Bí Gáyọ́sì Ṣe Ran Àwọn Ará Lọ́wọ́
GÁYỌ́SÌ àtàwọn Kristẹni míì ní ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro. Ńṣe làwọn kan nínú ìjọ ń tan ẹ̀kọ́ èké kálẹ̀, wọ́n ń ṣi àwọn ará lọ́nà, wọ́n sì ń dá ìyapa sílẹ̀ nínú ìjọ. (1 Jòh. 2:18, 19; 2 Jòh. 7) Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Dìótíréfè máa ń sọ “ọ̀rọ̀ burúkú” nípa àpọ́sítélì Jòhánù àtàwọn míì. Yàtọ̀ síyẹn, kì í tọ́jú àwọn Kristẹni tó ń rìnrìn-àjò, kì í sì í gbà wọ́n sílé rẹ̀. Bákan náà, kì í fẹ́ káwọn míì nínú ìjọ gba àwọn ará yẹn sílé. (3 Jòh. 9, 10) Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ nìyẹn lásìkò tí Jòhánù kọ lẹ́tà sí Gáyọ́sì. Nǹkan bí ọdún 98 Sànmánì Kristẹni ni àpọ́sítélì Jòhánù kọ lẹ́tà yìí, òun la mọ̀ sí “Ìwé Kẹta Jòhánù” nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì.
Láìka àwọn ìṣòro yìí sí, Gáyọ́sì fòótọ́ inú sin Jèhófà. Kí ló ṣe tó fi hàn pé ó jẹ́ olóòótọ́? Kí nìdí tó fi yẹ káwa náà ṣe bíi ti Gáyọ́sì? Báwo ni lẹ́tà tí Jòhánù kọ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀?
JÒHÁNÙ KỌ LẸ́TÀ SÍ Ọ̀RẸ́ RẸ̀ TÓ NÍFẸ̀Ẹ́
Ẹni tó kọ Jòhánù Kẹta pe ara rẹ̀ ní “àgbà ọkùnrin.” Èyí mú kí Gáyọ́sì ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n nípa tẹ̀mí mọ̀ pé àpọ́sítélì Jòhánù ni. Jòhánù pe Gáyọ́sì ní “olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́ ní tòótọ́.” Lẹ́yìn náà, Jòhánù tún gbàdúrà pé kí Gáyọ́sì ní ìlera tó dáa bó ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ ìwúrí tó ń gbéni ró ni Jòhánù sọ fún Gáyọ́sì.—3 Jòh. 1, 2, 4.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé alábòójútó ni Gáyọ́sì nínú ìjọ bó tiẹ̀ jẹ́ pé lẹ́tà náà kò sọ ní pàtó. Jòhánù gbóríyìn fún Gáyọ́sì torí pé ó máa ń ṣe àwọn ará lálejò, ó sì máa ń gbà wọ́n sílé rẹ̀ láìka pé àjèjì ni wọ́n. Èyí jẹ́ kí Jòhánù mọ̀ pé Gáyọ́sì ń fòótọ́ inú sin Jèhófà torí pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń lẹ́mìí aájò àlejò.—Jẹ́n. 18:1-8; 1 Tím. 3:2; 3 Jòh. 5.
Bí Jòhánù ṣe gbóríyìn fún Gáyọ́sì torí bó ṣe máa ń gba àwọn ará sílé fi hàn pé àwọn Kristẹni sábà máa ń rìnrìn-àjò látọ̀dọ̀ Jòhánù lọ sáwọn ìjọ tó wà káàkiri. Àwọn Kristẹni yìí máa ń sọ ohun tí wọ́n rí fún Jòhánù, ó sì lè jẹ́ pé àwọn ìròyìn tí wọ́n ń mú wá ló ń jẹ́ kí Jòhánù mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ìjọ.
Ó dájú pé ọ̀dọ̀ àwọn ará làwọn Kristẹni tó ń rìnrìn-àjò máa ń fẹ́ dé sí dípò ilé èrò. Ìdí sì ni pé oríṣiríṣi ìwàkiwà ló kún àwọn ilé èrò tó wà nígbà yẹn, títí kan ìṣekúṣe, wọn kì í sì í tọ́jú àwọn àlejò dáadáa. Torí náà ọ̀pọ̀ àwọn tó ń rìnrìn-àjò sábà máa ń dé sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ wọn, àwọn Kristẹni náà sì máa ń dé sọ́dọ̀ àwọn ará.
“TÌTORÍ ORÚKỌ RẸ̀ NI WỌ́N ṢE JÁDE LỌ”
Jòhánù tún sọ fún Gáyọ́sì pé kó túbọ̀ máa tọ́jú àwọn àlejò dáadáa nígbà tó sọ fún un pé kó “rán [àwọn arìnrìn-àjò] lọ ní ọ̀nà wọn lọ́nà tí ó yẹ Ọlọ́run.” Bí Jòhánù ṣe sọ fún un pé kó rán wọn lọ ní ọ̀nà wọn túmọ̀ sí pé kó pèsè ohun tí wọ́n máa nílò títí wọ́n á fi dé ibi tí wọ́n ń lọ. Ó ṣe kedere pé Gáyọ́sì ti máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn ará, Jòhánù náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀ torí pé àwọn tó ń rìnrìn-àjò máa ń sọ bí Gáyọ́sì ṣe ń tọ́jú wọn fún un.—3 Jòh. 3, 6.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé míṣọ́nnárì tàbí àwọn aṣojú Jòhánù làwọn àlejò yìí, wọ́n sì lè jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò. Èyí ó wù kí wọ́n jẹ́, torí kí wọ́n lè polongo ìhìn rere ni wọ́n ṣe ń rìnrìn-àjò. Jòhánù sọ pé: “Tìtorí orúkọ rẹ̀ ni wọ́n ṣe jáde lọ.” (3 Jòh. 7) Orúkọ Jèhófà ni Jòhánù ń tọ́ka sí nígbà tó sọ pé “tìtorí orúkọ rẹ̀,” ìdí ni pé ó ṣẹ̀sẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run ní ẹsẹ kẹfà ni. Torí náà, ara ìjọ Kristẹni làwọn arìnrìn-àjò yìí, ó sì yẹ kí wọ́n tọ́jú wọn. Bí Jòhánù ṣe sọ ọ́ gan-an ló rí, pé: “A wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti gba irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò, kí a lè di alábàáṣiṣẹ́pọ̀ nínú òtítọ́.”—3 Jòh. 8.
ÌRÀNLỌ́WỌ́ NÍGBÀ ÌṢÒRO
Kì í ṣe torí kí Jòhánù lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Gáyọ́sì nìkan ló ṣe kọ lẹ́tà sí i. Jòhánù tún fẹ́ ràn án lọ́wọ́ kó lè kojú ìṣòro ńlá kan tó wà nínú ìjọ. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Dìótíréfè ń dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni nígbà yẹn. Ọkùnrin yìí kì í tọ́jú àwọn ará tó jẹ́ arìnrìn-àjò, kì í sì í gbà wọ́n sílé. Bákan náà, kò fẹ́ káwọn míì nínú ìjọ ṣe wọ́n lálejò.—3 Jòh. 9, 10.
Kò sí àní-àní pé tí Dìótíréfè bá tiẹ̀ fẹ́ káwọn ará dé sílé òun, àwọn Kristẹni olóòótọ́ kò ní fẹ́ dé sọ́dọ̀ rẹ̀. Ìdí ni pé Dìótíréfè máa ń wá ipò ọlá nínú ìjọ, kì í sì í fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gba ohunkóhun tí Jòhánù bá sọ. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa ń sọ̀rọ̀ burúkú nípa àpọ́sítélì náà àtàwọn míì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jòhánù kò pè é ní olùkọ́ èké, síbẹ̀ ṣe ni Dìótíréfè ń tako ọlá àṣẹ àpọ́sítélì Jòhánù. Ìwà burúkú tí Dìótíréfè ń hù àti bó ṣe ń wá ipò ọlá nínú ìjọ fi hàn pé kì í ṣe adúróṣinṣin sí Jèhófà. Àpẹẹrẹ Dìótíréfè jẹ́ ká rí i pé àwọn agbéraga àtàwọn tó bá ń wá ipò ńlá máa ń dá ìyapa sílẹ̀ nínú ìjọ. Ìdí nìyẹn tí Jòhánù fi gba Gáyọ́sì nímọ̀ràn kan tó kan àwa náà lónìí, ó sọ pé: “Má ṣe jẹ́ aláfarawé ohun búburú.”—3 Jòh. 11.
ÌDÍ PÀTÀKÌ TÓ FI YẸ KÓ ṢE RERE
Jòhánù wá sọ̀rọ̀ nípa Kristẹni kan tó ń jẹ́ Dímẹ́tíríù tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere. Dímẹ́tíríù kò fìwà jọ Dìótíréfè. Jòhánù sọ pé: “Dímẹ́tíríù ti ní ẹ̀rí tí a jẹ́ sí i . . . Ní ti tòótọ́, àwa, pẹ̀lú, ń jẹ́rìí, ìwọ sì mọ̀ pé òótọ́ ni ẹ̀rí tí àwa ń jẹ́.” (3 Jòh. 12) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Dímẹ́tíríù nílò ìrànlọ́wọ́ Gáyọ́sì, ó sì lè jẹ́ pé lẹ́tà kẹta tí Jòhánù kọ yìí ló fi jẹ́ kí Gáyọ́sì mọ̀ nípa Dímẹ́tíríù tó sì fi dámọ̀ràn rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Dímẹ́tíríù fúnra rẹ̀ ló fi lẹ́tà náà jíṣẹ́ fún Gáyọ́sì. Ó sì ṣeé ṣe kó kín ọ̀rọ̀ tí Jòhánù sọ lẹ́yìn torí pé aṣojú Jòhánù ni tàbí kó jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò.
Kí wá nìdí tí Jòhánù fi sọ fún Gáyọ́sì pé kó túbọ̀ máa gba àwọn ará lálejò nígbà tó jẹ́ pé ó ti máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀? Ṣé Jòhánù wò ó pé ó yẹ kóun fún Gáyọ́sì níṣìírí ni? Àbí Jòhánù ń ronú pé Gáyọ́sì lè má gba àwọn ará lálejò mọ́ torí bí Dìótíréfè ṣe ń lérí pé òun á lé ẹni tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ kúrò nínú ìjọ? Èyí ó wù kó jẹ́, Jòhánù fọkàn Gáyọ́sì balẹ̀ nígbà tó sọ fún un pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe rere pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (3 Jòh. 11) Ìdí pàtàkì nìyẹn tó fi yẹ kó máa ṣe rere, kó má sì jáwọ́ nínú rẹ̀.
Ǹjẹ́ lẹ́tà tí Jòhánù kọ yìí mú kí Gáyọ́sì túbọ̀ lẹ́mìí aájò àlejò? Ó dájú pé ó ṣe bẹ́ẹ̀, torí pé Jòhánù Kẹta wà lára ìwé tí Jèhófà jẹ́ kó wà nínú Bíbélì kó lè fún gbogbo wa níṣìírí láti ‘jẹ́ aláfarawé ohun rere.’
OHUN TÁ A RÍ KỌ́ NÍNÚ JÒHÁNÙ KẸTA
Bá ò tiẹ̀ mọ púpọ̀ nípa Gáyọ́sì arákùnrin ọ̀wọ́n yìí, síbẹ̀ a lè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì látinú ìwọ̀nba tá a mọ̀ nípa rẹ̀.
Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn Kristẹni tó rìnrìn-àjò láti kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà ló jẹ́ kí ọ̀pọ̀ wa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lónìí. Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ Kristẹni lónìí là ń lọ sọ́nà jíjìn láti tan ìhìn rere kálẹ̀. Síbẹ̀ bíi ti Gáyọ́sì, àwa náà lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń rìnrìn-àjò nítorí ìhìn rere, irú bí alábòójútó àyíká àti ìyàwó rẹ̀. Bákan náà, a lè ṣèrànwọ́ fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ṣí lọ sáwọn ibi tí àìní gbé pọ̀ yálà lórílẹ̀-èdè wọn tàbí lórílẹ̀-èdè míì. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa “máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò.”—Róòmù 12:13; 1 Tím. 5:9, 10.
Ìkejì, ká má jẹ́ kó yà wá lẹ́nu táwọn kan nínú ìjọ bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí àwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ bó tiẹ̀ jẹ́ pé irú ẹ̀ ò wọ́pọ̀. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ fún Jòhánù, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà. (2 Kọ́r. 10:7-12; 12:11-13) Kí ló yẹ ká ṣe táwọn kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìjọ? Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé: “Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, ẹni tí ó tóótun láti kọ́ni, tí ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu lábẹ́ ibi, kí ó máa fún àwọn tí kò ní ìtẹ̀sí ọkàn rere ní ìtọ́ni pẹ̀lú ìwà tútù.” Tá ò bá fara ya kódà nígbà tí wọ́n bá múnú bí wa, àwọn tó ń ṣàríwísí nínú ìjọ lè yíwà pa dà. Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà “lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà tí ń ṣamọ̀nà sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—2 Tím. 2:24, 25.
Ìkẹta, ó yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn Kristẹni tó ń fòótọ́ inú sin Jèhófà láìka àtakò tí wọ́n ń kojú. Àpọ́sítélì Jòhánù gbóríyìn fún Gáyọ́sì, ó sì fún un níṣìírí pé ohun tó tọ́ ló ń ṣe. Bákan náà lónìí, ó yẹ káwọn alàgbà máa ṣe bíi ti Jòhánù, kí wọ́n máa gbóríyìn fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin, kí wọ́n sì máa fún wọn níṣìírí kí “agara” má bàa dá wọn.—Aísá. 40:31; 1 Tẹs. 5:11.
Lóòótọ́, lẹ́tà tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ sí Gáyọ́sì ni ìwé tó kéré jù nínú Bíbélì, torí pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò pọ̀. Síbẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú rẹ̀ ṣàǹfààní gan-an fáwa Kristẹni lónìí.