Orí 8
Lílàkàkà Láti Jẹ́ Aṣẹ́gun
SÍMÍNÀ
1. (a) Ìjọ wo ni Jésù tá a ti ṣe lógo fi iṣẹ́ rẹ̀ kejì ránṣẹ́ sí? (b) Bí Jésù ṣe pe ara rẹ̀ ní “Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn,” kí ló rán àwọn Kristẹni nínú ìjọ náà létí?
LÓNÌÍ, ahoro ni ìlú Éfésù ayé ọjọ́un, àwókù rẹ̀ nìkan lèèyàn lè rí. Àmọ́ ìlú ńlá kan ṣì wà níbi tí Jésù fiṣẹ́ rẹ̀ kejì ránṣẹ́ sí. Orílẹ̀-èdè Turkey ni ìlú ọ̀hún wà, Izmir sì lorúkọ rẹ̀. Ó jẹ́ kìlómítà mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [56] sí àríwá ibi tí àwókù ìlú Éfésù wà. Dòní olónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìjọ mẹ́rin níbẹ̀ tó ń fìtara ṣiṣẹ́. Ní ọ̀rúndún kìíní, ìlú Símínà ló wà níbi tí ìlú Izmir wà báyìí. Wàyí o, fetí sí ọ̀rọ̀ tí Jésù tún sọ. Ó ní: “Sì kọ̀wé sí áńgẹ́lì ìjọ ní Símínà pé: Ìwọ̀nyí ni ohun tí òun wí, ‘Ẹni Àkọ́kọ́ àti Ẹni Ìkẹyìn,’ ẹni tí ó di òkú tẹ́lẹ̀, tí ó sì tún wá sí ìyè.” (Ìṣípayá 2:8) Bí Jésù ṣe sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Símínà pé òun jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn, ńṣe ló ń rán wọn létí pé òun ni olùpàwà-títọ́mọ́ àkọ́kọ́ tí Jèhófà fọwọ́ ara rẹ̀ jí dìde sí ìyè tẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá aláìleèkú, àti pé òun lẹni ìkẹyìn tí Jèhófà fọwọ́ ara rẹ̀ jí dìde bẹ́ẹ̀. Jésù ló máa jí gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yòókù dìde. Nítorí náà, ó kúnjú ìwọ̀n dáadáa láti fún àwọn arákùnrin rẹ̀ nímọ̀ràn, àwọn tí wọ́n nírètí láti ní ìyè àìleèkú ní ọ̀run bíi tiẹ̀.
2. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ Ẹni “tí ó ti di òkú tẹ́lẹ̀ tí ó sì tún wá sí ìyè” fi fún gbogbo Kristẹni níṣìírí?
2 Nínú kéèyàn fara da inúnibíni nítorí òdodo, Jésù ló gbapò iwájú, ó sì rí èrè rẹ̀ gba. Jíjẹ́ tó jẹ́ olóòótọ́ títí dé ojú ikú àti jíjí tó jí dìde ló mú kí gbogbo Kristẹni nírètí. (Ìṣe 17:31) Bí Jésù ṣe “di òkú tẹ́lẹ̀ tí ó sì tún wá sí ìyè” fi hàn pé ohunkóhun téèyàn bá fara dà nítorí òtítọ́ kì í ṣe lórí asán. Àjíǹde Jésù máa ń fún gbogbo Kristẹni níṣìírí gan-an, pàápàá tó bá di pé kí wọ́n jìyà nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Ṣé ò ń jìyà nítorí ìgbàgbọ́ rẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tẹ̀ lé e fún ìjọ Símínà lè fún ọ níṣìírí.
3. (a) Ọ̀rọ̀ ìfinilọ́kànbalẹ̀ wo ni Jésù sọ fún àwọn Kristẹni ní Símínà? (b) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tálákà làwọn Kristẹni ní Símínà, kí nìdí tí Jésù fi sọ pé “ọlọ́rọ̀” ni wọ́n?
3 Jésù sọ pé: “Mo mọ ìpọ́njú àti ipò òṣì rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́—àti ọ̀rọ̀ òdì láti ẹnu àwọn tí ń sọ pé àwọn jẹ́ Júù, síbẹ̀ tí wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ sínágọ́gù Sátánì.” (Ìṣípayá 2:9) Oríyìn nìkan ni Jésù gbé fún àwọn arákùnrin rẹ̀ tó wà ní Símínà, kò sọ pé ohun kan kù díẹ̀ káàtó nípa wọn. Wọ́n ti jìyà gan-an nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Tálákà ni wọ́n, wọn ò ní ohun ìní tara, ó sì ṣeé ṣe kíyẹn jẹ́ nítorí ìṣòtítọ́ wọn. (Hébérù 10:34) Àwọn ohun tẹ̀mí ló jẹ wọn lógún jù, wọ́n sì ti kó ìṣúra jọ pa mọ́ ní ọ̀run bí ìmọ̀ràn Jésù. (Mátíù 6:19, 20) Nítorí náà, ojú “ọlọ́rọ̀” ni Olórí Olùṣọ́ Àgùntàn fi wò wọ́n—Fi wé Jákọ́bù 2:5.
4. Àwọn wo ló ṣe àtakò púpọ̀ sí àwọn Kristẹni ní Símínà, kí sì ni àwọn alátakò náà jẹ́ lójú Jésù?
4 Ohun kan tí Jésù kíyè sí ni pé àwọn Kristẹni tí wọ́n wà ní Símínà ti fara da ọ̀pọ̀ àtakò táwọn Júù ṣe sí wọn. Ṣáájú ìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹlẹ́sìn Júù wọ̀nyẹn dìídì gbógun ti ìtànkálẹ̀ ìsìn Kristẹni. (Ìṣe 13:44, 45; 14:19) Láìpẹ́ lẹ́yìn tí Jerúsálẹ́mù pa run, àwọn Júù tí wọ́n wà ní Símínà ṣì ń fi ẹ̀mí bíi ti Sátánì yìí hàn. Abájọ tó fi jẹ́ pé “sínágọ́gù Sátánì” ni wọ́n lójú Jésù!a
5. Ìdánwò wo ní ń bẹ níwájú fún àwọn Kristẹni ní Símínà?
5 Pẹ̀lú irú ìkórìíra tí wọ́n ní sáwọn Kristẹni ní Símínà yìí, Jésù tù wọ́n nínú pé: “Má fòyà àwọn ohun tí ìwọ máa tó jìyà rẹ̀. Wò ó! Èṣù yóò máa bá a nìṣó ní sísọ àwọn kan nínú yín sí ẹ̀wọ̀n kí a lè dán yín wò ní kíkún, kí ẹ sì lè ní ìpọ́njú fún ọjọ́ mẹ́wàá. Jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú, dájúdájú, èmi yóò sì fún ọ ní adé ìyè.” (Ìṣípayá 2:10) Nínú ẹsẹ yìí lédè Gíríìkì, ìgbà mẹ́ta ni Jésù lo ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ ẹlẹ́ni púpọ̀ náà, “yín,” èyí tó fi hàn pé ìjọ náà lódindi ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan. Jésù kò ṣèlérí pé àdánwò àwọn Kristẹni ní Símínà yóò dópin láìpẹ́. Àwọn kan lára wọn ò ní yéé jìyà inúnibíni wọ́n á sì sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. Wọ́n á ní ìpọ́njú fún “ọjọ́ mẹ́wàá.” Nọ́ńbà náà, ẹẹ́wàá, dúró fún pátápátá porogodo tàbí ìpé pérépéré nínú àwọn nǹkan ti orí ilẹ̀ ayé. Kódà àwọn olùpàwà-títọ́mọ́ wọ̀nyẹn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí yóò rí ìdánwò tó le gan-an nígbà tí wọ́n ṣì wà nínú ẹran ara.
6. (a) Kí nìdí tí kò fi yẹ káwọn Kristẹni ní Símínà fòyà? (b) Kí ni Jésù fi parí iṣẹ́ tó rán sí ìjọ tó wà ní Símínà?
6 Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kò yẹ káwọn Kristẹni ní Símínà fòyà tàbí juwọ́ sílẹ̀. Bí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ títí dé òpin, “adé ìyè” ni èrè tí wọ́n á rí gbà, fún àwọn, èyí jẹ́ ìwàláàyè àìleèkú ní ọ̀run. (1 Kọ́ríńtì 9:25; 2 Tímótì 4:6-8) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wo ẹ̀bùn iyebíye yìí gẹ́gẹ́ bí ohun tó yẹ láti tìtorí rẹ̀ fi gbogbo nǹkan mìíràn rúbọ, àní ìwàláàyè rẹ̀ ti orí ilẹ̀ ayé pàápàá. (Fílípì 3:8) Ó hàn gbangba pé bó ṣe rí lójú àwọn olùṣòtítọ́ tó wà ní Símínà nìyẹn. Ọ̀rọ̀ tí Jésù fi parí iṣẹ́ tó rán sí wọn ni pé: “Kí ẹni tí ó bá ní etí gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ: Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni ikú kejì kì yóò pa lára lọ́nàkọnà.” (Ìṣípayá 2:11) Ó mú un dá àwọn tó bá ṣẹ́gun lójú pé wọ́n á ní ìyè àìleèkú ní ọ̀run, èyí tí ọwọ́ ikú kò lè tẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 15:53, 54.
“Ìpọ́njú fún Ọjọ́ Mẹ́wàá”
7, 8. Bíi ti ìjọ tó wà ní Símínà, báwo ni ìjọ Kristẹni ṣe di èyí tí a “dán . . . wò ní kíkún” lọ́dún 1918?
7 Bíi tàwọn Kristẹni ní Símínà, ẹgbẹ́ Jòhánù àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn lónìí ni a ti “dán . . . wò ní kíkún,” ìdánwò náà sì ṣì ń bá a lọ. Jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ lábẹ́ àdánwò fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí èèyàn Ọlọ́run. (Máàkù 13:9, 10) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn Kristẹni ní Símínà jẹ́ ojúlówó ìtùnú fáwọn èèyàn Jèhófà kéréje jákèjádò ayé ní kété lẹ́yìn tí ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀. (Ìṣípayá 1:10) Látọdún 1879 làwọn wọ̀nyí ti ń hú ọrọ̀ tẹ̀mí jáde látinú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì ń fún àwọn ẹlòmíràn lára ọrọ̀ tẹ̀mí náà ní fàlàlà. Ṣùgbọ́n nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, wọ́n dojú kọ ìkórìíra àti àtakò gbígbónájanjan nítorí pé wọn kò lọ́wọ́ sí wàhálà ogun náà, àti nítorí pé wọ́n ń fi àìṣojo túdìí àṣírí àṣìṣe àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Wọ́n rí inúnibíni, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ló sì ṣokùnfà rẹ̀. Inúnibíni yìí le gan-an nígbà tó di ọdún 1918, a sì lè fi wé ohun táwọn Júù ní Símínà fojú àwọn Kristẹni tó wà ní Símínà rí.
8 Inúnibíni tó ń wáyé lákòókò náà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bá a débi tó le gan-an nígbà tí wọ́n rán Joseph F. Rutherford tó jẹ́ ààrẹ tuntun fún Watch Tower Society àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ méje lọ sẹ́wọ̀n ní June 22, 1918, ogún [20] ọdún sì ni wọ́n ní ọ̀pọ̀ jù lọ wọn máa lò lẹ́wọ̀n. Ní oṣù mẹ́sàn-án lẹ́yìn náà, wọ́n gba ìdúró wọn wọ́n sì tú wọn sílẹ̀. Ní May 14, 1919, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fagi lé ẹjọ́ tí kò tọ́ tí wọ́n dá fún wọn; wọ́n fi hàn pé àádóje [130] àṣìṣe ló wà nínú ìgbẹ́jọ́ náà. Ní 1918, adájọ́ Manton tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì tó sì jẹ́ abẹnugan nínú ẹgbẹ́ St. Gregory Ńlá kọ̀ láti gba onídùúró àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn. Lẹ́yìn náà, ní 1939, ilé ẹjọ́ dá òun náà lẹ́jọ́, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n ọdún méjì wọ́n sì ní kó sanwó ìtanràn tí iye rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] dọ́là lórí ẹ̀sùn mẹ́fà tí wọ́n fi kàn án pé ó tọrọ owó ó sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
9. Kí ni Hitler fojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí ní Jámánì nígbà ìṣàkóso Násì, báwo lèyí sì ṣe rí lára ẹgbẹ́ àlùfáà?
9 Nígbà ìṣàkóso Násì ní Jámánì, Hitler fòfin de iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pátápátá. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n fi ìwà ìkà sé ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti ẹ̀wọ̀n, níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti kú, wọ́n sì pa nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n kọ̀ láti jà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hitler. Ọ̀rọ̀ àlùfáà Kátólíìkì kan tí wọ́n tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn The German Way ti May 29, 1938 fi hàn pé àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ṣètìlẹyìn fún Ìjọba Hitler láti ṣe gbogbo èyí. Díẹ̀ nínú ohun tí àlùfáà náà sọ ni pé: “Ní báyìí, wọ́n ti fòfin de àwọn tí wọ́n ń pè ní . . . Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì [ìyẹn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] lórílẹ̀-èdè Jámánì . . . Nígbà tí Adolf Hitler gorí àlééfà, Ẹgbẹ́ Àwọn Bíṣọ́ọ̀bù Kátólíìkì ilẹ̀ Jámánì ò yéé béèrè ohun tí wọ́n fẹ́, ni Hitler bá sọ pé: ‘Oníjàngbọ̀n làwọn tí wọ́n ń pè ní Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Onítara [ìyẹn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] wọ̀nyí; . . . afàwọ̀rajà ni wọ́n lójú mi; mi ò lè fàyè gba Judge Rutherford tó jẹ́ ará Amẹ́ríkà yìí láti ba àwọn Kátólíìkì ilẹ̀ Jámánì lórúkọ jẹ́; mo fòpin sí ìsìn [àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] ní Jámánì.’” Àlùfáà náà gbóríyìn fún Hitler fún ohun tó sọ yìí, ó ní: “Sàdáńkátà!”
10. (a) Báwo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fojú winá inúnibíni bí ọjọ́ Olúwa ṣe ń tẹ̀ síwájú? (b) Kí ló sábà máa ń jẹ́ àbájáde rẹ̀ táwa Kristẹni bá jà fún òmìnira ìsìn nílé ẹjọ́?
10 Bí ọjọ́ Olúwa ṣe ń tẹ̀ síwájú, Ejò náà àti irú-ọmọ rẹ̀ ò yéé bá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn jà. Púpọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí ni wọ́n fi sẹ́wọ̀n tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí lọ́nà rírorò. (Ìṣípayá 12:17) Àwọn ọ̀tá wọ̀nyẹn ò yéé ‘fi òfin dìmọ̀ ìwà ìkà,’ ṣùgbọ́n àwa èèyàn Jèhófà ò yẹhùn lórí ọ̀rọ̀ tá a sọ, pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Sáàmù 94:20; Ìṣe 5:29) Lọ́dún 1954, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ pé: ‘Láàárín ogójì ọdún tó kọjá, ó ju àádọ́rin [70] orílẹ̀-èdè lọ tí wọ́n ti ṣe òfin tó ká àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ kò tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí wọn.’ Àwa Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jà fún òmìnira ìsìn nílé ẹjọ́ níbi tó bá ti ṣeé ṣe, a sì ti ṣẹ́gun láwọn orílẹ̀-èdè kan. Ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà nìkan, àádọ́ta [50] ìgbà ni ilé ẹjọ́ ti dá wa láre.
11. Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù wo nípa àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ ló ti ṣẹ sára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọjọ́ Olúwa?
11 Yàtọ̀ sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò tún sí àwọn mìíràn tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn tẹ̀ lé àṣẹ tí Jésù pa pé ká san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì. (Lúùkù 20:25; Róòmù 13:1, 7) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lara wa ni wọ́n ti fi sẹ́wọ̀n ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lábẹ́ onírúurú ìjọba, ó sì ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ títí di ìsinsìnyí ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ní Yúróòpù, ní Áfíríkà, àti ní Éṣíà. Kò tún sí àwọn mìíràn tí wọn fi iye tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nínú wọn sẹ́wọ̀n. Ara ohun tí Jésù sọ nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ńlá nípa àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ ni pé: “Nígbà náà ni àwọn ènìyàn yóò fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́, wọn yóò sì pa yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” (Mátíù 24:3, 9) Dájúdájú, èyí ti ṣẹ sára àwa Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọjọ́ Olúwa.
12. Báwo ni ẹgbẹ́ Jòhánù ṣe fún àwa èèyàn Ọlọ́run lókun láti kojú inúnibíni?
12 Ẹgbẹ́ Jòhánù ń bá a lọ láti rán àwa èèyàn Ọlọ́run létí kókó pàtàkì tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Símínà, ìdí tí wọ́n sì fi ń ṣe èyí ni láti fún wa lókun láti kojú inúnibíni. Bí àpẹẹrẹ, bí inúnibíni Násì ṣe bẹ̀rẹ̀, Ilé Ìṣọ́ gbé àwọn àpilẹ̀kọ kan jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì ní 1933 àti 1934. Irú àwọn àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ ni, “Ẹ Má Bẹ̀rù Wọn,” èyí tó jíròrò Mátíù 10:26-33; “Ìdánwò Lílekoko,” tó dá lórí Dáníẹ́lì 3:17, 18; àti “Ẹnu Àwọn Kìnnìún,” tí wọ́n gbé ka Dáníẹ́lì 6:22. Láàárín ọdún 1980 sí 1989 tó jẹ́ àkókò tá a kọ́kọ́ tẹ ìwé yìí jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì àti àkókò tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fojú winá inúnibíni rírorò ní èyí tó ju ogójì [40] ilẹ̀ lọ, ẹgbẹ́ Jòhánù ti fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ fún àwa èèyàn Ọlọ́run lókun nípasẹ̀ àwọn àpilẹ̀kọ bíi, “Wọn Jẹ Alayọ Bi A Tilẹ̀ Nṣe Inunibini Si Wọn!” àti “Awọn Kristian Nkoju Inunibini Pẹlu Ifarada.”b
13. Bíi tàwọn Kristẹni ní Símínà, kí nìdí táwa Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fi bẹ̀rù inúnibíni?
13 Ní tòdodo, àwa Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jìyà inúnibíni àtàwọn ìdánwò mìíràn fún ọjọ́ mẹ́wàá ìṣàpẹẹrẹ. Bíi tàwọn Kristẹni ní Símínà láyé ọjọ́un, a ò bẹ̀rù; bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ kí ẹnikẹ́ni nínú wa fòyà bí wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ṣe ń burú sí i. A ti múra tán láti fayọ̀ fara da ìjìyà, kódà láti fara dà á tí wọ́n bá ‘kó àwọn ohun ìní wa lọ.’ (Hébérù 10:32-34) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń sọ ọ́ di tara wa, a óò jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́. Jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jèhófà lágbára láti dáàbò bò ọ́ bó o ṣe ń pa ìṣòtítọ́ rẹ mọ́, á sì ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “[Ẹ] kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.”—1 Pétérù 5:6-11.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní nǹkan bí ọgọ́ta [60] ọdún lẹ́yìn tí Jòhánù kú, wọ́n fi iná sun Polycarp ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún [86] ní Símínà nítorí pé ó kọ̀ láti sọ pé òun ò nígbàgbọ́ nínú Jésù mọ́. Ìwé kan tá a gbọ́ pé wọ́n kọ ní àkókò tí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀, tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ The Martyrdom of Polycarp, sọ pé nígbà tí wọ́n ń kó igi tí wọ́n máa fi dá iná náà jọ, “àwọn Júù ràn wọ́n lọ́wọ́, ìtara tó sì pọ̀ lápọ̀jù ni wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn,” bẹ́ẹ̀, “ọjọ́ Sábáàtì ńlá” lọ́jọ́ ìpànìyàn náà bọ́ sí.
b Wo Ilé Ìṣọ́ November 1, 1933 lédè Gẹ̀ẹ́sì; Ilé Ìṣọ́ October 1 àti 15, December 1 àti 15, 1934 lédè Gẹ̀ẹ́sì; Ile-Iṣọ Naa ti November 1, 1983.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 39]
Fún ọ̀pọ̀ ọdún làwọn òpìtàn ti ń jẹ́rìí sí ìdúróṣinṣin àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Jámánì nígbà ìṣàkóso Násì. Ìwé náà Mothers in the Fatherland, láti ọwọ́ òpìtàn Claudia Koonz, tí wọ́n tẹ̀ ní 1986, sọ pé: “Ọ̀kẹ́ àìmọye gbogbo àwọn ará ilẹ̀ Jámánì tí wọn ò sí nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Násì wá ọ̀nà bí wọ́n á ṣe máa gbé lábẹ́ àkóso Násì bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò gba ti àkóso náà. . . . Àmọ́ ní ìhà kejì, ọ̀kẹ́ kan [20,000] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ jálẹ̀ láti gbà pẹ̀lú ohun tí Ìjọba Násì ní kí wọ́n ṣe. . . . Àwọn ló ta yọ nínú àwọn tí wọn para pọ̀ yarí fún Ìjọba Násì, ìsìn wọn sì tì wọ́n lẹ́yìn. Àtìbẹ̀rẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ti gbà fún Ìjọba Násì lọ́nà èyíkéyìí. Kódà nígbà táwọn ọlọ́pàáanú tá a mọ̀ sí Gestapo pa iléeṣẹ́ wọn tó wà ní Jámánì run ní 1933 tí wọ́n sì fòfin de ẹ̀ya ìsìn wọn, síbẹ̀ wọ́n kọ̀ láti sọ pé ‘Heil Hitler’ [tó túmọ̀ sí Ti Hitler Ni Ìgbàlà]. Nǹkan bí ìdajì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà (tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn jẹ́ ọkùnrin) ni wọ́n rán lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, wọ́n pa ẹgbẹ̀rún kan lára wọn, ẹgbẹ̀rún mìíràn sì kú láàárín ọdún 1933 sí 1945. . . . Àwọn àlùfáà Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì ń rọ àwọn ọmọ ìjọ wọn pé kí wọ́n ṣe ohun tí Hitler sọ. Tí wọ́n bá kọ̀, àṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì àti ti Ìjọba ni wọ́n tàpá sí yẹn.”