Orí 44
Bí Ìṣípayá Ṣe Kàn Ọ́
1. (a) Ìdánilójú wo ni áńgẹ́lì náà fún Jòhánù nípa gbogbo àwọn àgbàyanu ìlérí tó wà nínú ìwé Ìṣípayá? (b) Ta lẹni tó wí pé, “Mo ń bọ̀ kíákíá,” ìgbà wo sì ni ‘bíbọ̀’ yí?
BÓ O ṣe ka àpèjúwe tó gbádùn mọ́ni nípa Jerúsálẹ́mù Tuntun yẹn, ó ṣeé ṣe kó o béèrè pé: ‘Ǹjẹ́ irú nǹkan àgbàyanu bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ lóòótọ́?’ Jòhánù dáhùn ìbéèrè yẹn nípa ríròyìn àwọn ọ̀rọ̀ tí áńgẹ́lì náà sọ tẹ̀ lé e, ó ní: “Ó sì wí fún mi pé: ‘Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́; bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà Ọlọ́run àwọn àgbéjáde onímìísí tí ó jẹ́ ti àwọn wòlíì rán áńgẹ́lì rẹ̀ jáde láti fi àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn ẹrú rẹ̀. Sì wò ó! mo ń bọ̀ kíákíá. Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń pa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé yìí mọ́.’” (Ìṣípayá 22:6, 7) Gbogbo ìlérí àgbàyanu tó wà nínú Ìṣípayá máa nímùúṣẹ lóòótọ́! Áńgẹ́lì náà sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jésù, ó polongo pé Jésù ń bọ láìpẹ́, “kíákíá.” Èyí ní láti jẹ́ bíbọ̀ Jésù “bí olè” láti pa àwọn ọ̀tá Jèhófà run kó sì mú ìparí ológo ti Ìṣípayá wọlé dé. (Ìṣípayá 16:15, 16) Nítorí náà, a ní láti mú kí ìgbésí ayé wa bá àwọn ọ̀rọ̀ “àkájọ ìwé yìí,” ìyẹn Ìṣípayá mu, ká lè pè wá ní aláyọ̀ lákòókò yẹn.
2. (a) Kí ni Jòhánù ṣe nítorí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìṣípayá tó rí gbà, kí sì ni áńgẹ́lì náà sọ fún un? (b) Kí ni ọ̀rọ̀ áńgẹ́lì náà pé, “Ṣọ́ra!” àti, “Jọ́sìn Ọlọ́run” kọ́ wa?
2 Pẹ̀lú ìran tó kún rẹ́rẹ́ tí Jòhánù rí yìí, kò yani lẹ́nu pé orí rẹ̀ wú gidigidi. Ó sọ ohun tó ṣe fún wa, pé: “Tóò, èmi Jòhánù ni ẹni tí ń gbọ́, tí ó sì ń rí nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo gbọ́, tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti jọ́sìn níwájú ẹsẹ̀ áńgẹ́lì tí ó ti ń fi nǹkan wọ̀nyí hàn mí. Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi pé: ‘Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Gbogbo ohun tí mo jẹ́ ni ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ àti ti àwọn arákùnrin rẹ tí wọ́n jẹ́ wòlíì àti ti àwọn tí ń pa àwọn ọ̀rọ̀ àkájọ ìwé yìí mọ́. Jọ́sìn Ọlọ́run.’” (Ìṣípayá 22:8, 9; fi wé Ìṣípayá 19:10.) Ìkìlọ̀ tí Jòhánù gbọ́ lẹ́ẹ̀mejì yìí pé kó má ṣe jọ́sìn àwọn áńgẹ́lì bọ́ sákòókò nígbà ayé rẹ̀, nítorí pé nígbà yẹn, ó hàn gbangba pé àwọn kan ń ṣe irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀ tàbí tí wọ́n ń sọ pé àwọn rí àkànṣe ìṣípayá gbà lọ́dọ̀ àwọn áńgẹ́lì. (1 Kọ́ríńtì 13:1; Gálátíà 1:8; Kólósè 2:18) Lónìí, ó fi hàn gbangba pé Ọlọ́run nìkan la gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn. (Mátíù 4:10) A kò gbọ́dọ̀ fi jíjọ́sìn ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun mìíràn sọ ìjọsìn mímọ́ gaara di ìbàjẹ́.—Aísáyà 42:5, 8.
3, 4. Kí ni áńgẹ́lì náà ń bá a lọ láti sọ fún Jòhánù, báwo sì làwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ṣe ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀?
3 Jòhánù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ó tún sọ fún mi pé: ‘Má ṣe fi èdìdì di àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé yìí, nítorí àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti sún mọ́lé. Ẹni tí ń ṣe àìṣòdodo, kí ó máa ṣe àìṣòdodo síbẹ̀; kí a sì sọ ẹni tí ó jẹ́ eléèérí di eléèérí síbẹ̀; ṣùgbọ́n kí olódodo máa ṣe òdodo síbẹ̀, kí a sì sọ ẹni mímọ́ di mímọ́ síbẹ̀.’”—Ìṣípayá 22:10, 11.
4 Àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró lónìí ń ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ áńgẹ́lì náà. Wọn ò fi èdìdì di àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀, ìyẹn ni pé wọn ò fi bò. Kódà, ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ti Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence (ti July 1879) ṣe àlàyé lórí ọ̀pọ̀ ẹsẹ nínú ìwé Ìṣípayá. Gẹ́gẹ́ bá a ti mẹ́nu kàn án nínú orí àkọ́kọ́ ìwé yìí, fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ àwọn ìwé alanilóye mìíràn jáde lórí Ìṣípayá. Wàyí o, a tún ń pe gbogbo àwọn tó fẹ́ràn òtítọ́ pé kí wọ́n fiyè sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ alágbára tó wà nínú Ìṣípayá àti ìmúṣẹ wọn.
5. (a) Báwọn èèyàn ò bá fẹ́ láti fiyè sí àwọn ìkìlọ̀ àti ìmọ̀ràn inú Ìṣípayá ńkọ́? (b) Kí ló yẹ kí àwọn onínú tútù àti olódodo ṣe?
5 Báwọn èèyàn ò bá fẹ́ láti fiyè sí àwọn ìkìlọ̀ àti ìmọ̀ràn tí ń bẹ nínú ìwé Ìṣípayá, tóò, kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó! “Ẹni tí ń ṣe àìṣòdodo, kí ó máa ṣe àìṣòdodo síbẹ̀.” Àwọn tí ń yíràá nínú ẹ̀gbin sànmánì tó gbọ̀jẹ̀gẹ́ yìí lè kú sínú ẹ̀gbin yẹn tó bá wù wọ́n bẹ́ẹ̀. Láìpẹ́, Jèhófà yóò mú àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ pátápátá, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìparun Bábílónì Ńlá. Kí àwọn onínú tútù máa fi aápọn kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ wòlíì náà pé: “Ẹ wá Jèhófà . . . Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù. Bóyá a lè pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.” (Sefanáyà 2:3) Ní ti àwọn tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà nísinsìnyí, “kí olódodo máa ṣe òdodo síbẹ̀, kí a sì sọ ẹni mímọ́ di mímọ́ síbẹ̀.” Àwọn tó gbọ́n mọ̀ pé àǹfààní onígbà kúkúrú tí ń wá láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kò tó àwọn ìbùkún àìlópin tí àwọn tí ń lépa òdodo àti ìjẹ́mímọ́ yóò gbádùn. Bíbélì wí pé: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (2 Kọ́ríńtì 13:5) Ipa ọ̀nà tó o bá yàn láti máa tọ̀ ló máa pinnu irú èrè tí wàá rí gbà.—Sáàmù 19:9-11; 58:10, 11.
6. Kí ni Jèhófà sọ bó ti ń bá àwọn òǹkàwé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ fún ìgbà ìkẹyìn nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà?
6 Wàyí o, Jèhófà, Ọba ayérayé fẹ́ bá àwọn tí ń ka ìwé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ fún ìgbà ìkẹyìn nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà, ó ní: “Wò ó! Mo ń bọ̀ kíákíá, èrè tí mo sì ń fi fúnni wà pẹ̀lú mi, láti san fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ ti rí. Èmi ni Ááfà àti Ómégà, ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn, ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti òpin. Aláyọ̀ ni àwọn tí ó fọ aṣọ wọn, kí ọlá àṣẹ láti lọ síbi àwọn igi ìyè lè jẹ́ tiwọn, kí wọ́n sì lè gba ẹnubodè wọlé sínú ìlú ńlá náà. Lẹ́yìn òde ni àwọn ajá wà àti àwọn tí ń bá ẹ̀mí lò àti àwọn àgbèrè àti àwọn òṣìkàpànìyàn àti àwọn abọ̀rìṣà àti gbogbo ẹni tí ó fẹ́ràn irọ́, tí ó sì ń bá a lọ ní pípurọ́.”—Ìṣípayá 22:12-15.
7. (a) Kí ni Jèhófà “ń bọ̀ kíákíá” láti ṣe? (b) Èé ṣe tí àwùjọ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kì yóò fi ní ìpín kankan nínú Jerúsálẹ́mù Tuntun?
7 Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà Ọlọ́run tẹnu mọ́ ipò rẹ̀ ayérayé gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ àti òtítọ́ náà pé ohun tí òun ní lọ́kàn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni òun yóò mú ṣẹ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ó “ń bọ̀ kíákíá” láti mú ìdájọ́ ṣẹ àti pé yóò san èrè fún àwọn tí ń fi gbogbo ọkàn wá a. (Hébérù 11:6) Àwọn ìlànà rẹ̀ ni yóò pinnu àwọn tí yóò san èrè fún àti àwọn tí yóò ṣá tì. Àwùjọ àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti hùwà bí “ajá tí kò lè fọhùn,” wọ́n ń ṣe bí ẹní pé wọn kì í ṣe àwọn ohun to burú jáì tí Jèhófà mẹ́nu kàn yìí. (Aísáyà 56:10-12; tún wo Diutarónómì 23:18, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.) Dájúdájú, wọ́n “fẹ́ràn” àwọn ẹ̀kọ́ èké wọ́n sì “ń bá a lọ” láti máa fi kọ́ni, wọ́n ò sì fiyè sí ìmọ̀ràn Jésù sí ìjọ méje náà rárá. Fún ìdí yìí, wọn kò ní ìpín kankan nínú Jerúsálẹ́mù Tuntun.
8. (a) Kìkì àwọn wo ni yóò “lọ síbi àwọn igi ìyè,” kí sì ni èyí túmọ̀ sí? (b) Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe “fọ aṣọ wọn,” báwo sì ni wọ́n ṣe ń bá a lọ láti pa ipò mímọ́ tí kò lábàwọ́n tí wọ́n wà níwájú Ọlọ́run mọ́?
8 Kìkì àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ‘fọ aṣọ wọn’ lóòótọ́ kí wọ́n lè wà ní mímọ́ tónítóní lójú Jèhófà, ni Ọlọ́run fún láǹfààní láti “lọ síbi àwọn igi ìyè.” Èyíinì ni pé, wọ́n gba ẹ̀tọ́ àti àṣẹ láti wà láàyè ní àìleèkú ní ipò wọn ní ọ̀run. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 3:22-24; Ìṣípayá 2:7; 3:4, 5.) Lẹ́yìn ikú wọn gẹ́gẹ́ bí èèyàn, wọ́n wọlé sínú Jerúsálẹ́mù Tuntun nípa àjíǹde. Áńgẹ́lì méjìlá náà fún wọn láyè láti wọlé, nígbà tí wọ́n dínà mọ́ ẹnikẹ́ni tó sọ irọ́ pípa tàbí ìwà àìmọ́ dàṣà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó sọ pé òun ní ìrètí ti ọ̀run. Ogunlọ́gọ̀ ńlá lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ti “fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” ó sì jẹ́ ọ̀ranyàn fún wọn láti pa ipò mímọ́ tí kò lábàwọ́n tí wọ́n wà níwájú Ọlọ́run mọ́. Wọ́n á lè máa wà ní mímọ́ bí wọ́n bá yẹra fún àwọn ìwà burúkú tí Jèhófà sọ pé kò dára yìí, tí wọ́n sì fi ìṣílétí tí Jésù fúnni nínú iṣẹ́ tó rán sáwọn ìjọ méje náà sọ́kàn.—Ìṣípayá 7:14; orí 2 àti 3.
9. Àwọn ọ̀rọ̀ wo ni Jésù sọ, àwọn wo sì ló darí ìhìn rẹ̀ àti gbogbo Ìṣípayá sí ní pàtàkì?
9 Lẹ́yìn tí Jèhófà sọ̀rọ̀ tán, Jésù sọ̀rọ̀. Ó sọ ọ̀rọ̀ ìṣírí fún àwọn ọlọ́kàn rere tí ń ka Ìṣípayá, ó ní: “Èmi, Jésù, rán áńgẹ́lì mi láti jẹ́rìí fún yín nípa nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ìjọ. Èmi ni gbòǹgbò àti ọmọ Dáfídì, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ títànyòyò.” (Ìṣípayá 22:16) Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní pàtàkì wà fún “àwọn ìjọ.” Èyí jẹ́ ìhìn kan fún ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé lákọ̀ọ́kọ́. Ohun gbogbo tó wà nínú Ìṣípayá ni a darí rẹ̀ ní pàtàkì sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí yóò gbé nínú Jerúsálẹ́mù Tuntun. Nípasẹ̀ ìjọ yẹn, ogunlọ́gọ̀ ńlá pẹ̀lú ní àǹfààní láti ní òye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àgbàyanu wọ̀nyí.—Jòhánù 17:18-21.
10. Èé ṣe tí Jésù fi pe ara rẹ̀ ní (a) “gbòǹgbò àti ọmọ Dáfídì”? (b) “ìràwọ̀ òwúrọ̀ títànyòyò”?
10 Jésù Kristi ló ni iṣẹ́ mímú Ìṣípayá náà dé ọ̀dọ̀ Jòhánù tó sì tipasẹ̀ Jòhánù dé inú ìjọ. Jésù ni “gbòǹgbò àti ọmọ Dáfídì.” Ìlà ìran Dáfídì ló ti wá gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ Ọba Ìjọba Jèhófà. Òun ni yóò tún di “Baba Ayérayé” fún Dáfídì, táá sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ “gbòǹgbò” Dáfídì. (Aísáyà 9:6; 11:1, 10) Òun ni Ọba títí lọ, Ọba tí kò ní kú ní ìlà Dáfídì, tó mú májẹ̀mú Jèhófà pẹ̀lú Dáfídì ṣẹ, òun sì tún ni “ìràwọ̀ òwúrọ̀ títànyòyò” tí a sọ tẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Mósè. (Númérì 24:17; Sáàmù 89:34-37) Òun ni “ìràwọ̀ ojúmọ́” tó yọ, tó mú ọ̀yẹ̀ là. (2 Pétérù 1:19) Gbogbo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí Bábílónì Ńlá ọ̀tá ńlá náà kò lè dènà yíyọ ológo yìí.
Wí Pé: “Máa Bọ̀!”
11. Ìkésíni tó wà fún gbogbo èèyàn wo ni Jòhánù nawọ́ rẹ̀ síni nísinsìnyí, ta sì ló lè dáhùn sí i?
11 Nísinsìnyí ó ti yí kan Jòhánù fúnra rẹ̀ láti sọ̀rọ̀. Pẹ̀lú ọkàn tó kún fún ìmọrírì nítorí gbogbo ohun tó ti rí tó sì ti gbọ́, ó kígbe sókè pé: “Àti ẹ̀mí àti ìyàwó ń bá a nìṣó ní sísọ pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí ń gbọ́ sì wí pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣípayá 22:17) Àwọn àǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù la kì yóò fi mọ sọ́dọ̀ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], nítorí èyí jẹ́ ìkésíni sí gbogbo èèyàn. Ẹ̀mí Jèhófà tí ń súnni ṣiṣẹ́ ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ìyàwó náà, kí ìhìn náà lè máa bá a nìṣó láti máa dún ketekete pé: “Gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Tún wo Aísáyà 55:1; 59:21.) Ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ òdodo ń gbẹ la ké sí láti “máa bọ̀” kó sì gbà lára ìpèsè ọlọ́làwọ́ ti Jèhófà. (Mátíù 5:3, 6) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ni ti gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí láti jẹ́ ara ẹgbẹ́ ti orí ilẹ̀ ayé tí wọ́n dáhùn sí ìkésíni ẹgbẹ́ Jòhánù ẹni àmì òróró!
12. Báwo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe dáhùn sí ìkésíni Ìṣípayá 22:17?
12 Láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1930 wá, iye àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ń pọ̀ sí i ti “ń gbọ́,” ìyẹn ni pé wọ́n ń fiyè sí ìkésíni náà. Bíi tàwọn ẹni àmì òróró ẹrú ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n ti di mímọ́, aláìlábààwọ́n lójú Jèhófà. Wọ́n ń wọ̀nà fún àkókò tí Jerúsálẹ́mù Tuntun yóò sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run láti mú kí ọ̀pọ̀ ìbùkún ṣàn dé ọ̀dọ̀ ìran èèyàn. Bí ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe gbọ́ ìhìn Ìṣípayá tí ń wúni lórí, yàtọ̀ sí pé wọ́n ń sọ pé “Máa bọ̀!,” wọ́n tún ń fi akitiyan kó àwọn mìíràn jọ sínú ètò Jèhófà, wọ́n sì ń kọ́ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú láti pòkìkí pé: “Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀.” Nítorí náà ńṣe ni ogunlọ́gọ̀ ńlá ń pọ̀ sí i, bí iye wọn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà [6,000,000] ní igba ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀ káàkiri ayé ṣe ń bá àwọn ẹni àmì òróró ẹgbẹ́ ìyàwó tí iye wọn dín sí ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án [9,000] ṣe nínú iṣẹ́ pípe àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.”
13. Ìkìlọ̀ wo ni Jésù ṣe?
13 Lẹ́yìn èyíinì, Jésù ló tún sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, pé: “Mo ń jẹ́rìí fún olúkúlùkù ẹni tí ó gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ àkájọ ìwé yìí pé: Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe àfikún kan sí nǹkan wọ̀nyí, Ọlọ́run yóò fi àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ tí a kọ sínú àkájọ ìwé yìí kún ẹni náà; bí ẹnikẹ́ni bá sì mú ohunkóhun kúrò nínú àwọn ọ̀rọ̀ àkájọ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ́run yóò mú ìpín rẹ̀ kúrò nínú àwọn igi ìyè àti kúrò nínú ìlú ńlá mímọ́ náà, àwọn nǹkan tí a kọ̀wé nípa wọn nínú àkájọ ìwé yìí.”—Ìṣípayá 22:18, 19.
14. Ọwọ́ wo ló yẹ kí ẹgbẹ́ Jòhánù fi mú “àsọtẹ́lẹ̀” Ìṣípayá?
14 Àwọn tí wọ́n jẹ́ ti ẹgbẹ́ Jòhánù gbọ́dọ̀ pe àfiyèsí àwọn ẹlòmíì sí “àsọtẹ́lẹ̀” Ìṣípayá. Wọn kò gbọ́dọ̀ fi bò tàbí kí wọ́n fi kún un. Wọ́n gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn tó wà nínú rẹ̀ ní gbangba, “láti orí ilé.” (Mátíù 10:27) Ìṣípayá ní ìmísí Ọlọ́run. Ta ni yóò ṣàyà gbàǹgbà láti ṣe ìyípadà ọ̀rọ̀ kan lára ohun tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ tó sì fi ránṣẹ́ nípasẹ̀ Jésù Kristi, ẹni tó ti ń jọba nísinsìnyí? Dájúdájú, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò pàdánù ìyè tó ń wá, yóò sì rí àwọn ìyọnu tí yóò wá sórí Bábílónì Ńlá àti sórí gbogbo ayé.
15. Kí ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé òun ń “jẹ́rìí nípa nǹkan wọ̀nyí” àti sísọ tó sọ pé “mo ń bọ̀ kíákíá” fi hàn?
15 Jésù wá fi ọ̀rọ̀ ìṣírí ìkẹyìn kún un pé: “Ẹni tí ó jẹ́rìí nípa nǹkan wọ̀nyí wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni; mo ń bọ̀ kíákíá.’” (Ìṣípayá 22:20a) Jésù ni “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́.” (Ìṣípayá 3:14) Bó bá jẹ́rìí sí àwọn ìran Ìṣípayá, kò gbọ́dọ̀ sírọ́ ńbẹ̀. Léraléra ni òun àti Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ń tẹnu mọ́ òtítọ́ náà pé àwọn ń bọ̀ “kíákíá,” tàbí láìpẹ́, ìgbà karùn-ún tí Jésù máa sọ bẹ́ẹ̀ rèé. (Ìṣípayá 2:16; 3:11; 22:7, 12, 20) ‘Bíbọ̀’ náà jẹ́ láti mú ìdájọ́ ṣẹ sórí aṣẹ́wó ńlá náà, “àwọn ọba” òṣèlú àti gbogbo àwọn yòókù tí wọ́n ta ko “ìjọba Olúwa wa [Jèhófà] àti ti Kristi rẹ̀.”—Ìṣípayá 11:15; 16:14, 16; 17:1, 12-14.
16. Pẹ̀lú bó o ṣe mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù ń bọ̀ kíákíá, kí ló yẹ kó o ṣe tìpinnu-tìpinnu?
16 Mímọ̀ tí ìwọ mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù ń bọ̀ kíákíá yẹ kó fún ọ níṣìírí láti fi “wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà . . . sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí.” (2 Pétérù 3:12) Tó bá dà bíi pé mìmì kan ò lè mi ayé tó jẹ́ ara ètò àwọn nǹkan Sátánì, ìtànjẹ lásán ni. Ohun yòówù tó bá dà bíi pé ọ̀run, ìyẹn àwọn alákòóso tó wà lábẹ́ Sátánì, gbé ṣe, ohun náà ò ní wà pẹ́. Nǹkan wọ̀nyẹn ò ní sí mọ́. (Ìṣípayá 21:1) Ọ̀dọ̀ Jèhófà, Ìjọba rẹ̀ lábẹ́ Jésù Kristi, àti ayé tuntun tó ṣèlérí nìkan la ti lè rí ohun tó máa wà títí lọ. Má ṣe jẹ́ kí èyí kúrò lọ́kàn rẹ láé!—1 Jòhánù 2:15-17.
17. Ipa wo ló yẹ kí mímọ̀ tó o mọrírì ìjẹ́mímọ́ Jèhófà ní lórí rẹ?
17 Nítorí náà, àdúrà wa ni pé kí ohun tó o ti kọ́ nínú ìwé Ìṣípayá ní ipa tó jinlẹ̀ lórí ìgbésí ayé rẹ. Ǹjẹ́ kíkó tó o kófìrí ibi tí Jèhófà wà ní ọ̀run ò tẹ ògo àti ìjẹ́mímọ́ títayọlọ́lá tí Ẹlẹ́dàá wa ní mọ́ ọ lọ́kàn? (Ìṣípayá 4:1–5:14) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti sin irú Ọlọ́run bẹ́ẹ̀! Ǹjẹ́ kí ìmọrírì rẹ fún ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ sún ọ láti fojú ribiribi wo ìmọ̀ràn Jésù sí àwọn ìjọ méje wọ̀nyẹn kó o sì yẹra fún àwọn nǹkan bí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì, ìbọ̀rìṣà, ìṣekúṣe, ìlọ́wọ́ọ́wọ́, ẹ̀ya ìsìn àwọn apẹ̀yìndà, tàbí ohunkóhun mìíràn tó lè sọ iṣẹ́ ìsìn rẹ di èyí tí Jèhófà kò tẹ́wọ́ gbà. (Ìṣípayá 2:1–3:22) Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá pẹ̀lú lè tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù sí ẹgbẹ́ Jòhánù, pé: “Ní ìbámu pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ tí ó pè yín, kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín.”—1 Pétérù 1:15, 16.
18. Nínú kí ló yẹ kó o ti kó ipa kíkún bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, èé sì ti ṣe tí a kò fi gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ yìí falẹ̀ lónìí?
18 Láfikún, àdúrà wa ni pé kó o ní àkọ̀tun ìtara bó o ti ń pòkìkí “ọdún ìtẹ́wọ́gbà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà àti ọjọ́ ẹ̀san níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa.” (Aísáyà 35:4; 61:2) Yálà o jẹ́ ara agbo kékeré tàbí ara ogunlọ́gọ̀ ńlá, a gbà ọ́ níyànjú pé kó o nípìn-ín kíkún bó bá ti lè ṣeé ṣe tó nínú pípolongo ìtújáde ìbínú Jèhófà tó wà nínú àwokòtò méje, ìyẹn sísọ nípa àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run lórí ayé Sátánì. Bákan náà, da ohùn rẹ pọ̀ mọ́ ìpòkìkí aláyọ̀ ti ìhìn rere àìnípẹ̀kun nípa Ìjọba Jèhófà àti ti Kristi rẹ̀ tá a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀. (Ìṣípayá 11:15; 14:6, 7) Má ṣe fi iṣẹ́ yìí falẹ̀. Ǹjẹ́ kí ọ̀pọ̀ tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà mọ̀ pé a wà ní ọjọ́ Olúwa, kí èyí sì sún wọn láti dara pọ̀ nínú iṣẹ́ pípòkìkí ìhìn rere náà. Ǹjẹ́ kí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tẹ̀ síwájú dórí yíya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run kí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi. Rántí o, “àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti sún mọ́lé”!—Ìṣípayá 1:3.
19. Kí ni ọ̀rọ̀ ìparí látẹnu àgbàlagbà àpọ́sítélì náà Jòhánù, kí sì ni ọ̀rọ̀ náà ń sún ọ ṣe?
19 Nípa báyìí, pẹ̀lú Jòhánù, a fi ìtara ọkàn gbàdúrà pé: “Àmín! Máa bọ̀, Jésù Olúwa.” Jòhánù, àgbàlagbà àpọ́sítélì náà, sì fi kún un pé: “Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jésù Kristi Olúwa wà pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́.” (Ìṣípayá 22:20b, 21) Kí ó wà pẹ̀lú gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ẹ̀ ń ka ìwé yìí pẹ̀lú. Ǹjẹ́ kẹ́ ẹ nígbàgbọ́ pé ìparí ológo ti Ìṣípayá kù sí dẹ̀dẹ̀, kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè dara pọ̀ mọ́ wa nínú ṣíṣe“Àmín!” tó tinú ọkàn wá.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 314]
“Lẹ́yìn òde ni àwọn ajá wà . . . ”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 315]
“Aláyọ̀ ni àwọn tí wọ́n . . . gba ẹnubodè wọlé sínú ìlú ńlá náà”