Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́—Lò Ó Láti Yin Jehofa
“Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ lati inú àpilẹ̀ṣe ti ara rẹ̀ ń wá ògo ti ara rẹ̀; ṣugbọn ẹni naa tí ń wá ògo ẹni tí ó rán an, ẹni yii jẹ́ olóòótọ́.”—JOHANNU 7:18.
1. Nígbà wo àti báwo ni ètò ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ṣe bẹ̀rẹ̀?
ÌMỌ̀ ẹ̀kọ́ ti bẹ̀rẹ̀ látayébáyé. Ìmọ̀ ẹ̀kọ́ bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Jehofa Ọlọrun, Atóbilọ́lá Olùkọ́ni àti Olùdánilẹ́kọ̀ọ́ náà, dá Ọmọkùnrin rẹ̀ àkọ́bí. (Isaiah 30:20; Kolosse 1:15) Ẹnì kan tí ó lè kẹ́kọ̀ọ́ ní tààràtà láti ọ̀dọ̀ Atóbilọ́lá Olùkọ́ni náà fúnra rẹ̀ nìyí! Láàárín àìmọye ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Bàbá náà, Ọmọkùnrin yẹn—tí a wá mọ̀ sí Jesu Kristi—gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ gígadabú nípa àwọn ànímọ́, iṣẹ́ àti àwọn ète Jehofa Ọlọrun. Gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan lórí ilẹ̀ ayé, Jesu lè sọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé: “Emi kò ṣe nǹkankan ní àdáṣe ti ara mi; ṣugbọn gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọnyi.”—Johannu 8:28.
2-4. (a) Ní ìbámu pẹ̀lú Johannu orí 7, àwọn ipò wo ni ó yí wíwà tí Jesu wà níbi Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìsìn ní ọdún 32 Sànmánì Tiwa ká? (b) Èé ṣe tí àwọn Júù fi ṣe kàyéfì nípa agbára ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí Jesu ní?
2 Báwo ni Jesu ṣe lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó gbà? Jálẹ̀ àkókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́ta àti ààbọ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó ṣàjọpín ohun tí ó kọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn láìṣàárẹ̀. Ṣùgbọ́n, òún ṣe èyí pẹ̀lú ète pàtàkì kan lọ́kàn. Kí sì ni ìyẹn? Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ Jesu nínú Johannu orí 7, níbi tí ó ti ṣàlàyé ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti ète ìkọ́ni rẹ̀.
3 Gbé bí ọ̀ràn náà ṣe wáyé yẹ̀ wò. Ó jẹ́ ìgbà ìwọ́wé ọdún 32 ti Sànmánì Tiwa, ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta lẹ́yìn ìbatisí Jesu. Àwọn Júù pé jọ ní Jerusalemu fún Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìsìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjíròrò nípa Jesu ti ń lọ yíká ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ àkọ́kọ́ àjọyọ̀ náà. Jesu lọ sí tẹ́ḿpìlì nígbà tí àjọyọ̀ náà ti dé ìdajì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni. (Johannu 7:2, 10-14) Gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń rí, ó fi hàn pé òún jẹ́ Olùkọ́ títóbi lọ́lá.—Matteu 13:54; Luku 4:22.
4 Johannu orí 7, ẹsẹ 15 sọ pé: “Nitori naa awọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì, wí pé: ‘Bawo ni ọkùnrin yii ṣe ní ìmọ̀ ìwé, nígbà tí kò kẹ́kọ̀ọ́ ní awọn ilé-ẹ̀kọ́?’” O ha mọ ìdí tí ó fi rú wọn lójú bí? Jesu kò lọ sí èyíkéyìí nínú ilé ẹ̀kọ́ àwọn rábì, púrúǹtù ni—lójú ìwòye tiwọn! Síbẹ̀, Jesu lè fi ìrọ̀rùn ṣí àwọn abala Àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́, kí ó sì kà wọ́n. (Luku 4:16-21) Họ́wù, káfíńtà ará Galili yìí tún ń fún wọn ní ìtọ́ni láti inú Òfin Mose! (Johannu 7:19-23) Báwo ni èyí ṣe ṣeé ṣe?
5, 6. (a) Báwo ni Jesu ṣe ṣàlàyé orísun ẹ̀kọ́ rẹ̀? (b) Ní ọ̀nà wo ni Jesu gbà lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀?
5 Jesu ṣàlàyé, gẹ́gẹ́ bí a ti kà ní ẹsẹ 16 àti 17 pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣugbọn ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi. Bí ẹnikẹ́ni bá ní ìfẹ́ ọkàn lati ṣe ìfẹ́ inú Rẹ̀, oun yoo mọ̀ nipa ẹ̀kọ́ naa bóyá lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni tabi mo ń sọ̀rọ̀ lati inú àpilẹ̀ṣe ti ara mi.” Wọ́n fẹ́ mọ ẹni tí ó kọ́ Jesu lẹ́kọ̀ọ́, ó sì sọ fún wọn ní kedere pé, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ òún jẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun!—Johannu 12:49; 14:10.
6 Báwo ni Jesu ṣe lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ ní Johannu 7:18, Jesu wí pé: “Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ lati inú àpilẹ̀ṣe ti ara rẹ̀ ń wá ògo ti ara rẹ̀; ṣugbọn ẹni naa tí ń wá ògo ẹni tí ó rán an, ẹni yii jẹ́ olóòótọ́, kò sì sí àìṣòdodo kankan ninu rẹ̀.” Ẹ wo bí ó ti ṣe wẹ́kú tó pé, Jesu lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ láti mú ògo wá fún Jehofa, “Ẹni tí ó pé ní ìmọ̀”!—Jobu 37:16.
7, 8. (a) Báwo ni a ṣe ní láti lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́? (b) Àwọn ète pàtàkì mẹ́rin wo ní ó wà fún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó wà déédéé?
7 Nípa báyìí, a kọ́ ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye kan láti ọ̀dọ̀ Jesu—a ní láti lo ìmọ̀ ẹ̀kọ, kì í ṣe láti mú ògo wá fún ara wa, ṣùgbọ́n, láti mú ìyìn wá fún Jehofa. Kò sí ọ̀nà míràn tí ó dára jù láti lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́. Nígbà náà, báwo ni o ṣe lè lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ láti mú ìyìn wá fún Jehofa?
8 Láti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ túmọ̀ sí “láti dá lẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ ìtọ́ni tí ó bá àṣà mu àti ìfidánrawò tí a bójú tó ní pàtàkì nínú òye iṣẹ́, òwò, tàbí iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe kan.” Nísinsìnyí, ẹ jẹ́ kí a yẹ àwọn ète pàtàkì mẹ́rin tí ìmọ̀ ẹkọ́ tí ó wà déédéé ní, àti bí a ṣe lè lo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn wọ̀nyí láti yin Jehofa wò. Ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó wà déédéé yẹ kí ó ràn wá lọ́wọ́ (1) láti kàwé lọ́nà jíjá gaara, (2) láti kọ̀wé lọ́nà tí ó ṣeé kà, (3) láti dàgbà sókè ní ti èrò orí àti ìwà híhù, àti (4) láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ gbígbéṣẹ́, tí a nílò fún ìgbésí ayé ojoojúmọ́.
Kíkọ́ Láti Kàwé Lọ́nà Jíjá Gaara
9. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti jẹ́ òǹkàwé jíjá gaara?
9 Èkíní ni, kíkọ́ láti kàwé lọ́nà jíjá gaara. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ láti jẹ́ òǹkàwé jíjá gaara? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ṣàlàyé pé: “Ìwé kíkà . . . ṣe pàtàkì fún ẹ̀kọ́ kíkọ́, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára òye iṣẹ́ pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́. . . . Àwọn òǹkàwé tí wọ́n dáńgájíá ń mú kí ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ àwùjọ tí ó láásìkí, tí ó sì ń méso jáde ṣeé ṣe. Àwọn pẹ̀lú, nígbà kan náà, ń gbádùn ìgbésí ayé tí ó kún fún ìrírí, tí ó sì túbọ̀ ń tẹ́ni lọ́rùn.”
10. Báwo ni kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbádùn ìgbésí ayé wa lọ́nà tí ó kún fún ìrírí, tí ó sì tẹ́ni lọ́rùn sí i?
10 Bí ìwé kíkà ní gbogbogbòò bá lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbádùn “ìgbésí ayé tí ó kún fún ìrírí, tí ó sì túbọ̀ ń tẹ́ni lọ́rùn,” ẹ wo bí èyí ti jẹ́ òtítọ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ tó nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun! Irú ìwé kíkà bẹ́ẹ̀ ń ṣí iyè inú àti ọkàn-àyà wa payá sí àwọn èrò àti ète Jehofa, lílóye ìwọ̀nyí ní kedere sì ń mú kí ìgbésí ayé wa ní ìtumọ̀. Ní àfikún sí i, Heberu 4:12 sọ pé, “ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè ó sì ń sa agbára.” Bí a ti ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí a sì ń ṣàṣàrò lórí rẹ̀, a ń fà wá sún mọ́ Òǹkọ̀wé rẹ̀, a sì ń sún wa láti ṣe àwọn ìyípadà nínú ìgbésí ayé wa, kí a baà lè wù ú sí i. (Galatia 5:22, 23; Efesu 4:22-24) A tún ń sún wa láti ṣàjọpín àwọn òtítọ́ ṣíṣeyebíye tí a kà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Gbogbo èyí ń mú ìyìn bá Atóbilọ́lá Olùkọ́ni náà, Jehofa Ọlọrun. Ó dájú pé, kò sí ọ̀nà míràn tí ó dára ju èyí lọ láti lo agbára ìkàwé wa!
11. Kí ni ó yẹ kí a fi kún ètò ìdákẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà déédéé?
11 Yálà a jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà, a rọ̀ wá láti kọ́ láti kàwé lọ́nà jíjá gaara, nítorí pé, ìwé kíkà ń kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé Kristian wa. Ní àfikún sí kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun déédéé, ó yẹ kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìdákẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà déédéé ní gbígbé ẹsẹ Bibeli yẹ̀ wò láti inú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́, kíkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!, àti mímúra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé wa nínú. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian wa ńkọ́? Ó ṣe kedere pé, wíwàásù ní gbangba, ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn, àti dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé, gbogbo rẹ̀ ń béèrè agbára ìkàwé tí ó já gaara.
Kíkọ́ Láti Kọ̀wé Lọ́nà Tí Ó Ṣeé Kà
12. (a) Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti kọ́ láti kọ̀wé lọ́nà tí ó ṣeé kà? (b) Ìkọ̀wé pípegedé jù lọ wo ni a tí ì ṣe rí?
12 Ète kejì ni pé, ó yẹ kí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó wà déédéé ràn wá lọ́wọ́ láti kọ̀wé lọ́nà tí ó ṣeé kà. Kì í ṣe kìkì pé ìwé kíkọ ń gbé ọ̀rọ̀ àti èrò wa jáde nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń pa wọ́n mọ́. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, àwọn ọkùnrin Júù bí 40 kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí o wá di Ìwé Mímọ́ onímìísí sórí bébà pápírọ́ọ̀sì tàbí awọ. (2 Timoteu 3:16) Dájúdájú, èyí jẹ́ ìkọ̀wé títóbi lọ́lá jù lọ tí a tí ì ṣe rí! Láìsí iyè méjì, Jehofa dáàbò bo ṣíṣe àdàkọ àti àtúndàkọ àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ wọnnì jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún, tí wọ́n fi dé ọ̀dọ̀ wa ní ọ̀nà tí ó ṣeé gbára lé. A kò ha kún fún ọpẹ́ pé Jehofa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà ní kíkọ sílẹ̀, dípò gbígbára lé títa á látaré látẹnudẹ́nu bí?—Fi wé Eksodu 34:27, 28.
13. Kí ni ó fi hàn pé àwọn ọmọ Israeli mọ̀wé kọ?
13 Ní ìgbà àtijọ́, kìkì àwọn kan tí wọ́n rí já jẹ ni wọ́n mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, irú bí àwọn akọ̀wé ní Mesopotamia àti Egipti. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ti àwọn orílẹ̀-èdè, a fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní Israeli níṣìírí láti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Àṣẹ náà fún àwọn ọmọ Israeli, nínú Deuteronomi 6:8, 9, láti kọ̀wé sára òpó ìlẹ̀kùn ilé wọn, bí ó tilẹ̀ hàn gbangba pé, ó jẹ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, dọ́gbọ́n túmọ̀ sí pé, wọ́n mọ̀wé kọ. A kọ́ àwọn ọmọ láti mọ̀wé kọ nígbà tí wọ́n ṣì kéré. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan lérò pé, Kàlẹ́ńdà Gezer, tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àpẹẹrẹ ìkọ̀wé Heberu ìgbàanì tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ, jẹ́ eré ìdárayá àkọ́sórí fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́.
14, 15. Kí ni àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí ó dára, tí ó sì gbámúṣé láti lo agbára ìkọ̀wé wa?
14 Ṣùgbọ́n, báwo ni a ṣe lè lo agbára ìkọ̀wé wa ní ọ̀nà tí ó ṣàǹfààní, tí ó sì gbámúṣé? Dájúdájú, ó jẹ́ nípa kíkọ àkọsílẹ̀ ní àwọn ìpàdé, àpéjọ, àti àpéjọpọ̀ Kristian. Kódà, lẹ́tà “onígbólóhùn ṣókí” kan tí a kọ, lè fún ẹnì kan tí ń ṣàìsàn ní ìṣírí, tàbí kí ó dúpẹ́ lọ́wọ́ arákùnrin tàbí arábìnrin kan nípa tẹ̀mí tí ó fi inú rere tàbí aájò àlejò hàn sí wa. (1 Peteru 5:12) Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan nínú ìjọ ti pàdánù olólùfẹ́ kan nínú ikú, lẹ́tà ṣókí tàbí káàdì kan lè “gbẹnu sọ lọ́nà tí ń tuni nínú” fún wa. (1 Tessalonika 5:14) Kristian arábìnrin kan tí àrùn jẹjẹrẹ pa ìyá rẹ̀ ṣàlàyé pé: “Ọ̀rẹ́ kan kọ lẹ́tà àtàtà sí mí. Ìyẹn ṣèrànlọ́wọ́ ní ti gidi nítorí pé, mo lè kà á ní àkàtúnkà.”
15 Ọ̀nà kan tí ó ta yọ lọ́lá jù lọ láti lo agbára ìkọ̀wé láti mú ìyìn wá fún Jehofa jẹ́ nípa kíkọ lẹ́tà kan láti fúnni ní ìjẹ́rìí Ìjọba. Nígbà míràn, ó lè pọn dandan láti máa ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn tuntun tí wọ́n ń gbé ní àwọn ibi àdádó gan-an. Àìsàn lè mú kí ó ṣòro fún ọ láti lọ láti ilé dé ilé fún ìgbà díẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí lẹ́tà sọ ohun tí ìwọ fúnra rẹ ì bá fi ẹnu sọ.
16, 17. (a) Ìrírí wo ni ó fi ìníyelórí kíkọ lẹ́tà láti jẹ́rìí Ìjọba fúnni hàn? (b) O ha lè sọ irú ìrírí bẹ́ẹ̀ bí?
16 Gbé ìrírí kan yẹ̀ wò. Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Ẹlẹ́rìí kan kọ lẹ́tà kan tí ń fúnni ní ìjẹ́rìí Ìjọba sí obìnrin opó kan, tí a kéde ikú ọkọ rẹ̀ nínú ìwé ìròyìn àdúgbò náà. Kò sí èsì kankan. Lẹ́yìn náà, ní November 1994, èyí tí ó ti lé ní ọdún 21 lẹ́yìn ìgbà yẹn, Ẹlẹ́rìí náà rí lẹ́tà kan gbà láti ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin obìnrin ọjọ́sí. Ọmọbìnrin náà kọ̀wé pé:
17 “Ní April 1973, ẹ kọ̀wé sí ìyá mi láti tù wọ́n nínú lẹ́yìn ikú bàbá mi. Mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ní àkókò náà. Ìyá mi kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ṣùgbọ́n, títí di ìsinsìnyí, wọn kò tí ì di ìránṣẹ́ Jehofa. Ṣùgbọ́n, ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn ṣamọ̀nà mi sínú òtítọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ní 1988, mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli mi—ọdún 15 lẹ́yìn gbígba lẹ́tà yín. Mo ṣe batisí ní March 9, 1990. Mo dúpẹ́ gidigidi fún lẹ́tà yín tí ẹ kọ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, mo sì láyọ̀ láti jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé àwọn irúgbìn tí ẹ fún ti dàgbà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jehofa. Ìyá mi fún mi ní lẹ́tà yín láti tọ́jú rẹ̀, èmi yóò sì fẹ́ láti mọ̀ yín. Mo nírètí pé lẹ́tà yìí yóò dé ọ̀dọ̀ yín.” Lẹ́tà ọmọbìnrin náà, tí ó ní àdírẹ́sì àti nọ́ḿbà fóònù rẹ̀ nínú, dé ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́rìí náà tí ó kọ̀wé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú. Finú wòye ìyàlẹ́nu ọ̀dọ́bìnrin náà, nígbà tí ó gba ìkésíni orí fóònù láti ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́rìí náà—ẹni tí ó ṣì ń kọ lẹ́tà láti ṣàjọpín ìrètí Ìjọba náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn!
Dídàgbà Ní Ti Èrò Orí, Ìwà Híhù, àti Nípa Tẹ̀mí
18. Ní àwọn àkókò tí a kọ Bibeli, báwo ni àwọn òbí ṣe bójú tó ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ti èrò orí àti ìwà híhù?
18 Ète kẹta ni pé, ó yẹ kí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó wà déédéé ràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà sókè ní ti èrò orí àti ìwà híhù. Ní àwọn àkókò tí a kọ Bibeli, a ka kíkọ́ àwọn ọmọ ní ẹ̀kọ́ èrò orí àti ìwà rere sí ojúṣe àkọ́kọ́ fún àwọn òbí. Kì í ṣe kìkì pe a kọ́ àwọn ọmọ láti mọ̀ọ́kọ, mọ̀ọ́kà nìkan ni, ṣùgbọ́n ní pàtàkì jù, a tún fi Òfin Ọlọrun, tí ó ní gbogbo ìgbòkègbodò ìgbésí ayé wọn nínú kọ́ wọn. Nípa báyìí, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ní ìtọ́ni nípa àwọn ojúṣe wọn ní ti ìsìn, àwọn ìlànà tí ń ṣàkóso ìgbéyàwó, ipò ìbátan ìdílé, àti ìwà rere takọtabo, àti àwọn ojúṣe wọn sí ọmọnìkejì wọn nínú. Kì í ṣe pé irú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dàgbà sókè ní ti èrò orí àti ìwà rere nìkan ni, ṣùgbọ́n nípa tẹ̀mí pẹ̀lú.—Deuteronomi 6:4-9, 20, 21; 11:18-21.
19. Níbo ni a ti lè rí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó fi àwọn ìlànà ìwà híhù dídára jù lọ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀, tí ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí hàn?
19 Lónìí ńkọ́? Ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ayé, tí ó dára ṣe pàtàkì. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà sókè ní ti èrò orí. Ṣùgbọ́n, ibo ni a lè yíjú sí fún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó lè fi ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere tí ó dára jù lọ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀ hàn wá, tí yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà sókè nípa tẹ̀mí? Láàárín ìjọ Kristian, a ní ètò ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ti ìṣàkóso Ọlọrun, èyí tí kò sí ní ibòmíràn lórí ilẹ̀ ayé. A lè gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ aláìṣeédíyelé tí ń lọ lọ́wọ́ yìí—ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá—lọ́fẹ̀ẹ́ nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bibeli, pa pọ̀ pẹ̀lú ìtọ́ni tí a ń pèsè ní àwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ, àti àpéjọpọ̀! Kí ni ohun tí ó ń kọ́ wa?
20. Kí ni ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń kọ́ wa, kí sì ni àwọn ìyọrísí rẹ̀?
20 Nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, a kọ́ àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́, “àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́.” (Heberu 6:1) Bí a ṣe ń tẹ̀ síwájú, a ń gba “oúnjẹ líle” sínú—ìyẹn ni, òtítọ́ jíjinlẹ̀. (Heberu 5:14) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a tún ń kọ́ àwọn ìlànà Ọlọrun, èyí tí ń kọ́ wa bí a ṣe ní láti máa gbé bí Ọlọrun ṣe ń fẹ́ kí a gbé. Fún àpẹẹrẹ, a kọ́ láti yẹra fún àwọn ìwà àti ìṣe tí ‘ń sọ ẹran ara di ẹlẹ́gbin’ àti láti ní ọ̀wọ̀ fún àṣẹ àti fún ara ènìyàn àti ohun ìní àwọn ẹlòmíràn. (2 Korinti 7:1; Titu 3:1, 2; Heberu 13:4) Ní àfikún sí i, a wá mọrírì ìjẹ́pàtàkì jíjẹ́ aláìlábòsí àti aláápọn nínú iṣẹ́ wa àti ìníyelórí gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Bibeli lórí ìwà rere takọtabo. (1 Korinti 6:9, 10; Efesu 4:28) Bí a ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú mímú àwọn ìlànà wọ̀nyí lò nínú ìgbésí ayé wa, a ń dàgbà sókè nípa tẹ̀mí, ipò ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọrun sì túbọ̀ ń jinlẹ̀ sí i. Síwájú sí i, ìwà-bí-Ọlọ́run wa ń sọ wa di ọmọọ̀lú rere, láìka ibi yòówù tí a lè máa gbé sí. Èyí sì lè sún àwọn ẹlòmíràn láti fògo fún Orísun ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá—Jehofa Ọlọrun.—1 Peteru 2:12.
Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Gbígbéṣẹ́ fún Ìgbésí Ayé Ojoojúmọ́
21. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ gbígbéṣẹ́ wo ní àwọn ọmọ́ rí gbà ní àwọn àkókò tí a kọ Bibeli?
21 Ète kẹrin ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó wà déédéé jẹ́, láti fún ẹnì kan ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ gbígbéṣẹ́ tí ó nílò fún ìgbésí ayé ojoojúmọ́. Ní àwọn àkókó tí a kọ Bibeli, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí òbí ń fúnni ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ gbígbéṣẹ́ nínú. A kọ́ àwọn ọmọbìnrin ní ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ ilé. Orí tí ó kẹ́yìn ìwé Owe fi hàn pé, ìwọ̀nyí ní láti pọ̀, kí wọ́n sì jẹ́ onírúurú. Nípa báyìí, a mú àwọn ọmọbìnrin gbara dì láti rànwú, hun aṣọ, gbọ́únjẹ, kí wọ́n sì bójú tó ìtọ́jú ilé, ìṣòwò, àti ríra ilé àti ilẹ̀. A sábà máa ń kọ́ àwọn ọmọkùnrin ní iṣẹ́ ọwọ́ bàbá wọn, ì báà jẹ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ tàbí òwò tàbí iṣẹ́ ọnà. Jesu kọ́ iṣẹ́ káfíńtà láti ọ̀dọ̀ bàbá tí ó jẹ́ alágbàtọ́ rẹ̀, Josẹfu; nípa báyìí, kì í ṣe pé a pè é ní “ọmọkùnrin káfíńtà” nìkan ni, ṣùgbọ́n, a tún pè é ní “káfíńtà” pẹ̀lú.—Matteu 13:55; Marku 6:3.
22, 23. (a) Kí ni ìmọ̀ ẹ̀kọ́ yẹ kí ó múra àwọn ọmọ sílẹ̀ fún? (b) Kí ni ó yẹ kí ó jẹ́ ète ìsúnniṣe wa ní yíyan àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ nígbà tí ó bá dà bíi pé ó pọn dandan?
22 Bákan náà lónìí, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó wà déédéé gan-an ní ìmúrasílẹ̀ láti gbọ́ bùkátà ìdílé nígbà tí ó bá yá nínú. Ọ̀rọ̀ aposteli Paulu, tí a rí ní 1 Timoteu 5:8, fi hàn pé, pípèsè fún ìdílé ẹni jẹ́ ojúṣe mímọ́ ọlọ́wọ̀. Ó kọ̀wé pé: “Dájúdájú bí ẹni kan kò bá pèsè fún awọn wọnnì tí wọ̀n jẹ́ tirẹ̀, ati ní pàtàkì fún awọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà agbo ilé rẹ̀, oun ti sẹ́ níní ìgbàgbọ́ ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” Nítorí náà, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ yẹ kí ó múra àwọn ọmọ sílẹ̀ fún àwọn ẹrù iṣẹ́ tí wọn yóò tẹ́wọ́ gbà nínú ìgbésí ayé lọ́jọ́ ọ̀la, kí ó sì mú wọn gbara dì láti di mẹ́ḿbà aṣiṣẹ́kára láwùjọ.
23 Báwo ni ó ṣe yẹ kí a lépa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ayé tó? Èyí lè yàtọ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí èkejì. Ṣùgbọ́n bí àtiríṣẹ́ bá béèrè fún àfikún ìdálẹ́kọ̀ọ́ sí ìwọ̀nba èyí tí òfín béèrè, ó kù sọ́wọ́ àwọn òbí láti darí àwọn ọmọ wọn nínú ṣíṣe ìpinnu nípa àlékún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tàbí ìdálẹ́kọ̀ọ́, ní gbígbé àwọn àǹfààní àti ìfàsẹ́yìn tí ó ṣeé ṣe kí irú àfikún ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ mú wá yẹ̀ wò. Ṣùgbọ́n, kí ni ó yẹ kí ó jẹ́ ète ìsúnniṣe ẹnì kan ní yíyan àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ nígbà tí ìyẹn bá dà bíi pé ó pọn dandan? Dájúdájú kì í ṣe ọrọ̀, ògo ara ẹni, tàbí ìyìn. (Owe 15:25; 1 Timoteu 6:17) Rántí ẹ̀kọ́ tí a kọ́ nínú àpẹẹrẹ Jesu pé—a ní láti lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ láti mú ìyìn wá fún Jehofa. Bí a bá yan àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́, ète ìsúnniṣe wa ní láti jẹ́, ìfẹ́ ọkàn láti gbọ́ bùkátà ara wa lọ́nà tí ó tọ́, kí a baà lè ṣiṣẹ́ sin Jehofa lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian.—Kolosse 3:23, 24.
24. Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ lára Jesu, tí kò yẹ kí a gbàgbé?
24 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a jẹ́ aláápọn nínú ìsapá wa láti ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ti ayé tí ó wà déédéé. Ǹjẹ́ kí a lo àǹfààní ti ètò ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá tí ń lọ lọ́wọ́, tí ètò àjọ Jehofa ń pèsè lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ǹjẹ́ kí a má sì ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ pàtàkì náà tí a kọ́ lára Jesu Kristi, ọkùnrin tí ó ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ jú lọ, tí ó tí ì gbé orí ilẹ̀ ayé yìí rí—a ní láti lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́, kí í ṣe láti fògo fún ara wa, bí kò ṣe láti mú ìyìn wá fún Olùkọ́ni títóbi lọ́lá jù lọ, Jehofa Ọlọrun!
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
◻ Báwo ni Jesu ṣe lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀?
◻ Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti kọ́ láti kàwé lọ́nà jíjá gaara?
◻ Báwo ni a ṣe lè lo agbára àtikọ̀wé láti mú ìyìn wá fún Jehofa?
◻ Báwo ni ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà sókè ní ti ìwà rere àti nípa tẹ̀mí?
◻ Ìdálẹ́kọ̀ọ́ gbígbéṣẹ́ wo ni ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó wà déédéé gbọ́dọ̀ ní nínú?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]
Ìrànwọ́ Gbígbéṣẹ́ fún Àwọn Olùkọ́ni
Ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ní 1995 sí 1996, Watch Tower Society mú ìwé pẹlẹbẹ kan tí a pè ní Jehovah’s Witnesses and Education jáde. A tẹ ìwé pẹlẹbẹ aláwọ̀ mèremère, olójú ewé 32 yìí jáde ní pàtàkì fún àwọn olùkọ́ni. Títi di ìsinsìnyí, a ti túmọ̀ rẹ̀ sí èdè 58.
Èé ṣe tí a fi ṣe ìwé pẹlẹbẹ fún àwọn olùkọ́ni? Láti lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye ìgbàgbọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Kí ni ó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ náà? Lọ́nà tí ó rọrùn, tí ó sì yéni, ó ṣàlàyé ojú ìwòye wa lórí àwọn ọ̀ràn bí àfikún ìmọ̀ ẹ̀kọ́, ọjọ́ ìbí àti Kérésìmesì, àti kíkí àsíá. Ìwé pẹlẹbẹ náà tún fi àwọn olùkọ́ni lọ́kàn balẹ̀ pé, a fẹ́ kí àwọn ọmọ wa lo àǹfààní ẹ̀kọ́ wọn lọ́nà dídára jú lọ àti pé, a ṣe tán láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùkọ́ni, nípa fífi ọkàn ìfẹ́ àtàtà hàn nínú ìmọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ wa.
Báwo ni a ṣe lè lo ìwé pẹlẹbẹ náà, Education? Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn olùkọ́ ni a ṣe é fún, ẹ jẹ́ kí a ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn olùkọ́, àwọn ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́, àti àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn ní ilé ẹ̀kọ́. Ǹjẹ́ kí ìwé pẹlẹbẹ yìí ran gbogbo irú àwọn olùkọ́ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́, láti lóye ojú ìwòye àti ìgbàgbọ́ wa àti ìdí tí a fi sọ pé a lẹ́tọ̀ọ́ láti dá yàtọ̀ nígbà míràn. A rọ àwọn òbí láti lo ìwé pẹlẹbẹ náà gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún ìjíròrò ara ẹni pẹ̀lú àwọn olùkọ́ni àwọn ọmọ wọn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ní Israeli ìgbàanì a kò kóyán ìmọ̀ ẹ̀kọ́ kéré