ORÍ KẸJỌ
Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
1. Àdúrà tí àwọn èèyàn mọ̀ dáadáa wo la fẹ́ jíròrò báyìí?
ÀÌMỌYE èèyàn ló mọ àdúrà tá à ń pè ní Baba Wa Tí Ń Bẹ Ní Ọ̀run tàbí Àdúrà Olúwa. Jésù fi àdúrà yìí kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe lè gbàdúrà. Àwọn nǹkan wo ló sọ nínú àdúrà náà? Kí nìdí tí àdúrà náà fi ṣe pàtàkì fún wa lónìí?
2. Nǹkan pàtàkì mẹ́ta wo ni Jésù kọ́ wa pé ká máa béèrè nínú àdúrà wa?
2 Jésù sọ pé: “Torí náà, ẹ máa gbàdúrà lọ́nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́. Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run.’” (Ka Mátíù 6:9-13.) Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé ká máa gbàdúrà fún nǹkan mẹ́ta yìí?—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 20.
3. Kí ló yẹ ká mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run?
3 A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. A sì ti jíròrò ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún àwa èèyàn àti fún ayé. Àmọ́ kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Kí Ìjọba rẹ dé”? A máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run túmọ̀ sí, ohun tó máa ṣe àti bó ṣe máa sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́.
KÍ NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN?
4. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run, ta sì ni Ọba Ìjọba náà?
4 Jèhófà dá ìjọba kan sílẹ̀ ní ọ̀run, ó sì ti yan Jésù láti jẹ́ Ọba ìjọba náà. Bíbélì pé ìjọba yẹn ní Ìjọba Ọlọ́run. Jésù ni “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa.” (1 Tímótì 6:15) Jésù lè ṣe àwọn ohun rere tó pọ̀ ju ti alákòóso èyíkéyìí lọ, ó sì ní agbára ju gbogbo àwọn alágbára èèyàn lọ.
5. Láti ibo ni Ìjọba Ọlọ́run á ti máa ṣàkóso? Ibo ló máa ṣàkóso lé lórí?
5 Lẹ́yìn ogójì (40) ọjọ́ tí Jésù jíǹde, ó pa dà sí ọ̀run. Nígbà tó yá, Jèhófà sọ ọ́ di Ọba Ìjọba náà. (Ìṣe 2:33) Láti ọ̀run ni Ìjọba Ọlọ́run á ti máa ṣàkóso lé ayé lórí. (Ìfihàn 11:15) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Ìjọba Ọlọ́run ní ‘ìjọba ọ̀run.’—2 Tímótì 4:18.
6, 7. Kí ló mú kí Jésù jẹ́ ọba tó dára ju gbogbo ọba lọ?
6 Bíbélì sọ pé Jésù dára ju ọba èyíkéyìí lọ láyé torí pé òun ni “ẹnì kan ṣoṣo tó ní àìkú.” (1 Tímótì 6:16) Kò sí èèyàn èyíkéyìí tó jọba tí ò ní kú, àmọ́ Jésù ò ní kú láé. Ìdí nìyẹn tó fi dá wa lójú pé gbogbo àwọn ohun rere tí Jésù máa ṣe fún wa máa wà pẹ́ títí.
7 Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù máa jẹ́ ọba olódodo àti aláàánú, ó ní: “Ẹ̀mí Jèhófà máa bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára, ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Jèhófà. Ìbẹ̀rù Jèhófà máa jẹ́ ìdùnnú rẹ̀. Kò ní gbé ìdájọ́ rẹ̀ ka ohun tó fojú rí, kò sì ní gbé ìbáwí rẹ̀ ka ohun tó fetí gbọ́ lásán. Ó máa dá ẹjọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀ [tàbí aláìní] bó ṣe tọ́.” (Àìsáyà 11:2-4) Ǹjẹ́ kì í ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni wàá fẹ́ kó jẹ́ ọba rẹ?
8. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù nìkan kọ́ ló máa ṣàkóso?
8 Ọlọ́run ti yan àwọn èèyàn díẹ̀ láti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù ní ìjọba ọ̀run. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Tí a bá ń fara dà á nìṣó, a tún jọ máa jọba.” (2 Tímótì 2:12) Àwọn mélòó ló máa jọba pẹ̀lú Jésù?
9. Àwọn mélòó ló máa jọba pẹ̀lú Jésù? Ìgbà wo ni Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í yàn wọ́n?
9 Ní Orí 7 ìwé yìí, a kẹ́kọ̀ọ́ pé àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran kan. Ó rí Jésù tó ti di Ọba ní ọ̀run pẹ̀lú àwọn ọba míì tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000). Àwọn wo ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) yìí? Jòhánù ṣàlàyé pé “a kọ orúkọ [Jésù] àti orúkọ Baba rẹ̀ sí iwájú orí wọn.” Ó tún fi kún un pé: “Àwọn ló ń tẹ̀ lé Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà [ìyẹn Jésù] lọ síbikíbi tó bá ń lọ. A rà wọ́n látinú aráyé.” (Ka Ìfihàn 14:1, 4.) Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) jẹ́ Kristẹni olóòótọ́ tí Ọlọ́run ti yàn, “wọ́n sì máa ṣàkóso bí ọba lé ayé lórí” pẹ̀lú Jésù. Tí wọ́n bá kú, wọ́n máa jíǹde sí ọ̀run. (Ìfihàn 5:10) Láti ìgbà ayé àwọn àpọ́sítélì ni Jèhófà ti ń yan àwọn Kristẹni olóòótọ́ láti jẹ́ ara àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n máa jẹ́ ọba.
10. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa bó ṣe ṣètò pé kí Jésù àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ṣàkóso àwa èèyàn?
10 Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó ṣètò pé kí àwọn èèyàn kan jọba pẹ̀lú Jésù. Torí pé ọ̀rọ̀ wa yé Jésù, ó máa ṣàkóso wa lọ́nà tó dára. Ó mọ bí ìyà ṣe máa ń rí lára torí pé òun náà ti jìyà rí nígbà tó wá sáyé. Pọ́ọ̀lù sọ pé ọ̀rọ̀ wa máa ń dun Jésù, ó lè “bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa,” àti pé, ó jẹ́ “ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bíi tiwa.” (Hébérù 4:15; 5:8) Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) náà mọ bí ìyà ṣé ń rí lára, torí pé èèyàn ni wọ́n tẹ́lẹ̀. Wọ́n ti fara da àìpé àti àìsàn. Torí náà, ó dá wa lójú pé Jésù àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa, wọ́n sì mọ àwọn ìṣòro tá a ní.
KÍ NI ÌJỌBA ỌLỌ́RUN MÁA ṢE?
11. Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ní ọ̀run?
11 Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ní ọ̀run. Kí nìdí? Ní Orí 3, a kẹ́kọ̀ọ́ pé Sátánì Èṣù ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Lẹ́yìn tí Sátánì ṣọ̀tẹ̀, Jèhófà gbà á láyè láti dúró fún ìgbà díẹ̀ ní ọ̀run pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. Torí náà, kì í ṣe gbogbo àwọn tó wà ní ọ̀run ló ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nígbà yẹn. Ní Orí 10, a máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù.
12. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì méjì wo ni Ìfihàn 12:10 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
12 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò pẹ́ sí ìgbà tí Jésù di Ọba Ìjọba Ọlọ́run ló bá Sátánì jagun. (Ka Ìfihàn 12:7-10.) Ẹsẹ 10 sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì méjì kan. Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso nígbà tí Jésù Kristi di Ọba, ó sì lé Sátánì kúrò lọ́run wá sáyé. A ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wáyé.
13. Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run nígbà tí wọ́n lé Sátánì kúrò?
13 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, inú àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ dùn nígbà tí wọ́n lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run. A kà pé: “Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tó ń gbé inú wọn!” (Ìfihàn 12:12) Ní báyìí, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà ní ọ̀run torí pé gbogbo wọn ló ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.
14. Ní báyìí, kí ló ń ṣẹlẹ̀ láyé torí pé wọ́n ti lé Sátánì kúrò ní ọ̀run?
14 Àmọ́, àwọn nǹkan burúkú ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn láyé, “torí pé Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá” àti pé ó ń “bínú gidigidi, ó mọ̀ pé ìgbà díẹ̀ ló kù fún òun.” (Ìfihàn 12:12) Inú ń bí Sátánì gan-an. Wọ́n ti lé e kúrò ní ọ̀run, ó sì mọ̀ pé òun máa pa run láìpẹ́. Ìdí nìyẹn tó fi ń dá wàhálà sílẹ̀, tó sì ń fa ìrora àti ìyà kárí ayé.
15. Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé?
15 Àmọ́, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé kò tíì yí pa dà. Ó ṣì fẹ́ kí àwọn èèyàn pípé gbé ayé títí láé nínú Párádísè. (Sáàmù 37:29) Báwo ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa mú kí èyí ṣeé ṣe?
16, 17. Kí ni Dáníẹ́lì 2:44 sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run?
16 Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 2:44 sọ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba yẹn, Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀, tí kò ní pa run láé. A ò ní gbé ìjọba yìí fún èèyàn èyíkéyìí míì. Ó máa fọ́ àwọn ìjọba yìí túútúú, ó máa fòpin sí gbogbo wọn, òun nìkan ló sì máa dúró títí láé.” Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí kọ́ wa nípa Ìjọba Ọlọ́run?
17 Àkọ́kọ́, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa bẹ̀rẹ̀ àkóso “ní ọjọ́ àwọn ọba yẹn.” Èyí túmọ̀ sí pé àwọn ìjọba míì ṣì máa wà ní ayé nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Ìkejì, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa wà títí láé, ìjọba míì kò sì ní rọ́pò rẹ̀. Ìkẹta, ogun máa ṣẹlẹ̀ láàárín Ìjọba Ọlọ́run àti àwọn ìjọba ayé yìí. Ṣùgbọ́n Ìjọba Ọlọ́run ló máa ṣẹ́gun, òun sì ni ìjọba kan ṣoṣo tó máa ṣàkóso gbogbo ayé. Ìgbà yẹn ni aráyé á tó gbádùn ìjọba tó dáa jù lọ.
18. Ogun ìkẹyìn wo ló máa wáyé láàárín Ìjọba Ọlọ́run àti àwọn ìjọba ayé yìí?
18 Báwo ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa rọ́pò àwọn ìjọba ayé yìí? Kí ogun tó kẹ́yìn, ìyẹn ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀, àwọn ẹ̀mí èṣù máa ṣi “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé” lọ́nà, “láti kó wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” Ìyẹn ni pé àwọn ìjọba èèyàn máa bá Ìjọba Ọlọ́run jà.—Ìfihàn 16:14, 16; wo Àlàyé Ìparí Ìwé 10.
19, 20. Kí nìdí tá a fi nílò Ìjọba Ọlọ́run láti máa ṣàkóso ayé?
19 Kí nìdí tá a fi nílò Ìjọba Ọlọ́run? Ó kéré tán, a nílò rẹ̀ nítorí ìdí mẹ́ta. Àkọ́kọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, ìdí nìyẹn tá a fi ń ṣàìsàn, tá a sì ń kú. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé a máa gbé títí láé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kódà, Jòhánù 3:16 sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”
20 Ìdí kejì tá a fi nílò Ìjọba Ọlọ́run ni pé àwọn èèyàn burúkú ló yí wa ká. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń parọ́, wọ́n ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ, wọ́n sì ń ṣèṣekúṣe. Àwa èèyàn ò lè mú wọn kúrò, àmọ́ Ọlọ́run máa mú wọn kúrò. Àwọn tí kò bá jáwọ́ nínú ìwà burúkú máa pa run nínú ogun Amágẹ́dọ́nì. (Ka Sáàmù 37:10.) Ìdí kẹta tá a fi nílò Ìjọba Ọlọ́run ni pé ìjọba èèyàn ò lágbára láti máa darí àwọn èèyàn, wọ́n burú, ìwà ìbàjẹ́ sì kún ọwọ́ wọn. Wọn ò ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.
21. Báwo ni Ìjọba náà ṣe máa rí i dájú pé ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ní ayé?
21 Lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, Ìjọba Ọlọ́run máa rí i dájú pé ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ní ayé. Bí àpẹẹrẹ, ó máa pa Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ run. (Ìfihàn 20:1-3) Àwọn èèyàn ò ní máa ṣàìsàn, wọn ò sì ní máa kú mọ́. Ìràpadà tí Ọlọ́run pèsè máa mú kó ṣeé ṣe fún àwọn olóòótọ́ èèyàn láti gbé inú Párádísè títí láé. (Ìfihàn 22:1-3) Ìjọba náà máa sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. Kí ni èyí túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé, gbogbo èèyàn á máa bọlá fún orúkọ Jèhófà.—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 21.
ÌGBÀ WO NI JÉSÙ DI ỌBA?
22. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù kò di ọba nígbà tó wà láyé tàbí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tó jíǹde?
22 Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: “Kí Ìjọba rẹ dé.” Torí náà, ó dájú pé Ìjọba Ọlọ́run máa dé lọ́jọ́ iwájú. Jèhófà máa kọ́kọ́ fìdí Ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, lẹ́yìn náà, á wá sọ Jésù di ọba Ìjọba náà. Ṣé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí Jésù pa dà sí ọ̀run ló di Ọba? Rárá, kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ tí Jésù jíǹde, àpọ́sítélì Pétérù àti Pọ́ọ̀lù mú kí ọ̀rọ̀ yìí túbọ̀ ṣe kedere nígbà tí wọ́n sọ bí àsọtẹ́lẹ̀ inú Sáàmù 110:1 ṣe ṣẹ sí Jésù lára. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, Jèhófà sọ pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” (Ìṣe 2:32-35; Hébérù 10:12, 13) Báwo ni Jésù ṣe dúró pẹ́ tó kí Jèhófà tó sọ ọ́ di Ọba?
Ìjọba Ọlọ́run máa rí i dájú pé ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ní ayé
23. (a) Ìgbà wo ni Jésù di ọba Ìjọba Ọlọ́run? (b) Kí la máa kọ́ ní orí tó kàn?
23 Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú 1914, àwùjọ Kristẹni olóòótọ́ kan gbà pé 1914 máa jẹ́ ọdún pàtàkì nínú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń wáyé láti ọdún 1914 sì fi hàn pé òótọ́ ni ohun tí wọ́n sọ. Kódà, ọdún yẹn ni Jésù di Ọba. (Sáàmù 110:2) Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n lé Sátánì kúrò lọ́run wá sí ayé. Ní báyìí, ‘ìgbà díẹ̀ ló kù fún un.’ (Ìfihàn 12:12) Ní orí tó kàn, a máa rí àwọn ẹ̀rí míì tó fi hàn pé àkókò yẹn la wà báyìí. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ pé láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa rí i dájú pé ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé.—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 22.