“Ìwọ Ha Nífẹ̀ẹ́ Mi Ju Ìwọ̀nyí Lọ Bí?”
“Símónì ọmọkùnrin Jòhánù, ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi ju ìwọ̀nyí lọ bí?”—JÒH. 21:15.
1, 2. Ẹ̀kọ́ wo ni Pétérù kọ́ lẹ́yìn tó fi gbogbo òru wá ẹja?
MÉJE lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lọ sí Òkun Gálílì láti lọ pẹja, àmọ́ wọn ò rẹ́ja pa ní gbogbo òru mọ́jú. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, Jésù tó ti jíǹde dúró sétíkun, ó ń wò wọ́n. Ó wá sọ fún wọn pé “ ‘Ẹ ju àwọ̀n sí ìhà ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ ó sì rí díẹ̀.’ Nígbà náà ni wọ́n jù ú, ṣùgbọ́n wọn kò lè fà á wọlé mọ́ nítorí ògìdìgbó ẹja.”—Jòh. 21:1-6.
2 Lẹ́yìn tí Jésù pèsè oúnjẹ àárọ̀ fún wọn, ó yíjú sí Símónì Pétérù, ó sì bi í pé: “Símónì ọmọkùnrin Jòhánù, ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi ju ìwọ̀nyí lọ bí?” Kí ni Jésù ní lọ́kàn? Ó ṣe kedere pé Pétérù fẹ́ràn iṣẹ́ ẹja pípa gan-an. Torí náà, ó jọ pé Jésù fẹ́ mọ ohun tí Pétérù fẹ́ràn jù. Ṣé Jésù ni Pétérù fẹ́ràn jù ni àbí iṣẹ́ ẹja pípa? Ṣé àwọn ẹja tó pa lọ́jọ́ yẹn ló gbà á lọ́kàn jù àbí àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ wọn? Pétérù dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ni fún ọ.” (Jòh. 21:15) Pétérù fi hàn lóòótọ́ pé òun nífẹ̀ẹ́ Jésù. Látìgbà yẹn lọ, ṣe ló ń lo gbogbo okun rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù gbé fún wọn. Ó sì gbé iṣẹ́ ribiribi ṣe nínú ìjọ Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní.
3. Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni kíyè sára?
3 Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún Pétérù? Ó kọ́ wa pé ká kíyè sára kí ìfẹ́ tá a ní fún Kristi má bàa di tútù débi pé àá wá dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Jésù mọ̀ pé àwọn nǹkan tó ń kó àníyàn báni máa pọ̀ gan-an nínú ayé yìí, á sì mú kí nǹkan nira. Nínú àpèjúwe kan tí Jésù sọ nípa afúnrúgbìn, ó sọ pé àwọn kan máa tẹ́wọ́ gba “ọ̀rọ̀ ìjọba náà” wọ́n á sì tẹ̀ síwájú, àmọ́ tó bá yá “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀” máa “fún ọ̀rọ̀ náà pa.” (Mát. 13:19-22; Máàkù 4:19) Ẹ ò rí i pé téèyàn ò bá kíyè sára, ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu lè gbani lọ́kàn débi pé èèyàn á bẹ̀rẹ̀ sí í dẹwọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Abájọ tí Jésù fi kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé.”—Lúùkù 21:34.
4. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa ká lè mọ̀ bóyá a nífẹ̀ẹ́ Kristi gan-an? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
4 Bíi ti Pétérù, ó yẹ káwa náà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Kristi gan-an, ká rí i pé iṣẹ́ ìwàásù tó gbé fún wa ló gbawájú láyé wa. Kí la lè ṣe tá ò fi ní dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà? Ó ṣe pàtàkì ká máa bi ara wa látìgbàdégbà pé: ‘Kí lohun tí mo fẹ́ràn jù gan-an? Ṣé àwọn nǹkan tara tí mò ń ṣe ló máa ń yá mi lára jù ni àbí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run?’ Ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan mẹ́ta tó jẹ́ pé téèyàn ò bá ṣọ́ra, ó lè mú kí ìfẹ́ téèyàn ní fún Kristi di tútù. Àwọn nǹkan náà ni iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, eré ìnàjú àtàwọn ohun ìní tara.
MÁ ṢE JẸ́ KÍ IṢẸ́ OÚNJẸ ÒÒJỌ́ DÍ Ẹ LỌ́WỌ́
5. Ojúṣe wo ni Ọlọ́run gbé lé àwọn olórí ìdílé lọ́wọ́?
5 Ẹja pípa kì í ṣe eré ọwọ́ dilẹ̀ fún Pétérù, ohun tó fi ń gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀ ni. Àwọn olórí ìdílé mọ̀ pé ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé àwọn lọ́wọ́ ni pé káwọn pèsè fún àwọn tó wà nínú ìdílé wọn. (1 Tím. 5:8) Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè bójú tó ojúṣe yẹn. Àmọ́, láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ọ̀rọ̀ iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ máa ń kóni lọ́kàn sókè.
6. Àwọn ìṣòro wo làwọn òṣìṣẹ́ ń kojú lẹ́nu iṣẹ́ wọn lóde òní?
6 Nítorí pé àwọn tó ń wáṣẹ́ pọ̀ gan-an ju iṣẹ́ tó wà nílẹ̀ lọ, ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ló ń forí ṣe fọrùn ṣe fọ́pọ̀ wákàtí àmọ́ tó jẹ́ pé owó tó ń wọlé fún wọn kò tó nǹkan. Yàtọ̀ síyẹn, ṣe làwọn iléeṣẹ́ ń mú káwọn òṣìṣẹ́ máa ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó, ìyẹn sì ń tán àwọn òṣìṣẹ́ lókun, kódà ó ń ṣàkóbá fún ìlera wọn. Bí òṣìṣẹ́ kan kò bá sì ṣe tán láti ṣe irú iṣẹ́ àṣekúdórógbó bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ máa bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
7, 8. (a) Ta ló yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí wa? (b) Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè Thailand kọ́ nípa iṣẹ́ rẹ̀?
7 Àwa Kristẹni mọ̀ pé Jèhófà ṣe pàtàkì sí wa ju ọ̀gá tó gbà wá síṣẹ́ lọ. (Lúùkù 10:27) Ìdí tá a fi ń ṣiṣẹ́ ni pé ká lè gbọ́ bùkátà ara wa àti ti ìdílé wa, ká sì lè ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn. Àmọ́ tá ò bá ṣọ́ra, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ lè dí ìjọsìn wa lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè Thailand sọ pé: “Mo máa ń tún ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà ṣe, iṣẹ́ mi nìyẹn mo sì gbádùn rẹ̀ gan-an, kódà mo máa ń wà nídìí rẹ̀ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ débi pé tipátipá ni mo fi ń ráyè fáwọn nǹkan tẹ̀mí. Nígbà tó yá, mo wá rí i pé tí mo bá máa fọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, àfi kí n wáṣẹ́ míì ṣe.” Kí ni arákùnrin náà ṣe?
8 Arákùnrin náà sọ pé: “Lẹ́yìn ọdún kan tí mo fi tuwó jọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ta áásìkiriìmù. Níbẹ̀rẹ̀, ọjà náà ò tà, ọ̀rọ̀ náà wá tojú sú mi. Yàtọ̀ síyẹn, bí mo bá pàdé àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀, ṣe ni wọ́n máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n máa ń bi mí pé kí ló sún mi dédìí iṣẹ́ tí mò ń ṣe, èmi tí mò ń ṣiṣẹ́ nínú ọ́fíìsì tí ọyẹ́ ti ń fẹ́ ni mo wá ń jókòó sídìí ọjà. Mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà, mo máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí n lè fara dà á, kí n sì lè túbọ̀ máa ráyè fún àwọn nǹkan tẹ̀mí. Kí n tó mọ̀, nǹkan ti bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Mo wá mọ irú áásìkiriìmù táwọn oníbàárà mi fẹ́. Lẹ́yìn yẹn, wàràwàrà ni mò ń tà, kódà ọjà mi kì í ṣẹ́ kù. Kí n sòótọ́, mo wá lówó lọ́wọ́ ju ìgbà tí mò ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì. Ní báyìí, kò sóhun tó ń kó mi lọ́kàn sókè mọ́ bíi ti àtijọ́, èyí sì ń fún mi láyọ̀. Àmọ́, ohun tó fún mi láyọ̀ jù ni pé mo túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.”—Ka Mátíù 5:3, 6.
9. Kí la lè ṣe tí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa kò fi ní gba gbogbo àkókò wa?
9 Jèhófà ò fẹ́ ká máa ṣe ìmẹ́lẹ́, torí pé iṣẹ́ lòògùn ìṣẹ́. (Òwe 12:14) Síbẹ̀, bí arákùnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ tán yìí ṣe sọ, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí iṣẹ́ wa gba gbogbo àkókò wa. Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí [ìyẹn àwọn ohun kòṣeémáàní] ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mát. 6:33) Ká lè mọ̀ bóyá iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tá à ń ṣe kò pa àwọn ojúṣe wa nípa tẹ̀mí lára, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé ó máa ń yá mi lára láti ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ mi, àmọ́ tó bá dọ̀rọ̀ nǹkan tẹ̀mí kì í yá mi lára?’ Tá a bá ń ronú lórí ọwọ́ tá a fi mú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àtọwọ́ tá a fi mú àwọn nǹkan tẹ̀mí, á jẹ́ ká mọ ohun tá a fẹ́ràn jù.
10. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Jésù kọ́ wa?
10 Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé nǹkan tẹ̀mí ló yẹ kó ṣáájú láyé wa. Nígbà kan tí Jésù lọ sílé Màríà àti Màtá, ṣe ni Màtá ń sá sókè sódò láti se oúnjẹ, àmọ́ Màríà ní tiẹ̀ jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jésù, ó sì ń tẹ́tí sí i. Nígbà tí Màtá ṣàròyé pé Màríà kò ran òun lọ́wọ́, Jésù sọ fún Màtá pé: “Màríà yan ìpín rere, a kì yóò sì gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 10:38-42) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ Màtá ní ẹ̀kọ́ pàtàkì. Táwa náà ò bá fẹ́ kí iṣẹ́ wa gbà wá lọ́kàn ju bó ti yẹ lọ, ká sì lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Kristi, a gbọ́dọ̀ “yan ìpín rere,” ká máa fàwọn nǹkan tẹ̀mí ṣáájú láyé wa.
ERÉ ÌNÀJÚ ÀTI ÌGBAFẸ́
11. Tó bá dọ̀rọ̀ pé ká sinmi ká sì gbádùn ara wa, kí ni Bíbélì sọ?
11 Ká sòótọ́, téèyàn bá ń ṣiṣẹ́, ó yẹ kó lásìkò ìsinmi, kó sì gbádùn ara rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Fún ènìyàn, kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí ó máa jẹ kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì jẹ́ kí ọkàn òun rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.” (Oníw. 2:24) Jésù náà máa ń wáyè sinmi. Nígbà kan tóun àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti wàásù gan-an, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, ẹ̀yin fúnra yín, ní ẹ̀yin nìkan sí ibi tí ó dá, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.”—Máàkù 6:31, 32.
12. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra tó bá dọ̀rọ̀ eré ìnàjú àti ìgbafẹ́? Sọ àpẹẹrẹ kan.
12 Òótọ́ ni pé ó dáa kéèyàn máa gbafẹ́, kéèyàn sì wáyè fún eré ìnàjú. Síbẹ̀ tá ò bá ṣọ́ra, àwọn nǹkan yìí lè gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ọ̀pọ̀ ló ní èrò náà pé, “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.” (1 Kọ́r. 15:32) Irú èrò yìí lọ̀pọ̀ èèyàn náà ní lónìí. Bí àpẹẹrẹ, lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ọ̀dọ́kùnrin kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù máa ń wá sípàdé. Àmọ́ nígbà tó yá, eré ìnàjú gbà á lọ́kàn débi pé kò wá sípàdé mọ́. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó wá rí i pé bóun ṣe gbájú mọ́ eré ìnàjú ń fa ìṣòro fún òun, òun ò sì láyọ̀. Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa dà, nígbà tó sì yá, ó di akéde. Lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ó sọ pé: “Ohun kan ṣoṣo tí mo kábàámọ̀ ni pé mo ti fọ̀pọ̀ àkókò ṣòfò kí n tó mọ̀ pé ìjọsìn Jèhófà ló máa ń fúnni láyọ̀ kì í ṣe eré ìnàjú táyé ń gbé lárugẹ.”
13. (a) Ṣàpèjúwe ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ń ṣàṣejù nídìí eré ìnàjú àti ìgbafẹ́. (b) Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa ṣàṣejù nídìí eré ìnàjú àti ìgbafẹ́?
13 Torí kára lè tuni kó sì jí pépé lèèyàn ṣe ń ṣeré ìnàjú. Àmọ́ báwo ló ṣe yẹ kéèyàn pẹ́ tó nídìí rẹ̀? Ẹ jẹ́ ká lo àpèjúwe yìí ná: Ọ̀pọ̀ wa ló fẹ́ràn ká máa jẹ ìpápánu lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ tó bá jẹ́ ìpápánu bíi bisikíìtì, súìtì tàbí kéèkì lẹnì kan kúndùn, ó máa ṣàkóbá fún ìlera rẹ̀. Torí náà, àwọn oúnjẹ tó ń ṣara lóore la sábà máa ń jẹ. Lọ́nà kan náà, téèyàn bá ti àṣejù bọ eré ìnàjú àti ìgbafẹ́, onítọ̀hún máa jó rẹ̀yìn nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Tá ò bá fẹ́ kírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa, ṣe ló yẹ ká máa lọ́wọ́ nínú àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run déédéé. Báwo la ṣe máa mọ̀ bóyá a ti ń ṣàṣejù nídìí eré ìnàjú? A lè yan ọ̀sẹ̀ kan, ká ṣàkọsílẹ̀ iye wákàtí tá a lò fún àwọn nǹkan tẹ̀mí bí lílọ sí ìpàdé, òde ẹ̀rí, ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìjọsìn ìdílé. Lẹ́yìn náà, ká wá fi wéra pẹ̀lú iye wákàtí tá a lò lọ́sẹ̀ kan náà nídìí eré ìnàjú, bí eré ìmárale, eré ọwọ́ dilẹ̀, tẹlifíṣọ̀n àtàwọn géèmù orí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà. Tá a bá fi wéra, èwo nínú méjèèjì là ń ṣe jù? Ǹjẹ́ kò ní gba pé ká dín iye àkókò tá à ń lò nídìí eré ìnàjú àti ìgbafẹ́ kù?—Ka Éfésù 5:15, 16.
14. Kí ló máa mú ká lè yan eré ìnàjú àti ìgbafẹ́ tó gbámúṣé?
14 Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa yan irú eré ìnàjú àti ìgbafẹ́ tó wù ú. Àmọ́ nínú ìdílé, olórí ìdílé ló máa ṣèpinnu. Ká lè yan èyí tó bójú mu, ó ṣe pàtàkì pé ká ronú lórí àwọn ìlànà Jèhófà tó wà nínú Bíbélì, ká sì yan eré ìnàjú tí kò tako àwọn ìlànà náà.a Kódà, Bíbélì sọ pé “ẹ̀bùn Ọlọ́run” ni eré ìnàjú àti ìgbafẹ́ tó gbámúṣé. (Oníw. 3:12, 13) Òótọ́ kan ni pé èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ lọ̀rọ̀ eré ìnàjú àti ìgbafẹ́. (Gál. 6:4, 5) Àmọ́, ká rí i pé a ò ṣàṣejù nídìí èyíkéyìí tá a bá yàn. Jésù sọ pé: “Ibi tí ìṣúra rẹ bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn-àyà rẹ yóò wà pẹ̀lú.” (Mát. 6:21) Nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Jésù dénú, a ò ní jẹ́ káwọn nǹkan tara gbà wá lọ́kàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run làá jẹ́ kó máa darí èrò wa, ọ̀rọ̀ wa àti ìṣe wa.—Fílí. 1:9, 10.
ṢỌ́RA FÚN KÍKÓ NǸKAN ÌNÍ JỌ
15, 16. (a) Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá ohun ìní tara ti ń gbà wá lọ́kàn? (b) Ìmọ̀ràn wo ni Jésù gbà wá nípa àwọn ohun ìní tara?
15 Lóde òní, ohun tó jẹ ọ̀pọ̀ èèyàn lógún ni àwọn nǹkan tó lòde, bí aṣọ, fóònù, àtàwọn nǹkan míì. Torí náà, ó ṣe pàtàkì kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa ṣàyẹ̀wò ọkàn rẹ̀, ká bi ara wa pé: ‘Ṣé kì í ṣe bí mo ṣe máa ní ọkọ̀ tó le ńlẹ̀ àtàwọn aṣọ tó lòde ni mò ń rò ṣáá tí mo sì ń wá kiri débi pé mi ò ń ráyè múra ìpàdé? Ṣé àwọn nǹkan tara tí mò ń ṣe lójoojúmọ́ ló ń gba gbogbo àkókò mi tí mi ò fi ń ráyè gbàdúrà tàbí ka Bíbélì?’ Tá a bá kíyè sí i pé ìfẹ́ tá a ní fáwọn nǹkan tara ti ń mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Kristi jó rẹ̀yìn, á dáa ká ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, pé: “Ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò.” (Lúùkù 12:15) Kí nìdí tí Jésù fi ṣe ìkìlọ̀ tó lágbára bẹ́ẹ̀?
16 Jésù sọ pé “kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì.” Ó tún sọ pé: “Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” Ìdí sì ni pé àwọn “ọ̀gá” méjèèjì yìí fẹ́ kéèyàn fi gbogbo ọkàn sin àwọn. Jésù wá sọ pé, èèyàn máa ní láti “kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì” tàbí kéèyàn “fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì.” (Mát. 6:24) Torí pé a jẹ́ aláìpé, a gbọ́dọ̀ máa sapá kí “àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara wa” má bàa borí wa, títí kan àwọn nǹkan tara.—Éfé. 2:3.
17. (a) Kí nìdí táwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ nǹkan tara kì í rí nǹkan míì rò ju bí wọ́n ṣe máa ní tibí ní tọ̀hún? (b) Kí ni kò ní jẹ́ ká máa lépa àwọn ohun ìní tara?
17 Àwọn tó fẹ́ràn nǹkan tara kì í ro nǹkan míì ju bí wọ́n ṣe máa ní tibí ní tọ̀hún. Ìdí sì ni pé èrò wọn ò bá ti Ọlọ́run mu. (Ka 1 Kọ́ríńtì 2:14.) Torí pé agbára ìwòye wọn kò já geere, ó ṣòro fún wọn láti fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Héb. 5:11-14) Ìyẹn ló fà á tó fi jẹ́ pé àwọn nǹkan tara ni wọ́n máa ń lé ṣáá, síbẹ̀ wọn kì í ní ìtẹ́lọ́rùn. (Oníw. 5:10) Àmọ́ o, ṣíṣe kù, téèyàn ò bá fẹ́ kí àwọn ohun ìní tara gba òun lọ́kàn jù, ó ṣe pàtàkì kó máa ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. (1 Pét. 2:2) Torí pé Jésù máa ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe fún un láti borí ìdẹwò. Táwa náà bá ń fàwọn ìlànà Jèhófà sílò, a ò ní máa lépa àwọn nǹkan ìní tara. (Mát. 4:8-10) Nípa bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jésù ju àwọn nǹkan ìní tara lọ.
18. Kí lo pinnu pé wàá ṣe?
18 Nígbà tí Jésù bi Pétérù pé: “Ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi ju ìwọ̀nyí lọ bí?” ṣe ló ń rán Pétérù létí pé àwọn nǹkan tẹ̀mí ló yẹ kó máa fi ṣáájú. Ìtumọ̀ orúkọ Pétérù ni “Òkúta Kan,” orúkọ yẹn sì rò ó torí pé ó nígbàgbọ́ tó lágbára bí òkúta. (Ìṣe 4:5-20) Ìpinnu tiwa náà ni pé a ò ní jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún Kristi jó rẹ̀yìn láé, a ò sì ní jẹ́ kí eré ìnàjú àti ìgbafẹ́, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àtàwọn ohun ìní tara gbà wá lọ́kàn. Torí náà, ká jẹ́ kí ìpinnu wa ojoojúmọ́ fi hàn pé bó ṣe rí lára Pétérù náà ló rí lára wa nígbà tó sọ fún Jésù pé: “Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ni fún ọ.”
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Eré Ìtura Tó O Yàn Máa Ṣe Ẹ́ Láǹfààní?” nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 2011, ojú ìwé 9 sí 12, ìpínrọ̀ 6 sí 15.