Ṣé Lóòótọ́ Lo Nígbàgbọ́ Nínú Ìhìn Rere?
“Ìjọba Ọlọ́run . . . ti sún mọ́lé. Ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere.”—MÁÀKÙ 1:15.
1, 2. Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé Máàkù 1:14, 15?
ỌDÚN 30 Sànmánì Tiwa ni. Jésù Kristi ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ títayọ lọ́lá ní Gálílì. Ó ń wàásù “ìhìn rere Ọlọ́run,” ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ń wọ ọ̀pọ̀ àwọn ará Gálílì lọ́kàn, bó ti ń sọ pé: “Àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti pé, ìjọba Ọlọ́run sì ti sún mọ́lé. Ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere.”—Máàkù 1:14, 15.
2 “Àkókò tí a yàn kalẹ̀” ti dé fún Jésù láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ àti fún àwọn èèyàn láti ṣe ìpinnu tí wọ́n fi máa rí ojú rere Ọlọ́run. (Lúùkù 12:54-56) ‘Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé’ nítorí pé Jésù tó jẹ́ Ọba lọ́la wà lọ́dọ̀ wọn. Ìwàásù rẹ̀ mú káwọn ọlọ́kàntútù ronú pìwà dà. Àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe fi hàn pé àwọn “ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere,” báwo sì làwa náà ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
3. Kí làwọn èèyàn ti ṣe láti fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú ìhìn rere?
3 Bíi ti Jésù, àpọ́sítélì Pétérù náà rọ àwọn èèyàn láti ronú pìwà dà. Nígbà tí Pétérù ń bá àwọn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí a sì batisí olúkúlùkù yín ní orúkọ Jésù Kristi fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì gba ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́.” Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló ronú pìwà dà, tí wọ́n ṣe batisí, tí wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn Jésù. (Ìṣe 2:38, 41; 4:4) Àwọn Kèfèrí tó ronú pìwà dà gbé ìgbésẹ̀ kan náà lọ́dún 36 Sànmánì Tiwa. (Ìṣe 10:1-48) Ní àkókò tá a wà yìí, ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere náà ń mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n ń ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, wọ́n sì ń ṣe batisí. Wọ́n ti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere ìgbàlà, wọ́n sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. Kò tán síbẹ̀ o, wọ́n tún ń fi òdodo ṣèwà hù, wọ́n sì ń ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn gbágbáágbá.
4. Kí ni ìgbàgbọ́?
4 Àmọ́ kí ni ìgbàgbọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Ìgbàgbọ́ tá a ní ló mú kó dá wa lójú pé gbogbo ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni yóò nímùúṣẹ, ńṣe ló dà bíi pé ó ti ṣẹ pàápàá. Ńṣe ló dà bíi pé a ní ìwé àdéhùn kan lọ́wọ́, èyí tó fi hàn pé àwa la ni ilẹ̀ kan. Ìgbàgbọ́ tún ni “ìfihàn gbangba-gbàǹgbà,” tàbí ẹ̀rí ìdánilójú, nípa ohun tí a kò rí. Agbára ìmòye wa àti ọkàn tó kún fún ìmoore ń mú kó dá wa lójú pé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ jóòótọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò tíì rí wọn.—2 Kọ́ríńtì 5:7; Éfésù 1:18.
A Nílò Ìgbàgbọ́!
5. Kí nìdí tí ìgbàgbọ́ fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀?
5 Ẹ̀mí ìjọsìn la bí mọ́ wa, a ò bí ìgbàgbọ́ mọ́ wa. Ká sòótọ́, “ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.” (2 Tẹsalóníkà 3:2) Àmọ́ ṣá o, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ kí wọ́n bàa jogún àwọn ìlérí Ọlọ́run. (Hébérù 6:12) Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́, ó kọ̀wé pé: “Nítorí tí a ní àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ yí wa ká, ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn, ẹ sì jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa, bí a ti tẹjú mọ́ Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jésù.” (Hébérù 12:1, 2) Kí ni “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn”? Àìní ìgbàgbọ́ ni, ó tiẹ̀ lè jẹ́ pípàdánù ìgbàgbọ́ téèyàn ní tẹ́lẹ̀ pàápàá. Tá a bá fẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, a gbọ́dọ̀ ‘tẹjú mọ́ Jésù’ ká sì máa tẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀. A tún ní láti sá fún ìwà pálapàla, ká kọjúùjà sí àwọn iṣẹ́ ti ara, ká sì yẹra fún ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, ìmọ̀ ọgbọ́n orí ti ayé, àti àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. (Gálátíà 5:19-21; Kólósè 2:8; 1 Tímótì 6:9, 10; Júúdà 3, 4) Kò tán síbẹ̀ o, a tún gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa àti pé ìmọ̀ràn tó wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbéṣẹ́ gan-an.
6, 7. Èé ṣe tó fi tọ́ láti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ìgbàgbọ́?
6 A ò lè fi ọgbọ́n tiwa fúnra wa dá ìgbàgbọ́ sínú ara wa. Ìgbàgbọ́ wà lára àwọn èso ti ẹ̀mí mímọ́ tàbí ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run. (Gálátíà 5:22, 23) Nígbà náà, tó bá wá jẹ́ pé ìgbàgbọ́ tá a ní ló yẹ ká fún lókun ńkọ́? Jésù sọ pé: “Bí ẹ̀yin . . . bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:13) Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ jẹ́ ká gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́, nítorí pé ìyẹn lè jẹ́ ká nígbàgbọ́ tá a nílò láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kódà lákòókò tí nǹkan ò bá rọgbọ.—Éfésù 3:20.
7 Ó tọ́ láti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi kún ìgbàgbọ́ wa. Nígbà tí Jésù fẹ́ lé ẹ̀mí èṣù jáde lára ọmọdékùnrin kan, baba ọmọ náà bẹ̀bẹ̀ pé: “Mo ní ìgbàgbọ́! Ràn mí lọ́wọ́ níbi tí mo ti nílò ìgbàgbọ́!” (Máàkù 9:24) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.” (Lúùkù 17:5) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ìgbàgbọ́, ká sì ní ìdánilójú pé Ọlọ́run yóò dáhùn irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀.—1 Jòhánù 5:14.
Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣe Pàtàkì
8. Báwo ni ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
8 Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù kú ikú ìrúbọ tó kú, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn-àyà yín dààmú. Ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú mi pẹ̀lú.” (Jòhánù 14:1) Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti nínú Ọmọ rẹ̀. Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wá ńkọ́? Ó lè sa ipa tó lágbára láti mú wa ṣe rere nínú ìgbésí ayé wa bí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tá a sì ń fi ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sílò pẹ̀lú ìdánilójú pé ó ń fún wa ní ìmọ̀ràn àti ìdarí tó dára jù lọ.—Hébérù 4:12.
9, 10. Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ohun tá a sọ nípa ìgbàgbọ́ nínú ìwé Jákọ́bù 1:5-8?
9 Ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá aláìpé kún fún wàhálà. Àmọ́, ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ ní ti gidi. (Jóòbù 14:1) Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé a ò mọ bá a ṣe lè kojú àdánwò pàtó kan. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa ní ìmọ̀ràn yìí pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un. Ṣùgbọ́n kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè nínú ìgbàgbọ́, láìṣiyèméjì rárá, nítorí ẹni tí ó bá ń ṣiyèméjì dà bí ìgbì òkun tí ẹ̀fúùfù ń bì, tí a sì ń fẹ́ káàkiri. Ní ti tòótọ́, kí ẹni yẹn má rò pé òun yóò rí ohunkóhun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà; ó jẹ́ aláìnípinnu, aláìdúrósójúkan ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.”—Jákọ́bù 1:5-8.
10 Jèhófà Ọlọ́run kò ní pẹ̀gàn wa nítorí pé a ò ní ọgbọ́n tá a sì wá ń gbàdúrà láti ní in. Dípò ìyẹn, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi ojú tó tọ́ wo àdánwò náà. Àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lè pe àfiyèsí wa sí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a nílò tàbí ká rí àwọn ẹsẹ náà nígbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà sì lè darí wa láwọn ọ̀nà mìíràn. Baba wa ọ̀run yóò fún wa ní ọgbọ́n láti kojú àwọn àdánwò bí a bá ń “bá a nìṣó ní bíbéèrè nínú ìgbàgbọ́, láìṣiyèméjì rárá.” A ò lè retí àtirí ohunkóhun gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run bí a bá dà bí ìgbì òkun tí ẹ̀fúùfù ń bì káàkiri. Kí nìdí? Nítorí pé èyí yóò túmọ̀ sí pé a ò nípinnu a ò sì lè dúró sójú kan nínú àdúrà tàbí láwọn ọ̀nà mìíràn—bẹ́ẹ̀ ni o, kódà nínú lílo ìgbàgbọ́ pàápàá. Nítorí náà, a ní láti ní ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nínú ìtọ́sọ́nà tó ń pèsè. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò nípa bó ṣe ń ranni lọ́wọ́ tó sì ń tọ́ni sọ́nà.
Ìgbàgbọ́ àti Ohun Ìgbẹ́mìíró
11. Tá a bá nígbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ̀rí ìdánilójú wo ló wà fún wa nípa àwọn ohun tá a nílò lójoojúmọ́?
11 Tó bá jẹ́ pé awọ ò kájú ìlù fún wa tàbí pé a wà nínú ipò òṣì báyìí ńkọ́? Ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń fún wa ní ìrètí tó dájú pé Jèhófà yóò máa bójú tó ohun tá a nílò lójoojúmọ́, yóò sì pèsè ohun rere lọ́pọ̀ yanturu fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nínú ètò tuntun. (Sáàmù 72:16; Lúùkù 11:2, 3) Ó lè jẹ́ ìṣírí fún wa láti ronú lórí bí Jèhófà ṣe pèsè oúnjẹ fún Èlíjà ìránṣẹ́ rẹ̀ lákòókò kan tí ìyàn mú. Ẹ̀yìn ìyẹn ni Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí fi iṣẹ́ ìyanu pèsè ìyẹ̀fun àti òróró tí ò jẹ́ kí ebi pa obìnrin kan, ọmọ rẹ̀, àti Èlíjà kú. (1 Àwọn Ọba 17:2-16) Bákan náà ni Jèhófà ṣe pèsè fún wòlíì Jeremáyà nígbà táwọn ará Bábílónì gbógun ti Jerúsálẹ́mù. (Jeremáyà 37:21) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oúnjẹ díẹ̀ ni Jeremáyà àti Èlíjà rí jẹ, síbẹ̀ Jèhófà bójú tó wọn. Bákan náà ló ń ṣe fáwọn tó ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ lónìí.—Mátíù 6:11, 25-34.
12. Báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe lè ṣèrànwọ́ láti rí oúnjẹ òòjọ́ wa?
12 Ìgbàgbọ́ àti fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò kò ní sọ wá di olówó rẹpẹtẹ, àmọ́ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí oúnjẹ òòjọ́ wa. Láti ṣàpèjúwe: Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn láti jẹ́ aláìlábòsí, ká jẹ́ ọ̀jáfáfá, ká sì máa ṣe iṣẹ́ àṣekára. (Òwe 22:29; Oníwàásù 5:18, 19; 2 Kọ́ríńtì 8:21) A ò gbọ́dọ̀ fojú kéré bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká ní orúkọ rere níbi iṣẹ́ láé. Kódà láwọn ibi tí iṣẹ́ tó dáa ti ṣọ̀wọ́n pàápàá, àwọn òṣìṣẹ́ tó jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n jẹ́ ọ̀jáfáfá, tí wọ́n sì jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn ṣì ń rọ́wọ́ mú ju àwọn yòókù lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn òṣìṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lè máà lówó rẹpẹtẹ, wọ́n sábà máa ń ní àwọn ohun kòṣeémánìí àti ìtẹ́lọ́rùn pé àwọn ń jẹ oúnjẹ tí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣiṣẹ́ fún.—2 Tẹsalóníkà 3:11, 12.
Ìgbàgbọ́ Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Fara Da Ìbànújẹ́
13, 14. Báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìbànújẹ́?
13 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn kedere pé kì í ṣe ohun àjèjì láti banú jẹ́ nígbà tí èèyàn ẹni bá kú. Ábúráhámù baba ńlá olóòótọ́ nì ṣọ̀fọ̀ nígbà tí Sárà aya rẹ̀ ọ̀wọ́n kú. (Jẹ́nẹ́sísì 23:2) Ìbànújẹ́ dorí Dáfídì kodò nígbà tó gbọ́ pé Ábúsálómù ọmọ òun ti kú. (2 Sámúẹ́lì 18:33) Kódà Jésù ọkùnrin pípé nì sunkún nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ kú. (Jòhánù 11:35, 36) Nígbà tí èèyàn wa bá kú, ìbànújẹ́ lè dorí wa kodò gan-an, àmọ́ ìgbàgbọ́ tá a ní nínú àwọn ìlérí inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da irú ìbànújẹ́ bẹ́ẹ̀.
14 Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Mo ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọ́run, pé àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.’ (Ìṣe 24:15) Ó yẹ ká nígbàgbọ́ nínú ètò tí Ọlọ́run ṣe láti mú ogunlọ́gọ̀ èèyàn padà bọ̀ sí ìyè. (Jòhánù 5:28, 29) Lára wọn ni Ábúráhámù àti Sárà, Ísákì àti Rèbékà, Jékọ́bù àti Léà—tí gbogbo wọn ń sun oorun ikú báyìí tí wọ́n sì ń retí àjíǹde sínú ayé tuntun Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 49:29-32) Ayọ̀ tá à ń wí yìí á mà pọ̀ o, nígbà tí àwọn èèyàn wa bá jí nínú oorun ikú tí wọ́n ń sùn láti wá gbé níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé! (Ìṣípayá 20:11-15) Ní báyìí ná, ìgbàgbọ́ kò ní mú gbogbo ìbànújẹ́ kúrò, àmọ́ yóò mú ká sún mọ́ Ọlọ́run, tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ọ̀fọ̀ tó ń ṣẹ̀ wá.—Sáàmù 121:1-3; 2 Kọ́ríńtì 1:3.
Ìgbàgbọ́ Ń Fún Àwọn Tí Ìdààmú Ọkàn Bá Lókun
15, 16. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìdààmú ọkàn kì í ṣe ohun àjèjì fáwọn tó ń lo ìgbàgbọ́? (b) Kí la lè ṣe sí ìdààmú ọkàn?
15 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún fi hàn pé àwọn tó nígbàgbọ́ pàápàá lè dẹni tí ìdààmú ọkàn bá. Nígbà tí àdánwò líle koko dé bá Jóòbù, ó rò pé Ọlọ́run ti pa òun tì ni. (Jóòbù 29:2-5) Ipò bíbanilọ́kànjẹ́ tí Jerúsálẹ́mù àti àwọn ògiri rẹ̀ wà kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá Nehemáyà. (Nehemáyà 2:1-3) Inú Pétérù bà jẹ́ gan-an lẹ́yìn tó sẹ́ Jésù débi pé ó “sunkún kíkorò.” (Lúùkù 22:62) Pọ́ọ̀lù náà sì rọ àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ nínú ìjọ Tẹsalóníkà láti “máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Nítorí náà, pé ìdààmú ọkàn bá àwọn tó ń lo ìgbàgbọ́ lónìí kì í ṣe nǹkan àjèjì. Kí la wá lè ṣe láti kojú ìdààmú ọkàn?
16 Ìdààmú ọkàn lè bá wa nítorí pé à ń dojú kọ àwọn ìṣòro líle koko. Dípò tá a ó fi máa wò wọ́n bí ìṣòro tẹ́nì kan ò ní rí, a lè yanjú wọn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nípa fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Èyí lè ṣèrànwọ́ láti dín ìdààmú ọkàn wa kù. Kéèyàn máa ṣiṣẹ́ níwọ̀ntúnwọ̀nsì kó sì máa sinmi dáadáa tún lè ṣèrànwọ́. Ohun kan dájú: Ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń gbé ire tẹ̀mí lárugẹ nítorí pé ó ń jẹ́ ká túbọ̀ ní ìdánilójú pé ó ń bìkítà fún wa ní ti gidi.
17. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà bìkítà nípa wa?
17 Pétérù fún wa ní ìdánilójú onítùnú yìí pé: “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí ó lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ; bí ẹ ti ń kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.” (1 Pétérù 5:6, 7) Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Jèhófà ń fún gbogbo àwọn tí ó ṣubú ní ìtìlẹyìn, ó sì ń gbé gbogbo àwọn tí a tẹ̀ lórí ba dìde.” (Sáàmù 145:14) A gbọ́dọ̀ gba àwọn ìmúdánilójú wọ̀nyí gbọ́, nítorí pé inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la ti rí wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè máa ní ìdààmú ọkàn, síbẹ̀ ẹ wo bó ṣe ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun tó láti mọ̀ pé a lè kó gbogbo àníyàn wa lọ bá Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́!
Ìgbàgbọ́ Àtàwọn Àdánwò Mìíràn
18, 19. Báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àìsàn àti láti tu àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tó ń ṣàìsàn nínú?
18 Àdánwò ńláǹlà lè bá ìgbàgbọ́ wa nígbà tí àìsàn líle koko bá kọ lù wá tàbí àwọn èèyàn wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò ròyìn pé a fi iṣẹ́ ìyanu wo àwọn Kristẹni bí Ẹpafíródítù, Tímótì, àti Tírófímù sàn, síbẹ̀ ó dájú pé Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara dà á. (Fílípì 2:25-30; 1 Tímótì 5:23; 2 Tímótì 4:20) Yàtọ̀ síyẹn, onísáàmù náà kọrin nípa “ẹnikẹ́ni tí ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀,” pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbé e ró lórí àga ìnàyìn ti àmódi; gbogbo ibùsùn rẹ̀ ni ìwọ yóò yí padà dájúdájú nígbà àìsàn rẹ̀.” (Sáàmù 41:1-3) Báwo ni ọ̀rọ̀ onísáàmù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti tu àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tó ń ṣàìsàn nínú?
19 Ọ̀nà kan tá a lè gbà pèsè ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí ni pé kí àwa àtàwọn tó ń ṣàìsàn náà gbàdúrà pa pọ̀, ká sì tún fi wọ́n sínú àdúrà wa pẹ̀lú. Òótọ́ la kì í béèrè ìmúláradá lọ́nà ìyanu lóde òní, síbẹ̀ a lè gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wọn ní okun inú láti kojú àrùn wọn, kó sì tún fún wọn ní okun tẹ̀mí tí wọ́n nílò láti fara da àìlera náà. Jèhófà yóò mẹ́sẹ̀ wọn dúró, ìgbàgbọ́ wọn yóò sì lágbára nípa fífojú sọ́nà de àkókò náà nígbà tí “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Ẹ ò rí i pé ìtùnú ńlá ló jẹ́ láti mọ̀ pé ẹ̀dá ènìyàn onígbọràn yóò tipasẹ̀ Jésù Kristi tí a jí dìde àti Ìjọba Ọlọ́run bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, àìsàn, àti ikú! A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, ‘ẹni tí yóò wo gbogbo àrùn wa sàn,’ fún ọjọ́ ọ̀la kíkọyọyọ tá à ń wọ̀nà fún yìí.—Sáàmù 103:1-3; Ìṣípayá 21:1-5.
20. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìgbàgbọ́ lè mú ká borí “àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù” ti ọjọ́ ogbó?
20 Ìgbàgbọ́ tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú “àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù” ti ọjọ́ ogbó, tó máa ń mú kí ìlera àti okun dín kù. (Oníwàásù 12:1-7) Nítorí náà, àwọn arúgbó tó wà láàárín wa lè gbàdúrà bí onísáàmù arúgbó ti ṣe, ẹni tó kọ ọ́ lórin pé: “Ìwọ ni ìrètí mi, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ . . . Má ṣe gbé mi sọnù ní àkókò ọjọ́ ogbó; ní àkókò náà tí agbára mi ń kùnà, má ṣe fi mí sílẹ̀.” (Sáàmù 71:5, 9) Onísáàmù náà rí i pé òun nílò ìtìlẹ́yìn Jèhófà, bí ọ̀pọ̀ onígbàgbọ́ bíi tiwa tí wọ́n ti lo ọ̀pọ̀ ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run tí wọ́n sì ti darúgbó báyìí ṣe nílò rẹ̀. Nítorí ìgbàgbọ́ wọn, ó lè dá wọn lójú pé àwọn ní ìtìlẹ́yìn tí kì í kùnà tó jẹ́ ti apá Jèhófà tó wà títí láé.— Diutarónómì 33:27.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Rẹ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yingin
21, 22. Tá a bá nígbàgbọ́, báwo ni ìgbàgbọ́ yẹn ṣe kan àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run?
21 Ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ìhìn rere àti nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run látòkèdélẹ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Jákọ́bù 4:8) Òun ni Olúwa Ọba Aláṣẹ wa lóòótọ́, àmọ́ òun náà tún ni Ẹlẹ́dàá àti Baba wa. (Aísáyà 64:8; Mátíù 6:9; Ìṣe 4:24) Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Ìwọ ni Baba mi, Ọlọ́run mi àti Àpáta ìgbàlà mi.” (Sáàmù 89:26) Bí a bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti nínú Ọ̀rọ̀ onímìísí rẹ̀, àwa náà lè kà á sí ‘Àpáta ìgbàlà wa.’ Ẹ ò rí i pé àǹfààní amọ́kànyọ̀ gidi lèyí!
22 Jèhófà ni Baba àwọn Kristẹni tá a fi ẹ̀mí bí àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tí wọ́n ní ìrètí gbígbé lórí ilẹ̀ ayé. (Róòmù 8:15) Ìgbàgbọ́ nínú Baba wa ọ̀run kò sì lè yọrí sí ìjákulẹ̀ láé. Dáfídì sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Sáàmù 27:10) Ìyẹn nìkan kọ́ o, a tún ní ìdánilójú yìí pé: “Jèhófà kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ tì, nítorí orúkọ ńlá rẹ̀.”—1 Sámúẹ́lì 12:22.
23. Kí la ní láti ṣe ká tó lè gbádùn àjọṣe pípẹ́ títí pẹ̀lú Jèhófà?
23 Àmọ́ ṣá o, bá a bá fẹ́ gbádùn àjọṣe tó máa wà pẹ́ títí pẹ̀lú Jèhófà, a gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú ìhìn rere náà ká sì tẹ́wọ́ gba àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bí wọ́n ṣe jẹ́ gan-an, àní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (1 Tẹsalóníkà 2:13) A gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ tó jinlẹ̀ nínú Jèhófà, ká sì jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà wa. (Sáàmù 119:105; Òwe 3:5, 6) Ìgbàgbọ́ wa yóò máa pọ̀ sí i, bá a ṣe ń gbàdúrà sí i pẹ̀lú ìgbọ́kànlé tá a ní nínú ìyọ́nú, àánú, àti ìtìlẹ́yìn rẹ̀.
24. Èrò tí ń tuni nínú wo ló wà nínú Róòmù 14:8?
24 Ìgbàgbọ́ ń sún wa láti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run títí ayérayé. Tá a bá nígbàgbọ́ tó lágbára, bá a tiẹ̀ kú pàápàá, ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti ṣe ìyàsímímọ́ ni wá, a sì ní ìrètí àjíǹde. Bẹ́ẹ̀ ni o, “bí a bá wà láàyè àti bí a bá kú, a jẹ́ ti Jèhófà.” (Róòmù 14:8) Ẹ jẹ́ ká fi èrò tí ń tuni nínú yẹn sọ́kàn wa, bá a ti ń ní ìgbọ́kànlé nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń bá a lọ láti ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ni ìgbàgbọ́, kí sì nìdí tá a fi nílò ànímọ́ yìí?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká nígbàgbọ́ nínú ìhìn rere àti nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run látòkèdélẹ̀?
• Báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú onírúurú àdánwò?
• Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní yingin?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Jèhófà pèsè fún Jeremáyà àti Èlíjà nítorí pé wọ́n nígbàgbọ́
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Jóòbù, Pétérù, àti Nehemáyà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Tá a bá fẹ́ gbádùn àjọṣe pípẹ́ títí pẹ̀lú Jèhófà, a gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú ìhìn rere