Ori 17
Ọba naa Jà ní Armageddoni
1, 2. Ki ni awọn eniyan ayé ti ń sọ nipa Armageddoni?
BI OGUN Agbaye II ti ń sunmọ opin rẹ̀, Ọgagun Douglas MacArthur ti U.S. wi pe: “Awọn eniyan lati igba ibẹrẹ wá ti lepa alaafia. . . . Awọn ajọṣepọ ológun, ìdọ́gba agbara, imulẹ awọn orilẹ-ede, gbogbo wọn ni ọkọọkan ti kuna, ni fifi adanwo ogun jija lilekoko silẹ gẹgẹ bi ọna kanṣoṣo tí ó ṣẹku. Iparun yán-án-yán-án ti ogun ń mu wá ti bẹ́gidí yíyàn kanṣoṣo yii bayii. A ti ní anfaani wa ikẹhin. Bi a ko bá ní hùmọ̀ eto gigalọla kan tí ó si tubọ jẹ aláìpọ̀n sibikan, Armageddoni wa yoo wọle de ba wa.”
2 Nǹkan bii 35 ọdun lẹhin naa, bawo ni awọn orilẹ-ede ṣe ń tẹsiwaju pẹlu “anfaani ikẹhin” yii? Times ti London, England, ní eyi lati sọ labẹ akori naa “Awọn Ara West Germany Bẹru Armageddoni”: “Ojiji ogun adayajani ti tun pada si ń fóòró West Germany bi ipo-ọran lati orilẹ-ede si orilẹ-ede ti dabi eyi tí ó bẹrẹsii ń yọ̀tẹ̀rẹ́ lọna tí kò ṣeé ṣakoso.” Ninu ọrọ-ẹkọ kan tí akori rẹ̀ kà pe “Ayé Kọsẹ̀ sinu Òkùnkùn,” olóòtú Herald ti Miami, U.S.A., beere lọwọ awọn onkawe rẹ̀ boya wọn ti bẹrẹ sii loye otitọ naa “pé Armageddoni kii wulẹ ṣe itan àlọ́ kan lasan tí wọn kà nipa rẹ̀ ninu Bibeli, otitọ-gidi ni ó jẹ́,” ó sì fikun un pe: “Eniyan kan tí ó bá ní iwọn làkáàyè diẹ lè ṣe akopọ awọn iṣẹlẹ tí ó ti ṣẹlẹ kọja ní awọn ọdun diẹ sẹhin ki ó sì mọ̀ pe ayé wà lẹnu-ọna gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ninu itan. . . . Yoo sì mú iyipada titilae wá si ọna igbesi-aye eniyan.”
3, 4. Bawo ni oju-iwoye Bibeli nipa Armageddoni ṣe yatọ?
3 Nitootọ, araye duro ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ awọn iyipada ńláǹlà. Ṣugbọn a ha dojukọ Armageddoni nisinsinyi bi? Ki ni Armageddoni tumọsi?
4 Lọna ti ó dunmọni, Armageddoni yatọ si ohun tí pupọ julọ awọn eniyan rò. Nitori pe Bibeli ṣapejuwe ogun Armageddoni, kii ṣe gẹgẹ bi ogun runlérùnnà laaarin awọn orilẹ-ede ilẹ̀-ayé tabi ẹgbẹ awọn orilẹ-ede, ṣugbọn gẹgẹ bi “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare.” O jẹ ogun Ọlọrun lodisi “awọn ọba ayé”—tí ó tumọsi awọn oluṣakoso tí wọn kọ̀ lati juwọsilẹ nigba tí Ijọba Ọlọrun bá “dé” lati mú ki a ṣe ifẹ-inu rẹ̀ lori ilẹ̀-ayé. (Orin Dafidi 2:6-12; Danieli 2:44) Ó jẹ́ àmúwá nla Ọlọrun ti pipa awọn orilẹ-ede ati awọn eniyan buruku run, ni mimura ọna silẹ fun iṣakoso alalaafia ti Messia naa fun 1,000 ọdun.—Ìfihàn 16:14, 16; Orin Dafidi 46:8, 9; 145:20; Joeli 3:9-17; Nahumu 1:7-9.
AWỌN IMURASILẸ FUN OGUN NAA
5. Bawo ni a ṣe lè dá “aṣẹ́wó nla” inu Ìfihàn 17 mọ̀yàtọ̀?
5 Ìfihàn, ori 16 si 18, sọ pupọ fun wa nipa awọn iṣẹlẹ lori ilẹ̀-ayé ní gẹ́rẹ́ ki ogun Armageddoni tó bẹ́sílẹ̀. Ninu asọtẹlẹ naa, a nawọ́ ikesini naa jade pe: “Wá nihin in; emi yoo fi idajọ agbere [“aṣẹ́wó,” NW] nla nì tí ó jokoo lori omi pupọ hàn ọ.” “Aṣẹ́wó nla” yii ni a fihan wa lẹhin naa gẹgẹ bi “Babiloni Nla, iya awọn panṣaga ati awọn ohun irira ayé.” Gan-an gẹgẹ bi Babiloni igbaani, tí ó fidikalẹ si ìhà mejeeji Odò Eufrate, ṣe di “ìyá” fun eto-igbekalẹ isin onídán tí ó tàn lati Babiloni ká gbogbo ilẹ̀-ayé, bẹẹ gẹgẹ ni “Babiloni Nla” lonii ṣe di ilẹ-ọba isin eke agbaye tí ó jẹgàba nipa tẹmi lori “awọn eniyan ati ẹya ati orilẹ ati oniruuru ede,” si ipalara wọn. (Ìfihàn 17:1, 5, 15) Ó ní ninu ẹgbẹẹgbẹrun awọn ẹya isin, nla ati kekere, “Kristian” ati eyi tí kii ṣe Kristian, tí wọn kò jẹwọ Ọlọrun tootọ naa, Jehofa, ki wọn sì ṣiṣẹsin in.
6. Ìfihàn 16 tọkasi iṣẹlẹ wo tí ó rannileti nipa Babiloni igbaani?
6 Gẹgẹ bi iṣẹlẹ kan ṣaaju ogun naa ní Armageddoni, a fi angẹli kan hàn wa tí ó ń tú àwokòtò “ibinu Ọlọrun” jade. Síbo? “Sori Odò nla Eufrate, omi rẹ̀ sì gbẹ, ki a lè pese ọna fun awọn ọba lati ila-oorun wá.” (Ìfihàn 16:1, 12) Ní eyi tí ó jù 600 ọdun ṣaaju ki aposteli Johannu tó ṣe akọsilẹ asọtẹlẹ yẹn, Ọba Dariusi ti Media ati Kirusi ti Persia ti ya wọ̀ ilẹ Babiloni lati ila-oorun. Labẹ ìbòjú òkùnkùn, Kirusi yí ọna ìṣàn Eufrate pada si awọn ipa oju-ọna miiran, bi omi naa sì ti ń ṣàn lọ, ó rán ẹgbẹ ọmọ-ogun rẹ̀ si ilu-nla naa gbà ti ọna ìṣàn-omi naa tí ó ti gbẹ. Ní òru ọjọ kanṣoṣo, nigba tí awọn oluṣakoso ati awọn ọ̀tọ̀kùlú Babiloni ń pẹ̀gàn Jehofa ninu ariya alariwo ọlọ́tí, ilu-nla naa ni a ṣẹgun rẹ̀.—Danieli 5:1-4, 30, 31.
7. Alafijọ ode-oni wo ni a rí nisinsinyi?
7 Awa ha rí àfijọ ode-oni ninu eyi bi? Họwu, bẹẹni! Akoko ti tó fun Ọlọrun lati mú idajọ ṣẹ sori “Babiloni Nla,” ati ní pataki sori “ọmọbinrin” rẹ̀, eto-ajọ Kristẹndọm. Ìpẹ̀hìndà ati ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ Kristẹndọm ti di ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nisinsinyi! (Ìfihàn 18:24; Jeremiah 51:12, 13) Ní akoko lọọlọọ yii “awọn omi,” tabi “awọn eniyan,” tí wọn ti ṣe itilẹhin fun isin rẹ̀ tẹlẹri ti bẹrẹsii fi i silẹ. Itilẹhin fun isin ti bẹrẹsi jórẹ̀hìn, tí ọpọlọpọ eniyan sì ń yipada si awọn ẹkọ Darwin, Marx, Lenin ati Mao. Siwaju sii, gẹgẹ bi a ti sọtẹlẹ nipa “awọn ọjọ ikẹhin,” awọn eniyan ti di “olufẹ faaji jù olufẹ Ọlọrun lọ.”—2 Timoteu 3:1, 4.
8. (a) Ìpè wo ni awọn eniyan onítẹ̀sí òdodo ti ṣe igbọran sí? (b) Bawo ni ipò isin eke nisinsinyi ti rí ní ifiwera pẹlu isin tootọ?
8 Ohun tí ó tún ń dákún gbígbẹ “awọn omi” naa ni igbesẹ awọn eniyan onítẹ̀sí ododo tí wọn ti ṣe igbọran si ìpè ọrun naa nipa “Babiloni Nla” pe:
“Ẹ ti inu rẹ̀ jade, ẹyin eniyan mi, ki ẹ má baa ṣe alabaapin ninu ẹṣẹ rẹ̀, ki ẹ má baa sì ṣe gbà ninu àrùn rẹ̀.” (Ìfihàn 18:4)
Ilẹ-ọba isin eke agbaye, ati Kristẹndọm ní pataki, ń kédàárò awọn ṣọọṣi tí a ń tìpa, awọn àga ṣọọṣi tí ń ṣofo ati awọn alufaa ati obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé tí ń dinku. Àmọ́ ṣáá o, awọn wọnni tí wọn fi araawọn síhà ọ̀dọ̀ Dariusi Titobiju naa, Jehofa Ọlọrun, ati Kirusi Titobiju naa, Kristi Jesu, ti wọ̀ inu aásìkí tẹmi agbayanu kan. Iwọ ha jẹ́ ọ̀kan lara awọn wọnyi bi?
ṢIṢE AṢẸ́WÓ
9, 10. (a) “Ẹranko” adáyàjáni wo ni ó farahan ní “awọn ọjọ ikẹhin” wọnyi? (b) Ninu asọye kan fun gbogbo eniyan ní 1942, bawo ni a ṣe dá a mọ̀yàtọ̀ tí a sì ṣapejuwe ipa-ọna rẹ̀?
9 “Babiloni Nla,” nigba tí ó ń sọ pe oun jẹ́ ti Ọlọrun, ti fi igba gbogbo ní ibaṣepọ ti iṣelu, ati ni ero ìtúmọ̀ yii, ‘awọn ọba ayé ti ṣe agbere’ pẹlu rẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyi, ní “awọn ọjọ ikẹhin,” oun ní anfaani nla rẹ̀! Ki ni eyiini? Áà, níhìn-ín ni a rí “ẹranko ẹhànnà alawọ rírẹ̀dòdò kan.” Ki ni “ẹranko” yii lè jẹ́? Laisi aniani ó ń tọkasi awọn orilẹ-ede oloṣelu ayé, nitori pe awọn wọnyi ni a saba maa ń tọkasi ninu Bibeli labẹ ami ‘awọn ẹranko.’ (Ìfihàn 13:1-4, 11-15; Danieli 7:3-8, 17-25; 8:5-8, 20-22) Ṣugbọn níhìn-ín a ní “ẹranko” alápá-púpọ̀ kan, nitori pe ẹranko bibanilẹru yii ní “ori meje ati ìwo mẹwaa.”—Ìfihàn 17:3, NW.
10 Iru “ẹranko” alápá-púpọ̀ wo ni ó farahan ní “awọn ọjọ ikẹhin” wọnyi, ki ni ó sì ti jẹ iṣesi rẹ̀ ninu awọn iṣẹlẹ ayé? Ninu apejọpọ agbaye kan tí awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe ní 1942, ọrọ-asọye fun gbogbo eniyan tí akori rẹ̀ kà pe “Alaafia—Ó Ha Lè Wà Pẹtiti Bi?” pe afiyesi si asọtẹlẹ inu Ìfihàn 17:7, 8. Alasọye naa, ààrẹ Watch Tower, N. H. Knorr, fi ‘ẹranko ẹhànnà naa tí ó ti wà’ hàn gẹgẹ bi Imulẹ Awọn Orilẹ-ede—tí a mú jade ní 1920. Ṣugbọn nisinsinyi, ní akoko ogun ọdun naa ní 1942, ó wi pe: “Imulẹ naa niti tootọ ti wà ninu ipò aláìlètapútú fun saa kan, ó sì nílò ìmúsọjí bi yoo bá tún walaaye lẹẹkan sii lae. Ó ti lọ sinu ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ti àìṣiṣẹ́ ati àìgbéṣẹ́. ‘Oun kò sí.’” Ààrẹ Knorr ń baa lọ lati fihan pe “ẹranko ẹhànnà naa ti iwọ ri . . . wà, ṣugbọn ko si, . . . o si maa to goke wa lati inu ọgbun ainisalẹ, yoo si lọ sinu iparun.” Gan-an gẹgẹ bi asọtẹlẹ Bibeli ti wí, ‘ẹranko’ naa ni a músọjí ní 1945 gẹgẹ bi Iparapọ Awọn Orilẹ-ede.
11. (a) Eeṣe tí a fi ṣapejuwe “ẹranko ẹhànnà” yii gẹgẹ bi eyi tí ó “kún fun orukọ ọ̀rọ̀ òdì”? (b) Idajọ wo ni ó wà ní ipamọ fun “ẹranko ẹhànnà” naa?
11 “Ẹranko” tí ó tàn ká awọn orilẹ-ede yii, tí a mú jade lati pa “alaafia ati ailewu” mọ́ laaarin awọn orilẹ-ede, niti gàsíkíá “kún fun orukọ ọ̀rọ̀-òdì,” nitori ó sọ pe oun lè ṣe ohun tí kìkì Ijọba Ọlọrun nipasẹ Kristi lè ṣe aṣepari rẹ̀. (Ìfihàn 17:3) Aposteli Paulu sọtẹlẹ nipa akoko-iṣẹlẹ kan nigba tí awọn oluṣakoso ayé Satani onigberaga yoo maa kókìkí yìn araawọn gẹgẹ bi awọn oluṣe-alaafia. Ó wi pe:
“Ọjọ Oluwa ń bọ̀ wá gẹgẹ bi olè ní òru. Nigba tí wọn bá ń wi pe, alaafia ati ailewu; nigba naa ni iparun òjijì yoo dé sori wọn gẹgẹ bi ìrọbí lori obinrin tí ó lóyún; wọn ki yoo sì lè sala.” (1 Tessalonika 5:2, 3)
Gẹgẹ bi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti wi, ‘ẹranko ẹhànnà alaafia ati ailewu’ naa yoo ṣalabaapade imuṣẹ idajọ àṣekágbá ti a mú yá kánkán le e lori lati ọ̀dọ̀ Jehofa!
“Ó MÀ ṢE O” FUN AṢẸ́WÓ NAA!
12. Apejuwe wo nipa “aṣẹ́wó” naa ni ó ṣe Johannu ní kayefi?
12 Laibikita fun ikede Ọlọrun lodisi ẹranko ẹhànnà Iparapọ Awọn Orilẹ-ede ọlọ́rọ̀-òdì naa, “Babiloni Nla” ń wá ọ̀nà lati ní awọn ibaṣepọ oniṣekuṣe pẹlu rẹ̀. Bẹẹni, a yaworan rẹ̀ gẹgẹ bi ẹni tí ó jokoo bi ọbabinrin lori “ẹranko ẹhànnà” naa: “Obinrin naa ni a sì ṣelọ́ṣọ̀ọ́ ninu aṣọ elésè-àlùkò ati rírẹ̀dòdò bi òdòdó, a sì fi wúrà ati okuta iyebiye ati perli ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ ó sì ní ní ọwọ́ rẹ̀ ife wúrà kan tí ó kún fun awọn ohun ìsúni-fún-ìríra ati awọn ohun àìmọ́ agbere rẹ̀.” Abajọ tí Johannu fi kọwe nipa ipo-ọran yii pe: “Tóò, ní kíkófìrí rẹ̀ mo ṣe kayefi agbayanu”!—Ìfihàn 17:4, 6, NW.
13, 14. (a) Opin buburu wo ni ó ń durode isin eke? (b) Bawo ni yoo ṣe dé? (c) Ta ni yoo ṣọ̀fọ̀ Babiloni Nla, ṣugbọn eeṣe tí ó fi jẹ́ lati òkèèrè?
13 Ibaṣepọ oníkòríkòsùn yii laaarin ilẹ-ọba isin eke agbaye ti Babiloni ati ‘ẹranko alaafia ati ailewu’ ti Iparapọ Awọn Orilẹ-ede yoo yọrisi ìjábá. Bi ó tilẹ jẹ́ pe “Babiloni” oníwà bi awọn aṣẹ́wó lé rò pe oun jokoo fẹ̀kẹ̀tẹ̀ pẹlu eto agbaye naa, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ asọtẹlẹ ohun miiran fun un:
“Awọn ìwo mẹwaa tí iwọ sì rí, ati ẹranko ẹhànnà naa, awọn wọnyi yoo koriira aṣẹ́wó naa, wọn yoo sì sọ ọ di ahoro ati onihooho, wọn yoo sì jẹ awọn apá ibi ẹran-ara rẹ̀ wọn yoo sì fi iná sun ún patapata.” (Ìfihàn 17:16, NW)
Dajudaju opin tí ó kún fun ègbé ni yoo si jẹ fun ilẹ-ọba isin eke agbaye!
14 Isọdahoro “Babiloni Nla” yoo ṣẹlẹ ní wàrà-ǹṣeṣà.
“Ìyọnu-àjàkálẹ̀ rẹ̀ yoo . . . dé ní ọjọ kan, iku ati ọ̀fọ̀ ati ìyàn, a ó sì fi iná sun ún patapata, nitori pe Jehofa Ọlọrun, tí ó ṣèdájọ́ rẹ̀, jẹ́ alagbara.” (Ìfihàn 18:8, NW)
Ṣugbọn awọn wọnni tí yoo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ yoo wà. Awọn wọnyi ki yoo jẹ́ “ìwo mẹwaa” arógunyọ̀ tí ó fi pẹlu ẹ̀tàn yipada lodisi i, ṣugbọn awọn miiran lara awọn oloṣelu oluṣakoso tí ó ti saba maa ń ṣe wọléwọ̀de pẹlu awọn alufaa fun àṣehàn, ati lati ṣe iranlọwọ bò aṣiri iṣẹ òkùnkùn wọn. Awọn wọnyi yoo ṣèdárò rẹ̀ lati òkèèrè, nitori ibẹru ki awọn má baa ṣalabaapin ninu ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ní wiwi pe:
“Ó mà ṣe o, ó mà ṣe o, iwọ ilu-nla titobi, Babiloni iwọ ilu-nla alagbara, nitori pe ní wakati kan ni idajọ rẹ dé!”—Ìfihàn 18:9, 10, NW.
15. Ta ni ẹlomiran tí ó tún fasẹhin, eesitiṣe?
15 Awọn eniyan Oniṣowo Aládàá-ńlá, ẹgbẹ awọn eniyan-keniyan, ati awọn alọnilọwọgba oníjìbìtì miiran pẹlu ni yoo wà, tí wọn ti lo awọn ibaṣepọ onisin lati fi ohun tí wọn pè ní “ijẹmimọ” daṣọ bo awọn ibalo oníwà-ìbàjẹ́ wọn ati lati mú itura débá ẹ̀rí-ọkàn wọn tí imọlara ẹ̀bi ń nà ní pàṣán. Awọn wọnyi, pẹlu, yoo sọ ọ̀rọ̀ aṣọtunsọ yii pe:
“Ó mà ṣe o, ó mà ṣe o . . . , nitori pe ní wakati kan awọn ọrọ̀ nlanla bẹẹ ni a ti parun!” (Ìfihàn 18:11-19, NW)
Awọn ṣọọṣi kà-ǹkàkà-ǹkà olówó-gọbọi, awọn ilẹ ati ọrọ̀ tí wọn ti tòjọ pelemọ, awọn akọsilẹ ìfowópamọ́ olówó-gegere ní banki ati awọn okòwò aládàá-ńlá ti awọn isin ayé—gbogbo iwọnyi ni yoo ti di alaiwulo.
16. Awọn ẹgbẹ mẹta wo ni wọn wà ní ìlà fun iparun?
16 Ìsìn ayé alagabagebe, iṣowo ọlọ́kàn-án-júwà, iṣelu oníwà-ìbàjẹ́—gbogbo ẹ̀ka mẹtẹẹta eto-ajọ Satani lori ilẹ̀-ayé ni wọn wà ní ìlà fun imuṣẹ idajọ Jehofa. Ki ni yoo tẹle e lẹhin tí a bá ti palẹ̀ isin eke mọ́?
ỌBA NAA BẸRẸSII GBÉGBÈÉSẸ̀!
17, 18. (a) Ki ni yoo tẹle isọdahoro “Babiloni Nla,” eesitiṣe? (b) Ta ni ṣẹgun nikẹhin? (c) Awọn wo ni a ó pamọ láàyè? (d) Bawo ni iwọ ṣe lè jẹ́ ọ̀kan lara awọn wọnyi?
17 Awọn agbara iṣelu alatunṣe tegbòtigàgá wọnni tí wọn pa isin ayé run kò ní ojú ìlóye ohun tẹmi. Wọn kò tẹwọgba Ijọba Messia, tí a gbekalẹ ní 1914. Kàkà bẹẹ, wọn fi tagbaratagbara tako awọn wọnni tí ń pokiki Ijọba naa tí wọn kede àìdásítọ̀túntòsì Kristian wọn niti iṣelu ati ogun awọn “ijọba” ayé.—Ìfihàn 12:17; Johannu 17:14, 16.
18 Lẹhin ipalẹmọ “Babiloni Nla,” awọn “ìwo” oníwà-bí-ẹranko ẹhànnà wọnni ni a lè reti pe wọn yoo ṣe ikọlu àṣekágbá wọn si awọn Kristian Ẹlẹ́rìí fun Jehofa, awọn ọmọlẹhin Ọdọ-Agutan naa níhìn-ín lori ilẹ̀-ayé tí ó dabi ẹni pe wọn kò ni olugbeja. (Esekieli 38:14-16; Jeremiah 1:19) Bawo ni awọn ọ̀tá wọnyi yoo ti ṣe si ninu ogun naa? Asọtẹlẹ naa dahun pe:
“Awọn wọnyi ni yoo sì maa bá Ọdọ-Agutan jagun, Ọdọ-Agutan naa yoo sì ṣẹgun wọn: nitori oun ni Oluwa awọn oluwa, ati Ọba awọn ọba: awọn tí ó sì wà pẹlu rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọn sì jẹ́ oloootọ yoo sì ṣẹgun pẹlu.” (Ìfihàn 17:14)
Bi ó tilẹ jẹ́ pe wọn kò kó ipa kankan ninu ogun naa, iyoku awọn ẹni-ami-ororo ọmọlẹhin Jesu lori ilẹ̀-ayé, papọ pẹlu awọn ẹlẹgbẹ wọn tí awọn pẹlu ti dahun si ìpè naa fun ‘iṣẹ-isin mímọ́,’ ni a ó pamọ láàyè. Iwọ ha jẹ́ ọ̀kan lara awọn wọnyi tí ń gbadura nisinsinyi paapaa fun ‘dídé’ Ijọba Ọlọrun ní Armageddoni bi?—Romu 12:1, 2; fiwe 2 Kronika 20:5, 6, 12-17.
19. (a) Iwọ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí ati olulaaja si ki ni? (b) Ki ni awọn ohun iyebiye tí yoo kùnà nigba naa?
19 Bẹẹni, iwọ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí ati olulaaja ninu ogun alájàálù-ibi naa ní Armageddoni. Iwọ lè kíyèsí bi “Ọba awọn ọba,” pẹlu ẹgbẹ ọmọ-ogun awọn angẹli ọrun lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣe ń jà fun idalare ipò ọba-aláṣẹ Jehofa. Nibẹ ni iwọ ti lè rí ogun tí ó gajulọ lodisi awọn eniyan buburu, lodisi awọn agberaga ati awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun alagbara-nla wọn ati awọn “oniṣowo” ọlọ́rọ̀ tí ó ń tì wọn lẹhin! Awọn àkójọ ohun-ija atọmiki tí ó ti ná wọn ní ọpọ billion naira yoo já wọn kulẹ ninu ìjà-ogun naa! Awọn ọ̀kánjúwà elérè àjẹpajúdé, tí wọn ti fi awọn ipese epo ati ounjẹ ṣe fayawọ yoo rii pe awọn èrè ti wọn ti fi èru kojọ ti di alainiyelori mọ́, bi ọja idunaadura owo idokowo lagbaye ti ń wolulẹ, ti iniyelori wúrà gẹgẹ bi ọna igbanisilẹ si ń ja lọ silẹ ṣooroṣo si òfo. Nitori “bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; ibi kan, ibi kanṣoṣo, kiyesi i, o de. Wọn o sọ fadaka wọn si igboro, wura wọn ni a o si mu kuro; fadaka wọn ati wura wọn kì yoo si le gbà wọn là ni ọjọ ibinu Oluwa; . . . wọn yoo sì mọ̀ pe emi ni [Jehofa, NW].”—Esekieli 7:5, 19, 27.
20. Nibo ni iwọ ti lè rí ààbò tootọ?
20 Ní ọjọ Armageddoni yẹn, iwọ lè rí ààbò, kii ṣe ninu ohun-ìní ti ara eyikeyii, ṣugbọn ninu dídúró gbọnyin níhà ọ̀dọ̀ Jehofa ati “Ọba awọn ọba” rẹ̀. Yoo sinmi lori igbọran rẹ si awọn ọ̀rọ̀ wolii naa:
“Ẹ wá Oluwa, gbogbo ẹyin ọlọkan tútù ayé, tí ń ṣe idajọ rẹ̀; ẹ wá ododo, ẹ wá ìwà-pẹ̀lẹ̀: boya a o pa yin mọ́ ní ọjọ ibinu Oluwa.” (Sefaniah 2:3; tún wò Isaiah 26:20, 21; Danieli 12:1.)
Nitori ní Armageddoni, Ọba naa tí ó jokoo lori ẹṣin funfun iṣapẹẹrẹ naa “ń ṣedajọ, ó sì ń jagun ninu ododo.” Nigba tí o bá n fi ‘ọpa irin ṣamọna awọn orilẹ-ede,’ si iparun wọn, yoo mú “ogunlọgọ nla eniyan” (NW) tí a wọ̀ ní aṣọ-ìgúnwà funfun jade ninu “ipọnju nla,” tí yoo sì ṣe oluṣọ-agutan wọn ninu ifẹ, yoo sì “ṣe amọna wọn si ibi orisun omi ìyè.” Ǹjẹ́ ki iwọ lè jẹ́ ọ̀kan ninu awọn wọnyi!—Ìfihàn 19:11-16; 7:9, 14, 17.
21. Awọn wo ni yoo pejọ ní Armageddoni, ṣugbọn eeṣe tí yoo fi jasi pàbó?
21 Pagidarì fun Iparapọ Awọn Orilẹ-ede, awọn ijọba alatilẹhin rẹ̀ ati awọn agbara ogun tí wọn ti tòjọ pelemọ! Ẹ jẹ́ ki wọn pejọ ní Armageddoni “lati bá ẹni tí ó jokoo lori ẹṣin [funfun] naa ati ogun [ọrun] rẹ̀ jagun”! Pàbó ni gbogbo rẹ̀! “Ọba awọn ọba” yoo fi wọn sọ̀kò, ki a sọ ọ lọna bẹẹ, sinu “adágún iná,” si iparun wọn. Iyoku eto-ajọ Satani ori ilẹ̀-ayé ni a o palẹ rẹ̀ mọ́ bakan naa, nitori idà gígùn Ọba naa lagbara gidigidi, ó lè ṣawari ki ó sì pa ọ̀tá eyikeyii run.—Ìfihàn 19:17-21.
22. Bawo ni awọn wolii Ọlọrun ṣe ṣapejuwe ìjà ní Armageddoni?
22 Nipasẹ awọn ohun-ọṣẹ́ ati awọn ìyọnu-àjàkálẹ̀ tí a fi ranṣẹ lati ọrun, “Jehofa yoo sì fi àrùn kọlu gbogbo awọn eniyan” tí wọn jà lodisi Ijọba rẹ̀, ati, laisi aniani, ninu idarudapọ wọn awọn wọnyi yoo fi awọn ohun-ija apanirun wọn rọ̀jò iku sori araawọn lẹnikinni-keji, nitori pe ‘ọwọ́ olukuluku yoo dide si ọwọ́ ẹnikeji rẹ̀.’ Ṣugbọn bi iwọ bá jẹ́ ọ̀kan lara awọn tí ń kepe orukọ Jehofa, a ó ‘gbà ọ là.’—Joeli 2:31, 32; Sekariah 14:3, 12, 13, NW; Esekieli 38:21-23; Jeremiah 25:31-33.
23. (a) Eyi yoo jẹ́ otente fun ki ni? (b) Awọn ọ̀rọ̀ Jesu wo ni ó gbọdọ mú wa layọ?
23 Eyiini ni yoo jẹ́ otente “ami” alasọtẹlẹ ti Jesu—“ipọnju nla iru eyi tí kò sí lati igba ibẹrẹ ọjọ ìwà titi di isinsinyi, bẹẹkọ, irú rẹ̀ ki yoo sì sí.” Ẹ wò bi a ti layọ tó pe a ó “ké” ọjọ wọnni “kúrú” nitori “awọn ayanfẹ”! Iwọ, pẹlu, lè laaja gẹgẹ bi ọ̀kan ninu awọn “agutan” tí Jesu késí lati “jogun ijọba”!—Matteu 24:21, 22; 25:33, 34.
24. (a) Igbesẹ wo ni a ó gbé nigba naa lodisi Satani, eesitiṣe? (b) Ki ni yoo tẹle e?
24 Nigba tí ogun Armageddoni bá pari, Satani fúnraarẹ̀, ẹni buruku naa tí ó ti ṣokunfa àṣìlò agbara iṣakoso eniyan lori ilẹ̀-ayé, ni a ó gbámú, tí a ó dè tí a ó sì jù sinu ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ “fun ẹgbẹrun ọdun.” Eeṣe? Ó jẹ́ nitori pe “ki ó má baa tàn awọn orilẹ-ede jẹ mọ́.” (Ìfihàn 20:2, 3) Nigba naa ni ojúmọ́ sanmani ológo julọ ninu gbogbo itan eniyan yoo mọ́. Ki ni 1,000 ọdun naa yoo sì tumọsi fun awọn aduroṣinṣin wọnni tí wọn ti ṣiṣẹ tí wọn sì ti gbadura fun ‘dídé’ Ijọba naa? Laisi aniani, iwọ yoo fẹ lati mọ̀.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 169]
“AṢẸ́WÓ” NAA ATI “ẸRANKO” NAA
Ki ni ipo-ibatan tí ó wà laaarin ilẹ-ọba isin eke agbaye ati ‘ẹranko ẹhànnà alaafia ati ailewu naa’? “Babiloni Nla” ha ti wa anfaani agbara iṣakoso ninu Imulẹ Awọn Orilẹ-ede ati, lẹhin naa, ninu Iparapọ Awọn Orilẹ-ede bi? Ẹ jẹ́ ki awọn otitọ-iṣẹlẹ dahun:
Lẹhin tí a ti wéwèé Imulẹ Awọn Orilẹ-ede ní 1918, “Bulletin” Igbimọ Apapọ Ṣọọṣi Kristi ní America lọ jinna dé ipò wiwi pe: “Gẹgẹ bi Kristian a fi tagbaratagbara damọran igbekalẹ Imulẹ kan ti Awọn Orilẹ-ede Olominira nigba Àpérò Alaafia tí ń bọ̀. Irú Imulẹ bẹẹ kii ṣe irin iṣẹ onigba diẹ fun ete iṣelu lasan; kàkà bẹẹ ó jẹ́ ifihan Ijọba Ọlọrun lọna iṣelu lori ilẹ̀-ayé. . . . Awọn akọni tí wọn kú ìbá ti kú lasan ayafi bi ilẹ̀-ayé titun kan ninu eyi tí ododo ń gbé bá ti inu ijagunmolu jade wá.”
Nigba tí Iparapọ Awọn Orilẹ-ede ń ṣe àjọyọ̀ ogún ọdun ọjọ-ìbí rẹ̀ ní 1965, Associated Press lati San Francisco rohin pe: “Awọn aṣaaju isin agbaye meje pẹlu awọn ọmọlẹhin wọn tí ó jù 2,000 million lọ jakejado ayé, darapọ ní gbígbé ọwọ́ wọn soke ninu adura labẹ òrùlé kan lonii ní itilẹhin ìyánhànhàn Iparapọ Awọn Orilẹ-ede fun alaafia agbaye. Popu Paul VI fi ibukun rẹ̀ ranṣẹ lati Romu . . . si ipade fun awọn Katoliki, Protẹstanti, Ju, Hindu, onisin Buddha, Musulumi, ati awọn Kristian ti Orthodox ti Ìlà-Oòrùn (Griki). . . . Rabbi Louis Jacobs . . . ṣapejuwe ‘Iparapọ Awọn Orilẹ-ede gẹgẹ bi ireti kanṣoṣo fun alaafia pipẹtiti ninu ayé kan tí lilaaja rẹ̀ sinmi lé e lori.’”
Ní October 1965, Popu Paul VI ṣapejuwe Iparapọ Awọn Orilẹ-ede gẹgẹ bi “eyi tí ó tobijulọ ninu awọn eto-ajọ agbaye,” ó sì fikun un pe: “Awọn eniyan ilẹ̀-ayé yíjúsí Iparapọ Awọn Orilẹ-ede gẹgẹ bi ireti ikẹhin fun iṣọkan ati alaafia.”
Nigba tí ó ń bá Ipade Gbogbogboo ti Iparapọ Awọn Orilẹ-ede sọrọ ní October 2, 1979, Popu John Paul II wi pe: “Idi pataki tí mo fi dásí ọran yii lonii, laisi tabi-ṣugbọn, ni ìdè ifọwọsowọpọ akanṣe tí ó so ọla-aṣẹ popu pọ̀ mọ́ eto-ajọ Iparapọ Awọn Orilẹ-ede. . . . Mo ní ireti pe Iparapọ Awọn Orilẹ-ede yoo maa baa lọ titilae lati jẹ́ ibi ikorijọ gigajulọ fun alaafia ati idajọ-ododo, ibujokoo dídájú fun ominira awọn eniyan ati ẹnikọọkan ninu ìyánhànhàn wọn fun ọjọ-ọla didaraju.” Sibẹ ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀ oniṣẹju 62, popu kò mẹnukan Jesu Kristi tabi Ijọba naa rara.
Ní titẹwọgba awọn arọ́pò atọwọda fun Ijọba Ọlọrun, isin eke ń yíjúsí òtúbáńtẹ́ ireti. Lẹhin kikilọ lodisi gbigbẹkẹle awọn oluṣakoso eniyan, Orin Dafidi 146:3-6 (NW) sọ fun wa pe: “Alayọ ni ẹni naa . . . ẹni tí ireti rẹ̀ wà ninu Jehofa Ọlọrun rẹ̀, Olùṣẹ̀dá ọrun ati ayé.” Luku 2:10-14 fi Olugbala araye hàn gẹgẹ bi “Kristi Oluwa.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 173]
ITOTẸLERA AWỌN IṢẸLẸ TÍ YOO ṢAMỌNA SI ARMAGEDDONI
● A gbé ọran ariyanjiyan ipò ọba-aláṣẹ agbaye dide, awọn orilẹ-ede to ohun-ija jọ pelemọ
● Jijoro itilẹhin awọn eniyan fun isin ayé
● Igbe manigbagbe ti “Alaafia ati ailewu!” nipasẹ awọn orilẹ-ede
● “Ìwo mẹwaa” ológun ti Iparapọ Awọn Orilẹ-ede pa isin ayé run
● Awọn “ìwo” ẹranko ẹhànnà naa ṣe ikọlu ikẹhin si awọn ọmọlẹhin “Ọdọ-agutan”
● “Ọba awọn ọba” pa awọn orilẹ-ede ati awọn ọmọ-ogun run ní Armageddoni
PẸLU SATANI ATI AWỌN ẸMI EṢU RẸ̀ TI A FI SỌ̀KÒ SINU Ọ̀GBUN ÀÌNÍSÀLẸ̀ IJỌBA ẸGBẸRUN ỌDUN OLÓGO TI KRISTI BẸRẸ