Ṣafarawe Aanu Ọlọrun Lonii
“Jọwọ jẹ ki a ṣubu, sọ́wọ́ Jehofa, nitori aanu rẹ̀ pọ lọpọlọpọ.”—2 SAMUẸLI 24:14, NW.
1. Bawo ni Dafidi ṣe nimọlara nipa aanu Ọlọrun, eesitiṣe?
ỌBA DAFIDI mọ̀ lati inu iriri pe Jehofa jẹ alaaanu ju awọn eniyan lọ. Pẹlu igbọkanle pe awọn ọna, tabi ipa ọna Ọlọrun, jẹ eyi ti o dara julọ, Dafidi ni ifẹ ọkan lati kẹkọọ awọn ọna Rẹ̀ ati lati rin ninu otitọ Rẹ. (1 Kironika 21:13; Saamu 25:4, 5) Iwọ ha nimọlara kan naa bii ti Dafidi bi?
2. Iru imọran wo ni Jesu fifunni ni Matiu 18:15-17 nipa bi a ṣe nilati bojuto ẹ̀ṣẹ̀ wiwuwo?
2 Bibeli fun wa ni ijinlẹ oye nipa ironu Ọlọrun, koda lori iru awọn ọran bii ohun ti awa nilati ṣe bi ẹnikan ba dẹṣẹ lodi si wa. Jesu sọ fun awọn apọsteli rẹ̀, awọn ti yoo di alaboojuto Kristian lẹhin naa pe: “Bi arakunrin rẹ ba da ẹ̀ṣẹ̀ kan, lọ ṣí ariwisi rẹ̀ paya laaarin iwọ ati oun nikan. Bi o ba fetisilẹ si ọ, iwọ ti jèrè arakunrin rẹ.” Iwa aitọ naa ti o mulọwọ nihin-in kii wulẹ ṣe aṣiṣe ara ẹni ṣakala kan ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ wiwuwo, iru bii jìbìtì tabi ibanijẹ. Jesu wi pe bi igbesẹ yii ko ba yanju ọran naa ti awọn ẹlẹrii ba si wa larọọwọto, ẹni naa ti a ṣẹ̀ si nilati mu wọn dani lọ lati fi ẹ̀rí hàn pe ohun kan wà tí kò tọ́. Eyi ha jẹ igbesẹ ikẹhin ti a lè gbé bi? Bẹẹkọ. “Bi [ẹlẹṣẹ naa] ko ba fetisilẹ si wọn, sọ fun ijọ. Bi oun ko ba fetisilẹ si ijọ paapaa, jẹ ki o dabi eniyan awọn orilẹ-ede ati gẹgẹ bi agbowo ode kan si ọ.”—Matiu 18:15-17, NW.
3. Ki ni ohun ti Jesu nilọkan nigba ti o wi pe alaitọ kan ti kò ronupiwada nilati dabi “eniyan awọn orilẹ-ede ati gẹgẹ bi agbowo ode kan”?
3 Nitori pe Juu ni wọn, awọn apọsteli naa yoo loye ohun ti o tumọsi lati ba ẹlẹṣẹ kan lò “gẹgẹ bi awọn eniyan orilẹ-ede ati gẹgẹ bi agbowo ode.” Awọn Juu maa nyẹra fun ibakẹgbẹpọ pẹlu awọn eniyan orilẹ-ede, ti wọn sì koriira awọn Juu ti wọn nṣiṣẹ gẹgẹ bi agbowo ode fun Roomu.a (Johanu 4:9; Iṣe 10:28) Nipa bayii, Jesu ngba awọn ọmọlẹhin naa nimọran pe bi ijọ ba kọ ẹlẹṣẹ kan silẹ, wọn nilati jawọ kikẹgbẹpọ pẹlu rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, bawo ni iyẹn ṣe baramu pẹlu wíwà ti Jesu maa ńwà pẹlu awọn agbowo ode ni awọn igba miiran?
4. Loju iwoye awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ninu Matiu 18:17, eeṣe ti Jesu fi lè ni ajọṣepọ pẹlu awọn agbowo ode ati awọn ẹlẹṣẹ?
4 Luuku 15:1 wi pe: “Gbogbo awọn agbowo ode ati awọn ẹlẹṣẹ sì sunmọ ọn lati gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.” Kii ṣe olukuluku agbowo ode tabi ẹlẹṣẹ ni o wà nibẹ, ṣugbọn “gbogbo” ní ero-itumọ ti ọpọlọpọ. (Fiwe Luuku 4:40.) Awọn wo ni? Awọn wọnni ti wọn lọkan ifẹ ninu pe ki a dari ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọn. Iru awọn bawọnyi ni a ti fà sunmọ ihin-iṣẹ ironupiwada ti Johanu Arinibọmi ni iṣaaju. (Luuku 3:12; 7:29) Nitori naa nigba ti awọn miiran wá sọdọ Jesu, iwaasu rẹ̀ fun wọn kò tako imọran rẹ̀ ni Matiu 18:17. Ṣakiyesi pe “ọpọ awọn agbowo ode ati ẹlẹṣẹ [fetisi Jesu] wọn sì tọ̀ ọ́ lẹhin.” (Maaku 2:15) Awọn wọnyi kii ṣe awọn ti wọn fẹ lati maa baa lọ ninu ọna igbesi-aye buburu kan, ni kikọ iranlọwọ eyikeyii. Kaka bẹẹ, wọn gbọ́ ihin-iṣẹ Jesu, o si wọ̀ wọn lọkan ṣinṣin. Koda bi wọn ba tilẹ ndẹṣẹ sibẹsibẹ, bi o tilẹ jẹ pe o ṣeeṣe ki wọn maa gbiyanju lati ṣe awọn iyipada, “oluṣọ agutan rere naa” nipasẹ iwaasu rẹ̀ fun wọn nṣafarawe baba rẹ̀ alaaanu.—Johanu 10:14.
Idariji, Iṣẹ Aigbọdọmaṣe Kristian Kan
5. Ipo wo ni Ọlọrun dìmú niti didariji ni?
5 Awa ni awọn idaniloju ọlọyaya wọnyi nipa imuratan Baba wa lati dariji: “Bi awa ba jẹwọ ẹ̀ṣẹ̀ wa, oloootọ ati olododo ni oun lati dari ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wa, ati lati wẹ̀ wá nù kuro ninu aiṣododo gbogbo.” “Iwe nǹkan wọnyi ni mo kọ si yin, ki ẹ ma baa dẹ́ṣẹ̀. Bi ẹnikẹni ba sì dẹṣẹ, awa ni alagbawi lọdọ Baba, Jesu Kristi, olododo.” (1 Johanu 1:9; 2:1) Idariji ha ṣeeṣe fun ẹnikan ti a ti yọ lẹgbẹ bi?
6. Bawo ni a ṣe le dariji ẹni kan ti a ti yọ lẹgbẹ ki a sì gbà á sipo pada?
6 Bẹẹni. Ni akoko ti a yọ ẹnikan lẹgbẹ fun ẹ̀ṣẹ̀ ti kò ronu piwada rẹ̀, awọn alagba ti o ṣoju fun ijọ naa ṣalaye fun un pe o ṣeeṣe fun un lati ronupiwada ki o sì gba idariji Ọlọrun. O lè wá si awọn ipade ni Gbọngan Ijọba, nibi ti oun ti lè gbọ́ awọn itọni Bibeli ti o lè ràn án lọwọ lati ronupiwada. (Fiwe 1 Kọrinti 14:23-25.) Bi akoko ṣe nlọ o lè wá ọna fun ìgbàsípò padà ninu ijọ mimọ tonitoni naa. Nigba ti awọn alagba yoo ba pade pọ pẹlu rẹ̀ lẹhin naa, wọn yoo gbiyanju lati pinnu yala oun ti ronupiwada ti o sì ti fi ipa ọna ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ silẹ. (Matiu 18:18) Bi iyẹn ba jẹ ipo ọran naa, oun ni a lè gbàsípò padà, ni ìlà pẹlu awokọṣe naa ti o wà ninu 2 Kọrinti 2:5-8. Bi o ba ṣẹlẹ pe a ti yọ ọ́ lẹgbẹ fun ọpọlọpọ ọdun, oun yoo nilati ṣe isapa alaapọn lati tẹsiwaju. Oun tun le nilo iranlọwọ ti o pọ̀ lẹhin naa lati mu ìmọ̀ Bibeli rẹ̀ ati imọriri dagba soke ki oun baa le di Kristian alagbara nipa tẹmi.
Pipada Sọdọ Jehofa
7, 8. Awokọṣe wo ni Ọlọrun fi lelẹ ni isopọ pẹlu awọn eniyan rẹ̀ ti a kó lọ ni igbekun?
7 Ṣugbọn njẹ awọn alagba funraawọn le gbe igbesẹ idanuṣe eyikeyii ni lilọ sọdọ ẹnikan ti a ti yọ lẹgbẹ? Bẹẹni. Bibeli fihan pe aanu ni a nfihan kii wulẹ ṣe nipasẹ fifawọ ijiya sẹhin ṣugbọn lọpọ igba nipasẹ awọn igbesẹ ti o fidi mulẹ. Awa ni apẹẹrẹ Jehofa. Ṣaaju ki o to ran awọn eniyan rẹ̀ alaiṣootọ lọ sinu igbekun, oun lọna asọtẹlẹ nawọ ireti naa jade fun ipadabọ wọn: “Ranti awọn nǹkan wọnyi, Óò Jakọbu, ati iwọ, Óò Israẹli, nitori pe iwọ jẹ iranṣẹ mi. . . . Emi yoo pa irelana kọja rẹ̀ kuro gan-an gẹgẹ bi pẹlu awọsanma kan, ati ẹṣẹ rẹ gan-an gẹgẹ bi pẹlu iwọjọpọ awọsanma. Pada sọdọ mi, nitori emi yoo rà ọ́ pada.”—Aisaya 44:21, 22, NW.
8 Nigba naa, ni akoko lilọ si igbekun naa, Jehofa gbe awọn igbesẹ siwaju sii, ni hihuwa lọna ifojusọna fun rere. Oun ran awọn wolii, awọn aṣoju rẹ̀, lati kesi Israẹli lati ‘wa oun ki wọn sì ri oun.’ (Jeremaya 29:1, 10-14) Ni Esekiẹli 34:16 (NW), oun fi araarẹ̀ wé oluṣọ agutan kan o si fi awọn eniyan orilẹ-ede Israẹli we agutan ti o sọnu: “Eyi ti o sọnu ni emi yoo wa kiri, ati eyi ti a fọn kaakiri ni emi yoo mu pada wa.” Ni Jeremaya 31:10, Jehofa pẹlu lo ara rẹ̀ lọna ifamiṣapẹẹrẹ lati jẹ oluṣọ agutan awọn ọmọ Israẹli. Bẹẹkọ, oun kò fi ara rẹ̀ hàn gẹgẹ bi oluṣọ agutan kan ti o wà ni ọgbà agutan ti o nduro de awọn ti o sọnu lati pada wa; kaka bẹẹ, oun fi ara rẹ̀ hàn gẹgẹ bi oluṣọ agutan ti nwa awọn ti o ti sọnu kiri. Ṣakiyesi pe koda nigba ti awọn eniyan naa ni gbogbogboo jẹ alaironupiwada ti a sì rán wọn lọ si igbekun, Ọlọrun fi idanuṣe sapa lati ṣe iwakiri fun ipadabọ wọn. Ati ni ìlà pẹlu Malaki 3:6, Ọlọrun ki yoo yi ọna ibalo rẹ̀ pada ninu iṣeto Kristian.
9. Bawo ni apẹẹrẹ Ọlọrun ṣi di eyi ti a tẹle ninu ijọ Kristian?
9 Eyi ko ha damọran pe idi kan le wa fun awọn igbesẹ ti a danuṣe siha awọn kan ti a ti yọ lẹgbẹ ti wọn si ti le ronupiwada bayii? Ranti pe apọsteli Pọọlu funni ni itọsọna lati yọ ọkunrin buruku naa kuro ninu ijọ Kọrinti. Lẹhin naa oun gba ijọ naa niyanju lati fidi ifẹ wọn mulẹ si ọkunrin naa nitori ironupiwada rẹ̀, ti eyi sì ṣamọna si igbasipo pada rẹ̀ sinu ijọ lẹhin naa.—1 Kọrinti 5:9-13; 2 Kọrinti 2:5-11.
10. (a) Èrò wo ni o nilati sún isapa eyikeyii ṣiṣẹ ninu wa lati ṣebẹwo sọdọ awọn ti a ti yọlẹgbẹ? (b) Eeṣe ti kò fi nii jẹ awọn ibatan Kristian ni ẹni ti yoo lo idanuṣe lati ṣebẹwo?
10 Iwe gbedegbẹyọ ti a fayọ ni ibẹrẹ naa wi pe: ‘Ipilẹ naa ti o ba ọgbọ́n ironu mu fun imukuro jẹ lati daabobo ọpa-idiwọn awujọ naa: “iwukara diẹ ni nmu gbogbo iyẹfun di wiwu” (1 Kọr. 5:6). Ero yii ṣe kedere ninu ọpọ julọ ayọka ọrọ Bibeli ati akọsilẹ iwe mimọ ti o jẹ ojulowo, ṣugbọn idaniyan fun ẹni naa, koda lẹhin iyọkuro, jẹ ipilẹ fun àrọwà Pọọlu ninu 2 Kọr. 2:7-10.’ (Ikọwe italics jẹ tiwa.) Nipa bayii, idaniyan iru eyi ni a nilati fihan lọna ọgbọ́n ironu lonii nipasẹ awọn oluṣọ agutan agbo naa. (Iṣe 20:28; 1 Peteru 5:2) Awọn ọ̀rẹ́ atijọ ati awọn ibatan le reti pe ẹni kan ti a yọ lẹgbẹ yoo pada, sibẹsibẹ nitori ọ̀wọ̀ fun àṣẹ ti o wà ninu 1 Kọrinti 5:11, wọn ki yoo kẹgbẹ pọ pẹlu ẹni kan ti a ti yọ kuro.b Wọn fi silẹ fun awọn oluṣọ agutan ti a yan sipo lati gbe igbesẹ idanuṣe naa lati rii bi iru ẹni bayii ba nifẹẹ ọkan si pipada.
11, 12. Iru awọn ti a yọ kuro wo ni awọn alagba ki yoo fẹ lati bẹ̀wò, ṣugbọn iru awọn wo ni wọn le bẹwo?
11 Ki yoo jẹ ohun ti o ṣerẹgi koda fun awọn alagba lati gbe igbesẹ idanuṣe siha awọn kan bayii ti a ti yọ kuro, iru bii awọn apẹhinda, ti ‘nsọrọ odi, lati fa awọn ọmọlẹhin sẹhin wọn.’ Awọn wọnyi jẹ ‘olukọ eke ti ngbiyanju lati mu ẹ̀yà isin ti npanirun wọle ti wọn yoo sì maa ko ijọ naa nífà pẹlu awọn ọ̀rọ̀ ayederu.’ (Iṣe 20:30; 2 Peteru 2:1, 3, NW) Bibeli pẹlu kò pese ipilẹ eyikeyii fun iṣawari awọn kan ti a ti yọ lẹgbẹ ti wọn jẹ aríjàgbà tabi ti wọn nfi aapọn fun iwa aitọ niṣiiri.—2 Tẹsalonika 2:3; 1 Timoti 4:1; 2 Johanu 9-11; Juuda 4, 11.
12 Bi o ti wu ki o ri, ọpọlọpọ awọn ẹni ti a yọ kuro ni ko ri bayii. Ẹni kan ti le dawọ iwa-aitọ wiwuwo ti a fi yọ ọ́ lẹgbẹ duro. Ẹlomiran ti le maa lo tábà, tabi o ti lè maa mu ọtí amupara ni awọn akoko ti o ti kọja, ṣugbọn oun bayii ko gbiyanju lati ṣamọna awọn miiran sinu iwa aitọ. Ranti pe koda ṣaaju ki Israẹli ti o wà ni igbekun to yipada si Ọlọrun, oun rán awọn aṣoju ti ńrọ̀ wọn lati pada wa. Yala Pọọlu tabi awọn alagba ninu ijọ Kọrinti lo idanuṣe lati ṣe ibẹwo sọdọ ọkunrin naa ti a yọlẹgbẹ, Bibeli kò sọ. Nigba ti ọkunrin yẹn ti ronupiwada ti o sì fopin si ìwà palapala rẹ̀, Pọọlu dari ijọ naa lati mú un padabọsipo.
13, 14. (a) Ki ni o fihan pe awọn kan ti a ti yọ kuro lè dahun pada si igbesẹ idanuṣe alaaanu? (b) Bawo ni ẹgbẹ awọn alagba ṣe le ṣeto pe ki a ṣebẹwo?
13 Ni awọn akoko aipẹ yii awọn ipo ọran kan ti wà ninu eyi ti o ṣẹlẹ pe alagba kan ti lọ ba ẹni kan ti a ti yọlẹgbẹ.c Nibi ti o ba ti bojumu, oluṣọ agutan naa ni ṣoki yoo la awọn igbesẹ ti a nilati gbe fun ìgbàsípò padà lẹsẹẹsẹ. Diẹ ninu awọn eniyan bawọnyi ronupiwada ti a sì gbà wọn sipo pada. Iru abajade onidunnu naa fihan pe awọn ẹni ti a ti yọ lẹgbẹ tabi ti wọn mú araawọn kuro lè wà ti wọn yoo dahunpada si iyọsini alaaanu ti a ṣe lati ọwọ́ awọn oluṣọ agutan. Ṣugbọn bawo ni awọn alagba ṣe lè bojuto ọran yii? O pọ̀ tán, lẹẹkan lọdun, ẹgbẹ awọn alagba nilati ṣayẹwo yala iru awọn ẹni bawọnyi wà ti wọn ngbe ni ipinlẹ wọn.d Awọn alagba naa yoo kori afiyesi jọ sori awọn ti a ti mu kuro fun eyi ti o ti ju ọdun kan lọ. Ni ibamu pẹlu awọn ayika ipo naa, bi o ba jẹ ohun ti o ba ọgbọ́n mu, wọn yoo yàn awọn alagba meji (ti a reti pe ki o jẹ awọn wọnni ti wọn jẹ ojulumọ pẹlu ipo ọran naa) lati ṣebẹwo sọdọ iru ẹni bẹẹ. Ibẹwo eyikeyii ni a ki yoo ṣe sọdọ ẹnikẹni ti o fami ẹmi-ironu lilekoko ti o lewu han tabi ti wọn jẹ ki o di mímọ̀ pe awọn kò nilo iranlọwọ.—Roomu 16:17, 18; 1 Timoti 1:20; 2 Timoti 2:16-18.
14 Awọn oluṣọ agutan meji naa lè lò ẹrọ ibanisọrọpọ lati beere nipa ṣiṣe ibẹwo kukuru kan, tabi wọn lè yà ni akoko kan ti o bojumu. Laaarin ibẹwo naa, wọn kò ni lati jẹ ki oju wọn le koko tabi rẹwẹsi ṣugbọn wọn nilati fi pẹlu ọ̀yàyà fi idaniyan alaaanu wọn han. Dipo ṣiṣatunyẹwo ọran ti o ti kọja naa, wọn lè jiroro awọn ọrọ iwe Bibeli iru bii Aisaya 1:18 ati 55:6, 7 ati Jakọbu 5:20. Bi ẹni naa ba lọkan ifẹ si pipada sinu agbo Ọlọrun, wọn lè fi pẹlu aanu ṣalaye awọn igbesẹ ti oun gbọdọ gbe, iru bii kika Bibeli ati awọn itẹjade ti Watch Tower Society ati pipesẹ si awọn ipade ni Gbọngan Ijọba.
15. Ki ni awọn alagba ti wọn nṣe ikesini sọdọ ẹnikan ti a ti yọ lẹgbẹ nilati fi sọ́kàn?
15 Awọn alagba wọnyi yoo nilo ọgbọ́n ati iwoyemọ lati pinnu boya ifihan ironupiwada wà ati boya yoo bọgbọnmu lati tun ṣebẹwo pada. Wọn nilati fi i sọkan, dajudaju, pe awọn kan ti a yọ lẹgbẹ ki yoo ‘sọji si ironupiwada’ lae. (Heberu 6:4-6; 2 Peteru 2:20-22) Lẹhin ibẹwo naa, awọn meji naa yoo fun Igbimọ Iṣẹ-isin Ijọ ni irohin alafẹnusọ ṣoki. Awọn, lẹhin naa, yoo sọ fun ẹgbẹ́ awọn alagba ni ipade wọn ti o tẹle e. Idanuṣe alaaanu ti awọn alagba naa yoo ti fi oju iwoye Ọlọrun han: “Ẹ yipada si ọdọ mi, emi yoo sì yipada si ọ̀dọ̀ yin, ni Oluwa [“Jehofa,” NW] awọn ọmọ ogun wi.”—Malaki 3:7.
Iranlọwọ Alaaanu Miiran
16, 17. Oju wo ni o yẹ ki a fi wo awọn Kristian ti wọn jẹ́ ibatan ẹni kan ti a ti yọ lẹgbẹ?
16 Ki ni nipa ti awa ti a kii ṣe alaboojuto ti a ko sì ni gbe iru igbesẹ idanuṣe bẹẹ siha awọn wọnni ti a ti yọ lẹgbẹ? Ki ni ohun ti awa lè ṣe ti yoo ṣe deedee pẹlu iṣeto yii ati ni iṣafarawe Jehofa?
17 Niwọn igba ti a ba ti yọ ẹnikan lẹgbẹ tabi ti o mu ara rẹ̀ kuro, awa nilati tẹle itọni naa: “Ẹ jawọ ninu kiko ẹgbẹ́ pọ̀ pẹlu ẹnikẹni ti a npe ni arakunrin ti o ba jẹ àgbèrè tabi oniwọra eniyan tabi abọriṣa tabi apẹgan tabi ọmutipara tabi alọnilọwọgba, ki ẹ ma tilẹ ba iru eniyan bẹẹ jẹun.” (1 Kọrinti 5:11, NW) Ṣugbọn itọsọna ti o ba Bibeli mu yii ko ni lati nipa lori oju iwoye wa lori awọn mẹmba idile Kristian ti ngbe pọ pẹlu ẹni kan ti a ti yọlẹgbẹ. Awọn Juu ìgbà atijọ huwapada lọna lilekoko si awọn agbowo ode debi pe ikoriira wọn ni a mu gbooro koda de ọdọ idile agbowo ode naa. Jesu kò fọwọsi iyẹn. Oun sọ pe ẹlẹṣẹ kan ti o kọ iranlọwọ silẹ ni a nilati balo “gẹgẹ bi eniyan awọn orilẹ-ede ati gẹgẹ bi agbowo ode kan”; oun ko sọ wi pe awọn mẹmba idile Kristian ni a nilati balo lọna bẹẹ.—Matiu 18:17, NW.
18, 19. Ki ni awọn ọna diẹ ninu eyi ti awa lè gbà ṣaṣefihan jijẹ Kristian wa siha awọn ibatan oluṣotitọ ti ẹni kan ti a ti yọ kuro?
18 Ni pataki julọ ni o yẹ ki awa ṣetilẹhin fun awọn mẹmba idile naa ti wọn jẹ Kristian oluṣotitọ. Wọn ti lè maa dojukọ irora ati awọn ìdíwọ́ nitori gbigbe ninu ile pẹlu ẹni kan ti a ti yọ kuro ti o sì le maa ko irẹwẹsi ba awọn ilepa tẹmi wọn niti gidi. Oun le yan lati maṣe jẹ ki awọn Kristian ṣe ibẹwo si ile naa; tabi bi wọn ba wa lati ri awọn mẹmba aduroṣinṣin ti wọn wà ninu idile naa, oun lè ṣalaini iwarere tó lati yẹra fun awọn alejo naa. O tun lè ṣediwọ fun awọn isapa idile naa lati lọ si gbogbo ipade Kristian ati awọn apejọ. (Fiwe Matiu 23:13.) Awọn Kristian ti a tipa bayii fi anfaani dù nitootọ lẹtọọsi aanu wa.—2 Kọrinti 1:3, 4.
19 Ọna kan ti awa lè gba nawọ aanu jade jẹ nipa ‘sisọrọ pẹlu itunu’ ki a sì ni ijumọsọrọpọ ti nfunni ni iṣiri pẹlu iru awọn oluṣotitọ bawọnyi ninu agbo idile naa. (1 Tẹsalonika 5:14) Awọn anfaani rere wà pẹlu lati funni ni itilẹhin ṣaaju ati lẹhin awọn ipade, nigba ti a ba wà ninu iṣẹ isin papa tabi nigba ti a ba wa papọ ni awọn akoko miiran. Awa kò nilati mẹnukan iyọnilẹgbẹ ṣugbọn a lè jiroro ọpọlọpọ awọn nǹkan ti ngbeniro. (Owe 25:11; Kolose 1:2-4) Nigba ti awọn alagba yoo maa baa lọ lati ṣe oluṣọ agutan awọn Kristian ninu idile naa, awa lè rii pe awa pẹlu le ṣebẹwo laisi nini ibaṣepọ pẹlu ẹni ti a yọ kuro naa. Bi o ba ṣẹlẹ pe ẹni ti a ti yọ lẹgbẹ naa ba dahun nigba ti a ba nṣebẹwo tabi banisọrọ lori tẹlifoonu, awa wulẹ le beere fun ibatan Kristian naa ti awa fẹ lati ri. Ni awọn igba miiran, awọn mẹmba idile Kristian naa ni o le ṣeeṣe fun lati tẹwọgba ikesini kan si ile wa fun ikẹgbẹpọ. Koko naa ni pe: Awọn—ọ̀dọ́ ati àgbà—jẹ iranṣẹ ẹlẹgbẹ wa, mẹmba ijọ Ọlọrun olufẹ, ti ko yẹ ki a takete si.—Saamu 10:14.
20, 21. Bawo ni awa ṣe nilati nimọlara ki a sì gbegbeesẹ bi a ba gba ẹni kan pada?
20 Agbegbe miiran fun fifi aanu hàn ṣi silẹ nigba ti a ba gba ẹni ti a yọ kuro naa sipo pada. Awọn akawe Jesu tẹnumọ ayọ ti nbẹ ni ọrun nigba ti ‘ẹlẹṣẹ kan ba ronupiwada.’ (Luuku 15:7, 10) Pọọlu kọwe si awọn ara Kọrinti nipa ọkunrin naa ti a ti yọ lẹgbẹ: “Ẹ nilati fi inurere dariji ki ẹ sì tù ú ninu, pe lọna kan ṣaa ki apọju ibanujẹ rẹ̀ ma baa gbe iru eniyan bẹẹ mì. Nitori naa mo gbà yin niyanju ki ẹ mu ifẹ yin daju fún un.” (2 Kọrinti 2:7, 8, NW) Ẹ jẹ ki a fi imọran yẹn silo pẹlu ironu jinlẹ ati tifẹtifẹ ni awọn ọjọ ati awọn ọsẹ lẹhin ti a ti mu ẹni kan padabọ sipo.
21 Akawe Jesu nipa ọmọkunrin onínàákúnàá mu awọn ewu jade ti awa nilati yẹra fun. Arakunrin àgbà naa kò yọ si ìpadà onínàákúnàá naa ṣugbọn o fi ibinu hàn. Njẹ ki awa maṣe dabi iyẹn, ni gbígbin èrò buburu sinu lori iwa aitọ ti o ti kọja tabi ṣiṣaini itẹlọrun nipa bi a ṣe gba ẹni kan sipo pada. Kaka bẹẹ, gongo wa ni lati dabii baba naa, ẹni ti o ṣakawe idahunpada Jehofa. Baba naa layọ pe ọmọkunrin rẹ̀, ti o ti sọnu ti o sì dabi ẹni ti o ti kú gan-an, ni a ri tabi ni o pada walaaye. (Luuku 15:25-32) Ni ibamu pẹlu eyi, awa yoo sọ̀rọ̀ falala pẹlu arakunrin naa ti a gbà sipo pada ti a o sì tipa bẹẹ fún un ni iṣiri. Bẹẹni, awa nilati fihan gbangba pe awa nfi aanu hàn, gẹgẹ bi Baba wa ọrun alaaanu ti ndarijini ti nṣe.—Matiu 5:7.
22. Ki ni o ni ninu fun wa lati ṣafarawe Jehofa Ọlọrun?
22 Ko si iyemeji rara pe bi awa ba fẹ lati ṣe afarawe Ọlọrun wa, awa nilati fi aanu hàn ni ibamu pẹlu awọn aṣẹ ati idajọ ododo rẹ̀. Onisaamu naa ṣapejuwe rẹ̀ lọna bayii: “Oloore ọ̀fẹ́ ni Oluwa [“Jehofa,” NW], o kún fun aanu; o lọ́ra lati binu, o sì ni aanu pupọ. Oluwa [“Jehofa,” NW] ṣeun fun ẹni gbogbo; iyọnu rẹ̀ sì nbẹ lori iṣẹ rẹ̀ gbogbo.” (Saamu 145:8, 9) Iru awokọṣe onifẹẹ wo ni eyi jẹ fun awọn Kristian lati farawe!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Awọn agbowo ode ni pataki ni awujọ awọn Juu ti nbẹ ni Palẹstini tẹmbẹlu fun awọn idi melookan: (1) wọn maa nko owó jọ fun agbara ilẹ okeere ti o gba ilẹ Israẹli, ni titipa bayii ṣe itilẹhin alaiṣe taara fun iwa ika yii; (2) wọn jẹ olokiki buruku alaitẹle ilana iwarere, ti wọn ndi ọlọ́rọ̀ nipasẹ kiko awọn ẹlomiran ti wọn jẹ awọn eniyan wọn tikaraawọn nífà; ati (3) iṣẹ wọn mu ki wọn ni ifarakanra deedee pẹlu awọn Keferi, ti o mu ki wọn di alaimọ niti ọna ijọsin. Ṣiṣaika awọn agbowo ode si ni a ri ninu M[ajẹmu] T[itun] ati iwe itan awọn Juu . . . Ni ibamu pẹlu eyi ti a mẹnukan gbẹhin yii, ikoriira ni a nilati mu gbooro koda si idile agbowo ode.”—The International Standard Bible Encyclopedia.
b Bi o ba ṣẹlẹ pe ninu agbo idile Kristian kan ibatan kan wà ti a ti yọ lẹgbẹ, ẹni yẹn sibẹ yoo ṣì jẹ apakan awọn ajọṣepọ ati igbokegbodo ti a nṣe deedee lati ọjọ de ọjọ ninu agbo ile naa. Eyi lè ni ninu wiwa nibẹ nigba ti a ba ngbe awọn akojọpọ ọ̀rọ̀ nipa tẹmi yẹwo gẹgẹ bi idile kan.—Wo Ilé-ìṣọ́nà ti November 15, 1988, oju-iwe 19 si 20.
c Wo 1991 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, oju-iwe 53 si 54.
d Bi Ẹlẹrii eyikeyii, ninu iwaasu ile-de-ile tabi ni ọna miiran, ba mọ̀ nipa ẹni kan ti a ti yọ lẹgbẹ ti ngbe ninu ipinlẹ naa, oun nilati fi isọfunni yẹn tó awọn alagba leti.
Iwọ Ha Ṣakiyesi Awọn Koko Wọnyi Bi?
◻ Bawo ni awọn Juu ṣe nba awọn agbowo ode ati awọn ẹlẹṣẹ lò, ṣugbọn eeṣe ti Jesu fi ni ibalo pẹlu diẹ ninu awọn wọnyi?
◻ Ki ni ipilẹ Iwe Mimọ ti o wà fun igbesẹ idanuṣe alaaanu ti a gbe siha ọ̀dọ̀ ọpọlọpọ ti o ti sọnu?
◻ Bawo ni ẹgbẹ awọn alagba ṣe lè lo iru idanuṣe bẹẹ, siha ọ̀dọ̀ awọn wo sì ni?
◻ Bawo ni awa ṣe lè fi aanu hàn siha ọ̀dọ̀ awọn wọnni ti a gbà sipo pada ati siha ọdọ awọn idile awọn ẹni ti a ti yọ lẹgbẹ?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]
Ẹnikẹni ti o ba ti fi ìgbà kan ri jẹ apakan ijọ Ọlọrun mimọtonitoni ati alayọ ṣugbọn ti a ti yọlẹgbẹ bayii tabi ti o mu ara rẹ̀ kuro ko nilati duro sinu iru ipo bẹẹ titilọ. Kaka bẹẹ, onitọhun lè ronupiwada ki o sì gbe igbesẹ idanuṣe lati jumọsọrọpọ pẹlu awọn alagba ijọ. Ọna naa lati pada ṣi silẹ.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Garo Nalbandian