Ojú Ìwòye Bíbélì
Ilẹ̀ Ayé Yóò Ha Jóná Lúúlúú Bí?
NÍPA jíjóná di èédú nínú ìpakúpa rẹpẹtẹ ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kan, tàbí jíjóná deérú nípasẹ̀ oòrùn tí ó tóbi sí i, tàbí nípa kí òrìṣà kan tínú ń bí dáná sun ún—ọ̀nà ìparun náà lè yàtọ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìdánilójú pé, pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé, ibùgbé àdánidá aráyé, yóò dópin nínú ooru gbígbóná janjan kan tí yóò jó gbogbo nǹkan lúúlúú.
Àwọn kan ń tọ́ka sí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí ń tọ́ka sí iná ńlá aṣèparun kan, tí a darí láti ọ̀run wá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san fún bí ènìyàn ṣe kọjá àyè rẹ̀ lòdì sí ilẹ̀ ayé. Àwọn mìíràn ṣe àtúnwí èrò Paul Davies, ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní Yunifásítì Adelaide, Australia, tí ó kọ̀wé nípa ohun tí ó rí, bí ìparun oníná tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, tí ilẹ̀ ayé ń kó sí. Ó dá àbá èrò orí nínú ìwé rẹ̀, The Last Three Minutes, pé: “Bí oòrùn ṣe ń tóbi sí i láìdẹwọ́, yóò bo . . . Ilẹ̀ Ayé mọ́ inú àkámọ́ oníná rẹ̀. Pílánẹ́ẹ̀tì wa yóò di èédú.” Kí ni òtítọ́ nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé? Báwo ni ó ṣe yẹ kí a lóye àwọn ẹsẹ Bíbélì tí ó jọ pé wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìsọdahoro oníná?
Ọlọ́run Ha Bìkítà Bí?
Ní Jeremáyà 10:10-12, a sọ fún wa pé: “[Jèhófà], Ọlọ́run òtítọ́ ni. . . . Òun ti dá ayé nípa agbára rẹ̀, òun ti pinnu [ilẹ̀ tí ń méso wá] nípa ọgbọ́n rẹ̀, ó sì na àwọn ọ̀run nípa òye rẹ̀.” Ọlọ́run dá ilẹ̀ ayé, ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀. Nítorí náà, ó lo ọgbọ́n, ìfẹ́, àti òye, láti fìṣọ́ra ṣètò ilẹ̀ ayé láti wà títí láìlópin gẹ́gẹ́ bí ibùgbé àdánidá ẹlẹ́wà fún aráyé.
Nípa bí Ọlọ́run ṣe dá aráyé, Bíbélì ròyìn pé: “Àti akọ àti abo ni ó dá wọn. Ọlọ́run sì súre fún wọn, Ọlọ́run sì wí fún wọn pé, Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa rẹ̀, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ sì ṣe ìkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Nígbà tí ó parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀, ó lè polongo láìsí iyè méjì pé “dáradára ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Ó fẹ́ kí ó máa wà bẹ́ẹ̀ nìṣó. Lọ́nà kan náà tí àwọn tí ń fojú sọ́nà láti di òbí máa ń gbà ṣàgbékalẹ̀, tí wọ́n sì ń pèsè iyàrá ibùsùn fún ọmọ tí wọ́n ń fojú sọ́nà fún, Ọlọ́run gbin ọgbà ẹlẹ́wà kan, ó sì fi ọkùnrin náà, Ádámù, síbẹ̀, láti máa ro ó, àti láti máa bójú tó o.—Jẹ́nẹ́sísì 2:15.
Ádámù pa ìjẹ́pípé àti ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ láti máa bójú tó ilẹ̀ ayé tì. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ Ẹlẹ́dàá pa ète Tirẹ̀ tì bí? Aísáyà 45:18 dọ́gbọ́n túmọ̀ sí pé, kò ṣe bẹ́ẹ̀: “Báyìí ni Olúwa wí, ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run; . . . tí ó mọ ayé . . . ; ó ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò dá a lásán, ó mọ ọ́n kí a lè gbé inú rẹ̀.” (Tún wo Aísáyà 55:10, 11.) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn ti kọ ẹrù iṣẹ́ àbójútó rẹ̀ sílẹ̀, Ọlọ́run ń bá a lọ láti máa mú àdéhùn tirẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ayé àti àwọn ohun alààyè orí rẹ̀ ṣẹ. Òfin tí a fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì pèsè àyè “ìgbà ìsinmi fún ilẹ̀ náà” lọ́dún méjeméje. Ó tún ní àwọn òfin ìhùwà ìgbatẹnirò tí ó fún àwọn ẹranko ní ààbò nínú. (Léfítíkù 25:4; Ẹ́kísódù 23:4, 5; Diutarónómì 22:1, 2, 6, 7, 10; 25:4; Lúùkù 14:5) Ìwọ̀nyí jẹ́ kìkì àpẹẹrẹ mélòó kan nínú Bíbélì, tí ń fi hàn pé Ọlọ́run bìkítà gidigidi nípa aráyé àti nípa gbogbo ohun tí ó fà lé ènìyàn lọ́wọ́ láti bójú tó.
“Ilẹ̀ Ayé ti Ìṣáájú”
Nígbà náà, báwo ni a ṣe lè mú kí àwọn ẹsẹ Bíbélì, tí ó jọ pé wọ́n ta kora, bára dọ́gba? Ọ̀kan lára irú wọn ni Pétérù Kejì 3:7, tí ó kà gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ King James Version, pé: “Àwọn ọ̀run àti ayé, tí ń bẹ nísinsìnyí, nípa ọ̀rọ̀ kan náà, ni a ti tò jọ bí ìṣúra fún iná, a pa wọ́n mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run.” Òmíràn ni Ìṣípayá 21:1, tí ó sọ pé: “Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan; nítorí ọ̀run ti ìṣáájú àti ilẹ̀ ayé ti ìṣáájú ti kọjá lọ.”
Bí a bá gba àwọn ọ̀rọ̀ Pétérù ní olówuuru, tí pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé sì ní láti jóná nínú iná gidi, a jẹ́ pé, àwọn ọ̀run gidi—àwọn ìràwọ̀ àti àwọn ẹ̀dá ọ̀run mìíràn—ni a óò fi iná pa run pẹ̀lú. Bí ó ti wù kí ó rí, àlàyé yìí forí gbárí pẹ̀lú ìdánilójú tí a rí nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Mátíù 6:10 pé: “Kí ìfẹ́ inú rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bíi ní ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú,” àti Orin Dáfídì 37:29 pé: “Olódodo ni yóò jogún ayé, yóò sì máa gbé inú rẹ̀ láéláé.” Síwájú sí i, ipa wo ni iná lè ní lórí oòrùn tí ó gbóná janjan tẹ́lẹ̀ àti lórí àwọn ìràwọ̀, tí ń pèsè ìbúgbàù agbára átọ̀mù léraléra?
Ní òdì kejì, Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ilẹ̀ ayé” lọ́nà àfiṣàpẹẹrẹ. Fún àpẹẹrẹ, Jẹ́nẹ́sísì 11:1 wí pé: “Gbogbo [ilẹ̀ ayé] sì jẹ́ èdè kan.” Níbí, ọ̀rọ̀ náà, “ilẹ̀ ayé,” ń tọ́ka sí aráyé lápapọ̀, tàbí àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn. (Tún wo Àwọn Ọba Kìíní 2:1, 2; Kíróníkà Kíní 16:31.) Àyíká ọ̀rọ̀ Pétérù Kejì 3:5, 6 dọ́gbọ́n túmọ̀ sí ìlò àfiṣàpẹẹrẹ kan náà fún “ilẹ̀ ayé.” Ó tọ́ka sí ọjọ́ Nóà nígbà tí a pa àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn oníwà ibi kan run nínú Ìkún Omi náà, ṣùgbọ́n a dáàbò bo Nóà àti agbo ilé rẹ̀ pẹ̀lú àgbáyé náà fúnra rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 9:11) Lọ́nà kan náà, nínú Pétérù Kejì 3:7, ó sọ pé àwọn tí a óò pa run ni “àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́-Ọlọ́run.” Ojú ìwòye yìí fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú gbogbo apá yòó kù nínú Bíbélì. Àwùjọ oníwà ibi tí a sàmì sí fún ìparun náà tún ni “ilẹ̀ ayé ti ìṣáájú” tí a tọ́ka sí nínú Ìṣípayá 21:1, tí a fà yọ ṣáájú.
Ní tòótọ́, lọ́nà kan náà tí bàbá kan lórí ilẹ̀ ayé yóò gbà gbé gbogbo ìgbésẹ̀ tí ó bá ṣeé ṣe láti rí i dájú pé a kò pa ibùgbé rẹ̀ lára, Jèhófà Ọlọ́run ní ìdàníyàn ọlọ́kàn ìfẹ́ mímúná nípa ìṣẹ̀dá rẹ̀. Nígbà kan rí, ó lé àwọn ènìyàn oníwà àìmọ́ àti oníwà ibi kan jáde kúrò ní ilẹ̀ Àfonífojì Jọ́dánì ọlọ́ràá, ó sì mú un dá àwọn olùṣàbójútó tuntun fún ilẹ̀ náà, tí wọ́n wà nínú májẹ̀mú kan pẹ̀lú rẹ̀, lójú pé, bí wọ́n bá pa àwọn òfin òun mọ́, ‘ilẹ̀ náà kì yóò bì wọ́n jáde nítorí pé wọ́n bà á jẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti wà ṣáájú wọn.’—Léfítíkù 18:24-28.
“Ilẹ̀ Ayé Tuntun Kan”
Lónìí, àwùjọ kan tí ó jẹ́ oníwà ìbàjẹ́ ní ti ìbálòpọ̀ takọtabo, tí ó ń hùwà ìkà lọ́nà rírorò, tí ó sì ń hùwà ìbàjẹ́ ní ti ìṣèlú, ti ba ilẹ̀ ayé jẹ́. Ọlọ́run nìkan ló lè gbà á sílẹ̀. Òun yóò ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Nínú Ìṣípayá 11:18, ó ṣèlérí “láti mú àwọn wọnnì tí ń run ayé bà jẹ́ wá sí ìrunbàjẹ́.” Àwọn ènìyàn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn dénúdénú ni yóò máa gbé orí ilẹ̀ ayé tí a mú pa dà sípò, tí a sì sọ dọ̀tun náà. (Hébérù 2:5; fi wé Lúùkù 10:25-28.) Àwọn ìyípadà tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run yóò jinlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí Bíbélì fi sọ̀rọ̀ nípa “ilẹ̀ ayé tuntun kan”—àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tuntun kan.
Bí a bá ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bí Orin Dáfídì 37:29, tí a sì lóye ọ̀rọ̀ tí Kristi sọ nínú Mátíù 6:10, ó dá wa lójú pé àwọn ipá àdánidá tí kò ní agbára láti darí nǹkan tàbí ènìyàn kì yóò pa pílánẹ́ẹ̀tì wa run. Wọn kì yóò ké ète Ọlọ́run nígbèrí. (Orin Dáfídì 119:90; Aísáyà 40:15, 26) Aráyé olóòótọ́ yóò gbé orí ilẹ̀ ayé nínú ipò ẹwà àìláàlà àti ìdùnnú àìlópin. Òtítọ́ nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé nìyẹn, nítorí èyí ni ète Ẹlẹ́dàá aráyé onífẹ̀ẹ́, ó sì ti jẹ́ bẹ́ẹ̀ tipẹ́.—Jẹ́nẹ́sísì 2:7-9, 15; Ìṣípayá 21:1-5.