Orí 36
Ìlú Ńlá Náà Pa Run
Ìran 12—Ìṣípayá 18:1–19:10
Ohun tó dá lé: Ìṣubú àti ìparun Bábílónì Ńlá; a kéde ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn
Ìgbà tó nímùúṣẹ: Látọdún 1919 títí di ẹ̀yìn ìpọ́njú ńlá
1. Kí ni yóò fi hàn pé ìpọ́njú ńlá ti bẹ̀rẹ̀?
IKÚ Bábílónì Ńlá yóò dé lójijì, lọ́nà tó ń da jìnnìjìnnì boni, òfò náà yóò kàmàmà! Yóò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àjálù tó burú jù lọ látìgbà táláyé ti dáyé, yóò sì fi hàn pé ìpọ́njú ńlá ti bẹ̀rẹ̀, ìyẹn “ìpọ́njú ńlá . . . irúfẹ́ èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.”—Mátíù 24:21.
2. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ilẹ̀ ọba ìṣèlú ti wà tí wọ́n sì ti pa rẹ́, irú ilẹ̀ ọba wo ni kò tíì pa rẹ́?
2 Ó ti pẹ́ gan-an tí ìsìn èké ti wà. Ó ti wà láìsí ìdílọ́wọ́ kankan látìgbà ayé Nímírọ́dù ẹni tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ, tó ń ta ko Jèhófà tó sì ní káwọn èèyàn kọ́ ilé gogoro Bábélì. Nígbà tí Jèhófà da èdè àwọn ọlọ̀tẹ̀ èèyàn wọ̀nyẹn rú tó sì fọ́n wọn ká káàkiri ayé, ìsìn èké Bábílónì bá wọn lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 10:8-10; 11:4-9) Láti ìgbà náà wá, àwọn ilẹ̀ ọba ìṣèlú ti wà wọ́n sì ti pa rẹ́, ṣùgbọ́n ìsìn Bábílónì ṣì ń bá a lọ. Ìsìn Bábílónì ti kó ọ̀pọ̀ nǹkan mọ́ra ó sì ti pín sí onírúurú ọ̀nà, bẹ́ẹ̀ ló ṣe di ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, ìyẹn Bábílónì Ńlá tí Ìwé Ìṣípayá sọ tẹ́lẹ̀. Apá títayọ jù lọ nínú rẹ̀ ni ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, èyí tó jáde wá látinú àpapọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ Bábílónì ayé ọjọ́un àti ẹ̀kọ́ “Kristẹni” apẹ̀yìndà. Nítorí pé Bábílónì Ńlá tí wà tipẹ́, ó ṣòro gan-an fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbà pé yóò pa run.
3. Báwo ni ìwé Ìṣípayá ṣe mú un dání lójú pé ìparun ìsìn èké dájú?
3 Nítorí náà, ó dáa bí ìwé Ìṣípayá ṣe mú un dáni lójú pé ìparun ìsìn èké dájú àti bó ṣe ṣàlàyé kúnnákúnná fún wa lẹ́ẹ̀mejì nípa bí ìṣubú rẹ̀ àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa tẹ̀ lé e yóò ṣe yọrí sí ìparun rẹ̀ pátápátá. A ti rí i pé ìsìn èké jẹ́ “aṣẹ́wó ńlá” tí Ọlọ́run á lo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ìyẹn àkóso ìṣèlú, láti pa run. (Ìṣípayá 17:1, 15, 16) Àmọ́ nínú ìran mìíràn tá a fẹ́ gbẹ́ yẹ̀ wò báyìí, ìsìn èké jẹ́ ìlú ńlá kan, tí Bábílónì ìgbàanì ṣàpẹẹrẹ rẹ̀.
Bábílónì Ńlá Ṣubú Yakata
4. (a) Ìran wo ni Jòhánù rí tẹ̀ lé e? (b) Báwo la ṣe lè dá áńgẹ́lì náà mọ̀, kí sì nìdí tó fi dára gan-an pé òun ló máa kéde ìṣubú Bábílónì Ńlá?
4 Jòhánù ń bá ìròyìn náà lọ, pé: “Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, mo rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, pẹ̀lú ọlá àṣẹ ńlá; a sì mú ilẹ̀ ayé mọ́lẹ̀ kedere láti inú ògo rẹ̀. Ó sì ké jáde pẹ̀lú ohùn líle, pé: ‘Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá ti ṣubú.’” (Ìṣípayá 18:1, 2a) Èyí jẹ́ ìgbà kejì tí Jòhánù máa gbọ́ ìkéde áńgẹ́lì yẹn. (Wo Ìṣípayá 14:8.) Àmọ́, lọ́tẹ̀ yìí ọlá ńlá áńgẹ́lì ọ̀run yẹn mú kí ìkéde náà túbọ̀ ṣe pàtàkì, nítorí ògo áńgẹ́lì náà tànmọ́lẹ̀ sí gbogbo ilẹ̀ ayé! Ta ni áńgẹ́lì náà? Nígbà tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì ń ròyìn nípa ìran ọ̀run kan ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú, ó sọ pé “ilẹ̀ ayé pàápàá mọ́lẹ̀ yòò nítorí ògo rẹ̀ [Jèhófà].” (Ìsíkíẹ́lì 43:2) Áńgẹ́lì kan ṣoṣo tó lè tàn, tí ògo rẹ̀ á ṣeé fi wé ti Jèhófà yóò jẹ́ Jésù Olúwa, ẹni tí í ṣe “àgbéyọ ògo [Ọlọ́run] àti àwòrán náà gẹ́lẹ́ ti wíwà rẹ̀ gan-an.” (Hébérù 1:3) Lọ́dún 1914 Jésù di ọba ní ọ̀run, láti ìgbà náà wá ló sì ti ń lo àṣẹ lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí alájùmọ̀ jẹ Ọba àti Onídàájọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Nítorí náà, ó dáa gan-an pé òun ló máa kéde ìṣubú Bábílónì Ńlá.
5. (a) Ta ni áńgẹ́lì náà ń lò láti polongo ìṣubú Bábílónì Ńlá? (b) Nígbà tí ìdájọ́ bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ “ilé Ọlọ́run,” kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì?
5 Ta ni áńgẹ́lì tó ní àṣẹ ńlá yìí ń lò láti polongo ìròyìn àgbàyanu yìí fún aráyé? Àwọn èèyàn tá a tú sílẹ̀ nígbà tí ìṣubú Bábílónì Ńlá wáyé ni, ìyẹn àwọn tó ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé lára àwọn ẹni àmì òróró tí í ṣe ẹgbẹ́ Jòhánù. Látọdún 1914 sí 1918, àwọn wọ̀nyí jìyà púpọ̀ lọ́wọ́ Bábílónì Ńlá, ṣùgbọ́n lọ́dún 1918, Jèhófà Olúwa àti “ońṣẹ́ májẹ̀mú [Ábúráhámù]” rẹ̀, Jésù Kristi, bẹ̀rẹ̀ ìdájọ́ lórí “ilé Ọlọ́run,” ìyẹn àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni. Nípa bẹ́ẹ̀ a mú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì apẹ̀yìndà wá jẹ́jọ́. (Málákì 3:1; 1 Pétérù 4:17) Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tó pàpọ̀jù táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fà wá sórí ara wọn nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ipa tí wọn kó nínú ṣíṣe inúnibíni sáwọn olùṣòtítọ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, àtàwọn ẹ̀kọ́ èké Bábílónì tí wọ́n fi ń kọ́ni kò ràn wọ́n lọ́wọ́ ní àkókò ìdájọ́ yẹn; bẹ́ẹ̀ sì ni apá èyíkéyìí nínú Bábílónì Ńlá kò yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run.—Fi wé Aísáyà 13:1-9.
6. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Bábílónì Ńlá ṣubú lọ́dún 1919?
6 Nítorí náà, Bábílónì Ńlá ṣubú lọ́dún 1919, èyí tó mú kó ṣeé ṣe láti tú àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀ àti láti mú wọn bò sípò sí ilẹ̀ aásìkí tẹ̀mí wọn, bíi pé lọ́jọ́ kan ṣoṣo. (Aísáyà 66:8) Lọ́dún yẹn, Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi, tí wọ́n jẹ́ Dáríúsì Títóbi Jù àti Kírúsì Títóbi Jù, rí sí i pé ìsìn èké kò lágbára lórí àwọn èèyàn Jèhófà mọ́. Kò ṣeé ṣe fún ìsìn èké mọ́ láti dí wọn lọ́wọ́ jíjọ́sìn Jèhófà, kò ṣeé ṣe fún un mọ́ láti sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ kéde fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ gbọ́ pé Bábílónì Ńlá tó dà bí aṣẹ́wó máa kàgbákò, kò sì lè sọ pé kí wọ́n má ṣe kéde, pé kò ní pẹ́ mọ́ tí Jèhófà máa fi hàn pé òun nìkan lòun lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run!—Aísáyà 45:1-4; Dáníẹ́lì 5:30, 31.
7. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kò pa Bábílónì Ńlá run lọ́dún 1919, ojú wo ló fi wò ó? (b) Nígbà tí Bábílónì Ńlá ṣubú lọ́dún 1919, kí ló yọrí sí fún àwọn èèyàn Jèhófà?
7 Lóòótọ́, Jèhófà kò pa Bábílónì Ńlá run lọ́dún 1919 bí ìlú Bábílónì kò ṣe pa run lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Kristẹni nígbà tó ṣubú sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Kírúsì ará Páṣíà. Ṣùgbọ́n ojú tí Jèhófà fi wò ó ni pé, àjọ ìsìn èké yẹn ti ṣubú. A ti dá a lẹ́bi, ó ń dúró de ìparun; nítorí náà, ìsìn èké kò lè mú àwọn èèyàn Jèhófà lẹ́rú mọ́. (Fi wé Lúùkù 9:59, 60.) Jèhófà tú àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ pé kí wọ́n máa sìn gẹ́gẹ́ bí ẹrú olóòótọ́ àti olóye fún Ọ̀gá wọn, ìyẹn ni pé kí wọ́n máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò. Wọ́n ti gba ìdájọ́ “O káre láé,” Ọ̀gá wọn sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n mú ọwọ́ wọn dí lẹ́ẹ̀kan sí i lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà.—Mátíù 24:45-47; 25:21, 23; Ìṣe 1:8.
8. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni olùṣọ́ inú Aísáyà 21:8, 9 pòkìkí rẹ̀, ẹgbẹ́ wo lónìí sì ni olùṣọ́ náà ṣàpẹẹrẹ?
8 Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn Jèhófà lo àwọn wòlíì mìíràn láti sàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yẹn. Aísáyà sọ̀rọ̀ nípa olùṣọ́ kan tó “ké bí kìnnìún pé: ‘Jèhófà, orí ilé ìṣọ́ ni mo dúró sí nígbà gbogbo ní ọ̀sán, ibi ìṣọ́ mi sì ni mo dúró sí ní gbogbo òru.’” Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni olùṣọ́ náà rí tó sì fi ìgboyà pòkìkí rẹ̀ bíi ti kìnnìún? Bó ṣe ṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà rèé: “Ó ti ṣubú! Bábílónì ti ṣubú, gbogbo ère fífín ti àwọn ọlọ́run rẹ̀ ni òun [Jèhófà] ti wó mọ́lẹ̀!” (Aísáyà 21:8, 9) Olùṣọ́ yìí ṣàpẹẹrẹ ẹgbẹ́ Jòhánù tó wà lójúfò rekete lónìí, bí ẹgbẹ́ náà ti ń lo ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí ètò Ọlọ́run ń pèsè láti fi máa polongo káàkiri pé Bábílónì ti ṣubú.
Agbára Bábílónì Ńlá Ti Ń Tán Lọ
9, 10. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí agbára ìsìn Bábílónì látìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní? (b) Báwo ni áńgẹ́lì alágbára ńlá náà ṣe ṣàpèjúwe ipò tí Bábílónì Ńlá wà lẹ́yìn tó ṣubú?
9 Nígbà tí ìlú Bábílónì ayé ọjọ́un ṣubú lọ́dún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, agbára rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í jó àjórẹ̀yìn díẹ̀díẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún títí tó fi dahoro pátápátá. Lọ́nà kan náà, agbára ìsìn Bábílónì tòde òní ti ń tán lọ kárí ayé lọ́nà tó yá kánkán látìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Nílẹ̀ Japan, wọ́n fòfin de ìjọsìn olú ọba Ṣintó lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì. Lórílẹ̀-èdè Ṣáínà, ìjọba Kọ́múníìsì ló ń darí gbogbo ohun tí ìsìn ń ṣe àti bí ìsìn ṣe ń yan àwọn èèyàn sípò. Ní àríwá Yúróòpù tí ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ti gbilẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ti dágunlá sí ìsìn. Bákan náà, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìyapa àti èdèkòyédè abẹ́lé tó ń wáyé nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì kárí ayé ti sọ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì di aláìlera.—Fi wé Máàkù 3:24-26.
10 Kò sí àní-àní pé gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ apá kan ‘gbígbẹ tí odò Yúfírétì gbẹ ráúráú’ láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún kíkọ táwọn ológun máa kọ lu Bábílónì Ńlá. Ohun mìíràn tó tún fi hàn pé omi yìí ti ń ‘gbẹ ráúráú’ ni ìkéde tí póòpù ṣe lóṣù October ọdún 1986 pé Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì gbọ́dọ̀ “di alágbe lẹ́ẹ̀kan sí i” nítorí àwọn gbèsè jaburata tó jẹ. (Ìṣípayá 16:12) Ní pàtàkì látọdún 1919, àṣírí Bábílónì Ńlá ti tú sójútáyé pé ó ti di ilẹ̀ ahoro nípa tẹ̀mí, gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì alágbára ńlá náà ṣe kéde pé: “Ó sì ti di ibi gbígbé àwọn ẹ̀mí èṣù àti ibi ìlúgọpamọ́ sí fún gbogbo èémí àmíjáde àìmọ́ àti ibi ìlúgọpamọ́ sí fún gbogbo ẹyẹ àìmọ́ àti èyí tí a kórìíra!” (Ìṣípayá 18:2b) Láìpẹ́, Bábílónì Ńlá yóò di ilẹ̀ ahoro, á rí bí àwókù Bábílónì tó wà lórílẹ̀-èdè Iraq tòde òní.—Tún wo Jeremáyà 50:25-28.
11. Lọ́nà wo ni Bábílónì Ńlá gbà di “ibi gbígbé àwọn ẹ̀mí èṣù” àti ibi ìlúgọpamọ́ sí fún ‘gbogbo èémí àmíjáde àìmọ́ àti àwọn ẹyẹ àìmọ́’?
11 Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀mí èṣù” tí ẹsẹ yẹn mẹ́nu kàn fara pẹ́ ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀mí èṣù onírìísí ewúrẹ́” (se‘i·rimʹ) tí Aísáyà lò nígbà tó ń ṣàpèjúwe bí Bábílónì ṣe rí lẹ́yìn tó ṣubú. Bí Aísáyà ṣe sọ ọ́ rèé: “Ibẹ̀ sì ni àwọn olùgbé àwọn ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò dùbúlẹ̀ sí dájúdájú, ilé wọn yóò sì kún fún àwọn òwìwí idì. Ibẹ̀ sì ni àwọn ògòǹgò yóò máa gbé, àwọn ẹ̀mí èṣù onírìísí ewúrẹ́ pàápàá yóò sì máa tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri níbẹ̀.” (Aísáyà 13:21) Èyí lè má tọ́ka sí àwọn ẹ̀mí èṣù ní ti gidi, kàkà bẹ́ẹ̀ ó lè jẹ́ pé ohun tó ń tọ́ka sí ni àwọn ẹran onírun yàwìrì tí ń gbé aṣálẹ̀ tí ìrísí wọn ń mú káwọn tó bá rí wọn ronú nípa ẹ̀mí èṣù. Wíwà tí irú àwọn ẹran bẹ́ẹ̀ wà nínú àwókù Bábílónì Ńlá lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, pa pọ̀ pẹ̀lú afẹ́fẹ́ onímájèlé tí kò ríbi fẹ́ lọ (èyí tí “èémí àmíjáde àìmọ́” ṣàpẹẹrẹ) àtàwọn ẹyẹ àìmọ́, ń fi hàn pé Bábílónì Ńlá ti kú nípa tẹ̀mí. Kò nawọ́ ìrètí níní ìyè sí aráyé rárá.—Fi wé Éfésù 2:1, 2.
12. Báwo ni ipò tí Bábílónì Ńlá wà ṣe bá àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà tó wà nínú Jeremáyà orí 50 mu?
12 Ipò tó wà tún bá àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà mu, ó ní: “‘Idà kan wà lòdì sí àwọn ará Kálídíà,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àti lòdì sí àwọn olùgbé Bábílónì àti lòdì sí àwọn ọmọ aládé rẹ̀ àti lòdì sí àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀. . . . Ìparundahoro wà lórí omi rẹ̀, a ó gbẹ ẹ́ táútáú. Nítorí ilẹ̀ ère fínfín ni, wọ́n sì ń ṣe bí ayírí nítorí àwọn ìran wọn tí ń da jìnnìjìnnì boni. Nítorí náà, àwọn olùgbé ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò máa gbé pẹ̀lú àwọn ẹranko tí ń hu, inú rẹ̀ sì ni ògòǹgò yóò máa gbé; a kì yóò sì gbé inú rẹ̀ mọ́ láé, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí mọ́ láti ìran dé ìran.’” Ìbọ̀rìṣà àti gbígba àdúrà àwítúnwí kò lè gba Bábílónì Ńlá lọ́wọ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tó máa dà bí ìgbà tí Ọlọ́run bi Sódómù àti Gòmórà ṣubú.—Jeremáyà 50:35-40.
Wáìnì Tí Ń Ru Ìfẹ́ Ìgbónára Sókè
13. (a) Báwo ni áńgẹ́lì alágbára ńlá náà ṣe pe àfiyèsí sí bí ìwà aṣẹ́wó Bábílónì Ńlá ṣe gbòòrò tó? (b) Ìwà ìṣekúṣe wo ló wọ́pọ̀ ní Bábílónì ìgbàanì tá a tún rí nínú Bábílónì Ńlá?
13 Lẹ́yìn èyíinì, áńgẹ́lì alágbára ńlá náà pe àfiyèsí sí bí ìwà aṣẹ́wó Bábílónì Ńlá ṣe gbòòrò tó, ó pòkìkí pé: “Nítorí pé tìtorí wáìnì tí ń ru ìfẹ́ ìgbónára àgbèrè rẹ̀ sókè,a gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ti di ẹran-ìjẹ, àwọn ọba ilẹ̀ ayé sì bá a ṣe àgbèrè, àwọn olówò arìnrìn-àjò ilẹ̀ ayé sì di ọlọ́rọ̀ nítorí agbára fàájì aláìnítìjú rẹ̀.” (Ìṣípayá 18:3) Bábílónì Ńlá ti fi àwọn ohun àṣà àìmọ́ tó wà nínú ìsìn rẹ̀ kọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Gẹ́gẹ́ bí Herodotus òpìtàn Gíríìkì ti wí, ní Bábílónì ìgbàanì, wọ́n fi dandan lé e pé kí gbogbo omidan fi ipò wúńdíá rẹ̀ ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó nínú ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe nínú tẹ́ńpìlì wọn. Dòní olónìí, ìwà ìṣekúṣe tí ń ríni lára ni àwọn ère gbígbẹ́ tí ogun ti bà jẹ́ tó wà ní Angkor Wat lórílẹ̀-èdè Kampuchea ń gbé lárugẹ, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ère tó wà nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Khajuraho, nílẹ̀ Íńdíà. Àwọn ère náà fi ọlọ́run Vishnu hàn láàárín àwọn àwòrán rírínilára tó ń mú kí ọkàn fà sí ìṣekúṣe. Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àṣírí ìwà ìṣekúṣe àwọn ajíhìnrere orí tẹlifíṣọ̀n tú síta lọ́dún 1987 àti lọ́dún 1988, èyí tó fì wọ́n làkàlàkà. Bákan náà, àṣírí àwọn òjíṣẹ́ ìsìn tó ń bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ tú. Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí fi hàn pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì pàápàá fàyè gba ìwà àgbèrè lọ́nà tó pabanbarì. Àmọ́, gbogbo orílẹ̀-èdè ti kó sínú páńpẹ́ oríṣi ìwà àgbèrè mìíràn tó burú jáì.
14-16. (a) Àjọṣe tí kò bófin mu wo ló wà láàárín ìsìn àti ìṣèlú nílẹ̀ Ítálì tí ìjọba Oníkùmọ̀ ń ṣàkóso? (b) Nígbà tí Ítálì gbógun ti ilẹ̀ Abisíníà, kí làwọn bíṣọ́ọ̀bù Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì sọ?
14 Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ a ti ṣàgbéyẹ̀wò àjọṣe aláìbófinmu tó wà láàárín ìsìn àti ìṣèlú, èyí tó gbé Hitler dé ipò olórí ìjọba Násì nílẹ̀ Jámánì. Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn pẹ̀lú jìyà nítorí títì tí ìsìn tojú bọ àwọn ohun tó ń lọ nínú ayé. Bí àpẹẹrẹ: Nílẹ̀ Ítálì tí ìjọba aláṣẹ oníkùmọ̀ ti ń ṣàkóso, ní ọjọ́ kọkànlá oṣù February, ọdún 1929, Mussolini àti Kádínà Gasparri fọwọ́ sí Àdéhùn Lateran tó sọ Ìlú Vatican di ìpínlẹ̀ olómìnira tí ń ṣe ìjọba lórí ara rẹ̀. Póòpù Pius Kọkànlá sọ pé òun ti “dá Ítálì padà fún Ọlọ́run, àti Ọlọ́run padà fún Ítálì.” Àmọ́, ṣé òótọ́ ni? Ó dáa, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà. Ní ọjọ́ kẹta oṣù October, ọdún 1935, Ítálì gbógun ti ilẹ̀ Abisíníà, ó sọ pé Abisíníà jẹ́ “ilẹ̀ oníwà òǹrorò tó ṣì ń ṣe òwò ẹrú.” Àmọ́ ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ta ni òǹrorò nínú àwọn méjèèjì? Ǹjẹ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì dẹ́bi fún ìwà ìkà tí Mussolini hù? Nígbà tí póòpù ń sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tí ò lè tètè yé èèyàn ló lò, àmọ́ àwọn bíṣọ́ọ̀bù rẹ̀ ò ṣẹ́ ọ̀rọ̀ kù sábẹ́ ahọ́n nígbà tí wọ́n ń gbàdúrà fún àwọn ọmọ ogun Ítálì “ilẹ̀ baba” wọn. Nínú ìwé náà, The Vatican in the Age of the Dictators, Anthony Rhodes ròyìn pé:
15 “Nínú Lẹ́tà Olùṣọ́ Àgùntàn rẹ̀ ti ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù October ọdún [1935], Bíṣọ́ọ̀bù ìlú Udine [ní Ítálì] kọ̀wé pé, ‘Kò bákòókò mu bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ ká sọ̀rọ̀ nípa bóyá ohun tá à ń ṣe náà dára tàbí kò dára. Bó ṣe jẹ́ pé ọmọ ilẹ̀ Ítálì ni wá, pàápàá jù lọ tá a tún jẹ́ Kristẹni, ojúṣe wa ni láti ṣe ipa tiwa nínú bí àwọn ohun ìjà ilẹ̀ wa á ṣe ṣàṣeyọrí.’ Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù October, Bíṣọ́ọ̀bù ìlú Padua kọ̀wé pé, ‘Ní àkókò lílekoko tá a wà yìí, a rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ nígbàgbọ́ nínú àwọn olóṣèlú wa àtàwọn ọmọ ogun wa.’ Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù October, Bíṣọ́ọ̀bù ìlú Cremona ya àwọn àsíá ẹgbẹ́ ọmọ ogun sí mímọ́ ó sì sọ pé: ‘Kí ìbùkún Ọlọ́run wà lórí àwọn ọmọ ogun wa wọ̀nyí tí wọn yóò lọ sí Áfíríkà láti ṣẹ́gun àwọn ilẹ̀ ọlọ́ràá fún Ítálì àgbà orílẹ̀-èdè, tí wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí wọ́n gba àṣà ilẹ̀ Róòmù àti ti ẹ̀sìn Kristẹni. Ǹjẹ́ kí Ítálì tún ṣe ojúṣe rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tó ń fi ẹ̀sìn Kristẹni kọ́ gbogbo ayé.’”
16 Àwọn àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ló gbàdúrà fáwọn ọmọ ogun tó gbógun ja ilẹ̀ Abisíníà. Lọ́nàkọnà, ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni nínú àwọn wọ̀nyí lè sọ pé àwọ́n dà bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí ‘ọrùn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ èèyàn gbogbo’?—Ìṣe 20:26.
17. Báwo ni ìyà ṣe jẹ́ orílẹ̀-èdè Sípéènì nítorí pé àwọn àlùfáà rẹ̀ kò “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀”?
17 Yàtọ̀ sí Jámánì, Ítálì àti Abisíníà, Sípéènì ni orílẹ̀-èdè mìíràn tójú rẹ̀ rí màbo látàrí ìwà àgbèrè Bábílónì Ńlá. Ohun tí ìjọba dẹmọ ṣe láti dín agbára ńlá tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ní kù wà lára ohun tó mú kí Ogun Abẹ́lé wáyé nílẹ̀ Sípéènì lọ́dún 1936 sí 1939. Nígbà tí ogun abẹ́lé náà bẹ̀rẹ̀, Franco onísìn Kátólíìkì, tó jẹ́ olórí ìjọba aláṣẹ oníkùmọ̀ àti aṣáájú àwọn ọmọ ogun aṣọ̀tẹ̀-síjọba, sọ pé òun jẹ́ “Olórí Ogun Mímọ́ Tí Ìsìn Kristẹni Ń Jà,” ó sì pa oyè yẹn tì nígbà tó yá. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Sípéènì ló kú nínú ogun abẹ́lé náà. Yàtọ̀ sí èyí, iye kan tí wọ́n bù kéré fi hàn pé, àwọn Aṣọ̀tẹ̀-síjọba ọmọlẹ́yìn Franco pa ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì [40,000] àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Popular Front, ẹgbẹ́ òṣèlú Popular Front pẹ̀lú sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ [8,000] àwọn abẹnugan nínú ìsìn, ìyẹn àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, àwọn àlùfáà, àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, àtàwọn tó ń múra àtidi obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé. Ìpayà àti àdánù tí ogun abẹ́lé yẹn fà kàmàmà, ó sì fi hàn pé ìwà ọgbọ́n ni kéèyàn ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:52) Ẹ wo bó ti ń kóni nírìíra tó pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lọ́wọ́ nínú ìtàjẹ̀sílẹ̀ tó burú jáì yìí! Dájúdájú, àwọn àlùfáà wọn ò “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀” rárá!—Aísáyà 2:4.
Àwọn Olówò Arìnrìn-Àjò
18. Ta ni “àwọn olówò arìnrìn-àjò ilẹ̀ ayé”?
18 Àwọn wo ni “àwọn olówò arìnrìn-àjò ilẹ̀ ayé”? Láìsí àní-àní, ohun tá a mọ̀ wọ́n sí lóde òní ni àwọn oníṣòwò, àwọn oníṣòwò kàǹkà-kàǹkà, àwọn ọlọ́gbọ́n bérébéré nínú iṣẹ́ ajé ńláńlá. A ò sọ pé ó burú láti lọ́wọ́ nínú òwò tó bófin mu. Bíbélì gba àwọn oníṣẹ́ ajé nímọ̀ràn ọlọgbọ́n, ó kìlọ̀ pé àbòsí, ìwọra, àti àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ kò dára. (Òwe 11:1; Sekaráyà 7:9, 10; Jákọ́bù 5:1-5) “Fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi” ni èrè tó tóbi jù. (1 Tímótì 6:6, 17-19) Ṣùgbọ́n, ayé Sátánì kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo. Ìwà ìbàjẹ́ pọ̀ gidigidi. Ó wà nínú ìsìn, nínú ìṣèlú àti nínú iṣẹ́ ajé ńláńlá. Látìgbàdégbà ni ilé iṣẹ́ ìròyìn ń tú àṣírí ìwà ìbàjẹ́, irú bí àwọn àgbà òṣìṣẹ́ ìjọba tí ń kówó jẹ àti ṣíṣe fàyàwọ́ àwọn ohun ìjà ogun.
19. Àwọn ohun wo nípa ọrọ̀ ajé ayé ló ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàlàyé ìdí tí ìwé Ìṣípayá ò fi sọ̀rọ̀ àwọn olówò ilẹ̀ ayé sí dáadáa?
19 Lọ́dọọdún, iye tó ń lọ sórí òwò ohun ìjà ogun jákèjádò ayé ti lé ní ẹgbẹ̀rún bílíọ̀nù [1,000,000,000,000] owó dọ́là, bẹ́ẹ̀ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni wọ́n fi àwọn ohun kòṣeémáàní ìgbésí ayé du. Èyí mà kúkú burú o. Síbẹ̀, ó jọ pé inú àwọn ohun ìjà ni wọ́n ti ń rówó ṣe ìtìlẹyìn tó pọ̀ fún ọrọ̀ ajé ayé. Ní ọjọ́ kọkànlá oṣù April ọdún 1987, àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Spectator ti London ròyìn pé: “Téèyàn bá ka àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣe àwọn ohun ìjà, èèyàn á rí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà irínwó [400,000] ní Amẹ́ríkà àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta lé lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [750,000] ní Yúróòpù. Ṣùgbọ́n kàyéfì gbáà ni pé, bí ìlọsíwájú ṣe ń bá àwùjọ àti ọrọ̀ ajé ayé látàrí ṣíṣe àwọn ohun ìjà jáde, àwọn èèyàn kò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ ronú nípa bóyá àwọn tí ń ṣe ohun ìjà ọ̀hún jáde wà láìséwu.” Owó gọbọi ni wọ́n ń rí bí wọ́n ṣe ń fi bọ́ǹbù àtàwọn ohun ìjà mìíràn ṣòwò káàkiri ayé, àní wọ́n tún ń tà wọ́n fún àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n di ọ̀tá wọn pàápàá. Lọ́jọ́ kan ṣáá, àwọn tí wọ́n ń ta àwọn bọ́ǹbù wọ̀nyẹn fún lè padà wá yìn ín lù wọ́n láti pa wọ́n run. Ẹ ò rí i pé ìfọwọ́-ara-ẹni-ṣera-ẹni nìyẹn máa jẹ́! Yàtọ̀ síyẹn, ìwà jìbìtì kún ọwọ́ àwọn oníléeṣẹ́ tó ń ṣe ohun ìjà. Ìwé ìròyìn Spectator sọ pé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan, “lọ́dọọdún iléeṣẹ́ ètò ààbò ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ìyẹn Pentagon, ń pàdánù àwọn ohun ìjà àti ohun èlò tí owó rẹ̀ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án mílíọ̀nù [900] dọ́là láìmọ bó ṣe ṣẹlẹ̀.” Abájọ tí ìwé Ìṣípayá ò fi sọ̀rọ̀ àwọn olówò ilẹ̀ ayé sí dáadáa!
20. Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé ìsìn ti lọ́wọ́ nínú ìwà ìbàjẹ́ iṣẹ́ ajé?
20 Bí áńgẹ́lì ológo náà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ìsìn ti lọ́wọ́ nínú àwọn ìwà ìbàjẹ́ iṣẹ́ ajé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì wà nínú àwọn tó jẹ́ kí ilé ìfowópamọ́ Banco Ambrosiano ní Ítálì kógbá sílé lọ́dún 1982. Ńṣe ni wọ́n ń fi ẹjọ́ ọ̀ràn náà falẹ̀ láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, wọn ò ṣèwádìí àwọn tó kówó jẹ tí ilé ìfowópamọ́ náà fi kógbá sílé. Ní oṣù February ọdún 1987, àwọn adájọ́ ìlú Milan pàṣẹ pé kí wọ́n fòfin mú mẹ́ta nínú àwọn àlùfáà Kátólíìkì tó wà nílùú Vatican, títí kan Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan, lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ṣe onígbọ̀wọ́ ìwà jìbìtì tó mú kí ilé ìfowópamọ́ náà wọ gbèsè ńlá, ṣùgbọ́n àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì kò jẹ́ kí wọ́n dá àwọn ọ̀daràn náà padà sí orílẹ̀-èdè wọn fún ìjẹ́jọ́. Ní oṣù July ọdún 1987, láìka gbogbo àtakò sí, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn gíga jù lọ ní Ítálì fagi lé ìfòfinmúni náà, ohun tó sì jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀ ni àdéhùn kan tó ti wà láàárín Vatican àti ìjọba Ítálì.
21. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù kò lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ajé tó ń kọni lóminú nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n kí la rí lónìí nínú ìsìn Bábílónì?
21 Ǹjẹ́ Jésù lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ajé tó ń kọni lóminú nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé? Ó tì o. Kò tilẹ̀ ní dúkìá kankan, nítorí “kò ní ibì kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.” Jésù gba ọ̀dọ́ ọlọ́rọ̀ tó jẹ́ olùṣàkóso nímọ̀ràn pé: “Ta gbogbo ohun tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn òtòṣì, ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run; sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.” Ìmọ̀ràn àtàtà nìyẹn jẹ́, nítorí ì bá ti ràn án lọ́wọ́ láti bọ́ nínú gbogbo àníyàn tó ń ṣe nítorí iṣẹ́ ajé. (Lúùkù 9:58; 18:22) Ìsìn Bábílónì kò tẹ́ lé ọ̀rọ̀ yẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ajé ńlá tó ríni lára. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1987, ìwé ìròyìn Albany Times Union sọ pé ẹni tó ń mójú tó ọ̀ràn ìnáwó àgbègbè tó wà lábẹ́ bíṣọ́ọ̀bù àgbà Kátólíìkì ní ìlú Miami, Florida, nílẹ̀ Amẹ́ríkà, jẹ́wọ́ pé ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ní owó ìdókòwò nínú àwọn ilé iṣẹ́ tí ń ṣe àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà, àwọn ilé iṣẹ́ tí ń ṣe àwọn sinimá oníwà ìbàjẹ́, àti sìgá.
“Ẹ Jáde Kúrò Nínú Rẹ̀, Ẹ̀yin Ènìyàn Mi”
22. (a) Kí ni ohùn kan láti ọ̀run wí? (b) Kí ló máyọ̀ wá fún àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Kristẹni àti lọ́dún 1919?
22 Ọ̀rọ̀ tí Jòhánù sọ tẹ̀ lé e tún tọ́ka sí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀, ó ní: “Mo sì gbọ́ tí ohùn mìíràn láti ọ̀run wá wí pé: ‘Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.’” (Ìṣípayá 18:4) Nínú Ìwé Mímọ́, ara ohun tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣubú Bábílónì ayé ọjọ́un máa ń sọ ni àṣẹ tí Jèhófà pa fáwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹ fẹsẹ̀ fẹ kúrò ní àárín Bábílónì.” (Jeremáyà 50:8, 13) Lọ́nà kan náà, nítorí pé Bábílónì Ńlá máa dahoro, àwọn èèyàn Ọlọ́run là ń rọ̀ láti sá àsálà nísinsìnyí. Lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Kristẹni, inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olóòótọ́ dùn púpọ̀ nígbà tí wọ́n láǹfààní láti sá kúrò ní ìlú Bábílónì. Lọ́nà kan náà, inú àwọn èèyàn Ọlọ́run dùn nígbà tí wọ́n rí ìtúsílẹ̀ kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì lọ́dún 1919. (Ìṣípayá 11:11, 12) Látìgbà yẹn, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn mìíràn ti ṣe ìgbọràn sí àṣẹ náà láti sá kúrò nínú Bábílónì Ńlá.
23. Báwo ni ohùn tó wá láti ọ̀run ṣe tẹnu mọ́ ọn pé ó jẹ́ kánjúkánjú láti sá kúrò nínú Bábílónì Ńlá?
23 Ṣé bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó ni pé kéèyàn sá kúrò nínú Bábílónì Ńlá, kéèyàn yọwọ́yọsẹ̀ kúrò nínú jíjẹ́ ara ìsìn ayé kéèyàn sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pátápátá? Bẹ́ẹ̀ ni o, nítorí pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo Bábílónì Ńlá tó jẹ́ abàmì ìsìn àtọdúnmọ́dún làwa náà ní láti fi wò ó. Ọlọ́run ò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ó pè é ní aṣẹ́wó ńlá. Nítorí náà, ohùn láti ọ̀run wá sọ fún Jòhánù síwájú sí i nípa aṣẹ́wó yìí pé: “Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti wọ́ jọpọ̀ títí dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti mú àwọn ìṣe àìṣèdájọ́ òdodo rẹ̀ wá sí ìrántí. Ẹ ṣe sí i, àní gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀ ti ṣe síni, ẹ sì ṣe sí i ní ìlọ́po méjì, bẹ́ẹ̀ ni, ìlọ́po méjì iye ohun tí ó ṣe; nínú ife tí ó fi àdàlù kan sí, ẹ fi ìlọ́po méjì àdàlù náà sí i fún un. Dé àyè tí ó ṣe ara rẹ̀ lógo, tí ó sì gbé nínú fàájì aláìnítìjú, dé àyè yẹn ni kí ẹ fún un ní ìjoró àti ọ̀fọ̀. Nítorí pé nínú ọkàn-àyà rẹ̀, ó ń wí ṣáá pé, ‘Mo jókòó bí ọbabìnrin, èmi kì í sì í ṣe opó, èmi kì yóò sì rí ọ̀fọ̀ láé.’ Ìdí nìyẹn tí àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀, ikú àti ọ̀fọ̀ àti ìyàn, yóò fi dé ní ọjọ́ kan ṣoṣo, a ó sì fi iná sun ún pátápátá, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣèdájọ́ rẹ̀, jẹ́ alágbára.”—Ìṣípayá 18:5-8.
24. (a) Àwọn èèyàn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ sá kúrò nínú Bábílónì Ńlá láti yẹra fún kí ni? (b) Ẹ̀ṣẹ̀ wo làwọn tí wọ́n ò sá kúrò nínú Bábílónì Ńlá ń ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀?
24 Ẹ ò rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lágbára! Nítorí náà, ó yẹ kéèyàn ṣe ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Jeremáyà rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ọjọ́ rẹ̀ láti ṣe ohun tó yẹ, ó ní: “Ẹ sá lọ kúrò nínú Bábílónì, . . . nítorí ó jẹ́ àkókò ẹ̀san tí ó jẹ́ ti Jèhófà. Ìlòsíni kan wà tí yóò san padà fún un. Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, kí olúkúlùkù yín sì pèsè àsálà fún ọkàn rẹ̀ lọ́wọ́ jíjófòfò ìbínú Jèhófà.” (Jeremáyà 51:6, 45) Lọ́nà kan náà, ohùn tó wá láti ọ̀run náà ń kìlọ̀ fáwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí láti sá kúrò nínú Bábílónì Ńlá kí ìyọnu tó máa dé bá a má bàa kàn wọ́n. Nísinsìnyí, à ń pòkìkí ìdájọ́ Jèhófà lórí ayé yìí, títí kan Bábílónì Ńlá, ìdájọ́ náà yóò sì dà bí ìyọnu ńláǹlà. (Ìṣípayá 8:1–9:21; 16:1-21) Àwọn èèyàn Ọlọ́run ní láti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ìsìn èké bí wọn ò bá fẹ́ kí ìdájọ́ Jèhófà tó dà bí ìyọnu ńláǹlà yẹn kàn wọ́n kí wọ́n sì pa run pọ̀ mọ́ ìsìn èké. Yàtọ̀ síyẹn, bí wọn ò bá kúrò nínú ètò ìsìn èké, wọn yóò pín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Bíi ti Bábílónì Ńlá wọn yóò jẹ̀bi ìwà panṣágà nípa tẹ̀mí àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ “gbogbo àwọn tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 18:24; fi wé Éfésù 5:11; 1 Tímótì 5:22.
25. Báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe jáde kúrò nínú Bábílónì ìgbàanì?
25 Ṣùgbọ́n, báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ń jáde kúrò nínú Bábílónì Ńlá? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe jáde kúrò nínú Bábílónì ayé ọjọ́un? Wọ́n jáde kúrò nínú Bábílónì ayé ọjọ́un nípa rírin ìrìn àjò kúrò níbẹ̀ padà sí iyàn-níyàn Ilẹ̀ Ìlérí. Àmọ́ ó ṣì tún ku ohun mìíràn tí wọ́n máa ṣe. Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ èyí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ yí padà, ẹ yí padà, ẹ jáde kúrò níbẹ̀, ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan; ẹ jáde kúrò ní àárín rẹ̀, ẹ wẹ ara yín mọ́, ẹ̀yin tí ń gbé àwọn nǹkan èlò Jèhófà.” (Aísáyà 52:11) Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ní láti pa gbogbo ìwà àìmọ́ ti ìsìn Bábílónì tì, èyí tó lè ta àbààwọ́n sí ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe sí Jèhófà.
26. Báwo làwọn Kristẹni ará Kọ́ríńtì ṣe ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà pé, ‘Ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́ kan ohun àìmọ́’?
26 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ Aísáyà yọ nínú lẹ́tà rẹ̀ tó kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì, ó ní: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? Tàbí àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn? . . . ‘Nítorí náà, ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́.’” Kò di dandan pé káwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì fi Kọ́ríńtì sílẹ̀ kí wọ́n tó lè ṣègbọràn sí àṣẹ yẹn. Ńṣe ni wọ́n ní láti yẹra fún àwọn tẹ́ńpìlì àìmọ́ táwọn èèyàn ti ń ṣe ìsìn èké, wọn ò sì gbọ́dọ̀ kọ́ ìṣe àìmọ́ àwọn abọ̀rìṣà wọ̀nyẹn. Lọ́dún 1919, àwọn èèyàn Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í sá kúrò nínú Bábílónì Ńlá lọ́nà yìí, wọ́n wẹ ara wọn mọ́ kúrò nínú àwọn ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà àìmọ́ èyíkéyìí. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wọn láti sin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn rẹ̀ tá a ti wẹ̀ mọ́.—2 Kọ́ríńtì 6:14-17; 1 Jòhánù 3:3.
27. Àwọn ìbáradọ́gba wo ní ń bẹ láàárín ìdájọ́ lórí Bábílónì ìgbàanì àti lórí Bábílónì Ńlá?
27 Ìṣubú Bábílónì ìgbàanì àti ahoro tó dà nígbẹ̀yìngbẹ́yín ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. “Nítorí títí dé ọ̀run ni ìdájọ́ rẹ̀.” (Jeremáyà 51:9) Lọ́nà kan náà, ẹ̀ṣẹ̀ Bábílónì Ńlá ti “wọ́ jọpọ̀ títí dé ọ̀run,” tí Jèhófà fúnra rẹ̀ fi kíyè sí i. Ó ti jẹ̀bi àìṣèdájọ́ òdodo, ìbọ̀rìṣà, ìṣekúṣe, ìninilára, ìfipájalè, àti ìṣìkàpànìyàn. Ìṣubú Bábílónì ìgbàanì jẹ́ ara ẹ̀san tó rí gbà fún ohun tó ti ṣe fún tẹ́ńpìlì Jèhófà àtàwọn olùjọsìn tòótọ́ rẹ̀. (Jeremáyà 50:8, 14; 51:11, 35, 36) Ìṣubú Bábílónì Ńlá àti ìparun rẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín lọ́nà kan náà jẹ́ ìgbẹ̀san fún ohun tó ti ṣe sí àwọn olùjọsìn tòótọ́ láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá. Kódà, ìparun rẹ̀ ìkẹyìn ló máa jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ‘ọjọ́ ẹ̀san látọwọ́ Ọlọ́run wa.’—Aísáyà 34:8-10; 61:2; Jeremáyà 50:28.
28. Ìlànà ìdájọ́ òdodo wo ni Jèhófà máa lò fún Bábílónì Ńlá, kí sì nìdí?
28 Lábẹ́ Òfin Mósè, bí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá ja ará ìlú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lólè, ó ní láti san án padà ó kéré tán ní ìlọ́po méjì. (Ẹ́kísódù 22:1, 4, 7, 9) Nígbà ìparun Bábílónì Ńlá tí ń bọ̀, Jèhófà yóò lo ìlànà ìdájọ́ òdodo tó fara jọ ọ́. Bábílónì Ńlá yóò gba ìlọ́po méjì ohun tó fi fúnni. Kì yóò rí àánú gbà nítorí pé òun náà kò fi àánú kankan hàn sáwọn tó kó nígbèkùn. Ó ń jẹ lára àwọn èèyàn ilẹ̀ ayé kó lè máa wà nínú “fàájì aláìnítìjú” lọ. Ìyà yóò jẹ òun náà á sì ṣọ̀fọ̀. Bábílónì ìgbàanì rò pé òun wà níbi ààbò tí mìmì kan ò ti lè mi òun, ó ń ṣògo pé: “Èmi kì yóò jókòó gẹ́gẹ́ bí opó, èmi kì yóò sì mọ àdánù àwọn ọmọ.” (Aísáyà 47:8, 9, 11) Bábílónì Ńlá pẹ̀lú sọ pé mìmì kan ò lè mi òun. Ṣùgbọ́n ìparun rẹ̀ tí Jèhófà tó “jẹ́ alágbára” ti pàṣẹ rẹ̀, yóò ṣẹlẹ̀ lójijì, bí ẹni pé “ní ọjọ́ kan ṣoṣo”!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 263]
“Àwọn Ọba . . . Bá A Ṣe Àgbèrè”
Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1800, àwọn olówò ará Yúróòpù ń ṣe fàyàwọ́ oògùn olóró opium púpọ̀ gan-an wọ ilẹ̀ Ṣáínà. Ní oṣù March ọdún 1839 àwọn aláṣẹ ará Ṣáínà gbìyànjú láti dáwọ́ òwò aláìbófinmu náà dúró nípa fífi ipá gba ọ̀kẹ́ kan [20,000] àpótí oògùn olóró náà lọ́wọ́ àwọn oníṣòwò ará Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Èyí yọrí sí gbọ́nmi-sí-omi-ò-tó láàárín Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ṣáínà. Bí àjọṣe tó wà láàárín orílẹ̀-èdè méjèèjì yẹn ṣe ń bà jẹ́ sí i, àwọn míṣọ́nárì ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì kan rọ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láti sọ ọ́ di ogun, wọ́n sọ gbólóhùn bíi:
“Gbọ́nmi-si-omi-ò-to yìí mú inú mi dùn nítorí pé mo rò pé ó lè mú kí ìjọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì bínú, Ọlọ́run nínú agbára rẹ̀ sì lè lo ìyẹn láti fi wó ògiri ìdènà tí kò jẹ́ kí ìhìn rere nípa Kristi wọ ilẹ̀ Ṣáínà.”—Ẹni tó sọ bẹ́ẹ̀ ni Henrietta Shuck, tó jẹ́ míṣọ́nárì ìjọ Southern Baptist.
Níkẹyìn, ogun bẹ́ sílẹ̀, ìyẹn ogun tá a mọ̀ lónìí sí Ogun Opium. Gbogbo ọkàn làwọn míṣọ́nárì ṣọ́ọ̀ṣì fi fún Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì níṣìírí láti jà nípa sísọ àwọn ọ̀rọ̀ bí ìwọ̀nyí:
“Mo rí i pé mi ò gbọ́dọ̀ wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí Ogun Opium tàbí ogun Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, kàkà bẹ́ẹ̀, mo rí i pé Ọlọ́run ló ń lo ìwà ibi èèyàn láti fi fọ́ ohun ìdènà tí kò jẹ́ kí àánú rẹ̀ ráyè wọ ilẹ̀ Ṣáínà.”—Ẹni tó sọ bẹ́ẹ̀ ni Peter Parker, tó jẹ́ míṣọ́nárì ìjọ Congregational.
Ọ̀gbẹ́ni Samuel W. Williams, tóun náà jẹ́ míṣọ́nárì ìjọ Congregational fi kún un pé: “Ó hàn gbangba pé ọwọ́ Ọlọ́run wà nínú gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, a kò sì ṣiyè méjì pé Ẹni tó sọ pé Òun wá láti mú idà wá sórí ayé ti dé láti yára pa àwọn ọ̀tá Rẹ̀ run kó sì bẹ̀rẹ̀ ìjọba Rẹ̀. Yóò máa sojú wọn dé nìṣó títí yóò fi fìdí Ọmọ Aládé Àlàáfíà náà múlẹ̀.”
Míṣọ́nárì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ J. Lewis Shuck kọ̀wé nípa bí wọ́n ṣe pa àwọn ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà nípakúpa, ó ní: “Mo ka irú nǹkan bẹ́ẹ̀ . . . sí ohun èlò tí Olúwa lò láti fi gbá àwọn pàǹtírí tí ń dènà ìlọsíwájú Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Ọlọ́run dà nù.”
Míṣọ́nárì ìjọ Congregational kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elijah C. Bridgman fi kún un pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run ti lo agbára èèyàn láti fi lànà sílẹ̀ fún ìjọba Rẹ̀ . . . Irinṣẹ́ lásán lèèyàn kàn jẹ́ nínú ṣíṣẹ ohun pàtàkì yìí; Ọlọ́run gan-an lẹni tó ń fi agbára rẹ̀ darí wọn. Gómìnà ńlá gbogbo orílẹ̀-èdè ló lo Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láti fìyà jẹ ilẹ̀ Ṣáínà àti láti rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀.”—A mú ọ̀rọ̀ yìí látinú àpilẹ̀kọ náà, “Ends and Means,” tí Stuart Creighton Miller kọ lọ́dún 1974 tí wọ́n sì tẹ̀ jáde nínú ìwé The Missionary Enterprise in China and America (Ìwádìí tí Harvard ṣe tí John K. Fairbank sì ṣàtúntẹ̀ rẹ̀).
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 264]
“Àwọn Olówò Arìnrìn-Àjò . . . Di Ọlọ́rọ̀”
“Láàárín ọdún 1929 sí ìgbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀, [Bernadino] Nogara [tó jẹ́ olùbójútó ọ̀ràn ìnáwó ìlú Vatican] yan àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì àtàwọn aṣojú wọn tó wà nílùú Vatican láti ṣiṣẹ́ ní onírúurú ilé iṣẹ́ tó ń pawó wọlé fún ilẹ̀ Ítálì, pàápàá ní ilé iṣẹ́ iná mànàmáná, ilé iṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ orí tẹlifóònù, níbi ètò ìyánilówó àti ìfowópamọ́, àwọn ojú ọ̀nà rélùwéè kéékèèké, àti ṣíṣe àwọn ohun èlò iṣẹ́ ọ̀gbìn, ṣíṣe sìmẹ́ǹtì, àti onírúurú òwú tí wọ́n fi ń ṣe aṣọ. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìdágbálé wọ̀nyí mú èrè wá.
“Nogara fi ìwọra gba àwọn ilé iṣẹ́ mélòó kan, irú bí ilé iṣẹ́ La Società Italiana della Viscosa, La Suppertessile, La Società Meridionale Industrie Tessili, àti La Cisaraion. Ó sọ àwọn ilé iṣẹ́ wọ̀nyí di ọ̀kan ṣoṣo, èyí tó pè ní CISA-Viscosa tó sì fi sábẹ́ àṣẹ Baron Francesco Maria Oddasso tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì tó wà nílùú Vatican tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé gidigidi. Lẹ́yìn náà ó lo ọgbọ́n láti jẹ́ kí ilé iṣẹ́ tuntun náà di ara ilé iṣẹ́ ahunṣọ tó tóbi jù lọ ní Ítálì, tí wọ́n ń pè ní SNIA-Viscosa. Lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ìpín ìjọ Kátólíìkì tó wà nílùú Vatican nínú ilé iṣẹ́ SNIA-Viscosa túbọ̀ ń gbèrú sí i, nígbà tó sì yá, àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì gba àkóso ilé iṣẹ́ náà, ohun tó sì fi hàn bẹ́ẹ̀ ni pé Baron Oddasso di igbá kejì ààrẹ ilé iṣẹ́ náà nígbà tó yá.
“Báyìí ni Nogara ṣe kó wọnú ilé iṣẹ́ ìhunṣọ. Ó tún kó wọnú àwọn ilé iṣẹ́ mìíràn nítorí pé ọgbọ́n ẹ̀tàn pọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí ọkùnrin tí kò mọ tara rẹ̀ nìkan yìí . . . ṣe láti mú kí ètò ọrọ̀ ajé Ítálì gbèrú pọ̀ ju ti ọkùnrin oníṣòwò èyíkéyìí mìíràn látìgbà ìwáṣẹ̀ ilẹ̀ Ítálì . . . Kò tíì ṣeé ṣe fún Benito Mussolini láti ṣe ìdásílẹ̀ ilẹ̀ ọba tó ní lọ́kàn, ṣùgbọ́n ó ti mú kó ṣeé ṣe fún àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì àti Bernadino Nogara láti dá irú ilẹ̀ àkóso mìíràn sílẹ̀.”—The Vatican Empire, láti ọwọ́ Nino Lo Bello, ojú ìwé 71 sí 73.
Èyí wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ kan ṣoṣo nípa ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tímọ́tímọ́ láàárín àwọn olówò ilẹ̀ ayé àti Bábílónì Ńlá. Abájọ tí àwọn olówò wọ̀nyí yóò fi ṣọ̀fọ̀ nígbà tí alájọṣe wọn nínú iṣẹ́ ajé kò bá sí mọ́!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 259]
Bí àwọn èèyàn ṣe ń lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé, wọ́n mú ìsìn Bábílónì dání pẹ̀lú wọn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 261]
Bí olùṣọ́, ẹgbẹ́ Jòhánù ń pòkìkí pé Bábílónì ti ṣubú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 266]
Àwókù Bábílónì ìgbàanì fi hàn pé ìparun ń bọ̀ wá sórí Bábílónì Ńlá