Ẹ Maa Gbé Ẹnikinni Keji Ró
“Ki ọ̀rọ̀ idibajẹ kan maṣe ti ẹnu yin jade, bikoṣe ọ̀rọ̀ eyikeyii ti o dara fun igbeniro.”—EFESU 4:29, NW.
1, 2. (a) Eeṣe ti a fi lè sọ ọ́ lọna titọna pe ọ̀rọ̀ sisọ jẹ́ iyanu kan? (b) Ikilọ wo ni o yẹ nipa ọ̀nà ti a gbà ń lo ahọ́n wa?
“ỌRỌ SISỌ jẹ́ okùn agbayanu naa ti ń so awọn ọ̀rẹ́, idile ati ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà papọ . . . Lati inu ero inu eniyan ati ìsúnkìmọ́ra ọ̀wọ́ awọn iṣu ẹran [ahọ́n] ti ń ṣiṣẹ ṣọkan, awa ń mú ìró ti ń múni nimọlara ifẹ, owú, ọ̀wọ̀—niti gidi eyikeyii ninu ero imọlara eniyan jade.”—Hearing, Taste and Smell.
2 Ahọ́n wa fi pupọpupọ ju ohun eelo kan ti a ń lo fun ìgbémì tabi ìtọ́wò lọ; ó jẹ́ apakan lara agbara-iṣe wa lati ṣajọpin ohun ti a ń rò ati imọlara wa. “Ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà kekere,” ni Jakọbu kọwe. “Oun ni awa fi ń yin Oluwa [“Jehofa,” NW] ati Baba, oun ni a sì fi ń bú eniyan, ti a dá ni aworan Ọlọrun.” (Jakọbu 3:5, 9) Bẹẹni, awa lè lo ahọ́n wa ni awọn ọ̀nà rere bii fifi yin Jehofa. Ṣugbọn ni jíjẹ́ alaipe, a lè fi tirọruntirọrun lo ahọ́n wa lati fi sọrọ apanilara tabi ohun ti o buru. Jakọbu kọwe pe: “Ẹyin ará mi, nǹkan wọnyi kò yẹ́ ki o ri bẹẹ.”—Jakọbu 3:10.
3. A gbọdọ fun apá ìhà meji wo nipa ọ̀rọ̀ sisọ wa ni afiyesi?
3 Nigba ti kò si eniyan kankan ti o lè ṣakoso ahọ́n rẹ̀ lọna pipe, pẹlu idaniloju awa nilati lakaka lati ṣe imusunwọnsii. Aposteli Paulu gbà wá nimọran pe: “Ki ọ̀rọ̀ idibajẹ kan maṣe ti ẹnu yin jade, bikoṣe ọ̀rọ̀ eyikeyii ti o dara fun ìgbéniró gẹgẹ bi aini naa bá ti wà, ki o lè fi ohun ti o wọ̀ fun awọn olugbọ.” (Efesu 4:29, NW) Ṣakiyesi pe ọ̀rọ̀ ìyànjú yii pín si apá ìhà meji: Ohun ti awa nilati lakaka lati yẹra fun ati ohun ti awa gbọdọ gbidanwo lati ṣe. Ẹ jẹ ki a gbé apa ìhà mejeeji yẹwo.
Yiyẹra fun Ọ̀rọ̀ Idibajẹ
4, 5. (a) Ijakadi wo ni awọn Kristian ní nipa ọ̀rọ̀ rírùn? (b) Aworan wo ni o yẹ àpólà-ọ̀rọ̀ naa “ọ̀rọ idibajẹ”?
4 Efesu 4:29 lakọọkọ rọ̀ wá pe: “Ki ọ̀rọ̀ idibajẹ kan maṣe ti ẹnu yin jade.” Iyẹn lè má rọrun. Idi kan ni pe ọ̀rọ̀ isọkusọ wọ́pọ̀ tobẹẹ ninu ayé ti o yí wa ká. Ọpọlọpọ awọn ọ̀dọ́ Kristian ń gbọ́ ọ̀rọ̀ isọkusọ lojoojumọ, nitori awọn ọmọ ile-iwe ẹlẹgbẹ wọn lè ronu pe o ń fikun itẹnumọ tabi mu ki wọn farahan bii ẹni ti o tubọ le jù. Ó lè má ṣeeṣe fun wa lẹkun-un-rẹrẹ lati yẹra fun gbigbọ awọn ọ̀rọ̀ rírùn, ṣugbọn awa lè a sì gbọdọ ṣe isapa àfẹ̀rí-ọkàn ṣe lati maṣe gbà wọn sinu. Wọn kò ni ààyè kankan ninu ero-inu ati ẹnu wa.
5 Labẹ ọ̀rọ̀ ikilọ Paulu ni ọrọ Griki kan ti o nii ṣe pẹlu ẹja ti o ti bajẹ tabi eso ti ó ti rà wà. Fi inu ro eyi: Iwọ rí ọkunrin kan ti kò ni suuru ti o sì gbanajẹ ní kiakia. Nikẹhin ó bú jade, iwọ sì rí ẹja rírà kan ti o ń jade ni ẹnu rẹ̀. Lẹhin naa iwọ ri eso jijẹra ti ń bù tìì ti ó yí gbiri jade, ti ó sì fọ́n si gbogbo awọn ti ó wà nitosi lara. Ta ni oun jẹ? Bawo ni yoo ti buru tó bi oun bá jẹ́ eyikeyii lara wa! Sibẹ, iru aworan bẹẹ lè ṣe rẹgi bi awa bá ‘jẹ ki awọn ọ̀rọ̀ idibajẹ ti ẹnu wa jade.’
6. Bawo ni Efesu 4:29 ṣe kan ọ̀rọ̀ sisọ lilekoko, ti ó lòdì?
6 Ifisilo miiran fun Efesu 4:29 ni pe ki a yẹra fun jíjẹ́ ẹni ti o lekoko ju nigba gbogbo. A gbà pe, gbogbo wa ní ero ati yíyàn nipa awọn ohun ti a kò fẹran tabi tẹwọgba, ṣugbọn iwọ ha ti wà ni ayika ẹnikan ti o jọ pe o ni ọ̀rọ̀ odi kan (tabi ọ̀rọ̀ odi pupọ) nipa gbogbo eniyan, ibikibi tabi ohunkohun ti a bá mẹnuba? (Fiwe Romu 12:9; Heberu 1:9.) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń ba nǹkan jẹ́, ń munisorikọ tabi ń ṣeparun. (Orin Dafidi 10:7; 64:2-4; Owe 16:27; Jakọbu 4:11, 12) Ó lè má mọ bi oun ti jọ awọn alárìíwísí tí Malaki ṣapejuwe tó. (Malaki 3:13-15) Bawo ni àyà rẹ̀ ìbá ti já tó bi ẹnikan ti o wà nitosi bá sọ fun un pe ẹja rírà ati eso jijẹra ń yọ́ pọ́rọ́ jade ni ẹnu rẹ̀!
7. Ìṣàyẹ̀wò ara-ẹni wo ni ẹnikọọkan wa nilati ṣe?
7 Nigba ti ó rọrun lati tete mọ̀ bí ẹnikan bá ń sọ awọn ọ̀rọ̀ ti o lodi tabi ti o lekoko leralera, beere lọwọ araarẹ pe, ‘Emi ha tẹsi lati dà bẹẹ bi? Niti tootọ, mo ha jẹ bẹẹ bi?’ Yoo jẹ́ ohun ti o lọgbọn-ninu lati ronu lẹẹkọọkan lori ète naa ti ọ̀rọ̀ wa ni. Wọn ha jẹ́ ti òdì ni pataki, tí ó sì lekoko bi? Awa ha ń sọrọ bi awọn èké olutunu mẹta Jobu bi? (Jobu 2:11; 13:4, 5; 16:2; 19:2) Eeṣe ti iwọ kò fi wá apá ẹ̀ka didara kan lati mẹnuba? Bi ijumọsọrọpọ kan bá jẹ́ eyi ti o lekoko lọpọ julọ, eeṣe ti o kò fi yi i si awọn ọ̀ràn agbéniró?
8. Malaki 3:16 pese ẹ̀kọ́ wo niti ọ̀rọ̀ sisọ, bawo sì ni a ṣe lè fihàn pe a ń fi ẹ̀kọ́ naa silo?
8 Malaki fi iyatọ ifiwera yii hàn pe: “Nigba naa ni awọn ti o bẹru Oluwa [“Jehofa,” NW] ń ba araawọn sọrọ nigbakugba; Oluwa [“Jehofa,” NW] sì tẹ́tí si i, ó sì gbọ́, a sì kọ iwe iranti kan niwaju rẹ̀, fun awọn ti o bẹru Oluwa [“Jehofa,” NW], ti wọn sì ń ṣe aṣaro orukọ rẹ̀.” (Malaki 3:16) Iwọ ha ṣakiyesi bi Ọlọrun ṣe dahunpada si awọn ọ̀rọ̀ ti ń gbéniró bi? Ki ni o ṣeeṣe ki iru ijumọsọrọpọ bẹẹ ni lori awọn alabaakẹgbẹpọ? Awa lè kọ́ ẹ̀kọ́ kan nipa ọ̀rọ̀ wa ojoojumọ. Bawo ni yoo ti tubọ dara fun awa ati awọn ẹlomiran tó bi iru ijumọsọrọpọ wa kan bá ṣàgbéyọ ‘irubọ ọpẹ wa si Ọlọrun.’—Heberu 13:15.
Ṣiṣẹ Lori Gbígbé Awọn Ẹlomiran Ró
9. Eeṣe ti awọn ipade Kristian fi jẹ akoko rere lati gbé awọn ẹlomiran ró?
9 Awọn ipade ijọ jẹ akoko pipegede lati sọ ọ̀rọ̀ “eyikeyii ti o dara fun ìgbéniró gẹgẹ bi aini naa bá ti wà, ki o lè fi ohun ti o wọ̀ fun awọn olugbọ.” (Efesu 4:29, NW) Awa lè ṣe iyẹn nigba ti a bá ń sọ ọ̀rọ̀ lori isọfunni Bibeli, ti a bá ń nípìn-ín ninu àṣefihàn, tabi ṣalaye ninu awọn apá ti o ni ibeere ati idahun. Awa tipa bẹẹ jẹrii si Owe 20:15 pe: “Ètè ìmọ̀, eelo iyebiye ni.” Ta ni ó sì mọ iye ọkàn ti yoo kàn tabi ti yoo gbéró?
10. Lẹhin rironu siwa-sẹhin lori awọn ti a ti sábà maa ń bá jumọsọrọpọ, atunṣebọsipo wo ni ó lè wà deedee? (2 Korinti 6:12, 13)
10 Akoko ṣaaju ati lẹhin ipade tun rọrun fun gbigbe awọn ẹlomiran ró pẹlu awọn ọ̀rọ̀ ti o wọ̀ fun awọn ti ń gbọ́. Ó lè rọrun lati lo akoko yii ninu nini ijumọsọrọpọ gbigbadunmọni pẹlu awọn molẹbi ati awọn ọ̀rẹ́ kéréje ti a maa ń gbadun itura ti ara lọdọ wọn. (Johannu 13:23; 19:26) Bi o ti wu ki o ri, ni ìlà pẹlu Efesu 4:29, eeṣe ti iwọ kò fi wá awọn ẹlomiran lati bá sọrọ? (Fiwe Luku 14:12-14.) A lè pinnu ṣaaju lati lọ rekọja sisọ ẹ kú deedee iwoyi o lori eré tabi lọna aṣa si awọn ẹni titun kan, awọn agbalagba tabi awọn ọmọde koda ni jijokoo pẹlu awọn ọmọde ki a baa lè tubọ fi ara wa si ipo wọn. Ojulowo ìfẹ́-ọkàn ati akoko ọ̀rọ̀ agbéniró yoo mu ki awọn ẹlomiran tilẹ lè sọ asọtunsọ ero-imọlara Dafidi ni Orin Dafidi 122:1.
11. (a) Àṣà wo ni awọn kan ti mu dagba nipa jijokoo? (b) Eeṣe ti awọn kan fi ń mọọmọ jokoo sibi ọtọọtọ?
11 Iranlọwọ miiran si ijumọsọrọpọ ti ń gbéniró ni jijokoo nibi ọtọọtọ ni awọn ipade. Abiyamọ kan lè nilati jokoo si itòsí ile itura, tabi alailera kan le nilati nilo ibi ijokoo ti ó ní ààyè ìbákọjá, ṣugbọn ki ni nipa awa yooku? Àṣà amọnilara kan-naa lè mu kí a maa pada si ijokoo tabi agbegbe kan pàtó; koda ẹyẹ kan a maa pada sinu ìtẹ́ rẹ̀ laitase. (Isaiah 1:3; Matteu 8:20) Bi o ti wu ki o ri, laifọrọ sabẹ ahọ́n sọ, niwọn bi a ti lè jokoo si ibikibi, eeṣe ti a kò fi mu aaye ijokoo wa yatọsira—apa ọ̀tún, apa osi, ẹ̀bá iwaju ati bẹẹ bẹẹ lọ—ki a sì tipa bẹẹ dojulumọ lọna ti ó sàn jù pẹlu awọn ẹni yiyatọsira? Nigba ti kò sí ilana kankan pe ki a ṣe eyi, awọn alagba ati awọn adagbadenu miiran ti wọn maa ń yi ibi ti wọn ń jokoo si pada ti rii pe o rọrun lati fi ohun ti ó wọ̀ fun ọpọlọpọ dipo ki o wulẹ jẹ kìkì iwọnba awọn ọ̀rẹ́ ti o sunmọ wọn.
Gbéniró ni Ọ̀nà Bii Ti Ọlọrun
12. Itẹsi ti kò dara wo ni o ti farahan jalẹ ìtàn?
12 Ìfẹ́-ọkàn Kristian lati gbé awọn ẹlomiran ró gbọdọ sun un lati ṣafarawe Ọlọrun lọna yii dipo titẹle itẹsi eniyan ti titẹle ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn ofin.a Awọn eniyan alaipe ti fi ìgbà pipẹ ni itẹsi lati ṣakoso lori awọn ti o yi wọn ká, koda awọn iranṣẹ Ọlọrun diẹ ti juwọsilẹ fun imọlara yii. (Genesisi 3:16; Oniwasu 8:9) Ni ọjọ Jesu awọn aṣaaju isin Ju “di ẹrù wuwo ti ó si ṣoro lati rù, wọn a sì gbé e ka awọn eniyan ni ejika; ṣugbọn awọn tikaraawọn kò jẹ́ fi ìka wọn kan ẹrù naa.” (Matteu 23:4) Wọn yí awọn àṣà alailepanilara pada si ofin atọwọdọwọ aigbọdọmaṣe. Ninu aniyan aniju wọn nipa ofin eniyan, wọn gbojufo awọn ohun ti Ọlọrun fihàn pe o ṣe pataki ju. Kò si ẹni kankan ti wọn gbéró nipa ṣiṣe ọpọ ofin wọn ti kò ba iwe mimọ mu; ọ̀nà wọn kì í ṣe ọ̀nà Ọlọrun.—Matteu 23:23, 24; Marku 7:1-13.
13. Eeṣe ti kò fi yẹ lati humọ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ofin fun awọn Kristian ẹlẹgbẹ wa?
13 Awọn Kristian ń fẹ́ lati dìrọ̀ mọ́ awọn ofin atọrunwa niti tootọ. Bi o tilẹ jẹ pe, awa, lè ṣubu sọwọ itẹsi lati ṣe ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn ofin ti o nira. Eeṣe? Fun ohun kan, awọn ohun ti ẹnikan fẹ́ tabi ohun ti ẹnikan yàn yatọ sira, nitori naa awọn kan lè rí ohun ti ẹlomiran koriira ti o sì nimọlara pe a gbọdọ wọgi lé gẹgẹ bi ohun ti o ṣetẹwọgba. Awọn Kristian yatọ sira, pẹlu, ninu ilọsiwaju wọn siha idagbadenu nipa tẹmi. Ṣugbọn ǹjẹ́ ṣiṣe ọpọlọpọ ofin ha ni ọ̀nà bii ti Ọlọrun lati ran awọn ẹlomiran lọwọ lati tẹsiwaju siha idagbadenu bi? (Filippi 3:15; 1 Timoteu 1:19; Heberu 5:14) Àní nigba ti ẹnikan bá ń lépa ipa-ọna kan ti o farahan bi eyi ti o légbákan tabi tí ó lewu niti tootọ, ǹjẹ́ ofin ìkàléèwọ̀ ha ni ojutuu ti o dara julọ bi? Ọ̀nà Ọlọrun ni fun awọn ti o tootun lati gbiyanju lati mú ẹnikan ti o ṣìnà padabọsipo nipa fifi ọkàntútù bá ẹni yẹn ronu pọ̀.—Galatia 6:1.
14. Awọn ète wo ni ofin ti Ọlọrun fifun Israeli ṣiṣẹ fun?
14 Loootọ, nigba ti ó ń lo Israeli gẹgẹ bi awọn eniyan rẹ̀, Ọlọrun lànà ọgọrọọrun awọn ofin silẹ nipa ijọsin inu tẹmpili, awọn irubọ, àní imọtoto paapaa. Eyi jẹ́ ohun yíyẹ fun orilẹ-ede yiyatọ gédégbé kan, ọpọlọpọ ninu awọn ofin naa sì ni ijẹpataki alasọtẹlẹ ó sì ṣeranwọ lati ṣamọna awọn Ju si Messia naa. Paulu kọwe pe: “Nitori naa ofin ti jẹ́ olukọni lati múni wá sọdọ Kristi, ki a lè dá wa lare nipa igbagbọ. Ṣugbọn lẹhin ìgbà ti igbagbọ ti de, awa kò sí labẹ olukọni mọ.” (Galatia 3:19, 23-25) Lẹhin ti a ti fagi lé Ofin lori òpó igi idaloro, Ọlọrun kò fun awọn Kristian ni itotẹlera gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ awọn ofin lori ọpọ julọ apá ìhà igbesi-aye, bi ẹni pe iyẹn ni ọ̀nà lati gbà gbé wọn ró ninu igbagbọ.
15. Itọsọna wo ni Ọlọrun ti pese fun awọn Kristian olujọsin?
15 Dajudaju, a kò wà lailofin. Ọlọrun paṣẹ fun wa lati takete si ibọriṣa, agbere ati panṣaga, ati ilokulo ẹ̀jẹ̀. Ó ka iṣikapaniyan, irọ́ pípa, ìbẹ́mìílò, ati awọn oniruuru ẹṣẹ miiran léèwọ̀ ni pàtó. (Iṣe 15:28, 29; 1 Korinti 6:9, 10; Ìfihàn 21:8) Ó sì pese imọran kedere lori ọpọlọpọ ọ̀ràn ninu Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Sibẹ, dé ìwọ̀n giga ju bi ó ti rí pẹlu awọn ọmọ Israeli lọ, awa lẹ́rù iṣẹ lati kẹkọọ ki a sì fi awọn ilana Bibeli silo. Awọn alagba lè gbé awọn ẹlomiran ró nipa ríràn wọn lọwọ lati rí ki wọn sì gbé awọn ilana wọnyi yẹwo dipo wiwulẹ wá tabi ṣe awọn ofin.
Awọn Alagba Ti Wọn Ń Gbéniró
16, 17. Awọn aposteli fi apẹẹrẹ rere wo lélẹ̀ nipa ṣiṣe ofin fun awọn olujọsin ẹlẹgbẹ wọn?
16 Paulu kọwe pe: “Ibi ti a ti dé ná, ẹ jẹ́ ki a maa rìn ni oju-ọna kan-naa.” (Filippi 3:16) Ni ìlà pẹlu oju-iwoye bii ti Ọlọrun yẹn, aposteli naa ba awọn ẹlomiran lò ni ọ̀nà ti ó gbéniró. Fun apẹẹrẹ, ibeere kan dide nipa yala lati jẹ ẹran ti ó ti lè wá lati inu tẹmpili oriṣa kan. Ǹjẹ́ alagba yii, boya fun ète iṣedeedee delẹ tabi ìmúrọrùn, lànà ofin diẹ fun gbogbo awọn ti wọn wà ninu ijọ ijimiji bi? Bẹẹkọ. Oun gba pe oniruuru ninu ìmọ̀ ati itẹsiwaju siha idagbadenu lè ṣamọna awọn Kristian wọnni dori yíyàn yiyatọ sira. Ni tirẹ, oun pinnu lati gbé apẹẹrẹ rere kalẹ.—Romu 14:1-4; 1 Korinti 8:4-13.
17 Iwe Mimọ Kristian lede Griki fihàn pe awọn aposteli pese imọran ti ń ranni lọwọ nitootọ lori awọn ọ̀ràn ara-ẹni melookan, iru bii nipa aṣọ wíwọ̀ ati ìmúra, ṣugbọn wọn kò yijusi ṣiṣe awọn ofin ti o ṣee fisilo ninu gbogbo ọ̀ràn. Lonii eyi jẹ́ apẹẹrẹ rere fun awọn Kristian alaboojuto, awọn ti wọn nifẹẹ ọkàn ninu gbígbé agbo ró. Ó sì mú ọ̀nà ti Ọlọrun gbà bá Israeli igbaani lò paapaa gbooro siwaju.
18. Jehofa fun Israeli ni ofin wo nipa aṣọ wíwọ̀?
18 Ọlọrun kò fun awọn ọmọ Israeli ni ofin jàn-ànràn-jan-an-ran nipa iwọṣọ. Ni kedere awọn ọkunrin ati obinrin lo aṣọ-àlàbora, tabi ẹ̀wù awọleke ti o jọra, bi o tilẹ jẹ pe ti obinrin kan ni a lè pa láró tabi ki o tubọ jẹ́ aláwọ̀ mèrèmèrè. Awọn ẹ̀yà mejeeji tún ń wọ sa·dhinʹ, tabi ẹ̀wù-àwọ̀tẹ́lẹ̀. (Onidajọ 14:12; Owe 31:24; Isaiah 3:23) Awọn ofin wo nipa aṣọ wíwọ̀ ni Ọlọrun fifunni? Kò gbọdọ sí yala ọkunrin tabi obinrin ti o gbọdọ wọ awọn aṣọ ti a mọ̀ mọ ẹ̀yà odikeji, ni kedere pẹlu èrò ibẹya-kan-naa-lopọ lọkan. (Deuteronomi 22:5) Lati fi yíyàtọ̀ ti wọn yàtọ̀ si awọn orilẹ-ede ti o yi wọn ka hàn, awọn ọmọ Israeli ni wọn nilati fi wajawaja si etí ẹ̀wù wọn, pẹlu fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù loke wajawaja naa, ati boya ìṣẹ́tí-aṣọ ni igun aṣọ-àlàbora naa. (Numeri 15:38-41) Iyẹn ní ipilẹ jẹ́ gbogbo itọsọna ti Ofin fi funni nipa ọ̀nà ìgbàwọṣọ.
19, 20. (a) Itọsọna wo ni Bibeli fifun awọn Kristian lori ìwọṣọ ati ìmúra? (b) Oju-iwoye wo ni awọn alagba gbọdọ ní nipa ṣiṣe awọn ofin nipa irisi ara-ẹni?
19 Nigba ti awọn Kristian kò sí labẹ Ofin, awa ha ní awọn kulẹkulẹ ofin miiran nipa iwọṣọ tabi ìṣọ̀ṣọ́ ti a lana rẹ̀ silẹ fun wa ninu Bibeli bi? Kì í ṣe bẹẹ niti gidi. Ọlọrun pese awọn ilana ti o wà deedee ti a lè fisilo. Paulu kọwe pe: “Ki awọn obinrin ki o fi aṣọ iwọntunwọnsi ṣe araawọn ni ọ̀ṣọ́, pẹlu itiju ati ìwà airekọja; kì í ṣe pẹlu irun dídì ati wura, tabi pearli, tabi aṣọ olowo iyebiye.” (1 Timoteu 2:9) Peteru rọni pe dipo kiko afiyesi jọ sori ìṣaralọ́ṣọ̀ọ́, awọn Kristian obinrin gbọdọ ko afiyesi jọ sori “ẹni ti o farasin ni ọkàn, ninu ọ̀ṣọ́ aidibajẹ ti ẹmi irẹlẹ ati ẹmi tutu.” (1 Peteru 3:3, 4) Pe a ṣakọsilẹ iru imọran bẹẹ damọran pe awọn Kristian kan ni ọrundun kìn-ín-ní ni aini ti nilati wà fun lati tubọ wà niwọntunwọnsi ki wọn sì kó araawọn nijaanu ninu iwọṣọ ati ìmúra wọn. Sibẹ, dipo bibeere fun—tabi kíka—awọn ọ̀nà ìgbàwọṣọ kan leewọ, awọn aposteli wulẹ pese amọran tí ń gbéniró ni.
20 A gbọdọ bọwọ a sì bọwọ fun Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni gbogbogboo fun irisi oniwọntunwọnsi wọn. Bi o tilẹ ri bẹẹ, awọn ọ̀nà ìgbàwọṣọ yàtọ̀ lati orilẹ-ede si orilẹ-ede ati laaarin agbegbe kan tabi ijọ paapaa. Niti tootọ, alagba kan ti ó ni awọn èrò lilagbara tabi ohun ti ó wù ú ninu ìwọṣọ ati ìmúra lè pinnu lọna bẹẹ gẹgẹ fun araarẹ̀ ati idile rẹ̀. Ṣugbọn niti agbo, oun nilati fi kókó Paulu sọ́kàn pe: “Kì í ṣe nitori ti awa tẹ gàba lori igbagbọ yin, ṣugbọn awa jẹ́ oluranlọwọ ayọ yin: nitori ẹyin duro nipa igbagbọ.” (2 Korinti 1:24) Bẹẹni, ní didena agbara àtinúdá eyikeyii lati gbé awọn ofin kalẹ fun ijọ, awọn alagba ń ṣiṣẹ lati gbé igbagbọ awọn miiran ró.
21. Bawo ni awọn alagba ṣe lè pese iranlọwọ ti ń gbéniró bi ẹnikan bá ń ṣe àṣerégèé ninu ìwọṣọ?
21 Gẹgẹ bi o ti rí ni ọrundun kìn-ín-ní, nigba miiran ẹni titun kan tabi ẹni ti o jẹ alailera nipa tẹmi kan lè tẹle ipa-ọna ti o gbé ibeere dide tabi ti kò bá ọgbọ́n mu ninu ìwọṣọ tabi ìlò ìtúnraṣe tabi ohun ọ̀ṣọ́. Ki ni nigba naa? Lẹẹkan si, Galatia 6:1 pese itọsọna fun awọn Kristian alagba ti wọn fi otitọ-inu fẹ́ lati ṣeranwọ. Ṣaaju ki alagba kan tó pinnu lati pese imọran, oun lè fi ọgbọ́n wadii ọ̀rọ̀ wò lọdọ alagba ẹlẹgbẹ rẹ̀ kan, a fọwọsi pe ki ó má lọ sọdọ alagba kan ti ó mọ̀ pe ó ṣajọpin ohun ti oun nifẹẹ sí tabi èrò rẹ̀. Bi àṣà ayé ninu ọ̀nà ìwọṣọ tabi ìmúra bá dabi eyi ti ń nipa lori ọpọlọpọ ninu ijọ, ẹgbẹ́ awọn alagba lè jiroro ọ̀nà ti o dara julọ lati gbà pese iranlọwọ, iru bii apá oninuure kan, ti ń gbéniró ninu ipade tabi nipa pipese itilẹhin lẹnikọọkan. (Owe 24:6; 27:17) Gongo wọn yoo jẹ́ lati fun oju-iwoye ti a fihàn ni 2 Korinti 6:3 niṣiiri pe: “A kò sì ṣe ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ohunkohun, ki iṣẹ-iranṣẹ ki o maṣe di isọrọ buburu si.”
22. (a) Eeṣe ti kò fi gbọdọ maa yọnilẹnu bi awọn oju-iwoye ọtọọtọ bá wà? (b) Apẹẹrẹ rere wo ni Paulu pese?
22 Awọn Kristian alagba ti ‘ń ṣabojuto agbo Ọlọrun ni ikawọ wọn’ ń fẹ́ lati ṣe gẹge bi Peteru ti lapa èrò rẹ̀, iyẹn ni pe, ‘lai lo agbara lori ijọ.’ (1 Peteru 5:2, 3) Ninu ipa iṣẹ onifẹẹ wọn, awọn ibeere lè dide lori awọn ọ̀ràn nibi ti ìyànláàyò ọtọọtọ lè wà. Boya àṣà adugbo ni lati duro lati ka awọn ipinrọ nigba Ikẹkọọ Ilé-Ìṣọ́nà. Iṣeto awujọ fun iṣẹ-isin pápá ati ọpọ awọn kulẹkulẹ miiran nipa iṣẹ-ojiṣẹ funraarẹ ni a lè bojuto ni ọ̀nà ti ó bá adugbo mu. Sibẹ, yoo ha jẹ́ eléwu bi ẹnikan bá ni ọ̀nà ti ó yatọ fẹẹrẹ bi? Awọn alaboojuto onifẹẹ nífẹ̀ẹ́-ọkàn pe ki ‘ohun gbogbo di ṣiṣe tẹyẹtẹyẹ ati lẹsẹlẹṣẹ,’ ede isọrọ naa ti Paulu lò nipa awọn ẹbun oniṣẹ iyanu. Ṣugbọn ayika ọ̀rọ̀ fihàn pe patakì ífẹ ọkan Paulu ni “idagbasoke [“ìgbéró,” NW] ijọ. (1 Korinti 14:12, 40) Oun kò fi itẹsi èrò kankan hàn lati ṣe ọpọ ofin ti kò lopin, bi ẹni pe ibaramu patapata tabi ijafafa latokedelẹ ni gongo pataki ti ó fojusun. Ó kọwe pe: “Oluwa ti fi [ọla-aṣẹ] fun wa fun idagbasoke yin kì í ṣe fun ibiṣubu yin.”—2 Korinti 10:8.
23. Ki ni awọn ọ̀nà diẹ ninu eyi ti a lè gbà ṣafarawe apẹẹrẹ Paulu nipa gbígbé awọn ẹlomiran ró?
23 Paulu laiṣiyemeji ṣiṣẹ lati gbé awọn miiran ró nipa ọ̀rọ̀ agbeniro ati afunni niṣiiri. Dipo kikẹgbẹpọ pẹlu kìkì agbo awọn ọ̀rẹ̀ diẹ, oun ṣe isapa akanṣe lati ṣebẹwo sọdọ ọpọlọpọ awọn arakunrin ati arabinrin, ati awọn ti wọn lagbara nipa tẹmi ati awọn wọnni ti aini wa fun ni pataki lati di ẹni ti a gbéró. Oun sì tẹnumọ ifẹ—dipo awọn ofin—nitori “ifẹ nii gbéniró.”—1 Korinti 8:1.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Laaarin idile kan oniruuru ofin lè jọ bi eyi ti o yẹ ni ṣiṣe, ní sísinmi lori awọn ipo ayika. Bibeli paṣẹ fun awọn obi lati pinnu awọn ọ̀ràn fun awọn ọmọ wọn keekeeke.—Eksodu 20:12; Owe 6:20; Efesu 6:1-3.
Awọn Kókó Atunyẹwo
◻ Eeṣe ti iyipada fi yẹ bi a bá nítẹsì siha ọ̀rọ̀ sisọ ti ó lodi tabi ti o lekoko?
◻ Ki ni a lè ṣe lati tubọ jẹ́ agbéniró ninu ijọ?
◻ Ki ni apẹẹrẹ bii ti Ọlọrun nipa ṣiṣe ọpọlọpọ ofin fun awọn ẹlomiran?
◻ Ki ni yoo ran awọn alagba lọwọ lati yẹra fun ṣiṣe awọn ofin eniyan fun agbo?