Àìsáyà
35 Aginjù àti ilẹ̀ tí kò lómi máa yọ̀,+
Aṣálẹ̀ tó tẹ́jú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa yọ ìtànná bíi sáfúrónì.+
Wọ́n máa rí ògo Jèhófà, ẹwà Ọlọ́run wa.
4 Ẹ sọ fún àwọn tó ń ṣàníyàn nínú ọkàn wọn pé:
“Ẹ jẹ́ alágbára. Ẹ má bẹ̀rù.
Ẹ wò ó! Ọlọ́run yín máa wá gbẹ̀san,
Ọlọ́run máa wá láti fìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹni.+
Ó máa wá gbà yín sílẹ̀.”+
Torí omi máa tú jáde ní aginjù,
Odò sì máa ṣàn ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú.
7 Ilẹ̀ tí ooru ti mú kó gbẹ táútáú máa di adágún omi tí esùsú* kún inú rẹ̀,
Ilẹ̀ gbígbẹ sì máa di ìsun omi.+
Aláìmọ́ kò ní gba ibẹ̀ kọjá.+
Àwọn tó ń rìn lójú ọ̀nà ló wà fún;
Òmùgọ̀ kankan ò sì ní rìn gbéregbère lọ síbẹ̀.
9 Kò ní sí kìnnìún kankan níbẹ̀,
Ẹranko ẹhànnà kankan kò sì ní wá sórí rẹ̀.
10 Àwọn tí Jèhófà rà pa dà máa pa dà wá,+ wọ́n sì máa kígbe ayọ̀ wá sí Síónì.+
Ayọ̀ tí kò lópin máa dé orí wọn ládé.+
Wọ́n á máa yọ̀ gidigidi, inú wọn á sì máa dùn,
Ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ kò ní sí mọ́.+