‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
“Ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ ti ń dúró de àánú Olúwa wa Jésù Kristi pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.”—JÚÚDÀ 21.
1, 2. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, báwo la sì ṣe mọ̀ pé kò kàn ní ṣàdédé mú ká dúró nínú ìfẹ́ òun?
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN ti fi hàn ní àìmọye ọ̀nà pé òun nífẹ̀ẹ́ wa. Láìsí àní-àní, ẹ̀rí tó ga jù lọ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ni bó ṣe ṣètò ẹbọ ìràpadà. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún aráyé pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi rán Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n wá sórí ilẹ̀ ayé láti wá kú fún wa. (Jòh. 3:16) Ohun tó mú kí Jèhófà ṣe èyí ni pé ó fẹ́ ká máa gbé títí láé, ó sì fẹ́ ká máa jọlá ìfẹ́ òun títí láé!
2 Àmọ́ ǹjẹ́ ó yẹ ká rò pé Jèhófà á kàn ṣàdédé pa wá mọ́ nínú ìfẹ́ rẹ̀, ìyẹn ni pé ṣé á mú ká dúró nínú ìfẹ́ òun, láìka ohun yòówù tá a bá pinnu láti ṣe sí? Kò yẹ bẹ́ẹ̀ o, nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú ìwé Júúdà, ẹsẹ 21 ni pé: “Ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ ti ń dúró de àánú Olúwa wa Jésù Kristi pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.” Gbólóhùn náà “ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run” fi hàn pé ohun kan wà tá a retí pé kí àwa fúnra wa ṣe. Kí wá lohun náà tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká bàa lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run?
Báwo La Ṣe Lè Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run?
3. Kí ni Jésù sọ pé ó pọn dandan fóun láti máa ṣe kóun bàa lè dúró nínú ìfẹ́ Bàbá òun?
3 A rí ìdáhùn ìbéèrè yìí nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù fẹnu ara rẹ̀ sọ lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé kó tó kú. Ó sọ pé: “Bí ẹ bá pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ óò dúró nínú ìfẹ́ mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àwọn àṣẹ Baba mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.” (Jòh. 15:10) Ó ṣe kedere pé Jésù mọ̀ pé bóun bá máa ní àjọṣe rere pẹ̀lú Jèhófà Bàbá òun, ó di dandan kóun máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Bí Jésù, ẹni pípé, Ọmọ Ọlọ́run bá rí i pé ìyẹn pọn dandan fóun, ṣé kò yẹ káwa náà máa pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́ ká lè ní àjọṣe rere pẹ̀lú rẹ̀?
4, 5. (a) Ọ̀nà pàtàkì wo la lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣàìgbọràn sáwọn òfin Jèhófà?
4 Ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni pé ká máa ṣègbọràn sí i. Bí àpọ́sítélì Jòhánù ṣe sọ ọ̀rọ̀ náà rèé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòh. 5:3) Lóòótọ́, kì í fi bẹ́ẹ̀ wu àwọn èèyàn lóde òní pé káwọn máa gbọ́ràn sí ẹnì kan lẹ́nu. Àmọ́, ṣé ẹ kíyè sí gbólóhùn náà, “Síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira”? Ìyẹn fi hàn pé Jèhófà kò béèrè pé ká ṣe ohun tágbára wa ò lè gbé.
5 Ẹ jẹ́ ká ṣàkàwé rẹ̀ lọ́nà yìí: Ǹjẹ́ wàá sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ kan pé kó gbé ẹrù kan tó o mọ̀ pé ó wúwo jù fún un láti gbé? Ó dájú pé o ò ní fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀! Bẹ́ẹ̀ sì rèé, inúure Jèhófà pọ̀ ju tiwa lọ fíìfíì, ó sì mọ ibi tágbára wa mọ. Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà “rántí pé ekuru ni wá.” (Sm. 103:14) Kò jẹ́ sọ láé pé ká ṣohun tágbára wa ò gbé. Torí náà, kò sídìí tó fi yẹ ká máa ṣàìgbọràn sáwọn òfin Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká wo ṣíṣègbọràn sí Jèhófà Baba wa ọ̀run gẹ́gẹ́ bí àǹfààní àgbàyanu tá a ní láti fi hàn pé òótọ́ la nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Ẹ̀bùn Pàtàkì Kan Tí Jèhófà Fún Wa
6, 7. (a) Kí ló ń jẹ́ ẹ̀rí ọkàn? (b) Kí lo lè fi ṣàkàwé bí ẹ̀rí ọkàn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run?
6 Nínú ayé tó kún fún oríṣiríṣi nǹkan yìí, ó di dandan fún wa láti máa ṣe ọ̀pọ̀ ìpinnu tó kan ọ̀ràn ìgbọràn wa sí Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè mọ̀ dájú bóyá àwọn ìpinnu tá a ń ṣe bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu tàbí kò bá a mu? Jèhófà ti fún wa lẹ́bùn kan tó máa ràn wá lọ́wọ́ gan-an lórí ọ̀ràn ìgbọràn yìí. Ẹ̀bùn yẹn ni ẹ̀rí ọkàn. Kí ló ń jẹ́ ẹ̀rí ọkàn? Ẹ̀rí ọkàn ni àkànṣe èrò kan tó wà nínú ọkàn wa tó ń jẹ́ ká mohun tó tọ́ yàtọ̀ sóhun tí kò tọ́. Ó máa ń ṣiṣẹ́ bí adájọ́ tó ń gbénú wa, tó máa ń jẹ́ ká lè ṣàyẹ̀wò àwọn ìpinnu tá a ní láti ṣe nígbèésí ayé, tàbí ká lè ronú lórí àwọn ohun tá a ti ṣe ká sì yẹ̀ wọ́n wò, bóyá wọ́n dára tàbí wọn ò dára.—Ka Róòmù 2:14, 15.
7 Ọ̀nà wo ni ẹ̀rí ọkàn wa lè gbà máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣohun tó tọ́? Ẹ jẹ́ ká gbé àkàwé kan yẹ̀ wò. Arìnrìn-àjò kan ń rìn ní aṣálẹ̀ kan tó lọ salalu. Kò sí ipa ọ̀nà kankan tó lè tọ̀, kò sí títì, kò sì sí àkọlé kankan tó lè darí rẹ̀ síbi tó ń lọ. Síbẹ̀, kò ṣìnà ibi tó ń lọ. Ọgbọ́n wo ló wá dá sí i? Ó lo ohun èèlò atọ́nisọ́nà kan tó ń jẹ́ kọ́ńpáàsì tó ń ràn án lọ́wọ́. Kọ́ńpáàsì yìí dà bí aago kékeré kan. Bí arìnrìn-àjò yìí kò bá ní ohun èlò yìí, kò ní lè débi tó ń lọ. Bákan náà, bí èèyàn ò bá ní ẹ̀rí ọkàn, kò sí bó ṣe máa lè hùwà tó tọ́, kò ní lè ṣohun tó bójú mu, kò sì ní lè ṣàwọn ìpinnu tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu nígbèésí ayé rẹ̀.
8, 9. (a) Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa ibi tí agbára ẹ̀rí ọkàn wa mọ? (b) Kí la lè ṣe láti rí i dájú pé ẹ̀rí ọkàn wa wúlò fún wa bó ṣe yẹ?
8 Àmọ́ bíi ti ohun èlò atọ́nisọ́nà tó ń jẹ́ kọ́ńpáàsì yẹn, ó níbi tágbára ẹ̀rí ọkàn mọ. Bí arìnrìn-àjò tá a sọ yìí bá fi ohun èlò atọ́nisọ́nà tá à ń sọ yẹn sẹ́gbẹ̀ẹ́ agbérin tútù, ó lè jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ségesège. Báwa náà bá jẹ́ kí ìfẹ́ ọkàn wa jẹ wá lógún ju bó ṣe yẹ lọ, kí ló máa ṣẹlẹ̀? Ńṣe ni ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan máa jọba lọ́kàn wa, ìyẹn sì lè jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ségesège. Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé “ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” (Jer. 17:9 Òwe 4:23) Síwájú sí i, bí arìnrìn-àjò tá à ń sọ yìí kò bá lo ohun èlò atọ́nisọ́nà yẹn pa pọ̀ pẹ̀lú ìwé atọ́nisọ́nà tó péye, ó lè ṣìnà. Báwa pẹ̀lú ò bá gbára lé ìtọ́sọ́nà Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó dájú, tí kì í sì í yí pa dà, ẹ̀rí ọkàn wa lè má ṣèrànlọ́wọ́ kankan fún wa. (Sm. 119:105) Ó bani nínú jẹ́ pé nínú ayé yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé ohun tó bá ń wù wọ́n lọ́kàn wọn ṣáá ló máa ń jẹ wọ́n lógún jù lọ, wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Ka Éfésù 4:17-19.) Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi máa ń ṣe àwọn nǹkan tó burú jáì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn.—1 Tím. 4:2.
9 Àwa gbọ́dọ̀ pinnu pé a ò ní fìwà jọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láé! Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìṣó ká sì jẹ́ kó máa kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa, kó bàa lè wúlò fún wa bó ṣe yẹ. A ní láti máa gbọ́ ohun tí ẹ̀rí ọkàn wa tá a ti fi Bíbélì kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá ń sọ fún wa dípò ká jẹ́ kí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan máa darí wa. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ máa gbìyànjú láti máa wo ti ẹ̀rí ọkàn àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ọ̀wọ́n nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Ká máa sa gbogbo ipá wa láti má ṣe mú wọn kọsẹ̀, ká máa rántí pé ẹ̀rí ọkàn àwọn ará wa lè má fàyè gba àwọn nǹkan tí ẹ̀rí ọkàn tiwa fàyè gbà.—1 Kọ́r. 8:12; 2 Kọ́r. 4:2; 1 Pét. 3:16.
10. Àwọn nǹkan mẹ́ta wo la máa gbé yẹ̀ wò nípa ìgbésí ayé wa?
10 Ẹ jẹ́ ká wá ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà mẹ́ta nínú ìgbésí ayé wa tó ti yẹ ká máa ṣègbọràn láti lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀nà tá a máa gbé yẹ̀ wò yìí, ó ní ipa tí ẹ̀rí ọkàn wa máa ń kó. Àmọ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa tó lè máa fún wa ní ìtọ́sọ́nà tó bójú mu láwọn ọ̀nà yẹn, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ rí i dájú pé a fi ìlànà Bíbélì tọ́ ọ sọ́nà. Àwọn ọ̀nà mẹ́ta tá à ń gbà ṣègbọràn sí Jèhófà láti lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ rèé: (1) À ń nífẹ̀ẹ́ àwọn tí Jèhófà fẹ́ràn; (2) à ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ; (3) à ń sapá láti wà ní mímọ́ lójú Ọlọ́run.
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Tí Jèhófà Fẹ́ràn
11. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn tí Jèhófà fẹ́ràn?
11 Kókó àkọ́kọ́ ni pé a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn tí Jèhófà fẹ́ràn. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, ńṣe làwa èèyàn dà bíi tìmùtìmù àti kànrìnkàn tí wọ́n máa ń fa omi mu. A máa ń fẹ́ láti máa ṣe bíi tàwọn tá a jọ wà pa pọ̀. Ẹlẹ́dàá wa mọ̀ dáadáa pé bíbá àwọn èèyàn aláìpé dọ́rẹ̀ẹ́ lè pani ó sì lè lani. Ìdí nìyẹn tó fi fún wa nímọ̀ràn ọlọgbọ́n yìí pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20; 1 Kọ́r. 15:33) Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó fẹ́ “rí láburú.” Ohun tó wu olúkúlùkù wa ni pé ká “gbọ́n.” Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà kì í ṣe ẹni tá a lè kọ́ lọ́gbọ́n kó bàa lè gbọ́n sí i, kì í sì í ṣe ẹni tẹ́nì kan lè kọ́ ní ìkọ́kúkọ̀ọ́. Síbẹ̀, ó fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa nípa irú ẹni tó yẹ ká máa bá rìn. Òun fúnra rẹ̀ yan àwọn èèyàn aláìpé lọ́rẹ̀ẹ́. Àmọ́ irú àwọn wo ló yàn lọ́rẹ̀ẹ́?
12. Irú àwọn ẹni wo ni Jèhófà máa ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́?
12 Jèhófà pe Ábúráhámù baba-ńlá àwọn Júù ní “ọ̀rẹ́ mi.” (Aísá. 41:8) Ọkùnrin yìí jẹ́ àpẹẹrẹ tó ta yọ ní ti ìṣòtítọ́, òdodo àti ìgbọràn, ẹni tó nígbàgbọ́ gidi ni. (Ják. 2:21-23) Irú àwọn tí Jèhófà máa ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́ nìyẹn. Títí dòní ló ṣì ń yan irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́. Bó bá jẹ́ pé irú àwọn tí Jèhófà ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́ nìyẹn, ṣé kò wá ṣe pàtàkì pé káwa náà wá ẹni rere yàn lọ́rẹ̀ẹ́, ká máa bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn ká bàa lè gbọ́n?
13. Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí wàá fi lè yan ẹni tó yẹ lọ́rẹ̀ẹ́?
13 Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí wàá fi lè yan ẹni tó yẹ lọ́rẹ̀ẹ́? Ohun kan tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé kó o ṣàyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì. Ìwọ ronú nípa irú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tó wà láàárín Rúùtù àti Náómì tó jẹ́ ìyá ọkọ rẹ̀, ti àárín Dáfídì àti Jónátánì, pẹ̀lú ti àárín Tímótì àti Pọ́ọ̀lù. (Rúùtù 1:16, 17; 1 Sám. 23:16-18; Fílí. 2:19-22) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló fà á táwọn tá a dárúkọ yìí fi jẹ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn, ìdí tó ṣe pàtàkì jù ni pé olúkúlùkù wọn ní ojúlówó ìfẹ́ fún Jèhófà. Ṣó o lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n fẹ́ràn Jèhófà bíi tìẹ? Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé wàá rí ọ̀pọ̀ irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú ìjọ Ọlọ́run. Irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ò ní jẹ́ kó o rí láburú ní ti pé wọn ò ní jẹ́ kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà bà jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà, láti máa mú àjọṣe ìwọ pẹ̀lú rẹ̀ sunwọ̀n sí i, kó o sì máa fúnrúgbìn sí ipa tẹ̀mí. (Ka Gálátíà 6:7, 8.) Irú wọn ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.
Bọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ
14. Àwọn nǹkan wo ló máa ń mú kó ṣòro fún wa lọ́pọ̀ ìgbà láti bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ?
14 Ọ̀nà kejì tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni pé ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ. Kí ló máa ń mú kó ṣòro fún wa láwọn ìgbà míì láti bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ? Ohun kan ni pé aláìpé làwọn èèyàn tó wà nípò àṣẹ. Yàtọ̀ síyẹn, aláìpé làwa fúnra wa. Ìfẹ́ àbínibí láti ṣàìgbọràn máa ń wá sí wa lọ́kàn ni ṣáá.
15, 16. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn tí Jèhófà gbé àṣẹ lé lọ́wọ́ pé kí wọ́n máa darí àwọn èèyàn òun? (b) Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ látinú ojú tí Jèhófà fi wo ìwà ọ̀tẹ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì hù sí Mósè?
15 Nítorí ìdí èyí, ìbéèrè yìí lè máa wá sí ọ lọ́kàn pé, ‘Bó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ló ṣòro tó láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ, kí nìdí tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún wọn?’ Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí tan mọ́ ọ̀ràn ẹni tó jẹ́ ọba aláṣẹ. Ta lo gbà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, tó o fẹ́ kó máa ṣàkóso rẹ? Bá a bá gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ tiwa, a gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ̀. Bá ò bá bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ̀, ṣé a lè sọ lóòótọ́ pé òun ni Alákòóso wa? Síwájú sí i, àwọn èèyàn aláìpé ni Jèhófà sábà máa ń gbé àṣẹ lé lọ́wọ́ pé kí wọ́n máa darí àwọn èèyàn òun. Bá a bá ń ṣọ̀tẹ̀ sáwọn èèyàn tí Jèhófà ń lò wọ̀nyí, ojú wo ló máa fi wo ohun tá a ṣe?—Ka 1 Tẹsalóníkà 5:12, 13.
16 Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kùn tí wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí Mósè, ojú tí Jèhófà fi wo ọ̀ràn náà ni pé òun ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí. (Núm. 14:26, 27) Ọlọ́run ò tíì yí padà. Bá a bá lọ ṣọ̀tẹ̀ pẹ́nrẹ́n sáwọn tí Jèhófà fi sípò láti máa darí wa, Jèhófà fúnra rẹ̀ là ń ṣọ̀tẹ̀ sí!
17. Ìwà wo ló yẹ ká máa hù sáwọn tó wà nípò àṣẹ nínú ìjọ?
17 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká rí ìwà tó yẹ ká máa hù sáwọn tó wà nípò àṣẹ nínú ìjọ Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.” (Héb. 13:17) Lóòótọ́, ó máa gba pé ká sapá gidigidi ká tó lè jẹ́ onígbọràn àti onítẹríba. Àmọ́ má gbàgbé pé nítorí ká bàa lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run la ṣe ń sa gbogbo ipá wa. Ṣé kò wá yẹ ká túbọ̀ rúnpá rúnsẹ̀ sí i?
Máa Wà ní Mímọ́ Lójú Jèhófà
18. Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ ká máa wà ní mímọ́?
18 Ọ̀nà kẹta tá à ń gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni pé ká sapá láti máa wà ní mímọ́ lójú rẹ̀. Àwọn òbí sábà máa ń ṣiṣẹ́ kára káwọn ọmọ wọn lè wà ní mímọ́ tónítóní. Kí nìdí ẹ̀? Ìdí kan ni pé, ó ṣe pàtàkì kí ọmọ náà wà ní mímọ́ tónítóní kò má bàa kó àrùn kí ara rẹ̀ sì le. Síwájú sí i, ọmọ tó bá mọ́ tónítóní máa ń dùn-ún rí mọ́ni, ìrísí rẹ̀ á sì fi hàn pé àwọn òbí rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ wọ́n sì ń bójú tó o. Àwọn ohun tó fà á tí Jèhófà fi ń fẹ́ ká máa wà ní mímọ́ náà nìyẹn. Ó mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa wà ní mímọ́, torí ìmọ́tótó ń borí àrùn mọ́lẹ̀. Ó sì tún mọ̀ pé bá a bá ń wà ní mímọ́, ó máa buyì kún òun tóun jẹ́ Bàbá wa ọ̀run. Ìyẹn sì ṣe pàtàkì púpọ̀ torí pé báwọn èèyàn bá ṣe ń kíyè sí i pé a yàtọ̀ gedegbe sáwọn èèyàn inú ayé tó ti bà jẹ́ bàlùmọ̀ yìí, wọ́n lè fẹ́ wá máa sin Ọlọ́run tá à ń sìn.
19. Báwo la ṣe mọ̀ pé ìmọ́tótó nípa tara ṣe pàtàkì?
19 Àwọn apá ibo ló ti yẹ ká wà ní mímọ́? Ká sòótọ́, kò yọ ibì kankan sílẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa. Jèhófà sọ ọ́ kedere fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì tó jẹ́ èèyàn rẹ̀ pé ìmọ́tótó nípa tara ṣe pàtàkì fún wọn. (Léf. 15:31) Ìlànà nípa àwọn ọ̀ràn bíi bíbo ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́lẹ̀, fífọ àwọn nǹkan èlò inú ilé àti fífọ ọwọ́, ẹsẹ̀ àti aṣọ wà nínú Òfin Mósè. (Ẹ́kís. 30:17-21; Léf. 11:32; Núm. 19:17-20; Diu. 23:13, 14) Èyí ń rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé Jèhófà Ọlọ́run wọn jẹ́ mímọ́, ìyẹn ni pé ó mọ́ tónítóní, kò sì lábààwọ́n. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mímọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú.—Ka Léfítíkù 11:44, 45.
20. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà wà ní mímọ́?
20 Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ nínú lóde. Ká má máa fàyè gba èròkerò. Ká máa rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ àwọn ìlànà Jèhófà lórí ìwà mímọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣekúṣe ti jàrábà àwọn èèyàn ayé yìí. Èyí tó ṣe pàtàkì jù níbẹ̀ ni pé, à ń fẹ́ kí ìjọsìn wa máa wà ní mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà, a ò fàyè gba àbààwọ́n kankan látinú ìsìn èké. A ò gbàgbé ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run mí sí tó wà nínú ìwé Aísáyà 52:11, pé: “Ẹ yí padà, ẹ yí padà, ẹ jáde kúrò níbẹ̀, ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan; ẹ jáde kúrò ní àárín rẹ̀, ẹ wẹ ara yín mọ́.” Ọ̀nà tá a lè gbà wà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí lákòókò tá a wà yìí ni pé ká má fọwọ́ kan ohunkóhun tí Bàbá wa ọ̀run bá kà sí aláìmọ́, ìyẹn gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ ìsìn èké. Ìdí nìyẹn tí a kì í fi í lọ́wọ́ sáwọn ayẹyẹ ìsìn tàbí àwọn àjọ̀dún tó gbajúmọ̀ táwọn èèyàn ayé máa ń ṣe. Lóòótọ́, kò rọrùn láti máa wà ní mímọ́, àmọ́ ohun táwa èèyàn Jèhófà ń sakun láti ṣe nìyẹn torí pé ó máa jẹ́ ká lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.
21. Báwo la ṣe lè rí i dájú pé a ò kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run?
21 Títí ayé ni Jèhófà fẹ́ ká dúró nínú ìfẹ́ òun. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù wa ló gbọ́dọ̀ rí i dájú pé gbogbo ipá òun lòun ń sà láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. A lè ṣe èyí nípa títẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ká sì máa fi ìfẹ́ wa sí Jèhófà hàn nípa ṣíṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ kó dá wa lójú pé kò sí ohunkóhun tó “lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.”—Róòmù 8:38, 39.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo ni ẹ̀rí ọkàn wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run?
• Kí nìdí tá a fi ní láti nífẹ̀ẹ́ àwọn tí Jèhófà fẹ́ràn?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ?
• Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé káwa èèyàn Ọlọ́run máa wà ní mímọ́?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
ÌWÉ KAN TÓ JẸ́ KÁ MỌ BÁ Ó ṢE MÁA HÙWÀ RERE
Ní àpéjọ àgbègbè ọdún 2008 sí 2009, a mú ìwé tuntun kan tó ní ojú ewé igba ó lé mẹ́rìnlélógún [224] jáde, orúkọ ìwé náà ni ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run.’ Kí ni ìwé tuntun yìí wà fún? A ṣe é láti ran àwa Kristẹni lọ́wọ́ láti lè mọ àwọn ìlànà Jèhófà ká sì lè fẹ́ràn àwọn ìlànà náà. Àwọn ìwà tó yẹ kí Kristẹni máa hù ló pilẹ̀ jíròrò. Bó o bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run,’ ó máa mú kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé títẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nínú ìgbésí ayé wa ni ọ̀nà tó dára jù lọ téèyàn lè máa gbà lo ayé rẹ̀ nísinsìnyí, ìyẹn ló sì máa sinni lọ sí ìyè ayérayé lọ́jọ́ iwájú.
Yàtọ̀ síyẹn, a ṣe ìwé yìí kó bàa lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé ṣíṣègbọràn sí Jèhófà kì í ṣe ohun tó nira. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ọ̀nà tá a lè gbà fi han Jèhófà bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó. Torí náà, ìwé yìí máa mú ká bi ara wa pé, ‘Kí nìdí tí mo fi ń ṣègbọràn sí Jèhófà?’
Àwọn kan máa ń ṣàṣìṣe burúkú kan, ní ti pé wọ́n kúrò nínú ìfẹ́ Jèhófà. Lọ́pọ̀ ìgbà ohun tó fà á kì í ṣe pé wọn ò lóye àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì, bí kò ṣe nítorí pé wọ́n hùwà tó burú jáì. Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó nígbà náà pé ká túbọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ àti ìmọrírì tá a ní fáwọn òfin Jèhófà àtàwọn ìlànà tó fi ń tọ́ wa sọ́nà lójoojúmọ́ máa pọ̀ sí i! Ó dá wa lójú pé ìwé tuntun yìí máa ran àwa àgùntàn Jèhófà kárí ayé lọ́wọ́ láti lè máa dúró lórí ohun tó tọ́, ká sì lè fi Sátánì hàn gẹ́gẹ́ bí onírọ́, lékè gbogbo rẹ̀, ká lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run!—Júúdà 21.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
“Bí ẹ bá pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ óò dúró nínú ìfẹ́ mi, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àwọn àṣẹ Baba mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀”