“Ẹ Máa Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo Ọlọ́run Tí Ń bẹ Lábẹ́ Àbójútó Yín”
“Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú.”—1 PÉT. 5:2.
1. Kí nìdí tí Pétérù fi kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́?
KÍ OLÚ ỌBA NÉRÒ tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Róòmù ni àpọ́sítélì Pétérù ti kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́. Ó kọ ọ́ kó bàa lè fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ní ìṣírí, torí pé Èṣù “ń rìn káàkiri” ó ń wá bó ṣe máa pa wọ́n jẹ. Kí àwọn Kristẹni bàa lè mú ìdúró wọn lòdì sí Èṣù, wọ́n gbọ́dọ̀ ‘pa agbára ìmòye wọn mọ́’ kí wọ́n sì ‘rẹ ara wọn sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run.’ (1 Pét. 5:6, 8) Ó sì tún pọn dandan pé kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan. Wọn kò gbọ́dọ̀ máa ‘bu ara wọn ṣán, kí wọ́n sì máa jẹ ara wọn ní àjẹrun,’ torí pé ìyẹn lè mú kí wọ́n ‘pa ara wọn rẹ́ ráúráú lẹ́nì kìíní-kejì.’—Gál. 5:15.
2, 3. Ta ló yẹ kí àwọn Kristẹni máa bá jìjàkadì, kí la sì máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e?
2 Ọ̀rọ̀ tiwa náà lónìí dà bíi ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Èṣù ń wá bó ṣe máa pa àwa náà jẹ. (Ìṣí. 12:12) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, “ìpọ́njú ńlá . . . , irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé” ti ń sún mọ́lé. (Mát. 24:21) Bí kò ṣe yẹ kí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní máa bá ara wọn ṣe awuyewuye, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ kí àwa náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, láwọn ìgbà míì a máa nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn àgbà ọkùnrin tí wọ́n ní ìrírí kí awuyewuye má bàa wáyé.
3 Ẹ jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò bí àwọn alàgbà ṣe lè ní ìmọrírì tó pọ̀ sí i fún àǹfààní tí wọ́n ní láti máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn ‘agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó wọn.’ (1 Pét. 5:2) Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò ọ̀nà tó yẹ káwọn alàgbà máa gbà ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn. Nínú àpilẹ̀kọ tá a máa jíròrò lẹ́yìn èyí, a máa ṣàlàyé bí ìjọ ṣe lè ‘ní ẹ̀mí ìkanisí fún àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára tí wọ́n sì ń ṣe àbójútó’ agbo. (1 Tẹs. 5:12) Bá a bá ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí, wọ́n máa ràn wá lọ́wọ́ láti dúró gbọn-in lòdì sí olórí Elénìní wa, níwọ̀n bá a ti mọ̀ pé òun là ń bá jìjàkadì.—Éfé. 6:12.
Ẹ Máa Ṣé Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo Ọlọ́run
4, 5. Ojú wo ló yẹ kí àwọn àgbà ọkùnrin máa fi wo agbo? Ṣàlàyé.
4 Pétérù gba àwọn àgbà ọkùnrin tó wà láàárín àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní níyànjú pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo agbo tó fi sí ìkáwọ́ wọn ni kí àwọn náà máa fi wò ó. (Ka 1 Pétérù 5:1, 2.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì sọ pé Pétérù dà bí ọwọ̀n nínú ìjọ, kò bá àwọn alàgbà sọ̀rọ̀ bíi pé ó sàn jù wọ́n lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbà wọ́n níyànjú bí alàgbà torí pé alàgbà bíi tiwọn ni òun náà. (Gál. 2:9) Bíi ti Pétérù, Ìgbìmọ̀ Olùdarí náà ń gba àwọn alàgbà ìjọ níyànjú lónìí láti sapá kí wọ́n lè bójú tó iṣẹ́ ńlá tó já lé wọn léjìká, ìyẹn ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run.
5 Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé kí àwọn àgbà ọkùnrin máa ‘ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó wọn.’ Ó ṣe pàtàkì kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà àti Jésù Kristi ló ni agbo náà. Àwọn alàgbà máa jíhìn fún Jèhófà nítorí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí àwọn àgùntàn Ọlọ́run. Ká sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ kan tó rìnrìn àjò sọ pé kó o bá òun tọ́jú àwọn ọmọ òun títí tí òun fi máa dé. Ǹjẹ́ o kò ní tọ́jú wọn dáadáa kó o sì máa fún wọn ní oúnjẹ? Bí ara ọ̀kan nínú wọn kò bá yá, ǹjẹ́ o kò ní rí i dájú pé ó gba ìtọ́jú tó yẹ? Lọ́nà kan náà, àwọn alàgbà ìjọ gbọ́dọ̀ máa “ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.” (Ìṣe 20:28) Wọ́n máa ń fi sọ́kàn pé ẹ̀jẹ̀ Kristi Jésù tó ṣeyebíye ni Ọlọ́run fi ra àgùntàn kọ̀ọ̀kan. Torí pé àwọn alàgbà mọ̀ pé àwọn máa jíhìn fún Ọlọ́run nítorí àwọn àgùntàn wọ̀nyí wọ́n ń bọ́ wọn, wọ́n ń dáàbò bò wọ́n, wọ́n sì ń bójú tó wọn.
6. Kí ni ojúṣe àwọn olùṣọ́ àgùntàn ìgbàanì?
6 Ronú nípa ojúṣe àwọn olùṣọ́ àgùntàn nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Bí wọ́n ti ń da àwọn àgùntàn náà káàkiri, wọ́n ní láti fara da ooru ní ọ̀sán, wọ́n á sì tún fara da otútù ní òru. (Jẹ́n. 31:40) Kódà wọ́n máa ń fi ẹ̀mí ara wọn wewu nítorí àwọn àgùntàn. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Dáfídì, ọmọdékùnrin tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, gba àwọn àgùntàn rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹranko ẹhànnà, tó fi mọ́ kìnnìún àti béárì. Dáfídì sọ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn pé, òun ‘rá irùngbọ̀n rẹ̀ mú, òun sì ṣá a balẹ̀, òun sì fi ikú pa á.’ (1 Sám. 17:34, 35) Dáfídì mà láyà o! Kò ṣàì mọ̀ pé àwọn ẹranko ẹhànnà náà lè fa òun ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ! Síbẹ̀, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti dáàbò bo àwọn àgùntàn rẹ̀.
7. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè dáàbò bo àgùntàn tí Èṣù bá fẹ́ pa jẹ?
7 Lónìí, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ wà lójúfò torí pé bíi kìnnìún ni Èṣù ṣe máa ń gbéjà ko àwọn àgùntàn tó wà lábẹ́ àbójútó wọn. Ó lè gba pé kí wọ́n lo irú ìgboyà téèyàn nílò kó tó lè gba àgùntàn lẹ́nu ẹranko ẹhànnà. Bí àwọn alàgbà bá lo ìgboyà bíi ti Dáfídì tó máa ń rá irùngbọ̀n ẹranko ẹhànnà mú, àwọn náà á lè dáàbò bo agbo kí Èṣù má bàa pa wọ́n jẹ. Wọ́n lè fèròwérò pẹ̀lú arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó ti fẹ́ kó sínú pàkúté Sátánì láìfura. (Ka Júúdà 22, 23.) Àmọ́ ṣá o, kò sí bí àwọn alàgbà ṣe lè ṣe gbogbo èyí láìsí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà. Wọ́n máa ń fi ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àgùntàn tó bá ṣèṣe, wọ́n á di ojú ọgbẹ́ rẹ̀, wọ́n á sì bá a fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó dà bí òróró atunilára wọ́ ọ.
8. Ibo ni àwọn alàgbà máa ń darí àwọn àgùntàn sí, ọ̀nà wo ni wọ́n sì ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀?
8 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn tún máa ń darí àwọn àgùntàn lọ sí ibi tí wọ́n á ti rí koríko jẹ àti ibi tí omi wà. Bákan náà, àwọn alàgbà máa ń darí àwọn àgùntàn sínú ìjọ nípa gbígbà wọ́n níyànjú láti máa wá sí ìpàdé déédéé kí wọ́n lè rí “oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” kí wọ́n sì jẹ ẹ́ ní àjẹyó. (Mát. 24:45) Èyí lè gba pé kí àwọn alàgbà lo àkókò tó pọ̀ láti ran àwọn tó ń ṣàìsàn tẹ̀mí lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn lókun. Ó ṣeé ṣe kí àgùntàn kan tó ti sọ nù máa gbìyànjú láti pa dà sínú agbo. Dípò tí àwọn alàgbà á fi máyà já irú àgùntàn bẹ́ẹ̀, wọ́n á fi pẹ̀lẹ́ ṣàlàyé àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ fún un, wọ́n á sì jẹ́ kó mọ bó ṣe lè fi àwọn ìlànà náà sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀.
9, 10. Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn alàgbà máa bójú tó àwọn tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí?
9 Bó o bá ń ṣàìsàn, irú dókítà wo lo máa fẹ́ kó tọ́jú rẹ? Ṣé èyí tí á kàn tẹ́tí sí ẹ díẹ̀, táá júwe oògùn tó yẹ kó o lò fún ẹ, táá sì yára kọjá lọ sọ́dọ̀ aláìsàn míì ni? Àbí wàá kúkú yàn láti lọ sọ́dọ̀ dókítà tó máa jẹ́ kó o sọ tinú ẹ, tó máa ṣàlàyé àìsàn tó ń ṣe ẹ́, tó sì máa jẹ́ kó o mọ irú ìtọ́jú tó yẹ kó o gbà?
10 Bákan náà, àwọn alàgbà lè fetí sílẹ̀ bí ẹni tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí bá ń sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì bá a wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn, nípa bẹ́ẹ̀ á dà bíi pé wọ́n ‘fi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà.’ (Ka Jákọ́bù 5:14, 15.) Bíi básámù láti Gílíádì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè mú kí ara tu aláìsàn náà. (Jer. 8:22; Ìsík. 34:16) Bí àwọn alàgbà bá jẹ́ kí ẹni tó ń ṣe ségesège mọ bó ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, ìyẹn lè mú kó pa dà máa ṣe déédéé nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Oore ńlá làwọn alàgbà máa ṣe ẹni tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí bí wọ́n bá gbọ́ tẹnu rẹ̀ tí wọ́n sì gbàdúrà pẹ̀lú rẹ̀.
Kì Í Ṣe Lábẹ́ Àfipáṣe bí Kò Ṣe Tinútinú
11. Kí ló mú kí àwọn alàgbà máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tinútinú?
11 Lẹ́yìn náà ni Pétérù wá rán àwọn àgbà ọkùnrin létí ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n máa gbà ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn àti ọ̀nà tí kò yẹ kí wọ́n máa gbà ṣe é. Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run, “kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú.” Kí ló ń mú káwọn alàgbà máa lo ara wọn tinútinú nítorí àwọn ará? Bí àpẹẹrẹ, kí ló mú kí Pétérù máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run kó sì máa bọ́ àwọn àgùntàn Jésù? Ìfẹ́ àtọkànwá tó ní sí Olúwa ló mú kó máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Jòh. 21:15-17) Ìfẹ́ náà ni kì í jẹ́ kí àwọn alàgbà “wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn.” (2 Kọ́r. 5:14, 15) Ìfẹ́ tí àwọn alàgbà ní fún Ọlọ́run àtàwọn ará yìí ló ń sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wọn láti máa lo ara wọn nítorí agbo, tí wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn, tí wọ́n sì ń lo owó àti àkókò wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 22:37-39) Wọ́n ń yọ̀ǹda ara wọn, kì í ṣe tipátipá, bí kò ṣe tinútinú.
12. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe yọ̀ǹda ara rẹ̀ tó?
12 Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn alàgbà máa yọ̀ǹda ara wọn tó? Bí àwọn alàgbà ṣe ń bójú tó àwọn àgùntàn, ńṣe ni wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, bí Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. (1 Kọ́r. 11:1) Torí pé Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún àwọn ará tó wà ní Tẹsalóníkà, ó sọ fún wọn pé: “Ó dùn mọ́ wa nínú jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn àwa fúnra wa pẹ̀lú.” Ọ̀nà wo ni wọ́n gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Ó ní: “Àwa di ẹni pẹ̀lẹ́ láàárín yín, bí ìgbà tí abiyamọ ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ tirẹ̀.” (1 Tẹs. 2:7, 8) Pọ́ọ̀lù mọ bí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ṣe máa ń rí lára abiyamọ. Kò sí ohun tí ìyá kan kò lè ṣe torí àwọn ọmọ rẹ̀, kódà ó lè jí láàárín òru kó lè fún wọn lóúnjẹ.
13. Kí nìdí tí ọ̀kan kò fi gbọ́dọ̀ pa èkejì lára nínú ojúṣe àwọn alàgbà?
13 Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run pa ojúṣe wọ́n nínú ìdílé lára. (1 Tím. 5:8) Àkókò ṣíṣeyebíye tí àwọn alàgbà ì bá máa lò pẹ̀lú ìdílé wọn ni wọ́n fi ń bójú tó ọ̀ràn ìjọ. Ọ̀kan lára ohun tí wọ́n lè ṣe tí ọ̀kan kò fi ní pa èkejì lára ni pé kí wọ́n máa ké sí àwọn míì láti dara pọ̀ mọ́ wọn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé tàbí láwọn ìgbà míì. Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni alàgbà kan tó ń jẹ́ Masanao ní orílẹ̀-èdè Japan ti máa ń ké sí àwọn tí kò tíì gbéyàwó àtàwọn ìdílé tó jẹ́ pé aya àtàwọn ọmọ nìkan ni wọ́n wà nínú òtítọ́ láti dara pọ̀ mọ́ ìdílé rẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó ṣe, lára àwọn tó ràn lọ́wọ́ di alàgbà àwọn náà sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere tí Masanao fi lélẹ̀.
Ẹ Sá fún Èrè Àbòsí, Ẹ Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo Pẹ̀lú Ìháragàgà
14, 15. Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn alàgbà ṣọ́ra fún “ìfẹ́ fún èrè àbòsí,” báwo ni wọ́n sì ṣe lè tipa bẹ́ẹ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù?
14 Pétérù tún gba àwọn alàgbà níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo, “kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà.” Iṣẹ́ àwọn alàgbà máa ń gba àkókò tó pọ̀, síbẹ̀ wọn kò retí pé kí ẹnikẹ́ni sanwó iṣẹ́ fáwọn. Pétérù rí i pé ó pọn dandan kí òun kìlọ̀ fún àwọn àgbà ọkùnrin bíi tòun nípa ewu tó wà nínú ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo nítorí “ìfẹ́ fún èrè àbòsí.” Irú ewu bẹ́ẹ̀ fara hàn kedere nínú ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì táwọn aṣáájú ẹ̀sìn “Bábílónì Ńlá” ń gbé, èyí tó ń sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di abòṣì. (Ìṣí. 18:2, 3) Lónìí, ìdí rere wà tí àwọn alàgbà kò fi gbọ́dọ̀ fàyè gba ohunkóhun tó bá máa mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.
15 Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fáwọn alàgbà ìjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpọ́sítélì ni tó sì lè sọ ara rẹ̀ di “ẹrù ìnira tí ń wọni lọ́rùn” fún àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà, kò “jẹ oúnjẹ lọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń ṣe “òpò àti làálàá ní òru àti ní ọ̀sán.” (2 Tẹs. 3:8) Ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà tó fi mọ́ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ arìnrìn-àjò, ń fi irú àpẹẹrẹ àtàtà bẹ́ẹ̀ lélẹ̀ lónìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í kọ̀ báwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ bá hùwà ọ̀làwọ́ sí wọn, wọn kì í “gbé ẹrù ìnira tí ń wọni lọ́rùn” ka ẹnikẹ́ni lórí.—1 Tẹs. 2:9.
16. Kí ló túmọ̀ sí láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo “pẹ̀lú ìháragàgà”?
16 Àwọn alàgbà máa ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo “pẹ̀lú ìháragàgà.” Ẹ̀mí ìháragàgà yìí máa ń fara hàn kedere nínú bí wọ́n ṣe ń ran agbo lọ́wọ́ torí pé wọ́n ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. Àmọ́ ṣá o, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé wọ́n ń fipá mú agbo láti sin Jèhófà; àwọn alàgbà tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ kì í sì í gba àwọn míì níyànjú láti máa fi ẹ̀mí ìbánidíje sin Ọlọ́run. (Gál. 5:26) Àwọn alàgbà mọ̀ pé àgùntàn kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra. Wọ́n máa ń hára gàgà láti ran àwọn ará lọ́wọ́ kí wọ́n lè fayọ̀ sin Jèhófà.
Kì Í Ṣe bí Ẹní Ń Jẹ Olúwa Lé Agbo Lórí, Ṣùgbọ́n Kí Ẹ Di Àpẹẹrẹ fún Agbo
17, 18. (a) Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro fáwọn àpọ́sítélì nígbà míì láti lóye ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ wọn pé ó yẹ kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? (b) Ipò tó jọ ìyẹn wo la lè bá ara wa nínú rẹ̀?
17 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe jíròrò rẹ̀, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé Ọlọ́run ló ni agbo tí wọ́n ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn rẹ̀ kì í ṣe àwọn. Wọ́n máa ń ṣọ́ra láti má ṣe “jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí.” (Ka 1 Pétérù 5:3.) Ìgbà míì wà tí àwọn àpọ́sítélì Jésù wá àǹfààní iṣẹ́ ìsìn pẹ̀lú èrò tí kò tọ́ lọ́kàn. Wọ́n fẹ́ láti wà ní ipò ọlá bíi tàwọn tó ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè.—Ka Máàkù 10:42-45.
18 Lónìí, ó máa dára kí àwọn ará tó “ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó” máa ṣàyẹ̀wò ara wọn dáadáa kí wọ́n lè mọ ohun táwọn ń tìtorí rẹ̀ wá àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. (1 Tím. 3:1) Ó yẹ kí àwọn tó ti di alàgbà báyìí bi ara wọn láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n bóyá agbára láti máa darí àwọn ẹlòmíràn ni wọ́n ń wá tàbí ńṣe ni wọ́n ń wá ipò ọlá, bí àwọn àpọ́sítélì kan ti ṣe. Bí àwọn àpọ́sítélì bá ní irú ìṣòro yìí, a jẹ́ pé ó yẹ kí àwọn alàgbà ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n má bàa fàyè gbà èrò tó máa ń darí àwọn èèyàn ayé, tí wọ́n fi máa ń fẹ́ láti lo agbára lórí àwọn míì.
19. Kí ni àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ máa rántí bí wọ́n bá ń dáàbò bo agbo?
19 Ohun kan ni pé ó máa ń pọn dandan nígbà míì pé káwọn alàgbà lo àṣẹ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ láti fúnni ní ìbáwí líle, irú bíi nígbà tí wọ́n bá ń dáàbò bo agbo lọ́wọ́ “àwọn aninilára ìkookò.” (Ìṣe 20:28-30) Pọ́ọ̀lù sọ fún Títù pé kó “máa gbani níyànjú, kí o sì máa fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà pẹ̀lú ọlá àṣẹ kíkún.” (Títù 2:15) Síbẹ̀, bí àwọn alàgbà bá ń lo ọlá àṣẹ tí wọ́n ní láti báni wí, wọ́n gbọ́dọ̀ fi ọ̀wọ̀ fún àwọn tí ọ̀ràn kàn. Wọ́n mọ̀ pé dípò táwọn á fi máa dẹ́bi fún ẹnì kan lọ́nà líle koko, báwọn bá fẹ̀sọ̀ pàrọwà fún un, ọ̀rọ̀ àwọn á wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi tó fi máa fẹ́ láti ṣe ohun tó yẹ.
20. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè máa fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ bíi ti Jésù?
20 Àpẹẹrẹ rere tí Kristi fi lélẹ̀ ló ń mú káwọn alàgbà nífẹ̀ẹ́ agbo. (Jòh. 13:12-15) Bí a bá ń kà nípa bó ṣe kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, ó máa ń mú wa lọ́kàn yọ̀. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ tún wọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́kàn, ó sì ń mú kí wọ́n máa lo ‘ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, bí wọ́n ti ń kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá ju àwọn lọ.’ (Fílí. 2:3) Bíi ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ó máa ń wu àwọn alàgbà náà lónìí láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, èyí sì máa ń mú kí wọ́n fẹ́ láti di “àpẹẹrẹ fún agbo.”
21. Èrè wo làwọn alàgbà lè máa fojú sọ́nà fún?
21 Nígbà tí Pétérù fẹ́ parí ọ̀rọ̀ tó fi ṣí àwọn àgbà ọkùnrin létí, ó mẹ́nu kan ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí láti ṣe lọ́jọ́ iwájú. (Ka 1 Pétérù 5:4.) Àwọn alábòójútó tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró máa “gba adé ògo tí kì í ṣá” nígbà tí wọ́n bá wà pẹ̀lú Kristi lókè ọ̀run. Àwọn tí Jèhófà yàn lára “àwọn àgùntàn mìíràn” láti máa bójú tó agbo máa ní àǹfààní láti máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ àkóso “olórí olùṣọ́ àgùntàn.” (Jòh. 10:16) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn a máa jíròrò bí àwọn tó wà nínú ìjọ ṣe lè máa kọ́wọ́ ti àwọn tá a yàn sípò láti máa mú ipò iwájú.
Àtúnyẹ̀wò
• Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu fún Pétérù láti gba àwọn alàgbà bíi tiẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tó wà lábẹ́ àbójútó wọn?
• Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn alàgbà máa bójú tó àwọn tó ń ṣàìsàn nípa tẹ̀mí?
• Kí ló máa ń mú kí àwọn alàgbà ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tó wà lábẹ́ àbójútó wọn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Bí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ní ìgbà àtijọ́, àwọn alàgbà lónìí gbọ́dọ̀ dáàbò bo “àwọn àgùntàn” tó wà lábẹ́ àbójútó wọn