Fara Wé Jèhófà—Máa Ṣe Òdodo àti Ìdájọ́ Òdodo
“Èmi ni Jèhófà, Ẹni tí ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́, ìdájọ́ òdodo àti òdodo ní ilẹ̀ ayé; nítorí nǹkan wọ̀nyí ni mo ní inú dídùn sí.”—JEREMÁYÀ 9:24.
1. Ìrètí àgbàyanu wo ni Jèhófà nawọ́ rẹ̀ jáde?
JÈHÓFÀ ṣèlérí pé ọjọ́ ń bọ̀ tí olúkúlùkù yóò mọ òun. Nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Aísáyà, ó sọ pé: “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” (Aísáyà 11:9) Ìrètí àgbàyanu yìí mà ga o!
2. Kí ni mímọ Jèhófà wé mọ́? Èé ṣe?
2 Ṣùgbọ́n o, kí ni ó túmọ̀ sí láti mọ Jèhófà? Jèhófà fi ohun tó jà jù han Jeremáyà, ó ní: “Níní . . . ìjìnlẹ̀ òye àti níní . . . ìmọ̀ mi, pé èmi ni Jèhófà, Ẹni tí ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́, ìdájọ́ òdodo àti òdodo ní ilẹ̀ ayé; nítorí nǹkan wọ̀nyí ni mo ní inú dídùn sí.” (Jeremáyà 9:24) Nípa báyìí, láti mọ Jèhófà wé mọ́ mímọ bí ó ṣe ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ òdodo. Bí àwa náà bá ní ànímọ́ wọ̀nyẹn, inú rẹ̀ yóò dùn sí wa. Báwo ni a ṣe lè ní ànímọ́ wọ̀nyẹn? Nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Jèhófà ti tọ́jú àkọsílẹ̀ ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé látayébáyé. Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, a lè wá mọ ọ̀nà òdodo àti ìdájọ́ òdodo Jèhófà, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ fara wé e.—Róòmù 15:4.
Bí Ó Ti Jẹ́ Adájọ́dẹ́tọ̀ọ́ Tó, Ó Tún Jẹ́ Oníyọ̀ọ́nú
3, 4. Èé ṣe tí Jèhófà fi tọ̀nà ní pípa Sódómù àti Gòmórà run?
3 Ìdájọ́ àtọ̀runwá lórí Sódómù àti Gòmórà jẹ́ àpẹẹrẹ tó fakíki, èyí tó ṣàpèjúwe onírúurú ìhà tí ìdájọ́ òdodo Jèhófà ní. Kì í ṣe kìkì pé Jèhófà fi ìyà tó yẹ jẹ wọ́n nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún pèsè ìgbàlà fún àwọn ẹni yíyẹ. Ǹjẹ́ ó tilẹ̀ tọ̀nà kí a pa ìlú wọ̀nyẹn run? Ábúráhámù, tí kò mọ bí ìwà burúkú Sódómù ti gogò tó, kò kọ́kọ́ gbà pé ó tọ̀nà. Jèhófà mú un dá Ábúráhámù lójú pé bí a bá lè rí olódodo mẹ́wàá péré, òun yóò dá ìlú náà sí. Dájúdájú, Jèhófà kì í fi ìwàǹwára gbé ìgbésẹ̀ ìdájọ́ òdodo, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe aláìlójú àánú.—Jẹ́nẹ́sísì 18:20-32.
4 Àbẹ̀wò tí áńgẹ́lì méjì náà ṣe sí Sódómù jẹ́rìí sí i pé ìwàkíwà ìlú náà bùáyà. Nígbà tí àwọn ọkùnrin ìlú náà, “láti orí ọmọdékùnrin dórí àgbà ọkùnrin,” gbọ́ pé ọkùnrin méjì dé sílé Lọ́ọ̀tì, wọ́n rọ́ lu ilé náà pẹ̀lú ète pé kí gbogbo wọn látòkè délẹ̀ fipá bá àwọn ọkùnrin méjì náà lò pọ̀. Háà, ìwàkíwà wọn mà tún gàgaàrá o! Láìsí àní-àní, ìdájọ́ tí Jèhófà mú wá sórí ìlú náà jẹ́ ti ìdájọ́ òdodo.—Jẹ́nẹ́sísì 19:1-5, 24, 25.
5. Báwo ni Ọlọ́run ṣe dá Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ nídè kúrò ní Sódómù?
5 Lẹ́yìn tí Pétérù tọ́ka sí ìparun Sódómù àti Gòmórà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ akini-nílọ̀, ó kọ̀wé pé: “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.” (2 Pétérù 2:6-9) A kì bá tí sọ pé a ti ṣe ìdájọ́ òdodo tó múná dóko ká ní a gbá Lọ́ọ̀tì olódodo àti ìdílé rẹ lọ, pa pọ̀ mọ́ àwọn ará Sódómù aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run. Nítorí èyí, àwọn áńgẹ́lì Jèhófà kìlọ̀ fún Lọ́ọ̀tì nípa ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Nígbà tí Lọ́ọ̀tì ń lọ́ra, “nínú ìyọ́nú Jèhófà,” àwọn áńgẹ́lì náà fa òun, aya rẹ̀, àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ lọ́wọ́ jáde kúrò nílùú náà. (Jẹ́nẹ́sísì 19:12-16) A lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò fi irú àníyàn bẹ́ẹ̀ hàn fún àwọn olódodo nígbà ìparun tí ń bọ̀ wá sórí ètò búburú yìí.
6. Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a dààmú jù nípa ìdájọ́ tí ń bọ̀ wá sórí ètò àwọn nǹkan búburú yìí?
6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òpin ètò yìí yóò jẹ́ àkókò “fún pípín ìdájọ́ òdodo jáde,” kò sídìí fún dídààmú jù. (Lúùkù 21:22) Ìdájọ́ tí Ọlọ́run yóò ṣe ní Amágẹ́dọ́nì yóò jẹ́ “òdodo . . . látòkè délẹ̀.” (Sáàmù 19:9) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ tí Ábúráhámù kọ́, àwa ènìyàn lè gbára lé ìdájọ́ òdodo Jèhófà láìmikàn, nítorí pé ìdájọ́ òdodo rẹ̀ ga fíofío ju tiwa lọ. Ábúráhámù béèrè pé: “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé kì yóò ha ṣe ohun tí ó tọ́ bí?” (Jẹ́nẹ́sísì 18:25; fi wé Jóòbù 34:10.) Tàbí gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti sọ ọ́ ní wẹ́kú, “ta ni ó ń kọ́ [Jèhófà] ní ipa ọ̀nà ìdájọ́ òdodo?”—Aísáyà 40:14.
Ìgbésẹ̀ Òdodo Láti Gba Aráyé Là
7. Ìsopọ̀ wo ló wà láàárín ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run àti àánú rẹ̀?
7 Kì í wá ṣe pé ìgbà tí Ọlọ́run bá fẹ́ fìyà jẹ àwọn olùṣe búburú nìkan ni a máa ń rí ìdájọ́ òdodo rẹ̀. Jèhófà pe ara rẹ̀ ní “Ọlọ́run òdodo àti Olùgbàlà.” (Aísáyà 45:21) Ní gbangba gbàǹgbà, ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ wà láàárín òdodo, tàbí ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, àti ìfẹ́ rẹ̀ láti gba aráyé là lọ́wọ́ ìyọrísí ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The International Standard Bible Encyclopedia, Ẹ̀dà ti ọdún 1982, ń ṣàlàyé lórí ẹsẹ yìí, ó tọ́ka sí i pé “ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ń wá ọ̀nà tó ṣe gúnmọ́ láti gbà fi àánú Rẹ̀ hàn àti láti ṣe ìgbàlà Rẹ̀ parí.” Èyí kò wá túmọ̀ sí pé ó pọndandan kí a fi àánú pẹ̀rọ̀ sí ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, ó túmọ̀ sí pé tàánútàánú ni Ọlọ́run ń ṣe ìdájọ́ òdodo rẹ̀. Pípèsè tí Ọlọ́run pèsè ìràpadà fún ìgbàlà aráyé ni àpẹẹrẹ títayọ jù lọ nínú ọ̀ràn ti ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run yìí.
8, 9. (a) Kí ni àpèjúwe náà, “ìgbésẹ̀ òdodo kan,” we mọ́? Èé ṣe? (b) Kí ni Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ wa?
8 Ohun náà gan-an tí a fi san ìràpadà—ìwàláàyè ṣíṣeyebíye ti Jésù Kristi, Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run—jẹ́ iye tí ó ga gan-an nítorí pé ọ̀pá ìdiwọ̀n Jèhófà kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀, àní òun alára ń tẹ̀ lé ọ̀pá ìdiwọ̀n náà. (Mátíù 20:28) Ìwàláàyè pípé, ti Ádámù, ni a ti pàdánù, nítorí náà ìwàláàyè pípé ni a nílò láti fi tún ìwàláàyè rà padà fún àtọmọdọ́mọ Ádámù. (Róòmù 5:19-21) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ipa ọ̀nà ìwà títọ́ Jésù, títí kan sísan tí ó san ìràpadà, jẹ́ “ìgbésẹ̀ òdodo kan.” (Róòmù 5:18, àlàyé ẹsẹ̀ ìwé) Èé ṣe tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀? Nítorí pé lójú ìwòye Jèhófà, láti ra aráyé padà ni ohun tó tọ̀nà, tó sì bá ìdájọ́ òdodo mu, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ná òun alára kò kéré. Àwọn ọmọ Ádámù dà bí “esùsú . . . tí a ti pa lára,” tí Ọlọ́run kò fẹ́ tẹ̀ fọ́, tàbí bí “òwú àtùpà . . . tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jó lọ́úlọ́ú,” tí kò wù ú láti fẹ́ pa. (Mátíù 12:20) Ọlọ́run ní ìdánilójú pé ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, yóò dìde láti inú àtọmọdọ́mọ Ádámù.—Fi wé Mátíù 25:34.
9 Báwo ló ṣe yẹ kí a dáhùn padà sí ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo tí kò láfiwé yìí? Ọ̀kan lára ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ wa ni pé “kí a ṣe ìdájọ́ òdodo.” (Míkà 6:8) Báwo ni a ṣe lè ṣe èyí?
Máa Wá Ìdájọ́ Òdodo, Máa Lépa Òdodo
10. (a) Kí ni ọ̀nà kan tí a gbà ń ṣe ìdájọ́ òdodo? (b) Báwo ni a ṣe lè máa wá òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́?
10 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a gbọ́dọ̀ máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù ti Ọlọ́run. Nítorí pé ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run jẹ́ òdodo, tó sì bá ìdájọ́ òdodo mu, àwa yóò máa ṣe ìdájọ́ òdodo bí a bá ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n ọ̀hún. Èyí ni ohun tí Jèhófà ń retí láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀. Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ kọ́ ṣíṣe rere; ẹ wá ìdájọ́ òdodo.” (Aísáyà 1:17) Jésù fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ní irú ìmọ̀ràn yẹn nínú Ìwàásù lórí Òkè, nígbà tó sọ fún wọn pé kí wọ́n ‘máa wá ìjọba náà àti òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mátíù 6:33) Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì láti “máa lépa òdodo.” (1 Tímótì 6:11) Bí a bá ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù ti Ọlọ́run, tí a sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, ìyẹn yóò fi hàn pé a ń lépa òdodo àti ìdájọ́ òdodo. (Éfésù 4:23, 24) Lédè mìíràn, a ń wá ìdájọ́ òdodo nípa ṣíṣe àwọn nǹkan lọ́nà ti Ọlọ́run.
11. Èé ṣe tí a fi ní láti gbéjà ko ìjẹgàba ẹ̀ṣẹ̀, báwo sì ni a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
11 Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ ní àmọ̀dunjú, kì í rọrùn fún ènìyàn aláìpé láti ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu, tó sì tọ̀nà. (Róòmù 7:14-20) Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tí ń bẹ ní Róòmù ní ìṣírí pé kí wọ́n gbéjà ko ìjẹgàba ẹ̀ṣẹ̀, kí wọ́n lè jọ̀wọ́ ara wọn, tí wọ́n ti yà sí mímọ́, fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí “ohun ìjà òdodo,” èyí tí yóò wúlò fún Ọlọ́run ní mímú ète rẹ̀ ṣẹ. (Róòmù 6:12-14) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ déédéé àti fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, a lè gba “ìlànà èrò orí Jèhófà” sínú, kí a sì máa ‘bá wa wí nínú òdodo.’—Éfésù 6:4; 2 Tímótì 3:16, 17.
12. Kí ni a ní láti yẹra fún bí a óò bá máa ṣe sí àwọn ẹlòmíràn bí a ti fẹ́ kí Jèhófà máa ṣe sí wa?
12 Èkejì, a ń ṣe ìdájọ́ òdodo bí a bá ń ṣe sí àwọn ẹlòmíràn bí a ti fẹ́ kí Jèhófà máa ṣe sí wa. Ó rọrùn láti ní ọ̀pá ìdiwọ̀n méjì—èyí tó gbọ̀jẹ̀gẹ́ fún ara wa, ṣùgbọ́n èyí tí kò gba gbẹ̀rẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Ó máa ń rọrùn fún wa láti wí àwíjàre lórí àwọn àléébù tiwa, ṣùgbọ́n a kì í pẹ́ ṣe lámèyítọ́ àwọn ẹlòmíràn nítorí àṣìṣe tiwọn, tí ó lè máà tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ tiwa. Jésù béèrè láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi wá ń wo èérún pòròpórò tí ó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n tí o kò ronú nípa igi ìrólé tí ó wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ?” (Mátíù 7:1-3) A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé kò sẹ́ni kankan lára wa tó lè dúró bí Jèhófà bá bẹ̀rẹ̀ sí yẹ àwọn àṣìṣe wa wò fínnífínní. (Sáàmù 130:3, 4) Bí ìdájọ́ òdodo Jèhófà bá gbà á láyè láti gbójú fo àìlera àwọn arákùnrin wa, ta ni àwa jẹ́ láti máa dá wọn lẹ́jọ́?—Róòmù 14:4, 10.
13. Èé ṣe tí ẹni tó jẹ́ olódodo yóò fi kà á sí àìgbọ́dọ̀máṣe láti máa wàásù Ìjọba náà?
13 Ẹ̀kẹta, a ń fi ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ṣèwà hù bí a bá jẹ́ ògbóṣáṣá nínú iṣẹ́ ìwàásù. Jèhófà fún wa ní ìmọ̀ràn pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.” (Òwe 3:27) Kò ní tọ̀nà láti fi òjò ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè, èyí tí Ọlọ́run ti rọ̀ fún wa, mọ sọ́dọ̀ ara wa. Òtítọ́ ni, ọ̀pọ̀ ènìyàn lè kọ ìhìn iṣẹ́ wa, ṣùgbọ́n níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run bá ṣì nawọ́ àánú sí wọn, ṣe ni ó yẹ kí a ṣe tán láti máa fún wọn ní àǹfààní náà kí wọ́n lè “wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Gẹ́gẹ́ bí Jésù, inú wa máa ń dùn nígbà tó bá ṣeé ṣe fún wa láti ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe òdodo àti ìdájọ́ òdodo. (Lúùkù 15:7) Ìsinsìnyí ni àkókò tí ó wọ̀ fún wa láti ‘máa fún irúgbìn ní òdodo.’—Hóséà 10:12.
Àwọn “Ọmọ Aládé fún Ìdájọ́ Òdodo”
14. Ipa wo ni àwọn alàgbà ń kó nínú ọ̀ràn ìdájọ́ òdodo?
14 Gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa tọ ipa ọ̀nà òdodo, ṣùgbọ́n àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristẹni ní ojúṣe pàtàkì nínú ọ̀ràn yìí. Ìṣàkóso ọmọ aládé ti Jésù ni a óò ‘gbé ró nípasẹ̀ ìdájọ́ òdodo àti nípasẹ̀ òdodo.’ Fún ìdí yìí, ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ni ọ̀pá ìdiwọ̀n àwọn alàgbà. (Aísáyà 9:7) Wọ́n ń rántí ohun tí a ṣàpèjúwe lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ nínú Aísáyà 32:1, pé: “Wò ó! Ọba kan yóò jẹ fún òdodo; àti ní ti àwọn ọmọ aládé, wọn yóò ṣàkóso bí ọmọ aládé fún ìdájọ́ òdodo.” Gẹ́gẹ́ bí àwọn alábòójútó tí ẹ̀mí yàn, tàbí “ìríjú Ọlọ́run,” àwọn alàgbà ní láti máa ṣe nǹkan lọ́nà Ọlọ́run.—Títù 1:7.
15, 16. (a) Báwo ni àwọn alàgbà ṣe ń fara wé olùṣọ́ àgùntàn olóòótọ́ inú àkàwé Jésù? (b) Kí ni ìmọ̀lára àwọn alàgbà nípa àwọn tó ti ṣáko lọ nípa tẹ̀mí?
15 Jésù fi hàn pé ìdájọ́ òdodo Jèhófà jẹ́ oníyọ̀ọ́nú, aláàánú, àti agbatẹnirò. Lékè gbogbo rẹ̀, ó gbìyànjú láti ran àwọn tó níṣòro lọ́wọ́, ó sì gbìyànjú “láti wá kiri àti láti gba ohun tí ó sọnù là.” (Lúùkù 19:10) Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn inú àkàwé Jésù tó wá àgùntàn tó sọnù kàn, àwọn alàgbà ń wá àwọn tó ti ṣáko lọ nípa tẹ̀mí rí, wọ́n sì ń sapá láti darí wọn padà sínú agbo.—Mátíù 18:12, 13.
16 Dípò kíka àwọn tó dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo sí aláìwúlò, ṣe ni àwọn alàgbà ń wá ọ̀nà àtiwò wọ́n sàn, kí wọ́n sì ṣamọ̀nà wọn sí ìrònúpìwàdà, bí ó bá ṣeé ṣe. Inú wọ́n máa ń dùn tó bá ṣeé ṣe fún wọn láti ran ẹnì kan tó ti ṣáko lọ lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n o, ó máa ń bà wọ́n nínú jẹ́ tí olùṣe búburú bá kọ̀ tí kò ronú pìwà dà. Nígbà náà, ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Ọlọ́run sọ ọ́ di dandan fún wọn láti yọ aláìronúpìwàdà náà lẹ́gbẹ́. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bíi ti baba ọmọ onínàákúnàá náà, wọ́n ṣì nírètí pé lọ́jọ́ kan, ‘orí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà yóò wálé.’ (Lúùkù 15:17, 18) Nítorí èyí, àwọn alàgbà máa ń gbé ìgbésẹ̀ láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn kan tí a ti yọ lẹ́gbẹ́ láti rán wọn létí bí wọ́n ṣe lè padà sínú ètò àjọ Jèhófà.a
17. Kí ni góńgó àwọn alàgbà nígbà tí wọ́n bá ń gbọ́ ẹjọ́ nípa ìwà àìtọ́, ànímọ́ wo sì ni yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dórí góńgó yìí?
17 Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí àwọn alàgbà fara wé ìdájọ́ òdodo Jèhófà nígbà tí wọ́n bá ń gbọ́ ẹjọ́ nípa ìwà àìtọ́. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ “ń sún mọ́” Jésù “ṣáá” nítorí wọ́n nímọ̀lára pé yóò lóye àwọn, yóò sì ran àwọn lọ́wọ́. (Lúùkù 15:1; Mátíù 9:12, 13) Dájúdájú, kì í ṣe pé Jésù gbọ̀jẹ̀gẹ́ fún ìwà àìtọ́. Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tí Sákéù, tí àwọn èèyàn mọ̀ sí alọ́nilọ́wọ́gbà, bá Jésù jẹun ló sún un láti ronú pìwà dà, tó sì ṣàtúnṣe gbogbo ìpọ́njú tó ti mú bá àwọn ẹlòmíràn. (Lúùkù 19:8-10) Àwọn alàgbà lónìí ní góńgó kan náà nígbà ìgbẹ́jọ́—láti mú kí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ronú pìwà dà. Bí wọ́n bá ṣeé sún mọ́ gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣeé sún mọ́, yóò rọrùn fún ọ̀pọ̀ olùṣe búburú láti wá bá wọn fún ìrànlọ́wọ́.
18. Kí ni yóò jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún àwọn alàgbà láti dàbí “ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù”?
18 Ọkàn-àyà tí ó tètè ń gba tẹni rò yóò ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti ṣe ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, èyí tí kò rorò tàbí kí ó jẹ́ aláìgbatẹnirò. Ó gba àfiyèsí pé, Ẹ́sírà múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀, kì í ṣe èrò inú rẹ̀ nìkan, kí ó bàa lè kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìdájọ́ òdodo. (Ẹ́sírà 7:10) Ọkàn-àyà tí ń gba tẹni rò yóò jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún àwọn alàgbà láti fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ yíyẹ sílò, kí wọ́n sì gba ti ipò olúkúlùkù rò. Nígbà tí Jésù wo obìnrin tó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ sàn, ó fi hàn pé ìdájọ́ òdodo Jèhófà túmọ̀ sí lílóye èrò tí òfin ń gbìn síni lọ́kàn àti ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ pẹ̀lú. (Lúùkù 8:43-48) Àwọn alàgbà tí ń fi ìyọ́nú ṣe ìdájọ́ òdodo ni a lè fi wé “ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù,” fún àwọn tí àìlera tiwọn, tàbí tí ètò burúkú yìí tí a ń gbé inú rẹ̀ ti hàn léèmọ̀.—Aísáyà 32:2.
19. Báwo ni arábìnrin kan ṣe dáhùn padà nígbà tí a mú ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run lò?
19 Arábìnrin kan tó dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo wá mọyì ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ní tààràtà. Ó jẹ́wọ́ pé: “Kí n sòótọ́, ẹ̀rù àtilọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà kọ́kọ́ ń bà mí. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe mí jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, wọ́n sì fi ọ̀wọ̀ mi wọ̀ mí. Àwọn alàgbà dà bí baba, wọn kì í ṣe òṣónú adájọ́. Wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti lóye pé Jèhófà kì yóò kọ̀ mí sílẹ̀ bí mo bá pinnu láti tún ọ̀nà mi ṣe. Mo kẹ́kọ̀ọ́ ní tààràtà nípa bí ó ti ń bá wa wí gẹ́gẹ́ bí Baba onífẹ̀ẹ́. Ó ṣeé ṣe fún mi láti tú ohun tó wà nínú ọkàn-àyà mi jáde fún Jèhófà, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pé yóò gbọ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi. Ní bíbojú wẹ̀yìn, mo lè sọ tòótọ́-tòótọ́ pé ìjókòó èmi àti àwọn alàgbà yẹn ní ọdún méje sẹ́yìn jẹ́ ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Láti ìgbà yẹn, mo ti ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.”
Pa Ìdájọ́ Òdodo Mọ́, sì Máa Ṣe Ohun Tí Í Ṣe Òdodo
20. Kí ni àwọn àǹfààní lílóye àti ṣíṣe òdodo àti ìdájọ́ òdodo?
20 A dúpẹ́ o, pé ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run wé mọ́ ohun tó ju fífún olúkúlùkù ènìyàn ní ohun tó tọ́ sí i. Ìdájọ́ òdodo Jèhófà ti mú kí ó yọ̀ǹda ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́. (Sáàmù 103:10; Róòmù 5:15, 18) Ọlọ́run ń bá wa lò lọ́nà yìí nítorí pé ìdájọ́ òdodo rẹ̀ ń gba ti ipò wa rò, ó sì ń wá ọ̀nà láti gbani là dípò kí ó kani sí aláìwúlò. Ní tòótọ́, lílóye ibi tí ìdájọ́ òdodo Jèhófà nasẹ̀ dé túbọ̀ fà wá sún mọ́ ọn. Bí a sì ti ń làkàkà láti fara wé apá yìí nínú àkópọ̀ ìwà rẹ̀, a ó bù kún ìgbésí ayé wa àti ti àwọn ẹlòmíràn gidigidi. Baba wa ọ̀run kò ní ṣàìfiyèsí lílépa tí a ń lépa ìdájọ́ òdodo. Jèhófà ṣèlérí fún wa pé: “Ẹ pa ìdájọ́ òdodo mọ́, kí ẹ sì máa ṣe ohun tí í ṣe òdodo. Nítorí pé ìgbàlà mi kù sí dẹ̀dẹ̀ kí ó wọlé wá, àti òdodo mi kí a ṣí i payá. Aláyọ̀ ni ẹni kíkú tí ń ṣe èyí.”—Aísáyà 56:1, 2.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Ẹ̀kọ́ wo ni ìparun Sódómù àti Gòmórà kọ́ wa nípa ìdájọ́ òdodo Jèhófà?
◻ Èé ṣe tí ìràpadà fi jẹ́ ìfihàn títayọ ti ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́ Ọlọ́run?
◻ Ọ̀nà mẹ́ta wo ni a lè gbà ṣe ìdájọ́ òdodo?
◻ Ọ̀nà pàtàkì wo ni àwọn alàgbà fi lè fara wé ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Nípa iṣẹ́ ìwàásù wa, a ń fi ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ṣèwà hù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Nígbà tí àwọn alàgbà bá fi ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ṣèwà hù, yóò rọrùn fún àwọn tó níṣòro láti wá bá wọn fún ìrànlọ́wọ́