Máa Ṣe Bí Ọba
“Kí ó kọ ẹ̀dà òfin yìí sínú ìwé kan fún ara rẹ̀ . . . Kí ó sì máa wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀.”—DIUTARÓNÓMÌ 17:18, 19.
1. Kristẹni kan lè gbìyànjú láti dà bí àwọn wo?
KÒ JỌ pé wàá ka ara rẹ sí ọba, ò báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin. Kristẹni tòótọ́ wo, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ló máa ka ara rẹ̀ sí ọba aláyélúwà tó gúnwà pẹ̀lú ọ̀pá àṣẹ, bíi ti àwọn ọba rere náà Dáfídì, Jòsáyà, Hesekáyà tàbí Jèhóṣáfátì? Ṣùgbọ́n, o lè dà bíi wọn, ó sì yẹ kó o dà bíi wọn, ó kéré tán ní ọ̀nà pàtàkì kan. Ọ̀nà wo nìyẹn? Èé sì ti ṣe tó fi yẹ kó o dà bí wọn lọ́nà yẹn?
2, 3. Kí ni Jèhófà ti rí tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ènìyàn tí yóò jẹ ọba, kí sì ni irú ọba bẹ́ẹ̀ ní láti ṣe?
2 Nígbà ayé Mósè, tipẹ́tipẹ́ kí Ọlọ́run tó fọwọ́ sí i pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ẹ̀dá èèyàn jọba lórí wọn, ni Ó ti rí i ṣáájú pé níjọ́ ọjọ́ kan, àwọn èèyàn Òun á bẹ̀rẹ̀ sí gbèrò àtiní ọba. Ìdí nìyẹn tó fi mí sí Mósè láti fi àwọn ìtọ́ni tó jẹ mọ́ ọ̀ràn yìí kún inú májẹ̀mú Òfin. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìtọ́ni fún kábíyèsí, ìyẹn ìlànà fáwọn ọba.
3 Ọlọ́run sọ pé: “Lẹ́yìn-ọ̀-rẹ̀yìn, nígbà tí o bá dé sí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, . . . tí o sì wí pé, ‘Jẹ́ kí ń yan ọba kan lé ara mi lórí, bí ti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó yí mi ká’; ọba tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò yàn ni kí ìwọ yàn lé ara rẹ lórí láìkùnà. . . . Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí ó bá mú ìjókòó rẹ̀ lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó kọ ẹ̀dà òfin yìí sínú ìwé kan fún ara rẹ̀ . . . Kí ó sì máa wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀, kí ó bàa lè kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, kí ó lè máa pa gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí àti ìlànà wọ̀nyí mọ́ nípa títẹ̀lé wọn.”—Diutarónómì 17:14-19.
4. Kí ni ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún àwọn ọba wé mọ́?
4 Bẹ́ẹ̀ ni o, ọba tí Jèhófà bá yàn fáwọn olùjọsìn rẹ̀ ní láti ṣàdàkọ àwọn ìwé tó o lè rí nínú Bíbélì tìrẹ. Àdàkọ yẹn á jẹ́ ẹ̀dà tirẹ̀. Ọba náà á wá máa ka ẹ̀dà yẹn lójoojúmọ́, léraléra. Kì í ṣe torí àtihá a sórí o. Ìkẹ́kọ̀ọ́ ló wà fún, ó sì ní ète tó ń ṣiṣẹ́ fún. Ọba tó bá máa rí ojú rere Jèhófà kò gbọ́dọ̀ dẹ̀yìn lẹ́yìn irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀, kí ó lè ní àyà ìgbàṣe. Ó tún ní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ ìwé tá a mí sí wọ̀nyẹn bó bá fẹ́ jẹ́ ọba rere, tí ìlú tòrò nígbà tirẹ̀.—2 Àwọn Ọba 22:8-13; Òwe 1:1-4.
Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Bí Ọba
5. Àwọn apá wo nínú Bíbélì ni Dáfídì Ọba ní láti dà kọ kí ó sì kà, ojú wo ló sì fi wo ṣíṣe èyí?
5 Láti lè tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí, kí lo rò pé ó ṣeé ṣe kí Dáfídì ṣe nígbà tó jọba ní Ísírẹ́lì? Tóò, ó ti ní láti ṣe àdàkọ ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì (ìyẹn Jẹ́nẹ́sísì, Ẹ́kísódù, Léfítíkù, Númérì, Diutarónómì). Sáà ronú bí yóò ṣe wọ Dáfídì lọ́kàn tó, bó ṣe ń fi ojú wo Òfin náà lọ́kọ̀ọ̀kan, tó sì ń fọwọ́ ara rẹ̀ dà á kọ. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé Mósè pẹ̀lú ló kọ ìwé Jóòbù àti Sáàmù 90 àti 91. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé Dáfídì da àwọn wọ̀nyẹn náà kọ? Ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀. Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí ìwé Jóṣúà, Onídàájọ́ àti Rúùtù ti wà nígbà yẹn. Ìwọ náà lè rí i pé Dáfídì Ọba ti ní láti ní ohun púpọ̀ láti kà ní àkàyé nínú Bíbélì. Kò sì sí àní-àní pé ó ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé òun ló sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 19:7-11 nípa Òfin Ọlọ́run.
6. Ìdánilójú wo la ní pé Jésù fẹ́ràn Ìwé Mímọ́ bíi ti Dáfídì baba ńlá rẹ̀?
6 Dáfídì Títóbi Jù—ìyẹn Jésù, Ọmọ Dáfídì—tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yẹn. Ó jẹ́ àṣà Jésù láti máa lọ sí sínágọ́gù tí ń bẹ ládùúgbò rẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó máa ń gbọ́ tí wọ́n ń ka Ìwé Mímọ́ sétí ìgbọ́ àwọn èèyàn níbẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣàlàyé rẹ̀. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jésù alára ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sétí ìgbọ́ àwọn èèyàn, tó sì sọ bó ṣe ní ìmúṣẹ. (Lúùkù 4:16-21) Kò tiẹ̀ sí ni, kíá lo máa rí i pé Jésù mọ Ìwé Mímọ́ débi tí wọ́n ń mọ̀ ọ́n dé. Sáà ka àwọn ìwé Ìhìn Rere, kí o sì ṣàkíyèsí bí Jésù ti ń sọ léraléra pé “a kọ̀wé rẹ̀ pé” tàbí àwọn ọ̀nà míì tó gbà tọ́ka sí àwọn ibì kan pàtó nínú Ìwé Mímọ́. Àní, ìgbà mọ́kànlélógún ni ìwé Mátíù fi hàn pé Jésù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù nígbà tó ń ṣe Ìwàásù Lórí Òkè.—Mátíù 4:4-10; 7:29; 11:10; 21:13; 26:24, 31; Jòhánù 6:31, 45; 8:17.
7. Báwo ni Jésù ṣe yàtọ̀ sí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn?
7 Jésù tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú Sáàmù 1:1-3, tó kà pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú, . . . ṣùgbọ́n inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru. . . . Gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.” Ẹ wo bó ṣe yàtọ̀ sí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé rẹ̀ tó, ìyẹn àwọn tó “jókòó ní ìjókòó Mósè,” àmọ́ tí wọn kò kọbi ara sí “òfin Jèhófà”!—Mátíù 23:2-4.
8. Èé ṣe tó fi jẹ́ pé asán lórí asán ni gbogbo kíkà tàwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù sọ pé àwọn ń ka Bíbélì?
8 Ṣùgbọ́n o, ibì kan wà tó ṣeé ṣe kí ó kọ àwọn kan lóminú, nítorí pé lójú tiwọn ó lè dà bíi pé ṣe ni Jésù ń sọ pé kí àwọn jáwọ́ nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nínú Jòhánù 5:39, 40, a ka ohun tí Jésù sọ fáwọn kan nígbà ayé rẹ̀, pé: “Ẹ ń wá inú àwọn Ìwé Mímọ́ kiri, nítorí ẹ rò pé nípasẹ̀ wọn ẹ óò ní ìyè àìnípẹ̀kun; ìwọ̀nyí gan-an sì ni ó ń jẹ́rìí nípa mi. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ kò fẹ́ wá sọ́dọ̀ mi kí ẹ lè ní ìyè.” Ọ̀rọ̀ yìí kò fi hàn pé Jésù ń sọ fáwọn Júù tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n jáwọ́ nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń fi yé wọ́n pé alágàbàgebè tàbí ẹlẹ́nu méjì ni wọ́n. Wọ́n gbà pé Ìwé Mímọ́ lè ṣamọ̀nà àwọn lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n ṣebí Ìwé Mímọ́ kan náà tí wọ́n ń kà ló yẹ kó darí wọn sọ́dọ̀ Jésù tí í ṣe Mèsáyà. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n kọ Jésù sílẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ẹ̀kọ́ tí wọ́n sọ pé àwọn ń kọ́ kò ṣe wọ́n láǹfààní rárá, torí pé wọn o fi tinútinú kọ́ ọ, wọn ò sì gbẹ̀kọ́.—Diutarónómì 18:15; Lúùkù 11:52; Jòhánù 7:47, 48.
9. Àpẹẹrẹ àtàtà wo ni àwọn àpọ́sítélì àtàwọn wòlíì ìgbàanì fi lélẹ̀?
9 Ẹ ò rí i pé èrò àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, títí kan àwọn àpọ́sítélì, yàtọ̀ pátápátá sí èyí! Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ “Ìwé Mímọ́, èyí tí ó lè [sọni] di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.” (2 Tímótì 3:15) Nínú èyí, wọ́n dà bí àwọn wòlíì ìgbàanì tó ṣe “ìwádìí aláápọn àti ìwákáàkiri àfẹ̀sọ̀ṣe.” Àwọn wòlíì yẹn kò ṣe ìwádìí yẹn gìrìgìrì fún oṣù díẹ̀ tàbí fún ọdún kan, kí wọ́n sì wá ṣíwọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé “wọ́n ń bá a nìṣó ní ṣíṣe àyẹ̀wò,” pàápàá jù lọ nípa Kristi àti àwọn ògo tó wà nínú iṣẹ́ ìgbàlà tí yóò ṣe fáráyé. Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pétérù kọ, ìgbà mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ló fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú Bíbélì.—1 Pétérù 1:10, 11.
10. Èé ṣe tó fi yẹ kí kálukú wa nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
10 Fún ìdí yìí, ó ṣe kedere pé fífarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ọ̀kan lára ojúṣe àwọn ọba tó jẹ ní Ísírẹ́lì ìjelòó. Jésù tẹ̀ lé ìtọ́ni kan náà yìí. Kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀kan lára ẹrù iṣẹ́ àwọn tí yóò bá Kristi jọba ní ọ̀run. (Lúùkù 22:28-30; Róòmù 8:17; 2 Tímótì 2:12; Ìṣípayá 5:10; 20:6) Ìtọ́ni tá a fún àwọn ọba yìí tún ṣe pàtàkì fún gbogbo àwọn tí ń wọ̀nà fún ìbùkún orí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.—Mátíù 25:34, 46.
Bó Ṣe Jẹ́ Ojúṣe Ọba Ló Jẹ́ Ojúṣe Ìwọ Náà
11. (a) Ìṣòro wo ló lè dojú kọ àwọn Kristẹni nípa ọ̀ràn ìkẹ́kọ̀ọ́? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló máa dáa ká bi ara wa?
11 A lè fi tòótọ́tòótọ́ sọ ọ́ láìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀ pé olúkúlùkù Kristẹni ló yẹ kó máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A kò gbọ́dọ̀ fi mọ sígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́kọ́ kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó yẹ kí kálukú wa pinnu láti yẹra fún dídàbí àwọn kan nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí wọ́n dẹwọ́ dídákẹ́kọ̀ọ́ nígbà tó yá. Wọ́n kọ́ “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run,” irú bí “àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ nípa Kristi.” Àmọ́, wọn ò tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ kíkọ́, ìyẹn ni kò jẹ́ kí wọ́n “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.” (Hébérù 5:12-6:3) Fún ìdí yìí, àwa náà lè bi ara wa léèrè pé: ‘Ojú wo ni mo fi ń wo dídákẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, yálà mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni ni tàbí mo ti wà níbẹ̀ tipẹ́? Pọ́ọ̀lù gbàdúrà pé kí àwọn Kristẹni ọjọ́ òun máa “pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run.” Ǹjẹ́ èmi náà fẹ́ pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye?’—Kólósè 1:9, 10.
12. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti máa nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìṣó?
12 Kókó pàtàkì tó máa jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ múná dóko ni kí o nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Sáàmù 119:14-16 sọ̀rọ̀ nípa ṣíṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, lọ́nà tó gbéṣẹ́, kí o lè nífẹ̀ẹ́ sí i. Òótọ́ ni èyí pẹ̀lú, láìka bó ti pẹ́ tó téèyàn ti di Kristẹni sí. Kí kókó yìí lè túbọ̀ wọ̀ wá lọ́kàn, ẹ jẹ́ ká rántí àpẹẹrẹ Tímótì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristẹni alàgbà yìí ti ń sìn tipẹ́ gẹ́gẹ́ bí “ọmọ ogun àtàtà ti Kristi Jésù,” síbẹ̀ Pọ́ọ̀lù rọ̀ ọ́ pé kí ó máa sa gbogbo ipá rẹ̀ láti “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tímótì 2:3, 15; 1 Tímótì 4:15) Dájúdájú, kíkẹ́kọ̀ọ́ déédéé wà lára sísa “gbogbo ipá” rẹ.
13. (a) Báwo lo ṣe lè rí àkókò púpọ̀ sí i fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (b) Àwọn ìyípadà wo lo lè ṣe láti rí àkókò púpọ̀ sí i fún ìkẹ́kọ̀ọ́?
13 Ohun kan tó lè jẹ́ kó o ní ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ tó jíire ni láti ṣètò àkókò déédéé fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Báwo lo ṣe ń ṣe sí nínú ọ̀ràn yìí? Ohun yòówù kó jẹ́ ìdáhùn rẹ àtọkànwá, ǹjẹ́ o ò rò pé wàá jàǹfààní nínú lílo àkókò púpọ̀ sí i fún ìdákẹ́kọ̀ọ́? O lè béèrè pé, ‘Ibo ni mo ti fẹ́ ráyè ṣèyẹn?’ Ó dára, àwọn kan ti fi kún àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn nípa títètè jí láàárọ̀. Wọ́n lè fi ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ka Bíbélì tàbí kí wọ́n fi ṣe ìwádìí lórí àwọn kókó kan. Ọgbọ́n mìíràn rèé, tó o bá ṣe ìyípadà díẹ̀ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ pé ojoojúmọ́ lo ń ka ìwé ìròyìn tàbí tí ò ń gbọ́ ìròyìn alaalẹ́ lórí tẹlifíṣọ̀n, ṣé ó lè ṣeé ṣe láti fi ìròyìn sílẹ̀ fún ọjọ́ kan péré láàárín ọ̀sẹ̀? O lè fi àkókò náà kún àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́jọ́ yẹn. Bí o bá fi ìdákẹ́kọ̀ọ́ rọ́pò nǹkan bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tó o yà sọ́tọ̀ fún ìròyìn lọ́jọ́ kan, yóò lé ní wákàtí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tí wàá fi kún àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́dún kan. Sáà fojú inú wo ohun gidi tí wàá jèrè tó o bá fi wákàtí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n kún àkókò tó o fi ń ka Bíbélì tàbí tó o fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́! Àbá míì tún rèé: Lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, gbé ìgbòkègbodò rẹ yẹ̀ wò lópin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Wò ó bóyá nǹkan kan wà tó o lè pa tì tàbí kó o dín àkókò tó o fi ń ṣe é kù, kó o lè túbọ̀ ráyè fún kíkà Bíbélì tàbí ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́.—Éfésù 5:15, 16.
14, 15. (a) Èé ṣe tí níní góńgó fi ṣe pàtàkì nínú ọ̀ràn ìdákẹ́kọ̀ọ́? (b) Àwọn góńgó wo lèèyàn lè máa lépa nínú ọ̀ràn Bíbélì kíkà?
14 Kí ló máa jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ túbọ̀ rọrùn, kó sì túbọ̀ máa wù ọ́ ṣe? Níní góńgó tí ò ń lépa ni. Kí ni àwọn góńgó tó jíire tó o lè máa lépa? Fún ọ̀pọ̀ èèyàn, góńgó àkọ́kọ́ tó dára jù ni kíka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Bóyá títí di bá a ṣe ń wí yìí, o ti ka àwọn apá ibì kan nínú Bíbélì, o sì ti jàǹfààní nínú rẹ̀. Ṣé o lè wá pinnu báyìí láti ka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin? Láti ka Bíbélì parí, góńgó àkọ́kọ́ tó o lè máa lépa ni kíka ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Lẹ́yìn náà góńgó kejì lè jẹ́ kíka ìyókù Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Lẹ́yìn tó o bá ti rí ayọ̀ àti àǹfààní tó wà níbẹ̀, góńgó tó kàn lè jẹ́ bíbẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ìwé tí Mósè kọ àtàwọn ìwé tó dá lé ọ̀rọ̀ ìtàn, títí kan ìwé Ẹ́sítérì. Tó o bá parí ìyẹn tán, wàá wá rí i pé níbi tó o ti bá a dé yìí, kò yàtọ̀ sí tẹni tó fò sókè tó ti bẹ́jó lórí, àtika ìyókù Bíbélì kò ní nira mọ́. Obìnrin kan, tó jẹ́ ẹni nǹkan bí ọdún márùnlélọ́gọ́ta nígbà tó di Kristẹni, kọ ọjọ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí ka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ sínú èèpo ẹ̀yìn Bíbélì rẹ̀. Nígbà tó kà á tán, ó tún kọ ọjọ́ tó parí rẹ̀ síbẹ̀. Ẹ̀ẹ̀marùn-ún ló ti ká Bíbélì tán báyìí! (Diutarónómì 32:45-47) Dípò tí ì bá sì fi máa kà á lórí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà tàbí kó tẹ̀ ẹ́ jáde látinú kọ̀ǹpútà, Bíbélì fúnra rẹ̀ ló gbé tó ń kà á.
15 Àwọn kan tó ti parí kíka Bíbélì lódindi ti ṣe àwọn nǹkan míì láti mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń ṣe nìṣó túbọ̀ so èso rere, kí ó sì túbọ̀ máa mérè wá. Ohun tó o tún lè ṣe ni láti gbé àwọn ìsọfúnni kan yẹ̀ wò kó o tó ka ìwé Bíbélì kọ̀ọ̀kan. Èèyàn lè rí ìsọfúnni àtàtà nínú ìwé “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial” àti Insight on the Scriptures, nípa ìtàn lórí ìwé kọ̀ọ̀kan, ọ̀nà tá a gbà kọ wọ́n àti ohun téèyàn lè rí jèrè nínú ìwé kọ̀ọ̀kan.a
16. Àpẹẹrẹ wo ló yẹ ká yẹra fún tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
16 Nígbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́, yẹra fún nǹkan kan tí ọ̀pọ̀ àwọn tó pera wọn ní ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ń ṣe. Ohun tí wọ́n máa ń jókòó tì ni wíwá fìn-ín ìdí kókò àwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ, bíi pé ìwé téèyàn ṣe ni wọ́n ń yẹ̀ wò. Àwọn kan tiẹ̀ ti bá a débi sísọ pé àwọn èèyàn báyìí-báyìí nìkan ni ìwé Bíbélì báyìí-báyìí wà fún tàbí kí wọ́n gbé oríṣiríṣi àbá kalẹ̀ nípa ìdí tá a fi kọ ọ́, àti èrò tó wà lọ́kàn ẹ̀dá ènìyàn tó kọ ìwé kọ̀ọ̀kan. Ìyọrísí irú ìrònú bẹ́ẹ̀ tá a gbé ka ọgbọ́n orí lè jẹ́ káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí wo Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ìwé ìtàn lásánlàsàn tàbí bí ìwé tó kàn ń sọ̀rọ̀ nípa bí ọ̀ràn ẹ̀sìn ṣe bẹ̀rẹ̀. Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ làwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mìíràn gbájú mọ́, irú bíi ṣíṣàlàyé mẹ̀bẹ́mẹ̀yẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ kan nínú Bíbélì. Ohun tí wọ́n jókòó tì ni wíwá fìn-ín ìdí kókò àwọn ọ̀rọ̀ kan látinú èdè Hébérù àti Gíríìkì, dípò pípọkànpọ̀ sórí ìsọfúnni tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ o rò pé títẹ̀lé irú ọ̀nà yẹn lè jẹ́ kéèyàn ní ìgbàgbọ́ tó jiná dénú, tó ń súnni ṣiṣẹ́?—1 Tẹsalóníkà 2:13.
17. Kí nìdí tó fi yẹ ká wo Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ìwé tí ìsọfúnni inú rẹ̀ wà fún gbogbo èèyàn?
17 Ǹjẹ́ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ wọ̀nyí tilẹ̀ tọ̀nà? Ṣé òótọ́ ni pé kókó kan ṣoṣo ló wà nínú ìwé Bíbélì kọ̀ọ̀kan tàbí pé àwọn èèyàn báyìí-báyìí nìkan ni ìwé kan wà fún? (1 Kọ́ríńtì 1:19-21) Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wúlò fún àwọn èèyàn níbi gbogbo àti nígbà gbogbo. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnì kan la kọ ìwé kan sí níbẹ̀rẹ̀, bíi Tímótì tàbí Títù, tàbí sí àwùjọ kan pàtó, bí àwọn ará Gálátíà tàbí àwọn ará Fílípì, gbogbo wa la lè ka ìwé wọ̀nyí, gbogbo wa ló sì yẹ kó máa kà á. Ìwé wọ̀nyí wúlò fún gbogbo wa gan-an. Ìwé kan ṣoṣo sì lè jíròrò ọ̀pọ̀ ẹṣin ọ̀rọ̀, kí ó sì ṣàǹfààní fún onírúurú èèyàn. Àní sẹ́, àwọn ìsọfúnni tó wà nínú Bíbélì wà fún gbogbo èèyàn kárí ayé. Ìdí sì rèé tá a fi túmọ̀ rẹ̀ sí àwọn èdè tó wà jákèjádò ayé.—Róòmù 15:4.
Àǹfààní Tó Lè Ṣe fún Ìwọ Àtàwọn Ẹlòmíràn
18. Bó o ṣe ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí ló yẹ kó o máa ronú lé lórí?
18 Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ, wàá rí i pé ó ṣàǹfààní gan-an láti lóye ohun tí Bíbélì wí, kí o sì gbìyànjú láti rí bí ìsọfúnni kọ̀ọ̀kan ṣe tan mọ́ra. (Òwe 2:3-5; 4:7) Ohun tí Jèhófà ṣí payá nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wé mọ́ ète rẹ̀ tímọ́tímọ́. Nítorí náà, bó o ṣe ń ka Bíbélì, máa kíyè sí bí ìsọfúnni àti ìmọ̀ràn inú rẹ̀ ṣe tan mọ́ ète Ọlọ́run. O lè fara balẹ̀ ronú nípa bí ìṣẹ̀lẹ̀ kan, ìsọfúnni kan, tàbí àsọtẹ́lẹ̀ kan ṣe tan mọ́ ète Jèhófà. Bi ara rẹ pé: ‘Kí ni èyí ń sọ fún mi nípa Jèhófà? Báwo ló ṣe tan mọ́ ète Ọlọ́run tí yóò ní ìmúṣẹ nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀?’ O tún lè bi ara rẹ pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè lo ìsọfúnni yìí? Ǹjẹ́ mo lè fi kọ́ àwọn ẹlòmíì tàbí kí n fi fúnni nímọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́?’—Jóṣúà 1:8.
19. Àwọn wo ló ń jàǹfààní nígbà tó o bá ń ṣàlàyé ohun tó o kọ́ fáwọn ẹlòmíràn? Ṣàlàyé.
19 Ríronú nípa àwọn ẹlòmíràn tún ń ṣàǹfààní lọ́nà mìíràn. Bó o ṣe ń ka Bíbélì, tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, wàá rí àwọn nǹkan tuntun kọ́, òye rẹ á sì jinlẹ̀ sí i. Gbìyànjú láti máa sọ èyí mọ́ ọ̀rọ̀, nínú ìjíròrò tí ń gbéni ró nínú ìdílé tàbí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. Bó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní àkókò yíyẹ pẹ̀lú ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ó dájú pé irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ yóò ṣàǹfààní. Bó o ṣe ń fi tòótọ́tòótọ́ àti tìtaratìtara sọ ohun tó o kọ́ tàbí àwọn apá ibòmíràn tó o gbádùn, yóò mú kí irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ túbọ̀ wọ àwọn ẹlòmíràn lọ́kàn. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, yóò ṣe ìwọ alára láǹfààní. Lọ́nà wo? Àwọn ògbógi sọ pé èèyàn ò ní tètè gbàgbé ohun tó mọ̀ tàbí ohun tó kọ́, bó bá lò ó tàbí tó ń sọ ọ́ lásọtúnsọ, bíi kó máa sọ ọ́ fáwọn ẹlòmíràn nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ọ.b
20. Èé ṣe tó fi ṣàǹfààní láti máa ka Bíbélì ní gbogbo ìgbà?
20 Kò sígbà tó o ka ìwé Bíbélì kan tí o ò ní rí ohun tuntun kọ́. Háà á ṣe ọ́, pé ìsọfúnni tó tóyẹn wà níbi tó o ti kà kọjá tẹ́lẹ̀ láìmọ̀ pé ẹ̀kọ́ tó ṣe gúnmọ́ wà níbẹ̀. Òye rẹ á wá kún sí i. Ó yẹ kí èyí tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa lọ́kàn pé, àwọn ìwé Bíbélì kì í ṣe ìwé èèyàn lásánlàsàn, bí kò ṣe ìwé tó kún fún ìṣúra, tó yẹ kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ ní gbogbo ìgbà fún ire ara rẹ. Rántí pé àwọn ọba bíi Dáfídì, ní láti “máa kà á ní gbogbo ọjọ́” ayé wọn.
21. Kí ni èrè tó o lè retí láti rí nínú jíjáramọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
21 Dájúdájú, àwọn tó bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀jinlẹ̀ máa ń jàǹfààní rẹpẹtẹ. Wọ́n ń jèrè ìṣúra àti ìjìnlẹ̀ òye tẹ̀mí. Àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run á túbọ̀ dán mọ́rán, á túbọ̀ gbámúṣé. Wọ́n á tún di èèyàn àtàtà nínú ìdílé, arákùnrin àti arábìnrin àtàtà nínú ìjọ Kristẹni. Wọ́n á di ẹni bí ẹni, èèyàn bí èèyàn, lójú àwọn ará ìta tí kò tíì di olùjọsìn Jèhófà.—Róòmù 10:9-14; 1 Tímótì 4:16.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí jáde, wọ́n sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí la ní kí àwọn ọba Ísírẹ́lì máa ṣe?
• Àpẹẹrẹ wo ni Jésù àtàwọn àpọ́sítélì fi lélẹ̀ nínú ọ̀ràn kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
• Ìyípadà wo lo lè ṣe láti fi kún àkókò ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ?
• Irú ẹ̀mí wo ló yẹ kó o máa fi kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]
“Bíbélì Gan-an Ló Yẹ Ká Gbé Dání”
“Bí a bá ń wá . . . atọ́ka ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, ibi tó dára jù lọ láti lọ ni orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ṣùgbọ́n bá a bá fẹ́ ka Bíbélì, tá a fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀, tá a fẹ́ ronú lé e lórí, tá a fẹ́ ṣàṣàrò lé e lórí, òun gan-an ló yẹ ká gbé dání, torí pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nìkan ṣoṣo lọ̀rọ̀ inú rẹ̀ fi lè wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin.”—Gertrude Himmelfarb, ògúnnágbòǹgbò ọ̀jọ̀gbọ́n tó ti fẹ̀yìn tì, láti City University, New York.