Orí 16
Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Tí Ń Sáré Kútúpà Kútúpà!
Ìran 3—Ìṣípayá 6:1-17
Ohun tó dá lé: Bí àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ṣe gẹṣin wọn, àwọn ẹlẹ́rìí ajẹ́rìíkú lábẹ́ pẹpẹ àti ọjọ́ ìkannú ńlá
Ìgbà tó nímùúṣẹ: Láti 1914 títí di ìparun ètò àwọn nǹkan yìí
1. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí Jòhánù mọ àwọn ohun tó wà nínú àkájọ ìwé àràmàǹdà tí Jésù ṣí?
LÁYÉ tó kún fún yánpọnyánrin yìí, ǹjẹ́ kò jẹ wá lọ́kàn gan-an láti mọ “àwọn ohun tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́”? Dájúdájú ó jẹ wá lọ́kàn, nítorí ó kan àwa fúnra wa! Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa fọkàn bá Jòhánù lọ nísinsìnyí bí Jésù ṣe ń ṣí àkájọ ìwé tó fa kíki yẹn. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe pé Jòhánù máa kà á o. Nítorí kí ni? Nítorí pé Jèhófà lo “àwọn àmì” láti fi jẹ́ kó mọ ohun tó wà nínú rẹ̀. Ọ̀wọ́ ìran alágbára tí àwọn nǹkan ńláńlá ti ṣẹlẹ̀ ni Jèhófà sì lò láti fi fi àwọn àmì náà hàn án.—Ìṣípayá 1:1, 10.
2. (a) Kí ni Jòhánù rí tó sì gbọ́, òye kí ni ìrísí kérúbù náà sì jẹ́ kí Jòhánù ní? (b) Ta ni kérúbù àkọ́kọ́ pàṣẹ fún, kí sì nìdí tó o fi dáhùn bẹ́ẹ̀?
2 Gbọ́ ohun tí Jòhánù wí bí Jésù ṣe ṣí àkọ́kọ́ nínú èdìdì àkájọ ìwé náà: “Mo sì rí nígbà tí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ṣí ọ̀kan nínú àwọn èdìdì méje náà, mo sì gbọ́ tí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè náà wí pẹ̀lú ohùn bí ti ààrá pé: ‘Máa bọ̀!’” (Ìṣípayá 6:1) Èyí ni ohùn kérúbù àkọ́kọ́. Ìrísí rẹ̀ tó dà bíi kìnnìún yóò jẹ́ kí Jòhánù ní òye pé ètò Jèhófà yóò fìgboyà mú àwọn ìdájọ́ òdodo Rẹ̀ ṣẹ. Ta sì ni ó pàṣẹ fún pé kó máa bọ̀? Kò lè jẹ́ Jòhánù, nítorí a ti ké sí Jòhánù ṣáájú ìgbà náà pé kó wá kópa nínú àwọn ìran alásọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí. (Ìṣípayá 4:1) Ńṣe ni “ohùn bí ti ààrá” yẹn ń pe àwọn mìíràn tó máa kópa nínú àkọ́kọ́ lára ọ̀wọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńláńlá mẹ́rin kan.
Ẹṣin Funfun Náà àti Akọni Tó Gùn Ún
3. (a) Kí ni Jòhánù ṣàpèjúwe nísinsìnyí? (b) Ní ìbámu pẹ̀lú bí Bíbélì ṣe máa ń fi àmì ṣe àpẹẹrẹ, kí ni ẹṣin funfun náà ní láti dúró fún?
3 Jòhánù, tòun ti ẹgbẹ́ Jòhánù onítara àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn òde òní, láǹfààní láti rí ìran ayárakánkán kan! Jòhánù sọ pé: “Mo sì rí, sì wò ó! ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní ọrun kan; a sì fún un ní adé, ó sì jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” (Ìṣípayá 6:2) Bẹ́ẹ̀ ni, ẹṣin funfun kan ló bẹ́ jáde ní ìdáhùn sí “Máa bọ̀!” tó dún bí ààrá yẹn. Nínú Bíbélì, wọ́n sábà máa ń fi ẹṣin ṣàpẹẹrẹ ogun jíjà. (Sáàmù 20:7; Òwe 21:31; Aísáyà 31:1) Àwọ̀ funfun ẹṣin yìí, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ akọ ẹṣin ẹlẹ́wà kan, ń kọ mànà láti fi hàn pé ó jẹ́ mímọ́, kò sí lálèébù. (Fi wé Ìṣípayá 1:14; 4:4; 7:9; 20:11.) Ẹ wo bí èyí ti bá a mu tó, nítorí ńṣe ló ń fi hàn pé ogun yẹn mọ́ ó sì jẹ́ ogun òdodo ní ojú mímọ́ Jèhófà!—Tún wo Ìṣípayá 19:11, 14.
4. Ta ni Ẹni tó gun ẹṣin funfun náà? Ṣàlàyé.
4 Ta ni Ẹni tó gun ẹṣin yìí? Onítọ̀hún ní ọrun kan, tó jẹ́ ohun ìjà ogun, ṣùgbọ́n a tún fún un ní adé kan. Kìkì àwọn olódodo tá a rí tí wọ́n dé adé ní ọjọ́ Olúwa ni Jésù àti ẹgbẹ́ tí alàgbà mẹ́rìnlélógún náà dúró fún. (Dáníẹ́lì 7:13, 14, 27; Lúùkù 1:31-33; Ìṣípayá 4:4, 10; 14:14)a Kò dà bí ẹni pé a óò ṣe àpẹẹrẹ ọ̀kan nínú alàgbà mẹ́rìnlélógún náà gẹ́gẹ́ bí ẹni tó fúnra rẹ̀ dá ṣe ohun tó mú kó gba adé. Fún ìdí yìí, kò sí ẹlòmíì tí ẹlẹ́ṣin kan ṣoṣo gíro yìí lè jẹ́ bí kò ṣe Jésù Kristi. Jésù yìí ni Jòhánù ń wò ní ọ̀run ní àkókò pàtàkì nínú ìtàn, ìyẹn ọdún 1914, nígbà tí Jèhófà polongo pé, “Èmi, àní èmi, ti fi ọba mi jẹ,” tó sì tún sọ ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọba náà pé “kí èmi lè fi àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ.” (Sáàmù 2:6-8)b Nípa báyìí, bí Jésù ṣe ṣí èdìdì àkọ́kọ́, ńṣe ló sọ bí òun fúnra rẹ̀ yóò ṣe bá eré jáde lọ sí ojú ogun ní gbàrà tó bá di Ọba tó gba adé, ní àkókò tí Ọlọ́run ti yàn kalẹ̀.
5. Báwo ni onísáàmù náà ṣe ṣàpèjúwe Ẹni tó gun ẹṣin náà lọ́nà tó jọ ti Ìṣípayá 6:2?
5 Ìran yìí bá ọ̀rọ̀ Sáàmù 45:4-7, tí a darí rẹ̀ sí Ọba tí Jèhófà gbé gun orí ìtẹ́ ní tààràtà mu wẹ́kú. Ó sọ níbẹ̀ pé: “Àti nínú ọlá ńlá rẹ, kí o tẹ̀ síwájú dé àṣeyọrí sí rere; máa gẹṣin lọ nítorí òtítọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ àti òdodo, ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì máa fún ọ ní ìtọ́ni nínú àwọn ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù. Àwọn ọfà rẹ mú—àwọn ènìyàn ń ṣubú lábẹ́ rẹ—ní ọkàn-àyà àwọn ọ̀tá ọba. Ọlọ́run ni ìtẹ́ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé; ọ̀pá aládé àkóso rẹ jẹ́ ọ̀pá aládé ìdúróṣánṣán. Ìwọ nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà burúkú. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀ ńláǹlà yàn ọ́ ju àwọn alájọṣe rẹ.” Níwọ̀n bí Jòhánù ti mọ ọ̀rọ̀ àpèjúwe tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ yìí dáadáa, yóò mọ̀ pé ohun tí Jésù yóò gbé ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọba ló ń sọ.—Fi wé Hébérù 1:1, 2, 8, 9.
Ó Jáde Lọ Láti Ṣẹ́gun
6. (a) Kí nìdí tí Ẹni tó ń gẹṣin náà fi ní láti jáde lọ láti ṣẹ́gun? (b) Láàárín àwọn ọdún wo ni Jésù ń bá a lọ láti gun ẹṣin ìṣẹ́gun rẹ̀?
6 Ṣùgbọ́n, kí nìdí tí Ọba tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ládé náà fi ní láti gẹṣin láti lọ ja ogun? Ó jẹ́ nítorí pé nígbà tí Jèhófà fi jẹ ọba, àtakò kíkorò wáyé látọ̀dọ̀ Sátánì Èṣù olórí elénìní Jèhófà, àtàwọn èèyàn orí ilẹ̀ ayé tí wọ́n ń jẹ́ kí Sátánì lò wọ́n, yálà wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ tàbí wọn ò mọ̀ọ́mọ̀. Kódà kí Ìjọba náà fúnra rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ pàápàá, ogun ńlá kan wáyé ní ọ̀run. Máíkẹ́lì (tó túmọ̀ sí “Ta Ni Ó Dà Bí Ọlọ́run?”), lorúkọ tí Jésù ń jẹ́ nígbà tó ja ogun tó fi ṣẹ́pá Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ yìí, tó sì fi wọ́n sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 12:7-12) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni Jésù fi ń bá a lọ láti gun ẹṣin ìṣẹ́gun rẹ̀ lápá ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa bá a ṣe ń kó àwọn èèyàn oníwà-bí-àgùntàn jọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ṣì wà “lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” Jésù ń fi ìfẹ́ bá a lọ láti máa ṣolùṣọ́ àgùntàn àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin rẹ̀ àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ní ríran olúkúlùkù wọn lọ́wọ́ láti ja àjàṣẹ́gun nínú ìgbàgbọ́.—1 Jòhánù 5:19.
7. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù ti gbà ṣẹ́gun lórí ilẹ̀ ayé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lápá ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa, kí ló sì yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
7 Àwọn ọ̀nà mìíràn wo ni Jésù ti gbà ṣẹ́gun nínú ohun tó ti lé ní àádọ́rùn-ún [90] ọdún báyìí ní ọjọ́ Olúwa? Yíká ayé làwọn èèyàn Jèhófà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti gẹ́gẹ́ bí ìjọ ti ń rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìnira, pákáǹleke, àti inúnibíni tó dà bíi ti àwọn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe nígbà tó ń fúnni ní ẹ̀rí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 11:23-28) Ká sòótọ́, “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” ló ń jẹ́ kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè máa fara dà á lọ, pàápàá láwọn àgbègbè tí ogun àti ìwà ipá ti ń wáyé. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ṣùgbọ́n, àní lábẹ́ àwọn ipò tó le koko jù lọ pàápàá, àwọn Ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ lè sọ bí Pọ́ọ̀lù ti sọ, pé: “Olúwa dúró lẹ́bàá mi, ó sì fi agbára sínú mi, pé nípasẹ̀ mi, kí a lè ṣàṣeparí ìwàásù náà ní kíkún.” (2 Tímótì 4:17) Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù ti bá wọn ṣẹ́gun o. Yóò sì máa bá a lọ láti jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun fún wa, níwọ̀n ìgbà tí àwa bá ti pinnu láti ja ogun ìgbàgbọ́ wa ní àjàṣẹ́gun délẹ̀.—1 Jòhánù 5:4.
8, 9. (a) Àwọn ìṣẹ́gun kárí ayé wo ni ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti nípìn-ín nínú rẹ̀? (b) Ibo ni a ti rí ìdàgbàsókè tó wúni lórí gidigidi nínú iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
8 Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ti ja ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjàṣẹ́gun lábẹ́ ìtọ́sọ́nà Ọba rẹ̀ aṣẹ́gun. Ó dáàbò bo àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ̀nyí lọ́nà títayọ láìjẹ́ kí wọ́n pa rẹ́ ráúráú lọ́dún 1918, nígbà tí ètò ìṣèlú ti Sátánì ‘ṣẹ́gun’ wọn fún ìgbà díẹ̀. Nígbà tó sì di ọdún 1919, ó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó sì gbà wọ́n sílẹ̀. Lẹ́yìn náà ó wá fún wọn lókun kí wọ́n lè pòkìkí ìhìn rere náà “dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 13:7; Ìṣe 1:8.
9 Ṣáájú Ogun Àgbáyé Kejì àti lákòókò tógun yẹn ń lọ lọ́wọ́, àwọn ìjọba aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ tí wọ́n jọ ní Àjọṣepọ̀ gbìyànjú láti run àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè tí àwọn aṣáájú ìsìn, pàápàá àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Kátólíìkì, ti ṣètìlẹyìn fún àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ aninilára náà ní gbangba tàbí lábẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ẹgbẹ̀rún mọ́kànléláàádọ́rin, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́sàn-án [71,509] Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ń wàásù nígbà tí ogun náà bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1939 di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbẹ̀rún, ẹgbẹ̀ta ó lé mẹ́fà [141,606] nígbà tí ogun náà parí lọ́dún 1945, bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye tó ju ẹgbàárùn-ún [10,000] ló lo ọdún gígùn nínú ẹ̀wọ̀n àti ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì ti pa nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì. Iye àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ń fìtara wàásù kárí ayé ti pọ̀ ré kọjá mílíọ̀nù mẹ́fà lónìí. Ìdàgbàsókè pípabanbarì ti wáyé ní àwọn ilẹ̀ tí ẹ̀sìn Kátólíìkì ti rinlẹ̀ àti ní àwọn orílẹ̀-èdè tí inúnibíni tó burú jù lọ ti wáyé. Àpẹẹrẹ irú àwọn orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀ ni Jámánì, Ítálì àti Japan. Àròpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń wàásù ní orílẹ̀-èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí báyìí ti ju ọgbọ́n ọ̀kẹ́ [600,000] lọ dáadáa.—Aísáyà 54:17; Jeremáyà 1:17-19.
10. Àwọn àjàṣẹ́gun wo ni Ọba aṣẹ́gun náà ti fi bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ “nínú gbígbèjà àti fífi ìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin”?
10 Ọba wa aṣẹ́gun sì tún bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ onítara ní ti pé ó ṣamọ̀nà wọn débi pé wọ́n ja àjàṣẹ́gun púpọ̀ gan-an “nínú gbígbèjà àti fífi ìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin” ní àwọn ilé ẹjọ́ àti níwájú àwọn aláṣẹ. (Fílípì 1:7; Mátíù 10:18; 24:9) Èyí sì jẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, irú bíi ní Ọsirélíà, Ajẹntínà, Kánádà, Gíríìsì, Íńdíà, Swaziland, Switzerland, Turkey, àtàwọn ilẹ̀ mìíràn. Àwọn kan lára àádọ́ta [50] ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre sọ ọ́ gbangba pé a lẹ́tọ̀ọ́ láti polongo ìhìn rere “ní gbangba àti láti ilé dé ilé” àti pé a tún lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé a ò lọ́wọ́ sí àwọn ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà onífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni kankan. (Ìṣe 5:42; 20:20; 1 Kọ́ríńtì 10:14) Bí ọ̀nà ṣe ṣí sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìjẹ́rìí tó máa gbòòrò kárí ayé nìyẹn.
11. (a) Báwo ni Ẹni tó gẹṣin náà ṣe “parí ìṣẹ́gun rẹ̀”? (b) Ipa wo ló yẹ kí ṣíṣí tí a ṣí àwọn èdìdì kejì, ìkẹta, àti ìkẹrin ní lórí wa?
11 Báwo ni Jésù ṣe “parí ìṣẹ́gun rẹ̀”?c Gẹ́gẹ́ bá a ó ṣe rí i, ibi tó parí rẹ̀ sí ni pé ó mú ìsìn èké kúrò, ó sì ju gbogbo ìràlẹ̀rálẹ̀ ètò Sátánì tá a lè fojú rí tó kù sínú “adágún iná” ìṣàpẹẹrẹ láti pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti gbà dá Jèhófà láre pé òun ni ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Nísinsìnyí, à ń fi ìdánilójú wọ̀nà fún ọjọ́ yẹn, tí “Ọba àwọn ọba” wa yóò ja àjàṣẹ́gun ìkẹyìn lórí àjọ ìṣèlú Sátánì aninilára ní Amágẹ́dọ́nì! (Ìṣípayá 16:16; 17:14; 19:2, 14-21; Ìsíkíẹ́lì 25:17) Ní báyìí ná, Aṣẹ́gun tẹ́nikẹ́ni ò lè borí tó gun ẹṣin funfun náà ń gẹṣin nìṣó bí Jèhófà ti ń bá a lọ láti pe àwọn olóòótọ́ èèyàn wá sínú orílẹ̀-èdè òdodo Rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Aísáyà 26:2; 60:22) Ǹjẹ́ ò ń bá àwọn ẹni àmì òróró ẹgbẹ́ Jòhánù kópa nínú iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run aláyọ̀ náà tó ń gbòòrò sí i yìí? Ó dájú pé ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù rí nígbà tí Jésù ṣí èdìdì mẹ́ta tó tẹ̀ lé e nínú ìran yẹn, yóò mú kó o túbọ̀ káràmáásìkí iṣẹ́ Jèhófà fún ọjọ́ òní gan-an ni.
Wò Ó, Ẹṣin Aláwọ̀ Iná!
12. Kí ni Jésù sọ pé yóò jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba tí a kò lè fojú rí?
12 Bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé ti ń parí lọ, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ níkọ̀kọ̀ pé: “Kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” Nígbà tó máa fèsì, ó sàsọtẹ́lẹ̀ àwọn àjálù kan tí yóò jẹ́ “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà.” Jésù ní: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba; ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà, àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn àti àìtó oúnjẹ láti ibì kan dé ibòmíràn; àwọn ìran bíbanilẹ́rù yóò sì wà àti àwọn àmì ńláǹlà láti ọ̀run.” (Mátíù 24:3, 7, 8; Lúùkù 21:10, 11) Àwọn ohun tí Jòhánù rí nígbà tí a ṣí àwọn ìyókù èdìdì àkájọ ìwé náà bá àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe rẹ́gí gan-an ni. Wò ó nísinsìnyí bí Jésù tí a ti ṣe lógo ṣe ń ṣí èdìdì kejì náà!
13. Ìyàtọ̀ wo ni Jòhánù máa tó rí nínú ìlò agbára?
13 “Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kejì, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kejì wí pé: ‘Máa bọ̀!’” (Ìṣípayá 6:3) Kérúbù kejì, tí ó ní ìrísí akọ màlúù, ni ó pa àṣẹ náà. Agbára ni ànímọ́ tí èyí dúró fún, àmọ́ ó jẹ́ agbára tí a lò lọ́nà òdodo. Ṣùgbọ́n ní ìyàtọ̀ pátápátá, agbára tí wọ́n lò lọ́nà burúkú tó ń ṣekú pani lohun tí Jòhánù máa rí.
14. Ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin wo ni Jòhánù tún rí, kí sì ni ìran yìí ṣàpẹẹrẹ?
14 Ọ̀nà wo ni wọ́n wá gbà dáhùn ìkésíni kejì náà “Máa bọ̀!”? Ó jẹ́ lọ́nà yìí: “Òmíràn sì jáde wá, ẹṣin aláwọ̀ iná; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni a sì yọ̀ǹda fún láti mú àlàáfíà kúrò ní ilẹ̀ ayé kí wọ́n lè máa fikú pa ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì; a sì fún un ní idà ńlá kan.” (Ìṣípayá 6:4) Ìran tó burú jáì gan-an ni ní tòótọ́! Kò sì sí iyèméjì rárá ní ti ohun tó ṣàpẹẹrẹ: ogun ni! Kì í ṣe ogun òdodo, ìyẹn ogun àjàṣẹ́gun tí Ọba aṣẹ́gun tí Jèhófà yàn ń jà, àmọ́ ó jẹ́ ogun oníkà, táwọn èèyàn dá sílẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èyí tó kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìrora aláìnídìí. Ó bá a mu gan-an ni pé ẹṣin apọ́n-bí-iná ni ẹlẹ́ṣin yìí gùn!
15. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká ní àjọṣe kankan pẹ̀lú ẹlẹ́ṣin kejì?
15 Dájúdájú, Jòhánù kò ní fẹ́ ní àjọṣe kankan pẹ̀lú ẹlẹ́ṣin yìí àti gígùn tó ń gun ẹṣin lọ gbuurugbu, nítorí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn èèyàn Ọlọ́run pé: “Wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” (Aísáyà 2:4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jòhánù, “wà ní ayé” nígbà náà, tí ẹgbẹ́ Jòhánù àti ogunlọ́gọ̀ ńlá sì “wà ní ayé” lónìí, síbẹ̀, wọn “kì í ṣe apá kan” ètò àwọn nǹkan inú ayé tí ẹ̀jẹ̀ ti rin gbingbin yìí. Ohun ìjà tẹ̀mí la ní, ìyẹn ohun ìjà “alágbára láti ọwọ́ Ọlọ́run” tó ń jẹ́ ká lè fi aápọn pòkìkí òtítọ́, dípò tá a ó fi máa ja ogun nípa ti ara.—Jòhánù 17:11, 14; 2 Kọ́ríńtì 10:3, 4.
16. Ìgbà wo ni a fún ẹlẹ́ṣin pupa náà ní “idà ńlá kan,” báwo la sì ṣe fún un?
16 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ti wà ṣáájú ọdún 1914 tí Ẹni tó gun ẹṣin funfun náà gba adé rẹ̀. Ṣùgbọ́n “idà ńlá kan” ni wọ́n fún ẹni tó gun ẹṣin pupa nísinsìnyí. Kí ni èyí túmọ̀ sí? Láti ìgbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní ti bẹ́ sílẹ̀, ogun ẹ̀dá èèyàn ti túbọ̀ di èyí tí ẹ̀jẹ̀ rin gbingbin, tó sì túbọ̀ ń ṣèparun ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ní àárín ọdún 1914 sí 1918 táwọn èèyàn para wọn nípakúpa, àwọn ọkọ̀ afọ́nta, afẹ́fẹ́ májèlé, ọkọ̀ òfuurufú, ọkọ̀ ogun abẹ́ omi, ìbọn arọ̀jò ọta, àtàwọn ohun ìjà alágbára ni wọ́n lò, yálà kí wọ́n lò ó fún ìgbà àkọ́kọ́ tàbí kí wọ́n lò ó lọ́nà tí wọn ò gbà lò ó rí. Ní orílẹ̀-èdè tó tó méjìdínlọ́gbọ̀n ni wọ́n ti fi ipá mú gbogbo ará ìlú láti lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ ogun jíjà, tí wọn kò fi ọ̀rọ̀ ìjà ogun náà mọ sí kìkì àwọn tí ń fi ogun ṣiṣẹ́ ṣe. Iye ẹ̀mí tó ṣòfò bani lẹ́rù. Ó ju mílíọ̀nù mẹ́sàn-án àwọn jagunjagun tí wọ́n pa, àwọn ará ìlú tó kú pọ̀ lọ jàra. Àní lẹ́yìn tí ogun náà parí pàápàá, orí ilẹ̀ ayé ò padà ní àlàáfíà gidi kankan títí di báyìí. Ní ohun tó ju àádọ́ta ọdún lọ lẹ́yìn ogun yẹn, òṣèlú ará Jámánì náà Konrad Adenauer sọ pé: “Àìléwu àti ìparọ́rọ́ ti pòórá nínú ìgbésí ayé ọmọ ẹ̀dá látọdún 1914.” A yọ̀ǹda fún ẹni tó gẹṣin aláwọ̀ iná náà láti mú àlàáfíà kúrò ní ilẹ̀ ayé ní tòótọ́!
17. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, báwo ni ẹlẹ́ṣin pupa náà ṣe ti ń lo “idà ńlá”?
17 Ẹlẹ́ṣin pupa yìí gbẹ̀mí ọ̀kẹ́ àìmọye yẹn tán tàìgbà á tán báyìí ló tún bẹ́ gìjà sínú Ogun Àgbáyé Kejì. Wọ́n wá lo àwọn ohun èlò ìpakúpa tó túbọ̀ burú jáì ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, iye àwọn tó sì kú ju ìlọ́po mẹ́rin àwọn tó kú nínú Ogun Àgbáyé Kìíní. Ní 1945 bọ́ǹbù runlé-rùnnà méjì bú gbàù sórí Japan, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn run ráúráú ká tó pajú pẹ́ẹ́. Lákòókò Ogun Àgbáyé Kejì, ẹlẹ́ṣin pupa náà gbẹ̀mí àwọn tó lé ní mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́ta [55], kódà ìyẹn pàápàá kò tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ìròyìn kan tó ṣeé gbára lé sọ pé láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kejì “idà ńlá” náà ti gbẹ̀mí àwọn tó ju ogun [20] mílíọ̀nù lọ dáadáa.
18, 19. (a) Kàkà kí ìpakúpa tó ń wáyé láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kejì jẹ́ ẹ̀rí pé ìmọ̀ ẹ̀rọ àwọn ológun ti ní ìtẹ̀síwájú tó dára, ẹ̀rí kí ni ó jẹ́? (b) Ewu ńlá wo ni ó dojú kọ aráyé, ṣùgbọ́n kí ni Ẹni tó gẹṣin funfun náà yóò ṣe láti mú un kúrò?
18 Ṣé èyí wá ń fi hàn pé ìmọ̀ ẹ̀rọ àwọn ológun ti ní ìtẹ̀síwájú tó dára ni? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló jẹ́ ẹ̀rí pé ẹṣin pupa aláìláàánú náà ń bá eré rẹ̀ lọ kútúpà kútúpà. Ibo sì ni yóò parí eré sísá náà sí? Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan sọ pé yàtọ̀ sí pé àwọn èèyàn lè dìídì dá ogun tí wọ́n á ti lo ohun ìjà runlé-rùnnà tó lágbára gan-an sílẹ̀, ogun tí wọ́n á ti lo bọ́ǹbù runlé-rùnnà tiẹ̀ lè ṣèèṣì bẹ́ sílẹ̀ lójijì! Ṣùgbọ́n ó dùn mọ́ni pé èrò ti ajagunṣẹ́gun tó gun ẹṣin funfun náà yàtọ̀ síyẹn.
19 Níwọ̀n ìgbà tó bá ti jẹ́ pé ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè onígbèéraga àti ìkórìíra làwọn èèyàn fi ń ṣe gbogbo nǹkan, inú ewu ńláǹlà laráyé wà. Nítorí pé ìgbàkigbà ni ogun tí wọ́n á ti lo bọ́ǹbù runlé-rùnnà lè bẹ́ sílẹ̀. Kódà bí àwọn orílẹ̀-èdè bá tiẹ̀ fi ìbẹ̀rù kó gbogbo ohun ìjà runlé-rùnnà wọn dà nù, wọ́n á ṣì mọ̀ ọ́n ṣe. Kò ní pẹ́ sí wọn lọ́wọ́ láti tún ṣe gbogbo ohun ìjà náà padà tí wọ́n bá ní kí wọ́n ṣe é; fún ìdí yìí, ogun èyíkéyìí tí wọ́n bá ń fi àwọn ohun ìjà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ jà lè padà di ogun tí wọ́n á ti lo ohun ìjà runlé-rùnnà. Ẹ̀mí ìgbéraga àti ìkórìíra tó gbòde kan láàárín àwọn orílẹ̀-èdè lónìí máa sún aráyé láti para wọn rún pátápátá ni, àyàfi bí Ẹni tó gẹṣin funfun náà bá wá nǹkan ṣe sí àgbáàràgbá eré ti ẹṣin aláwọ̀ iná náà ń sá. Ẹ jẹ́ ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Kristi Ọba yóò gẹṣin rẹ̀ débi tí yóò fi parí ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí ayé tí Sátánì ń darí, tí yóò sì tún fìdí ilẹ̀ ayé tuntun tí ìfẹ́ yóò ti jọba múlẹ̀, ìyẹn ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fún ọmọnìkejì ẹni, èyí tó máa ń jẹ́ kí àlàáfíà jọba, tó ga jìnnàjìnnà ju àlàáfíà tipátipá táwọn orílẹ̀-èdè ń fẹ́, tí wọ́n ń tìtorí ẹ̀ fi ohun ìjà runlé-rùnnà halẹ̀ mọ́ni lóde òní táwọn èèyàn ń hùwà bí asínwín.—Sáàmù 37:9-11; Máàkù 12:29-31; Ìṣípayá 21:1-5.
Ẹṣin Dúdú Kan Bẹ́ Gìjà Jáde
20. Ìdánilójú wo la ní pé Ẹni tó gun ẹṣin funfun náà yóò wá nǹkan ṣe sí gbogbo àjálù?
20 Jésù wá ṣí èdìdì kẹta wàyí! Ngbọ́, Jòhánù, kí lo rí? “Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹta, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kẹta wí pé: ‘Máa bọ̀!’” (Ìṣípayá 6:5a) Ó dùn mọ́ni pé kérúbù kẹta yìí “ní ojú bí ti ènìyàn,” èyí tó dúró fún ìfẹ́. Ìfẹ́ tí a gbé ka orí ìlànà yóò gbilẹ̀ gidigidi nínú ayé tuntun Ọlọ́run, àní bí ànímọ́ rere yẹn ti hàn nínú ohun gbogbo tí à ń ṣe nínú ètò Jèhófà lónìí. (Ìṣípayá 4:7; 1 Jòhánù 4:16) Kí ó dá wa lójú pé Ẹni tó gun ẹṣin funfun náà, tó “gbọ́dọ̀ ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí Ọlọ́run yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀,” yóò fi ìfẹ́ mú gbogbo àjálù tí a ó máa fi han Jòhánù nísinsìnyí kúrò.—1 Kọ́ríńtì 15:25.
21. (a) Kí ni ẹṣin dúdú àti ẹni tó gùn ún ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí ló fẹ̀rí hàn pé ẹṣin dúdú náà ṣì ń sá kútúpà-kútúpà rẹ̀ kiri?
21 Kí ni Jòhánù rí lẹ́yìn náà, ní ìdáhùn sí ìkésíni kẹta náà, “Máa bọ̀!”? Ó ní: “Mo sì rí, sì wò ó! ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀.” (Ìṣípayá 6:5b) Ìyàn mímú hánhán nìyẹn o! Èyíinì lohun bíbanilẹ́rù tó wà nínú ìran alásọtẹ́lẹ̀ yìí. Ó ń tọ́ka sí báwọn nǹkan yóò ṣe rí ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Olúwa, nígbà tí a óò máa fi òṣùwọ̀n yín oúnjẹ léni lọ́wọ́. Látọdún 1914 wá ni ìyàn tó kárí ayé tí ń bá aráyé fínra. Ogun òde òní máa ń fa ìyàn gan-an lẹ́yìn tó bá parí, nítorí pé lọ́pọ̀ ìgbà, owó tí wọ́n sábà máa ń lò láti fi bọ́ àwọn aráàlú tí ebi ń pa ni wọ́n ń lò láti fi pèsè àwọn ohun ìjà ogun. Bí wọ́n ṣe má ń mú kí àwọn tó ń ṣíṣẹ́ lóko wọṣẹ́ ológun ní tipátipá, tí wọ́n máa ń ba àwọn pápá tí wọ́n ti jagun jẹ́ kanlẹ̀, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìlànà bíba dúkìá àti ilẹ̀ jẹ́ kó má bàa ṣe ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ọ̀tá láǹfààní, máa ń dín ìpèsè oúnjẹ kù gan-an ni. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní tí ebi pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kú! Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, ẹlẹ́ṣin dúdú náà, tó dúró fún ebi, kò dẹwọ́ ní òpin ogun náà. Ní àwọn ọdún 1930, mílíọ̀nù márùn-ún èèyàn ló ṣègbé lákòókò ìyàn kan ṣoṣo péré ní Ukraine. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ńṣe ni àìtó oúnjẹ àti ìyà tún pọ̀ sí i. Bí ẹṣin dúdú náà ti ń bá eré kútúpà kútúpà rẹ̀ lọ, Ìgbìmọ̀ Oúnjẹ Àgbáyé ròyìn ní àárín ọdún 1987 pé àwọn èèyàn tí iye wọn jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé méjìlá [512] mílíọ̀nù ní ń pebi mọ́nú tí ọ̀kẹ́ méjì ọmọ sí ń tipa àwọn àrùn tó jẹ mọ́ ebi kú lójoojúmọ́.
22. (a) Ìkéde wo ni ohùn kan ṣe, kí ló ni ká kíyè sára gidigidi nípa rẹ̀? (b) Kí ni iye tí owó ìlàrin òṣùwọ̀n àlìkámà kan àti ìlàrin òṣùwọ̀n mẹ́ta ọkà báálì jẹ́ ń fi hàn wá pé ó máa ṣẹlẹ̀?
22 Jòhánù ṣì lóhun púpọ̀ sí i láti sọ fún wa, ó ní: “Mo sì gbọ́ tí ohùn kan bí ẹni pé ní àárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà wí pé: ‘Ìlàrin òṣùwọ̀n àlìkámà fún owó dínárì kan, àti ìlàrin òṣùwọ̀n mẹ́ta ọkà báálì fún owó dínárì kan; má sì pa òróró ólífì àti wáìnì lára.’” (Ìṣípayá 6:6) Kérúbù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin jọ pahùn pọ̀ sọ ọ́ ni pé ó ṣe pàtàkì pé ká kíyè sára gidigidi nípa oúnjẹ tó wà nílẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bó ṣe di dandan pé káwọn èèyàn máa “jẹ oúnjẹ nípa ìwọ̀n àti nínú àníyàn ṣíṣe” ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Kristẹni. (Ìsíkíẹ́lì 4:16) Nígbà ayé Jòhánù, ìlàrin òṣùwọ̀n àlìkámà kan ni ìṣírò ìwọ̀n oúnjẹ òòjọ́ fún ọmọ ogun kan. Èló ni ìwọ̀n oúnjẹ bẹ́ẹ̀ lè náni? Dínárì kan ni, ìyẹn owó iṣẹ́ odidi ọjọ́ kan! (Mátíù 20:2)d Bí ọkùnrin kan bá ní ìdílé ńkọ́? Ó dára, òun lè ra ìlàrin òṣùwọ̀n mẹ́ta ọkà báálì tí a kò tíì ṣà dípò rẹ̀. Kódà ìdílé kékeré kan lásán ni ìyẹn lè bọ́. Àwọn èèyàn kò sì tiẹ̀ ka ọkà báálì sí oúnjẹ gidi bí àlìkámà láyé ìgbà yẹn.
23. Kí ni gbólóhùn náà, “Má sì pa òróró ólífì àti wáìnì lára” túmọ̀ sí?
23 Kí ni gbólóhùn náà, “Má sì pa òróró ólífì àti wáìnì lára,” túmọ̀ sí? Àwọn kan ti wò ó pé ó túmọ̀ sí pé nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò ṣaláìní oúnjẹ tó, tí wọn yóò sì máa pebi mọ́nú pàápàá, ìpalára kankan kò ní bá àwọn ohun táwọn ọlọ́rọ̀ fi ń ṣe fàájì. Ṣùgbọ́n ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, òróró àti wáìnì kì í ṣe nǹkan fàájì ní ti gidi. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ohun tó wọ́pọ̀ gan-an ni wọ́n ka búrẹ́dì, òróró, àti wáìnì sí. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 14:18; Sáàmù 104:14, 15.) Wọn kì í sábà rí omi tó dára, nítorí náà, wáìnì ni wọ́n máa fi ń ṣe omi mu lọ́pọ̀ ibi, nígbà mìíràn wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tó jẹ mọ́ ìṣègùn. (1 Tímótì 5:23) Ní ti òróró, ní ọjọ́ Èlíjà, bí opó Sáréfátì náà tiẹ̀ ṣe tálákà tó, òróró díẹ̀ ṣì ṣẹ́ kù nílé rẹ̀ tó máa fi se ìyẹ̀fun rẹ̀ tó ṣẹ́ kù. (1 Àwọn Ọba 17:12) Fún ìdí yìí, àṣẹ náà láti “má sì pa òróró ólífì àti wáìnì lára” jọ pé ó jẹ́ ìmọ̀ràn pé kí á má ṣe tètè lo àwọn ohun kòṣeémáàní wọ̀nyí tán, bí kò ṣe pé ká máa ṣún wọn lò. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a óò ‘pa wọ́n lára,’ èyíinì ni pé, wọn yóò tán ṣáájú kí ìyàn náà tó dópin.
24. Kí nìdí tí ẹṣin dúdú náà kò fi ní máa bá eré tó ń sá yẹn lọ fún ìgbà pípẹ́ mọ́?
24 Ẹ wo bí ayọ̀ wa ti tó pé Ẹni tó gẹṣin funfun náà yóò wá nǹkan ṣe sí eré kútúpà kútúpà tí ẹṣin dúdú náà ń sá! Ìdí ni pé ohun tó ti wà lákọọ́lẹ̀ nípa ìpèsè onífẹ̀ẹ́ Rẹ̀ fún ayé tuntun ni pé: “Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, olódodo yóò rú jáde, àti ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́. . . . Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:7, 16; tún wo Aísáyà 25:6-8.
Ẹṣin Ràndánràndán àti Ẹni Tí Ó Gùn Ún
25. Nígbà tí Jésù ṣí èdìdì kẹrin, ohùn ta ni Jòhánù gbọ́, kí sì ni èyí dúró fún?
25 Ìtàn náà kò tíì tán o. Jésù ṣí èdìdì kẹrin, Jòhánù sì sọ àbájáde rẹ̀ fún wa pé: “Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹrin, mo gbọ́ tí ohùn ẹ̀dá alààyè kẹrin wí pé: ‘Máa bọ̀!’” (Ìṣípayá 6:7) Ohùn kérúbù tó jọ ẹyẹ idì tí ń fò ni èyí. Ọgbọ́n tó ríran jìnnà ni èyí sì dúró fún. Bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, ó pọn dandan pé kí Jòhánù, ẹgbẹ́ Jòhánù, àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yòókù lórí ilẹ̀ ayé máa fara balẹ̀ wòye, kí wọ́n sì máa fi ọgbọ́n hùwà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a lè rí ààbò dé àyè kan kúrò lọ́wọ́ àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tí ń kó ìyọnu bá àwọn ọlọ́gbọ́n ayé tó wà nínú ìran agbéraga, oníwà pálapàla tòní.—1 Kọ́ríńtì 1:20, 21.
26. (a) Ta ni ẹlẹ́ṣin kẹrin, kí sì nìdí tí àwọ̀ ẹṣin rẹ̀ fi bá a mu wẹ́kú? (b) Ta ni ó ń tẹ̀ lé ẹlẹ́ṣin kẹrin, kí ni ó sì ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ń kó sínú rẹ̀?
26 Àwọn ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ mìíràn wo ló tún jáde báyìí bí ẹlẹ́ṣin kẹrin ti ń dáhùn ìpè náà? Jòhánù sọ fún wa, ó ní: “Mo sì rí, sì wò ó! ẹṣin ràndánràndán kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní orúkọ náà Ikú. Hédíìsì sì ń tẹ̀ lé e pẹ́kípẹ́kí.” (Ìṣípayá 6:8a) Ẹni tó gẹṣin ìkẹyìn náà ní orúkọ kan, ìyẹn Ikú. Nínú àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin Àpókálíìsì, òun nìkan ṣoṣo ló jẹ́ ká mọ ẹni tí òun jẹ́ ní tààràtà. Ó sì bá a mu wẹ́kú pé ẹṣin kan tí ó rí ràndánràndán ni Ikú gùn, nítorí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ náà ràndánràndán (Gíríìkì, khlo·rosʹ) nínú ìwé ẹ̀kọ́ Gíríìkì láti fi ṣàpèjúwe àwọn tí ojú wọn ti funfun bí ojú ẹni tó lárùn. Ó sì tún bá a mu wẹ́kú pé, Hédíìsì (ìyẹn ipò òkú) ń tẹ̀ lé Ikú pẹ́kípẹ́kí ní ọ̀nà kan tí a kò ṣàlàyé, nítorí pé inú Hédíìsì ni èyí tó pọ̀ jù nínú gbogbo àwọn tó tipa ìparun ẹlẹ́ṣin kẹrin kú wà. Ó dùn mọ́ni pé àjíǹde yóò wà fún àwọn wọ̀nyí, nígbà tí ‘ikú àti Hédíìsì bá jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́.’ (Ìṣípayá 20:13) Ṣùgbọ́n, báwo ni ọwọ́ Ikú ṣe ń tẹ àwọn tó ń pa?
27. (a) Báwo ni ọwọ́ ẹlẹ́ṣin náà, Ikú, ṣe ń tẹ àwọn tó ń pa? (b) Kí ni ìtumọ̀ “ìdá mẹ́rin ilẹ̀ ayé” tí Ikú ní ọlá àṣẹ lé lórí?
27 Ìran náà mẹ́nu kan díẹ̀ nínú ọ̀nà tí ọwọ́ ikú fi ń tẹ àwọn tó ń pa, ó ní: “A sì fún wọn ní ọlá àṣẹ lórí ìdá mẹ́rin ilẹ̀ ayé, láti máa fi idà gígùn pani àti àìtó oúnjẹ àti ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani àti àwọn ẹranko ẹhànnà ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 6:8b) Kì í ṣe dandan pé ìdá mẹ́rin iye àwọn tó ń gbé ayé ni ẹṣin tí wọ́n ń gùn yìí yóò nípa lé lórí bí kò ṣe ìpín ilẹ̀ ayé tó pọ̀, ó lè jẹ́ ibi táwọn èèyàn pọ̀ sí tàbí ibi táwọn tó ń gbé ibẹ̀ ò tó nǹkan. Ẹlẹ́ṣin yìí ló ń gba gbogbo àwọn tí idà ńlá ẹlẹ́ṣin kejì àti ìyàn àti àìtó oúnjẹ ti ẹlẹ́ṣin kẹta ba pá. Òun náà ń pa àwọn tirẹ̀ nípasẹ̀ ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani, ó sì tún rí àwọn mìíràn láti inú àwọn ìsẹ̀lẹ̀, irú èyí tí Lúùkù 21:10, 11 ṣàpèjúwe.
28. (a) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani” ṣe ṣẹ? (b) Báwo ni a ṣe dáàbò bo àwọn èèyàn Jèhófà kúrò lọ́wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àrùn lónìí?
28 Èyí tí ó ṣe pàtàkì níbi tí a dé yìí ni “ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani.” Gẹ́gẹ́ bí àbájáde ìparun Ogun Àgbáyé Kìíní, àrùn gágá pa ohun tí ó tó ogún mílíọ̀nù èèyàn lẹ́nu oṣù díẹ̀ péré láàárín ọdún 1918 sí 1919. Àgbègbè kan ṣoṣo lórí ilẹ̀ ayé tó yè bọ́ lọ́wọ́ àrùn tí ń ṣekú pani yìí ni erékùṣù kékeré St. Helena. Ní àwọn ibi tí àrùn náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa àwọn aráàlú tán, ńṣe ni wọ́n ń to igi jọ gègèrè láti fi jó àwọn òkú tó pọ̀ bí-ilẹ̀ bí-ẹní. Lónìí pẹ̀lú, àrùn ọkàn àti àrùn jẹjẹrẹ ti di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tó ń da jìnnìjìnnì bo àwọn èèyàn, bẹ́ẹ̀ ara tábà lílò lọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ti ń lùgbàdì àrùn wọ̀nyí. Nínú àwọn ọdún 1980 tí àwọn kan ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀wádún burúkú,” ìgbésí ayé tó lòdì lójú ohun tí Bíbélì wí tí àwọn kan ń gbé ti fi àrùn aṣekúpani tí a mọ̀ sí àrùn éèdì, kún “ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani” náà. Ní ọdún 2000, ìròyìn sọ pé ọ̀gá àgbà àwọn oníṣẹ́ abẹ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé “àfàìmọ̀ ni ò ní jẹ́ pé éèdì ni àrùn tó burú jù lọ látìgbà táláyé ti dáyé.” Ó sọ pé àádọ́ta ó lé méjì mílíọ̀nù èèyàn ló ti kó àrùn éèdì tàbí kòkòrò tó ń fà á, ogún mílíọ̀nù nínú iye yìí ló sì ti kú. Ẹ wo bí àwọn èèyàn Jèhófà ti kún fún ọpẹ́ tó pé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń pa wọ́n mọ́ kúrò nínú panṣágà àti àṣìlò ẹ̀jẹ̀ tó ń kó àrùn ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lónìí!—Ìṣe 15:28, 29; fi wé 1 Kọ́ríńtì 6:9-11.
29, 30. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ “ìgbésẹ̀ ìdájọ́ . . . mẹ́rin tí ń ṣeni léṣe” inú Ìsíkíẹ́lì 14:21 ṣe kàn wá lónìí? (b) Kí ni a lè lóye gbólóhùn náà, “àwọn ẹranko ẹhànnà,” inú Ìṣípayá 6:8 sí? (d) Kí ni ó dà bíi pé ó jẹ́ kókó pàtàkì tí ìran alásọtẹ́lẹ̀ náà ń gbìn sí wa lọ́kàn?
29 Ìran Jòhánù sọ pé àwọn ẹranko ẹhànnà ni ohun kẹrin tó máa fa ikú àìtọ́jọ́. Ní ti tòótọ́, ohun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ṣíṣí èdìdì kẹrin gbé jáde lọ́nà àkànṣe yìí, ìyẹn ogun, ìyàn, àrùn, àti àwọn ẹranko ẹhànnà ni wọ́n kà sí ohun tó sábà máa ń fa ikú àìtọ́jọ́ láyé ìgbàanì. Fún ìdí yìí, ńṣe ni wọ́n wúlẹ̀ dúró fún gbogbo ohun tó ń fa ikú àìtọ́jọ́ lónìí. Ó rí gẹ́gẹ́ bí ìkìlọ̀ tí Jèhófà ṣe fún Ísírẹ́lì ni, pé: “Bẹ́ẹ̀ ni yóò jẹ́ pẹ̀lú, nígbà tí ìgbésẹ̀ ìdájọ́ mi mẹ́rin tí ń ṣeni léṣe yóò wà—idà àti ìyàn àti aṣeniléṣe ẹranko ẹhànnà àti àjàkálẹ̀ àrùn—tí èmi ní tòótọ́ yóò rán sórí Jerúsálẹ́mù láti ké ará ayé àti ẹran agbéléjẹ̀ kúrò nínú rẹ̀.”—Ìsíkíẹ́lì 14:21.
30 Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni ìwé ìròyìn máa ń gbé ọ̀rọ̀ pé ẹranko ẹhànnà pa ẹnì kan lóde òní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ní àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nílẹ̀ olóoru, ẹranko sábà máa pa àwọn èèyàn lemọ́lemọ́. Ní ọjọ́ iwájú, àwọn ẹranko ṣì lè pààyàn jù bẹ́ẹ̀ lọ bí ogun bá ń sọ ilẹ̀ dahoro tàbí tí ìyàn bá mú àwọn èèyàn rù hangogo débi pé wọn ò lágbára láti kọjú ìjà sí àwọn ẹranko tí ebi ń pa. Ní àfikún, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn wà lónìí tó jẹ́ pé wọ́n máa ń hùwà bí ẹranko, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹranko aláìnírònú, èyí tó yàtọ̀ pátápátá sírú àwọn tí Aísáyà 11:6-9 ṣàpèjúwe wọn. Àwọn èèyàn wọ̀nyí ló sábà máa ń fa títàn tí ìwà ọ̀daràn tó jẹ mọ́ ìṣekúṣe, ìṣìkàpànìyàn, kíkó ìpayà báni, àti jíju bọ́ǹbù ń tàn káàkiri láyé òde òní. (Fi wé Ìsíkíẹ́lì 21:31; Róòmù 1:28-31; 2 Pétérù 2:12.) Ẹlẹ́ṣin kẹrin ń gba àwọn tí àwọn wọ̀nyí ń ṣekú pa pẹ̀lú. Ní ti tòótọ́, ó dà bí ẹni pé kókó pàtàkì tí ìran alásọtẹ́lẹ̀ yìí ń gbìn sí wa lọ́kàn ni pé ẹlẹ́ṣin ràndánràndán náà ń fi ikú àìtọ́jọ́ pa aráyé ní onírúurú ọ̀nà.
31. Láìfi ìparun tí àwọn tó gun ẹṣin pupa, dúdú, àti ràndánràndán fà pè, kí nìdí tá a fi lè fọkàn balẹ̀?
31 Ìsọfúnni tí a rí gbà látinú ṣíṣí tí Jésù ṣí èdìdì mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àkọ́kọ́ fi wá lọ́kàn balẹ̀ nítorí ó kọ́ wa pé ká má ṣe tìtorí ogun, ebi, àrùn, àtàwọn ohun mìíràn tó ń fa ikú àìtọ́jọ́ tó ń tàn kálẹ̀ jákèjádò lónìí bọ́hùn; bẹ́ẹ̀ ni ká má ṣe sọ ìrètí nù nítorí pé àwọn aṣáájú èèyàn kùnà láti yanjú àwọn ìṣòro ìsinsìnyí. Bí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé bá mú kó hàn kedere pé àwọn tó gun ẹṣin pupa, dúdú, àti ràndánràndán wà káàkiri lóde, má ṣe gbàgbé pé Ẹni tó gun ẹṣin funfun ni ẹni tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gun ẹṣin rẹ̀. Jésù ti di Ọba, àti pé nísinsìnyí ó ti ṣẹ́gun débi pé ó lé Sátánì kúrò ní ọ̀run. Lára ìṣẹ́gun rẹ̀ síwájú sí i ni pé ó ń kó àwọn tí wọ́n ṣẹ́ kù lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí àtàwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tí wọ́n wà jákèjádò orílẹ̀-èdè, tí iye wọn ń lọ sí ọ̀kẹ́ àìmọye, jọ pọ̀ fún líla ìpọ́njú ńlá já. (Ìṣípayá 7:4, 9, 14) Ńṣe ni yóò sì máa gẹṣin rẹ̀ nìṣó títí tí yóò fi parí ìṣẹ́gun rẹ̀.
32. Kí ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀ bí Jésù ṣe ń ṣí ọ̀kọ̀ọ̀kan èdìdì mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àkọ́kọ́?
32 Bí Jésù ṣe ń ṣí ọ̀kọ̀ọ̀kan èdìdì mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àkọ́kọ́ ni à ń gbọ́ ìkésíni náà: “Máa bọ̀!” Ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ìgbà náà ni ẹṣin kan àti ẹni tí ń gùn ún bẹ́ gìjà jáde. Bẹ̀rẹ̀ látorí èdìdì karùn-ún a kò gbọ́ irú ìpè bẹ́ẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlẹ́ṣin wọnnì ṣì ń gẹṣin lọ, wọn yóò sì máa bá eré kútúpà kútúpà náà lọ ni jálẹ̀ òpin ètò àwọn nǹkan. (Fi wé Mátíù 28:20.) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì mìíràn wo ni Jésù yóò ṣí payá bó ṣe ń ṣí èdìdì mẹ́ta tó ṣẹ́ kù? Àwọn èèyàn kò lè fojú rí àwọn kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ṣì ń bẹ ní ọjọ́ iwájú bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn lè fojú rí wọn. Àmọ́ ó dájú pé wọn yóò ní ìmúṣẹ. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí wọ́n jẹ́.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àmọ́ ṣá o, ṣàkíyèsí pé “obìnrin” inú Ìṣípayá 12:1 ní “adé” ìṣàpẹẹrẹ “oníràwọ̀ méjìlá.”
b Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé pé Jésù gba Ìjọba rẹ̀ lọ́dún 1914, wo ojú ìwé 215 sí 218 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
c Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ Bíbélì túmọ̀ gbólóhùn yìí sí “láti ṣẹ́gun” (Revised Standard, The New English Bible, King James Version) tàbí “pinnu láti ṣẹ́gun dandan” (Phillips, New International Version), lílò tí wọ́n lo ọ̀rọ̀ ìṣe atọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ láìtọ́ka àkókò (aorist subjunctive) níhìn-ín nínú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ fúnni ní èrò pé ohun náà parí tàbí pé ó dópin. Fún ìdí yìí ìwé Word Pictures in the New Testament ti Robertson sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ìṣe atọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ láìtọ́ka àkókò yìí ń fi hàn pé ó ṣẹ́gun pátápátá.”
d Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 92]
Ọba Náà Gẹṣin Ìjagunmólú
Láàárín ọdún 1930 sí 1940, àwọn ọ̀tá paraku gbìyànjú láti mú kó jọ bíi pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kò bófin mu, pé ìwà arúfin ni láti ṣe é, tàbí pé ó tiẹ̀ lè sojú ìjọba dé pàápàá. (Sáàmù 94:20) Àkọsílẹ̀ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé lọ́dún 1936 nìkan, ẹgbẹ̀rún kan ó lé mọ́kàndínláàádọ́jọ [1,149] ìgbà ni wọ́n fàṣẹ ọba mú wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí pe ọ̀pọ̀ ẹjọ́ títí fi dé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, díẹ̀ lára ẹjọ tí wọ́n sì ti borí pátápátá ló wà nísàlẹ̀ yìí.
Ní May 3, 1943, nínú ẹjọ́ tó wáyé láàárín Murdock àti Pennsylvania, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ pinnu pé àwọn Ẹlẹ́rìí kò nílò ìwé àṣẹ láti lè fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sóde kí wọ́n sì gbowó. Ní ọjọ́ yẹn kan náà, ìpinnu tí wọ́n ṣe nínú ẹjọ́ tó wáyé láàárín Martin àti Ìlú Struthers sọ pé ó bófin mu láti tẹ aago ilẹ̀kùn nígbà tá a bá ń pín àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú àti àwọn ọ̀ràn mìíràn tó jẹ mọ́ ìpolongo láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà.
Ní June 14, 1943, nínú ẹjọ́ tó wáyé láàárín Taylor àti Mississippi, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ pinnu pé àwa Ẹlẹ́rìí kò fi iṣẹ́ ìwàásù wa mú káwọn èèyàn ṣàì dúró ṣinṣin ti ìjọba. Ní ọjọ́ yẹn kan náà, nínú ẹjọ́ tó wáyé láàárín Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ètò Ẹ̀kọ́ ní Ìpínlẹ̀ West Virginia àti Barnette, Ilé Ẹjọ́ sọ pé àjọ ilé ẹ̀kọ́ kò ní ẹ̀tọ́ láti lé àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n kọ̀ láti kí àsíá jáde kúrò ní ilé ẹ̀kọ́. Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e gan-an, Ilé Ẹjọ́ Gíga Ọsirélíà mú òfin tí wọ́n fi de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè yẹn kúrò, wọ́n ní “òfin àdábọwọ́, ìgbésẹ̀ oníwàǹwára àti aninilára ni.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 94]
‘A Yọ̀ǹda fún Un Láti Mú Àlàáfíà Kúrò ní Ilẹ̀ Ayé’
Ibo ni ìmọ̀ ẹ̀rọ ń sin ayé yìí lọ? Ní January 22, 1987, ìwé ìròyìn The Globe and Mail ti Tòróńtò, Kánádà, ròyìn nǹkan wọ̀nyí láti inú ọ̀rọ̀ kan tí Ivan L. Head, ààrẹ Ibùdó Ìwádìí Lórí Ìdàgbàsókè Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ:
“Lọ́nà tó ṣeé gbára lé, a díwọ̀n rẹ̀ pé ọ̀kan nínú mẹ́rin gbogbo àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àti onímọ̀ ẹ̀rọ nínú ayé tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ìwádìí àti ìdàgbàsókè ní ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn ohun ìjà. . . . Ní ìdíwọ̀n ti ọdún 1986, owó tí wọ́n ń ná lórí nǹkan wọ̀nyí ju mílíọ̀nù kan ààbọ̀ dọ́là lọ ní ìṣẹ́jú kọ̀ọ̀kan. . . . Ǹjẹ́ gbogbo kìràkìtà lórí ìmọ̀ ẹ̀rọ yìí ń fi hàn pé ààbò túbọ̀ wà fún gbogbo wa? Àkójọ ohun ìjà runlé-rùnnà tí àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan tó jẹ́ alágbára ní lọ́wọ́ báyìí lágbára ju àpapọ̀ gbogbo ohun ọlọ́ṣẹ́ tí àwọn jagunjagun lò nínú Ogun Àgbáyé Kejì lọ lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000]. Ìyẹn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà Ogun Àgbáyé Kejì. Láti 1945 wá, ọ̀sẹ̀ méje péré ni ìgbòkègbodò ológun kò fi ṣẹlẹ̀ láyé. Ó lé ní àádọ́jọ [150] ogun láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tàbí ogun abẹ́lé táwọn èèyàn ti jà, èyí tí a díwọ̀n rẹ̀ pé ó ti mú ẹ̀mí tó ju ogún [20] mílíọ̀nù lọ. Ohun tó sì jẹ́ kí wọ́n lè gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn yìí ni ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun tó gbéṣẹ́ tó wà lóde báyìí lákòókò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tá a wà yìí.”
Nígbà tó fi máa di ọdún 2005, iye ẹ̀mí tí ìgbòkègbodò àwọn ológun ti mú lọ lé ní ogún [20] mílíọ̀nù dáadáa.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 98, 99]
Bá A Ṣe Ṣètò Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìṣípayá
Ní ibi tá a dé yìí nínú ìjíròrò wa nípa ìwé Ìṣípayá, a ti bẹ̀rẹ̀ sí í rí ọ̀nà tá a gbà ṣètò àwọn ohun tó wà nínú ìwé náà lọ́nà tó túbọ̀ ṣe kedere. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ àkọ́sọ tó ń runi sókè (Ìṣípayá 1:1-9), a lè sọ pé ìwé Ìṣípayá pín sí ìran mẹ́rìndínlógún gẹ́gẹ́ bá a ṣe tò wọ́n sísàlẹ̀ yìí:
ÌRAN KÌÍNÍ (1:10–3:22): Nípa ìmísí, Jòhánù rí Jésù tá a ti ṣe lógo, ẹni tó fi àwọn lẹ́tà ìmọ̀ràn ọlọ́yàyà ránṣẹ́ sí ìjọ méje.
ÌRAN KEJÌ (4:1–5:14): Ìran ìtẹ́ ológo ti Jèhófà Ọlọ́run ní ọ̀run. Jèhófà fi àkájọ ìwé kan fún Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.
ÌRAN KẸTA (6:1-17): Bí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ṣe ń ṣí àwọn èdìdì mẹ́fẹ̀ẹ̀fà àkọ́kọ́ ti àkájọ ìwé náà ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, ó ń ṣàfihàn ìran tó ní àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ púpọ̀ nínú, ìyẹn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ Olúwa. Àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin Àpókálíìsì gẹṣin jáde, àwọn ajẹ́rìíkú ẹrú Ọlọ́run gba aṣọ funfun, a sì ṣàpèjúwe ọjọ́ ìkannú ńlá náà.
ÌRAN KẸRIN (7:1-17): Àwọn áńgẹ́lì fawọ́ ẹ̀fúùfù ìparun sẹ́yìn títí a óò fi fi èdìdì di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tó jẹ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Ogunlọ́gọ̀ ńlá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè fi hàn pé ọlá Ọlọ́run àti ti Kristi làwọn fi rí ìgbàlà, a sì kó wọn jọ pọ̀ fún líla ìpọ́njú ńlá já.
ÌRAN KARÙN-ÚN (8:1–9:21): Nígbà tí a ṣí èdìdì keje, ìró kàkàkí méje dún, mẹ́fà àkọ́kọ́ nínú ìró kàkàkí náà ni ìran karùn-ún. Ìró kàkàkí mẹ́fẹ̀ẹ̀fà wọ̀nyí polongo àwọn ìfihàn ìdájọ́ Jèhófà lórí aráyé. Kàkàkí karùn-ún àti ìkẹfà pẹ̀lú nasẹ̀ àwọn ègbé kìíní àti èkejì.
ÌRAN KẸFÀ (10:1–11:19): Áńgẹ́lì alágbára kan fún Jòhánù ní àkájọ ìwé kékeré kan, a díwọ̀n tẹ́ńpìlì náà, a sì gbọ́ ìrírí àwọn ẹlẹ́rìí méjì. Ó parí pẹ̀lú fífun kàkàkí keje, tó polongo ègbé kẹta fún àwọn ọ̀tá Ọlọ́run, ìyẹn Ìjọba Jèhófà àti ti Kristi rẹ̀ tí ń bọ̀.
ÌRAN KEJE (12:1-17): Èyí ṣàpèjúwe ìbí Ìjọba náà, èyí tó yọrí sí fífi tí Máíkẹ́lì fi ejò náà, Sátánì, sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé.
ÌRAN KẸJỌ (13:1-18): Ẹranko ẹhànnà alágbára náà jáde wá látinú òkun, ẹranko oníwo méjì bíi ti ọ̀dọ́ àgùntàn sì rọ aráyé láti jọ́sìn ẹranko ẹhànnà náà.
ÌRAN KẸSÀN-ÁN (14:1-20): Ìran àgbàyanu nípa bí ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ṣe máa wà ní Òkè Síónì. Ìhìn àwọn áńgẹ́lì la gbọ́ káàkiri ayé, a kórè àjàrà ilẹ̀ ayé, a sì tẹ ìfúntí ìbínú Ọlọ́run.
ÌRAN KẸWÀÁ (15:1–16:21): A tún rí àgbàlá ọ̀run fìrí lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ̀yìn èyí ni wọ́n tú àwokòtò méje ti ìbínú Jèhófà jáde sórí ilẹ̀ ayé. Àpèjúwe alásọtẹ́lẹ̀ nípa òpin ètò Sátánì ló sì parí ẹ̀ka yìí pẹ̀lú.
ÌRAN KỌKÀNLÁ (17:1-18): Aṣẹ́wó ńlá náà, Bábílónì Ńlá, ń gun ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò kan, èyí tó lọ sínú ọ̀gbun fún ìgbà kúkúrú ṣùgbọ́n tó jáde wá lẹ́ẹ̀kan sí i tó sì wá pa á run.
ÌRAN KEJÌLÁ (18:1–19:10): Wọ́n kéde ìṣubú àti ìparun ìkẹyìn Bábílónì Ńlá. Lẹ́yìn tá a fikú pa á, àwọn kan ń ṣọ̀fọ̀, àwọn kan ń fi ìyìn fún Jèhófà; a kéde ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn.
ÌRAN KẸTÀLÁ (19:11-21): Jésù ṣáájú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run láti mú ìdájọ́ tó kún fún ìkannú Ọlọ́run ṣẹ sórí ètò Sátánì, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, àwọn alátìlẹyìn rẹ̀; àwọn ẹyẹ jòkújòkú ń jẹ òkú wọn.
ÌRAN KẸRÌNLÁ (20:1-10): Jíju Sátánì Èṣù sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi àti àwọn ọba ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ìdánwò ìkẹyìn fún aráyé, àti ìparun Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀.
ÌRAN KẸẸ̀Ẹ́DÓGÚN (20:11–21:8): Àjíǹde gbogbo gbòò àti Ọjọ́ Ìdájọ́ ńlá náà; ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan fara hàn, pẹ̀lú àwọn ìbùkún ayérayé fún aráyé olódodo.
ÌRAN KẸRÌNDÍNLÓGÚN (21:9–22:5): Ìran ológo nípa Jerúsálẹ́mù Tuntun, aya Ọ̀dọ́ Àgùntàn, ló parí Ìṣípayá. Ìpèsè Ọlọ́run fún ìmúláradá àti ìwàláàyè aráyé ń ṣàn wá látinú ìlú ńlá yẹn.
Ìṣípayá parí pẹ̀lú ìkíni ọlọ́yàyà àti ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ Jèhófà, Jésù, áńgẹ́lì náà àti Jòhánù fúnra rẹ̀. Ìpè tó wà fún gbogbo èèyàn ni pé “Máa bọ̀!”—Ìṣípayá 22:6-21.