Apa 5
Ẹbun Agbayanu ti Ominira Ifẹ-Inu
1, 2. Ki ni ẹbun agbayanu ti o jẹ apakan àdámọ́ni wa?
LATI loye idi ti Ọlọrun ti fi fayegba ijiya ati ohun ti oun yoo ṣe nipa rẹ̀, a nilati ni imọriri fun bi oun ṣe dá wa. Oun ṣe ju wiwulẹ dá wa pẹlu kiki ara kan ati ọpọlọ kan. Oun tun dá wa pẹlu awọn animọ akanṣe ti ero-ori ati ero-imọlara.
2 Apa pataki kan ninu ohun ti o parapọ jẹ ero-ori ati ero-imọlara wa ni ominira ifẹ-inu. Bẹẹni, Ọlọrun gbin agbara ọgbọn-ero-ori ti ominira lati ṣe yiyan sinu wa.O jẹ ẹbun agbayanu kan lati ọdọ rẹ̀ nitootọ.
Bi A Ṣe Ṣẹda Wa
3-5. Eeṣe ti a fi mọriri ominira ifẹ-inu?
3 Ẹ jẹ ki a gbe bi ominira ifẹ-inu ṣe wemọ gbigba ti Ọlọrun gba ijiya laaye yẹwo. Lati bẹẹrẹ, ronu nipa eyi: Iwọ ha mọriri nini ominira lati ṣe yiyan ohun ti iwọ yoo ṣe ati ti iwọ yoo sọ, ohun ti iwọ yoo jẹ ati ti iwọ yoo wọ̀, iru iṣẹ ti iwọ yoo ṣe, ati nibo ati bawo ni iwọ yoo ṣe maa gbe? Tabi iwọ yoo ha fẹ ki ẹnikan maa pinnu gbogbo awọn ọ̀rọ̀ ati igbegbeesẹ rẹ fun ọ ni gbogbo ìgbà ṣáá ni igbesi-aye rẹ bi?
4 Kò si eniyan ti ori rẹ̀ pé ti ń fẹ pe ki a gba igbesi-aye rẹ̀ kuro ni ikawọ rẹ̀ patapata bẹẹ. Eeṣe ti kò fi ri bẹẹ? Nititori ọna ti Ọlọrun gba ṣẹda wa ni. Bibeli sọ fun wa pe Ọlọrun ṣẹda eniyan ni ‘aworan ati ìrí rẹ̀,’ ọkan lara awọn agbara ọgbọn-ero-ori ti Ọlọrun funraarẹ̀ ní ni ominira lati ṣe yiyan. (Genesisi 1:26; Deuteronomi 7:6) Nigba ti o ṣẹda awọn eniyan, o fun wọn ni agbara ọgbọn-ero-ori agbayanu kan-naa—ẹbun ominira ifẹ-inu. Idi kan niyẹn ti o fi maa ń jẹ ijakulẹ funni ti a bá wà labẹ awọn oluṣakoso atẹniloriba.
5 Nitori naa ifẹ ọkan fun ominira kii ṣe èèṣì, nitori pe Ọlọrun jẹ Ọlọrun ominira. Bibeli wi pe: “Nibi ti ẹmi Oluwa [“Jehofa,” NW] bá si wà, nibẹ ni ominira gbe wà.” (2 Korinti 3:17) Nitori eyi, Ọlọrun fun wa ni ominira ifẹ-inu gẹgẹ bi apakan àdámọ́ni tiwa. Niwọn bi oun ti mọ ọna ti ero-ori ati ero-imọlara wa yoo gba ṣiṣẹ, oun mọ̀ pe awa yoo layọ julọ pẹlu nini ominira ifẹ-inu.
6. Bawo ni Ọlọrun ṣe ṣẹda ọpọlọ wa lati ṣiṣẹ ni iṣọkan pẹlu ominira ifẹ-inu?
6 Lati bá ẹbun ominira ifẹ-inu rin, Ọlọrun fun wa ni agbara lati ronu, wọn awọn ọran wo, ṣe awọn ipinnu, ki a sì mọ̀ ẹ̀tọ́ yatọ si aitọ. (Heberu 5:14) Nipa bayii, ominira ifẹ-inu ni a nilati gbekari yiyan oloye. A kò dá wa bi ti awọn robot (ọmọlangidi ti a ń fi ẹ̀rọ kọmputa dari) alainironu ti kò ni ifẹ-inu tiwọn funraawọn. Bẹẹ sì ni a kò ṣẹda wa lati huwa lọna itẹsi-ihuwa adanida bii ti awọn ẹranko. Kaka bẹẹ, ọpọlọ wa agbayanu ni a wéwèé-gbekalẹ lati ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu ominira lati ṣe yiyan wa.
Ibẹrẹ Didara Julọ
7, 8. Ibẹrẹ didara wo ni Ọlọrun fifun awọn obi wa akọkọ?
7 Lati fi bi Ọlọrun ti bikita to han, papọ pẹlu ẹbun ominira ifẹ-inu, awọn obi wa akọkọ, Adamu ati Efa, ni a fun ni gbogbo ohun ti ẹnikẹni le fi pẹlu ilọgbọn-ninu fẹ. A fi wọn sinu paradise nla, ti o dabi ọgba itura kan. Wọn ni ọpọ yamura ohun ini. Wọn ni ero-ori ati ara pipe, ti wọn kì yoo fi nilati dagba di arugbo tabi ṣaisan tabi ku—wọn ìbá ti walaaye titi lae. Wọn ìbá ti ni awọn ọmọ pipe ti ìbá ti ni ọjọ iwaju ayeraye alayọ pẹlu. Awọn iye eniyan ti ń gbooro sii naa ìbá si ti ni iṣẹ afunni-nitẹlọrun ti sisọ gbogbo ilẹ̀-ayé di paradise ni gbẹ̀hìngbẹ́hín.—Genesisi 1:26-30; 2:15.
8 Nipa ohun ti a pese, Bibeli ṣalaye pe: “Ọlọrun si ri ohun gbogbo ti o dá, si kiyesi i, daradara ni.” (Genesisi 1:31) Bibeli tun sọ nipa Ọlọrun pe: “Pipe ni iṣẹ rẹ̀.” (Deuteronomi 32:4) Bẹẹni, Ẹlẹdaa naa fun idile eniyan ni ibẹrẹ pipe kan. Kò tun lè dara jubẹẹ lọ. Ẹ wo iru Ọlọrun ti o bikita ti o fẹri han pe oun jẹ!
Ominira Ninu Ààlà
9, 10. Eeṣe ti a fi gbọdọ fi eto diwọn ominira ifẹ-inu lọna titọ?
9 Bi o ti wu ki o ri, Ọlọrun ha pete pe ki ominira ifẹ-inu jẹ aláìlààlà bi? Finuwoye ilu-nla kan ti o kun fun igbokegbodo láìní awọn ofin irinna, nibi ti ẹnikẹni lè wakọ̀ si iha eyikeyii ni idiwọn ìyárasáré eyikeyii. Iwọ yoo ha fẹ lati wakọ̀ labẹ irufẹ ayika wọnyẹn bi? Bẹẹkọ, eyiini yoo jẹ irinna rúdurùdu laini akoso ti yoo si yọrisi ọpọlọpọ jamba ọkọ̀ dajudaju.
10 Bakan naa ni pẹlu ẹbun Ọlọrun ti ominira ifẹ-inu. Ominira aláìlààlà yoo tumọ si rúdurùdu laini akoso lawujọ. Awọn ofin nilati wà lati ṣakoso igbokegbodo eniyan. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pe: “Ẹ huwa gẹgẹ bi eniyan olominira, ẹ ma si ṣe lo ominira yin gẹgẹ bi awawi fun iwa buruku.” (1 Peteru 2:16, JB) Ọlọrun ń fẹ ki a fi eto diwọn ominira ifẹ-inu fun ire mùtúmùwà. Oun pete fun wa lati ni, kii ṣe ominira patapata, ṣugbọn ominira aláàlà, ti o wà labẹ akoso ofin.
Awọn Ofin Ta Ni?
11. Awọn ofin ta ni a wéwéè gbe wa kalẹ lati ṣegbọran si?
11 Awọn ofin ta ni a wéwèé gbe wa kalẹ lati ṣegbọran si? Apa miiran ninu ẹsẹ-iwe naa ninu 1 Peteru 2:16 (JB) ṣalaye pe: “Ẹyin kii ṣe ẹru ẹnikẹni ayafi Ọlọrun.” Eyi kò tumọ si isinru atẹniloriba, ṣugbọn, kaka bẹẹ, o tumọ si pe a wéwèé gbe wa kalẹ lati jẹ alayọ julọ nigba ti a bá wà labẹ itẹriba fun awọn ofin Ọlọrun. (Matteu 22:35-40) Awọn ofin rẹ̀, ju awọn ofin eyikeyii ti eniyan ṣeto gbekalẹ lọ, pese itọsọna didara julọ. “Emi ni Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun rẹ, ti o kọ́ ọ fun èrè, ẹni ti o tọ́ ọ ni ọna ti iwọ iba maa lọ.”—Isaiah 48:17.
12. Ominira lati ṣe yiyan wo ni a ní ninu ààlà awọn ofin Ọlọrun?
12 Lẹṣẹkan naa, awọn ofin Ọlọrun yọnda fun ominira lati ṣe yiyan ńláǹlà ninu awọn ààlà wọn. Eyi yọrisi nini oniruuru o sì mu ki idile eniyan wuni. Ronu nipa oriṣiriṣi ounjẹ, aṣọ wíwọ̀, orin aladun, ìṣẹ ọwọ́, ati awọn ibugbe jakejado aye. Dajudaju awa fẹ́ lati ṣe yíyàn tiwa ninu iru awọn ọran bẹẹ ju kí a ní ki ẹlomiran wá pinnu fun wa lọ.
13. Awọn ofin ti a lè fojuri wo ni a gbọdọ ṣegbọran si fun ire tiwa funraawa?
13 A ṣẹda wa nipa bayii lati jẹ alayọ julọ nigba ti a bá wà ni itẹriba fun awọn ofin Ọlọrun fun ihuwasi eniyan. O jọra pẹlu ṣiṣe igbọran si awọn ofin ti a lè fojuri ti Ọlọrun. Fun apẹẹrẹ, bi a bá ṣaika ofin òòfà sí ti a si bẹ́ silẹ lati ibi giga kan, a o farapa tabi ku. Bi a bá ṣaika awọn ofin inu ara wa sí ti a sì dawọ ounjẹ jijẹ, mimu omi, tabi mímí atẹgun sinu duro, awa yoo ku.
14. Bawo ni a ṣe mọ pe a kò ṣẹda awọn eniyan lati wa lominira kuro lọdọ Ọlọrun?
14 Bi o ti daju pe a ṣẹda wa pẹlu aini naa lati wà ni itẹriba si awọn ofin ti o ṣee fojuri ti Ọlọrun, a ṣẹda wa pẹlu aini naa lati wà ni itẹriba si awọn ofin Ọlọrun ti iwa rere ati ti ẹgbẹ-oun-ọgba. (Matteu 4:4) A kò ṣẹda awọn eniyan lati wà lominira kuro lọdọ Oluṣe wọn ki wọn si ṣe aṣeyọri. Wolii Jeremiah wi pe: “Kii ṣe ti eniyan ti ń rin ani lati tọ iṣisẹ rẹ̀. Tọ mi sọna, Oo Jehofa.” (Jeremiah 10:23, 24, NW) Nitori naa ni gbogbo ọna a ṣẹda awọn eniyan lati gbe labẹ iṣakoso Ọlọrun, kii ṣe tiwọn funraawọn.
15. Njẹ awọn ofin Ọlọrun ìbá ti jẹ ẹru inira fun Adamu ati Efa bi?
15 Ṣiṣe igbọran si awọn ofin Ọlọrun kìbá tí jẹ ẹru inira fun awọn obi wa akọkọ. Kaka bẹẹ, ìbá ti ṣiṣẹyọri fun ire wọn ati ti gbogbo idile eniyan. Ibaṣepe awọn meji akọkọ kò rekọja ààlà awọn ofin Ọlọrun ni, gbogbo nǹkan ìbá lọ deedee. Nitootọ, awa nisinsinyi ìbá maa gbe ninu paradise agbayanu onitẹlọrun kan gẹgẹ bi idile eniyan oniṣọkan ati onifẹẹ kan! Kìbá má ti sí iwa buburu, ijiya, ati iku.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ẹlẹdaa naa fun awọn eniyan ni ibẹrẹ pipe kan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Iwọ yoo ha fẹ wakọ̀ ninu òpópónà ti igbokegbodo irinna kun fọfọ bi kò bá si ofin irinna kankan rara bi?