Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìṣípayá—Apá Kìíní
NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Jòhánù tó ti darúgbó wà lẹ́wọ̀n ní erékùṣù Pátímọ́sì, ó rí ọ̀wọ́ ìran mẹ́rìndínlógún. Nínú àwọn ìran náà, Jòhánù rí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi máa ṣe ní ọjọ́ Olúwa, ìyẹn láti ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 sí òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi. Inú ìwé Ìṣípayá tí Jòhánù kọ ní nǹkan bí ọdún 96 Sànmánì Kristẹni làwọn ìran tó gbádùn mọ́ni náà wà.
Ẹ jẹ́ ká wá ṣàgbéyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú Ìṣípayá 1:1—12:17, níbi tí Jòhánù kọ ìran méje tó kọ́kọ́ rí sí. Àwọn ìran náà kàn wá nítorí wọ́n dá lórí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí, wọ́n sì tún jẹ́ ká mọ ìgbésẹ̀ tí Jèhófà máa gbé láìpẹ́. Àwọn tó bá ń ka àkọsílẹ̀ yìí tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ yóò rí ìtùnú àti ìṣírí gbà gan-an.—Héb. 4:12.
“Ọ̀DỌ́ ÀGÙNTÀN NÁÀ” ṢÍ MẸ́FÀ LÁRA ÈDÌDÌ MÉJE NÁÀ
Lákọ̀ọ́kọ́, Jòhánù rí Jésù Kristi tí Ọlọ́run ti ṣe lógo, Jésù sì fi onírúurú iṣẹ́ rán an pé kó ‘kọ ọ́ sínú àkájọ ìwé kó sì fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje.’ (Ìṣí. 1:10, 11) Lẹ́yìn ìyẹn, ó rí ìtẹ́ kan tí wọ́n gbé kalẹ̀ lọ́run. Àkájọ ìwé kan tí wọ́n fi èdìdì méje dì wà lọ́wọ́ ọ̀tún Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ náà. “Kìnnìún tí ó jẹ́ ti ẹ̀yà Júdà,” ìyẹn “ọ̀dọ́ àgùntàn . . . tí ó ní ìwo méje àti ojú méje” ló jẹ́ ẹni tí “ó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà.”—Ìṣí. 4:2; 5:1, 2, 5, 6.
Ìran kẹta jẹ́ ká mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ bí “ọ̀dọ́ àgùntàn náà” ṣe ń ṣí èdìdì mẹ́fà àkọ́kọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Nígbà tó ṣí èdìdì kẹfà, ìsẹ̀lẹ̀ ńlá, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀ wáyé, ọjọ́ ńlá ìrunú náà sì dé. (Ìṣí. 6:1, 12, 17) Àmọ́ nínú ìran tó tẹ̀ lé e, Jòhánù rí ‘àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tó di ẹ̀fúùfù mẹ́rin ilẹ̀ ayé mú pinpin’ títí dìgbà tí fífi èdìdì di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì fi parí. Ó sì rí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí a kò fi èdìdì dì, “wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.”—Ìṣí. 7:1, 9.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:4; 3:1; 4:5; 5:6—Kí ni gbólóhùn náà “ẹ̀mí méje” ń tọ́ka sí? Ohun tó pé pérépéré lójú Ọlọ́run ni nọ́ńbà náà, eéje dúró fún. Nítorí náà, iṣẹ́ tí Jésù rán sí “àwọn ìjọ méje náà” wà fún gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run pátá tó wà nínú ìjọ tó ju ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] lọ kárí ayé. (Ìṣí. 1:11, 20) Níwọ̀n bí Jèhófà ti máa ń fúnni ní ẹ̀mí mímọ́ tó tó láti ṣe ohun tó bá fẹ́ ká ṣe, gbólóhùn náà “ẹ̀mí méje,” fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ lẹ́kún-únrẹ́rẹ́ láti fi òye fúnni àti láti bù kún àwọn tó ń fiyè sí àsọtẹ́lẹ̀ náà. Ó jọ pé méje-méje ni ìwé Ìṣípayá máa ń kó àwọn nǹkan tó ń ṣàlàyé pọ̀. Nọ́ńbà náà eéje tó wà níhìn-ín dúró fún ohun tó pé pérépéré, ohun tí ìwé náà sì dá lé lóòótọ́ ni mímú “àṣírí mímọ́ Ọlọ́run” “wá sí ìparí.”—Ìṣí. 10:7.
1:8, 17—Ta ni àwọn orúkọ oyè yìí, “Ááfà àti Ómégà,” àti “Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn” ń tọ́ka sí? Orúkọ oyè náà “Ááfà àti Ómégà” ń tọ́ka sí Jèhófà, ìyẹn sì fi hàn pé kò sí Ọlọ́run Olódùmarè kankan ṣáájú Jèhófà, kò sì ní sí èyíkéyìí lẹ́yìn rẹ̀. Òun ni “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti òpin.” (Ìṣí. 21:6; 22:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni Ìṣípayá 22:13 pè ní “ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn” ní ti pé kò sí ẹnì kankan ṣáájú rẹ̀ tàbí lẹ́yìn rẹ̀, àmọ́ Jésù Kristi ni “Ẹni àkọ́kọ́ àti Ẹni ìkẹyìn” ti inú orí kìíní ìwé Ìṣípayá, èyí sì hàn látinú ohun tí wọ́n ń sọ níbẹ̀. Òun ni èèyàn àkọ́kọ́ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ jí dìde ní ẹni ẹ̀mí tí kò lè kú, òun sì ni ẹni ìkẹyìn tí Jèhófà fúnra rẹ̀ jí dìde lọ́nà bẹ́ẹ̀.—Kól. 1:18.
2:7—Kí ni “párádísè Ọlọ́run”? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni Jésù ń sọ níbí, párádísè yìí ní láti tọ́ka sí ipò ìdẹ̀ra tó dà bíi ti inú Párádísè, tí wọ́n máa wà lọ́run, níbi tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ wà. Èrè táwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró máa gbà ni pé wọ́n á jẹ “nínú igi ìyè.” Èyí fi hàn pé wọ́n á gba àìleèkú.—1 Kọ́r. 15:53.
3:7—Ìgbà wo ni Jésù gba “kọ́kọ́rọ́ Dáfídì,” báwo ló sì ṣe ń lo kọ́kọ́rọ́ náà? Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, ó di Ọba Lọ́la tó wá látinú ìran Dáfídì. Àmọ́, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni Jésù tó gba kọ́kọ́rọ́ Dáfídì, nígbà tí Ọlọ́run gbé e ga sọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ lọ́run. Ibẹ̀ ló ti jogún gbogbo ẹ̀tọ́ Ìjọba Dáfídì. Látìgbà yẹn ni Jésù ti ń lo kọ́kọ́rọ́ náà láti ṣílẹ̀kùn àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó jẹ mọ́ Ìjọba náà. Lọ́dún 1919, Jésù fi “kọ́kọ́rọ́ ilé Dáfídì” lé èjìká “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” nípa yíyàn ẹgbẹ́ ẹrú náà sípò “lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.”—Aísá. 22:22; Mát. 24:45, 47.
3:12—Kí ni “orúkọ tuntun” tí Jésù ní? Orúkọ náà ní í ṣe pẹ̀lú ipò tuntun àtàwọn àǹfààní tí Jésù gbà. (Fílí. 2:9-11) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó mọ orúkọ yẹn bí Jésù ṣe mọ̀ ọ́n, síbẹ̀ Jésù kọ orúkọ náà sára àwọn arákùnrin rẹ̀ olóòótọ́ ní ọ̀run, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí wọ́n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. (Ìṣí. 19:12) Kódà Jésù tiẹ̀ tún fún wọn lára àwọn àǹfààní rẹ̀.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:3. Nítorí “àkókò tí a yàn kalẹ̀ [láti mú ìdájọ́ Ọlọ́run lórí ayé Sátánì ṣẹ] ti sún mọ́lé,” ó pọn dandan pé ká tètè lóye ìsọfúnni tó wà nínú ìwé Ìṣípayá ká sì ṣiṣẹ́ lé e lórí.
3:17, 18. Ká lè jẹ́ ọlọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí, a ní láti ra “wúrà tí a fi iná yọ́ mọ́” lọ́wọ́ Jésù. Ìyẹn ni pé a gbọ́dọ̀ sapá láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà. (1 Tím. 6:17-19) A tún ní láti wọ “ẹ̀wù àwọ̀lékè funfun,” èyí tó ń fi wá hàn pé a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi. A sì ní láti máa lo “oògùn ojú,” irú bí àwọn ìmọ̀ràn tó ń jáde nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, ká lè ní òye nǹkan tẹ̀mí kedere.—Ìṣí. 19:8.
7:13, 14. Àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún ń ṣàpẹẹrẹ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì nínú ògo wọn ti ọ̀run, níbi tí wọ́n ti jẹ́ ọba àti àlùfáà. Bí Dáfídì Ọba ṣe ṣètò àwọn àlùfáà lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ sí ìpín mẹ́rìnlélógún jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣètò àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún náà. Ọ̀kan lára àwọn alàgbà náà ló sọ ẹni tí ogunlọ́gọ̀ ńlá jẹ́ fún Jòhánù. Nítorí náà, àjíǹde àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti ní láti bẹ̀rẹ̀ kò tó di ọdún 1935. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ọdún yẹn la mú kí àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé mọ ẹni tí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jẹ́ gan-an.—Lúùkù 22:28-30; Ìṣí. 4:4; 7:9.
ṢÍṢÍ TÍ WỌ́N ṢÍ ÈDÌDÌ KÉJE MÚ KÍ KÀKÀKÍ MÉJE DÚN
Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ṣí èdìdì keje. Àwọn áńgẹ́lì méje gba kàkàkí méje. Mẹ́fà lára àwọn áńgẹ́lì náà fun kàkàkí wọn, wọ́n fi ń kéde ìdájọ́ sórí “ìdá mẹ́ta” aráyé, ìyẹn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. (Ìṣí. 8:1, 2, 7-12; 9:15, 18) Èyí ni ohun tí Jòhánù rí nínú ìran kárùn-ún. Jòhánù kópa nínú ìran tó tẹ̀ lé e. Nínú ìran yẹn, ó jẹ àkájọ ìwé kékeré, ó sì wọn ibùjọsìn tẹ́ńpìlì náà. Lẹ́yìn fífun kàkàkí keje, ohùn rara kéde pé: “Ìjọba ayé di ìjọba Olúwa wa àti ti Kristi rẹ̀.”—Ìṣí. 10:10; 11:1, 15.
Ìran keje túbọ̀ ṣàlàyé nípa ohun tó wà nínú Ìṣípayá 11:15, 17. Jòhánù rí àmì ńlá kan ní ọ̀run. Obìnrin tó wà lọ́run bí ọmọkùnrin kan, akọ. Wọ́n lé Èṣù kúrò lọ́run. Inú bí Èṣù sí obìnrin tó wà lọ́run náà, ó sì lọ “bá àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ rẹ̀ ja ogun.”—Ìṣí. 12:1, 5, 9, 17.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
8:1-5—Kí nìdí tí kẹ́kẹ́ fi pa ní ọ̀run, kí ni wọ́n sì fi sọ̀kò sílẹ̀ ayé lẹ́yìn náà? Kẹ́kẹ́ pa ní ọ̀run lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, kí Ọlọ́run bàa lè gbọ́ “àdúrà àwọn ẹni mímọ́” tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Èyí ṣẹlẹ̀ ní òpin Ogun Àgbáyé Kìíní. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kò gòkè lọ sọ́run ní òpin àwọn Àkókò Kèfèrí, bí ọ̀pọ̀ wọn ṣe retí. Wọ́n rí ọ̀pọ̀ ìṣòro lákòókò ogun náà. Nítorí náà, wọ́n gbàdúrà kíkankíkan fún ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Ní ìdáhùn sí àdúrà wọn, áńgẹ́lì náà fi iná ìṣàpẹẹrẹ sọ̀kò sílẹ̀ ayé, èyí tó mú kí iná ìtara àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró máa jó lala nípa tẹ̀mí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kéré níye, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣíṣẹ́ ìwàásù kárí ayé, èyí tó sọ ọ̀ràn Ìjọba Ọlọ́run di ọ̀ràn pàtàkì tó ń jó bí iná, èyí tó ń ràn láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Àwọn ìkìlọ̀ látinú Bíbélì ń dún bí ààrá, àwọn ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń tàn bíi mànàmáná tó ń kọ mọ̀nà, gbogbo àwọn ẹ̀sìn èké sì ń mì jìgìjìgì dórí ìpìlẹ̀ wọn, bí ìgbà tí ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀, bá ń mi ilé jìgìjìgì.
8:6-12; 9:1, 13; 11:15—Ìgbà wo ni àwọn áńgẹ́lì méje yẹn múra láti fun kàkàkí wọn, ìgbà wo ni àwọn kàkàkí náà dún, báwo ni wọ́n sì ṣe dún? Ìtọ́sọ́nà tá a fún àwọn tó jẹ́ ara ẹgbẹ́ Jòhánù tó sọjí lórí ilẹ̀ ayé, láàárín ọdún 1919 sí 1922, wà lára ìmúrasílẹ̀ táwọn áńgẹ́lì ṣe láti fun àwọn kàkàkí méje náà. Àwọn ẹni àmì òróró ń báṣẹ́ lọ pẹrẹu lẹ́nu àtúntò iṣẹ́ ìwàásù ní gbangba àti kíkọ́ ilé ìtẹ̀wé. (Ìṣí. 12:13, 14) Dídún àwọn kàkàkí náà ṣàpẹẹrẹ ìkéde táwọn èèyàn Ọlọ́run ń ṣe láìbẹ̀rù pẹ̀lú àtìlẹ́yìn àwọn áńgẹ́lì, pé ìdájọ́ Jèhófà máa dé sórí ayé Sátánì. Ìgbà àpéjọ tó wáyé ní ìlú Cedar Point, ní ìpínlẹ̀ Ohio lọ́dún 1922 ni àwọn kàkàkí náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í dún lọ́nà tó ṣe kedere, yóò sì máa dún lọ títí di ìgbà ìpọ́njú ńlá.
8:13; 9:12; 11:14—Ọ̀nà wo ni ìró àwọn kàkàkí mẹ́ta tó kẹ́yìn náà gbà jẹ́ “ègbé”? Nígbà tí ìró àwọn kàkàkí mẹ́rin àkọ́kọ́ jẹ́ ìpolongo tó ń tú àṣírí ipò òkú nípa tẹ̀mí táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì wà, ìró àwọn kàkàkí mẹ́ta tó kẹ́yìn jẹ́ ègbé ní ti pé wọ́n jẹ mọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan. Ìró kàkàkí karùn-ún jẹ mọ́ títú tí wọ́n tú àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀ lọ́dún 1919 kúrò nínú “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀,” tó túmọ̀ sí ipò àìṣiṣẹ́mọ́, àti bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ ìwàásù láìdáwọ́dúró, èyí tó dà bí oró lára àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. (Ìṣí. 9:1) Ìró kàkàkí kẹfà sì jẹ́ nípa agbo agẹṣinjagun tó bẹ́ jáde lọ́nà tí kò sírú rẹ̀ rí nínú ìtàn àti iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1922. Ìró kàkàkí tó kẹ́yìn dá lórí ìbí Ìjọba Mèsáyà.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
9:10, 19. Àlàyé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń gbé jáde nínú ìtẹ̀jáde láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ ń ta àwọn èèyàn bí oró. (Mát. 24:45) Àwọn àlàyé náà ṣàpẹẹrẹ ìrù eéṣú tó “ń tani bí àkekèé” àti ti ẹṣin àwọn agẹṣinjagun tí “ìrù wọn dà bí ejò.” Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn ìtẹ̀jáde náà ń ṣèkìlọ̀ nípa “ọjọ́ ẹ̀san [Jèhófà].” (Aísá. 61:2) Ẹ jẹ́ ká máa fi ìgboyà àti ìtara pín àwọn ìtẹ̀jáde náà.
9:20, 21. Ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́kàn tútù tí wọ́n ń gbé láwọn ibi tí wọn ò ti fi ẹ̀sìn Kristẹni ṣe ẹ̀sìn orílẹ̀-èdè wọn ń fetí sílẹ̀ dáadáa sí iṣẹ́ tá à ń jẹ́. Àmọ́, a ò retí pé kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn láti àwọn orílẹ̀-èdè yẹn, èyí tí ìwé Ìṣípayá pè ní “ìyókù àwọn ènìyàn,” máa ya wá sínú òtítọ́. Síbẹ̀, a ò ní jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù wa.
12:15, 16. “Ilẹ̀ ayé,” ìyẹn àwọn ètò ẹ̀dá èèyàn tí ń bẹ nínú ètò Sátánì fúnra rẹ̀, tàbí àwọn aláṣẹ ní onírúurú ilẹ̀, fàyè gba òmìnira ìsìn. Láti nǹkan bí ọdún 1940 wá ni àwọn aláṣẹ wọ̀nyẹn ti ń “gbé odò [inúnibíni] náà mì, èyí tí dírágónì náà pọ̀ jáde láti ẹnu rẹ̀.” Ká sòótọ́, nígbà tí Jèhófà bá fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa mú káwọn aláṣẹ mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Nítorí náà, ohun tí Òwe 21:1 sọ bá a mu pé: “Ọkàn-àyà ọba dà bí ìṣàn omi ní ọwọ́ Jèhófà. Ibi gbogbo tí ó bá ní inú dídùn sí, ni ó ń darí rẹ̀ sí.” Ó yẹ kí èyí fún ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run lókun.