Ìsìn Kristian Ìjímìjí àti Orílẹ̀-èdè
WÁKÀTÍ díẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀, Jesu sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kì í ṣe apákan ayé, ṣugbọn mo ti yàn yín kúrò ninu ayé, nítìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín.” (Johannu 15:19) Ṣùgbọ́n, èyí ha túmọ̀ sí pé, àwọn Kristian yóò máa ta ko àwọn aláṣẹ ayé yìí bí?
Wọn Kì Í Ṣe Ti Ayé, Bẹ́ẹ̀ Sì Ni Wọn Kì Í Ṣe Alátakò
Aposteli Paulu sọ fún àwọn Kristian tí ń gbé ní Romu pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ awọn aláṣẹ onípò gíga.” (Romu 13:1) Lọ́nà jíjọra, aposteli Peteru kọ̀wé pé: “Nitori Oluwa ẹ fi ara yín sábẹ́ gbogbo ohun tí ẹ̀dá ènìyàn ṣẹ̀dá: yálà sábẹ́ ọba gẹ́gẹ́ bí onípò gíga tabi sábẹ́ awọn gómìnà gẹ́gẹ́ bí awọn tí oun rán lati fi ìyà jẹ awọn aṣebi ṣugbọn lati yin awọn olùṣe rere.” (1 Peteru 2:13, 14) Ó hàn gbangba pé, fífi ara wa sábẹ́ Orílẹ̀-Èdè àti àwọn aṣojú rẹ̀ tí ó fẹ̀tọ́ yàn sípò jẹ́ ìlànà tí a tẹ́wọ́ gbà láàárín àwọn Kristian ìjímìjí. Wọ́n sakun láti jẹ́ aráàlú tí ń pa òfin mọ́ àti láti gbé ní ìrọwọ́rọsẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.—Romu 12:18.
Lábẹ́ àkòrí náà “Ṣọ́ọ̀ṣì àti Orílẹ̀-Èdè,” ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion, polongo pé: “Ní àwọn ọ̀rúndún mẹ́ta àkọ́kọ́ Lẹ́yìn Ikú Oluwa Wa, ṣọ́ọ̀ṣì Kristian wà ní dáńfó gedegbe sí àwùjọ Romu tí a fàṣẹ tì lẹ́yìn . . . Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn aṣáájú Kristian . . . fi ṣíṣe ìgbọràn sí òfin Romu àti jíjẹ́ adúróṣinṣin sí ọba aláyélúwà kọ́ni, títí dé ibi tí ìgbàgbọ́ Kristian fàyè gbà.”
Ọlá Ni, Kì Í Ṣe Ìjọsìn
Àwọn Kristian kò ta ko ọba aláyélúwà Romu. Wọ́n bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ rẹ̀, wọ́n sì fún un ní ọlá tí ó tọ́ sí ipò rẹ̀. Nígbà ìṣàkóso Ọba Aláyélúwà Nero, aposteli Peteru kọ̀wé sí àwọn Kristian tí ń gbé ní gbogbo agbègbè Ilẹ̀ Ọba Romu pé: “Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo, . . . ẹ máa fi ọlá fún ọba.” (1 Peteru 2:17) Kì í ṣe àwọn ọba ìlú nìkan ni a lo ọ̀rọ̀ náà, “ọba” fún láwùjọ àwọn tí ń sọ èdè Gíríìkì, ṣùgbọ́n a tún lò ó fún ọba aláyélúwà Romu. Aposteli Paulu gba àwọn Kristian tí ń gbé ní olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Romu nímọ̀ràn pé: “Ẹ fi awọn ohun ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, . . . fún ẹni tí ó béèrè fún ọlá, irúfẹ́ ọlá bẹ́ẹ̀.” (Romu 13:7) Dájúdájú, ọba aláyélúwà Romu béèrè fún ọlá. Nígbà tí ó yá, ó tilẹ̀ tún béèrè fún ìjọsìn. Ṣùgbọ́n, níhìn-ín, àwọn Kristian ìjímìjí pààlà sí i.
Nígbà ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ níwájú alákòóso kan ní Romu ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, a ròyìn pé Polycarp polongo pé: “Kristian ni mí. . . . A kọ́ wa láti fi gbogbo ọlá tí ó tọ́ . . . fún àwọn alágbára àti aláṣẹ tí Ọlọrun fi joyè.” Ṣùgbọ́n, Polycarp yàn láti kú kàkà tí yóò fi jọ́sìn ọba aláyélúwà. Theophilus ará Antioku, agbèjà ìgbàgbọ́ ní ọ̀rúndún kejì kọ̀wé pé: “Èmi yóò kúkú bọlá fún ọba aláyélúwà, kì í ṣe láti jọ́sìn rẹ̀ ní ti gidi, ṣùgbọ́n láti gbàdúrà fún un. Ṣùgbọ́n Ọlọrun, Ọlọrun tí ń bẹ láàyè, tí ó sì jẹ́ òtítọ́ ni èmi yóò jọ́sìn.”
Àwọn àdúrà yíyẹ wẹ́kú tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ọba aláyélúwà náà kò ní ìsopọ̀ kankan pẹ̀lú jíjọ́sìn ọba aláyélúwà tàbí pẹ̀lú ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni. Aposteli Paulu ṣàlàyé ète wọn pé: “Nitori naa mo gbani níyànjú, ṣáájú ohun gbogbo, pé kí a máa ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, àdúrà, ìbẹ̀bẹ̀fúnni, ọrẹ-ẹbọ ọpẹ́, nipa gbogbo onírúurú ènìyàn, nipa awọn ọba ati gbogbo awọn wọnnì tí wọn wà ní ibi ipò gíga; kí a lè máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí-ayé píparọ́rọ́ ati dídákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹlu ìfọkànsin Ọlọrun kíkún ati ìwà àgbà.”—1 Timoteu 2:1, 2.
‘Wọn Kò Tẹ̀ Sí Ibi Tí Ẹgbẹ́ Àwùjọ Tẹ̀ Sí’
Ìwà tí ó fi ọ̀wọ̀ hàn tí àwọn Kristian ìjímìjí hù yìí, kò mú wọn ní ìbárẹ́ kankan pẹ̀lú ayé tí wọ́n ń gbé ní ìgbà náà. Ọmọ ilẹ̀ Faransé, òpìtàn, A. Hamman, sọ pé, àwọn Kristian ìjímìjí “kò tẹ̀ sí ibi tí ẹgbẹ́ àwùjọ tẹ̀ sí.” Ní ti gidi, wọ́n kò tẹ̀ sí ibi tí ẹgbẹ́ àwùjọ méjèèjì tẹ̀ sí, ti àwọn Júù àti ti Romu, wọ́n sì dojú kọ ẹ̀tanú àti àṣìlóye púpọ̀ láti ìhà méjèèjì.
Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn aṣáájú Júù fi ẹ̀sùn èké kàn án, aposteli Paulu sọ nínú ìgbèjà rẹ̀ níwájú gómìnà Romu pé: “Emi kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan sí Òfin awọn Júù tabi sí tẹmpili tabi sí Kesari. . . . Mo ké gbàjarè sí Kesari!” (Ìṣe 25:8, 11) Nígbà tí ó mọ̀ pé àwọn Júù ń dìtẹ̀ láti pa òun, Paulu ké gbàjarè sí Nero, ó tipa báyìí ka ọlá àṣẹ ọba aláyélúwà Romu sí. Ní àbárèbábọ̀, nígbà ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ ní Romu, ó dà bíi pé a dá Paulu sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, a tún jù ú sẹ́wọ̀n lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, òfin àtọwọ́dọ́wọ́ sì fi hàn pé, Nero ni ó pàṣẹ pé kí a pa á.
Nípa ipò líle koko tí àwọn Kristian ìjímìjí wà nínú ẹgbẹ́ àwùjọ Romu, onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá àti ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, Ernst Troeltsch, kọ̀wé pé: “Gbogbo ipò àti ìlépa tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú jíjọ́sìn òrìṣà, tàbí pẹ̀lú jíjọ́sìn Ọba Aláyélúwà, tàbí àwọn tí ó ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìtàjẹ̀sílẹ̀ tàbí ìfìyà ikú jẹni, tàbí àwọn tí yóò mú àwọn Kristian lọ́wọ́ sí ìwà pálapàla ti ìbọ̀rìṣà ni a bẹ́gi dí.” Ipò yìí ha fi àyè sílẹ̀ fún ipò ìbátan alálàáfíà àti ọlọ́wọ̀ láàárín àwọn Kristian àti Orílẹ̀-Èdè bí?
Sísan “Awọn Ohun Ẹ̀tọ́” Kesari fún Un
Jesu gbé ìlànà kan kalẹ̀ tí ń ṣàkóso ìwà àwọn Kristian sí Orílẹ̀-Èdè Romu tàbí, ní ti gidi, sí ìjọba èyíkéyìí, nígbà tí ó polongo pé: “Ẹ san awọn ohun ti Kesari padà fún Kesari, ṣugbọn awọn ohun ti Ọlọrun fún Ọlọrun.” (Matteu 22:21) Ìmọ̀ràn tí a fún àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu yìí yàtọ̀ pátápátá sí ìṣarasíhùwà ọ̀pọ̀ àwọn Júù onífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, tí wọ́n fi ìbínú hàn sí ìjẹgàba Romu, tí wọ́n sì pe ìbófinmu sísan owó orí fún agbára ilẹ̀ òkèèrè níjà.
Lẹ́yìn náà, Paulu sọ fún àwọn Kristian tí ń gbé ní Romu pé: “Nitori naa ìdí tí ń múnilọ́ranyàn wà fún yín lati wà lábẹ́ àṣẹ, kì í ṣe nítìtorí ìrunú yẹn nìkan ṣugbọn nítìtorí ẹ̀rí-ọkàn yín pẹlu. Nitori ìdí nìyẹn tí ẹ̀yin fi ń san owó-orí pẹlu; nitori wọ́n [“awọn aláṣẹ onípò gíga” tí ń ṣèjọba] jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun sí gbogbo ènìyàn ní sísìn nígbà gbogbo fún ète yii gan-an. Ẹ fi awọn ohun ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, fún ẹni tí ó béèrè fún owó-orí, owó-orí; fún ẹni tí ó béèrè fún owó-òde, owó-òde.” (Romu 13:5-7) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristian kì í ṣe apá kan ayé, ó di ọ̀ranyàn fún wọn láti jẹ́ aráàlú tí kì í ṣàbòsí, tí ń san owó orí, tí ń san owó fún àwọn iṣẹ́ tí Orílẹ̀-Èdè ń ṣe.—Johannu 17:16.
Ṣùgbọ́n, àwọn ọ̀rọ̀ Jesu ha mọ sórí kìkì sísan owó orí bí? Níwọ̀n bí Jesu kò ti sọ ní pàtó ohun ti Kesari àti ohun ti Ọlọrun, àwọn ọ̀ràn tí ó ní ààlà wà tí a gbọ́dọ̀ pinnu ní ìbámu pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tàbí ní ìbámu pẹ̀lú òye wa nípa Bibeli lódindi. Ní èdè mìíràn, pípinnu àwọn ohun tí Kristian kan lè san fún Kesari nígbà míràn yóò ní ẹ̀rí ọkàn Kristian nínú, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlànà Bibeli ṣe là á lóye.
Ìwàdéédéé Àfẹ̀sọ̀ṣe Láàárín Ohun Àfẹ̀tọ́béèrè Méjì Tí Ń Bára Díje
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìtẹ̀sí láti gbàgbé pé, lẹ́yìn sísọ pé a ní láti san ohun ti Kesari padà fún un, Jesu fi kún un pé: “Ṣugbọn [ẹ san] awọn ohun ti Ọlọrun fún Ọlọrun.” Aposteli Peteru fi ohun tí ó gba iwájú jù lọ fún àwọn Kristian hàn. Kété lẹ́yìn fífúnni ní ìmọ̀ràn lórí fífi ara wa sábẹ́ “ọba,” tàbí ọba aláyélúwà, àti “àwọn gómìnà” rẹ̀, Peteru kọ̀wé pé: “Ẹ wà gẹ́gẹ́ bí awọn ẹni òmìnira, síbẹ̀ kí ẹ sì di òmìnira yín mú, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí bojúbojú kan fún ìwà búburú, bíkòṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú Ọlọrun. Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo, ẹ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ awọn ará, ẹ máa bẹ̀rù Ọlọrun, ẹ máa fi ọlá fún ọba.” (1 Peteru 2:16, 17) Aposteli náà fi hàn pé, àwọn Kristian jẹ́ ẹrú fún Ọlọrun, kì í ṣe fún olùṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní láti fi ọlá àti ọ̀wọ̀ tí ó yẹ hàn fún àwọn aṣojú Orílẹ̀-Èdè, wọ́n ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìbẹ̀rù Ọlọrun, ẹni tí àwọn òfin rẹ̀ ga lọ́lá jù lọ.
Ní àwọn ọdún tí ó ṣáájú, Peteru ti mú un ṣe kedere pé, òfin Ọlọrun ga lọ́lá ju ti ènìyàn lọ. Sanhẹdirin ti àwọn Júù jẹ́ ẹgbẹ́ olùṣàkóso tí àwọn ará Romu fún ní ọlá àṣẹ lórí ètò ìlú àti ìsìn. Nígbà tí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu láti dáwọ́ kíkọ́ni ní orúkọ Kristi dúró, Peteru àti àwọn aposteli mìíràn fèsì tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdúró gbọn-ingbọn-in pé: “Awa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò awọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Ó ṣe kedere pé, àwọn Kristian ìjímìjí ní láti di ìwàdéédéé àfẹ̀sọ̀ṣe mú láàárín ṣíṣègbọràn sí Ọlọrun àti ìtẹríba tí ó tọ́ fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláṣẹ. Bí Tertullian ṣe sọ ọ́ nìyí ní ọ̀rúndún kẹta Sànmánì Tiwa: “Bí gbogbo rẹ̀ bá jẹ́ ti Kesari, kí ni yóò ṣẹ́kù fún Ọlọrun?”
Jíjuwọ́sílẹ̀ fún Orílẹ̀-Èdè
Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ipò tí àwọn Kristian ní ọ̀rúndún kìíní dì mú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Orílẹ̀-Èdè bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn. Ìpẹ̀yìndà tí Jesu àti àwọn aposteli rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ gbilẹ̀ ní ọ̀rúndún kejì àti ìkẹta ti Sànmánì Tiwa. (Matteu 13:37, 38; Ìṣe 20:29, 30; 2 Tessalonika 2:3-12; 2 Peteru 2:1-3) Ìsìn Kristian apẹ̀yìndà juwọ́ sílẹ̀ fún ayé Romu, ó ṣàmúlò àwọn ayẹyẹ abọ̀rìṣà rẹ̀ àti ọgbọ́n èrò orí rẹ̀, kì í ṣe iṣẹ́ ìjọba nìkan ni ó tẹ́wọ́ gbà, ṣùgbọ́n ó tún tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ológun pẹ̀lú.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Troeltsch kọ̀wé pé: “Láti ọ̀rúndún kẹta síwájú, ipò náà túbọ̀ ń ṣòro sí i, nítorí pé àwọn Kristian túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní ipò tí ó yọrí ọlá Láwùjọ àti nínú àwọn iṣẹ́ kàǹkà kàǹkà, nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti ẹgbẹ́ lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba. Nínú àwọn àyọkà mélòó kan nínú àwọn àkọsílẹ̀ Kristian [tí kì í ṣe apá kan Bibeli], a fi ẹ̀hónú tí ó ní ìkannú hàn sí lílọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, a tún rí ìgbìdánwò láti juwọ́ sílẹ̀—àwọn ìjiyàn tí a pète láti pa àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ń ṣe kámi-kàmì-kámi lẹ́nu mọ́ . . . Láti ìgbà Constantine ni àwọn ìṣòro wọ̀nyí kò ti sí mọ́; èdè àìyedè láàárín àwọn Kristian àti àwọn kèfèrí dópin, gbogbo ipò ní Orílẹ̀-Èdè sì ṣí sílẹ̀.”
Bí ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa ti ń parí lọ, àmúlùmálà ìsìn Kristian, tí ń juwọ́ sílẹ̀ yìí, di ìsìn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Ọba Romu.
Jálẹ̀ ìtàn, Kirisẹ́ńdọ̀mù—tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, àti Pùròtẹ́sítáǹtì ṣojú fún—ń bá a nìṣó láti juwọ́ sílẹ̀ fún Orílẹ̀-Èdè, ní ríri ara wọn bọnú ìṣèlú rẹ̀ àti ṣíṣètìlẹyìn fún un nínú àwọn ogun rẹ̀. Kò sí àníàní pé ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n fi tọkàntọkàn jẹ́ mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì tí èyí ti kó ṣìbáṣìbo bá, ni inú wọn yóò dùn láti mọ̀ pé, àwọn Kristian ń bẹ lónìí tí wọ́n di ipò àwọn Kristian ní ọ̀rúndún kìíní mú nínú ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Orílẹ̀-Èdè. Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ méjèèjì tí ó tẹ̀ lé e yóò tú iṣu ọ̀ràn náà dé ìsàlẹ̀ ìkòkò.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Kesari Nero, ẹni tí Peteru kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Ẹ máa fi ọlá fún ọba”
[Credit Line]
Musei Capitolini, Roma
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Polycarp yàn láti kú dípò kí ó jọ́sìn ọba aláyélúwà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Kristian ìjímìjí jẹ́ aráàlú ẹlẹ́mìí àlàáfíà, aláìlábòsí, tí ń san owó orí