Orí 10
Bá A Ṣe Lè Kórìíra “Àwọn Ohun Ìjìnlẹ̀ Sátánì”
TÍÁTÍRÀ
1. Ibo ni Tíátírà wà sí àwọn ìjọ yòókù, irú àwọn ìsìn wo ló sì wà ńbẹ̀?
GÚÚSÙ ìlà oòrùn Bẹ́gámà (ìyẹn Págámù ayé ọjọ́un) ni ìlú Ákísà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú Turkey wà. Láti Págámù dé ìlú Ákísà tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù yìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìrìn kìlómítà mẹ́rìndínláàádọ́rin [66]. Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàá [1,900] ọdún sẹ́yìn, ìlú yìí ni ibi tí Tíátírà wà. Alábòójútó arìnrìn-àjò kan lè dé Tíátírà láìṣe wàhálà jìnnà bó bá gba ojú ọ̀nà orí ilẹ̀ tó wá láti Págámù, ó sì lè tibẹ̀ lọ yí ká àwọn ìjọ yòókù tí Ìṣípayá orí kẹta mẹ́nu bà, ìyẹn Sádísì, Filadẹ́fíà, àti Laodíkíà, torí àárín méjì wọn ló wà. Tíátírà ò fi bẹ́ẹ̀ rí bíi Págámù tó jẹ́ ojúkò pàtàkì kan fáwọn tó ń jọ́sìn olú ọba, ṣùgbọ́n àwọn ojúbọ àtàwọn tẹ́ńpìlì tí wọ́n yà sí mímọ́ fáwọn ọlọ́run Kèfèrí wà ńbẹ̀. Ojúkò pàtàkì ni Tíátírà tó bá dọ̀rọ̀ káràkátà.
2, 3. (a) Kí ni ìtàn sọ nípa ará Tíátírà kan tó di Kristẹni? (b) Kí ni jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ “Ọmọ Ọlọ́run” túmọ̀ sí fáwọn Kristẹni tó wà ní Tíátírà? Kí sì ni ìtumọ̀ níní tó ní ‘ojú tó dà bí ọwọ́ iná a-jó-fòfò’?
2 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù ní Makedóníà, ó pàdé obìnrin ará Tíátírà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lìdíà, ẹni tí ń ta aṣọ elésè àlùkò. Inú Lìdíà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ dùn láti gba ẹ̀kọ́ tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù, wọ́n sì ṣe é lálejò dáadáa. (Ìṣe 16:14, 15) Òun ni ará Tíátírà àkọ́kọ́ nínú ìtàn tó tẹ́wọ́ gba ìsìn Kristẹni. Nígbà tó ṣe, àwọn Kristẹni tó wà nílùú yìí wá di ìjọ kan. Ìjọ yìí ni Jésù ránṣẹ́ tó gùn jù sí: “Sì kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Tíátírà pé: Ìwọ̀nyí ni ohun tí Ọmọ Ọlọ́run wí, ẹni tí ojú tí ó ní dà bí ọwọ́ iná ajófòfò, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dà bí bàbà àtàtà.”—Ìṣípayá 2:18.
3 Èyí ni ìgbà kan ṣoṣo tá a rí gbólóhùn náà “Ọmọ Ọlọ́run” nínú Ìṣípayá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé láwọn ibòmíràn Jésù pe Jèhófà ní “Baba mi.” (Ìṣípayá 2:27; 3:5, 21) Ìlò orúkọ oyè náà níhìn-ín ṣeé ṣe kó rán àwọn Kristẹni ní Tíátírà létí nípa àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín Jésù àti Jèhófà. “Ojú tí” Ọmọ yìí ‘ní dà bí ọwọ́ iná a-jó-fòfò,’ èyí tó yẹ kó ran àwọn Kristẹni ní Tíátírà lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ìdájọ́ rẹ̀ máa gbóná lòdì sí ohunkóhun tó bá rí pé ó ń sọ ìjọ rẹ̀ di ẹlẹ́gbin. Nípa mímẹ́nu kan èsẹ̀ rẹ̀ tó ń tàn yòò bíi bàbà lẹ́ẹ̀kejì, ńṣe ló ń tẹnu mọ́ àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ tí kò ṣeé gbàgbé tóun fúnra rẹ̀ fi lélẹ̀ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Kò síyè méjì pé àwọn Kristẹni tó wà ní Tíátírà gba ìmọ̀ràn rẹ̀, ohun táwa náà sì gbọ́dọ̀ ṣe lónìí nìyẹn!—1 Pétérù 2:21.
4, 5. (a) Kí ló mú kí Jésù gbóríyìn fáwọn Kristẹni tó wà ní Tíátírà? (b) Ọ̀nà wo ni ìjọ tó wà ní Tíátírà gbà rí bí ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí?
4 Ó dùn mọ́ni pé Jésù lè gbóríyìn fáwọn tí ń bẹ ní Tíátírà. Ó ní: “Mo mọ àwọn iṣẹ́ rẹ, àti ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìfaradà rẹ, àti pé àwọn iṣẹ́ rẹ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ pọ̀ ju àwọn ti ìṣáájú.” (Ìṣípayá 2:19) Láìdà bí àwọn ará Éfésù, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ńbẹ̀ ò tíì pàdánù ìfẹ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n ní sí Jèhófà. Ìgbàgbọ́ wọn lágbára. Síwájú sí i, àwọn iṣẹ́ wọn ju tàtẹ̀yìnwá lọ, àti bíi ti ìjọ mẹ́ta tó ṣáájú, àwọn Kristẹni ní Tíátírà ní ìfaradà. Bẹ́ ẹ ló sì rí pẹ̀lú nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé lónìí! Ṣe làwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀mí ìtara tí ètò Ọlọ́run fi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ń sún tọmọdé tàgbà láti máa ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà lẹ́yìn. Àwọn tó ń sìn bí aṣáájú-ọ̀nà túbọ̀ ń pọ̀ sí i, wọ́n sì ń tipa báyìí fọgbọ́n lo àkókò tó ṣẹ́ kù láti pòkìkí ìrètí ológo, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run tó ń bọ̀!—Mátíù 24:14; Máàkù 13:10.
5 Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún sẹ́yìn lọ̀pọ̀ olùṣòtítọ́, tí wọ́n jẹ́ àṣẹ́kù ẹni àmì òróró àti ogunlọ́gọ̀ ńlá, ti ń fi ìfaradà ṣiṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, nígbà tó sì jẹ́ pé ṣe ni aráyé ń rì sínú àìnírètí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ káwa jẹ́ onígboyà! Ìṣípayá jẹ́rìí sí òtítọ́ táwọn wòlíì Ọlọ́run tó ṣáájú sọ. “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.”—Sefanáyà 1:14; Jóẹ́lì 2:1; Hábákúkù 2:3; Ìṣípayá 7:9; 22:12, 13.
“Obìnrin Yẹn Jésíbẹ́lì”
6. (a) Láìka àwọn nǹkan rere táwọn ara Tíátírà ń ṣe sí, ìṣòro wo ni Jésù kíyè sí nínú ìjọ náà tó nílò àfiyèsí ní kíákíá? (b) Ta ni Jésíbẹ́lì, ǹjẹ́ ó tọ́ kó sọ pé wòlíì obìnrin lòun?
6 Ojú Jésù tó ń jó fòfò tún ti rí nǹkan míì. Ó kíyè sóhun kan tó yẹ kó fún láfiyèsí ní kíákíá. Ó sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Tíátírà pé, “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ní èyí lòdì sí ọ, pé ìwọ fi àyè gba obìnrin yẹn Jésíbẹ́lì, ẹni tí ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì obìnrin, ó sì ń kọ́, ó sì ń ṣi àwọn ẹrú mi lọ́nà láti ṣe àgbèrè àti láti jẹ àwọn ohun tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà.” (Ìṣípayá 2:20) Ní ọ̀rúndún kẹwàá ṣááju Sànmánì Kristẹni, òkìkí ìṣìkàpànìyàn, panṣágà àti ìwà ìjẹgàba ìyàwó Áhábù Ọba Ísírẹ́lì, ìyẹn Jésíbẹ́lì olùjọ́sìn Báálì, kàn káàkiri. Jéhù, ẹni àmì òróró Jèhófà, sì pa á. (1 Àwọn Ọba 16:31; 18:4; 21:1-16; 2 Àwọn Ọba 9:1-7, 22, 30, 33) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé abọ̀rìṣà ni Jésíbẹ́lì, kò lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé wòlíì obìnrin lòun. Òun ò rí bíi Míríámù àti Dèbórà, àwọn obìnrin tí wọ́n sìn bíi wòlíì olùṣòtítọ́ ní Ísírẹ́lì. (Ẹ́kísódù 15:20, 21; Àwọn Onídàájọ́ 4:4; 5:1-31) Ẹ̀mí Jèhófà ò sì sún un láti sọ tẹ́lẹ̀ bó ṣe sún Ánà arúgbó àtàwọn ọmọbìnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ti Fílípì ajíhìnrere bí.—Lúùkù 2:36-38; Ìṣe 21:9.
7. (a) Nígbà tí Jésù mẹ́nu ba “obìnrin yẹn Jésíbẹ́lì,” kí ló ní lọ́kàn? (b) Ọ̀nà wo làwọn obìnrin tó ṣeé ṣe kí wọ́n kóra jọ gbà dá ìfẹ́ inú ara wọn láre?
7 Ó wá ṣe kedere pé ayédèrú wòlíì ni “obìnrin yẹn Jésíbẹ́lì” tó ń pera ẹ̀ ní wòlíì obìnrin nílùú Tíátírà. Kò ní ìtìlẹyìn ẹ̀mí Ọlọ́run. Ta lobìnrin yìí? Ó jọ pé, aláìnítìjú obìnrin kan tàbí àwùjọ àwọn obìnrin aláìnítìjú tí wọ́n ń ba ìjọ jẹ́ ni. Àwọn obìnrin kan tó ń dara pọ̀ lè ti máa mú káwọn tó wà nínú ìjọ lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe, tí wọ́n á sì máa fi ògbójú dá ara wọn láre nípa lílọ́ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan lọ́rùn kó lè ti ohun tí wọ́n ń ṣe lẹ́yìn. Ìsọtẹ́lẹ̀ èké ni! Wọ́n tan àwọn mìíràn láti lọ́wọ́ nínú ìwàkuwà bíi tiwọn, ìyẹn “àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.” (Kólósè 3:5) Wọn máa ń mú káwọn tí wọ́n wà nínú ìjọ máa hùwà tí ò dáa àti ìwà tinú-mi-ni-màá-ṣe, irú èyí tí púpọ̀ jù lọ lára àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kà sí ohun tó tọ́, tàbí tí wọ́n ń gbójú fò dá.
8. (a) Kí ni Jésù kéde nípa “Jésíbẹ́lì” tó wà ní Tíátírà? (b) Ọ̀nà wo ni ìwà tí ò tọ́ táwọn obìnrin ní ti gbà wọnú ìjọ lóde òní?
8 Jésù tẹ̀ síwájú láti sọ fáwọn alàgbà tó wà ní Tíátírà pé: “Mo sì fún un ní àkókò láti ronú pìwà dà, ṣùgbọ́n kò fẹ́ láti ronú pìwà dà àgbèrè rẹ̀. Wò ó! Mo máa tó sọ ọ́ sórí ibùsùn àìsàn, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà sínú ìpọ́njú ńlá, àyàfi bí wọ́n bá ronú pìwà dà àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Ìṣípayá 2:21, 22) Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jésíbẹ́lì àkọ́kọ́ ṣe jẹ gàba lórí Áhábù lọ́nà tó hàn gbangba tó sì ta ko Jéhù tí Ọlọ́run ń lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, bákan náà, irú ìwà táwọn obìnrin ní yìí lè máa dọ́gbọ́n darí àwọn ọkọ àtàwọn alàgbà. Ó dà bí ẹni pé àwọn alàgbà tó wà ní Tíátírà fàyè gba ìwà àìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni tí Jésíbẹ́lì ń hù. Níhìn-ín Jésù kéde ìkìlọ̀ kan tó lágbára fún wọn, ìkìlọ̀ ọ̀hún sì kan gbogbo ìjọ àwa èèyàn Jèhófà kárí ayé lónìí. Lóde òní, díẹ̀ lára irú àwọn obìnrin onínú líle bẹ́ẹ̀ ti sún ọkọ wọn láti di apẹ̀yìndà kódà wọ́n ti gbé àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lọ sílé ẹjọ́.—Fi wé Júúdà 5 sí 8.
9. (a) Kí ló dé tí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún Jésíbẹ́lì ò fi ní í ní ipa tó búburú lórí gbogbo àwọn obìnrin tó wà nínú ìjọ? (b) Ìgbà wo la tó lè sọ pé obìnrin kan fìwà jọ Jésíbẹ́lì?
9 Lọ́nàkọnà, ìwà àwọn obìnrin wọ̀nyẹn ò tíì ní ipa tó burú lórí àwọn obìnrin olùṣòtítọ́ tó wà nínú ìjọ Kristẹni. Lóde òní, àwọn arábìnrin olùṣòtítọ́ ni wọ́n ń ṣe èyí tó pọ̀ jù lára iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà; nípasẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tí wọ́n ń darí, wọ́n ń mú ọ̀pọ̀ èèyàn tuntun wá sínú ìjọ. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sì ń ti ìṣètò yìí lẹ́yìn, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Sáàmù 68:11 pé: “Jèhófà tìkara rẹ̀ ni ó sọ àsọjáde náà; àwọn obìnrin tí ń sọ ìhìn rere jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá.” Báwọn aya bá níwà pẹ̀lẹ́, tí wọ́n sì ń fún ọkọ wọn lọ́wọ̀ tó yẹ, èyí tó “níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run,” wọ́n á sùn àwọn ọkọ wọn láti ṣe rere. (1 Pétérù 3:1-4) Ọba Lémúẹ́lì gbóṣùbà fún aya tó mẹ̀tọ́ tó sì mọṣẹ́ níṣẹ́. (Òwe 31:10-31) Ìgbà tóbìnrin kan ò bá hùwà bó ṣe tọ́, tó ń tan àwọn ọkùnrin láti dẹ́ṣẹ̀ tàbí tó ń ta kò wọ́n tàbí tí ò tẹrí ba fún ipò orí nìkan la lè sọ pé ó fìwà jọ Jésíbẹ́lì.—Éfésù 5:22, 23; 1 Kọ́ríńtì 11:3.
10. (a) Kí ló mú kí Jésíbẹ́lì àtàwọn ọmọ rẹ̀ gba ìdájọ́? (b) Nínú ipò eléwu wo làwọn tí wọ́n di ọmọ Jésíbẹ́lì wà, kí làwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sì ní láti ṣe?
10 Ní títọ́ka sí “obìnrin yẹn Jésíbẹ́lì,” Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ: “Ṣe ni èmi yóò fi ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani pa àwọn ọmọ rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ìjọ yóò mọ̀ pé èmi ni ẹni tí ń wá inú kíndìnrín àti ọkàn-àyà, èmi yóò sì fi fún yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ yín.” (Ìṣípayá 2:23) Jésù ti yọ̀ǹda àkókò fún Jésíbẹ́lì àtàwọn ọmọ rẹ̀ láti ronú pìwà dà, ṣùgbọ́n torí pé wọn ò jáwọ́ nínú ìṣekúṣe, dandan ni kí ìdájọ́ wá sórí wọn. Ọ̀rọ̀ yìí kan àwọn Kristẹni lónìí gbọ̀ngbọ̀n. Àwọn tó ń fara wé Jésíbẹ́lì, yálà lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọmọ rẹ̀ nípa títẹ ìlànà Bíbélì lórí ipò orí àti ìwà rere lójú tàbí tí wọ́n gbé agídí wọ̀ bí ẹ̀wù láti lè máa tàpá sí àṣẹ tí ètò Ọlọ́run bá gbé kalẹ̀, wà ní ipò àìsàn eléwu nípa tẹ̀mí. Ó dájú pé bí irú ẹnì bẹ́ẹ̀ bá tọ àwọn alàgbà ìjọ lọ láti gbàdúrà fún un, “àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá, Jèhófà yóò sì gbé e dìde,” kìkì bó bá ń gbé ìgbé ayé rẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó gbàdúrà fún ni o. Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé òun lè tan Ọlọ́run tàbí Kristi jẹ nípa gbígbìyànjú láti bo ìwà àìtọ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀ tàbí nípa dídíbọ́n ṣe bí ẹni tó ń fi ìtara sin Ọlọ́run.—Jákọ́bù 5:14, 15.
11. Báwo la ṣe ń ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ láti wà lójúfò kí àwọn obìnrin má bàa nípa tí ò bójú mu lórí ìjọ?
11 Ó dùn mọ́ wa nínú pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ló wà lójúfò sí ewu yìí. Àwọn alàgbà wà lójúfò sí àwọn tó dà bíi pé wọ́n ń hùwà àìtọ́ àtàwọn tí ìrònú wọn ò bá ìlànà Ọlọ́run mu. Wọ́n ń gbìyànjú láti ṣèrànwọ́ fún tọkùnrin tobìnrin tí wọ́n forí lé ọ̀nà eléwu kí wọ́n bàa lè tún àárín àwọn àti Ọlọ́run ṣe kí wọ́n sì padà bọ̀ sípò kó tó pẹ́ jù. (Gálátíà 5:16; 6:1) Lọ́nà onífẹ̀ẹ́, síbẹ̀ láìgba gbẹ̀rẹ́, àwọn Kristẹni alábòójútó wọ̀nyí kì í fàyè gbà obìnrin èyíkéyìí láti dá ẹgbẹ́ tó jọra pẹ̀lú ẹgbẹ́ tó ń jà fẹ́tọ̀ọ́ àwọn obìnrin sílẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, lóòrèkóòrè ni ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pèsè ìmọ̀ràn tó bá àkókò mu.a
12. Lọ́nà wo ni ẹgbẹ́ Jòhánù òde òní gbà ń fi ìtara tó jọ ti Jéhù hàn?
12 Síbẹ̀, tá a bá rẹ́ni tó lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe tó burú jáì, pàápàá tẹ́ni náà ti wá sọ ọ́ dàṣà, bí ò bá ronú pìwà dà, dandan ni ká yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. À lè rántí bí Jéhù ṣe lo ìtara láti rí i pé òun rẹ́yìn gbogbo ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú Jésíbẹ́lì ní Ísírẹ́lì. Bákan náà, ẹgbẹ́ Jòhánù òde òní kì í gba gbẹ̀rẹ́, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún “Jèhónádábù” alábàákẹ́gbẹ́ wọn, wọ́n sì ń jẹ́ kó hàn pé àwọn yàtọ̀ gédégédé sáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí ò gbóná tí ò tutù.—2 Àwọn Ọba 9:22, 30-37; 10:12-17.
13. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí wọ́n bá juwọ́ sílẹ̀ fún ipa búburú táwọn obìnrin ń ní nínú ìjọ?
13 Gẹ́gẹ́ bí Ońṣẹ́ àti Onídàájọ́ Jèhófà, ohun tó tọ́ ni Ọmọ Ọlọ́run ń ṣe bó ṣe ń fi Jésíbẹ́lì òde òní hàn yàtọ̀ tó sì ń sọ ọ́ sórí ibùsùn àìsàn, látàrí àìsàn rẹ̀ nípa tẹ̀mí tó ti di mọ́ọ́lí sí i lára. (Málákì 3:1, 5) Àwọn tí wọ́n juwọ́ sílẹ̀ fún ipa táwọn obìnrin wọ̀nyẹn ń ní lórí ìjọ á rí ìpọ́njú lílekoko, ìyẹn ìbànújẹ́ dídi ẹni tá a yọ lẹ́gbẹ́, tá a ké kúrò nínú ìjọ Kristẹni bí ìgbà tí wọ́n ti kú. Bí wọ́n bá kọ̀ láti ronú pìwà dà, kí wọ́n ṣẹ́rí padà, kí wọ́n sì dẹni tá a gbà padà sínú ìjọ, ikú ń dúró dè wọ́n nípasẹ̀ “ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani”—ó pẹ́ tán nígbà ìpọ́njú ńlá. Kó tó di ìgbà náà, a lè gbà wọ́n padà sínú ètò Ọlọ́run bí wọ́n bá ronú pìwà dà àwọn ìwà àìtọ́ wọn tọkàntọkàn.—Mátíù 24:21, 22; 2 Kọ́ríńtì 7:10.
14. (a) Báwo ni Jésù ṣe ń lo àwọn alàgbà láti bójú tó àwọn ìṣòro kan, irú bíi bóyá nígbà tá a bá rí ẹnikẹ́ni tó fẹ́ fìwà jọ Jésíbẹ́lì? (b) Báwo ni ìjọ ṣe ní láti ṣètìlẹyìn fáwọn alàgbà tó ń bójú tó irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀?
14 “Gbogbo àwọn ìjọ́” gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Jésù ń wádìí àwọn “kíndìnrín,” èrò tó wà ní odò ikùn wa, àti ‘ọkàn,’ irú ẹni tá a jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún, títí kan àwọn èrò tó ń sún wa ṣe àwọn nǹkan. Fún ìdí yìí, ó ń lo àwọn ìràwọ̀ tó ṣeé gbọ́kàn lé, tàbí àwọn alàgbà láti bójú tó àwọn ìṣòro kan, bóyá nígbà tá a bá rí ẹnikẹ́ni tó fẹ́ fìwà jọ Jésíbẹ́lì. (Ìṣípayá 1:20) Lẹ́yìn táwọn alàgbà wọ̀nyí bá ti wádìí irú ọ̀ràn yìí dáadáa tí wọ́n sì ṣèdájọ́, kò tọ́ fún ẹnikẹ́ni láti máa tọpinpin ohun tó fa ìpinnu tí wọ́n ṣe. Gbogbo wa la ní láti máa fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba bí àwọn alàgbà bá ṣe yanjú ọ̀ràn sí ká sì máa bá a nìṣó láti máa ṣètìlẹyìn fáwọn ìràwọ̀ ìjọ wọ̀nyí. Bá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti sí àwọn ìṣètò tó ń wáyé nínú ètò rẹ̀, a óò rí èrè rẹ̀ gbà. (Sáàmù 37:27-29; Hébérù 13:7, 17) Ní tìrẹ, ǹjẹ́ kí ìpín rẹ jẹ́ ìbùkún nígbà tí Jésù bá ń san án fún ẹnì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àwọn iṣẹ́ rẹ̀.—Gálátíà 5:19-24; 6:7-9.
“Ẹ Di Ohun Tí Ẹ Ní Mú Ṣinṣin”
15. (a) Kí ni Jésù sọ fáwọn tí Jésíbẹ́lì ò tíì kó sí lórí? (b) Kí ló fi hàn pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó pera wọn ní Kristẹni nígbà náà lọ́hùn-ún lọ́dún 1918 ló gba ẹ̀kọ́ àwọn aṣáájú ìsìn apẹ̀yìndà gbọ́?
15 Àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tó tẹ̀ lé e tuni lára, ó ní: “Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ̀yin yòókù tí ó wà ní Tíátírà, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kò gba ẹ̀kọ́ yìí, ẹ̀yin tí kò mọ ‘àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Sátánì,’ bí wọ́n ti ń wí, ni mo wí fún [yín] pé: Èmi kò ní gbé ẹrù ìnira èyíkéyìí mìíràn rù yín. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin títí èmi yóò fi dé.” (Ìṣípayá 2:24, 25) Àwọn tó jẹ́ olùṣòtítọ́ ṣì wà ní Tíátírà, àwọn tí wọn ò tíì jẹ́ kí Jésíbẹ́lì kó sáwọn lórí. Bákan náà, fún ogójì [40] ọdún ṣáájú ọdún 1918 àti látìgbà náà wá, kì í ṣe gbogbo àwọn tó pera wọn ní Kristẹni ni wọ́n ń gbé ìgbé ayé oníwà ìbàjẹ́ tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Agbo kékeré ti àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a mọ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nísinsìnyí, tí gbìyànjú láti ran àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ́wọ́ láti rí i pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ táwọn aṣáájú ìsìn wọn fi ń kọ́ àwọn èèyàn ni ò bá ìsìn Kristẹni mu, wọ́n sì ti pinnu láti jáwọ́ nínú gbogbo àwọn ìgbàgbọ́ àtàwọn àṣà Bábílónì tí wọ́n gbà lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn apẹ̀yìndà. Èyí tó ní nínú ẹ̀kọ́ tinú-mi-ni-màá-ṣe tí “obìnrin yẹn Jésíbẹ́lì” fi ń kọ́ni.
16. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù àti ìgbìmọ̀ olùdarí ìjọ Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní ò fi ẹrù ìnira èyíkéyìí kún un, àwọn nǹkan wo la ò gbọ́dọ̀ ṣe?
16 Bákan náà, ẹ̀gbẹ́ Jòhánù òde ti fún àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ogunlọ́gọ̀ ńlá, ní ìṣírí láti ṣọ́ra fáwọn ohun tó lè sún wọ́n sí ìṣekúṣe, bí eré ìnàjú tó kún fún ẹ̀gbin. Kò sí ìdí fún wa láti wò ohun ìbàjẹ́ ká fi lè mọ ohun tá ò gbọ́dọ̀ ṣe tàbí ká sọ ara wa di ẹlẹ́gbin látàrí wíwá fìn-ín ìdí kókò. Ohun tó máa fi hàn pé a gbọ́n ni pé ká má ṣe lọ́wọ́ sí “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Sátánì.” Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti wí: “Èmi kò ní gbé ẹrù ìnira èyíkéyìí mìíràn rù yín.” Èyí rán wa létí ìpinnu Ìgbìmọ̀ Olùdarí ìjọ Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní pé: “Nítorí ẹ̀mí mímọ́ àti àwa fúnra wa ti fara mọ́ ṣíṣàìtún fi ẹrù ìnira kankan kún un fún yín, àyàfi nǹkan pípọndandan wọ̀nyí, láti máa ta kété sí àwọn ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà àti sí ẹ̀jẹ̀ àti sí ohun tí a fún lọ́rùn pa àti sí àgbèrè. Bí ẹ bá fi tìṣọ́ra-tìṣọ́ra pa ara yín mọ́ kúrò nínú nǹkan wọ̀nyí, ẹ óò láásìkí. Kí ara yín ó le o!” (Ìṣe 15:28, 29) Ẹni tó bá fẹ́ kí àárín òun àti Ọlọ́run gún gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ìsìn èké, nínú àṣìlò ẹ̀jẹ̀ (bí ìfàjẹ̀-síni lára), àti nínú ìṣekúṣe! Ó sì tún ṣeé ṣe kẹ́ni náà ní ìlera tó dáa pẹ̀lú.
17. (a) Báwo ni Sátánì ṣe ń fi “àwọn ohun ìjìnlẹ̀” dẹ àwọn èèyàn wò lónìí? (b) Èrò wo ló yẹ ká ní sí “àwọn ohun ìjìnlẹ̀” tó ṣòroó ṣàlàyé nínú ayé Sátánì yìí?
17 Sátánì ní “àwọn ohun ìjìnlẹ̀” mìíràn lónìí, irú bí àwọn ìméfò tó ṣòroó lóye àti ọgbọ́n èèyàn tí kì í ṣeé ṣàlàyé tó ń fi àwọn amòye hàn bí ẹni tó ti ní gbogbo ìmọ̀, láfikún sí tinú-mi-ni-màá-ṣe àti èròkerò, tó fi mọ́ ìbẹ́mìílò àti ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n. Ojú wo ni Ẹlẹ́dàá ọlọ́gbọ́n gbogbo fi ń wo “àwọn ohun ìjìnlẹ̀” wọ̀nyí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ, ó ní: “Ṣe ni èmi yóò mú kí ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ṣègbé.” Àmọ́ “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” yàtọ̀ síyẹn torí wọ́n rọrùn, wọ́n ṣe kedere, wọ́n sì ń múni lọ́kàn yọ̀. Ṣe làwọn Kristẹni tó gbọ́n máa ń kọ “àwọn ohun ìjìnlẹ̀” tó ṣòroó ṣàlàyé nínú ayé Sátánì sílẹ̀. Rántí pé, “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́-ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Kọ́ríńtì 1:19, Kingdom Interlinear; 2:10; 1 Jòhánù 2:17.
18. Àwọn ìbùkún wo ni Jésù ṣèlérí fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n bá jẹ́ olùṣòtítọ́ títí dópin, àǹfààní wo sì làwọn ẹni àmì òroró tó jí dìde wọ̀nyí á ní ní Amágẹ́dọ́nì?
18 Jésù wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ̀rọ̀ amúnilọ́kànyọ̀ fáwọn Kristẹni tó wà ní Tíátírà. Ìṣírí làwọn ọ̀rọ̀ náà sì máa ń jẹ́ fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lónìí: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, tí ó sì pa àwọn iṣẹ́ mi mọ́ títí dé òpin ni èmi yóò fún ní ọlá àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn ènìyàn tó bẹ́ẹ̀ tí a óò fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ bí àwọn ohun èlò amọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti gbà láti ọwọ́ Baba mi.” (Ìṣípayá 2:26, 27) Àǹfààní tí ò láfiwé lóòótọ́! Àṣẹ táwọn ẹni àmì òróró aṣẹ́gun rí gbà nígbà àjíǹde yìí ló fún wọn láǹfààní láti bá Jésù lo “ọ̀pá irin” ìparun lòdì sí àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ̀tẹ̀ ní Amágẹ́dọ́nì. Gbogbo kùkùkẹ̀kẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ló sì máa rọlẹ̀ nígbà tí ohun ìjà olóró tí wọ́n gbójú lé bá dún púkẹ́ bí ìbọn ṣeréṣeré tí omi wọnú rẹ̀ lọ́jọ́ tí Kristi bá fọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí wẹ́wẹ́ bí ìgbà tó ń fọ ohun èlò amọ̀.—Sáàmù 2:8, 9; Ìṣípayá 16:14, 16; 19:11-13, 15.
19. (a) Ta ni “ìràwọ̀ òwúrọ̀,” ọ̀nà wo làwọn aṣẹ́gun sì máa gbà rí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yìí gbà? (b) Báwo ló ṣe máa jẹ́ ìṣírí fáwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá?
19 Jésù fi kún un pé: “Ṣe ni èmi yóò sì fún un ní ìràwọ̀ òwúrọ̀.” (Ìṣípayá 2:28) Nígbà tó yá, Jésù fúnra rẹ̀ ṣàlàyé ohun tí “ìràwọ̀” yìí jẹ́, ó ní: “Èmi ni gbòǹgbò àti ọmọ Dáfídì, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ títànyòyò.” (Ìṣípayá 22:16) Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù lẹni tó mú kí àsọtẹ́lẹ̀ náà nímùúṣẹ, ìyẹn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà fipá mú Báláámù tí ń lọ́ tìkọ̀ sọ pé: “Ìràwọ̀ kan yóò sì yọ láti inú Jékọ́bù wá, ọ̀pá aládé kan yóò sì dìde ní tòótọ́ láti inú Ísírẹ́lì.” (Númérì 24:17) Ọ̀nà wo ni Jésù máa wá gbà fún àwọn tí wọ́n ṣẹ́gun ní “ìràwọ̀ òwúrọ̀”? Ẹ̀rí wà pé á ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífi ara rẹ̀ fún wọn, nípa níní àjọṣe tímọ́tímọ́ jù lọ pẹ̀lú wọn. (Jòhánù 14:2, 3) Ó dájú pé èyí á sún wọn láti lo ìfaradà! Ó tún máa jẹ́ kí ogunlọ́gọ̀ ńlá mọ̀ pé láìpẹ́ “ìràwọ̀ òwúrọ̀ títànyòyò” máa tó lo Ìjọba Ọlọ́run tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ láti mú kí orí ilẹ̀ ayé padà di Párádísè!
Máa Bá Ìwà Títọ́ Nìṣó
20. Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó rán wa létí àwọn ìkùdíẹ̀–káàtó kan nínú ìjọ Tíátírà?
20 Iṣẹ́ tí Jésù rán yìí ti ní láti jẹ́ ìṣírí ńlá fáwọn Kristẹni tó wà ní Tíátírà. Àbẹ́ ò rí nǹkan—Ọmọ Ọlọ́run tó ti wà nínú ògo lọ́run bá àwọn Kristẹni tó wà ní Tíátírà sọ̀rọ̀ lórí díẹ̀ lára àwọn ìṣòro wọn! Ohun tó dájú ni pé àwọn kan nínú ìjọ gba ìbẹ̀wò onífẹ̀ẹ́ yẹn. Iṣẹ́ yìí ló tíì gùn jù lọ lára iṣẹ́ méje tí Jésù rán sáwọn ìjọ méje, òun ló sì tún ràn wá lọ́wọ́ láti dá ìjọ Kristẹni tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀ lónìí. Lọ́dún 1918 nígbà tí Jésù wá sí tẹ́ńpìlì Jèhófà láti ṣèdájọ́, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn àjọ tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni ló ti wọnú ìbọ̀rìṣà, tí ìṣekúṣe sì ti sọ ìjọsìn wọn di ẹlẹ́gbin. (Jákọ́bù 4:4) Ìgbàgbọ́ àwọn kan lára wọn dá lórí ẹ̀kọ́ àwọn obìnrin onínú líle ti ọ̀rúndún kọkàndínlógún, irú bí Ellen White ti ẹ̀sìn Seventh Day Adventist àti Mary Baker Eddy ti ìsìn Christian Scientist, kódà lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ló ti ń wàásù láti orí àga ìwàásù. (Fi wé 1 Tímótì 2:11, 12.) Láàárín oríṣi ìsìn Kátólíìkì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, Màríà ni wọ́n sábà máa ń bọlá fún ṣáájú Ọlọ́run àti Kristi. Àmọ́ Jésù ò bọlá fún Màríà lọ́nà bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 2:4; 19:26) Ṣé a wá lè pe àwọn àjọ tó bá fàyè gba ipa tí ò bójú mu táwọn obìnrin ń ní lórí ìjọ ní Kristẹni?
21. Àwọn ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo lẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè kọ́ látinú iṣẹ́ tí Jésù rán sí ìjọ tó wà ní Tíátírà?
21 Àwọn Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, yálà wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́ Jòhánù tàbí àwọn àgùntàn mìíràn, ní láti ronú lórí iṣẹ́ tí Jésù rán sí ìjọ yìí. (Jòhánù 10:16) Ó lè máa ṣe àwọn kan bíi pé kí wọ́n wá ọ̀nà àbùjá bíi ti àwọn ọmọ ẹ̀yin Jésíbẹ́lì ará Tíátírà yẹn. Ó sì tún lè máa ṣe wọn bíi kí wọ́n sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn. Lónìí, àwọn ọ̀ràn bíi jíjẹ ohun tí wọ́n fi ẹ̀jẹ̀ ṣe lè di àdánwò fáwọn kan tàbí kẹ̀ kó di pé wọ́n gbọ́dọ̀ gba ẹ̀jẹ̀. Àwọn kan lè máa rò pé ìtara táwọn fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn pápá tàbí sísọ àsọyé lè fún àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe tinú àwọn lórí àwọn nǹkan kan, irú bíi wíwo àwọn sinimá àti àwọn fídíò tó ń fi ìwà ipá àti ìṣekúṣe hàn, tàbí fífi ọtí líle kẹ́ra bà jẹ́. Nígbà tí Jésù ń ki àwọn Kristẹni tó wà ní Tíátírà nílọ̀, ó sọ fún wa pé a ò gbọ́dọ̀ dán irú àṣà bẹ́ẹ̀ wò láé. Jèhófà fẹ́ ká jẹ́ mímọ́, ká fi gbogbo ọkàn wa sin òun, ká má sì jẹ́ ṣekuṣẹyẹ bíi ti ọ̀pọ̀ Kristẹni tó wà ní Tíátírà.
22. Báwo ni Jésù ṣe tẹnu mọ́ bó ṣe ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ elétí ọmọ?
22 Lákòótán, Jésù polongo pé: “Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.” (Ìṣípayá 2:29) Nígbà kẹrin, Jésù tún ọ̀rọ̀ ìṣírí yìí sọ, èyí tó máa jẹ́ ọ̀rọ̀ ìkádìí fún gbogbo àwọn iṣẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó ń bọ̀ lọ́nà. Ṣé elétí ọmọ ni ọ́? Nígbà náà, máa bá a nìṣó ní fífetí sílẹ̀ bí Ọlọ́run ṣe ń lo ẹ̀mí rẹ̀ láti máa pèsè ìmọ̀ràn nípasẹ̀ àwọn tó ń lò.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí àpẹẹrẹ, wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Obìnrin Kristẹni Olóòótọ́ Jẹ́ Ẹni Ọ̀wọ́n Tó Ń Sin Ọlọ́run” nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 2003.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 51]
Lóde òní, àwọn arábìnrin olùṣòtítọ́ ni wọ́n ń ṣe èyí tó pọ̀ jù lára iṣẹ́ ìjẹ́rìí bí wọ́n ṣe ń fi ìrẹ̀lẹ̀ fara mọ́ ìlànà ètò Ọlọ́run