Bíbójútó Àwọn Nǹkan Ìní Ọ̀gá Náà
1 Ní àkókò tí a kọ Bíbélì, ìríjú máa ń wà ní ipò ẹni tí a gbẹ́kẹ̀ lé gan-an. Ábúráhámù fún ìríjú rẹ̀ ní iṣẹ́ wíwá aya fún ọmọ rẹ̀, Ísákì. (Jẹ́n. 24:1-4) Nítorí èyí, a fún ìríjú náà ní ẹ̀rù iṣẹ́ láti rí i dájú pé ìlà ìdílé Ábúráhámù ń bá a lọ. Ẹ̀rù iṣẹ́ yẹn mà ga o! Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Ohun tí a ń retí nínú àwọn ìríjú ni pé kí a rí ènìyàn ní olùṣòtítọ́”!—1 Kọ́r. 4:2.
Iṣẹ́ Ìríjú Kristẹni
2 Nínú Bíbélì, a ṣàpèjúwe apá mélòó kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìríjú. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá àwọn ará Éfésù sọ̀rọ̀ nípa “iṣẹ́ ìríjú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi fún mi nítorí yín.” (Éfé. 3:2; Kól. 1:25) Ó wo iṣẹ́ tí a fún un láti mú ìhìn rere náà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìríjú tí òun gbọ́dọ̀ fi ìṣòtítọ́ ṣe. (Ìṣe 9:15; 22:21) Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sí àwọn arákùnrin rẹ̀ ẹni àmì òróró pé: “Ẹ ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì láìsí ìráhùn. Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn kan gbà, ẹ lò ó fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gẹ́gẹ́ bí ìríjú àtàtà fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi hàn ní onírúurú ọ̀nà.” (1 Pét. 4:9, 10; Héb. 13:16) Ohun yòówù tí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní wọnnì bá ní nípa ti ara jẹ́ nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà. Nítorí náà, wọ́n jẹ́ ìríjú fún àwọn nǹkan wọ̀nyẹn, ó sì yẹ kí wọ́n lò ó lọ́nà ti Kristẹni.
3 Lónìí, ojú kan náà ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo nǹkan. Wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run, wọ́n sì wo gbogbo ohun tí wọ́n ní—ìgbésí ayé wọn, okun wọn, ohun ìní wọn nípa ti ara—gẹ́gẹ́ bí èso “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi hàn ní onírúurú ọ̀nà.” Gẹ́gẹ́ bí ìríjú àtàtà, wọ́n mọ̀ pé àwọn yóò jíhìn fún Jèhófà Ọlọ́run lórí ọ̀nà tí wọ́n bá gbà lo àwọn nǹkan wọ̀nyí. Ní àfikún sí i, a ti fún wọn ní ìmọ̀ nípa ìhìn rere. Èyí pẹ̀lú jẹ́ ohun àfisíkàáwọ́-ẹni tí wọ́n fẹ́ láti lò lọ́nà tí ó dára jù lọ: láti gbé orúkọ Jèhófà lárugẹ, kí wọ́n sì ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti wá sínú ìmọ̀ òtítọ́.—Mát. 28:19, 20; 1 Tím. 2:3, 4; 2 Tím. 1:13, 14.
4 Báwo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń bójú tó ẹrù iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìríjú? Ìròyìn ọdọọdún fi hàn pé lọ́dún tó kọjá nìkan, wọ́n lò ju bílíọ̀nù kan wákàtí ní wíwàásù “ìhìn rere ìjọba” náà kárí ayé, wọ́n sì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tí ó ju 4,500,000 pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ó fi ìfẹ́ hàn. (Mát. 24:14) Ìṣòtítọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìríjú Jèhófà ni wọ́n tún fi hàn nípasẹ̀ àwọn ọrẹ ọlọ́làwọ́ wọn fún iṣẹ́ tí a ń ṣe kárí ayé àti ní ṣíṣètìlẹyìn fún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àdúgbò, nípasẹ̀ ẹ̀mí aájò àlejò wọn sí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn mìíràn, àti nípasẹ̀ inú rere wọn tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ sí àwọn tí ń bẹ nínú àìní gidigidi—irú bí àwọn tí ń jìyà nítorí ogun jíjà. Gẹ́gẹ́ bí àwùjọ, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń bójú tó àwọn nǹkan ìní Ọ̀gá náà dáadáa.
“Olóòótọ́ Ìríjú náà, Ẹni Tí Í Ṣe Olóye”
5 Kì í ṣe àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan nìkan ni a gbé iṣẹ́ ìríjú lé lọ́wọ́ ṣùgbọ́n a gbé e lé ètò àjọ lọ́wọ́ pẹ̀lú. Jésù pe ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé ní “olóòótọ́ ìríjú náà, ẹni tí í ṣe olóye.” (Lúùkù 12:42) Ẹrù iṣẹ́ “olóòótọ́ ìríjú” yìí ni láti fúnni ní “ìpèsè oúnjẹ,” kí wọ́n sì mú ipò iwájú nínú wíwàásù ìhìn rere náà lágbàáyé. (Ìṣí. 12:17) Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú èyí, ẹgbẹ́ olóòótọ́ ìríjú náà, tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ń ṣojú fún, ni Ọlọ́run fún ní ẹrù iṣẹ́ láti lo “tálẹ́ńtì” ti ara àti tẹ̀mí lọ́nà tí ó tọ́. (Mát. 25:15) Ní ìbámu pẹ̀lú àpẹẹrẹ “olóòótọ́ ìríjú náà,” ẹ̀ka ilé iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan ń sa gbogbo ipá láti lo gbogbo owó tí a dá lọ́nà tí ó mọ́gbọ́n dání, láti mú ire Ìjọba náà tẹ̀ síwájú. Gbogbo irú àwọn ọrẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun àfisíkàáwọ́-ẹni, “olóòótọ́ ìríjú náà, ẹni tí í ṣe olóye” ni ó sì ni ẹrù iṣẹ́ láti rí i dájú pé a lò ó fún ohun tí a pète rẹ̀ fún, wọ́n sì ń rí sí i pé a lò ó lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, pé a ń ṣúnwó ná, tí a sì ń lò ó lọ́nà tí ó gbéṣẹ́.
6 Àpẹẹrẹ kan nínú bí a ṣe ń lo owó tí a dá lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu ni a rí nínú ìlọsókè nínú ìgbòkègbodò ìwé títẹ̀ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe ní ọ̀rúndún ogún yìí. Pípín Bíbélì àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì—ìwé ìròyìn, ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé kékeré, ìwé àṣàrò kúkúrú, àti Ìròyìn Ìjọba—kiri ti kó ipa pàtàkì nínú títan “ìhìn rere náà” kálẹ̀ ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí. (Máàkù 13:10; 2 Tím. 3:1) Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sì ti jẹ́ irinṣẹ́ pàtàkì nínú pípèsè ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu’ fún “agbo ilé Ọlọ́run” àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn.”—Mát. 24:45; Éfé. 2:19; Ìṣí 7:9; Jòh. 10:16.
7 Ní ìbẹ̀rẹ̀ pàá, gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn tí ń fi iṣẹ́ ìtẹ̀wé ṣòwò ń tẹ̀. Ṣùgbọ́n ní àwọn ọdún 1920, a pinnu pé yóò gbéṣẹ́ jù yóò sì ṣàǹfààní nípa tẹ̀mí bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá ń fúnra wọn tẹ ìwé wọn. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, iṣẹ́ ìtẹ̀wé rọra bẹ̀rẹ̀ lọ́nà kékeré ní 1920 ní Brooklyn, New York, títí ó fi di ńlá gan-an. Nígbà tí yóò fi di 1967 àwọn ibi ìtẹ̀wé ti gba ilẹ̀ tí ó tó àdúgbò mẹ́rin. Ìwé títẹ̀ ni a ti bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ mìíràn pẹ̀lú, ṣùgbọ́n nínú èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú wọn, Ogun Àgbáyé Kejì ti dá a dúró.
8 Bí iṣẹ́ ìtẹ̀wé ní United States ṣe gbilẹ̀ tó, kò tóbi tó rárá láti tẹ̀wé fún gbogbo àgbáyé. Nítorí náà, ní àwọn ọdún lẹ́yìn ogun, iṣẹ́ ìwé títẹ̀ ni a bẹ̀rẹ̀ tàbí tí ó ti ń tẹ̀ síwájú ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè mìíràn, títí kan Denmark, England, Gíríìsì, Gúúsù Áfíríkà, Ìwọ̀-Oòrùn Germany, Kánádà àti Switzerland. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, Australia, Brazil, Finland, Ghana, Japan, Nàìjíríà, àti Philippines ni a ti fi kún orílẹ̀-èdè wọ̀nyí. Mélòó kan nínú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí pẹ̀lú ń tẹ ìwé ẹlẹ́yìn líle. Bákan náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, àwọn míṣọ́nnárì ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì ni a dá lẹ́kọ̀ọ́ nínú iṣẹ́ ìwé títẹ̀ tí a sì rán lọ sí mélòó kan nínú àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí láti ran àwọn arákùnrin tí ó wà ní àdúgbò náà lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwé títẹ̀.
9 Ní àwọn ọdún 1980, iye àwọn orílẹ̀-èdè tí a ti ń tẹ ìwé ìròyìn ti fò sókè dé 51.a Ẹ wo bí gbogbo èyí ti jẹ́ lílo àwọn nǹkan ìní Ọ̀gá náà lọ́nà rere tó! Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ ẹ̀rí tí ó lágbára nípa ìbísí nínú iṣẹ́ Ìjọba náà tó! Ẹ sì wo bí èyí ti jẹ́ ẹ̀rí tí ó lágbára nípa ìtìlẹyìn ọlọ́làwọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ‘fi àwọn ohun ìní wọn tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà’! (Òwe 3:9) Nípa báyìí, wọ́n fi ara wọn hàn pé wọ́n jẹ́ ìríjú àtàtà ti àwọn ohun tí Jèhófà ti fi bù kún wọn ní onírúurú ọ̀nà.
Ìyípadà Nínú Ohun Tí A Gbájú Mọ́
10 Láàárín àwọn ọdún 1970 àti ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1980, ìtẹ̀síwájú tí ó gadabú dé bá ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ̀ ìwé títẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ṣàmúlò àwọn ọ̀nà tuntun tí a ń gbà tẹ̀wé. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n ń lo ọ̀nà ìgbàtẹ̀wé ti letterpress ti àtijọ́. Èyí yí padà ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàmúlò ẹ̀rọ ìtẹ̀wé alátẹ̀yípo tí ó túbọ̀ jẹ́ ti òde òní. Gẹ́gẹ́ bí àbájáde rẹ̀, àwọn ìtẹ̀jáde ẹlẹ́wà tí ó ní àwòrán mèremère ni a ń tẹ̀, dípò àwòrán aláwọ̀ méjì (àwọ̀ dúdú àti àwọ̀ mìíràn) tí ó ṣeé tẹ̀ lórí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé letterpress ti àtijọ́. Síwájú sí i, ìmọ̀ ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà yí ọ̀nà tí a ń gbà ṣètò fún ìwé títẹ̀ padà pátápátá. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe Ètò Ìgbékalẹ̀ Ẹ̀rọ Onífọ́tò Atẹ̀wédíwọ̀n Elédè Púpọ̀ Tí Ń Bá Iná Ṣiṣẹ́ (Multilanguage Electronic Phototypesetting System [MEPS]), ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tí ń ṣèrànwọ́ nínú títẹ onírúurú èdè tí ó ju 370 lọ nísinsìnyí. Kò sí ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà tí a fi ń ṣòwò tí a lè fi wé ẹ̀rọ MEPS nínú agbára rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ní èdè púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀.
11 Ọpẹ́lọpẹ́ ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà MEPS àti lílò tí a ń lo àwọn ọgbọ́n ìhùmọ̀ mìíràn bí fífi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà, a tún ti tẹ̀ síwájú gidigidi nínú pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí a ń lo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti àtijọ́, àwọn ìwé ìròyìn tí a ń tẹ̀ ní èdè tí kì í ṣe Gẹ̀ẹ́sì máa ń gbé ìsọfúnni jáde lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù tàbí ọdún kan pàápàá lẹ́yìn tí ti Gẹ̀ẹ́sì ti jáde. Nísinsìnyí, Ilé Ìṣọ́ ń jáde lẹ́ẹ̀kan náà ní 115 onírúurú èdè, Jí! sì ń jáde ní 62 èdè. Èyí túmọ̀ sí pé ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí ń wá sí ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbàáyé ń gbé àkójọ ọ̀rọ̀ kan náà yẹ̀ wò lẹ́ẹ̀kan náà. Ìbùkún yìí mà ga o! Dájúdájú, nínáwó lórí gbogbo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tuntun yẹn jẹ́ ọ̀nà tí ó dára láti gbà lo àwọn nǹkan ìní Ọ̀gá náà!
Àwọn Àìní Mìíràn Nínú Ètò Àjọ
12 Àwọn ọ̀nà ìgbàtẹ̀wé tuntun yìí yí ohun tí ó jẹ́ àìní Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ti iṣẹ́ ìtẹ̀wé kárí ayé padà. Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé alátẹ̀yípo náà yára ju letterpress ti àtijọ́ lọ dáadáa, ṣùgbọ́n wọ́n tún wọ́nwó jù ú fíìfíì. Àwọn ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tí a fi ń ṣe iṣẹ́ tí ó jẹ mọ́ ọn, irú bí kíkọ̀wé, títúmọ̀, ṣíṣe iṣẹ́ ọnà, àti yíyàwòrán, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lágbára láti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan ju àwọn ẹ̀rọ ti àtijọ́, wọ́n tún wọ́nwó sí i pẹ̀lú. Ó wá hàn gbangba láìpẹ́ pé ó ti wọ́nwó jù láti máa tẹ ìwé ìròyìn ní àwọn orílẹ̀-èdè 51 ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nítorí náà, ní àwọn ọdún 1990, “olóòótọ́ ìríjú náà” tún ọ̀ràn náà yẹ̀ wò. Ìparí èrò wo ni wọ́n dé?
13 Ìwádìí fi hàn pé ‘àwọn ohun ìní tí ó níye lórí’ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn ń dá ni a óò ná lọ́nà tí ó sunwọ̀n sí i bí a bá pa iṣẹ́ ìtẹ̀wé náà pọ̀. Nítorí náà, iye àwọn ẹ̀ka tí ń tẹ̀wé ní a dín kù díẹ̀díẹ̀. Germany ti tẹ́wọ́ gba títẹ ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ní Ìlà-Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù, títí kan àwọn ilẹ̀ kan tí ó ti ń tẹ̀wé fúnra wọn tẹ́lẹ̀. Ítálì ń tẹ ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn apá kan ní Áfíríkà àti gúúsù ìlà oòrùn Yúróòpù, títí kan Gíríìsì àti Albania. Ní Áfíríkà, títẹ ìwé ìròyìn ni a fi mọ sí Nàìjíríà àti Gúúsù Áfíríkà nìkan. Pípa iṣẹ́ ìtẹ̀wé pọ̀ bí èyí ṣẹlẹ̀ yí ká ayé.
Àwọn Kókó Abájọ Tí A Gbé Yẹ̀ Wò
14 Ní July 1998, a óò ti ṣíwọ́ títẹ àwọn ìwé ìròyìn ní àwọn orílẹ̀-èdè Yúróòpù mélòó kan, títí kan Austria, Denmark, Faransé, Gíríìsì, Netherlands, àti Switzerland. Orílẹ̀-èdè Britain, Finland, Germany, Ítálì, Sípéènì, àti Sweden ni yóò gba iṣẹ́ títẹ̀wé ní Yúróòpù. Lọ́nà yìí, àwọn ìnáwó tí kò pọndandan ni a óò yẹra fún tí a óò sì lo owó tí a dá lọ́nà tí ó sàn jù fún iṣẹ́ tí a ń ṣe kárí ayé. Báwo ni a ṣe pinnu àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò máa bá a lọ láti jẹ́ ibi tí a ti ń tẹ̀wé àti àwọn ti yóò ṣíwọ́ títẹ̀wé? Ní pípa àṣẹ tí a fún un mọ́ láti bójú tó àwọn nǹkan ìní Ọ̀gá náà lọ́nà ọgbọ́n, “olóòótọ́ ìríjú náà” fara balẹ̀ gbé ìgbéṣẹ́ títẹ̀wé ní ibi kọ̀ọ̀kan yẹ̀ wò.
15 Ìdí pàtàkì tí a fi dáwọ́ ìwé títẹ̀ dúró ní àwọn orílẹ̀-èdè kan tí a sì pa iṣẹ́ náà pọ̀ níbòmíràn ni gbígbéṣẹ́ tí èyí gbéṣẹ́. Láti jẹ́ kí orílẹ̀-èdè kan máa tẹ̀wé fún ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè mìíràn rọrùn jù, ó sì jẹ́ ọ̀nà tí ó sàn jù tí a lè gbà lo àwọn irinṣẹ́ olówó gọbọi. A ń tẹ̀wé nísinsìnyí níbi ti owó tí ó ń náni ti kéré, tí àwọn ohun èlò wà lárọ̀ọ́wọ́tó, tí ohun èlò fún kíkó ẹrù ránṣẹ́ sì dára gan-an. Nípa báyìí, àwọn nǹkan ìní Ọ̀gá náà ni a ń lò dáadáa. Àmọ́ ṣá o, ṣíṣíwọ́ ìwé títẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kan kò túmọ̀ sí pé iṣẹ́ ìwàásù yóò dáwọ́ dúró níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ìwé tí a tẹ̀ ni yóò ṣì wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn yóò sì máa fi ìtara bá a lọ ní sísọ “ìhìn rere àlàáfíà” fún àwọn aládùúgbò wọn. (Éfé. 2:17) Síwájú sí i, ètò tí a tún ṣe yìí ti yọrí sí àwọn àǹfààní mìíràn.
16 Kí a mẹ́nu kan ànfààní kan, èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé òde òní tí a kó láti Denmark, Gíríìsì, Netherlands, àti Switzerland ni a kó ránṣẹ́ sí Nàìjíríà àti Philippines. Àwọn ọ̀jáfáfá tẹ̀wétẹ̀wé láti àwọn orílẹ̀-èdè Yúróòpù tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà láti bá àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé náà lọ, kí wọ́n sì dá àwọn tẹ̀wétẹ̀wé tí ó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí a ṣe ń lò wọ́n. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn ń rí ìwé ìròyìn tí ìrísí rẹ̀ dára gan-an gbà báyìí, irú èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ti ń rí gbà tẹ́lẹ̀.
17 Gbé àǹfààní mìíràn yẹ̀ wò: Ìnáwó lórí títẹ àwọn ìwé ìròyìn ni a ń bójú tó báyìí ní àwọn orílẹ̀-èdè díẹ̀ tí iṣẹ́ ìwé títẹ̀ ti ń bá a lọ. Gẹ́gẹ́ bí àbájáde èyí, ní àwọn ilẹ̀ tí a ti ṣíwọ́ ìwé títẹ̀, owó wà lọ́wọ́ báyìí fún àwọn ète mìíràn, irú bí kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ṣíṣèrànwọ́ láti bójú tó àìní àwọn ará ní àwọn ilẹ̀ tí ó tòṣì. Nípa bẹ́ẹ̀, ṣíṣọ́ àwọn nǹkan ìní Ọ̀gá náà lò túmọ̀ sí pé àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Kọ́ríńtì ni a óò lè lò lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ sí i lágbàáyé: “Èmi kò ní i lọ́kàn pé kí ó dẹrùn fún àwọn ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n kí ó nira fún yín; ṣùgbọ́n pé nípasẹ̀ ìmúdọ́gba, kí àṣẹ́kùsílẹ̀ yín nísinsìnyí gan-an lè dí àìnító wọn . . . kí ìmúdọ́gba lè ṣẹlẹ̀.”—2 Kọ́r. 8:13, 14.
18 Gẹ́gẹ́ bí àbájáde pípaṣẹ́pọ̀ yìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yí ká ayé ni a túbọ̀ so pọ̀ tímọ́tímọ́ ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Kì í ṣe ìṣòro fún Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Denmark pé kí a tẹ ìwé ìròyìn wọn ní Germany, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti máa ń tẹ̀ ẹ́ fúnra wọn tẹ́lẹ̀. Wọ́n kún fún ìmoore fún iṣẹ́ tí àwọn ará wọn ní Germany ń ṣe. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Germany ha ń fìbínú hàn pé a ń lo ọrẹ owó wọn láti pèsè ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún Denmark—tàbí fún Rọ́ṣíà, Ukraine, àti àwọn ilẹ̀ mìíràn bí? Rárá o! Wọ́n láyọ̀ láti mọ̀ pé ọrẹ owó àwọn ará wọn ní àwọn ilẹ̀ wọnnì ni a lè lò báyìí fún àwọn ète pàtàkì mìíràn.
Bíbójútó Àwọn Nǹkan Ìní
19 Ní gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yí ká ayé, àpótí ọrẹ kan máa ń wà tí a kọ “Ọrẹ fún Iṣẹ́ Society Kárí Ayé—Mátíù 24:14” sí lára. Àwọn ọrẹ àtinúwá tí a fi sínú àwọn àpótí wọ̀nyí wà fún lílò níbikíbi tí àìní bá wà. “Olóòótọ́ ìríjú náà” àti ẹ̀ka ilé iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ó máa ń pinnu bí a ṣe ń lo àwọn ọrẹ owó náà. Nítorí náà, níbi tí òfin bá ti gba èyí láàyè, owó tí a bá fi sínú àpótí ọrẹ ní orílẹ̀-èdè kan lè ṣètìlẹyìn fún ìgbòkègbodò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè mìíràn tí ó wà ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà sí ibẹ̀. A ti lo àwọn ọrẹ láti pèsè ìrànwọ́ pàjáwìrì fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí ń jìyà nítorí ìjì líle, ẹ̀fúùfù ńlá, ìsẹ̀lẹ̀ àti ogun abẹ́lé ní àwọn ilẹ̀ kan. A sì ń lo irú owó bẹ́ẹ̀ láti fi ṣètìlẹyìn fún àwọn míṣọ́nnárì ní àwọn ilẹ̀ tí ó ju 200 lọ.
20 Nínú ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bí ó ti sábà máa ń rí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a ń mẹ́nu kan ọ̀ràn owó lóṣù—ó sì máa ń jẹ́ fún kìkì ìṣẹ́jú díẹ̀. A kì í gbégbá owó kiri nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ní àwọn àpéjọ. A kì í tọrọ owó lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn. A kì í háyà àwọn tí ń báni ṣètò ìkówójọ. Bí ó ti sábà máa ń rí, Ilé Ìṣọ́ máa ń gbé àpilẹ̀kọ kan ṣoṣo jáde lọ́dún tí ń ṣàlàyé bí àwọn tí ń fẹ́ bẹ́ẹ̀ ṣe lè fi nǹkan ta Watch Tower Bible and Tract Society lọ́rẹ kí a lè fi ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ tí a ń ṣe kárí ayé. A kì í mẹ́nu kan ọ̀ràn ìnáwó Society déédéé nínú Jí! Nígbà náà, báwo ni a ṣe ń ṣàṣeparí iṣẹ́ bàtàkùnbatakun ti wíwàásù ìhìn rere náà kárí ayé, kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó pọndandan, bíbójútó àwọn tí ó wà nínú iṣẹ́ ìsìn àkànṣe alákòókò kíkún, àti ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn Kristẹni tí ó wà nínú àìní? Jèhófà ti fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́nà tí ó gadabú. (2 Kọ́r. 8:2) A ń lo àǹfààní yìí láti dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ó ti nípìn-ín nínú fífi ‘àwọn ohun ìní wọn tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà.’ Kí ó dá wọn lójú pé “olóòótọ́ ìríjú náà” yóò máa bá a nìṣó láti máa ṣọ́ àwọn nǹkan ìní Ọ̀gá náà. A sì gbàdúrà pé kí Jèhófà máa bá a lọ láti bù kún gbogbo ìṣètò tí a ń ṣe fún ìmúgbòòrò iṣẹ́ náà kárí ayé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní méje lára àwọn ilẹ̀ wọ̀nyí, àwọn ilé iṣẹ́ tí ń fi iṣẹ́ ìtẹ̀wé ṣòwò ni ó ń bá wọn tẹ̀wé wọn.