Àwọn Onídùnnú-ayọ̀ “Olùṣe Ọ̀rọ̀ Naa”
“Ẹ . . . fi ìwàtútù tẹ́wọ́gba gbígbin ọ̀rọ̀ naa sínú èyí tí ó lè gba ọkàn yín là. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ di olùṣe ọ̀rọ̀ naa, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan.” —JAKỌBU 1:21‚ 22.
1. Báwo ni a ṣe ní láti wo ẹṣin ọ̀rọ̀ ọdún wa fún 1996?
“ẸDI OLÙṢE Ọ̀RỌ̀ NAA.” Gbólóhùn abọ́ọ́dé yìí ní ìhìn iṣẹ́ tí ó lágbára. A fà á yọ láti inú “Lẹ́tà Jakọbu” nínú Bibeli, òun ni a óò sì fi hàn ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ọ̀rọ̀ ọdún fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jálẹ̀ 1996.
2, 3. Èé ṣe tí ó fi bá a mu wẹ́kú pé Jakọbu ní láti kọ lẹ́tà tí a fi orúkọ rẹ̀ pè?
2 Jakọbu, tí ó jẹ́ iyèkan Jesu Oluwa, ta yọ lọ́lá nínú ìjọ Kristian ìjímìjí. Ní àkókò kan lẹ́yìn àjíǹde Jesu, Oluwa wa fúnra rẹ̀ fara han Jakọbu, ó sì fara han gbogbo àwọn aposteli lẹ́yìn náà. (1 Korinti 15:7) Lẹ́yìn náà, nígbà tí a tú aposteli Peteru sílẹ̀ kúrò nínú túbú lọ́nà ìyanu, ó sọ fún àwùjọ àwọn Kristian tí wọ́n pé jọ pé: “Ẹ ròyìn nǹkan wọnyi fún Jakọbu ati awọn ará.” (Ìṣe 12:17) Ó dà bíi pé, Jakọbu, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ kì í ṣe aposteli, ṣalága ìpàdé ẹgbẹ́ olùṣàkóso ní Jerusalemu, nígbà tí àwọn aposteli àti àwọn alàgbà pinnu pé àwọn Kèfèrí tí wọ́n yí padà kò ní láti kọlà. Jakọbu kó ọ̀rọ̀ náà pọ̀ ní ṣókí, a sì fi ìpinnu tí ẹ̀mí mímọ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ.—Ìṣe 15:1-29.
3 Ó ṣe kedere pé, ìrònú dídàgbàdénú tí Jakọbu ní ní òòrìn púpọ̀. Síbẹ̀, ó fi ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́wọ́ pé, òun fúnra òun wulẹ̀ jẹ́ “ẹrú Ọlọrun ati ti Jesu Kristi Oluwa.” (Jakọbu 1:1) Lẹ́tà rẹ̀ tí a mí sí kún fún ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tí ó yè kooro àti ìṣírí fún àwọn Kristian lónìí. Ó parí rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún mẹ́rin ṣáájú kí àwọn ará Romu tó kọlu Jerusalemu lákọ̀ọ́kọ́, láti ọwọ́ Ọ̀gágun Cestius Gallus, lẹ́yìn tí a ti “wàásù” ìhìn rere náà lọ́nà gbígbòòrò “ninu gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kolosse 1:23) Àwọn àkókò líle koko nìyẹ́n jẹ́, àwọn ìránṣẹ́ Jehofa sì mọ̀ dáradára pé a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mú ìdájọ́ Rẹ̀ ṣẹ lórí orílẹ̀-èdè Júù.
4. Kí ni ó fi hàn pé àwọn Kristian ìjímìjí ní ìgbọ́nkànlé ńláǹlà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun?
4 Àwọn Kristian wọ̀nyẹn ní odindi Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu àti púpọ̀ jù lọ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Griki. Gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú títọ́ka tí wọ́n tọ́ka sí àwọn ìwé ìṣáájú náà ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ó dájú pé àwọn Kristian òǹkọ̀wé Bibeli ní ìgbẹ́kẹ̀lé ńláǹlà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Bákan náà lónìí, àwá ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tìtaratìtara, kí a sì fi í sílò nínú ìgbésí ayé wa. Kí a baà lè ní ìforítì, a nílò okun àti ìgboyà nípa tẹ̀mí, tí Ìwé Mímọ́ ń pèsè.—Orin Dafidi 119:97; 1 Timoteu 4:13.
5. Èé ṣe tí a fi nílò ìtọ́sọ́nà àkànṣe lónìí, níbo sì ni a óò ti rí i?
5 Lónìí, aráyé wà ní bèbè “ìpọ́njú ńlá . . . irúfẹ́ èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ lati ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Matteu 24:21) Lílà á já wa sinmi lé níní ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá. Báwo ni a ṣe lè rí èyí? Nípa ṣíṣí ọkàn wa payá sí àwọn ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ tí ó ní ìmísí ẹ̀mí Ọlọrun. Èyí yóò sún wa láti “di olùṣe ọ̀rọ̀ naa,” bí àwọn ìránṣẹ́ adúróṣinṣin Jehofa ní ìgbà àtijọ́. A ní láti fi taápọntaápọn ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, kí a kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, kí a sì lò ó fún ìyìn Jehofa.—2 Timoteu 2:15; 3:16, 17.
Fífara Dà Pẹ̀lú Ìdùnnú-Ayọ̀
6. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a ní ìdùnnú-ayọ̀ ní kíkojú àdánwò?
6 Nígbà tí ó ń bẹ̀rẹ̀ lẹ́tà rẹ̀, Jakọbu mẹ́nu kan ìdùnnú-ayọ̀, èkejì nínú èso ẹ̀mí Ọlọrun. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ìdùnnú-ayọ̀, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ nítòótọ́ pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín yii tí a ti dánwò ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà. Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré, kí ẹ̀yin lè pé pérépéré kí ẹ sì yèkooro ní gbogbo ọ̀nà, láìṣe aláìní ohunkóhun.” (Jakọbu 1:2-4; Galatia 5:22‚ 23) Báwo ni a ṣe lè sọ pé bíbá onírúurú àdánwò pàdé jẹ́ “ìdùnnú-ayọ̀”? Ó dára, Jesu pàápàá sọ nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí awọn ènìyàn bá gàn yín tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nitori mi. Ẹ yọ̀ kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú-ayọ̀, níwọ̀n bí èrè-ẹ̀san yín ti pọ̀ ní awọn ọ̀run.” (Matteu 5:11‚ 12) Ìtẹ́lọ́rùn onídùnnú-ayọ̀ wà nínú rírí ìbùkún Jehofa lórí ìsapá wa bí a ti ń tẹ̀ síwájú sí góńgó ìyè àìnípẹ̀kun.—Johannu 17:3; 2 Timoteu 4:7‚ 8; Heberu 11:8-10‚ 26‚ 35.
7. (a) Báwo ni a ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà? (b) Gẹ́gẹ́ bíi Jobu, báwo ni a ṣe lè san èrè fún wa?
7 Jesu fúnra rẹ̀ fara dà “nitori ìdùnnú-ayọ̀ tí a gbéka iwájú rẹ̀.” (Heberu 12:1‚ 2) Àwa pẹ̀lú lè fara dà, bí a ti ń fi tọkàntara wo àpẹẹrẹ ìgboyà Jesu! Gẹ́gẹ́ bí Jakọbu ti sọ, bí lẹ́tà rẹ̀ ti ń lọ sí òpin, Jehofa ń san èrè jìngbìnnì fún àwọn olùpàwàtítọ́ mọ́. Jakọbu sọ pé: “Wò ó! Awọn wọnnì tí wọ́n lo ìfaradà [ni] a ń pè ní aláyọ̀. Ẹ ti gbọ́ nipa ìfaradà Jobu ẹ sì ti rí àbárèbábọ̀ tí Jehofa mú wá, pé Jehofa jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi ninu ìfẹ́ni ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jakọbu 5:11) Rántí bí a ti san èrè fún ìwàtítọ́ Jobu nígbà tí a mú un padà bọ̀ sí ìlera dídára láti gbádùn ìgbésí ayé aláyọ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀. Ìfaradà nínú ìwà títọ́ lè mú irú ìdùnnú kan náà wá nínú Paradise ayé tuntun Ọlọrun, tí a ṣèlérí náà, gẹ́gẹ́ bí òtéńté ìdùnnú-ayọ̀ ṣíṣiṣẹ́ sin Jehofa nísinsìnyí.
Wíwá Ọgbọ́n
8. Báwo ni a ṣe lè rí òtítọ́, ọgbọ́n tí ó ṣeé mú lò, ipa wo sì ni àdúrà ń kó nínú èyí?
8 Kíkẹ́kọ̀ọ́ tí a bá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun taápọntaápọn, pa pọ̀ pẹ̀lú fífi í sílò lọ́nà gbígbéṣẹ́, yóò yọrí sí ọgbọ́n Ọlọrun, tí yóò sì mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti fara da àdánwò láàárín ìwà ìbàjẹ́ ètò ìgbékalẹ̀ Satani tí ń kú lọ. Báwo ni a ṣe lè ní ìdánilójú rírí irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀? Jakọbu sọ fún wa pé: “Bí ẹnikẹ́ni ninu yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, nitori oun a máa fifún gbogbo ènìyàn pẹlu ìwà-ọ̀làwọ́ ati láìsí gíganni; a óò sì fi í fún un. Ṣugbọn kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè ninu ìgbàgbọ́, láìṣiyèméjì rárá, nitori ẹni tí ó bá ń ṣiyèméjì dàbí ìgbì òkun tí ẹ̀fúùfù ń bì tí a sì ń fẹ́ káàkiri.” (Jakọbu 1:5‚ 6) A ní láti gbàdúrà taratara, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé tí kò mì, pé Jehofa yóò gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa àti pé yóò dáhùn wọn ní ọ̀nà tí ó dára lójú rẹ̀ àti ní àkókò tí ó tọ́ lójú rẹ̀.
9. Báwo ni Jakọbu ṣe ṣàpèjúwe ọgbọ́n Ọlọrun àti lílò rẹ̀?
9 Ọgbọ́n Ọlọrun jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Jehofa. Nígbà tí ó ń ṣàpèjúwe irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀, Jakọbu sọ pé: “Gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ lati òkè, nitori a máa sọ̀kalẹ̀ wá lati ọ̀dọ̀ Baba awọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá, kò sì sí àyídà ìyípo òjìji lọ́dọ̀ rẹ̀.” Lẹ́yìn náà, nínú lẹ́tà rẹ̀, Jakọbu ṣàlàyé àbájáde jíjèrè ọgbọ́n tòótọ́, nígbà tí ó wí pé: “Ta ni ninu yín tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ati olóye? Kí ó fi awọn iṣẹ́ rẹ̀ hàn lati inú ìwà rẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹlu ìwàtútù tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n. . . . Ọgbọ́n tí ó wá lati òkè á kọ́kọ́ mọ́níwà, lẹ́yìn naa ó lẹ́mìí-àlàáfíà, ó ń fòyebánilò, ó múra tán lati ṣègbọràn, ó kún fún àánú ati awọn èso rere, kì í pa awọn ààlà-ìyàtọ̀ olójúsàájú, kì í ṣe àgàbàgebè.”—Jakọbu 1:17; 3:13-17.
10. Báwo ni ìsìn èké ṣe yàtọ̀ gédégbé sí ìsìn tòótọ́?
10 Nínú ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, bóyá ní Kirisẹ́ńdọ̀mù tàbí ní àwọn ilẹ̀ mìíràn, lọ́pọ̀ ìgbà, ó jẹ́ àṣà àwọn olùjọsìn láti kọrin, kí wọ́n tẹ́tí sí àwọn àdúrà àgbàtúngbà, àti bóyá, kí wọ́n gbọ́ àwíyé. A kò fún wọn ní ìṣírí kankan nípa kíkéde ìhìn iṣẹ́ afúnninírètí, nítorí pé, èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú ìsìn kò rí ṣíṣeé ṣe náà láti ní ọjọ́ iwájú tí ó dára. Ìrètí ológo ti Ìjọba Messia Ọlọrun ni a kì í mẹ́nu kan rárá tàbí kí a ṣì í lóye pátápátá. Jehofa sọ lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn alátìlẹ́yìn Kirisẹ́ńdọ̀mù pé: “Àwọn ènìyàn mi ṣe ibi méjì: wọ́n fi Èmi, ìsun omi ìyè sílẹ̀, wọ́n sì wa kàǹga omi fún ara wọn, kàǹga fífọ́ tí kò lè dá omi dúró.” (Jeremiah 2:13) Wọn kò ní omi òtítọ́. Wọn kò ní ọgbọ́n àtọ̀runwá.
11, 12. (a) Báwo ni ó ṣe yẹ kí ọgbọ́n àtọ̀runwá sún wa ṣiṣẹ́? (b) Kí ni ọgbọ́n àtọ̀runwá ń kìlọ̀ fún wa nípa rẹ̀?
11 Ẹ wo bí èyí ti yàtọ̀ tó láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lónìí! Pẹ̀lú ipá alágbára tí Ọlọrun fún wọn, wọ́n ń fi ìhìn rere Ìjọba Rẹ̀ tí ń bọ̀ kún ayé. Wọ́n fìdí ọgbọ́n tí wọ́n ń sọ jáde múlẹ̀ gbọn-ingbọn-in lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. (Fi wé Owe 1:20; Isaiah 40:29-31.) Ní tòótọ́, wọ́n ń lo ìmọ̀ tòótọ́ àti òye lọ́nà gbígbéṣẹ́, ní kíkéde àwọn ète kíkọyọyọ ti Ọlọrun àti Ẹlẹ́dàá wa. Ó yẹ kí ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn wa pé, kí gbogbo ènìyàn tí ó wà nínú ìjọ “kún fún ìmọ̀ pípéye nipa ìfẹ́-inú [Ọlọrun] ninu ọgbọ́n gbogbo ati ìfinúmòye ti ẹ̀mí.” (Kolosse 1:9) Nígbà tí a bá ní ìpìlẹ̀ yìí, a óò sún tọmọdé tàgbà láti “di olùṣe ọ̀rọ̀ náà” ní gbogbo ìgbà.
12 “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” ń kìlọ̀ fún wa nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí ó lè yọrí sí pípàdánù ojú rere àtọ̀runwá. Jakọbu sọ pé: “Kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n. Olúkúlùkù ènìyàn gbọ́dọ̀ yára nipa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nipa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nipa ìrunú; nitori ìrunú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ yọrí sí òdodo Ọlọrun.” Bẹ́ẹ̀ ni, a ní láti yára, kí a sì hára gàgà láti tẹ́tí sí ìmọ̀ràn àtọ̀runwá, kí a sì fi í sílò. Ṣùgbọ́n, a ní láti ṣọ́ra, kí a má ṣe ṣi “ẹ̀yà-ara kékeré” náà, ahọ́n, lò. Nípasẹ̀ fífọ́nnu, ṣíṣe òfófó aláìlọ́gbọ́n, tàbí ṣíṣe oríkunkun, lọ́nà àpèjúwe, ahọ́n lè dáná ran “igbó igi tí ó tóbi gan-an.” Nítorí náà, a ní láti mú ìkẹ́gbẹ́pọ̀ alárinrin àti ìkóra-ẹni-níjàánu dàgbà.—Jakọbu 1:19, 20; 3:5.
13. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí a tẹ́wọ́ gba “gbígbin ọ̀rọ̀ náà”?
13 Jakọbu kọ̀wé pé: “Nitori bẹ́ẹ̀ ẹ mú gbogbo èérí-ẹ̀gbin kúrò ati ohun àṣerégèé yẹn, ìwà búburú, kí ẹ sì fi ìwàtútù tẹ́wọ́gba gbígbin ọ̀rọ̀ naa sínú èyí tí ó lè gba ọkàn yín là.” (Jakọbu 1:21) Ayé oníwọra yìí, pẹ̀lú ìgbésí ayé tèmi-làkọ́kọ́, onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì ṣekárími, àti ìwà ìbàjẹ́ rẹ̀, ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kọjá lọ. “Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun ni yoo dúró títí láé.” (1 Johannu 2:15-17) Ẹ wo bí ó ti ṣe pàtàkì tó nígbà náà, pé kí a tẹ́wọ́ gba “gbígbin ọ̀rọ̀ naa sínú”! Ọgbọ́n tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pèsè yàtọ̀ gédégbé sí ìbàjẹ́ ayé tí ń kú lọ yìí. A kò fẹ́ èyíkéyìí lára ìbàjẹ́ náà. (1 Peteru 2:1‚ 2) A ní láti nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti ìgbàgbọ́ lílágbára tí a gbìn sínú ọkàn wa, kí á baà lè pinnu láti má ṣe yà kúrò nínú àwọn ọ̀nà òdodo Jehofa. Ṣùgbọ́n, gbígbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ha tó bí?
Dídi “Olùṣe Ọ̀rọ̀ Naa”
14. Báwo ni a ṣe lè di “olùgbọ́” àti “olùṣe” Ọ̀rọ̀ náà?
14 A kà nínú Jakọbu 1:22 pé: “Ẹ di olùṣe ọ̀rọ̀ naa, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan, ní fífi ìgbèrò èké tan ara yín jẹ.” “Ẹ di olùṣe ọ̀rọ̀ naa”! Dájúdájú, ẹsin ọ̀rọ̀ yìí ni a tẹnu mọ́ nínú lẹ́tà Jakọbu. A ní láti fetí sílẹ̀, kí a sì ṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́’! (Genesisi 6:22) Ọ̀pọ̀ lónìí ń sọ pé, gbígbọ́ ìwàásù tàbí nínípìn-ín nínú ìjọsìn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àṣà ti tó, ṣùgbọ́n wọn kò ṣe ohunkóhun jù báyìí lọ. Wọ́n lè máa ronú pé, níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ń gbé ‘ìgbésí ayé rere’ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n tara wọn, ìyẹn ti tó. Síbẹ̀, Jesu Kristi sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀ kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Matteu 16:24) Ó dájú pé, ìgbésẹ̀ onífara-ẹni-rúbọ àti onífaradà ní títẹ̀ lé ipasẹ̀ Jesu ní ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọrun, ni a ń béèrè lọ́dọ̀ àwọn Kristian tòótọ́. Ní ti wọn, ìfẹ́ inú Ọlọrun lónìí rí bí ó ti rí ní ọ̀rúndún kìíní gan-an, nígbà tí Jesu tí a jí dìde náà pàṣẹ pé: “Nitori naa ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn.” (Matteu 28:19) Báwo ni o ti ń ṣe sí nínú èyí?
15. (a) Àkàwé wo ni Jakọbu fúnni, tí ń fi bí a ṣe lè di aláyọ̀ gẹ́gẹ́ bí “olùṣe ọ̀rọ̀ náà” hàn? (b) Èé ṣe tí wíwulẹ̀ tẹ̀ lé ọ̀nà ìjọsìn kan ṣáá kò fi tó?
15 Bí a bá tẹra mọ́ wíwo Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní àwòfín, ó lè dà bíi jígí ní fífi irú ẹni tí a jẹ́ gẹ́lẹ́ hàn wá. Jakọbu sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé naa tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn, ẹni yii, nitori tí oun kò di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, bíkòṣe olùṣe iṣẹ́ naa, yoo láyọ̀ ninu ṣíṣe é.” (Jakọbu 1:23-25) Àní, yóò jẹ́ aláyọ̀ “olùṣe ọ̀rọ̀ náà.” Ní àfikún sí i, ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ “olùṣe” nínú, gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ìgbésí ayé Kristian wa. A kò gbọdọ̀ tan ara wa jẹ láé, ní ríronú pé ìjọsìn elétò àṣà lásán ti tó. Jakọbu gbà wá nímọ̀ràn láti kíyè sí àwọn apá kan ìjọsìn tòótọ́ tí àwọn Kristian onítara pàápàá lè ti pa tì. Ó kọ̀wé pé: “Irú ọ̀nà-ètò ìjọsìn tí ó mọ́ tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú-ìwòye Ọlọrun ati Baba wa ni èyí: lati máa bójútó awọn ọmọ òrukàn ati awọn opó ninu ìpọ́njú wọn, ati lati pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò ninu ayé.”—Jakọbu 1:27.
16. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Abrahamu gbà di ‘ọ̀rẹ́ Jehofa,’ báwo sì ni a ṣe lè di ọ̀rẹ́ Rẹ̀?
16 Wíwulẹ̀ sọ pé, ‘Mo gba Ọlọrun gbọ́,’ kí a sì fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, kò tó. Gẹ́gẹ́ bí Jakọbu 2:19 ti ṣàlàyé pé: “Iwọ gbàgbọ́ pé Ọlọrun kan ni ń bẹ, àbí? Iwọ ń ṣe dáadáa níti gidi. Awọn ẹ̀mí-èṣù pàápàá gbàgbọ́ wọ́n sì gbọ̀n jìnnìjìnnì.” Jakọbu tẹnu mọ́ ọn pé “ìgbàgbọ́, bí kò bá ní awọn iṣẹ́, jẹ́ òkú ninu ara rẹ̀,” ó sì tọ́ka sí Abrahamu, ní sísọ pé: “Ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹlu awọn iṣẹ́ rẹ̀ ati nipa awọn iṣẹ́ rẹ̀ a sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ di pípé.” (Jakọbu 2:17‚ 20-22) Iṣẹ́ Abrahamu ní pípèsè ìrànwọ́ fún ìbátan rẹ̀ nínú, fífi ẹ̀mí aájò àlejò hàn, mímúra sílẹ̀ láti fi Isaaki rúbọ, àti ‘pípolongo ní gbangba’ ìgbàgbọ́ aláìmisẹ̀ nínú ìlérí Ọlọrun fún “ìlú-ńlá naa tí ó ní awọn ìpìlẹ̀ tòótọ́ gidi,” Ìjọba Messia ti ọjọ́ iwájú. (Genesisi 14:16; 18:1-5; 22:1-18; Heberu 11:8-10, 13, 14; 13:2) Lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, Abrahamu “di ẹni tí a ń pè ní ‘ọ̀rẹ́ Jehofa.’” (Jakọbu 2:23) A lè ka àwa pẹ̀lú sí ‘ọ̀rẹ́ Jehofa’ bí a ti ń fi akitiyan pòkìkí ìgbàgbọ́ àti ìrètí wa nínú Ìjọba òdodo rẹ̀ tí ń bọ̀.
17. (a) Èé ṣe tí a fi “polongo” Rahabu “ní olódodo,” báwo sì ni a ṣe san èrè fún un? (b) Àkọsílẹ̀ gígùn wo ni Bibeli pèsè nípa àwọn tí wọ́n “di olùṣe ọ̀rọ̀ naa”? (d) Báwo ni a ṣe san èrè fún Jobu, èé sì ti ṣe?
17 Àwọn tí wọ́n “di olùṣe ọ̀rọ̀ náà” ni a “polongo . . . ní olódodo nipa awọn iṣẹ́, kì í sì í ṣe nipa ìgbàgbọ́ nìkan.” (Jakọbu 2:24) Rahabu jẹ́ ẹnì kan tí ó fi iṣẹ́ kún ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú “ọ̀rọ̀” náà tí ó gbọ́ nípa àwọn ìṣe alágbára ńlá Jehofa. Ó gbé àwọn amí ọmọ Israeli pa mọ́, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sá àsálà, ó tún kó agbo ilé bàbá rẹ̀ jọ fún ìgbàlà. Nígbà àjíǹde, ẹ wo bí yóò ti láyọ̀ tó láti gbọ́ pé ìgbàgbọ́ rẹ̀, tí ó fi iṣẹ́ tì lẹ́yìn, sún un láti di ìyá ńlá Messia! (Joṣua 2:11; 6:25; Matteu 1:5) Heberu orí 11 pèsè àkọsílẹ̀ gígùn orúkọ àwọn mìíràn tí wọ́n “di olùṣe” nípa fífi ìgbàgbọ́ wọn hàn, a óò sì san èrè fún wọn jìngbìnnì. A kò sì gbọdọ̀ gbàgbé Jobu, ẹni tí ó sọ lábẹ́ àdánwò pé: “Ìbùkún ni orúkọ Oluwa.” Gẹ́gẹ́ bí a ti tọ́ka sí i tẹ́lẹ̀, ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ rẹ̀ yọrí sí èrè kíkọyọyọ. (Jobu 1:21; 31:6; 42:10; Jakọbu 5:11) Bákan náà, ìfaradà wa lónìí gẹ́gẹ́ bí “olùṣe ọ̀rọ̀ náà” yóò mú ojú rere Jehofa wá.
18, 19. Báwo ni àwọn arákùnrin tí a ti ni lára fún ọ̀pọ̀ ọdún ṣe “di olùṣe ọ̀rọ̀ naa,” ìbùkún wo sì ni ìgbòkègbodò wọn ti mú wá?
18 Lára àwọn tí wọ́n ti fara da ohun púpọ̀ jálẹ̀ àwọn ọdún yìí, ni àwọn arákùnrin wa ní Eastern Europe. Nísinsìnyí tí a ti mú ọ̀pọ̀ ìkálọ́wọ́kò kúrò, wọ́n ti di “olùṣe ọ̀rọ̀ náà” ní tòótọ́ ní àdúgbò wọn tuntun. Àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn aṣáájú ọ̀nà láti àwọn ilẹ̀ tí o yí wọn ká, ti ṣí lọ síbẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ ní kíkọ́ni àti ṣíṣètò. Ẹ̀ka ti Finland àti àwọn ẹ̀ka Watch Tower Society mìíràn tí ó wà nítòsí ti fi àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ọ̀mọ̀lé ránṣẹ́, ìtọrẹ ọlọ́làwọ́ ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé sì ti bójú tó ìnáwó kíkọ́ àwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ tuntun àti àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba.—Fi wé 2 Korinti 8:14‚ 15.
19 Ẹ wo ìtara tí àwọn ará tí a ti ni lára fún ọ̀pọ̀ ọdún fi dáhùn padà nínú pápá! Wọ́n ‘ń ṣiṣẹ́ kára, wọ́n sì ń tiraka’ láti lè san àsandípò, gẹ́gẹ́ bí a ti lè pè é, lórí gbogbo àǹfààní tí kò ṣí sílẹ̀ “ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú.” (1 Timoteu 4:10; 2 Timoteu 4:2) Fún àpẹẹrẹ, ní April tí ó kọjá yìí, ní Albania, níbi tí ìtẹ̀lóríba ti burú jáì tẹ́lẹ̀, gbogbo Ìròyìn Ìjọba tí a kó wá, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Èéṣe Tí Ìgbésí-Ayé Fi Kún Fún Ìṣòro Tóbẹ́ẹ̀?” ni a pín ní ọjọ́ mẹ́ta péré. Èyí jẹ́ ìgbésẹ̀ tí ó gbámúṣe lẹ́yìn Ìṣe Ìrántí ikú Jesu, tí 3,491 pésẹ̀ sí—tí ó fi púpọ̀púpọ̀ lé sí 538, tí wọ́n jẹ́ ògbóṣáṣá akéde wọn.
20. Kí ni iye àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí ní àìpẹ́ yìí tọ́ka sí, báwo sì ni a ṣe lè ran púpọ̀ lọ́wọ́?
20 Lọ́nà ṣíṣe pàtàkì, àwọn ilẹ̀ míràn pẹ̀lú ti fi kún iye àwọn tí ó pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí, èyí tí ó ti fi púpọ̀ lé ní 10,000,000 ní ọdún àìpẹ́ yìí. Ní ibi púpọ̀, àwọn ẹni tuntun, tí pípésẹ̀ àti jíjẹ́ òǹwòran níbi Ìṣe Ìrántí ti fún ìgbàgbọ́ wọn lókun, ti ‘ń di olùṣe ọ̀rọ̀ náà.’ A ha lè fún púpọ̀ sí i lára àwọn ẹni tuntun tí ń dàra pọ̀ níṣìírí láti tóótun fún àǹfààní náà bí?
21. Ní ìbámu pẹ̀lú ẹṣin ọ̀rọ̀ wa ọdún yìí, ipa ọ̀nà wo ni ó yẹ kí á tẹ̀ lé, pẹ̀lú ète wo sì ni?
21 Gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristian onítara ti ọ̀rúndún kìíní wọ̀nyẹn, àti ọ̀pọ̀ láti ìgbà náà wá, ẹ jẹ́ kí a pinnu láti tiraka ní ‘lílépa góńgó naa nìṣó fún ẹ̀bùn’ ìyè àìnípẹ̀kun, bóyá ìyẹn yóò jẹ́ ní Ìjọba ti ọ̀run tàbí ní ilẹ̀ ọba àkóso rẹ̀ ní ayé. (Filippi 3:12-14) Ìsapá èyíkéyìí tí a bá lè ṣe tó bẹ́ẹ̀, ó sì jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí ọwọ́ wa lè tẹ góńgó náà. Ìsinsìnyí kọ́ ni àkókò láti fà sẹ́yìn sí jíjẹ́ olùgbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ó jẹ́ àkókò láti ‘múra gírí kí a sì ṣiṣẹ́.’ (Haggai 2:4; Heberu 6:11‚ 12) Lẹ́yìn tí ‘a ti tẹ́wọ́ gba gbígbin ọ̀rọ̀ náà,’ ǹjẹ́ kí a ‘di aláyọ̀ olùṣe ọ̀rọ̀ náà’ nísinsìnyí àti títí láé.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Báwo ni a ṣe lè fara dà pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀?
◻ Kí ni “ọgbọ́n tí ó ti òkè wá,” báwo sì ni a ṣe lè lépa rẹ̀?
◻ Èé ṣe tí a fi gbọ́dọ̀ “di olùṣe ọ̀rọ̀ naa, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan”?
◻ Àwọn ìròyìn wo ni ó yẹ kí ó sún wa láti di “olùṣe ọ̀rọ̀ náà”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ǹjẹ́ kí àwa pẹ̀lú ṣí ọkàn-àyà wa payá sí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
A san èrè fún ìwàtítọ́ Jobu nípa mímú un padà bọ̀ sí ìgbésí ayé aláyọ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ pẹ̀lú àwọn olúlùfẹ́ rẹ̀