Jèhófà Mọ Bó Ṣe Máa Dá Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Nídè
“Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.”—2 PÉT. 2:9.
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ DÁ WA LÓJÚ PÉ JÈHÓFÀ:
Mọ àkókò tó máa mú àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ?
Máa lo agbára rẹ̀ nítorí àwọn èèyàn rẹ̀?
Mọ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá ṣe máa wáyé?
1. Báwo ni ipò àwọn nǹkan ṣe máa rí nígbà “ìpọ́njú ńlá”?
ỌLỌ́RUN máa mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí ayé Sátánì yìí lójijì, nígbà tí àwọn èèyàn kò rò tẹ́lẹ̀. (1 Tẹs. 5:2, 3) Bí “ọjọ́ ńlá Jèhófà” bá sì dé, ìdààmú yóò bá gbogbo aráyé. (Sef. 1:14-17) Aráyé á wà nínú ìnira, nǹkan kò sì ní fara rọ̀ fún wọn. Ó máa jẹ́ àkókò wàhálà, “irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí.”—Ka Mátíù 24:21, 22.
2, 3. (a) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà “ìpọ́njú ńlá”? (b) Kí ló lè máa fún wa lókun bá a ṣe ń retí àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀?
2 Bí “ìpọ́njú ńlá” náà bá ti ń lọ sí òpin, “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù” máa fi gbogbo agbára gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ní àsìkò yẹn “ẹgbẹ́ ológun tí ó pọ̀ níye” máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run “bí àwọsánmà láti bo ilẹ̀ náà.” (Ìsík. 38:2, 14-16) Kò sí àjọ èyíkéyìí tí àwọn èèyàn dá sílẹ̀ tó máa gbèjà àwọn èèyàn Jèhófà. Ọlọ́run nìkan ló máa lè gbà wọ́n là. Kí ni wọ́n máa ṣe nígbà tí àwọn ọ̀tá bá dójú sọ wọ́n kí wọ́n lè pa wọ́n run?
3 Tó o bá jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, ǹjẹ́ o ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà lè pa àwọn èèyàn rẹ̀ mọ́ láàyè nígbà ìpọ́njú ńlá náà àti pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀? Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò, ṣùgbọ́n láti fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ láti ké wọn kúrò.” (2 Pét. 2:9) Tá a bá ń ṣe àṣàrò lórí bí Jèhófà ṣe dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè nígbà àtijọ́, ìgbọ́kànlé tá a ní pé Jèhófà ní agbára láti dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè á túbọ̀ lágbára sí i. Torí náà, ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ mẹ́ta yẹ̀ wò.
Ó MÚ KÍ WỌ́N LA ÀKÚNYA OMI TÓ KÁRÍ AYÉ JÁ
4. Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ìkún-omi ṣe fi hàn pé Jèhófà kì í fi àkókò falẹ̀?
4 Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Ìkún-omi ọjọ́ Nóà. Kí Jèhófà lè mú àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ, kì í fi àkókò falẹ̀. Iṣẹ́ bàǹtàbanta wà nílẹ̀ láti ṣe, irú bíi kíkan ọkọ̀ áàkì àti kíkó àwọn ẹranko sínú ọkọ̀ náà kí Ìkún-omi tó bẹ̀rẹ̀. Àkọsílẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì kò sọ pé ẹ̀yìn tí wọ́n ti kan ọkọ̀ áàkì tán ni Jèhófà tó pinnu ìgbà tí Ìkún-omi máa wáyé, bíi pé ìyẹn á jẹ́ kó lè yí ìgbà tí Ìkún-omi máa bẹ̀rẹ̀ pa dà tó bá ṣẹlẹ̀ pé kíkan ọkọ̀ áàkì náà kò tètè parí. Kàkà bẹ́ẹ̀, kí Jèhófà tiẹ̀ tó sọ fún Nóà pé ó máa kan ọkọ̀ áàkì ló ti dá ìgbà tí Ìkún-omi máa bẹ̀rẹ̀. Báwo la ṣe mọ bẹ́ẹ̀?
5. Àṣẹ wo ni Jèhófà pa nínú àkọsílẹ̀ tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 6:3, ìgbà wo ló sì pa àṣẹ náà?
5 Bíbélì sọ fún wa pé Jèhófà pa àṣẹ kan ní ọ̀run. Ní ìbámu pẹ̀lú Jẹ́nẹ́sísì 6:3, ó sọ pé: “Ẹ̀mí mi kò ní fi àkókò tí ó lọ kánrin gbé ìgbésẹ̀ sí ènìyàn nítorí pé ó jẹ́ ẹlẹ́ran ara pẹ̀lú. Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọgọ́fà ọdún.” Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ nípa iye ọdún tí ẹ̀dá èèyàn á máa gbé láyé o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà ń kéde ìgbà tó máa fọ ìwà ibi mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé.a Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọdún 2370 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Ìkún-omi bẹ̀rẹ̀, a parí èrò sí pé ọdún 2490 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Ọlọ́run pa àṣẹ yẹn. Ní ìgbà yẹn, ẹni ọ̀rìnlénírínwó [480] ọdún ni Nóà. (Jẹ́n. 7:6) Ní nǹkan bí ogún [20] ọdún lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 2470 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Nóà bẹ̀rẹ̀ sí í bí àwọn ọmọ rẹ̀. (Jẹ́n. 5:32) Ó ṣì ku nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kí Ìkún-omi náà wáyé, síbẹ̀ Jèhófà kò tíì sọ ipa tí Nóà máa kó láti gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là fún un. Báwo ni Jèhófà ṣe máa dúró pẹ́ tó kó tó sọ fún Nóà?
6. Ìgbà wo ni Jèhófà pàṣẹ fún Nóà pé kó kan ọkọ̀ áàkì?
6 Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ọdún ni Jèhófà fi dúró kó tó wá sọ ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún Nóà. Kí ló mú ká rò bẹ́ẹ̀? Àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí fi hàn pé àwọn ọmọ Nóà ti dàgbà wọ́n sì ti gbéyàwó kí Ọlọ́run tó pàṣẹ fún Nóà pé kó kan ọkọ̀ áàkì. Jèhófà sọ fún un pé: “Èmi sì fìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ; ìwọ yóò sì wọnú áàkì náà, ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ àti aya rẹ àti aya àwọn ọmọkùnrin rẹ pẹ̀lú rẹ.” (Jẹ́n. 6:9-18) Torí náà, nígbà tí Jèhófà pàṣẹ fún Nóà pé kó kan ọkọ̀ áàkì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nǹkan bí ogójì [40] tàbí àádọ́ta [50] ọdún ló kù kí Ìkún-omi wáyé.
7. (a) Báwo ni Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣe fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́? (b) Ìgbà wo gan-an ni Ọlọ́run wá sọ ìgbà tí Ìkún-omi náà máa bẹ̀rẹ̀ fún Nóà?
7 Bí iṣẹ́ kíkan ọkọ̀ áàkì náà ṣe ń bá a nìṣó, Nóà àti ìdílé rẹ̀ ti ní láti máa ṣe kàyéfì nípa bí Ọlọ́run ṣe máa mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ àti ìgbà tí Ìkún-omi náà máa bẹ̀rẹ̀. Síbẹ̀, ti pé wọn kò mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa iṣẹ́ yìí kò dí wọn lọ́wọ́ kíkan ọkọ̀ áàkì. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Nóà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Jẹ́n. 6:22) Nígbà tó ku ọjọ́ méje kí Ìkún-omi bẹ̀rẹ̀, Jèhófà sọ ìgbà náà gan-an tí Ìkún-omi máa bẹ̀rẹ̀, ọjọ́ tó ṣẹ́ kù náà sì pọ̀ tó fún Nóà àti ìdílé rẹ̀ láti kó àwọn ẹranko sínú ọkọ̀ áàkì. Torí náà, nígbà tí Ọlọ́run wá ṣí ibú omi ọ̀run “ní ẹgbẹ̀ta ọdún ìwàláàyè Nóà, ní oṣù kejì, ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù,” ohun gbogbo ti wà ní sẹpẹ́.—Jẹ́n. 7:1-5, 11.
8. Báwo ni ìtàn nípa Ìkún-omi yìí ṣe mú un dá wa lójú pé Jèhófà mọ ìgbà tó máa dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè?
8 Ìtàn nípa Ìkún-omi jẹ́rìí sí i pé yàtọ̀ sí pé Jèhófà jẹ́ Olùpàkókòmọ́, ó tún jẹ́ Olùdáǹdè. Bí Jèhófà ṣe ń retí ìgbà tí òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí máa dé, ó yẹ kó dá wa lójú pé gbogbo ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe ló máa wáyé ní ìgbà tó ti yàn pé kí wọ́n ṣẹlẹ̀ àti ní “ọjọ́ àti wákàtí” tó ti yàn.—Mát. 24:36; ka Hábákúkù 2:3.
Ó DÁ WỌN NÍDÈ NÍ ÒKUN PUPA
9, 10. Báwo ni Jèhófà ṣe lo àwọn èèyàn rẹ̀ láti tan àwọn ẹgbẹ́ ológun Íjíbítì sínú ìdẹkùn?
9 Ní báyìí, a ti wá rí i pé Jèhófà ló máa ń pinnu àkókò tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan máa wáyé kó lè mú àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Àpẹẹrẹ kejì tá a máa gbé yẹ̀ wò sọ ìdí mìíràn tá a fi lè ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà máa dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè. Ó máa lo agbára rẹ̀ tí kò ní ààlà láti rí i dájú pé ohun tó ní lọ́kàn ní ìmúṣẹ. Agbára tí Jèhófà ní láti dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nídè dájú débi pé ó ti lò wọ́n rí láti tan àwọn ọ̀tá rẹ̀ sínú ìdẹkùn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn nígbà tó gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì.
10 Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó fi ilẹ̀ Íjíbítì sílẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́ta. Jèhófà mú kí Mósè darí wọn lọ́nà tó mú kí Fáráò ronú pé ńṣe ni wọ́n kàn ń rìn gbéregbère kiri. (Ka Ẹ́kísódù 14:1-4.) Ojú Fáráò kò kúrò lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lépa àwọn ẹrú rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí yìí, wọ́n sì ká wọn mọ́ Òkun Pupa. Ó wá jọ pé kò sí ọ̀nà àbáyọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ẹ́kís. 14:5-10) Àmọ́ kò sí ewu kankan fún wọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà máa tó bá wọn dá sí ọ̀rọ̀ náà.
11, 12. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́? (b) Ibo ni ọ̀rọ̀ náà já sí lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti dá sí i, kí sì ni ìtàn yìí kọ́ wa nípa Jèhófà?
11 “Ọwọ̀n àwọsánmà” tó ń darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá sí ẹ̀yìn wọn, kò jẹ́ kí àwọn ọmọ ogun Fáráò lè dé ọ̀dọ̀ wọn, ó sì tún jẹ́ kí wọ́n wà nínú òkùnkùn. Àmọ́ ọwọ̀n náà pèsè ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà ìyanu ní òru. (Ka Ẹ́kísódù 14:19, 20.) Jèhófà wá lo ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn líle láti pín òkun náà sí méjì, “ó sì yí ìsàlẹ̀ òkun padà di ilẹ̀ gbígbẹ.” Èyí gba àkókò gígùn torí àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Níkẹyìn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la àárín òkun kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ.” Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò sáré bíi ti àwọn ọmọ ogun Fáráò tó wà lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun wọn, ńṣe ni wọ́n rọra ń lọ. Síbẹ̀, kò jọ pé àwọn ọmọ ogun Íjíbítì lè bá wọn lọ́nà, torí pé Jèhófà ń jà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. “Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kó ibùdó àwọn ará Íjíbítì sínú ìdàrúdàpọ̀. Ó sì ń bá a lọ láti máa yọ àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ kúrò lára kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn, tí ó fi jẹ́ pé ìṣòro ni wọ́n fi ń wà wọ́n.”—Ẹ́kís. 14:21-25.
12 Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti sọdá sí òdì kejì òkun, Jèhófà pàṣẹ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ sórí òkun, kí omi náà lè padà wá sórí àwọn ará Íjíbítì, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun wọn àti àwọn agẹṣinjagun wọn.” Bí àwọn ọmọ ogún náà ṣe ń gbìyànjú láti sá lọ nítorí omi tó ń rọ́ bọ̀, “Jèhófà gbọn àwọn ará Íjíbítì dànù sí àárín òkun náà.” Kò sí ọ̀nà àbáyọ fún wọn. “Kò tilẹ̀ sí ẹyọ kan ṣoṣo nínú wọn tí ó ṣẹ́ kù.” (Ẹ́kís. 14:26-28) Jèhófà tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun ní agbára láti dá àwọn èèyàn òun nídè nínú ipòkípò tí wọ́n bá wà.
WỌ́N LA ÌPARUN JERÚSÁLẸ́MÙ JÁ
13. Ìtọ́ni wo ni Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, kí ló sì ṣeé ṣe kó ṣe wọ́n ní kàyéfì?
13 Jèhófà mọ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ṣe máa wáyé gẹ́lẹ́ kí àwọn ohun tó ní lọ́kàn lè ní ìmúṣẹ. A máa túbọ̀ mọ bí kókó yìí ti ṣe pàtàkì tó bá a ti ń ṣe àgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ kẹta, ìyẹn ni bí wọ́n ṣe sàga ti Jerúsálẹ́mù ní ọ̀rúndún kìíní. Ṣáájú ìparun tó wá sórí ìlú Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà ní ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, Jèhófà lo Ọmọ rẹ̀ láti fún àwọn Kristẹni tí wọ́n ń gbé àwọn ìlú náà ní ìtọ́ni tó máa mú kí wọ́n la ìparun náà já. Jésù sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nípasẹ̀ Dáníẹ́lì wòlíì, . . . nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.” (Mát. 24:15, 16) Ṣùgbọ́n, báwo ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe máa mọ̀ nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ?
14. Báwo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ṣe mú kí ìtúmọ̀ àwọn ìtọ́ni Jésù ṣe kedere?
14 Bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ń wáyé, ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù wá túbọ̀ ṣe kedere. Lọ́dún 66 Sànmánì Kristẹni, ọ̀gágun Cestius Gallus kó àwọn ọmọ ogun Róòmù wá sí ìlú Jerúsálẹ́mù kó lè paná ọ̀tẹ̀ tí àwọn Júù dá sílẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Júù ọlọ̀tẹ̀, tí wọ́n ń pè ní àwọn Onítara Ìsìn, lọ sá pa mọ́ sínú odi tí wọ́n mọ yí tẹ́ńpìlì ká, àwọn ọmọ ogun Róòmù bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ ògiri tẹ́ńpìlì náà nídìí. Àwọn Kristẹni tó wà lójúfò mọ ìtumọ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ dáadáa. Àwọn ọmọ ogun tí wọ́n jẹ́ kèfèrí gbé àwọn àsíá wọn (“ohun ìríra”) wá síbi ògiri tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù (“ibi mímọ́”). Àkókò nìyí fún àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù láti “bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.” Àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe máa lè jáde kúrò ní ìlú tí wọ́n ti sàga tì náà? Àwọn ohun tí wọn kò retí máa tó ṣẹlẹ̀.
15, 16. (a) Ìtọ́ni pàtó wo ni Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n fi ìtọ́ni náà sílò? (b) Orí kí ni ìdáǹdè wa máa sinmi lé?
15 Láìsí ìdí kan tó ṣe gúnmọ́, ọ̀gágun Cestius Gallus àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ fi ìlú Jerúsálẹ́mù sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà sí ìlú wọn. Àwọn Júù ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Onítara Ìsìn sì lépa wọn lọ. Lẹ́yìn tí àwọn tó ń jagun ti kúrò nílùú, àyè ṣí sílẹ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù láti fi ìlú náà sílẹ̀. Jésù ti sọ fún wọn tẹ́lẹ̀ pé kí wọ́n fi àwọn ohun ìní wọn sílẹ̀, kí wọ́n sì kúrò ní ìlú náà láìjáfara. (Ka Mátíù 24:17, 18.) Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ pọn dandan kí wọ́n tètè kúrò ní ìlú náà? Kò pẹ́ tí wọ́n fi rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí. Láàárín ọjọ́ mélòó kan, àwọn Onítara Ìsìn náà ti pa dà dé, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ipá mú àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà láti dara pọ̀ nínú ọ̀tẹ̀ náà. Lọ́gán, ipò nǹkan ti wá burú gan-an nínú ìlú náà bí àwùjọ àwọn Júù tí kò fara mọ́ ọ̀tẹ̀ náà ṣe ń gbìyànjú kí wọ́n lè gba ara wọn lọ́wọ́ àwọn Onítara Ìsìn yẹn. Ó túbọ̀ wá ṣòro láti sá lọ. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Róòmù pa dà dé lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, kò tiẹ̀ wá ṣeé ṣe mọ́ láti sá lọ. (Lúùkù 19:43) Wọ́n ká àwọn tó ń fi nǹkan falẹ̀ mọ́ inú ìlú! Àmọ́ ní ti àwọn Kristẹni tí wọ́n ti sá lọ sórí àwọn òkè, fífi ìtọ́ni tí Jésù fún wọn sílò gba ẹ̀mí wọn là. Wọ́n fojú ara wọn rí i pé Jèhófà mọ bó ṣe máa ń dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìtàn yìí?
16 Nígbà ìpọ́njú ńlá, ó máa pọn dandan pé kí àwa Kristẹni máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tá a bá ń rí gbà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nípasẹ̀ ètò rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àṣẹ tí Jésù pa pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun “bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá” ṣì kan àwa náà lónìí. Bí sísá wa ṣe máa jẹ́ ni a kò tíì mọ̀.b Àmọ́, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa mú kí ìtumọ̀ àwọn ìtọ́ni náà ṣe kedere sí wa bí àkókò bá ti tó fún wa láti fi wọ́n sílò. Níwọ̀n bí ìdáǹdè wa ti máa sinmi lórí jíjẹ́ tá a bá jẹ́ onígbọràn, ó dára ká bi ara wa pé: ‘Báwo ni mo ṣe ń dáhùn pa dà sí àwọn ìtọ́ni tí Jèhófà ń fún àwọn èèyàn rẹ̀ báyìí? Ṣé mo máa ń tètè dáhùn pa dà, àbí ńṣe ni mo máa ń lọ́ra láti ṣègbọràn?’—Ják. 3:17.
ỌLỌ́RUN FÚN WA LÓKUN NÍTORÍ ÀWỌN OHUN TÓ Ń BỌ̀ WÁ ṢẸLẸ̀
17. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Hábákúkù jẹ́ ká mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run?
17 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wá pa dà sórí ohun tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí nípa bí Gọ́ọ̀gù ṣe máa fi gbogbo agbára gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan tó jọ èyí, Hábákúkù sọ pé: “Mo gbọ́, ṣìbáṣìbo sì bá ikùn mi; ètè mí gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ sí ìró náà; ìjẹrà bẹ̀rẹ̀ sí wọnú egungun mi; ṣìbáṣìbo sì bá mi nínú ipò mi, kí n lè fi ìdákẹ́jẹ́ẹ́ dúró de ọjọ́ wàhálà, de gígòkè wá [Ọlọ́run] sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn [àwọn ọmọ ogun tó ń kó ìpayà báni], kí ó lè gbé sùnmọ̀mí lọ bá wọn.” (Háb. 3:16) Bí wòlíì náà ṣe gbọ́ nípa bí wọ́n ṣe máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run mú kí ṣìbáṣìbo bá ikùn rẹ̀, ètè rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, kò sì lókun nínú mọ́. Ó jọ pé ńṣe ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hábákúkù fi bí hílàhílo wa ṣe máa pọ̀ tó hàn nígbà tí àwọn ọmọ ogun Gọ́ọ̀gù bá rọ́ dé láti gbéjà kò wá. Síbẹ̀, wòlíì náà múra tán láti fi ìdákẹ́jẹ́ẹ́ dúró dé ọjọ́ ńlá Jèhófà, ó sì fọkàn tán Jèhófà pé ó máa dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè. Àwa náà lè ní irú ìdánilójú bẹ́ẹ̀.—Háb. 3:18, 19.
18. (a) Kí nìdí tí a kò fi ní láti bẹ̀rù ìgbéjàkò tó ń bọ̀? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
18 Láìsí àní-àní, àpẹẹrẹ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí ti jẹ́ ká rí i pé Jèhófà mọ bó ṣe lè dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè. Ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe kò ní kùnà; ìgbàlà wa dájú. Àmọ́, ká tó lè nípìn-ín nínú ìṣẹ́gun ológo náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ títí dé òpin. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè pa ìwà títọ́ wa mọ́ ní báyìí? Ohun tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn nìyẹn.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ǹjẹ́ ìgbà kankan wà tí àwọn ọmọ ogun Fáráò jẹ́ ewu fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?