Kí ni A Gbọ́dọ̀ Ṣe Láti Rí Ìgbàlà?
NÍGBÀ kan, ọkùnrin kan bi Jesu léèrè pé: “Oluwa, ìwọ̀nba díẹ̀ ha ni awọn wọnnì tí a ń gbàlà?” Báwo ni Jesu ṣe fèsì? Ó ha sọ pé: ‘Ṣáà gbà mí gẹ́gẹ́ bí Oluwa àti Olùgbàlà rẹ̀, a óò sì gbà ọ́ là bí’? Rárá o! Jesu wí pé: “Ẹ fi tokuntokun tiraka lati gba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé, nitori, mo sọ fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yoo wá ọ̀nà lati wọlé ṣugbọn wọn kì yoo lè ṣe bẹ́ẹ̀.”—Luku 13:23, 24.
Jesu ha kùnà láti dáhùn ìbéèrè ọkùnrin yẹn bí? Rárá o, ọkùnrin náà kò béèrè bí yóò ṣe nira tó láti lè rí ìgbàlà; ó béèrè bóyá iye náà yóò kéré. Nítorí náà, Jesu wulẹ̀ fi hàn pé, ìwọ̀nba ènìyàn tí ó kéré níye ju ohun tí ẹnì kan lè retí, yóò tiraka tokunratokunra láti gba ìbùkún àgbàyanu yìí.
Àwọn òǹkàwé kan lè fi ẹ̀hónú hàn pé, ‘Kì í ṣe ohun tí a sọ fún mi nìyẹn. Àwọn wọ̀nyí lè ṣàyọlò Johannu 3:16, tí ó sọ pé: “Nítorí Ọlọrun fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (King James Version) Ṣùgbọ́n, ìdáhùn wa ni pé: ‘Nígbà náà, kí ni a gbọ́dọ̀ gbà gbọ́? Ṣé pé Jesu gbé ayé ní ti gidi? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni. Ṣé pé òún jẹ́ Ọmọkùnrin Ọlọrun? Bẹ́ẹ̀ kúkú ni! Níwọ̀n ìgbà tí Bibeli sì ti pe Jesu ní “Olùkọ́” àti “Oluwa,” kò ha yẹ kí a gba ohun tí ó fi kọ́ni gbọ́, kí a ṣègbọràn sí i, kí a sì tẹ̀ lé e bí?’—Johannu 13:13; Matteu 16:16.
Títẹ̀ lé Jesu
Ẹ̀n-ẹ́n-ẹ̀n o, ibí gan-an ní ìṣòro náà wà! Ó dà bíi pé ọ̀pọ̀ ènìyàn tí a ti sọ fún pé wọ́n “ti rí ìgbàlà” ní èrò díẹ̀ yálà nípa títẹ̀ lé Jesu tàbí ṣíṣe ìgbọràn sí i. Ní tòótọ́, àlùfáà Pùròtẹ́sítáǹtì kan kọ̀wé pé: “Dájúdájú, ìgbàgbọ́ wa nínú Kristi yẹ kí ó máa bá a nìṣó. Ṣùgbọ́n ìjẹ́wọ́ náà pé ó gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó, tàbí pé ó pọn dandan kí ó rí bẹ́ẹ̀, kò ní ìtìlẹyìn rárá nínú Bibeli.”
Ní òdì kejì, Bibeli to àwọn àṣà àìmọ́ tí ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ènìyàn kan tí wọ́n rò pé àwọ́n “ti rí ìgbàlà” lẹ́sẹẹsẹ. Nípa ẹnì kan tí ó bá ń bá a lọ nínú irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀, ó kìlọ̀ fún àwọn Kristian pé: “Ẹ mú ènìyàn burúkú naa kúrò láàárín ara yín.” Dájúdájú, Ọlọrun kì yóò fẹ́ kí àwọn ènìyàn burúkú ba ìjọ Kristian jẹ́!—1 Korinti 5:11-13.
Nígbà náà, kí ni ó túmọ̀ sí láti tẹ̀ lé Jesu, báwo ni a si ṣe lè ṣe ìyẹn? Ó dára, kí ni Jesu ṣe? Ṣé oníwà àìmọ́? alágbèrè? ọ̀mùtípara? òpùrọ́ ni? Ó ha jẹ́ alábòsí nínú iṣẹ́ ajé bí? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ kọ́! O lè béèrè pé, ‘ṣùgbọ́n mo ha ní láti mú gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn kúrò nínú ìgbésí ayé mi bí?’ Fún ìdáhùn, gbé Efesu 4:17 sí 5:5 yẹ̀ wò. Kò sọ pé Ọlọrun yóò tẹ́wọ́ gbà wá láìka ohun yòówù tí a bá ṣe sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ fun wa pé, kí a yàtọ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè ayé tí wọ́n “ń rìn ninu àìlérè èrò-inú wọn, . . . ṣugbọn ẹ̀yin kò kẹ́kọ̀ọ́ Kristi bẹ́ẹ̀ . . . Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ èyí tí ó bá ìlà ipa-ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé . . . Kí ẹni tí ń jalè máṣe jalè mọ́ . . . Kí a má tilẹ̀ mẹ́nukan àgbèrè ati ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tabi ìwà ìwọra láàárín yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ awọn ènìyàn mímọ́ . . . Nitori ẹ̀yin mọ èyí, ní mímọ̀ ọ́n dájú fúnra yín, pé kò sí àgbèrè kankan tabi aláìmọ́ tabi oníwọra—èyí tí ó túmọ̀ sí jíjẹ́ abọ̀rìṣà—tí ó ní ogún èyíkéyìí ninu ìjọba Kristi ati ti Ọlọrun.”
A ha ń tẹ̀ lé Jesu bí a kò bá gbìyànjú, bí ó ti wù kí ó mọ, láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àpẹẹrẹ rẹ̀? Kò ha yẹ kí a ṣiṣẹ́ lórí mímú kí ìgbésí ayé wa jọ ti Kristi bí? Àwọn ènìyàn tí ń sọ bí ìwé àṣàrò kúkúrú àwọn onísìn kan ti sọ, pé: “Wá sọ́dọ̀ Kristi nísinsìnyí—bí o ṣe wà gan-an,” kì í sábà gbé ìbéèrè pàtàkì yẹn yẹ̀ wò, bí wọ́n bá tilẹ̀ fìgbà kan ṣe bẹ́ẹ̀ rí.
Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jesu kìlọ̀ pé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọrun “ń sọ inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọrun wa di àwáwí fún ìwà àìníjàánu tí wọ́n sì jásí èké sí Ẹni kanṣoṣo naa tí ó ni wá tí ó sì jẹ́ Oluwa wa, Jesu Kristi.” (Juda 4) Ní tòótọ́, báwo ni a ṣe lè sọ àánú Ọlọrun “di àwáwí fún ìwà àìníjàánu”? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa rírò pé ẹbọ Kristi kájú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá tí a lérò láti máa dá lọ, dípò àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àìpé ẹ̀dá ènìyàn tí a ń gbìyànjú láti fi sílẹ̀. Dájúdájú, a kì yóò fẹ́ láti fara mọ́ ọ̀kan lára àwọn ajíhìnrere tí a mọ̀ jú lọ ní America, tí ó sọ pé o kò ní lati “ṣe ìyípadà nínú ìgbésí ayé rẹ, tàbí pa ìwà burúkú tì, tàbí yí padà láti baà lè pa àwọn ìlànà Bibeli mọ́.”—Fi wé Ìṣe 17:30; Romu 3:25; Jakọbu 5:19, 20.
Ìgbàgbọ́ Ń Súnni Gbé Ìgbésẹ̀
A ti sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn pé, “gbígba Jesu gbọ́” wulẹ̀ jẹ́ ìṣe kan àti pé kì í ṣe dandan kí ìgbàgbọ́ wa lágbára tó, láti súnni ṣe ìgbọràn. Ṣùgbọ́n Bibeli kò gbà bẹ́ẹ̀. Jesu kò sọ pé, àwọn ènìyàn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ipa ọ̀nà Kristian ti rí ìgbàlà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wí pé: “Ẹni tí ó bá ti faradà á dé òpin ni ẹni naa tí a óò gbàlà.” (Matteu 10:22) Bibeli fi ipa ọ̀nà Kristian wa wé eré ìje, tí ìgbàlà sì jẹ́ ẹ̀bùn tí ó wà ní òpin rẹ̀. Ó sì rọni pé: “Ẹ sáré ní irúfẹ́ ọ̀nà bẹ́ẹ̀ kí ọwọ́ yín lè tẹ̀ ẹ́.”—1 Korinti 9:24.
Nípa báyìí, “gbígba Kristi” ní nínú ju wíwulẹ̀ gba àwọn ìbùkún tí ẹbọ aláìlẹ́gbẹ́ ti Jesu fúnni. Ó ń béèrè ìgbọràn. Aposteli Peteru sọ pé ìdájọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ “ní ilé Ọlọrun,” ó sì fi kún un pé: “Bí ó bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ wa, kí ni yoo jẹ́ òpin awọn wọnnì tí kò ṣègbọràn sí ìhìnrere Ọlọrun?” (1 Peteru 4:17) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ ṣe ju wíwulẹ̀ gbọ́, kí a sì gbà gbọ́. Bibeli sọ pé, a gbọ́dọ̀ “di olùṣe ọ̀rọ̀ naa, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan, ní fífi ìgbèrò èké tan [ara wa] jẹ.”—Jakọbu 1:22.
Ìhìn Iṣẹ́ ti Jesu Fúnra Rẹ̀
Ìwé Ìṣípayá nínú Bibeli ní àwọn ìhìn iṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ Jesu nínú, tí a tipasẹ̀ Johannu ta látaré sí àwọn ìjọ méje ti Kristian ní ìjímìjí. (Ìṣípayá 1:1, 4) Jesu ha sọ pé, níwọ̀n bí àwọn ènìyàn nínú àwọn ìjọ wọ̀nyí ti “gba” òun, ìyẹn ti tó bí? Rárá o. Ó buyìn fún ìṣe, akitiyan àti ìfaradà wọn, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́, ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Ṣùgbọ́n ó wí pé, Èṣù yóò dán wọn wò, àti pé, a óò san èrè fún wọn “lẹ́nìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ [wọn].”—Ìṣípayá 2:2, 10, 19, 23.
Nípa báyìí, Jesu ṣàpèjúwe ohun àìgbọdọ̀máṣe kan tí ó ga fíìfíì ju ohun tí púpọ̀ jù lọ nínú àwọn ènìyàn lóye nígbà tí a sọ fún wọn pé ìgbàlà wọn jẹ́ “iṣẹ́ tí a ti parí” gbàrà tí wọ́n bá ti “gba” Jesu níbi ìpàdé ìsìn kan. Jesu wí pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀ kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀ kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo. Nitori ẹni yòówù tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là yoo pàdánù rẹ̀; ṣugbọn ẹni yòówù tí ó bá pàdánù ọkàn rẹ̀ nitori mi yoo rí i.”—Matteu 16:24, 25.
Pé kí a sẹ́ ara wa? Pé kí a máa tẹ̀ lé Jesu nígbà gbogbo? Ìyẹn yóò béèrè ìsapá. Yóò yí ìgbésí ayé wa padà. Síbẹ̀, Jesu ha sọ ní tòótọ́ pé, àwa kan yóò ní láti ‘pàdánù ẹ̀mí wa’—pé a ní láti kú fún un bí? Bẹ́ẹ̀ ni, irú ìgbàgbọ́ yẹn máa ń wá kìkì nípa ìmọ̀ àwọn ohun ńláǹlà tí o lè kọ́ láti inú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ó hàn gbangba ní ọjọ́ tí àwọn agbawèrèmẹ́sìn tí wọn “kò . . . lè di ipò-àyè wọn mú lòdì sí ọgbọ́n ati ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀,” sọ Stefanu ní òkúta. (Ìṣe 6:8-12; 7:57-60) Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ni ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí wọ́n kú sínú àwọn ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Nazi, ti fi hàn ní àkókò wa, dípò tí wọn ì bá fi ṣẹ̀ sí ẹ̀rí ọkàn wọn tí a fi Bibeli dá lẹ́kọ̀ọ́.a
Ìtara Kristian
A gbọ́dọ̀ dúró gbọn-in gbọn-in ti ìgbàgbọ́ Kristian wa nítorí pé, ní ìyàtọ̀ sí ohun tí o lè gbọ́ ní àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan tàbí lórí àwọn ètò ìjọsìn orí tẹlifíṣọ̀n, Bibeli sọ pé, a lè ṣubú. Ó sọ nípa àwọn Kristian tí wọ́n pa “ipa ọ̀nà títọ́” tì. (2 Peteru 2:1, 15) Nípa báyìí, a ní láti ‘máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà wa yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.’—Filippi 2:12; 2 Peteru 2:20.
Ǹjẹ́ báyìí ni àwọn Kristian ọ̀rúndún kìíní, àwọn ènìyàn tí wọ́n gbọ́ ẹ̀kọ́ Jesu àti ti àwọn aposteli rẹ̀ ní ti gidi, ṣe lóye ọ̀ràn náà bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Wọ́n mọ̀ pé, wọ́n ní láti ṣe ohun kan. Jesu wí pé: “Nitori naa ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn lati máa pa gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún yín mọ́.”—Matteu 28:19, 20.
Oṣù méjì lẹ́yìn tí Jesu sọ ìyẹn, 3,000 ènìyàn ṣe batisí ní ọjọ́ kan ṣoṣo. Iye àwọn onígbàgbọ́ lọ sókè kíá sí 5,000. Àwọn tí wọ́n gbà gbọ́ kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Nígbà tí inúnibíni fọ́n wọn ká, ó wulẹ̀ ṣèrànwọ́ láti tan ìhìn iṣẹ́ wọn kálẹ̀ ni. Bibeli sọ pé, kì í ṣe àwọn aṣáájú díẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n “awọn wọnnì tí a túká la ilẹ̀ naa já, wọ́n ń polongo ìhìnrere ọ̀rọ̀ naa.” Nǹkan bí 30 ọdún lẹ́yìn náà, aposteli Paulu lè kọ lẹ́tà pé, a ti “wàásù” ìhìn rere náà “ninu gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.”—Ìṣe 2:41; 4:4; 8:4; Kolosse 1:23.
Paulu kò yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, bí àwọn ajíhìnrere orí tẹlifíṣọ̀n kan ti ń ṣe, nípa sísọ pé: ‘Gba Jesu nísinsìnyí, a óò sì gbà ọ́ là títí láé.’ Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìgbọ́kànlé tí àlùfáà ará America náà ní, ẹni tí ó kọ̀wé pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọmọdékùnrin ọ̀dọ́langba kan, . . . a ti gbà mí là.” Ní ohun tí ó lé ní 20 ọdún lẹ́yìn ìgbà tí Jesu fúnra rẹ̀ yan Paulu láti mú ìhìn iṣẹ́ Kristian tọ àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè lọ, aposteli òṣìṣẹ́kára yìí kọ̀wé pé: “Emi ń lu ara mi kíkankíkan mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú, pé, lẹ́yìn ti mo bá ti wàásù fún awọn ẹlòmíràn, kí emi fúnra mi má baà di ẹni tí a kò fi ojúrere tẹ́wọ́gbà lọ́nà kan ṣáá.”—1 Korinti 9:27; Ìṣe 9:5, 6, 15.
Ìgbàlà jẹ́ ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. A kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i. Síbẹ̀, ó ń béèrè ìsapá níhà ọ̀dọ̀ wa. Bí ẹnì kan bá fún ọ ní ẹ̀bùn tí ó níye lórí gidigidi, tí ìwọ kò sì fi ìmọrírì tí ó tó hàn láti mú un, kí o sì sọ ọ́ di tìrẹ, ìwà àìmoore rẹ lè sún ẹni tí ó fún ọ náà láti fi fún ẹlòmíràn. Tóò, báwo ni ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi ṣe níye lórí tó? Ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ni, ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fún un.
Àwọn Kristian tòótọ́ wà ní ipò àìléwu ní ti pé, wọ́n wà ní ipò ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọrun. Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, ìgbàlà wọn dájú. Lẹ́nìkọ̀ọ̀kan, wọ́n gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ọlọrun ń béèrè. Ṣùgbọ́n, a lè kùnà, nítorí Jesu wí pé: “Bí ẹnikẹ́ni kò bá dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu mi, a óò ya á dànù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kan a sì gbẹ.”—Johannu 15:6.
“Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Wà Láàyè”
Ìjíròrò tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ti ó ṣáájú wáyé ní nǹkan bí 60 ọdún sẹ́yìn. Johnny ṣì gbà gbọ́ pé, ìgbàlà ń wá nípasẹ̀ Jesu Kristi nìkan, ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé, a ní láti nàgà fún un. Ó dá a lójú pé, Bibeli tọ́ka sí orísun tòótọ́ kan ṣoṣo ti ìrètí fún aráyé àti pé, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ìwé àgbàyanu yẹn, kí ó sún wa ṣiṣẹ́, kí a sì jẹ́ kí ó sún wa sí àwọn ìṣe onífẹ̀ẹ́, onígbàgbọ́, onínúrere, onígbọràn àti onífaradà. Ó ti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà láti gbà ohun kan náà gbọ́, inú rẹ̀ sì ń dùn nísinsìnyí, láti rí wọn tí àwọn náà ń tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà lọ́nà kan náà. Ó dàníyàn pé, kí gbogbo ènìyàn ní irú ìgbàgbọ́ yẹn, ó sì ń ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe láti tẹ̀ ẹ́ mọ ọkàn àti ìrònú àwọn ẹlòmíràn.
A mí sí aposteli Paulu láti kọ̀wé pé, “ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè ó sì ń sa agbára.” (Heberu 4:12) Ó lè yí ìgbésí ayé padà. Ó lè sún ọ sí àwọn ìṣe onífẹ̀ẹ́, onígbàgbọ́ àti onígbọràn tí ó jẹ́ látọkànwá. Ṣùgbọ́n, o gbọ́dọ̀ ṣe ju wíwulẹ̀ “gba” ohun tí Bibeli sọ ní ti èrò orí lọ. Kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, kí o sì jẹ́ kí ó sún ọkàn-àyà rẹ ṣiṣẹ́. Jẹ́ kí ọgbọ́n rẹ̀ ṣamọ̀nà rẹ. Nǹkan bí 5,000,000 Ẹlẹ́rìí fún Jehofa, tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́mìí ìmúratán, ní àwọn ilẹ̀ tí ó lé ní 230 ń fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ lọni. Láti mọ ohun tí o lè kọ́ láti inú irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀, kọ̀wé sí àwọn tí ó tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde. Ìgbàgbọ́ àti okun tẹ̀mí tí ìwọ yóò jèrè, yóò mú inú rẹ dùn!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú ìwé rẹ̀, The Nazi State and the New Religions: Five Case Studies in Non-Conformity, Ọ̀mọ̀wé Christine E. King ròyìn pé: “A fi ìdajì àwọn Ẹlẹ́rìí [Jehofa] tí ó jẹ́ ará Germany sẹ́wọ̀n, ìdámẹ́rin nínú wọn sì pàdánù ẹ̀mí wọn.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Èé Ṣe Tí A Gbọ́dọ̀ “Máa Ja Ìjà Líle Fún Ìgbàgbọ́”?
A kọ ìwé Juda nínú Bibeli sí “awọn ẹni tí a pè . . . , tí a sì fi ààbò pamọ́ fún Jesu Kristi.” Ó ha sọ pé nítorí tí wọ́n ti ‘gba Jesu,’ ìgbàlà wọn ti dájú bí? Rárá o, Juda sọ fún irú àwọn Kristian bẹ́ẹ̀ láti “máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́.” Ó fún wọn ní ìdí mẹ́ta fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́ ni pé, Ọlọrun “gba awọn ènìyàn kan là kúrò ní ilẹ̀ Egipti,” ṣùgbọ́n, púpọ̀ nínú wọn ṣubú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Èkejì, àwọn áńgẹ́lì pàápàá dìtẹ̀, wọ́n sì di ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀kẹta, Ọlọrun pa Sodomu àti Gomorra run nítorí ìwà pálapàla takọtabo búburú jáì tí a ń hù ní àwọn ìlú wọ̀nyẹn. Juda gbé àwọn àkọsílẹ̀ Bibeli wọ̀nyí kalẹ̀ “gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ akininílọ̀.” Àní, àwọn onígbàgbọ́ pàápàá “tí a . . . fi ààbò pamọ́ fún Jesu Kristi” ní láti ṣọ́ra, kí wọ́n má baà ṣubú kúrò nínú ìgbàgbọ́ tòótọ́.—Juda 1-7.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
Èwo Ni Ó Tọ̀nà?
Bibeli sọ pé: “A ń polongo ènìyàn ní olódodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ láìka awọn iṣẹ́ òfin sí.” Ó tún sọ pé: “A óò polongo ènìyàn kan ní olódodo nipa awọn iṣẹ́, kì í sì í ṣe nipa ìgbàgbọ́ nìkan.” Èwo ni ó tọ̀nà? Ǹjẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ni a polongo wa ní olódodo, tàbí nípasẹ̀ iṣẹ́?—Romu 3:28; Jakọbu 2:24.
Ìdáhùn tí ó fohùn ṣọ̀kan láti inú Bibeli ni pé, méjèèjì ni ó tọ̀nà.
Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, Òfin tí Ọlọrun fúnni nípasẹ̀ Mose béèrè pé kí àwọn Júù olùjọsìn ṣe àwọn ìrúbọ àti ẹbọ pàtó, kí wọ́n pa àwọn ọjọ́ àjọ̀dún mọ́, kí wọ́n sì tẹ̀ lé àwọn ohun àbéèrèfún ní ti oúnjẹ àti nǹkan mìíràn. Irú “awọn iṣẹ́ òfin” bẹ́ẹ̀, tàbí ní ṣókí “iṣẹ́,” kò pọn dandan mọ́ lẹ́yìn tí Jesu pèsè ẹbọ pípe rẹ̀.—Romu 10:4.
Ṣùgbọ́n òkodoro òtítọ́ náà pé, ẹbọ gíga jù lọ ti Jesu rọ́pò àwọn iṣẹ́ tí a ṣe lábẹ́ Òfin Mose wọ̀nyí, kò túmọ̀ sí pé a lè ṣàìka àwọn ìtọ́ni Bibeli sí. Ó sọ pé: “Mélòómélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi . . . yoo wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kúrò ninu awọn òkú iṣẹ́ [àtijọ́] kí awa lè ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ fún Ọlọrun alààyè?”—Heberu 9:14.
Báwo ni a ṣe lè “ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ fún Ọlọrun alààyè”? Ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn, Bibeli sọ fún wa pé kí a gbógun ti àwọn iṣẹ́ ti ara, kí a dènà ìwà pálapàla ti ayé, kí a sì yẹra fún àwọn ìdẹkùn rẹ̀. Ó sọ pé: “Ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́,” mú “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹlu ìrọ̀rùn” kúrò, kí o sì “fi ìfaradà sá eré-ìje tí a gbéka iwájú wa, bí a ti ń fi tọkàntara wo Olórí Aṣojú ati Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jesu.” Bibeli sí rọ̀ wá láti má ṣe ‘káàárẹ̀, kí a sì rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn wa.’—1 Timoteu 6:12; Heberu 12:1-3; Galatia 5:19-21.
A kò lẹ́tọ̀ọ́ sí ìgbàlà nípa ṣíṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, nítorí kò sí ẹ̀dá ènìyàn kan tí ó lé ṣe ohun tí ó tó láti yẹ fún irú ìbùkún amúniṣeháà bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, a kò yẹ fún irú ẹ̀bùn pípabambarì yìí, bí a bá kùnà láti fi ìfẹ́ àti ìgbọràn wa hàn nípa ṣíṣe àwọn ohun tí Bibeli sọ pé Ọlọrun àti Kristi ń fẹ́ kí a ṣe. Láìsí iṣẹ́ láti fi ìgbàgbọ́ wa hàn, ìjẹ́wọ́ wa láti tẹ̀ lé Jesu kì yóò dójú ìwọ̀n rárá, nítorí Bibeli sọ ní kedere pé: “Ìgbàgbọ́, bí kò bá ní awọn iṣẹ́, jẹ́ òkú ninu ara rẹ̀.”—Jakọbu 2:17.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, kí ó sì sún ọ ṣiṣẹ́