Ori 16
“Ogunlọgọ Nla Eniyan” Kókìkí Ọba Naa
1, 2. (a) Bawo ni Jehofa ṣe tẹsiwaju lati mú asọtẹlẹ rẹ̀ tí ó wà ninu Isaiah 60:22 ṣẹ? (b) Iṣipaya otitọ atọrunwa tí ó pẹtẹrí wo ni a ṣe ní 1935?
NIPASẸ wolii rẹ̀, Jehofa kede pe: “Ẹni kekere kan yoo di ẹgbẹrun, ati kekere kan di alagbara orilẹ-ede: emi Oluwa yoo ṣe é kánkán ní akoko rẹ̀.” (Isaiah 60:22) Lọna agbayanu, Jehofa nitootọ bẹrẹsii “ṣe é kánkán.” Ní 1935 awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pejọ si apejọpọ ní Washington, D.C., U.S.A. Nibẹ ni a ti sọ ọ di mímọ̀ ní kedere pe Jehofa ti bẹrẹsii ṣe ikojọpọ “ogunlọgọ nla eniyan” ti awọn “agutan miiran”—awọn eniyan olubẹru Ọlọrun tí yoo jèrè ìyè ainipẹkun lori ilẹ̀-ayé tí a sọ di paradise, nipasẹ ‘dídé’ Ijọba Ọlọrun.—Johannu 10:16; Ìfihàn 7:9, NW.
2 Ìfihàn ori 7 ṣapejuwe rẹ̀ lọna yii: “Lẹhin” fifi èdìdí dí “agbo kekere” naa tí awọn àjògún Ijọba, tí iye wọn jẹ́ 144,000, “ogunlọgọ nla eniyan tí ẹnikẹni kò lè kà, lati inu orilẹ-ede gbogbo, ati ẹya ati eniyan ati lati inu ede gbogbo wa” ni a rí tí wọn duro niwaju ìtẹ́ Ọlọrun. Wọn tẹwọgba ipò ọba-aláṣẹ Jehofa gẹgẹ bi a ti lò ó nipasẹ Kristi rẹ̀. Pẹlu idunnu ni wọn fi fi ọla igbala fun Ọlọrun ati fun Ọ̀dọ́-agutan naa. Gẹgẹ bi agbo kan, wọn kò nilati kú lae, nitori pe awọn ni ó “jade wá lati inu ipọnju nla” lati jogun ìyè ainipẹkun ninu ilẹ̀-ayé tí a ti fọ̀mọ́.—Ìfihàn 7:4, 9, 10, 14, NW; Luku 12:32.
3. (a) “Ẹni kekere” naa ha ti di “ẹgbẹrun” nitootọ bi? (b) Bawo ni iwọ ṣe lè nípìn-ín ninu imuṣẹ Ìfihàn 7:15-17?
3 Iwọ ha ti mú iduro rẹ laaarin “ogunlọgọ nla eniyan” olujọsin yii lonii bi? Iwọ ha jẹ́ ọ̀kan lara awọn eniyan 4,000,000 ati jù bẹẹ lọ wọnyi ‘tí ń ṣe iṣẹ-isin mímọ́ fun Ọlọrun’ jakejado ayé bi? Nitootọ, ayé buruku Satani tí ń pọ́nnilójú ṣì yí ọ ká sibẹ, iwọ sì nilati farada ọpọlọpọ ikimọlẹ ninu igbesi-aye rẹ ojoojumọ. Ṣugbọn bi iwọ bá jẹ́ ọ̀kan lara “awọn agutan” Oluwa, iwọ wà labẹ aabo Ọlọrun. Ebi tabi oungbẹ kò tún nilati gbẹ ọ mọ́ fun awọn ohun ìgbẹ́mìíró tẹmi. Iwọ kò tún ní bẹru ibinu Ọlọrun tí ń jóni, nitori pe Ọdọ-agutan naa ń ṣe oluṣọ-agutan rẹ, ó sì ń ṣamọna rẹ lọ si ibi “orisun omi ìyè.” Nipa bayii, lọna iṣapẹẹrẹ, iwọ ni lọwọlọwọ ti ń ṣalabaapin ninu imuṣẹ ileri naa pe: “Ọlọrun yoo sì nù omije gbogbo nù kuro ní oju wọn.”—Ìfihàn 7:15-17.
ỌBA NAA BUKUN “AWỌN AGUTAN” RẸ̀
4. Ki ni ibatan tí ó wà laaarin Jesu ati “agbo kekere” rẹ̀?
4 Ní akoko Bibeli, àní titi di ọjọ wa paapaa, oluṣọ-agutan ara Gábàsì kan gbadun irẹpọ timọtimọ pẹlu awọn agutan rẹ̀. Ó pe ọkọọkan wọn ní orukọ, wọn sì mọ̀ ohùn rẹ̀ wọn sì tètè ń dahunpada láìjáfara bi ó ti ń dà wọn wọle tí ó sì ń dà wọn jade ninu ọgbà-àgùtàn naa. Jesu ninu Johannu ori 10 lò eyi nigba tí ó ń ṣe apejuwe, lakọọkọ, ipo-ibatan onifẹẹ tí ó wà laaarin araarẹ̀ ati “agbo kekere” ti 144,000 awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ẹni-ami-ororo, ní wiwi pe: “Emi ni oluṣọ-agutan rere, mo sì mọ̀ awọn temi, awọn temi sì mọ̀ mi. Gẹgẹ bi Baba ti mọ̀ mi, tí emi sì mọ̀ Baba; mo sì fi ẹmi mi lélẹ̀ nitori awọn agutan.” Awọn wọnyi di apakan “iru-ọmọ Abrahamu,” nipasẹ ẹni tí “gbogbo idile ayé” yoo ti bukun fun araawọn.—Johannu 10:14, 15; Genesisi 12:3; Galatia 3:28, 29.
5. (a) Iru ipo-ibatan alayọ wo ni a tọka siwaju sii ninu Johannu 10:16? (b) Awọn anfaani wo ni “awọn agutan miiran” ń gbadun nisinsinyi, kí sì ni ireti tí ń bẹ niwaju fun ẹgbẹ yii?
5 Nigba naa, ki ni ibatan tí ó wà laaarin “oluṣọ-agutan rere” naa ati awọn idile araye tí wọn yoo walaaye titilae lori ilẹ̀-ayé? Ọ̀kan ti ó jẹ́ onibukun julọ! Nitori pe Jesu wi nipa awọn wọnyi pe:
“Emi sì ní awọn agutan miiran, tí kii ṣe ti agbo yii [ti “agbo kekere” naa]; awọn ni emi kò lè ṣe aláìmúwá pẹlu, wọn yoo sì gbọ́ ohùn mi; wọn yoo sì jẹ́ agbo kan, oluṣọ-agutan kan.”
Lonii, “ogunlọgọ nla eniyan” ti awọn “agutan miiran” wọnyi ni a lè rí bi wọn ti ń jẹ koriko papọ pẹlu “agbo kekere” naa—tí gbogbo wọn ń fi pẹlu isopọṣọkan ṣe igbọran si “ohùn” oluṣọ-agutan wọn ní wiwaasu “ihinrere ijọba yii ní gbogbo ayé lati ṣe ẹ̀rí fun gbogbo orilẹ-ede.” Ayọ ni ìpín rẹ bi iwọ bá jẹ́ ọ̀kan lara awọn wọnyi! (Johannu 10:16; Matteu 24:14) Labẹ iṣakoso Ijọba naa, iye “awọn agutan miiran” yoo pọ si i wọ inu ọpọ billion nipasẹ ajinde awọn oku araye tí ó ti kú, bi ete Ọlọrun lati kún ilẹ̀-ayé pẹlu awọn eniyan olododo ti ń tẹsiwaju si àṣepé rẹ̀.—Genesisi 1:28.
6. Bawo ni asọtẹlẹ Jesu ṣe tọkasi ìgbà tí “awọn agutan miiran” wa sojutaye?
6 Pé “awọn agutan miiran” wa sojutaye ni ‘ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan’ yii ni a fihan nipasẹ apejuwe yii tí Jesu fi pari asọtẹlẹ rẹ̀ nipa “ami” wíwàníhìn-ín rẹ̀. (Matteu 24:3) Ó wi pe:
“Nigba ti Ọmọ eniyan yoo wá ninu ògo rẹ̀, ati gbogbo awọn angẹli mímọ́ pẹlu rẹ̀, nigba naa ni yoo jokoo lori ìtẹ́ ògo rẹ̀. Niwaju rẹ̀ ni a ó sì kó gbogbo orilẹ-ede jọ: yoo sì yà wọn si ọ̀tọ̀ kuro ninu araawọn, gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti ń yà agutan rẹ̀ kuro ninu ewurẹ. Oun yoo sì fi agutan si ọwọ ọ̀tún rẹ̀, ṣugbọn awọn ewurẹ si ọwọ́ òsì.” (Matteu 25:31-33)
Niwọn bi Ọba ológo naa ati awọn angẹli rẹ̀ ti jẹ́ aláìṣeefojúrí fun eniyan, bawo ni ó ṣe ń ṣe iṣe iyasọtọ naa?
7. (a) Bawo ni a ṣe ń dari iṣẹ iyasọtọ naa? (b) Ki ni iwọ gbọdọ ṣe lati lè rí idajọ tí ó dara gbà, eesitiṣe?
7 Awọn angẹli mímọ́ ni wọn ń pese ìdarísọ́nà fun iṣẹ yẹn. (Ìfihàn 14:6-12; fiwe Iṣe 8:26-29; 10:1-8.) Níhìn-ín lori ilẹ̀-ayé iyoku ninu “agbo kekere” naa, tí a pè ní “awọn arakunrin” Ọba naa ninu Matteu 25:40, ń mú ipo-iwaju ninu wiwaasu “ihinrere.” Ọba naa ń ṣe idajọ awọn eniyan ní ibamu pẹlu ihuwapada wọn si “awọn arakunrin” rẹ̀ ati ìhìn-iṣẹ́ Ijọba tí wọn ń pokiki. Ohun tí wọn bá ṣe sí “awọn arakunrin” rẹ̀ ni ó kàsí eyi tí wọn ṣe sí oun. Awọn eniyan tí wọn tẹwọgba “awọn arakunrin” Ọba naa pẹlu ifẹ alejo wà ní ìlà fun ibukun. Iwọ ha jẹ́ ọ̀kan lara awọn wọnyi bi? Dajudaju, o gbọdọ ṣe e ni aṣepari, ní titẹwọgba ìhìn-iṣẹ́ Ijọba naa tọkantọkan ati ní didi iranṣẹ Jehofa tí a yasimimọ tí ó sì ṣe baptisi, ní orukọ Jesu—nitori pe “kò sì sí igbala lọdọ ẹlomiran.”—Iṣe 4:12; Matteu 25:35-40.
8. Ninu ikesini ati awọn ileri wo ni iwọ lè ṣe ajọpin?
8 Gẹgẹ bi ọ̀kan lara “awọn agutan miiran” Oluwa, ki ni iwọ lè fojusọna fun? Ki ni yoo jẹ iyọrisi ṣiṣe tí iwọ ń ṣe igbọran si “ohùn” “oluṣọ-agutan rere” ati “ọba” naa? Ni kikede idajọ, Ọba naa wi fun “awọn agutan” onirẹlẹ tí ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún ojurere rẹ̀ pe: “Ẹ wá, ẹyin alabukun-fun Baba mi, ẹ jogún ijọba, tí a ti pese silẹ fun yin lati ọjọ ìwà.” Iwọ lè reti ṣiṣalabaapin ninu awọn ibukun Ijọba wọnyi tí ń jade wá lati ọ̀dọ̀ Baba wa, bi ‘awọn olododo ti ń kọja lọ sinu ìyè ainipẹkun.’ (Matteu 25:34, 46) Bẹẹni, iwọ lè reti lati ṣe alabaapin ninu imuṣẹ ọpọlọpọ awọn ileri alasọtẹlẹ, bi irufẹ eyi tí ó wà ninu Isaiah, tí ó wí nipa Jehofa pe: “Oun yoo gbé iku mì laelae; Oluwa Jehofa yoo nù omije nù kuro ní oju gbogbo eniyan; yoo sì mú ẹ̀gàn eniyan rẹ̀ kuro ní gbogbo ayé: nitori Oluwa ti wí i.” Awọn eniyan buruku lè pẹ̀gàn rẹ fun kiki igba diẹ sii ni. Nitori pe ileri Ọlọrun ni pe gbogbo ẹni tí ó bá ní ireti ninu Jehofa ni yoo gbadun “àsè” ọlọ́ràá ti awọn ohun rere ninu “ayé titun” laipẹ. Iwọ fẹ́ lati ṣe alabaapin ninu “àsè” naa, àbí bẹẹkọ?—Isaiah 25:6-9; 66:22.
“AWỌN EWURẸ” ATI AWỌN INUNIBINI
9, 10. (a) Eeṣe tí kò fi rọrun lati lepa ododo lonii? (b) Iṣarasihuwa wo ni ó yẹ ki o ní si awọn alatako, iranlọwọ wo ni iwọ sì lè reti lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun?
9 Ó lè má rọrun fun ọ lati lepa ipa-ọna ododo ni “awọn ọjọ ikẹhin” wọnyi. Satani ati awọn ẹni tí oun ti tanjẹ lè fi ọ ṣẹ̀sín, bi wọn ti ń ṣe gbogbo isapa onigbekuta wọn ikẹhin lati pa ayé yii ati araye tí ń bẹ lori rẹ̀ run. (2 Peteru 3:3, 4; 2 Timoteu 3:1) Nigba tí iwọ bá ṣe ikesini sí awọn aladuugbo rẹ pẹlu ìhìn-iṣẹ́ Ijọba naa, iwọ lè rí awọn kan tí ń fi iṣarasihuwa bii ti ewurẹ hàn. Eyi ni wọn ń ṣe nipa fifi aibikita tabi àìmọ̀wàáhù hàn, tabi nipasẹ atako ojúkojú.—Matteu 25:33, 42-45.
10 Àmọ́ ṣáá o, gẹgẹ bi ọ̀kan lara “awọn agutan” Oluwa, iwọ kò gbọdọ gbiyanju lati ṣèdájọ́ ẹni tí ó lè jẹ́ “ewurẹ.” Ti Ọba ni, kii ṣe ti “awọn agutan” rẹ̀ níhìn-ín lori ilẹ̀-ayé, lati ṣe idajọ. (Fiwe Romu 14:10-12.) Ati pe, bi ó tilẹ jẹ́ pe iwọ lè bá atako pade nitori jíjẹ́ tí iwọ jẹ́ olupokiki “ihinrere” naa, Ọlọrun yoo fun ọ lókun lati ṣe ifẹ-inu rẹ̀, gẹgẹ bi aposteli Peteru ti tọka ninu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi: “Ọlọrun ore-ọfẹ gbogbo . . . yoo sì ṣe yin ní àṣepé, yoo fi ẹsẹ yin mulẹ, yoo fun yin ní agbara.” (1 Peteru 5:10; fiwe 2 Korinti 12:10.) Pẹlupẹlu, aposteli Paulu funni ní ìṣílétí rere yii: “Niti iṣẹ [Ijọba] ṣiṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ maa ni ìgbóná ọkàn; ẹ maa sin Oluwa; ẹ maa yọ̀ ni ireti; ẹ maa mú suuru ninu ipọnju; ẹ maa duro gangan ninu adura.”—Romu 12:11, 12.
11. Ki ni ó lè jẹ́ abajade alayọ ti ìwà awokọṣe Kristian kan?
11 Iṣẹ-isin aduroṣinṣin ati adura atọkanwa rẹ si Jehofa, papọ pẹlu iwa Kristian alapẹẹrẹ rere rẹ, lè yọrisi mímú awọn kan tí wọn farahan lakọọkọ bi “ewurẹ” yipada di “agutan” nikẹhin. Suuru ati iwa-irẹlẹ awọn aya Kristian ti saba maa ń gbéṣẹ́ ní jijere awọn ọkọ alaigbagbọ “ní àìsọ̀rọ̀.” (1 Peteru 3:1, 2) Dajudaju awa kò fẹ́ rí ki awọn eniyan ‘kọja lọ sinu ikekuro ainipẹkun,’ ṣugbọn, kàkà bẹẹ, awa yoo fẹ́ lati ràn wọn lọwọ lati fi awọn iwa-bi-ewurẹ silẹ, ki wọn baa lè rí ìyè ainipẹkun gbà.—Matteu 25:41, 46.
“AWỌN AGUTAN” ADUROṢINṢIN PA IWATITỌ MỌ́
12. Bawo ni “awọn arakunrin” Ọba naa ati “awọn agutan” ṣe ṣetilẹhin fun araawọn lẹnikinni-keji ní akoko ode-oni?
12 A nilati ṣakiyesi rẹ̀ pe “awọn agutan” inu akawe Jesu gbiyanju gidigidi lati ṣe iranṣẹ fun “awọn arakunrin” Ọba naa nigba tí awọn wọnyi ń ṣaisan ati nigba tí wọn wà ninu ọgbà-ẹ̀wọ̀n. Ati ní awọn ibikan lori ilẹ̀-ayé lonii, fifi ohun koṣeemani igbesi-aye du ni ati inunibini, aisan ati ìfisẹ́wọ̀n ti jẹ́ iriri kii ṣe ti kìkì “agbo kekere” nikan ni ṣugbọn ti “awọn agutan miiran” pẹlu tí wọn ń fi pẹlu iduroṣinṣin ati iṣọkan ṣiṣẹsin pẹlu wọn. Fun apẹẹrẹ, ní 1933 si 1945, nigba tí Hitler oludasilẹ ẹgbẹ oṣelu Nazi ń ṣe ìgbétáásì rẹ̀ lati jọba lori ayé, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jiya inunibini kíkorò—lakọọkọ ni awọn orilẹ-ede tí ó jẹ́ ti Nazi ati Fascist ati lẹhin naa ni gbogbo awọn orilẹ-ede tí ń jagun. Pupọ, “agbo kekere” ati “awọn agutan miiran” ti Oluwa, ni a pa. Ṣugbọn wọn ṣẹgun lọna iyanu ní didi ìwàtítọ́ wọn mú láìyẹsẹ̀ si Ọba naa ati Ijọba rẹ̀!
13, 14. Iyatọ wo ni a ti ṣakiyesi laaarin iduro isin Kristẹndọm ati ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa?
13 Iyatọ ti o wà laaarin ipò ijuwọsilẹ awọn onisin Kristẹndọm ati ìwàtítọ́ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa labẹ ikimọlẹ ni awọn opitan ti sọrọ lélórí lọpọ igba. Fun apẹẹrẹ, ninu iwe naa A History of Christianity, tí a tẹjade ní London, England, ní 1976, lakọọkọ Paul Johnson sọ nipa awọn ṣọọṣi Katoliki ati awọn ṣọọṣi Ajihinrere ní Germany labẹ iṣakoso Hitler pe: “Awọn ṣọọṣi mejeeji ní gbogbogboo, ṣe itilẹhin tí ó kàmàmà fun ijọba naa. Awọn biṣọbu Katoliki faramọ ‘itẹnumọ titun, ti o lagbara lori ọla-aṣẹ ní orilẹ-ede Germany’; Biṣọbu Bornewasser sọ fun awọn ọ̀dọ́ Katoliki ní Cathedral ti Trier pe: ‘Pẹlu gbígbé ori wa soke ati igbesẹ fifẹsẹ mulẹ gbọnyin awa ti wọnú ijọba titun naa a sì ti muratan lati ṣiṣẹsin in pẹlu gbogbo agbara inu wa ati ọkàn wa.’ Ní January 1934, Hitler rí awọn aṣaaju Ajihinrere mejila, ati lẹhin ipade yii wọn . . . gbé ikede kan jade eyi tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ pe ‘awọn aṣaaju Ṣọọṣi Ajihinrere ti Germany fi pẹlu ìfìmọ̀ṣọ̀kan kede iduroṣinṣin wọn aláìyẹsẹ̀ fun Eto Ijọba Nazi ati aṣaaju rẹ̀.’”
14 Lẹhin naa, nipa awọn kereje tí wọn jẹ́wọ́ pe awọn jẹ Kristian awọn ti ó sọ pe wọn “rọ̀mọ́ awọn ilana wọn,” òǹkọ̀wé naa tẹsiwaju lati wi pe: “Awọn ti o jẹ akínkanjú julọ ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, awọn tí wọn kede ilodisi wọn delẹdelẹ lori ipilẹ ẹkọ wọn lati ibẹrẹ tí wọn sì jìyà nitori eyi. Wọn kọ̀jálẹ̀ lati fọwọsowọpọ lọnakọna pẹlu ijọba Nazi eyi tí wọn dalẹbi bi eyi ti o jẹ́ ti ibi patapata. . . . A dájọ́ iku fun ọpọlọpọ nitori kíkọ̀ lati tẹwọgba iṣẹ ológun . . . ; tabi ki wọn pari rẹ̀ si Dachau tabi ile-itọju wèrè. Idamẹta ni a pa niti gidi; ìpín mẹtadinlọgọrun-un ninu ọgọrun-un wọn jiya inunibini lọna kan tabi omiran. Awọn ni kìkì awujọ Kristian tí Himmler gboriyin fun.”
15. (a) Ki ni ihuwapada rẹ si lẹta awokọṣe naa ti o wà níhìn-ín? (b) Ki ni isapa Satani nigba Ogun Agbaye II, kí sì ni ẹ̀rí pe ó kùnà?
15 Wọn kò ṣe bẹẹ gẹgẹ bi awọn tí wọn gbagbọ pe awọn funraawọn lè fopinsi ogun, ṣugbọn gẹgẹ bi awọn Kristian aláìdásítọ̀túntòsì tí wọn ń ṣetilẹhin fun Ijọba Ọlọrun tí ń bọ̀, awọn ọdọ Ẹlẹ́rìí dojukọ ifisẹwọn ati ìfìyà-jẹni dipo ki wọn bà ìwàtítọ wọn jẹ́, gẹgẹ bi ‘lẹta ikẹhin’ kan tí ó farahan níhìn-ín yii ti fẹ̀rí hàn. Jakejado ilẹ̀-ayé, ìbáà ṣe ní awọn orilẹ-ede Alajọṣepọ ninu iṣelu tabi ti awọn Aládèéhùn Ifọwọsowọpọ, “awọn arakunrin” Ọba naa ati “awọn agutan” ẹlẹgbẹ wọn ni awujọ awọn eniyankeniyan ti kọlu, tí a lùbolẹ̀, tí a fisẹwọn tí a sì hùwà ìkà sí. Ṣugbọn wọn ṣẹgun ninu ogun-jíjà wọn tẹmi. Eṣu kò lè fọ́ iduroṣinṣin wọn fun Ijọba naa. Gẹgẹ bi ti Jesu ṣaaju wọn, wọn fi araawọn hàn gẹgẹ bi awọn tí kii ṣe “ti ayé” Satani.—Johannu 15:19.
ITOLẸSẸẸSẸ ẸKỌ IJỌBA NAA
16, 17. (a) Ki ni itolẹsẹẹsẹ ẹkọ ati imugbooro iṣẹ tí ó ṣísílẹ̀ nisinsinyi? (b) Eso iṣẹ yii wo ni a lè kiyesi?
16 Ààrẹ Watch Tower Society, J. F. Rutherford, kú ní 1942, tí Nathan H. Knorr sì rọ́pò rẹ̀. Laipẹ laijinna, a gbé awọn Ile-ẹkọ Iṣẹ-ojiṣẹ Iṣakoso Ọlọrun kalẹ ni gbogbo awọn ijọ Ẹlẹ́rìí Jehofa, awọn wọnyi sì ti ṣiṣẹ lọna tí kò ṣeédíyelé ní kíkọ́ awọn Ẹlẹ́rìí lọkunrin ati lobinrin lati sọ ìhìn-iṣẹ́ Ijọba naa fun awọn ẹlomiran lọna tí ó gbéṣẹ́ ati eyi tí ó tubọ ń yinilọkanpada. Là awọn ọdun kọja, oniruuru awọn ìwé ẹkọ ni a ti pese fun awọn ile-ẹkọ wọnyi. Bẹẹ ni a kò sì gbojufo pápá-oko ìjíhìn-iṣẹ́-Ọlọrun ni ilẹ ajeji dá. Ní February 1, 1943, a dá Watchtower Bible School of Gilead silẹ ní Ipinlẹ New York. Lati ọpọ orilẹ-ede ayé, ẹgbẹẹgbẹrun awọn ojiṣẹ alakooko-kikun oniriiri (“awọn aṣaaju-ọna”) ni a ti mú wá sí U.S.A., tí a ti dalẹkọọ tí a sì rán lọ “sí gbogbo ayé” lati waasu “ihinrere ijọba yii.”—Matteu 24:14; Romu 10:18.
17 Ẹ wò iru eso yiyanilẹnu tí ó ti jẹyọ lati inu ìgbétáásì ẹkọ kárí-ayé yii! Bi a ti ń tẹsiwaju ninu awọn ọdun 1990, apapọ iye awọn eniyan tí ń ṣalabaapin ninu àkàrà ati ọti-waini nigba Iṣe-iranti iku Jesu lọdọọdun, tí ń tipa bayii tọkasi ireti wọn fun wíwà ní isopọṣọkan pẹlu rẹ̀ ninu Ijọba rẹ̀ ọrun, ti lọsilẹ ni eyi tí ó dín si 9,000, bi pupọ sii ninu “awọn arakunrin” Ọba naa ti ń pari igbesi-aye wọn ti ori ilẹ̀-ayé ninu ìwàtítọ́. Ṣugbọn àròpọ̀ awọn ti wọn wá sibẹ, tí ó nifẹẹ si wiwalaaye titilae lori ilẹ̀-ayé gẹgẹ bi awọn ọmọ-abẹ Ijọba naa, ti gasoke jù 10,600,000 lọ. Ninu eyi ti o le ni 66,000 ijọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yika ayé lonii, “ogunlọgọ nla eniyan” ti “awọn agutan miiran” lọna titobiju ń kó ipa tí ó pọ̀ jù ninu iṣẹ ijẹrii naa. Wò bi anfaani rẹ ti tobi tó lati jẹ́ ọ̀kan lara awọn wọnyi!
18. (a) Bawo ni “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” naa ṣe ń bá iṣẹ rẹ̀ lọ? (b) Ninu iṣẹ pataki wo ni iwọ lè ṣajọpin nisinsinyi?
18 Bi ó tilẹ jẹ́ pe iye wọn ń dinku, awọn àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo ti “agbo kekere” ti Jesu, ẹgbẹ “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” naa, ń báa lọ lati bojuto igbokegbodo Ijọba naa. (Matteu 24:45-47, NW) Lati ṣe aṣepari eyi, ó ń ṣiṣẹ nipasẹ ẹgbẹ alakooso kan, iṣeto kan tí ó rí bakan naa pẹlu ti ijọ Kristian ọ̀rúndún kìn-ín-ní. (Iṣe 15:6; Luku 12:42-44) Pẹlu iku N. H. Knorr ní 1977, Frederick W. Franz, ní ẹni 83 ọdun, di ààrẹ Watch Tower Society kẹrin. Ní July 1, 1979, iwe-irohin Ilé-Ìṣọ́nà fúnraarẹ̀ pé 100 ọdun! Ọ̀rúndún kan ti kọja lati igba tí ó ti ń jẹ́rìí Ijọba naa. Bẹẹni, nipasẹ ìwé-títẹ̀ ati ọ̀rọ̀-ẹnu, “ihinrere” yii nipa Ijọba tí a ti gbekalẹ ni a ti pokiki ní gbogbo ayé fun ẹ̀rí. Iwọ ha jẹ́ ẹnikan tí ń ṣalabaapin ninu iṣẹ alanfaani yii ní titẹle apẹẹrẹ tí Jesu filelẹ bi? Gẹgẹ bi Paulu ti ṣí wa létí pe:
“Nipasẹ rẹ̀, ẹ jẹ́ ki a maa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọrun nigba gbogbo, eyiini ni eso ètè wa, tí ń jẹwọ orukọ rẹ̀.”—Heberu 13:15.
19. (a) Ipa-ọna wo ni Paulu damọran, ti o nii ṣe pẹlu “ọkan” ati “ẹnu”? (b) Awọn ibeere ti o ba akoko mu wo ni a lè beere níhìn-ín, bawo ni iwọ sì ṣe dahunpada?
19 Aposteli Paulu kede ninu lẹta miiran pe: “Ọkàn ni a fi ń gbagbọ si ododo; ẹnu ni a sì fi ń jẹwọ si igbala.” (Romu 10:10) Iwọ ha ń lò igbagbọ ninu “ihinrere” naa, tí ó ń pè afiyesi nisinsinyi si Ijọba Ọlọrun, tí a ti gbekalẹ ní ọrun lati 1914? Iwọ ha ‘n ṣe ipolongo ní gbangba fun igbala,’ bi o ti ń gbadura pe ki Ijọba Ọlọrun “dé” pẹlu gbogbo agbara iparun rẹ̀ lati mú eto-ajọ Satani kuro ní ayé bi? Iwọ ha jẹ́ onitara ní sisọ fun awọn miiran ‘ní gbangba ati lati ile dé ile’ nipa awọn ibukun Ijọba naa tí yoo ṣàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo araye nigba tí ifẹ-inu Ọlọrun bá di ṣiṣe laipẹ, “bii ti ọrun, bẹẹni ní ayé” bi? Iwọ ha ń fi pẹlu iduroṣinṣin ṣe itilẹhin fun ẹgbẹ ẹni ami ororo “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” naa ti awọn Kristian tootọ bi wọn ti ń tẹsiwaju ní mímú ipo-iwaju ní kikede ìhìn-iṣẹ́ Ijọba naa “lọ si gbogbo ilẹ, ati . . . si opin ilẹ̀-ayé,” ati ní ‘sisọ awọn eniyan orilẹ-ede gbogbo di ọmọ-ẹhin, ni bibaptisi ati ni kíkọ́ wọn bi’?—Matteu 6:10; 24:14, 45-47; 28:19, 20; Iṣe 5:42; 20:20; Romu 10:18.
20. Anfaani atobilọla wo ni iwọ lè gbadun nisinsinyi?
20 Iwọ lè gbadun anfaani atobilọla kan lonii nipa ‘ṣiṣe iṣẹ-isin mímọ́ lọ́sàn-án ati lóru niwaju ìtẹ́ Ọlọrun.’ Lẹsẹkan naa iwọ fi araarẹ si ìlà lati jẹ́ ọ̀kan lara “awọn ogunlọgọ nla eniyan” tí yoo jogun ìyè ainipẹkun lori ilẹ̀-ayé kan tí a sọ di ológo. (Ìfihàn 7:9-17) Ṣugbọn lakọọkọ ná Ijọba naa gbọdọ “dé” lati jà ogun Armageddoni! Ki ni Armageddoni yoo tumọsi fun araye ati ilẹ̀-ayé?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 159]
ÀÌDÁSÍTỌ̀TÚNTÒSÌ TITI DÉ OJU IKU
Nigba ogun agbaye keji, pupọ ninu awọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí fun Jehofa padanu ẹmi wọn nitori àìdásítọ̀túntòsì. Lẹta tí ń bẹ ní isalẹ yii jẹ́ apẹẹrẹ iru ọpọ awọn ‘lẹta ikẹhin’ tí irufẹ awọn Ẹlẹ́rìí onigboya bẹẹ kọ si awọn idile wọn. Marcel Sutter, ẹni 23 ọdun, tí ń gbé ní Alsace-Lorraine, ni ó kọ ọ́, ní wakati diẹṣaaju ki a to fi àáké bẹ́ ẹ lórí ní ọgbà-ẹ̀wọ̀n Torgau, Germany, ní August 1942.
“Ẹyin obi ati arabinrin mi ọ̀wọ́n,
“Nigba tí ẹ bá rí lẹta yii gbà, emi kò ní sí láàyè mọ́. Wakati diẹ péré ni ó wà laaarin emi ati iku. Mo bẹ̀ yin pe ki ẹ jẹ́ alagbara ati onigboya; ẹ maṣe sọkun, nitori pe mo ti ṣẹgun. Mo ti pari eré-ìje naa mo sì ti pa igbagbọ mọ́. Ǹjẹ́ ki Jehofa Ọlọrun ràn mi lọwọ titi dé opin. Kiki akoko kukuru ni ó wà laaarin wa ati Ijọba Oluwa wa Jesu Kristi. Laipẹ awa yoo tún rí araawa lẹẹkan sii ninu ayé alalaafia ati ododo tí ó daraju. Mo ń yọ̀ bi mo ti ń ronu nipa ọjọ naa, niwọn bi kò ti ní sí ìmí-ẹ̀dùn mọ́ nigba naa. Bawo ni eyiini yoo ti jẹ́ agbayanu tó! Mo ń yánhànhàn fun alaafia. Ní awọn wakati diẹ tí ó kẹhin yii mo ti ń ronu nipa yin ọkàn mi si dàrú diẹ nitori ironu naa pe kò ní ṣeeṣe fun mi lati fi ẹnu kò yin ní ẹnu pé ódìgbòóṣe. Ṣugbọn a gbọdọ mu suuru. Akoko naa ti sunmọle nigba tí Jehofa yoo dá Orukọ rẹ̀ láre tí yoo sì fẹ̀rí hàn fun gbogbo ẹ̀dá pe oun nikanṣoṣo ni Ọlọrun tootọ. Mo dàníyàn nisinsinyi lati yà iwọnba wakati diẹ tí ó kù ninu igbesi-aye mi sọtọ fun un, nitori naa emi yoo pari lẹta yii tí emi yoo sì sọ pe ódìgbòóṣe o titi a ó fi pade lẹẹkan sii laipẹ. Ìyìn fun Ọlọrun wa Jehofa! Pẹlu ifẹ atọkanwa ati ìkíni mi,
“Ọmọkunrin ati arakunrin yin ọ̀wọ́n,
Marcel”