Amágẹ́dọ́nì Yóò Ṣínà Ayọ̀
Ọ̀RỌ̀ tá a ń pè ní “Amágẹ́dọ́nì” yìí wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù kan tí wọ́n ń pè ní “Ha-Mágẹ́dọ́nì” tàbí “Òkè Ńlá Mẹ́gídò.” Ọ̀rọ̀ yìí wà nínú ìwé Ìṣípayá 16:16, tó kà pé: “Wọ́n sì kó wọn jọpọ̀ sí ibi tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.” Àwọn wo ló kóra wọn jọpọ̀ sí Amágẹ́dọ́nì, kí sì nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ní Ìṣípayá 16:14, tó fi ẹsẹ méjì péré ṣáájú ẹsẹ tá a fà yọ lókè yìí, a kà pé: “Àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá” kó ara wọn jọpọ̀ “sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” Láìsí àní-àní, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn lè mú kéèyàn béèrè àwọn ìbéèrè mìíràn tó gbàrònú. Àwọn ìbéèrè náà ni pé: Ibo làwọn “ọba” wọ̀nyí ti ń jagun? Nítorí kí ni wọ́n ṣe ń jà, ta ni wọ́n sì ń bá jagun? Ṣé àwọn ohun ìjà tó lè pa ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn run lẹ́ẹ̀kan náà ni wọ́n máa lò ni bí ọ̀pọ̀ èèyàn ti rò? Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni máa la ogun Amágẹ́dọ́nì já? Ẹ jẹ́ kí Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
Ǹjẹ́ bá a ṣe mẹ́nu kàn “Òkè Ńlá Mẹ́gídò” yẹn túmọ̀ sí pé orí òkè ńlá kan pàtó ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé ni wọ́n ti máa ja ogun Amágẹ́dọ́nì? Rárá o. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, irú òkè bẹ́ẹ̀ ò sí lágbègbè yẹn, òkìtì kan tó ga tó ogún mítà nítòsí àfonífojì kan tó tẹ́ pẹrẹsẹ ló wà níbi tí Mẹ́gídò ìgbàanì wà. Yàtọ̀ síyẹn, àgbègbè Mẹ́gídò kéré ju ibi tó lè gba gbogbo “àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn.” (Ìṣípayá 19:19) Àmọ́ ṣá o, nínú ìtàn Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé, Mẹ́gídò ni wọ́n ti ja àwọn kan lára àwọn ogun tó gbóná jù lọ táwọn ìṣẹ́gun tó wáyé níbẹ̀ sì kàmàmà. Nípa bẹ́ẹ̀, orúkọ náà, Amágẹ́dọ́nì dúró fún ogun kan tí ìṣẹ́gun rẹ̀ á kàmàmà tí aṣẹ́gun á sì hàn gbangba.—Wo àpótí náà, “Mẹ́gídò Ṣàpẹẹrẹ Amágẹ́dọ́nì Lọ́nà Tó Ṣe Wẹ́kú” ní ojú ìwé 5.
Amágẹ́dọ́nì ò kàn lè jẹ́ ogun kan táwọn orílẹ̀-èdè ayé ń bára wọn jà, nítorí Ìṣípayá 16:14 sọ pé “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé pátá” para pọ̀ ṣọ̀kan ní “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” Nínú àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí Jeremáyà láti kọ, ó sọ pé “àwọn tí Jèhófà pa” yóò wà káàkiri “láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ ayé títí lọ dé ìpẹ̀kun kejì ilẹ̀ ayé.” (Jeremáyà 25:33) Nítorí náà, Amágẹ́dọ́nì kì í ṣe ogun èèyàn tí wọ́n máa jà níbì kan pàtó ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Ogun Jèhófà fúnra rẹ̀ ni, ó sì máa kárí ayé.
Àmọ́, kíyè sí i pé ‘ibì’ kan la pe ní Amágẹ́dọ́nì nínú Ìṣípayá 16:16. Nínú Bíbélì, ‘ibì’ kan lè túmọ̀ sí ipò kan tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ kan. Ní ti èyí tí à ń sọ yìí, ohun tó túmọ̀ sí ni pé gbogbo ayé á kóra wọn jọ pọ̀ ṣọ̀kan láti bá Jèhófà jà. (Ìṣípayá 12:6, 14) Ní Amágẹ́dọ́nì, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé á para pọ̀ láti dojú ìjà kọ “àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń bẹ ní ọ̀run” lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi tó jẹ́ “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa.”—Ìṣípayá 19:14, 16.
Ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń sọ nípa Amágẹ́dọ́nì wá ńkọ́ o, pé ó jẹ́ fífi ohun ìjà runlérùnnà pa àwọn èèyàn lọ rẹ́kẹrẹ̀kẹ tàbí pé ó jẹ́ ìforígbárí láàárín àwọn ohun tó wà lọ́run àti lórí ilẹ̀ ayé? Ṣé Ọlọ́run tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ á wá gbà kí ìran ènìyàn àti ilẹ̀ ayé tó jẹ́ ilé wọn kàn pa run báyẹn? Rárá o. Ó sọ ní kedere pé òun kò dá ayé “lásán” ṣùgbọ́n òun “ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18; Sáàmù 96:10) Jèhófà kò ní fi iná pa ayé run nígbà Amágẹ́dọ́nì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 11:18.
Ìgbà Wo Ni Amágẹ́dọ́nì Máa Dé?
Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá, ìbéèrè kan wà tó ti ń mú káwọn èèyàn máa méfò lóríṣiríṣi. Ìbéèrè náà ni pé: Ìgbà wo ni Amágẹ́dọ́nì máa dé? Ṣíṣàyẹ̀wò ìwé Ìṣípayá àtàwọn apá ibòmíràn nínú Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa àkókò tí ogun pàtàkì yìí máa jà. Ìṣípayá 16:15 fi Amágẹ́dọ́nì wé dídé tí Jésù máa dé bí olè. Jésù tún lo àpèjúwe yẹn láti sọ nípa wíwá rẹ̀ láti pa ètò nǹkan ìsinsìnyí run.—Mátíù 24:43, 44; 1 Tẹsalóníkà 5:2.
Gẹ́gẹ́ bí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe fi hàn, àtọdún 1914 la ti wà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.a Àkókò tí Jésù pè ní “ìpọ́njú ńlá” ni yóò sàmì sí apá tó kẹ́yìn lára àwọn ọjọ́ ìkẹyìn náà. Bíbélì ò sọ bí àkókò náà ṣe máa gùn tó, àmọ́ àjálù tó máa bá a rìn yóò burú ju àjálù èyíkéyìí téèyàn tíì rí rí. Amágẹ́dọ́nì ni yóò wá kádìí ìpọ́njú ńlá náà.—Mátíù 24:21, 29.
Níwọ̀n bí Amágẹ́dọ́nì ti jẹ́ “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” kò sí ohun táwọn èèyàn lè ṣe láti sún un síwájú. Jèhófà ti yan ‘àkókò kan kalẹ̀’ tí ogun náà yóò bẹ̀rẹ̀. “Kì yóò pẹ́.”—Hábákúkù 2:3.
Ọlọ́run Òdodo Fẹ́ Ja Ogun Tó Tọ́
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi máa ja ogun kan tó kárí ayé? Ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó tayọ jù lọ ló máa mú kó ja ogun Amágẹ́dọ́nì, ànímọ́ náà sì ni ìdájọ́ òdodo. Bíbélì sọ pé: “Olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà.” (Sáàmù 37:28) Ó ń rí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù. Ó sì hàn gbangba pé èyí ò múnú rẹ̀ dùn rárá. Nítorí èyí, ó ti yan Ọmọ rẹ̀ láti ja ogun kan tó tọ́ kó lè pa gbogbo ètò búburú yìí run.
Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè ja ogun tó tọ́, tó máa pa kìkì àwọn tí ìparun tọ́ sí run, tí yóò sì dáàbò bo gbogbo àwọn olódodo níbikíbi tí wọ́n bá wà lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 24:40, 41; Ìṣípayá 7:9, 10, 13, 14) Òun nìkan ló sì lẹ́tọ̀ọ́ láti lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lórí gbogbo ayé nítorí pé òun ló dá wọn.—Ìṣípayá 4:11.
Kí ni Jèhófà máa fi pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run? A ò mọ̀ ọ́n. Ohun tá a kàn mọ̀ ni pé ohun tó lè fi pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè búburú run wà níkàáwọ́ rẹ̀. (Jóòbù 38:22, 23; Sefanáyà 1:15-18) Àmọ́ ṣá o, àwọn tó jẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé kò ní kópa nínú ogun náà. Ìran tó wà nínú Ìṣípayá orí kọkàndínlógún fi hàn pé kìkì àwọn ẹgbẹ́ ogun ọ̀run ni yóò dara pọ̀ mọ́ Jésù Kristi nínú ogun náà. Kò sí èyíkéyìí lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé tó máa kópa nínú rẹ̀.—2 Kíróníkà 20:15, 17.
Ọlọ́run Ọlọ́gbọ́n Fúnni Ní Ọ̀pọ̀ Ìkìlọ̀
Ṣé àwọn èèyàn máa là á já? Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tó yẹ kí Amágẹ́dọ́nì pa. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Jèhófà . . . kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà tún sọ pé, ‘ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.’—1 Tímótì 2:4.
Kíyẹn lè ṣeé ṣe, Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run ọlọgbọ́n ti rí i dájú pé à ń fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè wàásù “ìhìn rere Ìjọba náà” ní gbogbo ayé. Ìyẹn sì ti fún àwọn èèyàn níbi gbogbo láǹfààní àtila ogun náà já kí wọ́n sì rí ìgbàlà. (Mátíù 24:14; Sáàmù 37:34; Fílípì 2:12) Àwọn tó bá fi ọkàn tó dáa gba ìhìn rere náà lè la Amágẹ́dọ́nì já, wọ́n á wà láàyè títí láé, wọ́n á sì jẹ́ ẹni pípé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Ìsíkíẹ́lì 18:23, 32; Sefanáyà 2:3; Róòmù 10:13) Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun téèyàn máa retí pé kí Ọlọ́run tó jẹ́ ìfẹ́ ṣe nìyí?—1 Jòhánù 4:8.
Ṣé Ọlọ́run Ìfẹ́ Á Wá Jagun Ni?
Àmọ́, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn pé Ọlọ́run tóun fúnra rẹ̀ jẹ́ ìfẹ́ yóò tún pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn run báyẹn. A lè fi èyí wé ọ̀rọ̀ ilé kan tí àwọn aáyán pọ̀ sí gan-an. Ǹjẹ́ o ò gbà pé onílé kan tí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ ká lára yóò wá bóun ṣe máa pa àwọn aáyán náà nítorí ìlera àwọn ará ilé rẹ̀?
Lọ́nà kan náà, ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Jèhófà ní fún àwa ẹ̀dá èèyàn ló máa mú kó ja ogun Amágẹ́dọ́nì. Ìfẹ́ Ọlọ́run ni láti sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè, kó sọ àwọn èèyàn di pípé, kí wọ́n sì ní àlàáfíà, láìsí “ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.” (Míkà 4:3, 4; Ìṣípayá 21:4) Kí ló máa wá ṣe fáwọn tí ò jẹ́ káwọn èèyàn bíi tiwọn ní àlàáfíà kí ọkàn wọn sì balẹ̀? Nítorí tàwọn olódodo, Ọlọ́run gbọ́dọ̀ mú àwọn èèyàn tó dà bí aáyán yẹn kúrò pátápátá, ìyẹn àwọn ẹni ibi tó kọ̀ láti ronú pìwà dà.—2 Tẹsalóníkà 1:8, 9; Ìṣípayá 21:8.
Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú gbọ́nmi-si omi-ò-to àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ òde òní ló jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn èèyàn aláìpé tó ń ṣàkóso àtàwọn tó ń fi ìmọ̀-tara-ẹni-nìkan jà fún orílẹ̀-èdè wọn. (Oníwàásù 8:9) Fífẹ́ táwọn ìjọba èèyàn fẹ́ kí agbára wọn túbọ̀ máa pọ̀ sí i ni kò jẹ́ kí wọ́n fara mọ́ Ìjọba tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀. Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé wọ́n máa fi ìṣàkóso wọn sílẹ̀ fún Ọlọ́run àti Kristi. (Sáàmù 2:1-9) Ó di dandan kírú àwọn ìjọba bẹ́ẹ̀ pa rẹ́ ráúráú láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìṣàkóso Ìjọba Jèhófà lábẹ́ ìdarí Kristi. (Dáníẹ́lì 2:44) Ogun Amágẹ́dọ́nì gbọ́dọ̀ jà kí ọ̀ràn nípa ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtàwọn èèyàn lè yanjú lẹ́ẹ̀kan kó má sì tún wáyé mọ́.
Fún àǹfààní ìran ènìyàn ni Jèhófà ṣe fẹ́ jà nígbà Amágẹ́dọ́nì. Pẹ̀lú bí ipò nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i nínú ayé lónìí, kìkì ìṣàkóso pípé látọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan ló lè ṣe ohun tí aráyé ń fẹ́ fún wọn láìkù síbì kan. Kìkì Ìjọba rẹ̀ nìkan ló lè mú ojúlówó àlàáfíà àti aásìkí wá. Báwo ni ipò nǹkan ṣe máa rí nínú ayé bí Ọlọ́run kò bá dá sí ọ̀ràn náà láé? Ǹjẹ́ àwọn ìṣòro bí ìkórìíra, ìwà ipá, àti ogun kò ní máa bá àwọn èèyàn fínra nìṣó bó ṣe ń rí bọ̀ láti gbogbo ọ̀rúndún táwọn èèyàn ti ń ṣàkóso ara wọn? Láìsí àní-àní, ogun Amágẹ́dọ́nì jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó máa ṣe ìran èèyàn láǹfààní jù lọ!—Lúùkù 18:7, 8; 2 Pétérù 3:13.
Ogun Tó Máa Fòpin sí Gbogbo Ogun
Amágẹ́dọ́nì yóò ṣe ohun kan tí ogun mìíràn kò ṣe rí, ohun náà ni pé yóò fòpin sí gbogbo ogun. Àbí ta ló lè sọ pé kò wu òun kí ogun di nǹkan àtijọ́? Àwọn èèyàn ti sa gbogbo ipá wọn, síbẹ̀ wọn ò lè fòpin sí ogun. Bí gbogbo ipa táwọn èèyàn ń sà láti fòpin sí ogun ṣe kùnà yẹn túbọ̀ jẹ́ ká rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Jeremáyà sọ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Nípa ohun tí Jèhófà yóò ṣe yìí, Bíbélì ṣèlérí pé: “Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.”—Sáàmù 46:8, 9.
Ìgbà táwọn orílẹ̀-èdè bá ń fi ohun ìjà olóró pa ara wọn, tí wọ́n sì fẹ́ pa ayé run ni Ẹni tó dá ayé yóò dá sí ọ̀ràn náà nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀! (Ìṣípayá 11:18) Nítorí náà, ogun yìí yóò ṣe ohun táwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run ti ń retí látayébáyé. Yóò fi hàn kedere pé Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó ni ayé, ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ alákòóso lórí gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀.
Nítorí náà, Amágẹ́dọ́nì kì í ṣe ohun tó yẹ káwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo máa bẹ̀rù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló túbọ̀ fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ohun rere ń bọ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Ogun Amágẹ́dọ́nì yóò fọ gbogbo ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ibi mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Yóò tún ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ètò àwọn nǹkan tuntun òdodo lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Mèsáyà ti Ọlọ́run. (Aísáyà 11:4, 5) Amágẹ́dọ́nì kì í ṣe ìparun yán-ányán-án tó ń kó jìnnìjìnnì báni, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tó máa ṣínà ayọ̀ fáwọn olóòótọ́ èèyàn tí yóò wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé ló jẹ́.—Sáàmù 37:29.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo orí kọkànlá ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
MẸ́GÍDÒ ṢÀPẸẸRẸ AMÁGẸ́DỌ́NÌ LỌ́NÀ TÓ ṢE WẸ́KÚ
Àgbègbè tí Mẹ́gídò ayé ìgbàanì wà dára gan-an, èèyàn lè dúró síbẹ̀ kó sì máa wo ìwọ̀ oòrùn Àfonífojì Jésíréélì tó jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá ní apá àríwá ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Ìlú Mẹ́gídò ló ń darí ètò ìṣòwò àgbáyé àtàwọn ojú ọ̀nà ológun tó gba ibẹ̀ kọjá. Bí Mẹ́gídò ṣe di ibi tí wọ́n ti ń ja àwọn ogun tí ìṣẹ́gun wọn kàmàmà nìyẹn. Ohun tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Graham Davies kọ sínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Cities of the Biblical World—Megiddo ni pé: “Ó rọrùn fáwọn oníṣòwò àtàwọn tó ń ṣí káàkiri láti gba ibikíbi wọ ìlú Mẹ́gídò; àmọ́ tí aláṣẹ ibẹ̀ bá lágbára gan-an, ó lè máà jẹ́ káwọn èèyàn gba àwọn ọ̀nà wọ̀nyẹn wọlé mọ́, kó wá tipa bẹ́ẹ̀ máa darí ètò ìṣòwò àti ogun. Abájọ tí ìlú náà fi . . . jẹ́ ibi tó ṣeyebíye gan-an táwọn èèyàn máa ń tìtorí rẹ̀ jà, àwọn tó bá sì ṣẹ́gun yóò sa gbogbo ipá wọn kí ìlú náà má bàa bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.”
Ẹgbẹ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Kristẹni ni ìtàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ tá a máa ń gbọ́ nípa Mẹ́gídò ti bẹ̀rẹ̀. Ìgbà yẹn ni Thutmose Kẹta tó jẹ́ alákòóso ilẹ̀ Íjíbítì ṣẹ́gun àwọn alákòóso Kénáánì níbẹ̀. Ìtàn náà sì ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún títí wá fi di ọdún 1918, nígbà tí Ọ̀gágun Edmund Allenby, ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Turkey lọ́nà kíkàmàmà. Mẹ́gídò ni Ọlọ́run ti jẹ́ kí Bárákì Onídàájọ́ ṣẹ́gun Jábínì Ọba àwọn ará Kénáánì pátápátá. (Àwọn Onídàájọ́ 4:12-24; 5:19, 20) Àgbègbè yẹn náà ni Gídíónì Onídàájọ́ ti ṣẹ́gun àwọn ará Mídíánì lọ́nà tó kàmàmà. (Àwọn Onídàájọ́ 7:1-22) Ibẹ̀ náà ni wọ́n ti pa Ahasáyà Ọba àti Jòsáyà Ọba.—2 Àwọn Ọba 9:27; 23:29, 30.
Abájọ tó fi bá a mu wẹ́kú láti mẹ́nu kan Mẹ́gídò nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ ogun Amágẹ́dọ́nì, nítorí pé ibẹ̀ ni wọ́n ti ja ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun tí ìṣẹ́gun wọn kàmàmà. Amágẹ́dọ́nì jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣàpẹẹrẹ tó ṣe wẹ́kú láti fi ṣàpèjúwe bí Ọlọ́run ṣe máa ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ pátápátá.
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Jákèjádò ayé, àwọn èèyàn ń gbọ́ ìkìlọ̀, èyí sì ń fún wọn láǹfààní àtila Amágẹ́dọ́nì já
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Amágẹ́dọ́nì yóò ṣínà ayọ̀