Ríran Àwọn Opó Lọ́wọ́ Nínú Gbogbo Àdánwò Wọn
Ọ̀KAN lára ìtàn táwọn èèyàn mọ̀ jù lọ nípa àwọn opó ni ìtàn tí Bíbélì sọ nípa Rúùtù àti Náómì ìyá ọkọ rẹ̀. Opó làwọn obìnrin méjèèjì yìí. Àmọ́ kì í ṣe ọkọ nìkan ni Náómì pàdánù, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì ti kú pẹ̀lú. Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin yìí sì ni ọkọ Rúùtù. Ipò tí wọ́n bá ara wọn ṣeni láàánú gan-an, nítorí pé ibi tí wọ́n ń gbé jẹ́ àgbègbè tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀, tó sì jẹ́ pé àwọn ọkùnrin ló sábà máa ń gbọ́ bùkátà ìdílé.—Rúùtù 1:1-5, 20, 21.
Ṣùgbọ́n, Rúùtù aya ọmọ Náómì jẹ́ olùtùnú àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ pàtàkì, tó dúró tì í gbágbáágbá. Nígbà tó yá, Rúùtù wá “sàn fún [Náómì] ju ọmọkùnrin méje lọ”—kì í ṣe kìkì nítorí fífẹ́ tó fẹ́ Náómì dénú, àmọ́ pẹ̀lúpẹ̀lù nítorí ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run. (Rúùtù 4:15) Nígbà tí Náómì dá a lábàá pé kí Rúùtù padà lọ bá àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ ará Móábù, Rúùtù sọ ọ̀rọ̀ ìdúróṣinṣin tó wúni lórí jù lọ tí a tíì kà rí, ó ní: “Ibi tí o bá lọ ni èmi yóò lọ, ibi tí o bá sì sùn mọ́jú ni èmi yóò sùn mọ́jú. Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi. Ibi tí o bá kú sí ni èmi yóò kú sí, ibẹ̀ sì ni ibi tí a ó sin mí sí. Kí Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi, kí ó sì fi kún un, bí ohunkóhun yàtọ̀ sí ikú bá ya èmi àti ìwọ.”—Rúùtù 1:16, 17.
Jèhófà Ọlọ́run kíyè sí ìṣarasíhùwà Rúùtù. Ó bù kún agboolé kékeré Náómì àti Rúùtù, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ Rúùtù fẹ́ Bóásì ọmọ Ísírẹ́lì. Bí ẹni pé ọmọ tirẹ̀ gan-an ni Náómì ṣe tọ́jú ọmọ tí wọ́n bí, tó wá di baba ńlá fún Jésù Kristi. Ìtàn yìí jẹ́ àpẹẹrẹ ìtọ́jú tí Jèhófà ń fún àwọn opó tó bá sún mọ́ ọn, tó sì gbẹ́kẹ̀ lé e. Síwájú sí i, Bíbélì sọ fún wa pé ó mọrírì àwọn tó bá ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ran àwọn opó lọ́wọ́ nínú àdánwò wọn. Nítorí náà, báwo la ṣe lè ṣètìlẹyìn fáwọn opó tí ń bẹ láàárín wa lónìí?—Rúùtù 4:13, 16-22; Sáàmù 68:5.
Ìrànlọ́wọ́ Tó Ṣe Pàtó, Láìjẹ Gàba Lé Wọn Lórí
Nígbà táa bá ń ran opó kan lọ́wọ́, ohun tó dára jù ni pé ká sọ ìrànlọ́wọ́ pàtó táa fẹ́ ṣe gan-an, àmọ́ ká máà jẹ gàba lé e lórí. Yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣe pàtó bíi, “Jẹ́ kí n mọ̀ tóo bá nílò ohunkóhun.” Irú ọ̀rọ̀ yẹn lè má yàtọ̀ sí sísọ pé, “Kí ara yín yá gágá, kí ẹ sì jẹun yó dáadáa” fún ẹni tí òtútù àti ebi ń pa, láìṣe ìrànlọ́wọ́ kankan fún un. (Jákọ́bù 2:16) Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò ní béèrè fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá nílò nǹkan kan; dípò kí wọ́n béèrè, wọ́n á kúkú fìtìjú kárùn. Láti ran irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ ń béèrè òye, èyíinì ni fífòyemọ ohun tí wọ́n nílò. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ṣíṣe é láṣejù—pàápàá láìjẹ́ kí opó náà rímú mí mọ́—lè fa ìbínú àti èdè àìyedè. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú bí a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn lò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rọ̀ wá pé ká ní ìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan fún àwọn èèyàn, ó tún rán wa létí pé ká má ṣe jẹ́ ọ̀yọjúràn.—Fílípì 2:4; 1 Pétérù 4:15.
Irú ìwọ̀ntúnwọ̀nsì yẹn ni Rúùtù fi bá Náómì lò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Rúùtù dúró ti ìyá ọkọ rẹ̀ gbágbáágbá, kò kọjá àyè ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ gàba lé e lórí. Ó lo ìdánúṣe tó bọ́gbọ́n mu, irú bíi wíwá oúnjẹ fún Náómì àti fún ara rẹ̀, àmọ́ ó tún tẹ̀ lé ìtọ́ni Náómì.—Rúùtù 2:2, 22, 23; 3:1-6.
Ṣùgbọ́n ṣá o, ìrànlọ́wọ́ tẹ́nì kan nílò lè yàtọ̀ pátápátá sí ti ẹlòmíì. Sandra táa mẹ́nu kàn ṣáájú sọ pé: “Mo ní ohun tí mo nílò ní àkókò wàhálà mi—mo ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tó nífẹ̀ẹ́ mi, tó sì dúró tì mí.” Elaine táa mẹ́nu kàn ṣáájú, ní tirẹ̀, nílò àkókò láti dá wà. Nítorí náà, jíjẹ́ olùrànlọ́wọ́ túmọ̀ sí jíjẹ́ olóye àti wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kí á má máa tojú bọ ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn, ká sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣèrànwọ́ nígbà tí wọ́n bá nílò wa.
Ìtìlẹyìn Àwọn Ẹbí
Àwọn ẹbí tó láájò tó sì nífẹ̀ẹ́, ìyẹn bí a bá ní irú ẹbí yẹn, lè ṣe ohun púpọ̀ láti fi ọkàn opó kan balẹ̀ pé yóò lè kojú ipò náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan nínú ẹbí lè ṣe ìrànlọ́wọ́ ju àwọn míì lọ, gbogbo wọn ló ní ipa tí wọ́n lè kó. “Bí opó èyíkéyìí bá ní àwọn ọmọ tàbí àwọn ọmọ-ọmọ, kí àwọn wọ̀nyí kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ láti máa fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣe ìwà hù nínú agbo ilé tiwọn, kí wọ́n sì máa san àsanfidípò yíyẹ fún àwọn òbí wọn àti àwọn òbí wọn àgbà, nítorí tí èyí ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run.”—1 Tímótì 5:4.
Nínú àwọn ọ̀ràn kan, wọ́n lè máà nílò owó tàbí “àsanfidípò.” Àwọn opó kan ní owó tí wọ́n lè fi gbọ́ bùkátà ara wọn, àwọn míì lára wọn sì lè jàǹfààní látinú owó àjẹmọ́nú tí ìjọba ń san, ìyẹn bí irú ètò bẹ́ẹ̀ bá wà ní orílẹ̀-èdè wọn. Àmọ́ níbi tí àwọn opó bá ti jẹ́ aláìní, ó yẹ káwọn mẹ́ńbà ìdílé lè ṣèrànwọ́. Bí opó kan kò bá ní àwọn ìbátan tímọ́tímọ́ tó lè ṣètìlẹyìn, tàbí tí agbára irú àwọn ìbátan bẹ́ẹ̀ ò gbé e, Ìwé Mímọ́ rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ opó náà pé kí wọ́n ràn án lọ́wọ́, ó ní: “Ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé.”—Jákọ́bù 1:27.
Àwọn tó bá fi ìlànà Bíbélì wọ̀nyí sílò ń “bọlá fún àwọn opó” ní ti gidi. (1 Tímótì 5:3) Láti bọlá fún ẹnì kan, lédè mìíràn, túmọ̀ sí láti fi ọ̀wọ̀ onítọ̀hún wọ̀ ọ́. Àwọn táa bá bọlá fún máa ń mọ̀ pé a gbé àwọn gẹ̀gẹ̀, pé a ṣìkẹ́ àwọn, àti pé a gbé àwọn níyì. Wọn kì í nímọ̀lára pé nítorí àìríbi yẹ̀ ẹ́ sí làwọn ẹlòmíì fi ń ran àwọn lọ́wọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Rúùtù alára jẹ́ opó fún sáà kan, síbẹ̀ ó bọlá fún Náómì ní ti gidi, nípa fífi tinútinú àti tìfẹ́tìfẹ́ rí i dájú pé Náómì ń rí ìtọ́jú tó dáa gbà ní ti ara ìyára àti ní ti ìmí ẹ̀dùn. Àní, kíá làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí kan sáárá sí Rúùtù nítorí ìwà rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ tó fẹ́ fẹ́ ẹ fi sọ fún un pé: “Gbogbo ẹni tí ó wà nínú ìlú àwọn ènìyàn mi mọ̀ pé ìwọ jẹ́ obìnrin títayọ lọ́lá.” (Rúùtù 3:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ó dájú pé ìfẹ́ tí Náómì ní fún Ọlọ́run, àti bó ṣe jẹ́ afòyebánilò, àti ìmọrírì àtọkànwá tó ń fi hàn fún wàhálà tí Rúùtù ń ṣe ní tìtorí rẹ̀ ló jẹ́ kí ó dùn mọ́ Rúùtù nínú láti máa ràn án lọ́wọ́. Ẹ wo àpẹẹrẹ rere tí Náómì jẹ́ fáwọn opó lónìí!
Sún Mọ́ Ọlọ́run
Ṣùgbọ́n o, àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ kò lè múni gbàgbé gbogbo ẹ̀dùn ọkàn téèyàn ní nítorí ikú olólùfẹ́ ẹni. Fún ìdí yìí, ó ṣe pàtàkì pé kí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ túbọ̀ sún mọ́ “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Gbé àpẹẹrẹ Ánà yẹ̀ wò, opó olùfọkànsìn tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84] nígbà táa bí Jésù.
Nígbà tí ọkọ Ánà kú lẹ́yìn ọdún méje péré tí wọ́n ṣègbéyàwó, Jèhófà ló tọ̀ lọ fún ìtùnú. “Kì í pa wíwà ní tẹ́ńpìlì jẹ, [ó] ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ lóru àti lọ́sàn-án pẹ̀lú ààwẹ̀ àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.” (Lúùkù 2:36, 37) Ǹjẹ́ inú Jèhófà dùn sí ìfọkànsìn Ánà? Bẹ́ẹ̀ ni o! Jèhófà fi hàn pé òun fẹ́ràn rẹ̀ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ nípa jíjẹ́ kí ó rí ọmọ ọwọ́ tí yóò di Olùgbàlà aráyé. Ẹ wo bí èyí yóò ti wú Ánà lórí àti bó ṣe tù ú nínú tó! Dájúdájú, ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 37:4 ṣẹ sí i lára, pé: “Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà, òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.”
Ọlọ́run Ń Lo Àwọn Kristẹni Ẹlẹgbẹ́ Wa
Elaine, sọ pé: “Lẹ́yìn ikú David, ṣe ni ara bẹ̀rẹ̀ sí ro mí, ìrora ọ̀hún kò sì lọ, ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n ń fi ọ̀bẹ gún mi ní igbá àyà. Mo kọ́kọ́ rò pé oúnjẹ tí mo jẹ tí kò dà ló fà á. Lọ́jọ́ kan, ìrora ọ̀hún wá pọ̀ débi pé mo ronú pé ó di dandan láti lọ rí dókítà. Arábìnrin mi kan nípa tẹ̀mí tó jẹ́ olóye tó sì tún jẹ́ ọ̀rẹ́ mi, dá a lábàá pé ó lè jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn mi ló fà á, ó sì rọ̀ mí pé kí n bẹ Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú. Mo gba ìmọ̀ràn rẹ̀ lójú ẹsẹ̀, mo sì gba àdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́, tó sì jẹ́ àtọkànwá, mo bẹ Jèhófà pé kó jọ̀ọ́ ràn mí lọ́wọ́ láti borí àròdùn mi. Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀!” Ara Elaine bẹ̀rẹ̀ sí mókun, kò sì pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí ìrora gógó yẹn pàápàá fi lọ.
Ní pàtàkì, àwọn alàgbà ìjọ lè máa ṣe bí ọ̀rẹ́ onínúure sí àwọn opó tó ní àròdùn. Nípa fífún wọn ní ìtìlẹyìn àti ìtùnú déédéé nípa tẹ̀mí lọ́nà ọgbọ́n àti òye, àwọn alàgbà lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́ láìfi àdánwò pè. Níbi tó bá ti pọndandan, àwọn alàgbà tún lè ṣètò ìtìlẹyìn nípa ti ara. Dájúdájú, irú àwọn alàgbà oníyọ̀ọ́nú àti olóye bẹ́ẹ̀ jẹ́ “ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù.”—Aísáyà 32:2; Ìṣe 6:1-3.
Ìtùnú Títí Láé Látọ̀dọ̀ Ọba Tuntun fún Ilẹ̀ Ayé
Ẹni tí ìyá àgbàlagbà nì, Ánà, rí tó ń yọ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn ti di Mèsáyà Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run báyìí. Láìpẹ́, Ìjọba yìí yóò fòpin sí gbogbo ohun tí ń fa ìbànújẹ́, títí kan ikú. Lórí kókó yìí, ohun tí Ìṣípayá 21:3, 4 sọ ni pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé . . . Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí pé ibí yìí tọ́ka sí “aráyé”? Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ̀dá ènìyàn yóò gba òmìnira lọ́wọ́ ikú àti gbogbo ọ̀fọ̀ àti igbe ẹkún tó máa ń fà.
Ṣùgbọ́n ìhìn ayọ̀ yìí kò mọ síbẹ̀ o! Bíbélì tún ṣèlérí àjíǹde àwọn òkú. “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Gẹ́gẹ́ bíi Lásárù, tí Jésù jí dìde kúrò nínú ikú, wọn yóò jáde wá bí ẹ̀dá ènìyàn, kì í ṣe bí ẹ̀dá ẹ̀mí. (Jòhánù 11:43, 44) Àwọn tó bá “ṣe ohun rere” lẹ́yìn náà ni a óò gbé dé ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn, àwọn alára yóò sì ní ìrírí àbójútó bíi ti bàbá látọ̀dọ̀ Jèhófà, bí ó ti ‘ṣí ọwọ́ rẹ̀, tí ó sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.’—Sáàmù 145:16.
Àwọn tí olólùfẹ́ wọn ti kú, tí wọ́n sì gba ìrètí tó dájú yìí gbọ́, rí i pé ó jẹ́ orísun ìtùnú ńláǹlà. (1 Tẹsalóníkà 4:13) Nítorí náà, bóo bá jẹ́ opó, rí i dájú pé o ń “gbàdúrà láìdabọ̀” fún ìtùnú àti ìrànlọ́wọ́ tóo nílò lójoojúmọ́ kí o bàa lè borí onírúurú òkè ìṣòro. (1 Tẹsalóníkà 5:17; 1 Pétérù 5:7) Kí o sì máa wá àyè láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, kí àwọn èrò Ọlọ́run lè máa tù ọ́ nínú. Bóo bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, wàá rí i fúnra rẹ pé, láìka bí gbogbo àdánwò àti ìṣòro tí o dojú kọ gẹ́gẹ́ bí opó ṣe pọ̀ tó, ó dájú pé Jèhófà lè fún ọ ní ìbàlẹ̀ ọkàn.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Jíjẹ́ olùrànlọ́wọ́ túmọ̀ sí wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kí á má máa tojú bọ ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn, kí á sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣèrànwọ́ nígbà tí wọ́n bá nílò wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọlọ́run bù kún ìyá àgbàlagbà nì, Ánà, tó jẹ́ opó