Ìwé Kejì sí Tímótì
3 Àmọ́ kí o mọ èyí pé, àwọn ọjọ́ ìkẹyìn+ yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira. 2 Torí àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n á jẹ́ afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìmoore, aláìṣòótọ́, 3 ẹni tí kò ní ìfẹ́ àdámọ́ni, kìígbọ́-kìígbà,* abanijẹ́, ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu, ẹni tó burú gan-an, ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ ohun rere, 4 ọ̀dàlẹ̀, alágídí, ajọra-ẹni-lójú, wọ́n á fẹ́ràn ìgbádùn dípò Ọlọ́run, 5 wọ́n á jọ ẹni tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, àmọ́ ìṣe wọn ò ní fi agbára rẹ̀ hàn;+ yẹra fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀. 6 Lára wọn ni àwọn ọkùnrin kan ti jáde, tí wọ́n ń fi ẹ̀tàn wọnú àwọn agbo ilé, tí wọ́n sì ń tan àwọn aláìlera obìnrin tí ẹ̀ṣẹ̀ ti wọ̀ lọ́rùn, tí onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ń darí, 7 gbogbo ìgbà ni wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀ wọn ò ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́ rárá.
8 Bí Jánésì àti Jáńbérì ṣe ta ko Mósè, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn yìí ṣe ń ta ko òtítọ́ ṣáá. Ìrònú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ti dìbàjẹ́, ìgbàgbọ́ wọn ò sì ní ìtẹ́wọ́gbà. 9 Síbẹ̀, wọn ò ní kọjá ibi tí wọ́n dé, torí ìwà òmùgọ̀* wọn máa hàn kedere sí gbogbo èèyàn, bíi tàwọn ọkùnrin méjì yẹn.+ 10 Àmọ́, o ti tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ mi pẹ́kípẹ́kí, bí mo ṣe ń ṣe nǹkan,+ ohun tí mo ní lọ́kàn, ìgbàgbọ́ mi, sùúrù mi, ìfẹ́ mi, ìfaradà mi, 11 àwọn inúnibíni àti irú ìyà tó jẹ mí ní Áńtíókù,+ Íkóníónì+ àti Lísírà.+ Mo fara da àwọn inúnibíni yìí, Olúwa sì gbà mí nínú gbogbo wọn.+ 12 Ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.+ 13 Àmọ́ àwọn èèyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà á máa burú sí i, wọ́n á máa ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, wọ́n á sì máa ṣi àwọn náà lọ́nà.+
14 Àmọ́ kí ìwọ má ṣe fi àwọn nǹkan tí o ti kọ́ sílẹ̀, tí a sì mú kí o gbà gbọ́,*+ o sì mọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn 15 àti pé láti kékeré jòjòló + lo ti mọ ìwé mímọ́,+ èyí tó lè mú kí o di ọlọ́gbọ́n kí o lè rí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù.+ 16 Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí,+ ó sì wúlò fún kíkọ́ni,+ fún bíbáni wí, fún mímú nǹkan tọ́,* fún títọ́nisọ́nà nínú òdodo,+ 17 kí èèyàn Ọlọ́run lè kúnjú ìwọ̀n dáadáa, kó sì lè gbára dì pátápátá fún gbogbo iṣẹ́ rere.