Eré-Ìnàjú Ẹgbẹ́-Òun-Ọ̀gbà—Gbadun Awọn Anfaani Rẹ̀, Yẹra fun Awọn Idẹkun Rẹ̀
“Kò sí ohun ti ó dara fun eniyan ju ki o jẹ, ki o sì mu ati ki ó mú ọkàn rẹ̀ jadun ohun rere ninu làálàá rẹ̀.”—Oniwasu 2:24.
1. Ni awọn ọ̀na wo ni itọsọna Ọlọrun gbà ran awọn eniyan rẹ̀ lọwọ nipa eré-ìnàjú?
ITỌSỌNA Jehofa ń mú ọpọlọpọ anfaani wá fun awọn iranṣẹ rẹ̀. Awa lè ri eyi ninu agbegbe eré inaju. Itọsọna rẹ̀ ran awọn Kristian lọwọ lati yẹra fun aṣeregee ni apá ìhà eyikeyii ninu oju-iwoye. Awọn onisin kan, ti wọn rinkinkin mọ ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ ninu aṣọ wiwọ ati ihuwa, fojuwo gbogbo igbadun eyikeyii gẹgẹ bi ẹṣẹ. Ni ọwọ keji ẹwẹ, eyi ti o pọ julọ ninu awọn eniyan ń lepa adun ani bi iru awọn bẹẹ bá tilẹ forigbari pẹlu awọn ofin ati ilana Jehofa.—Romu 1:24-27; 13:13, 14; Efesu 4:17-19.
2. Ki ni o fi oju-iwoye ipilẹṣẹ tí Ọlọrun ní nipa eré-ìnàjú hàn?
2 Bi o ti wu ki o ri, ki ni, nipa ti awọn eniyan Ọlọrun? Ọpọ awọn ti wọn bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli ni ó yalẹnu lati mọ pe Ọlọrun niti tootọ dá awọn eniyan pẹlu agbara lati gbadun igbesi aye. Oun fun awọn obi wa akọkọ ni iṣẹ lati ṣe—ṣugbọn kì í ṣe iru iṣẹ amunisorikọ ti o ti samisi igbesi-aye eyi ti o pọ julọ ninu awọn eniyan alaipe. (Genesisi 1:28-30) Ronu nipa oniruuru awọn ọ̀nà gbigbamuṣe ti gbogbo awọn ti wọn ń gbé ninu Paradise ilẹ̀-ayé ìbá ti ri igbadun. Finuro ayọ wọn ni wíwo awọn ẹranko ẹhanna ti ki yoo mu ihalẹmọni wa ati oniruuru awọn ẹran ọ̀sìn ti ìbá ti jẹ́ apakan igbesi-aye ojoojumọ! Ati iru ounjẹ ti ìbá wà fun wọn lati inu “oniruuru igi ti o dara ni wíwò ti o sì dara fun ounjẹ”!—Genesisi 2:9; Oniwasu 2:24.
3-5. (a) Ète wo ni eré-ìnàjú nilati ṣiṣẹ fun? (b) Eeṣe ti awa fi lè ni idaniloju pe Ọlọrun kò tako awọn ọmọ Israeli lati wá igbadun?
3 Awọn igbokegbodo wọnyẹn, niti tootọ, ni a lè wò gẹgẹ bi eré-ìnàjú, tí ète rẹ̀ nisinsinyi ìbá ti jẹ́ bi o ti ri gan-an ninu Paradise: lati tu ọkàn ẹni lara ati lati sọ ọ́ di ọ̀tun siwaju sii fun igbokegbodo (iṣẹ) amesojade. Nigba ti eré-ìnàjú bá ṣaṣepari eyi, ó ni èrè ninu. Eyi ha tumọsi pe awọn oloootọ olujọsin lè wá aaye fun eré-ìnàjú ninu igbesi-aye wọn ani bi o tilẹ jẹ pe wọn kò tíì gbé ninu paradise? Bẹẹni. Insight on the Scriptures sọ nipa eré-ìnàjú laaarin awọn eniyan Jehofa igbaani pe:
4 “Ipanilẹrin-in ati ìgbọ́kàn kuro lara igbokegbodo deedee awọn ọmọ Israeli ni a kò mẹnuba lọna gbigbooro ninu akọsilẹ Bibeli. Bi o tilẹ ri bẹẹ, ó fi wọn hàn bi eyi ti a nilati wò pe o tó ti ó sì yẹ ni fifẹ nigba ti ó bá wà ni ibamu pẹlu awọn ilana isin orilẹ-ede naa. Iru awọn ere-itura pataki ti o wà ni fifi awọn ohun eelo orin ṣere, kikọ orin, ijo jíjó, ijumọsọrọpọ, ati awọn ere-idaraya miiran pẹlu. Pipa awọn àlọ́ ati mímú awọn ibeere didiju jade ni a gbé larugẹ lọpọlọpọ.—Onidajọ 14:12.”—Idipọ 1, oju-iwe 102.
5 Nigba ti Dafidi pada dé lẹhin ti o ti jagunmolu, awọn obinrin Heberu lo fèrè ati ilu nigba ti wọn ń ṣayẹyẹ. (Heberu, sa·chaqʹ). (1 Samueli 18:6, 7) Ọ̀rọ̀ Heberu naa ní ipilẹ tumọsi “rẹ́rìn-ín” awọn itumọ miiran sọrọ nipa “awọn obinrin aṣàríyá.” (Byington, Rotherham, The New English Bible) Nigba ti a gbé apoti ẹ̀rí naa, “Dafidi ati gbogbo ile Israeli sì ṣire [“ń ṣayẹyẹ,” NW] niwaju Oluwa lara gbogbo oniruuru eelo orin.” Mikali, iyawo Dafidi, ní oju-woye ti kò ṣe deedee, nitori ti oun tako lilọwọ ti Dafidi lọwọ ninu igbokegbodo eré-ìnàjú naa. (2 Samueli 6:5, 14-20) Jehofa sọ tẹlẹ pe awọn ẹni igbekun ti yoo pada lati Babiloni yoo ṣalabaapin ninu iru igbokegbodo alayọ bi iru eyi.—Jeremiah 30:18, 19; 31:4; fiwe Orin Dafidi 126:2.
6. Bawo ni Iwe Mimọ lede Griki ṣe ràn wá lọwọ ninu oju-iwoye wa nipa eré-ìnàjú?
6 Awa pẹlu gbọdọ wá ọ̀nà lati wà deedee nipa eré-ìnàjú. Fun apẹẹrẹ, awa ha mọriri rẹ̀, pe Jesu kì í ṣe aṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ niti gbigbadun awọn ohun yiyẹ? Oun lo akoko ni gbigbadun awọn ounjẹ atunilara, bii iru “àsè ńlá” ti Lefi ṣe. Nigba ti awọn olododo ara-ẹni kan takò ó fun jíjẹ ati mímu, Jesu kọ ọ̀nà ati oju-iwoye wọn silẹ. (Luku 5:29-31; 7:33-36) Sọyeranti, pẹlu, pe o lọ si ibi ayẹyẹ igbeyawo kan ti o sì tun ṣetilẹhin fun ayẹyẹ naa. (Johannu 2:1-10) Juda iyekan Jesu mẹ́nubà á pe awọn Kristian ni “àsè ifẹ,” ni kedere awọn àsè nibi ti awọn ti wọn jẹ́ alaini ti lè gbadun ounjẹ ati itẹlọrun, ibakẹgbẹpọ titunilara.—Juda 12.
Eré-ìnàjú Ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ni Akoko ati Ààyè Rẹ̀
7. Bawo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣe fun wíwà deedee niṣiiri niti ọ̀ràn eré-ìnàjú?
7 Oniwasu 10:19 sọrọ lọna didara nipa ‘àsè fun ẹrin ati ọtí waini ti ń mú inu alaaye dùn.’ Iyẹn kò dún bi ẹni pe eré-ìnàjú buru ninu araarẹ̀, àbí? Sibẹ iwe kan-naa wi pe: “Olukuluku ohun ni akoko wà fun, . . . ìgbà sisọkun ati ìgbà rírẹ́rìn-ín; ìgbà ṣiṣọfọ ati ìgbà jíjó.” (Oniwasu 3:1, 4) Bẹẹni, nigba ti kò dẹbi fun eré-ìnàjú bibojumu, Bibeli fun wa ni ikilọ oniṣọọra. Eyi wémọ́ imọran lati fi eré-ìnàjú ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà mọ si aaye rẹ̀ niti akoko ati títóbi rẹ̀. Ó tun kilọ fun wa nipa awọn ọ̀fìn eyi ti o sábà maa ń ṣẹlẹ pẹlu eré-ìnàjú ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà titobi.—2 Timoteu 3:4.
8, 9. Eeṣe ti akoko ti a ń gbe ninu rẹ̀ ati iṣẹ ti Ọlọrun fi fun wa fi gbọdọ nii ṣe pẹlu eré-ìnàjú?
8 A ṣakiyesi pe awọn Ju ti wọn padabọ lati Babiloni—ti wọn ni iṣẹ àṣekára pupọ lati ṣe—yoo ṣajọpin ninu isinmi gbigbadunmọni. Sibẹ, Jeremiah ti sọ ṣaaju pe oun ki yoo ‘jokoo ni ajọ awọn ẹlẹgan ti ń dapaara bẹẹ ni oun kì yoo bẹrẹ sii yọ ayọ.’ (Jeremiah 15:17, NW) A fun un ni iṣẹ atọrunwa lati kede ihin-iṣẹ nipa ijiya ti o rọdẹdẹ, nipa bẹẹ kì í ṣe akoko ti o tọ́ fun un lati maa ṣariya.
9 Awọn Kristian lonii ni a yàn lati kede ihin-iṣẹ Ọlọrun nipa ireti ati pipolongo idajọ rẹ̀ lodisi igbekalẹ eto awọn nǹkan buburu Satani. (Isaiah 61:1-3; Iṣe 17:30, 31) Ó gbọdọ ṣe kedere nigba naa pe awa kò nilati jẹ ki eré-ìnàjú di apa pataki ninu igbesi-aye wa. A lè ṣakawe eyi pẹlu ìwọ̀n iyọ̀ kekere tabi amóúnjẹdùn akanṣe kan ti ń mú adùn ounjẹ pọ sii. Iwọ yoo ha da amóúnjẹdùn naa gọ̀ọ̀rọ̀gọ̀ ní ìwọ̀n pupọ debi pe yoo bori agbara ounjẹ naa bi? Bẹ́ẹ̀kọ́, niti gidi. Ni ìlà pẹlu ọ̀rọ̀ Jesu ni Johannu 4:34 ati Matteu 6:33, ohun ti o kàn wá gbọ̀ngbọ̀n—ounjẹ wa—gbọdọ jẹ ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun. Nitori naa eré-ìtura dabii ohun ti ń mu adun nǹkan pọ sii. Ó gbọdọ tunilara ki o sì mú nǹkan sunwọn sii, kì í ṣe ki o tánnilókun, tabi ki o bonimọlẹ.
10. Eeṣe ti gbogbo wa fi gbọdọ ṣatunyẹwo bi akoko ti a ń lò lori eré-ìnàjú ti pọ̀ tó?
10 Bi o ti wu ki o ri, duro ki o sì ronu: Eyi ti o pọ julọ ninu awọn eniyan ki yoo ha sọ pe akoko ati afiyesi ti wọn fun eré-ìnàjú wà ni ìwọ̀n deedee bi? Bi wọn bá ti nimọlara lọna yiyatọ ni, wọn ìbá ti ṣe atunṣe. Eyi ko ha fihàn pe ẹnikọọkan wa gbọdọ duro diẹ ki a fi ironujinlẹ, ati tootọtootọ, ṣayẹwo ipa ti eré-ìnàjú ń kó niti gidi ninu igbesi-aye wa? Ó ha ti yọ́ wọnu igbesi-aye wa ti o sì ti di apa pataki bi? Fun apẹẹrẹ, awa ha maa ń tan tẹlifiṣọn lẹsẹkẹsẹ ti a bá ti de ile bi? Awa ha ti ni iṣeto yíya apa pupọ lara akoko wa sọtọ fun eré-ìnàjú lọsọọsẹ bi, bii fun apẹẹrẹ ni alaalẹ Friday tabi alaalẹ Saturday? Awa yoo ha nimọlara ijakulẹ bi akoko ti a dá naa bá tó ti a sì wà nile laisi eré-ìtura ti a ti wéwèé fun bi? Afikun ibeere meji sii: Ni ọjọ ti o tẹle ikorajọpọ kan, awa ha rii pe awa pẹ́ lode tabi rinrin-ajo ti o jinna tobẹẹ debi pe ó rẹ̀ wá tẹnutẹnu, boya ni didi ẹni ti a àárẹ̀ mú tobẹẹ ti a kò fi lè ṣajọpin ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristian tabi lati ṣiṣẹ ti ó pọ̀ tó ni ọjọ kan fun agbanisiṣẹ wa? Bi eré-ìnàjú wa lẹẹkọọkan, tabi nigba gbogbo, bà ni iru iyọrisi yẹn, ó ha jẹ́ igbadun ti o bojumu ti o sì wà deedee nitootọ bi?—Fiwe Owe 26:17-19.
11. Eeṣe ti atunyẹwo iru eré-ìnàjú wa fi jẹ ohun yíyẹ?
11 Ó tun lè dara fun wa lati ṣatunyẹwo, pẹlu, bi eré-ìnàjú wa ṣe rí. Pe a jẹ iranṣẹ Ọlọrun kì í ṣe ẹ̀rí pe eré-ìnàjú wa bojumu. Ronu nipa ohun ti aposteli Peteru kọwe rẹ̀ si awọn Kristian ẹni-ami-ororo. “Nitori ìgbà ti o ti kọja ti tó fun ṣiṣe ifẹ awọn keferi, rinrin ninu ìwà wọbia, ifẹkufẹẹ, ọtí amupara, irede òru, kiko ẹgbẹ́ ọmuti, ati ibọriṣa tii ṣe ohun irira.” (1 Peteru 4:3) Kì í ṣe pe oun ń nàka ẹ̀sùn, gẹgẹ bi a ṣe lè sọ pe ó jẹ́, ni fifẹsun kan awọn arakunrin rẹ̀ fun ṣiṣafarawe ohun ti awọn ti ó wà ninu ayé ń ṣe. Sibẹ, iwalojufo ṣe pataki fun awọn Kristian (nigba yẹn ati nisinsinyi) nitori pe ẹnikan lè fi tirọruntirọrun di ẹran-ìjẹ fun eré-ìnàjú apanilara.—1 Peteru 1:2; 2:1; 4:7; 2 Peteru 2:13.
Wà Lojufo si Awọn Idẹkun
12. Peteru kìn-ín-ní 4:3 tẹnumọ iru awọn idẹkun wo?
12 Si iru awọn idẹkun wo ni o yẹ ki a wà lojufo? Ó dara, Peteru mẹnuba “ọtí amupara, irede òru, kíkó ẹgbẹ́ ọmuti.” Alálàyé ọ̀rọ̀ kan ti ó jẹ́ ara Germany ṣalaye pe ọ̀rọ̀ Griki naa ti a lo “ni pataki nii ṣe pẹlu ọtí mímu nibi àsè ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà.” Ọjọgbọn ará Switzerland kan kọwe pe iru awọn aṣa wọnyẹn wọpọ nigba naa lọ́hùn-ún: “Apejuwe naa gbọdọ nii ṣe pẹlu awọn ipejọpọ ti a ṣeto tabi awọn ẹgbẹ́ ti a ń ṣe deedee paapaa ninu eyi ti wọn ti ń ṣe awọn igbokegbodo atiniloju ti a ṣapejuwe.”
13. Bawo ni lilo awọn ohun mímu ọlọ́tí líle ni awọn ikorajọpọ ti ṣe jẹ́ idẹkun? (Isaiah 5:11, 12)
13 Níní awọn ohun mímu ọlọti líle nibi ipejọpọ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà titobi ti dẹkun mú ọpọlọpọ. Kì í ṣe pe Bibeli ń dẹbi fun lilo awọn ohun mímu wọnni niwọntunwọnsi, nitori ti kò ṣe bẹẹ. Gẹgẹ bi ẹ̀rí fun eyi, Jesu ṣe waini nibi ayẹyẹ igbeyawo kan ni Kana. Ọtí amuju kò ti nilati ṣẹlẹ nibẹ, nitori Jesu yoo ṣegbọran si imọran Ọlọrun lati yẹra fun wíwà ninu awọn alámujù. (Owe 23:20, 21) Ṣugbọn ronu nipa kulẹkulẹ yii: Olori àsè naa sọ pe nibi awọn àsè miiran waini didara ni a kọ́kọ́ ń gbé kalẹ ‘nigba ti awọn eniyan bá sì mu un yó tán, ni a maa ń gbé eyi ti kò dara tobẹẹ kalẹ.’ (Johannu 2:10) Nitori naa ó jẹ ohun ti o wọpọ fun awọn Ju lati mutiyo ní awọn ibi ayẹyẹ igbeyawo nibi ti waini jaburata ti wà larọọwọto fun gbogbo eniyan.
14. Ni awọn ọ̀nà wo ni awọn Kristian olugbalejo fi lè koju idẹkun ti awọn ohun mímu ọlọ́tí líle lè mú wá?
14 Ni ibamu pẹlu eyi, awọn Kristian olugbalejo ti pinnu lati pese waini, bíà, ati awọn ohun mímu ọlọti líle miiran kìkì bi awọn funraawọn bá lè bojuto ohun ti a fifun awọn alejo wọn tabi ohun ti wọn mu. Bi awujọ kan bá tobi ju ohun ti olugbalejo kan lè bojuto funraarẹ ni taarata, bii ti awọn ayẹyẹ igbeyawo Ju ti a mẹnuba, ọpọ ọtí líle lè jẹ́ idẹkun lilewu kan. Ẹnikan ti o ti jà raburabu ti ó sì ti bori iṣoro kan pẹlu ọtí líle lè wá sibẹ. Iwọ lè mọriri rẹ̀ pe anfaani ti a kò ṣakoso ti oun bá ni fun ọtí líle lọ́fẹ̀ẹ́lófò lè dẹ ẹ́ wò lati tẹ́ araarẹ̀ lọrun rekọja ààlà ‘kí ó sì ba ayẹyẹ naa jẹ́ fun gbogbo eniyan. Baba kan ti o tun jẹ alaboojuto ni Germany ṣalaye pe idile oun maa ń janfaani lati inu ibakẹgbẹ alárinrin ni awọn ikorajọpọ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà pẹlu awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ-ẹni. Bi o ti wu ki o rí, ó fikun un pe, ṣiṣeeṣe naa pe ki awọn iṣoro jẹyọ ni o tubọ ga sii lọna ti o daju nigba ti bíà bá wa larọọwọto fàlàlà.
15. Bawo ni ọwọ́ ṣe lè tẹ itọsọna bibojumu nipa ikorajọpọ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà?
15 Ayẹyẹ igbeyawo naa ni Kana ní “olori àsè” kan. (Johannu 2:8) Eyi kò tumọsi pe idile kan ti o ni awujọ kan ti ń ṣebẹwo si ile wọn fun ounjẹ tabi fun akoko ibakẹgbẹ yoo nilati yan olori kan. Ọkọ ni yoo ni ẹrù-iṣẹ́ fun ṣiṣabojuto ohun ti ń ṣẹlẹ. Ṣugbọn yálà awujọ kan wulẹ jẹ́ idile meji tabi ti o tubọ tobi bakan ṣáá, ó gbọdọ daju pe ẹnikan ni o ni ẹrù-iṣẹ́ ohun tí ó bá ṣẹlẹ. Ọpọlọpọ awọn obi maa ń ṣayẹwo eyi nigba ti a bá pe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn si ikorajọpọ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. Wọn yoo kàn si olugbalejo naa lati beere ẹni ti yoo bojuto ayẹyẹ naa latokedelẹ, titi kan wíwà nibẹ de ipari rẹ̀. Awọn Kristian ti wọn jẹ́ òbí tilẹ ti ṣatunto itolẹsẹẹsẹ wọn ki wọn baa lè wà nibẹ ki ó lè jẹ pe tọmọde tagba wọn yoo lè gbadun ibakẹgbẹpọ tọtuntosi.
16. Ki ni awọn ironu afiṣọraṣe yíyẹ nipa bi ikorajọpọ kan yoo ti tobi tó?
16 Ẹka ile-iṣẹ Watch Tower Society ti o wà ni Canada kọwe pe: “Imọran ti o nii ṣe pẹlu didin ìtóbi ikorajọpọ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà kù ni awọn alagba kan ti loye rẹ̀ lati tumọsi pe ikorajọpọ titobi nibi awọn apejẹ igbeyawo wa ní itapa si imọran naa. Wọn ti pari ero pe bi a bá fun wọn nimọran lati jẹ ki ikorajọpọ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà mọniwọn, ni ìwọ̀n ti o ṣee ṣakoso, yoo jẹ ohun ti o lodi lati ni iye awọn eniyan ti o tó 200 tabi 300 nibi apejẹ igbeyawo kan.”a Dipo ṣiṣe itẹnumọ ti o pọju lori iye pato kan ti a gbekari oju-iwoye ara-ẹni, afiyesi akọkọ ni a gbọdọ fifun iṣabojuto lọna bibojumu, laika bi iye ti o pese ti lè pọ tó. Ìwọ̀n waini ti Jesu pese fihàn pe iye ti o pọ̀ diẹ ni o lọ sibi ayẹyẹ igbeyawo ni Kana, ṣugbọn ní kedere a ṣabojuto rẹ̀ lọna yiyẹ. Awọn àsè miiran nigba naa lọ́hùn-ún kò rí bẹẹ; bi wọn ti pọ tó lè ti jẹ okunfa ti o ṣamọna si ìkùkáàtó abojuto. Bi ikorajọpọ kan bá ti tobi tó, bẹẹni ipenija rẹ̀ yoo ti tobi tó, nitori pe o rọrun fun awọn alailera, ti wọn nitẹsi siha amuju, lati fi araawọn hàn. Ni awọn ikorajọpọ ti a kò ṣakoso wọn lè ṣe igbelarugẹ awọn igbokegbodo ti a lè gbé ibeere dide si.—1 Korinti 10:6-8.
17. Bawo ni a ṣe lè fi ìwà deedee Kristian hàn nigba ti a bá ń wéwèé ikorajọpọ kan?
17 Abojuto rere nipa ikorajọpọ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ní ìwéwèé ati imurasilẹ rẹ̀ ninu. Eyi kò tumọsi híhùmọ̀ igbekalẹ agbanilafiyesi lati mu ki o jẹ alailẹgbẹ tabi manigbagbe ṣugbọn ti yoo ṣafarawe awọn apejẹ ayé, iru bii awọn agbo-ijó ti awọn ti o pesẹ ti ń wọ aṣọ àṣà tabi awọn apejẹ oníjó ninu eyi ti a ń wọṣọ ti ń fi irisi ẹni pamọ. Iwọ ha lè woye awọn ọmọ Israeli oloootọ ni Ilẹ Ileri ti ń wéwèé fun apejẹ kan nibi ti gbogbo wọn ti nilati mura bii ti awọn Keferi ni Egipti tabi ilẹ miiran bi? Wọn yoo ha wéwèé ijo onifẹẹkufẹẹ tabi orin ẹhanna ti o ṣeeṣe ki o gbajumọ laaarin awọn keferi bi? Pada si Oke Sinai, a dẹkun mu wọn ninu orin ati ijo iru eyi ti o ṣeeṣe ki o wọpọ ni akoko yẹn ti o sì gbajumọ ni Egipti. Awa mọ bi Ọlọrun ati iranṣẹ rẹ̀ adagbadenu Mose ṣe wo eré-ìnàjú yẹn. (Eksodu 32:5, 6, 17-19) Fun idi yii, olugbalejo tabi oluṣabojuto ayẹyẹ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà naa gbọdọ ṣayẹwo boya orin tabi ijo eyikeyii yoo wà; bi o bá jẹ bẹẹni, oun gbọdọ ri daju pe ó wà ni ibamu pẹlu awọn ilana Kristian.—2 Korinti 6:3.
18, 19. Òye-inu wo ni awa lè jere lati inu pípè ti a pe Jesu wá si ibi ayẹyẹ igbeyawo kan, bawo sì ni awa ṣe lè fi eyi silo?
18 Lakootan, awa ranti pe ‘Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni a pe si ibi àsè igbeyawo.’ (Johannu 2:2) A gbà pe, Kristian kọọkan tabi idile wulẹ lè ṣebẹwo sọdọ awọn miiran fun akoko alárinrin ti ń gbeniro. Ṣugbọn fun awọn aṣeyẹ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ti a wéwèé fun, iriri fihàn pe pipinnu awọn wo ni wọn yoo wà nibẹ ṣaaju akoko a maa ṣeranlọwọ lati dena iṣoro. Ijẹpataki eyi ni a tẹnumọ nipasẹ alagba kan ni Tennessee, U.S.A., ẹni ti o ti tọ́ awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin ti wọn wà ninu iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun dagba. Ṣaaju ki oun tabi iyawo rẹ̀ tó gba ikesini kan, tabi fun awọn ọmọ wọn ni aaye lati lọ, oun yoo kàn sí olugbalejo naa lati ri i daju pe awọn olupesẹ naa ni a ti pinnu ṣaaju. Idile rẹ̀ ni a daabobo kuro lọwọ awọn idẹkun ti o ti ṣubu lu awọn kan nibi awọn ikorajọpọ ti o jẹ́ ti irú-wá-ògìrì-wá, boya fun ounjẹ kan, ijade-faaji kan, tabi eré-ìmárale, iru bii gbígbá bọọlu.
19 Jesu kò fun kíkésí kìkì awọn mọlẹbi, ọ̀rẹ́ atijọ, tabi ẹnikan ti o jẹ́ ojugba tabi ti o wà ninu ipo iṣunna-owo kan-naa pẹlu ẹni sibi ikorajọpọ kan niṣiiri. (Luku 14:12-14; Fiwe Jobu 31:16-19; Iṣe 20:7-9.) Bi iwọ bá fi tiṣọratiṣọra yan awọn ti iwọ yoo késí, ó rọrun lati jẹ ki ó ní awọn Kristian oniruuru ọjo-ori ati ipo ninu. (Romu 12:13; Heberu 13:2) Diẹ lara wọn lè jẹ́ alailera nipa tẹmi tabi awọn ẹni titun ti wọn lè janfaani lati inu ibakẹgbẹpọ pẹlu awọn Kristian ti wọn dagbadenu.—Owe 27:17.
Eré-Ìnàjú ni Ààyè Rẹ̀
20, 21. Eeṣe ti eré-ìnàjú fi lè ni ààyè lọna yíyẹ ninu igbesi-aye wa?
20 Ó jẹ́ ohun yíyẹ fun wa gẹgẹ bi awọn eniyan olubẹru Ọlọrun lati ni ọkàn-ìfẹ́ ninu eré-ìnàjú wa ki a sì daniyan pe ki o jẹ iru eyi ti o bojumu ati pe ki a wadeedee ninu iye akoko ti a ń lo fun un. (Efesu 2:1-4; 5:15-20) Òǹkọ̀wé ti a misi naa ti ó kọ iwe Oniwasu nimọlara lọna yẹn: “Nigba naa ni mo yin iré, nitori eniyan kò ní ohun rere labẹ oòrùn ju jijẹ ati mímu, ati ṣiṣe ariya nitori eyiini ni yoo bá a duro ninu làálàá rẹ̀ ni ọjọ ayé rẹ̀, ti Ọlọrun fi fun un labẹ oòrùn.” (Oniwasu 8:15) Iru adun ti a mú wà deedee bẹẹ lè tunilara o sì ń ṣeranwọ lati lé awọn iṣoro ati ikimọlẹ ti o wọpọ ninu eto igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi kuro.
21 Lati ṣakawe, aṣaaju-ọna ará Austria kan kọwe si ọ̀rẹ́ rẹ̀ atijọ kan pe: “A ni iṣerejade didara kan ni ọjọsi. Iye wa ti o tó 50 rinrin-ajo lọ si odo kekere kan nitosi Ferlach. Arakunrin B—— ṣaaju itolọwọọwọ naa ninu ọkọ rẹ̀, ni gbigbe awọn ohun eelo ìdáná mẹta, aga ti ó ṣee ká, tabili, titikan tabili tebutẹniisi kan dani. A gbadun rẹ̀ gan-an ni. Arabinrin kan ní duuru ọlọwọ, nipa bẹẹ ọpọlọpọ awọn orin Ijọba ń já lala. Awọn ará, lọmọde ati lagba, gbadun ibadọrẹẹ naa.” Oun ní iranti eré-ìtura ti a ṣakoso lọna didara ti a mú yago fun idẹkun iru bii ọtí amuju tabi ìwà ainijaanu.—Jakọbu 3:17, 18.
22. Nigba ti a bá ń gbadun eré-ìnàjú ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, ikilọ wo ni ẹnikọọkan wa gbọdọ fi si akọkọ ninu ironu wa?
22 Paulu rọ̀ wá lati maṣe jọ̀gọ̀nú fun ifẹkufẹẹ ara alaipe, ki a ma tilẹ ṣe ìwéwèé ti yoo ṣí wa silẹ si awọn idanwo. (Romu 13:11-14) Iyẹn ní ninu ìwéwèé fun eré-ìnàjú ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. Nigba ti a bá fi imọran rẹ̀ silo lori iru ohun bẹẹ, awa yoo lè yẹra fun awọn ipo ti o ti ṣamọna awọn diẹ sinu rírì ọkọ̀ tẹmi wọn. (Luku 21:34-36; 1 Timoteu 1:19) Dipo eyi awa yoo fi ọgbọ́n yan eré-ìtura gbigbamuṣe ti yoo ràn wá lọwọ lati pa ipo ibatan wa pẹlu Ọlọrun mọ́. Awa yoo tipa bẹẹ janfaani lati inu eré-ìnàjú ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ti a lè kà si ọ̀kan lara awọn ẹbun Ọlọrun.—Oniwasu 5:18.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ilé-Ìṣọ́nà ti April 15, 1984, ní imọran ti ó wà deedee lori ayẹyẹ igbeyawo ati àsè igbeyawo ninu. Ọkọ lọ́la kan ati iyawo rẹ̀, ati awọn miiran ti yoo ràn wọ́n lọwọ bakan-naa, lè ṣe araawọn lanfaani ni ṣiṣe atunyẹwo akojọpọ yii ṣaaju ṣiṣe ìwéwèé ayẹyẹ igbeyawo wọn.
Ki ni Ohun Ti A Ti Kọ́?
◻ Oju-iwoye oniwa deedee wo ni awa ri ninu Bibeli nipa gbigbadun eré-ìnàjú ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà?
◻ Eeṣe ti igbeyẹwo afiṣọraṣe fi gbọdọ wà nipa akoko ati iru eré-ìnàjú wa?
◻ Ki ni awọn ohun diẹ ti Kristian olugbalejo kan lè ṣe lati fi daabobo araarẹ kuro lọwọ awọn idẹkun?
◻ Bi o bá bojumu ti o sì wà deedee, ki ni eré-ìnàjú lè ṣaṣepari rẹ̀ fun awọn Kristian?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Olugbalejo tabi oludari kan ni ibi ikorajọpọ kan ni o ni ẹrù-iṣẹ́ lati rii pe awọn alejo ni a kò dẹkun mú