Yíyọ̀ Nínú Jèhófà Láìka Àwọn Àdánwò Sí
GẸ́GẸ́ BÍ GEORGE SCIPIO TI SỌ Ọ́
Ní December 1945, mo wà nínú yàrá kan ní ọsibítù, àìsàn tó ń ṣe mí burú débi pé mi ò lè gbéra rárá, ọwọ́ àti ẹsẹ̀ nìkan ló ṣeé gbé. Fún ìgbà díẹ̀ ni mo pè é o, àfi bí àwọn kan ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé bóyá ni màá lè rìn mọ́. Àdánwò burúkú mà lèyí o, fún èmi ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún tí ara mi le pọ́nkípọ́nkí tẹ́lẹ̀! Mo kọ̀ láti gba irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ohun tí mo fẹ́ ṣe pọ̀, àní èmi àti ọ̀gá mi fẹ́ rin ìrìn àjò kan lọ sí ilẹ̀ England lọ́dún tó tẹ̀ lé e.
MO JẸ́ ọ̀kan lára àwọn tí àjàkálẹ̀ àrùn ẹ̀gbà kan kọlù, èyí tó jà ká erékùṣù wa ní St. Helena. Ó pa èèyàn mọ́kànlá, ó sì sọ ọ̀pọ̀ di abirùn. Bí mo ti dùbúlẹ̀ sórí bẹ́ẹ̀dì, ṣe ni mo sáà ń ronú nípa ìgbésí ayé mi kúkúrú àti nípa ọjọ́ ọ̀la mi. Bí mo ti ń ronú o, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé, láìka ìpọ́njú tí mo ní sí, ìdí ṣì wà fún mi láti kún fún ayọ̀.
Báa Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Wẹ́rẹ́
Lọ́dún 1933 tí mo jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún, Tom, baba mi, ọlọ́pàá tó tún jẹ́ díákónì nínú Ìjọ Onítẹ̀bọmi, gba àwọn ìwé kan lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì. Wọ́n jẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún, tàbí lédè mìíràn, aṣáájú ọ̀nà, tó bẹ erékùṣù wa wò fún ìgbà díẹ̀.
Duru Ọlọrun lorúkọ ọ̀kan lára ìwé náà. Baba mi lò ó láti fi bá ìdílé wa ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì tún fi bá àwọn olùfìfẹ́hàn mélòó kan ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ ló kún inú ìwé náà, ìba ló yé mi mọ. Ṣùgbọ́n mo rántí pé nínú Bíbélì tèmi, mo sàmì sí gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a jíròrò. Kò pẹ́ tí baba mi fi mọ̀ dájú pé òtítọ́ lohun táa ń kẹ́kọ̀ọ́, ó yàtọ̀ sóhun tó ń wàásù nínú Ìjọ Onítẹ̀bọmi. Ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa rẹ̀, ó tún ń kọ́ni látorí àga ìwàásù pé kò sí Mẹ́talọ́kan, kò sí ọ̀run àpáàdì, àti pé kò sí àìleèkú ọkàn. Ni rúgúdù ńlá bá bẹ́ sílẹ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì.
Nígbà tó wá yá, wọ́n pèpàdé ìjọ, láti yanjú ọ̀ràn náà. Wọ́n béèrè pé, “Àwọn wo ló ń ṣe ti Àwọn Onítẹ̀bọmi?” Ọ̀pọ̀ jù lọ fi hàn pé ti Àwọn Onítẹ̀bọmi làwọn ń ṣe. Ìbéèrè tó tẹ̀ lé e ni, “Àwọn wo ló ń ṣe ti Jèhófà?” Èèyàn bí mẹ́wàá tàbí méjìlá fi hàn pé ti Jèhófà làwọn ń ṣe. Wọ́n ní kí àwọn wọ̀nyí fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀.
Bí ẹ̀sìn tuntun kan ṣe bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ ní St. Helena nìyẹn. Baba mi ránṣẹ́ sí orílé iṣẹ́ Watch Tower Society ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, pé kí wọ́n dákun fi ẹ̀rọ agbóhùnjáde ránṣẹ́, tí a óò máa fi gbé ohùn àwọn àsọyé tí wọ́n ti gbà sílẹ̀, jáde sáfẹ́fẹ́. Wọ́n sọ fún un pé ẹ̀rọ náà tóbi ju èyí tí wọ́n lè fi ránṣẹ́ sí St. Helena. Wọ́n wá fi ohun èlò agbóhùnjáde kékeré kan ránṣẹ́, lẹ́yìn náà làwọn ará wá béèrè fún méjì sí i. Wọ́n fi ẹsẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rin erékùṣù náà já, wọ́n ń gbé ìhìn náà lọ bá àwọn ènìyàn.
Bí ìhìn náà ti ń tàn kálẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni àtakò ń tàn kálẹ̀. Níléèwé mi, àwọn ọmọdé á máa kọrin pé: “Ará ilé, èrò ọ̀nà, ẹ wá gbọ́ o, ẹ wá gbọ́ o, ẹgbẹ́ Tommy Scipio ti gbé ẹ̀rọ giramafóònù wọn dé o!” Àdánwò gbáà lèyí jẹ́ fún mi, èmi ọmọléèwé tí mo fẹ́ kí àwọn ojúgbà mi gba tèmi. Kí ló ràn mí lọ́wọ́ láti forí tì í?
Ìdílé wa jẹ́ ti ẹlẹ́ni púpọ̀—àwa mẹ́fà ni ọmọ tó wà níbẹ̀—a máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé déédéé. A tún máa ń ka Bíbélì pa pọ̀ ní àràárọ̀ ká tó jẹun àárọ̀. Kò sí iyèméjì pé èyí ló ran ìdílé wa lọ́wọ́ láti dúró gbọn-in nínú òtítọ́ jálẹ̀ ọdún wọ̀nyẹn. Láti kékeré lèmi tilẹ̀ ti nífẹ̀ẹ́ Bíbélì, àti pé títí di báa ti ń wí yìí, ó ti mọ́ mi lára láti máa ka Bíbélì déédéé. (Sáàmù 1:1-3) Ìgbà tí mo fi máa kúrò níléèwé lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlá, mo ti dúró sán-ún nínú òtítọ́, ìbẹ̀rù Jèhófà sì ti wà nínú ọkàn-àyà mi digbí-digbí. Èyí jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti máa yọ̀ nínú Jèhófà láìka àdánwò wọ̀nyẹn sí.
Àdánwò àti Ayọ̀ Púpọ̀ Sí I
Bí mo ti wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, tí mo ń ronú nípa ọdún àtijọ́ wọnnì, àti ọjọ́ ọ̀la mi, ẹ̀kọ́ tí mo ń kọ́ láti inú Bíbélì jẹ́ kó yé mi pé, àìsàn yìí kì í ṣe ìdánwò tàbí ìjìyà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Jákọ́bù 1:12, 13) Síbẹ̀síbẹ̀, àdánwò burúkú gbáà ni àrùn ẹ̀gbà, nǹkan tó sì ti dá sí àgọ́ ara mi kò lè tán níbẹ̀ títí n óò fi kú.
Bí ara mi ti ń yá bọ̀, ó di dandan kí n tún padà kọ́ ìrìn rírìn. Àwọn iṣan kan ní apá mi tún kọṣẹ́. Àìmọye ìgbà ni mo ń ṣubú lójoojúmọ́. Síbẹ̀, pẹ̀lú àdúrà àtọkànwá àti ìsapá tí kò dáwọ́ dúró, ìgbà tó máa fi di ọdún 1947, mo ti lè fi ọ̀pá rìn.
Ìgbà yẹn ni ìfẹ́ Doris, ọ̀dọ́bìnrin kan táa jọ ní ìgbàgbọ́ kan náà, wọ̀ mí lọ́kàn. A ti kéré jù láti ronú ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n ṣá, mo rí nǹkan kan tó jẹ́ kí n túbọ̀ sapá láti kọ́ ìrìn. Mo tún fi iṣẹ́ mi sílẹ̀, nítorí pé owó oṣù tí wọ́n ń san fún mi kò tóó gbọ́ bùkátà ìyàwó, mo sì dá iléeṣẹ́ ìtọ́jú eyín sílẹ̀, ibẹ̀ ni mo ti ṣiṣẹ́ fọ́dún méjì tó tẹ̀ lé e. A ṣègbéyàwó lọ́dún 1950. Nígbà yẹn, èmi náà ti lówó tí ó tóó fi ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kékeré kan. Wàyí o, mo lè gbé àwọn ará lọ sípàdé àti sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá.
Ìtẹ̀síwájú Ìjọba Ọlọ́run ní Erékùṣù Náà
Ọdún 1951 ni Society rán aṣojú wọn àkọ́kọ́ sí wa. Ẹni náà ni Jacobus van Staden, ọ̀dọ́kùnrin kan láti Gúúsù Áfíríkà. A ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí lọ sí ilé kan tó dáa ni, nítorí náà ó ríbi dé sí lọ́dọ̀ wa fún odindi ọdún kan. Nígbà tó jẹ́ pé iṣẹ́ ara mi ni mo ń ṣe, a jọ lo àkókò púpọ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù, mo sì rí ohun púpọ̀ kọ́ látọ̀dọ̀ rẹ̀.
Jacobus, táwa ń pè ní Koos, ṣètò àwọn ìpàdé ìjọ tó ń lọ déédéé, gbogbo wa sì ń fayọ̀ pésẹ̀ síbẹ̀. Àtidé ìpàdé ọ̀hún mú ìṣòro lọ́wọ́, torí pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ méjì péré ni gbogbo olùfìfẹ́hàn ní. Págunpàgun ni ilẹ̀ ibẹ̀ rí, ó kún fún òkè, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí ọ̀nà tó dáa nígbà yẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ kékeré kọ́ ni rírí sí i pé gbogbo èèyàn pé sípàdé. Ṣe ni àwọn kan máa ń jí sí ìrìn. Màá wá fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi kékeré gbé ẹni mẹ́ta, màá já wọn sí ìdajì ọ̀nà. Wọn á bọ́ọ́lẹ̀, wọ́n á sì máa fẹsẹ̀ rin ìyókù. Màá tún padà lọ kó àwọn mẹ́ta mìíràn, màá já wọn sí ìdajì ọ̀nà, màá tún padà. Bí gbogbo wa pátá ṣe máa ń dé ìpàdé nìyẹn o. Ìgbà típàdé bá parí, bẹ́ẹ̀ la óò tún ṣe kó gbogbo èèyàn padà sílé.
Koos tún kọ́ wa ní ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó gbámúṣé lẹ́nu ọ̀nà. Onírúurú ìrírí la ní, àtèyí tó dáa, àtèyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ dáa. Ṣùgbọ́n ayọ̀ tí a ní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ta yọ gbogbo àdánwò tí àwọn alátakò iṣẹ́ ìwàásù wa fà. Láàárọ̀ ọjọ́ kan, mo ń bá Koos ṣiṣẹ́. Báa ti dẹ́nu ọ̀nà, a gbọ́ ohùn kan nínú ilé. Ọkùnrin kan ló ń ka Bíbélì sókè. Ketekete là ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú Aísáyà orí kejì, tí a mọ̀ bí ẹní mowó. Ìgbà tó kà á dé ẹsẹ̀ kẹrin la kanlẹ̀kùn. Ọkùnrin àgbàlagbà náà fi tẹ̀rín-tẹ̀yẹ ké sí wa wọlé, a sì fi ìwé Aísáyà 2:4 ṣàlàyé ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún un. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tó ń gbé ṣòroó dé gan-an, a bẹ̀rẹ̀ sí bá a kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A ní láti gun òkè kan kọjá, kí a sì gba orí àwọn òkúta tó wà nínú odò kan kọjá, ká tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá gun òkè mìíràn, ká tó wá sọ̀ kalẹ̀ lọ sílé rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìrìn wa ò já sásán. Àgbàlagbà ẹlẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ yìí tẹ́wọ́ gba òtítọ́, ó sì ṣèrìbọmi. Kí ó lè dé ìpàdé, ọ̀pá méjì ló fi ń tilẹ̀ rìn dé ibi tí mo ti lè fi ọkọ̀ gbé e. Lẹ́yìn náà, ó kú gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí olóòótọ́.
Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá lòdì sí iṣẹ́ wa, ó sì sábà máa ń sọ pé òun á rí i pé wọ́n lé Koos kúrò nílùú. Oṣooṣù ló máa ń pe Koos láti lù ú lẹ́nu gbọ́rọ̀. Fífún tí Koos sábà máa ń fún un ní ìdáhùn tó ṣe tààrà láti inú Bíbélì tilẹ̀ tún máa ń mú kí inú rẹ̀ túbọ̀ ru ṣùṣù. Gbogbo ìgbà tó bá pe Koos, ló máa ń kìlọ̀ fún un pé kó ṣíwọ́ ìwàásù, ṣùgbọ́n gbogbo ìgbà náà ni etí rẹ̀ máa ń gbọ́ ìwàásù. Kò yéé tako iṣẹ́ náà, àní lẹ́yìn tí Koos fi St. Helena sílẹ̀. Bí àìsàn ṣe ki kọmíṣọ́nnà mọ́lẹ̀ nìyẹn o, ni gìrìpá ọkùnrin tó ki pọ́pọ́ọ́pọ́ tẹ́lẹ̀, bá jò pátápátá, ó wá rù keegun. Ni àwọn dókítà bá wá ohun tó ń ṣe é tì. Ìyẹn ló bá kúrò ní erékùṣù náà.
Ìbatisí àti Ìtẹ̀síwájú Láìsọsẹ̀
Lẹ́yìn tí Koos ti wà ní erékùṣù náà fún oṣù mẹ́ta, ó ronú pé àkókò tó láti ṣètò fún ìbatisí. Àtirí odò tó dáa fún lílò dìṣòro. A wá pinnu pé ṣe la óò gbẹ́ kòtò ńlá, táa ó fi sìmẹ́ǹtì rẹ́ ẹ, táa ó sì pọnmi kún un. Ní òru tó ṣáájú ọjọ́ ìrìbọmi, òjò rọ̀, inú wa sì dùn gan-an bílẹ̀ ṣe mọ́ báyìí, táa rí i pé kòtò náà ti kún dẹ́nu.
Koos ló sọ ọ̀rọ̀ ìbatisí láàárọ̀ Sunday yẹn. Nígbà tó sọ pé kí àwa táa ó batisí dìde dúró, àwa mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n la dìde dúró láti dáhùn àwọn ìbéèrè táa sábà máa ń béèrè. Ó jẹ́ àǹfààní wa láti wà lára Àwọn Ẹlẹ́rìí táa kọ́kọ́ batisí ní erékùṣù náà. Ọjọ́ ayọ̀ tó ga jù lọ lọjọ́ yẹn jẹ́ nínú ìgbésí ayé mi, torí pé ẹ̀rù sábà máa ń bà mí pé kí Amágẹ́dọ́nì má lọ dé kí n tó ṣèrìbọmi.
Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ìjọ méjì la dá sílẹ̀, ọ̀kan ní Levelwood, èkejì ní Jamestown. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, mẹ́ta tàbí mẹ́rin lára wa á rin ìrìn àjò kìlómítà mẹ́tàlá lọ sí ìjọ kan, láti lọ darí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn nírọ̀lẹ́ Sátidé. Lẹ́yìn iṣẹ́ ìsìn pápá láàárọ̀ Sunday, a ó padà wá ṣe àwọn ìpàdé kan náà, àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, nínú ìjọ tiwa lọ́sàn-án àti nírọ̀lẹ́. Fún ìdí yìí, àwọn ìgbòkègbodò aláyọ̀ tó jẹ́ ti ìṣàkóso Ọlọ́run máa ń mú ọwọ́ wa dí fọ́fọ́ lópin ọ̀sẹ̀. Ọkàn mi ń fẹ́ gidigidi láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù ní àkókò kíkún, ṣùgbọ́n bùkátà ìdílé ò jẹ́. Nítorí náà, lọ́dún 1952, mo padà sẹ́nu iṣẹ́ ìjọba, mo ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí dókítà eyín.
Lọ́dún 1955, àwọn aṣojú arìnrìn-àjò Society, ìyẹn, àwọn alábòójútó àyíká, bẹ̀rẹ̀ sí ṣèbẹ̀wò sí erékùṣù náà lọ́dọọdún, ilé mi sì ni wọ́n máa ń dé sí lára àkókò ìbẹ̀wò wọn. Wọ́n ní ipa rere lórí ìdílé wa. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ sáà yẹn, ni èmi náà ní àǹfààní nínípìn-ín nínú fífi sinimá mẹ́ta tí Society ṣe hàn yí ká erékùṣù náà.
Àpéjọ Ìfẹ́ Àtọ̀runwá Tó Mìnrìngìndìn
Lọ́dún 1958, láti lè lọ sí Àpéjọ Àgbáyé Ìfẹ́ Àtọ̀runwá ní ìlú New York, mo tún kọ̀wé fiṣẹ́ ìjọba sílẹ̀. Mánigbàgbé ni àpéjọ yẹn jẹ́ nínú ìgbésí ayé mi—ìṣẹ̀lẹ̀ tó fún mi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí láti máa yọ̀ nínú Jèhófà. Nítorí àìsí ohun ìrìnnà púpọ̀ tó ń ná erékùṣù wa, oṣù márùn-ún ààbọ̀ la fi wà ní ìdálẹ̀. Ọjọ́ mẹ́jọ gbáko la fi ṣe àpéjọ náà, ìtòlẹ́sẹẹsẹ sì máa ń bẹ̀rẹ̀ láti aago mẹ́sàn-án àárọ̀ títí di aago mẹ́sàn-án alẹ́. Ṣùgbọ́n kò sú mi rí, bíi kí ilẹ̀ ìpàdé ọjọ́ kejì ti mọ́ ló máa ń ṣe mí. Mo ní àǹfààní ṣíṣojú St. Helena nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà fún ìṣẹ́jú méjì. Àyà mi já gan-an bí mo ti ń bá ogunlọ́gọ̀ ńlá sọ̀rọ̀ ní Pápá Ìṣeré Yankee àti ní Polo Grounds.
Àpéjọ náà fún ìpinnu mi lókun láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. Àsọyé fún gbogbo ènìyàn, “Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso—Òpin Ayé Ha Ti Sún Mọ́lé Bí?,” fúnni níṣìírí gidigidi. Lẹ́yìn àpéjọ náà, a ṣèbẹ̀wò sí oríléeṣẹ́ Society ní Brooklyn, a sì lọ wo gbogbo iléeṣẹ́ ẹ̀rọ. Mo bá Arákùnrin Knorr, tí í ṣe ààrẹ Watch Tower Society nígbà yẹn sọ̀rọ̀ nípa ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ náà ní St. Helena. Ó ní òun máa fẹ́ wá sí erékùṣù náà lọ́jọ́ kan. A mú àwọn kásẹ́ẹ̀tì tí a ká gbogbo àsọyé sí bọ̀, àti sinimá àpéjọ náà, láti ṣàjọpín wọn pẹ̀lú ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́.
Mo Lé Góńgó Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Bá
Bí mo ṣe dé, ni wọ́n ní kí n wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mi àtijọ́ padà, torí pé kò sí dókítà eyín ní erékùṣù náà. Ṣùgbọ́n mo ṣàlàyé pé mo ń gbèrò àtibẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Lẹ́yìn táa fà á lọ fà á bọ̀, a jọ dórí àdéhùn pé mo lè máa ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ mẹ́ta lọ́sẹ̀, ṣùgbọ́n owó oṣù tí wọ́n fẹ́ máa san tún wá pọ̀ ju èyí tí wọ́n ń san nígbà tí mo ń ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ mẹ́fà lọ́sẹ̀. Òótọ́ lọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:33) Fífi ẹsẹ̀ mi tó ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ rìn lọ sókè sódò àwọn ilẹ̀ olókè erékùṣù wa kò rọrùn rárá fún mi. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ṣe aṣáájú ọ̀nà fún ọdún mẹ́rìnlá, mo sì ran ọ̀pọ̀ alájọgbé mi ní erékùṣù náà lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́—dájúdájú ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà lèyí jẹ́.
Lọ́dún 1961, ìjọba fẹ́ rán mi lọ sí àwọn Erékùṣù Fíjì, láti lọ gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún méjì lọ́fẹ̀ẹ́, kí n lè di dókítà eyín tó pegedé. Wọ́n tilẹ̀ sọ pé kí ìdílé mi bá mi lọ. Àdánwò gbáà lèyí o, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí mo rò ó lọ rò ó bọ̀, mo ní mi ò lọ. N kò fẹ́ fi àwọn ará sílẹ̀ fún àkókò tó gùn tó yẹn, kí n sì pa àǹfààní tí mo ní láti sìn pẹ̀lú wọn tì. Dókítà àgbà tó ṣètò ìrìn àjò náà bínú rẹpẹtẹ. Ó sọ pé: “Bóo bá rò pé òpin ti sún mọ́lé tó yẹn, o ṣì lè ná owó tí ìwọ yóò pa kí òpin tó dé.” Ṣùgbọ́n mi ò yíhùn padà.
Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n pè mí sí Gúúsù Áfíríkà, fún Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba náà, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí yóò gba oṣù kan fún àwọn alábòójútó ìjọ. Wọ́n fún wa ní ìtọ́ni tó ṣeyebíye tó ràn wá lọ́wọ́ láti bójú tó iṣẹ́ wa nínú ìjọ lọ́nà tó túbọ̀ gbéṣẹ́. Lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́ náà, mo gba àfikún ìdánilẹ́kọ̀ọ́, nípa bíbá alábòójútó arìnrìn-àjò kan ṣiṣẹ́. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ ìjọ méjèèjì tó wà ní St. Helena wò fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí adelé alábòójútó àyíká. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, a rí àwọn arákùnrin mìíràn tó tóótun, a wá ń ṣe é ní àṣegbà.
Láàárín àkókò yìí, a ṣí láti Jamestown lọ sí Levelwood, níbi tí àìní púpọ̀ gbé wà, a sì ṣe ọdún mẹ́wàá níbẹ̀. Nígbà táa ń wí yìí, kòókòó jàn-án jàn-án mi ti pọ̀ jù—mo ń ṣe aṣáájú ọ̀nà, mo ń ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ mẹ́ta lọ́sẹ̀ fún ìjọba, mo tún ṣí ṣọ́ọ̀bù ọjà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Kò tán síbẹ̀ o, mo tún ń jókòó ti ọ̀ràn ìjọ, èmi àti ìyàwó mi sì ń bójú tó ìdílé wa tó ní ọmọ mẹ́rin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà. Kí ọrùn tó wọ̀ mí, mo jáwọ́ nínú iṣẹ́ tí mo ń fi ọjọ́ mẹ́ta ṣe, mo ta ṣọ́ọ̀bù, mo kó gbogbo ìdílé lọ sí Cape Town, ní Gúúsù Áfíríkà, fún ìsinmi oṣù mẹ́ta. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn la wá lọ sí Erékùṣù Ascension, a sì ṣe ọdún kan níbẹ̀. Lákòókò yẹn, a ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ Bíbélì.
Ìgbà táa padà sí St. Helena, a kó padà sí Jamestown. A tún ilé kan tí wọ́n kọ́ mọ́ ara Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe. Láti gbọ́ bùkátà ara wa, èmi àti John ọmọ mi pa ọkọ̀ Ford kan dà di ọkọ̀ ice cream, ọdún márùn-ún gbáko la fi ta ice cream. Kò pẹ́ táa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí tí mo fi wa ọkọ̀ náà jáàmù. Ó tàkìtì, ẹsẹ̀ mi méjèèjì sì há sábẹ́ ọkọ̀. Fún ìdí yìí, gbogbo iṣan tó wà nísàlẹ̀ eékún mi ló kú tipiri, oṣù mẹ́ta kọjá kí ara mi tó kọ́fẹ.
Ìbùkún Yàbùgà-Yabuga Tí Mo Ti Ní àti Èyí Tó Ń Bọ̀
Ìbùkún rẹpẹtẹ ti jẹ́ tiwa láti ọdún wọ̀nyẹn títí di ìsinsìnyí—àfikún ìdí fún ayọ̀ yíyọ̀. Ọ̀kan lára ìwọ̀nyí ni ìrìn àjò wa sí Gúúsù Áfíríkà, láti lọ ṣe àpéjọpọ̀ àṣekárí orílẹ̀-èdè ní ọdún 1985, àti láti ṣèbẹ̀wò sí ilé Bẹ́tẹ́lì, tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́. Òmíràn tún ni ìpín kékeré tí èmi àti John ọmọ mi ní nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ ẹlẹ́wà kan nítòsí Jamestown. A tún láyọ̀ pé mẹ́ta lára àwọn ọmọkùnrin wa ń sìn bí alàgbà, ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ọmọ wa sì ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ní Gúúsù Áfíríkà. Ó sì dájú pé a ti jèrè ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn púpọ̀ nínú ṣíṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gba ìmọ̀ pípéye nípa Bíbélì.
Pápá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa mọ níwọ̀n, kìkì èèyàn bí ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [5,000] ló wà níbẹ̀. Síbẹ̀, ṣíṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ kan náà léraléra ti so èso rere. Ìba díẹ̀ làwọn èèyàn tó ń ṣe láìfí sí wa. A mọ àwọn ará St. Helena sí àwọn tó yá mọ́ni, ṣe ni wọn á máa kí ẹ níbikíbi tóo bá ń lọ—ò báà máa rìn lójú ọ̀nà, ò báà máa wakọ̀ lọ. Ohun tí mo ti rí ni pé, bóo bá ṣe mọ àwọn èèyàn délédélé tó, bẹ́ẹ̀ ni yóò rọrùn tó láti jẹ́rìí fún wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ti ṣí lọ sókè òkun, a ṣì ní àádọ́jọ akéde.
Nítorí pé gbogbo àwọn ọmọ wa ti dàgbà, tí wọ́n sì ti fi ilé sílẹ̀, èmi àti ìyàwó mi nìkan ló kù nílé báyìí, lẹ́yìn ọdún méjìdínláàádọ́ta táa ti ṣègbéyàwó. Ìfẹ́ dídúróṣinṣin àti ìtìlẹ́yìn rẹ̀ ní gbogbo ọdún wọ̀nyí ti ràn mí lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní sísin Jèhófà tayọ̀tayọ̀, láìka àwọn àdánwò sí. Ara wa ti ń dara àgbà, ṣùgbọ́n nípa tẹ̀mí, a ń sọ agbára wa dọ̀tun lójoojúmọ́. (2 Kọ́ríńtì 4:16) Èmi, àti ìdílé mi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi, ń wọ̀nà fún ọjọ́ iwájú alárinrin, nígbà tí ara mi yóò tilẹ̀ tún sàn ju bó ṣe wà nígbà tí mo jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún. Ohun tó wà ní góńgó ẹ̀mí mi ni láti gbádùn ìjẹ́pípé ní gbogbo ọ̀nà, àti lékè gbogbo rẹ̀, láti máa sin Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ tí ń kẹ́ wa, àti Jésù Kristi, Ọba rẹ̀ tí ń jọba, títí láé.—Nehemáyà 8:10.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
George Scipio àti mẹ́ta lára àwọn ọmọ rẹ̀, tí ń sìn bí alàgbà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
George Scipio àti Doris, aya rẹ̀