Àwọn Kristẹni Tí Kì í Dá Sí Tọ̀túntòsì Láwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn
“Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.”—JÒHÁNÙ 17:16.
1, 2. Kí ni Jésù sọ nípa àjọṣe tó wà láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti ayé, ìbéèrè wo làwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí gbé dìde?
JÉSÙ gbàdúrà gígùn létígbọ̀ọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ tó kẹ́yìn ìgbé ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn pípé. Nínú àdúrà yìí, ó sọ ohun kan tó ṣàpèjúwe ìgbésí ayé gbogbo Kristẹni tòótọ́. Ohun tó sọ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni pé: “Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn, ṣùgbọ́n ayé ti kórìíra wọn, nítorí pé wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé. Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé, bí kò ṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà. Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.”—Jòhánù 17:14-16.
2 Ẹ̀ẹ̀méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù sọ ọ́, pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun kì í ṣe apá kan ayé. Síwájú sí i, yíyà tí wọ́n á ya ara wọn sọ́tọ̀ yìí ò ní ṣàì fa họ́ùhọ́ù, ìyẹn ni pé ayé á kórìíra wọn. Síbẹ̀, kò yẹ kí èyí kó ìpayà bá àwọn Kristẹni nítorí pé Jèhófà á máa ṣọ́ wọn. (Òwe 18:10; Mátíù 24:9, 13) Pẹ̀lú ohun tí Jésù sọ yìí, a lè wá béèrè pé: ‘Èé ṣe táwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fi í ṣe apá kan ayé? Kí ló túmọ̀ sí láti má ṣe jẹ́ apá kan ayé? Ojú wo làwọn Kristẹni á fi wo ayé nígbà tí ayé bá kórìíra wọn? Irú ojú wo ni wọ́n tiẹ̀ fi ń wo àwọn ìjọba ayé pàápàá?’ Ìdáhùn tó bá Ìwé Mímọ́ mu sáwọn ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì nítorí pé kò sẹ́ni tọ́rọ̀ yìí ò kàn.
“A Pilẹ̀ṣẹ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run”
3. (a) Kí nìdí tí a kì í fi í ṣe apá kan ayé? (b) Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé gbogbo ayé wà “lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà”?
3 Ọ̀kan lára ìdí tí a kì í fi í ṣe apá kan ayé ni nítorí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “A mọ̀ pé a pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Òtítọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ tí Jòhánù sọ nípa ayé. Ogun, ìwà ọ̀daràn, ìwà òǹrorò, ìninilára, ìwà àìṣòótọ́ àti ìwà ìṣekúṣe tó ń ràn bí iná ọyẹ́ nínú ayé lónìí fi hàn pé iṣẹ́ ọwọ́ Sátánì ni, kì í ṣe ti Ọlọ́run. (Jòhánù 12:31; 2 Kọ́ríńtì 4:4; Éfésù 6:12) Bí ẹnì kan bá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò ní lọ́wọ́ nínú àwọn ìwà búburú wọ̀nyẹn kò sì ní fojú rere wò wọ́n, èyí lá fi dẹni tí kì í ṣe apá kan ayé.—Róòmù 12:2; 13:12-14; 1 Kọ́ríńtì 6:9-11; 1 Jòhánù 3:10-12.
4. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé ti Jèhófà la jẹ́?
4 Jòhánù sọ pé àwọn Kristẹni “pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,” àmọ́ ní ti ayé, tiwọn kò rí bẹ́ẹ̀. Gbogbo àwọn tó bá ti ya ara wọn sí mímọ́ sí Jèhófà ti di tiẹ̀ nìyẹn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí a bá wà láàyè, a wà láàyè fún Jèhófà, bí a bá sì kú, a kú fún Jèhófà. Nítorí náà, bí a bá wà láàyè àti bí a bá kú, a jẹ́ ti Jèhófà.” (Róòmù 14:8; Sáàmù 116:15) Jíjẹ́ tá a jẹ́ ti Jèhófà yìí ń mú ká máa fún un ní ìjọsìn tá a yà sọ́tọ̀ gedegbe. (Ẹ́kísódù 20:4-6) Ìdí rèé tí Kristẹni tòótọ́ ò fi ní fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ jin ìlépa ohun ayé. Lóòótọ́ ni á máa fi ọ̀wọ̀ fún àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè o, àmọ́ kò ní jọ́sìn wọn yálà nípa ìṣe rẹ̀ tàbí lọ́kàn rẹ̀. Kò jẹ́ jọ́sìn àwọn ìlúmọ̀ọ́ká eléré ìdárayá tàbí àwọn òrìṣà òde òní mìíràn. Ó mọ̀ pé lóòótọ́ làwọn èèyàn ní òmìnira láti ṣe ohunkóhun tó bá wù wọ́n, àmọ́ Ẹlẹ́dàá nìkan lá máa jọ́sìn. (Mátíù 4:10; Ìṣípayá 19:10) Ìdí mìíràn tún rèé tí kì í fi í ṣe apá kan ayé.
“Ìjọba Mi Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”
5, 6. Báwo ni fífi ara wa sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ṣe yà wá sọ́tọ̀ nínú ayé?
5 Ọmọ ẹ̀yìn Kristi Jésù làwọn Kristẹni, wọ́n sì jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, èyí tó tún jẹ́ ìdí mìíràn tí wọn kì í fi í ṣe apá kan ayé. Nígbà tí Jésù ń jẹ́jọ́ níwájú Pọ́ńtù Pílátù, ó sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà kí a má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.” (Jòhánù 18:36) Ìjọba yìí la ó lò láti fi ya orúkọ Jèhófà sí mímọ́, tá a ó fi dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre, tá a ó fi mú kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀run. (Mátíù 6:9, 10) Ní gbogbo àkókò tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ńṣe ló ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó sì sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ò ní ṣíwọ́ iṣẹ́ yìí títí ètò àwọn nǹkan á fi wá sópin. (Mátíù 4:23; 24:14) Ní 1914, àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Ìṣípayá 11:15 nímùúṣẹ pé: “Ìjọba ayé di ìjọba Olúwa wa àti ti Kristi rẹ̀, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé àti láéláé.” Láìpẹ́, Ìjọba ọ̀run yìí nìkan ṣoṣo lá máa ṣàkóso ẹ̀dá èèyàn. (Dáníẹ́lì 2:44) Nígbà tó bá yá, àwọn aláṣẹ ayé pàápàá á gbà á lọ́gàá tipátipá.—Sáàmù 2:6-12.
6 Gbogbo ìwọ̀nyí fi yéni pé àwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù pé kí wọ́n ‘máa bá a nìṣó ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mátíù 6:33) Èyí kò sọ wọ́n dẹni tó ń dalẹ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé, ńṣe ló kàn yà wọ́n sọ́tọ̀ nípa tẹ̀mí kúrò nínú ayé. Olórí iṣẹ́ àwọn Kristẹni lónìí ni “jíjẹ́rìí kúnnákúnná nípa ìjọba Ọlọ́run,” gẹ́gẹ́ bíi tàwọn ti ọ̀rúndún kìíní. (Ìṣe 28:23) Kò sí ìjọba ẹ̀dá èèyàn tó lẹ́tọ̀ọ́ láti gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fúnni yìí.
7. Èé ṣe táwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fi í dá sí tọ̀túntòsì, ọ̀nà wo sì ni wọ́n ti gbà fi èyí hàn?
7 Bí a ti jẹ́ ti Jèhófà tí a sì tún jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù àti ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò lọ́wọ́ sí èyíkéyìí nínú ogun abẹ́lé àti ti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè táráyé ń bá ara wọn jà láti ọ̀rúndún ogún títí di ti ìkọkànlélógún yìí. A kì í gbè sápá kan nínú àwọn ogun yìí, a kì í sì í kọjú ohun ìjà kankan sẹ́nikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ ni a kì í torí ìdí èyíkéyìí máa bá àwọn èèyàn ayé polongo kiri. Ìgbàgbọ́ wa lágbára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ lójú àtakò lílekoko débi pé a ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tá a sọ fáwọn aláṣẹ nígbà ìjọba Násì ti Jámánì lọ́dún 1934 pé: “Kò sóhun tó kàn wá kan ọ̀ràn ìṣèlú, ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ Kristi Ọba rẹ̀ la fi gbogbo ara wa fún. A kì í ṣe ẹnikẹ́ni níbi. Ayọ̀ wa ló jẹ́ pé ká máa gbé lálàáfíà ká sì máa ṣe rere sí gbogbo èèyàn bá a bá ṣe láǹfààní láti ṣe é tó.”
Ikọ̀ àti Aṣojú fún Kristi
8, 9. Ọ̀nà wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà jẹ́ ikọ̀ àti aṣojú lónìí, báwo sì lèyí ṣe kan àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè?
8 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe ara rẹ̀ àtàwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tá a fòróró yàn ní “ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi, bí ẹni pé Ọlọ́run ń pàrọwà nípasẹ̀ wa.” (2 Kọ́ríńtì 5:20; Éfésù 6:20) Láti 1914 wá la ti lè fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ pé lóòótọ́ làwọn Kristẹni tá a fi òróró yàn jẹ́ ikọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí wọ́n jẹ́ “ọmọ” fún. (Mátíù 13:38; Fílípì 3:20; Ìṣípayá 5:9, 10) Síwájú sí i, Jèhófà ti tún mú “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn,” tí í ṣe àwọn Kristẹni tó ń retí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé, jáde látinú àwọn orílẹ̀-èdè, láti gbárùkù ti àwọn ọmọ tá a fòróró yàn nínú iṣẹ́ ikọ̀ tí wọ́n ń ṣe. (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16) Àwọn “àgùntàn mìíràn” yìí la lè pè ní “aṣojú” Ìjọba Ọlọ́run.
9 Ẹni tó jẹ́ ikọ̀ àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ kì í tojú bọ ọ̀ràn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ wọn. Lọ́nà kan náà, àwọn Kristẹni kì í dá sọ́ràn ìṣèlú àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé. Wọn kì í gbè síhà kankan nínú ọ̀ràn orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, ẹgbẹ́ tàbí àwùjọ èyíkéyìí. (Ìṣe 10:34, 35) Dípò èyí, ńṣe ni wọ́n ń “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.” (Gálátíà 6:10) Àìdásí-tọ̀túntòsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lè lẹ́nu àtisọ pé gbígbè tí wọ́n ń gbé síhà kan nínú ìran kan, orílẹ̀-èdè kan tàbí ẹ̀yà kan, ni ò jẹ́ kí òun gbọ́ ìhìn rere wọn.
Ìfẹ́ La Fi Ń Dá Wọn Mọ̀
10. Báwo ni ìfẹ́ ṣe ṣe pàtàkì tó sí Kristẹni kan?
10 Láfikún sáwọn ohun tá a ti sọ yìí, àwọn Kristẹni kì í dá sáwọn ohun tó ń lọ nínú ayé nítorí àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn. Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Ìfẹ́ ará ṣe kókó téèyàn bá fẹ́ jẹ́ Kristẹni. (1 Jòhánù 3:14) Èyí tó tún tan mọ́ àjọṣe tí Kristẹni kan ní pẹ̀lú Jèhófà, Jésù àti ìdílé rẹ̀ ni àjọṣe pẹ́kípẹ́kí tí Kristẹni kan ní pẹ̀lú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Ìfẹ́ rẹ̀ ò mọ sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ìjọ nìkan. Ó nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará [rẹ̀] nínú ayé.”—1 Pétérù 5:9.
11. Báwo ni ìfẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní fún ara wọn ṣe nípa lórí ìwà wọn?
11 Lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi ìfẹ́ ará tí wọ́n ní hàn nípa mímú ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 2:4 ṣẹ pé: “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” Minimini ni àárín àwọn Kristẹni tòótọ́ àti Ọlọ́run tòrò nítorí pé Jèhófà ló ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Aísáyà 54:13) Ohun burúkú gbáà ló máa jẹ́ fún wọn láti kọjú nǹkan ìjà sí Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn tàbí sí ẹnikẹ́ni ní orílẹ̀-èdè mìíràn, nítorí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn ará wọn. Àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tí wọ́n ní jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn wọn, ó sì fi hàn pé lóòótọ́ ni wọ́n ní ẹ̀mí Ọlọ́run. (Sáàmù 133:1; Míkà 2:12; Mátíù 22:37-39; Kólósè 3:14) Wọ́n ń “wá ọ̀nà láti rí àlàáfíà” kí wọ́n “sì máa lépa rẹ̀” nítorí wọ́n mọ̀ pé “ojú Jèhófà ń bẹ lọ́dọ̀ àwọn olódodo.”—Sáàmù 34:14, 15.
Ojú Táwọn Kristẹni Fi Ń Wo Ayé
12. Ìwà tí Jèhófà máa ń hù sáwọn èèyàn ayé wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fara wé, báwo sì ni wọ́n ṣe ń ṣe èyí?
12 Jèhófà ti sọ pé òun á dá ayé yìí lẹ́jọ́, àmọ́ kò tíì ṣèdájọ́ olúkúlùkù èèyàn tó wà nínú ayé. Jésù ló máa lò láti ṣe ìyẹn tó bá tó àsìkò lójú Rẹ̀. (Sáàmù 67:3, 4; Mátíù 25:31-46; 2 Pétérù 3:10) Ní báyìí ná, Jèhófà ń fi ìfẹ́ ńláǹlà hàn sí ẹ̀dá èèyàn. Ó tiẹ̀ fún wọn ní Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo kí wọ́n lè láǹfààní àtiwà láàyè títí láé. (Jòhánù 3:16) Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, à ń ṣàfarawé ìfẹ́ Ọlọ́run nípa sísọ fáwọn mìíràn nípa ètò tí Ọlọ́run ti ṣe fún ìgbàlà, kódà bí àwọn èèyàn ò tiẹ̀ ka gbogbo akitiyan wa sí pàápàá.
13. Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn aláṣẹ ayé?
13 Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn aláṣẹ ayé? Pọ́ọ̀lù dáhùn ìbéèrè yẹn nígbà tó kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga, nítorí kò sí ọlá àṣẹ kankan bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; àwọn ọlá àṣẹ tí ó wà ni a gbé dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Róòmù 13:1, 2) Àwọn ẹ̀dá èèyàn wà ní ipò àṣẹ ‘tó láàlà’ (ọ̀kan lè ju ìkejì lọ o, àmọ́ wọn ò lè tó Jèhófà láé) nítorí pé Olódùmarè gbà wọ́n láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹnì kan tó jẹ́ Kristẹni á máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ nítorí pé èyí jẹ́ apá kan ìgbọràn rẹ̀ sí Jèhófà. Ṣùgbọ́n kí la máa wá ṣe o tó bá ṣẹlẹ̀ pé ohun náà gan-an tí Ọlọ́run ní ká fóun ni ìjọba èèyàn náà ń béèrè fún?
Òfin Ọlọ́run àti Ti Késárì
14, 15. (a) Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe ṣe ọ̀ràn ṣíṣègbọràn tí ọ̀kan ò fi pa èkejì lára? (b) Kí làwọn Hébérù mẹ́ta ṣe nígbà tí ọ̀ràn ṣíṣègbọràn dójú ọ̀gbagadè, tí ọ̀kan fẹ́ pa ìkejì lára?
14 Dáníẹ́lì àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́ta fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ ní ti ọ̀ràn títẹríba fún ìjọba ẹ̀dá èèyàn láìjẹ́ kó pa ìtẹríba fún àṣẹ Ọlọ́run lára. Nígbà táwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́rin yìí wà nígbèkùn ní Bábílónì, wọ́n ṣègbọràn sófin ilẹ̀ náà, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi yàn wọ́n láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ àrà ọ̀tọ̀. Nígbà tí Dáníẹ́lì rí i pé ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà lè mú káwọn ṣe ohun tó lòdì sí Òfin Jèhófà, ó yáa ṣàlàyé fún ọ̀gá tó wà nídìí ètò ọ̀hún. Èyí ló mú kí wọ́n ṣe àwọn ètò àkànṣe kan tí yóò mú káwọn Hébérù mẹ́rin yìí má ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn wọn. (Dáníẹ́lì 1:8-17) Àpẹẹrẹ Dáníẹ́lì làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé, tí wọ́n fi máa ń fọgbọ́n ṣàlàyé bí ọ̀ràn wọn ṣe jẹ́ fún àwọn aláṣẹ kí ìṣòro má bàa bẹ́ sílẹ̀.
15 Àmọ́ nígbà tó yá, ọ̀ràn ìtẹríba wá dójú ọ̀gbagadè, ọ̀kan fẹ́ pa èkejì lára. Ọba Bábílónì gbé ère fàkìàfakia kan kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà, ó sì pe àwọn lóókọlóókọ, tó fi dórí àwọn olùṣàbójútó àgbègbè abẹ́ àṣẹ rẹ̀, pé kí wọ́n wá síbi ayẹyẹ tóun fẹ́ fi ṣí ère náà. Lásìkò yìí rèé, àwọn ọ̀rẹ́ Dáníẹ́lì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti di olùṣàbójútó láwọn àgbègbè tó wà lábẹ́ àṣẹ Bábílónì, ìpè yìí sì kàn wọ́n. Nígbà tí ayẹyẹ náà débì kan, ó di pé kí gbogbo àwọn tó pé jọ forí balẹ̀ níwájú ère náà. Àmọ́ àwọn Hébérù yìí mọ̀ pé èyí lòdì sí òfin Ọlọ́run. (Diutarónómì 5:8-10) Ni wọ́n bá wà lórí ìdúró nígbà tí gbogbo èèyàn yòókù forí balẹ̀. Ikú oró ni wọn ì bá kú fún àìgbọràn tí wọ́n ṣe sófin ọba yẹn, àmọ́ Ọlọ́run gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́nà àrà. Wọ́n gbà láti kú ju pé kí wọ́n ṣàìgbọràn sí Jèhófà.—Dáníẹ́lì 2:49–3:29.
16, 17. Kí làwọn àpọ́sítélì sọ nígbà tí wọ́n pàṣẹ pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, èé sì ti ṣe?
16 Ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n pe àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi wá síwájú àwọn aṣáájú tí wọ́n jẹ́ Júù ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù lórúkọ Jésù mọ́. Kí ni wọ́n wá ṣe? Jésù ti sọ pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn ní gbogbo orílẹ̀-èdè, èyí sì kan Jùdíà pẹ̀lú. Ó tún ti sọ fún wọn pé wọ́n á ṣe ẹlẹ́rìí òun ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo ayé. (Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 1:8) Àwọn àpọ́sítélì mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ káwọn ṣe gan-an ni àṣẹ tí Jésù pa yìí. (Jòhánù 5:30; 8:28) Ìdí rèé tí wọ́n fi sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 4:19, 20; 5:29.
17 Kì í ṣe pé àwọn àpọ́sítélì náà ń ṣọ̀tẹ̀. (Òwe 24:21) Àmọ́ báwọn aláṣẹ èèyàn ṣe sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ohun tí wọ́n kàn sọ ni pé, ‘Ọlọ́run la gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí, kì í ṣe èèyàn.’ Jésù sọ pé ká “san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Máàkù 12:17) Tá a bá ṣàìgbọràn sí àṣẹ tí Ọlọ́run pa nítorí pé ẹ̀dá èèyàn sọ pé ká ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ohun tó jẹ́ ti Ọlọ́run là ń fún èèyàn yẹn o. A ò sì ní jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. A óò fún Késárì ní gbogbo ohun tó bá tọ́ sí i o, àmọ́ Jèhófà la gbà pé ó jẹ́ aláṣẹ tó ga jù lọ. Òun ni Aláṣẹ láyé àti lọ́run, òun ni Ẹlẹ́dàá, òun gan-an ni Orísun àṣẹ.—Ìṣípayá 4:11.
Àá Dúró Gbọn-in
18, 19. Àpẹẹrẹ àwòkọ́ṣe wo ni ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ti fi lélẹ̀ nípa kéèyàn dúró gbọn-in, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn?
18 Ní bá a ṣe ń wí yìí, ọ̀pọ̀ ìjọba ló ti mọ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sí tọ̀túntòsì, inú wa sì dùn nítorí èyí. Àmọ́ láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn Ẹlẹ́rìí dojú kọ inúnibíni tó gbóná janjan. Ní gbogbo ọ̀rúndún ogún títí di àkókò tá a wà yìí, àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa kan ti ṣe wàhálà bí ẹní máa kú lẹ́nu bí wọ́n ṣe ń ja “ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́” nípa tẹ̀mí.—1 Tímótì 6:12.
19 Báwo la ṣe lè dúró gbọn-in bíi tiwọn? Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ fi í sọ́kàn pé wọ́n á ṣenúnibíni sí wa. Tó bá sì wá dé, a ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù kò sì yẹ kó yà wá lẹ́nu pàápàá. Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tímótì 3:12; 1 Pétérù 4:12) Ẹ gbọ́ ná, ọ̀nà dà tí wọn ò fi ní ṣenúnibíni sí wa nínú ayé tí Sátánì ń ṣàkóso? (Ìṣípayá 12:17) Níwọ̀n ìgbà tá a bá ti jẹ́ olóòótọ́, kò sí ni, àwọn kan á wà tí ọ̀ràn ọ̀hún á ‘rú lójú tí wọ́n á sì máa sọ̀rọ̀ wa tèébútèébú.’—1 Pétérù 4:4.
20. Òtítọ́ tó ń fúnni lókun wo la rán wa létí rẹ̀?
20 Ìkejì, ó dá wa lójú dáadáa pé Jèhófà àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ á tì wá lẹ́yìn. Èlíṣà ti sọ ọ́ láyé ọjọ́un pé, “àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.” (2 Ọba 6:16; Sáàmù 34:7) Ó lè jẹ́ pé tìtorí ohun dáadáa kan ni Jèhófà ṣì ṣe fàyè gba wàhálà táwọn alátakò ń kó bá wa fúngbà díẹ̀ sí i. Àmọ́, á máa fún wa lókun tá a nílò láti fara dà á. (Aísáyà 41:9, 10) Wọ́n tiẹ̀ ti pa àwọn mìíràn, àmọ́ èyí ò kó wa láyà jẹ. Jésù sọ pé: “Ẹ má sì bẹ̀rù àwọn tí ń pa ara ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ọkàn; ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lè pa àti ọkàn àti ara run nínú Gẹ̀hẹ́nà.” (Mátíù 10:16-23, 28) “Olùgbé fún ìgbà díẹ̀” la jẹ́ nínú ètò àwọn nǹkan yìí. À ń lo àkókò wa láti “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí,” ìyẹn ìwàláàyè títí láé nínú ayé tuntun Ọlọ́run. (1 Pétérù 2:11; 1 Tímótì 6:19) Bá a bá ṣáà ti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, kò sí ẹ̀dá èèyàn tó lè gba èrè yìí lọ́wọ́ wa rárá ni.
21. Kí ló yẹ ká máa fi sọ́kàn nígbà gbogbo?
21 Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká rántí àjọṣe ṣíṣeyebíye tá a ní pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ká máa fìgbà gbogbo dúpẹ́ fún ìbùkún tá a ní láti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi àti ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká fi gbogbo ọkàn wa nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, kí inú wa sì máa dùn sí ìfẹ́ táwọn náà ń fi hàn sí wa. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ onísáàmù náà pé: “Ní ìrètí nínú Jèhófà; jẹ́ onígboyà, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ jẹ́ alágbára. Bẹ́ẹ̀ ni, ní ìrètí nínú Jèhófà.” (Sáàmù 27:14; Aísáyà 54:17) Ìyẹn lá jẹ́ ká lè dúró gbọn-in bí àìmọye àwọn Kristẹni tó ti wà ṣáájú wa, ìrètí wa á dájú, a ó sì jẹ́ Kristẹni olóòótọ́ tí kì í dá sí tọ̀túntòsì, tí kì í sì í ṣe apá kan ayé.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Báwo ni àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ṣe yà wá sọ́tọ̀ nínú ayé?
• Bá a ṣe jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, báwo la ṣe lè ṣe é tá ò fi ní dá sí tọ̀túntòsì nínú ayé?
• Ọ̀nà wo ni ìfẹ́ tá a ní sáwọn ará wa ṣe lè mú ká máà dá sí tọ̀túntòsì, tá a ó sì jẹ́ ẹni tó yà sọ́tọ̀ nínú ayé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Báwo ni ìtẹríba wa fún Ìjọba Ọlọ́run ṣe kan àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn ayé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ẹ̀yà Hutu àti ẹ̀yà Tutsi ń fi tayọ̀tayọ̀ ṣíṣẹ́ pọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ẹ̀yà Júù kan àti ọmọ ilẹ̀ Lárúbáwá kan tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ará
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Kristẹni ará Serbia, Bosnia àti Croatia jọ wà lálàáfíà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Kí ló yẹ ká ṣe táwọn aláṣẹ bá pàṣẹ pé ká rú òfin Ọlọ́run?