Òwe
24 Má ṣe jowú àwọn ẹni ibi,
Má sì jẹ́ kó máa wù ọ́ láti bá wọn kẹ́gbẹ́,+
2 Nítorí ìwà ipá ni ọkàn wọn ń rò,
Ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ ìjàngbọ̀n.
5 Ẹni tó gbọ́n jẹ́ alágbára,+
Ìmọ̀ sì ni èèyàn fi ń mú kí agbára rẹ̀ pọ̀ sí i.
8 Ẹnikẹ́ni tó bá ń gbèrò ibi,
Ọ̀gá elétekéte la ó máa pè é.+
11 Gba àwọn tí wọ́n fẹ́ lọ pa sílẹ̀,
Sì fa àwọn tó ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ lọ sí ibi pípa sẹ́yìn.+
13 Ọmọ mi, jẹ oyin, nítorí ó dára;
Oyin inú afárá sì ń dùn lẹ́nu.
14 Lọ́nà kan náà, mọ̀ pé ọgbọ́n dára fún ọ.*+
Tí o bá wá a rí, ọjọ́ ọ̀la rẹ á dára
Ìrètí rẹ kò sì ní pa rẹ́.+
15 Má ṣe lúgọ sí tòsí ilé olódodo láti ṣe é níbi;
Má ṣe ba ibi ìsinmi rẹ̀ jẹ́.
16 Nítorí olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje, á sì tún dìde,+
Àmọ́ àjálù yóò mú kí ẹni burúkú ṣubú pátápátá.+
17 Tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú, má ṣe dunnú,
Tó bá sì kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ yọ̀;+
18 Nítorí Jèhófà yóò rí i, á sì bí i nínú,
19 Má ṣe kanra* nítorí àwọn aṣebi;
Má ṣe jowú àwọn ẹni ibi.
21 Ọmọ mi, bẹ̀rù Jèhófà àti ọba.+
Má sì bá àwọn oníyapa* kẹ́gbẹ́.+
22 Nítorí àjálù wọn yóò dé lójijì.+
Ta ló mọ ìparun tí àwọn méjèèjì* máa mú bá wọn?+
23 Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tún jẹ́ ti àwọn ọlọ́gbọ́n:
Kò dára láti máa ṣe ojúsàájú nínú ìdájọ́.+
24 Ẹni tó bá ń sọ fún ẹni burúkú pé, “Olódodo ni ọ́,”+
Àwọn èèyàn yóò gégùn-ún fún un, àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì dá a lẹ́bi.
26 Àwọn èèyàn yóò fi ẹnu ko ètè ẹni tó ń fi òótọ́ inú fèsì.*+
27 Múra iṣẹ́ tí o máa ṣe lóde sílẹ̀, kí o sì wá gbogbo nǹkan sílẹ̀ ní pápá;
Lẹ́yìn náà, kọ́ ilé* rẹ.
28 Má ṣe ta ko ọmọnìkejì rẹ láìnídìí.+
Má ṣe fi ètè rẹ tanni jẹ.+
32 Mo kíyè sí i, mo sì fi í sọ́kàn;
Mo rí i, mo sì kọ́ ẹ̀kọ́* yìí:
33 Oorun díẹ̀, ìtòògbé díẹ̀,
Kíkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi,
34 Ipò òṣì rẹ yóò sì dé bí olè,
Àti àìní rẹ bí ọkùnrin tó dìhámọ́ra.+