ORÍ 138
Kristi Wà Lọ́wọ́ Ọ̀tún Ọlọ́run
JÉSÙ JÓKÒÓ SÍ ỌWỌ́ Ọ̀TÚN ỌLỌ́RUN
SỌ́Ọ̀LÙ DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN
Ó YẸ KÍNÚ WA MÁA DÙN
Ohun kan ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹwàá lẹ́yìn tí Jésù lọ sọ́run, Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ jáde sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ìyẹn sì jẹ́rìí sí i pé Jésù ti wà lọ́run lóòótọ́. Ohun míì tó tún ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn túbọ̀ jẹ́ kó dá wa lójú. Àwọn èèyàn pa Sítéfánù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn torí pé ó ń fi tọkàntọkàn jẹ́rìí nípa Jésù. Sítéfánù sọ ohun kan nígbà táwọn èèyàn náà ń sọ ọ́ lókùúta, ó ní: “Ẹ wò ó! Mo rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ọmọ èèyàn sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.”—Ìṣe 7:56.
Ní gbogbo àsìkò tí Jésù fi wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ lọ́run, á máa retí ìgbà tí Baba máa fún òun ní ìtọ́ni pàtó kan bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Ọlọ́run mí sí Dáfídì láti kọ ọ́ pé: “Jèhófà sọ fún Olúwa mi [ìyẹn Jésù] pé: ‘Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.’ ” Tí àsìkò yẹn bá tó, Jésù “máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá [rẹ̀].” (Sáàmù 110:1, 2) Àmọ́ kí ni Jésù á máa ṣe látọ̀run bó ṣe ń dúró dígbà tó máa dojú ìjà kọ àwọn ọ̀tá rẹ̀?
Ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì 33 S.K. Àtìgbà yẹn ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọba tàbí ṣàkóso lórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn. (Kólósè 1:13) Jésù ń darí wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó sì ń múra wọn sílẹ̀ de iṣẹ́ tí wọ́n máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Iṣẹ́ wo nìyẹn? Ọlọ́run máa jí àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú dìde, wọ́n sì máa láǹfààní láti jọba pẹ̀lú Jésù ní Ìjọba ọ̀run.
Ọ̀kan lára àwọn tó máa bá Jésù ṣàkóso nínú Ìjọba yẹn ni Sọ́ọ̀lù tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Pọ́ọ̀lù, ìyẹn orúkọ rẹ̀ lédè Róòmù. Júù ni Sọ́ọ̀lù, ọjọ́ pẹ́ tó sì ti ní ìtara fún Òfin Ọlọ́run. Àmọ́ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ti ṣì í lọ́nà débi pé ó fọwọ́ sí i kí wọ́n sọ Sítéfánù lókùúta pa. Torí pé “inú [Sọ́ọ̀lù] ṣì ń ru, tó sì ń fikú halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Olúwa,” ó rìnrìn àjò lọ sí Damásíkù. Káyáfà àlùfáà àgbà fọwọ́ sí i pé kó fàṣẹ ọba mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, kó sì dá wọn pa dà sí Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 7:58; 9:1) Àmọ́ bí Sọ́ọ̀lù ṣe ń lọ sí Damásíkù, ìmọ́lẹ̀ kan láti ọ̀run kọ mànà yí i ká, torí náà ó ṣubú lulẹ̀.
Ni ohùn kan bá dún láti ọ̀run pé: “Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, kí nìdí tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” Sọ́ọ̀lù wá béèrè pé: “Ta ni ọ́, Olúwa?” Ohùn náà fèsì pé: “Èmi ni Jésù, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.”—Ìṣe 9:4, 5.
Jésù ní kí Sọ́ọ̀lù lọ sí Damásíkù, kó dúró síbẹ̀ dìgbà tóun máa sọ ohun tó máa ṣe fún un. Ṣe ni wọ́n mú Sọ́ọ̀lù lọ sínú ìlú náà torí ìmọ́lẹ̀ tó kọ mọ̀nà yẹn ò jẹ́ kó ríran mọ́. Jésù tún fara han ọmọ ẹ̀yìn kan nínú ìran, Ananáyà lorúkọ ẹ̀, ìlú Damásíkù ló sì ń gbé. Jésù sọ ibi tí Sọ́ọ̀lù wà fún Ananáyà, ó sì ní kó lọ bá a níbẹ̀. Ananáyà kọ́kọ́ lọ́ra láti lọ, àmọ́ Jésù fi í lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Ohun èlò tí a ti yàn ni ọkùnrin yìí jẹ́ fún mi láti mú orúkọ mi lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù pa dà ríran, Damásíkù ló ti “bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nípa Jésù . . . pé ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.”—Ìṣe 9:15, 20.
Jésù ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ títí kan àwọn ajíhìnrere míì kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù fúnra rẹ̀ bẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run sì jẹ́ kí iṣẹ́ náà yọrí sí rere. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) lẹ́yìn tí Jésù fara han Pọ́ọ̀lù nígbà tó ń lọ sí Damásíkù, Pọ́ọ̀lù kọ ọ́ pé a ti wàásù ìhìn rere yìí “láàárín gbogbo ẹ̀dá tó wà lábẹ́ ọ̀run.”—Kólósè 1:23.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jésù fi onírúurú ìran han àpọ́sítélì kan tó nífẹ̀ẹ́ gan-an, ìyẹn àpọ́sítélì Jòhánù. A lè rí ìran yẹn nínú ìwé Ìfihàn tó wà nínú Bíbélì. Ìran náà jẹ́ kó ṣeé ṣe fún Jòhánù láti rí Jésù nígbà tó pa dà dé nínú agbára Ìjọba. (Jòhánù 21:22) Ìran yìí jẹ́ kí “[Jòhánù] wà ní ọjọ́ Olúwa nípasẹ̀ ìmísí.” (Ìfihàn 1:10) Ìgbà wo ni ọjọ́ Olúwa yẹn máa bẹ̀rẹ̀?
Nígbà tá a fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì, a rí i pé “ọjọ́ Olúwa” yẹn bẹ̀rẹ̀ ní àkókò wa yìí. Ogun kan táwọn èèyàn mọ̀ sí Ogun Àgbáyé Kìíní jà lọ́dún 1914. Àtìgbà yẹn ni àwọn nǹkan bí ogun, onírúurú ìyọnu, àìtó oúnjẹ, ìmìtìtì ilẹ̀ àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míì ti túbọ̀ ń ṣẹlẹ̀ láyé. Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí sì jọra pẹ̀lú “àmì” tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé ó máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ti “wà níhìn-ín” àti pé “òpin” ti dé. (Mátíù 24:3, 7, 8, 14) Bákan náà, kì í ṣe ibi tí ìjọba Róòmù ń ṣàkóso nìkan làwọn èèyàn ti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, àwọn èèyàn ti ń gbọ́ ọ níbi gbogbo láyé.
Ọlọ́run mí sí Jòhánù láti ṣàpèjúwe ohun tíyẹn túmọ̀ sí, ó sọ pé: “Ní báyìí, ìgbàlà àti agbára dé àti Ìjọba Ọlọ́run wa pẹ̀lú àṣẹ Kristi rẹ̀.” (Ìfihàn 12:10) Bẹ́ẹ̀ ni, Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù wàásù nípa rẹ̀ nígbà tó wà láyé ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run!
Ìròyìn ayọ̀ nìyẹn jẹ́ fáwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Wọ́n á máa ronú nípa ohun tí Jòhánù sọ pé: “Torí èyí, ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tó ń gbé inú wọn! Ayé àti òkun gbé, torí pé Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ń bínú gidigidi, ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ló kù fún òun.”—Ìfihàn 12:12.
Èyí fi hàn pé kì í ṣe pé Jésù kàn jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún Baba rẹ̀ lásán. Ó ti di Ọba, ó sì máa pa gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ run láìpẹ́. (Hébérù 10:12, 13) Àwọn nǹkan wo ló máa wá ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn?