Jèhófà bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá, báwo ni májẹ̀mú yẹn sì ṣe dà bí ògiri ààbò? (b) Báwo ni Òfin Mósè ṣe fi hàn pé aráyé nílò ìràpadà?
9 Lọ́dún 1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jèhófà ṣe ohun kan tó jẹ́ ká mọ̀ sí i nípa àṣírí mímọ́ náà. Ó bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù dá májẹ̀mú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé májẹ̀mú yẹn, tó jẹ́ Òfin Mósè kò ṣiṣẹ́ mọ́ báyìí, apá pàtàkì ló jẹ́ nínú ètò tí Jèhófà ṣe láti mú ọmọ tó ṣèlérí náà wá. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Wo ọ̀nà mẹ́ta tó gbà rí bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, Òfin Mósè dà bí ògiri ààbò kan. (Éfésù 2:14) Àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ dà bí ògiri tó pààlà sáàárín àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí. Nípa bẹ́ẹ̀, Òfin Mósè ò jẹ́ kí ìlà ìdílé tí ọmọ náà ti máa wá dà rú. Èyí ló jẹ́ kí orílẹ̀-èdè yẹn ṣì wà títí dìgbà tí àkókò tó lójú Ọlọ́run pé ká bí Mèsáyà sí ìlà ìdílé Júdà.
10 Ìkejì, Òfin Mósè jẹ́ kó ṣe kedere pé aráyé nílò ìràpadà. Torí ó jẹ́ Òfin pípé, ó jẹ́ kó hàn gbangba pé àwọn èèyàn ò lè pa á mọ́ délẹ̀délẹ̀. Ńṣe ló “mú kí àwọn àṣìṣe fara hàn kedere, títí ọmọ tí a ṣe ìlérí náà fún á fi dé.” (Gálátíà 3:19) Òfin Mósè sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fi ẹran rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àmọ́ kò lè mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò pátápátá. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́ kò lè mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.” Òjìji ni wọ́n kàn jẹ́ fún ẹbọ ìràpadà Kristi tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Hébérù 10:1-4) Nítorí náà, fún àwọn Júù tó jẹ́ olóòótọ́, májẹ̀mú yẹn jẹ́ “olùtọ́ . . . tó ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi.”—Gálátíà 3:24.
11. Ohun àgbàyanu wo ni májẹ̀mú Òfin mú kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì máa retí, ṣùgbọ́n kí nìdí tí wọ́n fi pàdánù àǹfààní náà?
11 Ìkẹta, májẹ̀mú yẹn mú kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì máa retí ohun àgbàyanu kan. Jèhófà sọ fún wọn pé tí wọ́n bá ń pa májẹ̀mú yẹn mọ́, wọ́n máa di “ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́.” (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Lóòótọ́, inú Ísírẹ́lì nípa ti ara ni àwọn tá a kọ́kọ́ yàn pé ó máa wà nínú ìjọba àwọn àlùfáà ní ọ̀run ti wá. Àmọ́, Ísírẹ́lì lápapọ̀ da májẹ̀mú Òfin yẹn, wọ́n tún kọ Mèsáyà náà, èyí ló mú kí wọ́n pàdánù àǹfààní tó yẹ kí wọ́n ní. Nígbà náà, àwọn wo ni Jèhófà máa yàn láti rọ́pò wọn? Báwo sì ni àwọn tí Jèhófà yàn yìí ṣe máa tan mọ́ Ọmọ tá a ṣèlérí náà? Tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, ó máa jẹ́ ká rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí.
Májẹ̀mú Ìjọba Tí Jèhófà Bá Dáfídì Dá
12. Májẹ̀mú wo ni Jèhófà bá Dáfídì dá, kí ló sì jẹ́ ká mọ̀ nípa àṣírí mímọ́ Ọlọ́run?
12 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkànlá Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ sí i nípa àṣírí mímọ́ yìí nígbà tó bá Dáfídì dá májẹ̀mú ìjọba. Jèhófà ṣèlérí kan fún Ọba Dáfídì tó jẹ́ olóòótọ́. Ó sọ fún un pé: ‘Màá gbé ọmọ rẹ dìde lẹ́yìn rẹ, màá sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀. Màá fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.’ (2 Sámúẹ́lì 7:12, 13; Sáàmù 89:3) Ìlérí yìí jẹ́ ká rí i pé ilé Dáfídì ni ọmọ tá a ṣèlérí náà ti máa wá. Àmọ́, ṣé èèyàn kan wà tó lè ṣàkóso títí láé? (Sáàmù 89:20, 29, 34-36) Ṣé èèyàn kan sì wà tó lè gba àwa èèyàn lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú?
13, 14. (a) Bí Sáàmù 110 ṣe sọ, ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún ẹni tó yàn gẹ́gẹ́ bí Ọba? (b) Àwọn nǹkan míì wo ni àwọn wòlíì Jèhófà sọ nípa ọmọ tá a ṣèlérí náà?
13 Jèhófà mí sí Dáfídì láti kọ̀wé pé: “Jèhófà sọ fún Olúwa mi pé: ‘Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.’ Jèhófà ti búra, kò sì ní pèrò dà, ó ní: ‘Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé ní ọ̀nà ti Melikisédékì!’ ” (Sáàmù 110:1, 4) Ọmọ tá a ṣèlérí náà, tàbí Mèsáyà, ni àsọtẹ́lẹ̀ Dáfídì yìí ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. (Ìṣe 2:35, 36) “Ọwọ́ ọ̀tún” Jèhófà lọ́run ni Ọba yìí á ti máa ṣàkóso, kì í ṣe Jerúsálẹ́mù. Ìyẹn á jẹ́ kí àṣẹ rẹ̀ kárí gbogbo ayé dípò kó mọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì nìkan. (Sáàmù 2:6-8) Ohun míì wà tí ibí yìí tún jẹ́ ká mọ̀. Kíyè sí i pé Jèhófà búra pé Mèsáyà náà máa jẹ́ “àlùfáà . . . ní ọ̀nà ti Melikisédékì.” Bíi ti Melikisédékì, tó jẹ́ ọba àti àlùfáà láyé ìgbà Ábúráhámù ni ọ̀rọ̀ ọmọ tá a ṣèlérí yìí máa rí. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló máa fi jẹ Ọba àti Àlùfáà!—Jẹ́nẹ́sísì 14:17-20.
14 Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, Jèhófà lo àwọn wòlíì rẹ̀ láti jẹ́ ká túbọ̀ mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa àṣírí mímọ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, Àìsáyà jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n máa pa ọmọ yìí kó lè fi ẹ̀mí ẹ̀ ra aráyé pa dà. (Àìsáyà 53:3-12) Míkà sọ àsọtẹ́lẹ̀ ibi tí wọ́n máa bí Mèsáyà sí. (Míkà 5:2) Dáníẹ́lì tiẹ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àkókò pàtó tí ọmọ yẹn máa fara hàn àti ìgbà tó máa kú.—Dáníẹ́lì 9:24-27.
Ọlọ́run Ṣí Àṣírí Mímọ́ Náà Payá!
15, 16. (a) Báwo ni Ọmọ Jèhófà ṣe di “ẹni tí obìnrin bí”? (b) Kí ni Jésù jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí ẹ̀, ìgbà wo ló sì dé gẹ́gẹ́ bí ọmọ tá a ṣèlérí náà?
15 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà jẹ́ àṣírí títí dìgbà tí ọmọ náà máa fara hàn. Gálátíà 4:4 sọ pé: “Nígbà tí àkókò tó, Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀, ẹni tí obìnrin bí.” Lọ́dún 2 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, áńgẹ́lì kan sọ fún wúńdíá Júù kan tó ń jẹ́ Màríà pé: “Wò ó! o máa lóyún, o sì máa bí ọmọkùnrin kan, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù. Ẹni yìí máa jẹ́ ẹni ńlá, wọ́n á máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ, Jèhófà Ọlọ́run sì máa fún un ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀ . . . Ẹ̀mí mímọ́ máa bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ sì máa ṣíji bò ọ́. Ìdí nìyẹn tí a fi máa pe ẹni tí o bí ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.”—Lúùkù 1:31, 32, 35.
16 Nígbà tó yá, Jèhófà fi ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ sínú ilé ọlẹ̀ Màríà lọ́nà ìyanu, tó fi jẹ́ pé ara obìnrin ló ti jáde. Aláìpé ni Màríà. Síbẹ̀, Jésù ò jogún àìpé lára ẹ̀, torí pé “Ọmọ Ọlọ́run” ni. Àmọ́, ohun kan wà tó jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí ẹ̀. Ó lẹ́tọ̀ọ́ láti jogún ìtẹ́ Dáfídì torí pé àtọmọdọ́mọ Dáfídì làwọn òbí ẹ̀. (Ìṣe 13:22, 23) Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án, ó sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́.” (Mátíù 3:16, 17) Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ọmọ tá a ṣèlérí dé! (Gálátíà 3:16) Ó wá tó àkókò báyìí láti tún ṣí àwọn nǹkan míì payá nípa àṣírí mímọ́ náà.—2 Tímótì 1:10.
17. Àwọn nǹkan wo la wá mọ̀ nípa àwọn tí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 sọ̀rọ̀ nípa wọn?
17 Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó fi hàn pé Sátánì ni ejò inú Jẹ́nẹ́sísì 3:15, àti pé àwọn ọmọlẹ́yìn Sátánì ni ọmọ ejò náà. (Mátíù 23:33; Jòhánù 8:44) Nígbà tó yá, Jèhófà jẹ́ ká mọ bóun ṣe máa pa Sátánì àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ run pátápátá. (Ìfihàn 20:1-3, 10, 15) Ó sì tún wá hàn gbangba pé obìnrin náà ni “Jerúsálẹ́mù ti òkè,” ìyẹn apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà tó jẹ́ àpapọ̀ àwọn áńgẹ́lì tó dà bí aya fún Jèhófà.a—Gálátíà 4:26; Ìfihàn 12:1-6.
Májẹ̀mú Tuntun
18. Iṣẹ́ wo ni “májẹ̀mú tuntun” máa ṣe?
18 Ó jọ pé alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù la wá mọ àṣírí tó gbàfiyèsí jù lọ, ìyẹn ìgbà tó sọ̀rọ̀ nípa “májẹ̀mú tuntun” fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ olóòótọ́. (Lúùkù 22:20) Májẹ̀mú tuntun yìí dà bíi májẹ̀mú Òfin Mósè tó ti wà ṣáájú ní ti pé ó máa mú “ìjọba àwọn àlùfáà” jáde wá. (Ẹ́kísódù 19:6; 1 Pétérù 2:9) Ohun kan tó yàtọ̀ ni pé kì í ṣe orílẹ̀-èdè ti ara ni májẹ̀mú yìí máa mú jáde, àmọ́ ó jẹ́ orílẹ̀-èdè tẹ̀mí, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” Àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tó jẹ́ ẹni àmì òróró nìkan ló sì máa wà níbẹ̀. (Gálátíà 6:16) Àwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun yìí máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jésù láti bù kún aráyé!
19. (a) Kí nìdí tí májẹ̀mú tuntun fi lè mú “ìjọba àwọn àlùfáà” jáde? (b) Kí nìdí tá a fi pe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní “ẹ̀dá tuntun,” àwọn mélòó ló máa bá Jésù Kristi ṣàkóso lọ́run?
19 Àmọ́, kí nìdí tí májẹ̀mú tuntun fi lè mú “ìjọba àwọn àlùfáà” tó máa bù kún aráyé jáde? Ìdí ni pé kàkà kí májẹ̀mú yẹn máa dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi lẹ́jọ́ pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ńṣe ló mú kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbà nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù. (Jeremáyà 31:31-34) Bí Jèhófà bá sì ti lè kà wọ́n sí olódodo, ó máa sọ wọ́n dọmọ, wọ́n á di apá kan ìdílé ẹ̀ lọ́run, á sì fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n. (Róòmù 8:15-17; 2 Kọ́ríńtì 1:21) Wọ́n á wá dẹni tó ‘ní ìbí tuntun sí ìrètí tó wà láàyè tí a tọ́jú sí ọ̀run.’ (1 Pétérù 1:3, 4) Nǹkan tuntun ni bí Jèhófà ṣe fún èèyàn láǹfààní láti wá sí ọ̀run, ìdí nìyẹn tá a fi pe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tá a fẹ̀mí bí ní “ẹ̀dá tuntun.” (2 Kọ́ríńtì 5:17) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) èèyàn ló máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jésù Kristi láti ṣàkóso àwọn èèyàn tá a rà pa dà.—Ìfihàn 5:9, 10; 14:1-4.
20. (a) Apá míì wo nínú àṣírí mímọ́ ni Jèhófà ṣí payá lọ́dún 36 Sànmánì Kristẹni? (b) Àwọn wo ló máa gba ìbùkún tí Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù?
20 Àwọn ẹni àmì òróró yìí àti Jésù máa di “ọmọ Ábúráhámù.”b (Gálátíà 3:29) Àwọn Júù la kọ́kọ́ yàn láti jẹ́ ara wọn. Àmọ́, lọ́dún 36 Sànmánì Kristẹni, Jèhófà ṣí apá míì nínú àṣírí mímọ́ yẹn payá, ìyẹn ni pé: Ó yan àwọn Kèfèrí, tàbí àwọn tí kì í ṣe Júù, láti bá Jésù ṣàkóso ní ọ̀run. (Róòmù 9:6-8; 11:25, 26; Éfésù 3:5, 6) Ṣé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nìkan ló máa gba ìbùkún tá a ṣèlérí fún Ábúráhámù yìí ni? Rárá o, torí gbogbo ayé ni ẹbọ Jésù ṣe láǹfààní. (1 Jòhánù 2:2) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Jèhófà ṣí i payá pé “ogunlọ́gọ̀ èèyàn,” tí a kò lè ka iye wọn máa la ayé burúkú Sátánì yìí já. (Ìfihàn 7:9, 14) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa jíǹde, wọ́n sì máa láǹfààní láti gbé títí láé nínú Párádísè!—Lúùkù 23:43; Jòhánù 5:28, 29; Ìfihàn 20:11-15; 21:3, 4.
Ọgbọ́n Ọlọ́run àti Àṣírí Mímọ́
21, 22. Àwọn ọ̀nà wo ni àṣírí mímọ́ Jèhófà gbà fi ọgbọ́n rẹ̀ hàn?
21 Àṣírí mímọ́ yìí jẹ́ ọ̀nà kan tí “onírúurú ọgbọ́n Ọlọ́run” gbà fara hàn lọ́nà tó jọni lójú. (Éfésù 3:8-10) Bí Jèhófà ṣe gbé àṣírí yìí kalẹ̀ tó sì ń ṣí i payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé fi hàn pé ọgbọ́n ẹ̀ ò láfiwé. Jèhófà ló dá wa, ó mọ̀ pé a ò lè lóye àṣírí mímọ́ yìí lẹ́ẹ̀kan náà torí pé a jẹ́ aláìpé. Ó sì ń fún wa láǹfààní láti fi hàn pé òun la gbẹ́kẹ̀ lé.—Sáàmù 103:14.
22 Ọgbọ́n tí kò láfiwé ni Jèhófà lò bó ṣe yan Jésù láti jẹ́ Ọba. Nínú gbogbo ẹ̀dá, Ọmọ Jèhófà ló ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé jù lọ. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó kojú oríṣiríṣi ìṣòro, ìyẹn jẹ́ kó mọ ìṣòro táwọn èèyàn ń dojú kọ lámọ̀dunjú. (Hébérù 5:7-9) Àwọn tó máa bá Jésù jọba ńkọ́? Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ni Jèhófà ti fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn ọkùnrin àti obìnrin, látinú gbogbo ẹ̀yà, èdè àti oríṣiríṣi ipò tó yàtọ̀ síra. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí ìṣòro kankan táwọn tá a fẹ̀mí yàn yìí ò tíì kojú, gbogbo àwọn ìṣòro yìí ni wọ́n sì borí. (Éfésù 4:22-24) Ẹ ò rí i pé a máa gbádùn gan-an lábẹ́ àkóso àwọn ọba àti àlùfáà aláàánú yìí!
23. Kí nìdí tó fi jẹ́ àǹfààní ńlá pé a mọ̀ nípa àṣírí mímọ́ yẹn, kí ló sì yẹ ká ṣe?
23 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: ‘Àṣírí mímọ́ tí a fi pa mọ́ láti àwọn ètò àwọn nǹkan tó ti kọjá àti láti àwọn ìran tó ti kọjá ni a ti fi han àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.’ (Kólósè 1:26) Ká sòótọ́, àwọn ẹni mímọ́ tó jẹ́ ẹni àmì òróró Jèhófà ti mọ púpọ̀ nípa àṣírí mímọ́ yẹn, wọ́n sì ti jẹ́ kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn mọ̀ nípa ẹ̀. Àǹfààní tí gbogbo wa ní yìí mà ga lọ́lá o! Jèhófà ti jẹ́ ká “mọ àṣírí mímọ́ nípa ìfẹ́ rẹ̀.” (Éfésù 1:9) Torí náa, ó yẹ ká jẹ́ káwọn míì mọ̀ nípa àṣírí mímọ́ yìí, káwọn náà lè rí i pé àwámáridìí ni ọgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run!
a Ohun kan tún wà tí ìgbé ayé Jésù fi hàn, ìyẹn ni “àṣírí mímọ́ ti ìfọkànsin Ọlọ́run.” (1 Tímótì 3:16) Ọjọ́ pẹ́ tí ọ̀rọ̀ bóyá a lè rí ẹni tó máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lọ́nà pípé ti jẹ́ àṣírí. Jésù ló fi hàn pé ó ṣeé ṣe. Ó jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo àdánwò tí Sátánì gbé kò ó lójú.—Mátíù 4:1-11; 27:26-50.
b Jésù tún bá àwùjọ yìí “dá májẹ̀mú fún ìjọba kan.” (Lúùkù 22:29, 30) Jésù wá ń tipa bẹ́ẹ̀ bá “agbo kékeré” yìí ṣe àdéhùn pé wọ́n máa bá òun ṣàkóso ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí àwọn tó jẹ́ onípò kejì nínú ọmọ Ábúráhámù.—Lúùkù 12:32.